104 Bible Verses About Fear of the Lord

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Fear of the Lord
  1. 4 Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;

    Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.

    5 Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;

    ojú kò sì tì wọ́n.

    6 Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn rẹ̀;

    ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.

    7 Angẹli Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká

    ó sì gbà wọ́n.

    8 Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;

    ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.

    9 Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́,

    nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

    10 Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n;

    ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.

    11 Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi;

    èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.

    12  Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;

    kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?

    13 Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi

    àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.

    14 Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere;

    wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.

    15 Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo;

    etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn.

  2. 7 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀,

    ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́.

  3. 26 Nínú ìbẹ̀rù Olúwa ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára,

    yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.

    27 Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ orísun ìyè,

    tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.

  4. 26 “Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí kò sí ohun tó ń bọ̀ tí kò ní í fi ara hàn, tàbí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ tí a kò ní mọ̀ ni gbangba. 27 Ohun tí mo bá wí fún yín ní òkùnkùn, òun ni kí ẹ sọ ní ìmọ́lẹ̀. Èyí tí mo sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sì etí yín ni kí ẹ kéde rẹ́ lórí òrùlé. 28 Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó le pa ara nìkan; ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ẹ̀mí. Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí ó le pa ẹ̀mí àti ara run ní ọ̀run àpáàdì. 29 Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan? Síbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lu ilẹ̀ lẹ́yìn Baba yin. 30 Àti pé gbogbo irun orí yín ni a ti kà pé. 31 Nítorí náà, ẹ má ṣe fòyà; ẹ̀yin ní iye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.

  5. 9 kọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i

    kọ́ olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀.

    10 “Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,

    ìmọ̀ nípa Ẹni Mímọ́ ni òye.

    11 Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùn

    ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.

  6. 12 Àwọn wo ni ó bẹ̀rù Olúwa?

    Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.

    13 Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà,

    àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.

    14 Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀;

    ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.

    15 Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa,

    nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.

  7. 10 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:

    òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,

    ìyìn rẹ̀ dúró láé.

  8. 12 “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye;

    mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.

    13 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkórìíra ibi

    mo kórìíra ìgbéraga àti agídí,

    ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

    14 Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi

    mo ní òye àti agbára.

    15 Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso

    tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára.

    16 Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso,

    àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.

    17 Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi,

    àwọn tí ó sì wá mi rí mi.

    18 Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà,

    ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.

  9. 16 Báyìí ni àwa mọ̀, tí a sì gba ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa gbọ́.

    Ìfẹ́ ni Ọlọ́run; ẹni tí ó bá sì ń gbé inú ìfẹ́, ó ń gbé inú Ọlọ́run, àti Ọlọ́run nínú rẹ̀. 17  Nínú èyí ni a mú ìfẹ́ tí ó wà nínú wa pé, kí àwa bà á lè ni ìgboyà ní ọjọ́ ìdájọ́: nítorí pé bí òun tí rí, bẹ́ẹ̀ ni àwa sì rí ni ayé yìí. 18 Ìbẹ̀rù kò sí nínú ìfẹ́; ṣùgbọ́n ìfẹ́ tí ó pé ń lé ìbẹ̀rù jáde; nítorí tí ìbẹ̀rù ni ìyà nínú. Ẹni tí ó bẹ̀rù kò pé nínú ìfẹ́.

    19  Àwa fẹ́ràn rẹ̀ nítorí òun ni ó kọ́ fẹ́ràn wa.

  10. 7 Pípé ni òfin Olúwa,

    ó ń yí ọkàn padà.

    Ẹ̀rí Olúwa dánilójú,

    ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.

    8 Ìlànà Olúwa tọ̀nà,

    ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.

    Àṣẹ Olúwa ni mímọ́,

    ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.

    9 Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́,

    ó ń faradà títí láéláé.

    Ìdájọ́ Olúwa dájú

    òdodo ni gbogbo wọn.

    10 Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ,

    ju wúrà tí o dára jùlọ,

    wọ́n dùn ju oyin lọ,

    àti ju afárá oyin lọ.

    11 Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí;

    nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.

  11. 13 Nísinsin yìí,

    òpin gbogbo ọ̀rọ̀ tí a gbọ́ ni pé,

    bẹ̀rù Ọlọ́run, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́,

    nítorí èyí ni ojúṣe gbogbo ènìyàn.

    14 Nítorí Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ olúkúlùkù iṣẹ́

    àti ohun ìkọ̀kọ̀,

    kì bá à ṣe rere kì bá à ṣe búburú.

  12. 23 Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá;

    nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láìsí ewu.

  13. 28 Àti fún ènìyàn ni ó wí pé,

    “Kíyèsi i, ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n,

    àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.”

  14. 11 Ẹ sin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rù

    ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.

  15. 31 Nígbà náà ni ìjọ wà ni àlàáfíà yíká gbogbo Judea àti ni Galili àti ni Samaria, wọn ń fẹsẹ̀múlẹ̀, wọn ń rìn ní ìbẹ̀rù Olúwa, àti ni ìtùnú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn ń pọ̀ sí i.

  16. 18 Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n ṣìgàṣìgà fún ìbẹ̀rù. 19 Wọ́n wí fún Mose pé, “Ìwọ fúnra rẹ̀ máa bá wa sọ̀rọ̀, àwa yóò sì gbọ́. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kí ó bá wa sọ̀rọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò kú.”

    20 Mose sì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run wá láti dán an yín wò, kí ẹ̀rù Ọlọ́run kí ó lè máa wà ní ara yín, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣẹ̀.”

    21 Àwọn ènìyàn sì dúró ní òkèèrè nígbà tí Mose súnmọ́ ibi òkùnkùn biribiri níbi tí Ọlọ́run wà.

  17. 8 Olúwa ni aláàánú àti olóore,

    ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.

    9 Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo

    bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé,

    10 Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa

    bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́

    bí àìṣedéédéé wa.

    11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,

    bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

    12 Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn

    bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.

    13 Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀,

    bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

  18. 16 Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù Olúwa sì wà

    ju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu.

  19. 6 Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀

    nípasẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi.

  20. 28 Nítorí náà bí àwa tí ń gbà ilẹ̀ ọba ti a kò lè mì, ẹ jẹ́ kí a dá ọpẹ́ nípa èyí ti a fi lè máa sin Ọlọ́run ni ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù rẹ̀. 29  Nítorí pé, “Ọlọ́run wa, iná ti ń jó ni run ni.”

  21. 12 Nítorí náà ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ń gbọ́rọ̀ nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà ti mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n pàápàá nísinsin yìí tí èmi kò sí ni àárín yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì, 13  nítorí pé Ọlọ́run ni ó n ṣiṣẹ́ nínú yín, láti fẹ́ àti láti ṣiṣẹ́ fún ète rere rẹ̀.

  22. 27 Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá,

    ṣùgbọ́n a gé ọjọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú.

    28 Ìrètí olódodo ni ayọ̀,

    ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú jásí òfo.

    29 Ọ̀nà Olúwa jẹ́ ààbò fún olódodo,

    ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń ṣe ibi.

  23. 13 Ẹ máa tẹríba fún gbogbo ìlànà ènìyàn nítorí ti Olúwa, ìbá à ṣe fún ọba tàbí fún olórí. 14 Tàbí fún àwọn baálẹ̀, fún àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbẹ̀san lára àwọn tí ń ṣe búburú, àti fún ìyìn àwọn tí ń ṣe rere. 15 Ìfẹ́ Ọlọ́run sá ni èyí pé, ní rere í ṣe, kí ẹ lè dẹ́kun ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan òmùgọ̀ ènìyàn. 16 Ẹ máa gbé gẹ́gẹ́ bí ẹni òmìnira, ṣùgbọ́n ẹ ma ṣe lo òmìnira yín láti bo ibi mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n kí ẹ gbé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run. 17 Ẹ bọ̀wọ̀ fún gbogbo ènìyàn, ẹ fẹ́ àwọn ará, ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ bọ̀wọ̀ fún ọba.

  24. 12 Nísinsin yìí ìwọ Israẹli, kín ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ọkàn àti àyà rẹ, 13 àti láti máa kíyèsi àṣẹ àti ìlànà Olúwa tí mo ń fún ọ lónìí, fún ìre ara à rẹ.

    14 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.

  25. 1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

    Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,

    tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀.

    2 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé:

    ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún.

    3 Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀;

    òdodo rẹ̀ sì dúró láé.

  26. 11 Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:

    òun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn.

    12 Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Israẹli;

    yóò bùkún ilé Aaroni.

    13  Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,

    àti kékeré àti ńlá.

    14 Olúwa yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú,

    ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀.

    15 Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa

    ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

  27. 1 Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́, bí a ti ní àwọn ìlérí wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí, kí a sọ ìwà mímọ́ dí pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

  28. 6 Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run,

    àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀.

    7 Ó kó àwọn omi òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò;

    ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo.

    8 Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa:

    jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀.

    9 Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀;

    ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin.

  29. Orin fún ìgòkè.

    1 Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa:

    tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

    2 Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ

    ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ.

    3 Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere

    eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ;

    àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.

    4 Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà,

    tí ó bẹ̀rù Olúwa.

  30. 4 “Èmi sì wí fún yín ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó ń pa ara ènìyàn kú, lẹ́yìn èyí, wọn kò sì ní èyí tí wọ́n lè ṣe mọ́. 5  Ṣùgbọ́n èmi ó sì sọ ẹni tí ẹ̀yin ó bẹ̀rù fún yín: Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lágbára lẹ́yìn tí ó bá pànìyàn tan, láti wọ́ ni lọ sí ọ̀run àpáàdì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín òun ni kí ẹ bẹ̀rù.

  31. 5 Ó sì yan àwọn onídàájọ́ sí ilẹ̀ náà, ní olúkúlùkù ìlú olódi Juda. 6 Ó sì wí fun wọ́n pé, “Ẹ kíyèsi ohun tí ẹ̀yin ń ṣe, nítorí ìwọ kò ṣe ìdájọ́ fun ènìyàn ṣùgbọ́n fún Olúwa, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ ní ìdájọ́. 7 Nísinsin yìí jẹ́ kí ìbẹ̀rù Olúwa kí ó wá sí ọkàn rẹ̀. Ṣe ìdájọ́ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, nítorí pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run kò sí àìṣedéédéé tàbí ojúsàájú tàbí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”

  32. 11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,

    èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ;

    fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,

    kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.

    12 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;

    èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé.

  33. 12  “Má ṣe pe èyí ní ọ̀tẹ̀

    gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn yìí pè ní ọ̀tẹ̀,

    má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n bá bẹ̀rù,

    má sì ṣe fòyà rẹ̀.

    13 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ẹni tí ìwọ yóò kà sí mímọ́,

    Òun ni kí o bẹ̀rù

    Òun ni kí àyà rẹ̀ fò ọ́,

    14  Òun yóò sì jẹ́ ibi mímọ́

    ṣùgbọ́n fún ilé Israẹli méjèèjì ni yóò jẹ́, òkúta tí í mú ni kọsẹ̀

    àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú

    àti fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni yóò jẹ́ tàkúté àti ìdẹ̀kùn.

  34. 14 “Ẹ̀yin ti wí pé, ‘Asán ni láti sin Ọlọ́run. Kí ni àwa jẹ ní èrè, nígbà tí àwa ti pa ìlànà rẹ mọ́, tí àwa sì ń rìn kiri bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ní iwájú Olúwa àwọn ọmọ-ogun? 15 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí àwa pé agbéraga ni alábùkún fún. Ní òtítọ́ ni àwọn ti ń ṣe búburú ń gbèrú sí i, kódà àwọn ti ó dán Ọlọ́run wò ni a dá sí.’ ”

    16 Nígbà náà ni àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa ń ba ara wọn sọ̀rọ̀, Olúwa sì tẹ́tí sí i, ó sì gbọ́. A sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀, fún àwọn tí o bẹ̀rù Olúwa, tiwọn sì bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀.

    17 “Wọn yóò sì jẹ́ tèmi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “ni ọjọ́ náà, tí èmi ó dá; èmi yóò sì da wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí máa ń dá ọmọ rẹ̀ tí yóò sìn ín sí. 18 Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rí ìyàtọ̀, ìyàtọ̀ láàrín olódodo àti ẹni búburú, láàrín ẹni tí ń sìn Ọlọ́run, àti ẹni tí kò sìn ín.

  35. 26 Nítorí bí àwa ba mọ̀ ọ́n mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 27  Bí kò ṣe ìrètí ìdájọ́ tí ó ba ni lẹ́rù, àti ti ìbínú ti o múná, tí yóò pa àwọn ọ̀tá run. 28  Ẹnikẹ́ni tí ó ba gan òfin Mose, ó kú láìsí àánú nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta. 29  Mélòó mélòó ni ẹ rò pé a o jẹ ẹni náà ní ìyà kíkan, ẹni tí o tẹ Ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀ tí ó sì ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ti a fi sọ ọ́ di mímọ́ si ohun àìmọ́, tí ó sì ti kẹ́gàn ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́. 30  Nítorí àwa mọ ẹni tí o wí pé, Ẹ̀san ni ti èmi, Olúwa wí pé, “Èmi ó gbẹ̀san.” Àti pẹ̀lú, “Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.” 31 Ohun ẹ̀rù ni láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.

  36. 6 Mo sì rí angẹli mìíràn ń fò ní àárín méjì ọ̀run, pẹ̀lú ìyìnrere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn. 7 Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti Òkun, àti àwọn orísun omi!”

  37. 17 Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ ó ṣe ìlara sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,

    ṣùgbọ́n kí ìwọ ó wà ní ìbẹ̀rù Olúwa,

    ní ọjọ́ gbogbo.

    18 Nítorí pé ìgbẹ̀yìn ń bẹ nítòótọ́;

    ìrètí rẹ̀ kì yóò sì gé kúrò.

  38. 3 Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀,

    Olúwa, tá ni ìbá dúró.

    4 Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ,

    kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.

  39. 1 Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi,

    tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ,

    2 tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n

    tí ìwọ sì fi ọkàn rẹ sí òye,

    3 àní, bí ìwọ bá ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn,

    tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye

    4 bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bí i fàdákà

    tí ìwọ sì wa kiri bí ìṣúra tí a fi pamọ́.

    5 Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù Olúwa,

    ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.

    6 Nítorí Olúwa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n,

    láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá.

  40. 18 Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,

    sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.

    19 Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ;

    ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.

  41. 38  Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn. 39 Èmi ó fún wọn ní ọkàn kan àti ìṣe kí wọn kí ó lè máa bẹ̀rù mi fún rere wọn àti fún rere àwọn ọmọ wọn tí ó tẹ̀lé wọn. 40 Èmi ò bá wọn dá májẹ̀mú ayérayé, èmi kò ní dúró láti ṣe rere fún wọn, Èmi ó sì jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rù mi, wọn kì yóò sì padà lẹ́yìn mi.

  42. 9 Nítorí náà àwa ń ṣakitiyan, pé, bí àwa bá wà ní ilé tàbí bí a kò sí, kí àwa lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. 10 Nítorí pé gbogbo wa ni ó gbọdọ̀ fi ara hàn níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi; kí olúkúlùkù lè gbà èyí tí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó tọ́ sí i nígbà tí ó wà nínú ara ìbá à ṣe rere tàbí búburú.

    11 Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà; ṣùgbọ́n a ń fi wá hàn fún Ọlọ́run; mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hàn ní ọkàn yín pẹ̀lú. 12  Nítorí àwa kò sì ní máa tún yin ara wá sí i yín mọ́, ṣùgbọ́n àwa fi ààyè fún yín láti máa ṣògo nítorí wa, kí ẹ lè ní ohun tí ẹ̀yin yóò fi dá wọn lóhùn, àwọn ti ń ṣògo lóde ara kì í ṣe ní ọkàn. 13 Nítorí náà bí àwa bá ń sínwín, fún Ọlọ́run ni tàbí bí iyè wá bá ṣí pépé, fún yín ni. 14  Nítorí ìfẹ́ Kristi ń rọ̀ wá, nítorí àwa mọ̀ báyìí pé, bí ẹnìkan bá kú fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ nígbà náà, gbogbo wọ́n ni ó ti kú. 15 Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láààyè má sì ṣe wà láààyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde.

  43. 10 Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin,

    bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin

    11 Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

    sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.

  44. 20  Ọgbọ́n kígbe sókè ní pópó

    ó gbé ohùn rẹ̀ sókè láàrín ọjà;

    21 láàrín ọjà ni ó ti kígbe jáde

    ní ibodè ìlú ni ó ti sọ̀rọ̀ ọ rẹ̀:

    22 “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìmọ̀kan yóò fi fẹ́ àìmọ̀kan yín tó?

    Yóò ha ti pẹ́ tó tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò ṣe inú dídùn sí ìpẹ̀gàn tó?

    Àwọn aláìgbọ́n kórìíra ìmọ̀?

    23 Bí ẹ bá ti gbọ́ ìbáwí ì mi ni,

    ǹ bá ti tú ohun tí ó wà nínú ọkàn mi jáde fún yín

    kí n sì fi inú mi hàn sí i yín.

    24 Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pè

    kò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo na ọwọ́ sí wọn,

    25 níwọ́n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi,

    tí ẹ̀yin kò sì gba ìbáwí mi,

    26 Èmi pẹ̀lú yóò fi ìdààmú yín rẹ́rìn-ín;

    èmi yóò ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín.

    27 Nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín bí ìjì líle,

    nígbà tí ìdààmú bá dé bá ọ bí ààjà,

    nígbà tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọkàn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀.

    28 “Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn;

    wọn yóò fi ara balẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi.

    29 Níwọ́n bí wọ́n ti kórìíra ìmọ̀

    tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ̀rù Olúwa.

    30 Níwọ́n bí wọn kò ti gbà ìmọ̀ràn mi

    tí wọ́n sì kẹ́gàn ìmọ̀ràn mi,

    31 wọn yóò jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn

    wọn yóò sì jèrè èso ètè wọn ní kíkún.

  45. 50 Àánú rẹ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

    láti ìrandíran.

  46. 9  Ǹjẹ́ kí ha ni? Àwa ha sàn ju wọn lọ bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, nítorí a fihàn ṣáájú pé àti àwọn Júù àti àwọn Giriki, gbogbo wọn ni ó wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. 10  Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé,

    “Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan,

    11 kò sí ẹni tí òye yé,

    kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run.

    12 Gbogbo wọn ni ó ti yapa,

    wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè;

    kò sí ẹni tí ń ṣe rere,

    kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.”

    13  “Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀fun wọn:

    ahọ́n wọn n sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.”

    “Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.”

    14  “Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.”

    15  “Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀,

    16 ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn.

    17 Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀,”

    18  “Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.”

  47. 23 Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín mú Jordani gbẹ ní iwájú u yín títí ẹ̀yin fi kọjá. Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí Jordani gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Òkun Pupa, nígbà tí ó mú un gbẹ ní iwájú wa títí àwa fi kọjá. 24 Ó ṣe èyí kí gbogbo ayé lè mọ̀ pé ọwọ́ Olúwa ní agbára, àti kí ẹ̀yin kí ó lè máa bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín ní ìgbà gbogbo.”

  48. 5 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ

    má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ.

    6 Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ

    òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ.

    7  Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ

    bẹ̀rù Olúwa kí o sì kórìíra ibi.

  49. 33 Ìbẹ̀rù Olúwa kọ́ ènìyàn ní ọgbọ́n,

    ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ọlá.

  50. 4 Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Olúwa ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè.

  51. 5 A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga,

    Òun yóò kún Sioni pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo.

    6 Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹ

    ibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀;

    ìbẹ̀rù Olúwa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí.

  52. 6 Ǹjẹ́ ó di ọjọ́ kan, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá í pé níwájú Olúwa, Satani sì wá pẹ̀lú wọn. 7 Olúwa sì bi Satani wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?”

    Nígbà náà ní Satani dá Olúwa lóhùn wí pé, “Ní ìlọsíwá-sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”

    8 Olúwa sì sọ fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí í ṣe olóòtítọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti ó sì kórìíra ìwà búburú.”

    9 Nígbà náà ni Satani dá Olúwa lóhùn wí pé, “Jobu ha bẹ̀rù Ọlọ́run ní asán bí?” 10 “Ìwọ kò ha ti ṣọgbà yìí ká, àti yí ilé rẹ̀ àti yí ohun tí ó ní ká, ní ìhà gbogbo? Ìwọ bùsi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì ń pọ̀ si ní ilẹ̀.

  53. 23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ yìn ín!

    Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un!

    Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli!

  54. 18 Wò ó, ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

    àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin.

    19 Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú

    àti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn.

  55. 10 Nígbà náà ni mo tún rí ìsìnkú ènìyàn búburú—àwọn tí wọ́n máa ń wá tí wọ́n sì ń lọ láti ibi mímọ́ kí wọn sì gba ìyìn ní ìlú tàbí tí wọ́n ti ṣe èyí. Eléyìí pẹ̀lú kò ní ìtumọ̀.

    11 Nígbà tí a kò bá tètè ṣe ìdájọ́ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kíákíá, ọkàn àwọn ènìyàn a máa kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ láti ṣe ibi. 12 Bí ènìyàn búburú tó dẹ́ṣẹ̀ nígbà ọgọ́rùn-ún tilẹ̀ wà láààyè fún ìgbà pípẹ́, mo mọ̀ wí pé yóò dára fún ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó bẹ̀rù níwájú rẹ̀. 13 Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dára fún ènìyàn búburú, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fa ọjọ́ rẹ̀ gún tí ó dà bí òjìji, nítorí tí kò bẹ̀rù níwájú Ọlọ́run.

  56. 1  Èèkàn kan yóò sọ láti ibi kùkùté Jese,

    láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan yóò ti so èso.

    2  Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé e,

    ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye,

    ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára,

    ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa.

    3 Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa.

    Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí,

    tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́,

    4 ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní,

    pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu

    fún àwọn aláìní ayé.

    Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀,

    pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.

    5  Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀

    àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká.

  57. 7 Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ sọ fún ara wọn pé, “Wá, ẹ jẹ́ kí a sẹ́ kèké, kí àwa kí o le mọ̀ nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa.” Wọ́n ṣẹ́ kèké, kèké sì mú Jona. 8 Nígbà náà ni wọn wí fún un pé, “Sọ fún wa, àwa bẹ̀ ọ́, nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa? Kí ni iṣẹ́ rẹ? Níbo ni ìwọ ti wá? Kí ni orúkọ ìlú rẹ? Ẹ̀yà orílẹ̀-èdè wo sì ni ìwọ sì í ṣe?”

    9 Òun sì dá wọn lóhùn pé, “Heberu ni èmi, mo sì bẹ̀rù Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run ẹni tí ó dá Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀.”

    10 Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù gidigidi, wọn sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣe èyí?” (Nítorí àwọn ọkùnrin náà mọ̀ pé ó ń sá kúrò ní iwájú Olúwa ni, nítorí òun ti sọ fun wọn bẹ́ẹ̀).

    11 Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Kí ni kí àwa ó ṣe sí ọ kí Òkun lè dákẹ́ fún wa?” Nítorí Òkun ru, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle.

    12 Òun sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì sọ mi sínú Òkun, bẹ́ẹ̀ ni okun yóò sì dákẹ́ fún un yin. Nítorí èmi mọ̀ pé, nítorí mi ni ẹ̀fúùfù líle yìí ṣe dé bá a yín.”

    13 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà gbìyànjú gidigidi láti mú ọkọ̀ wà sí ilẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe é: nítorí tí Òkun túbọ̀ ru sí i, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle sí wọn. 14 Nítorí náà wọ́n kígbe sí Olúwa, wọ́n sì wí pé, “Olúwa àwa bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí àwa ṣègbé nítorí ẹ̀mí ọkùnrin yìí. Má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sí wa ní ọrùn, nítorí ìwọ, Olúwa, ti ṣe bí ó ti wù ọ́.” 15 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé Jona, tí wọ́n sì sọ ọ́ sínú Òkun, Òkun sì dẹ́kun ríru rẹ̀. 16 Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù Olúwa gidigidi, wọn si rú ẹbọ sí Olúwa, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́.

  58. 13  Bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ, Òun nìkan ni kí o sì máa sìn, búra ní orúkọ rẹ̀ nìkan. 14 Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run àwọn tí ó yí i yín ká; 15 torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrín yín, Ọlọ́run owú ni, ìbínú rẹ̀ yóò sì run yín kúrò ní ilẹ̀ náà.

  59. 24 Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé, ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì sìn ín nínú òtítọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn an yín, ẹ kíyèsi ohun ńlá tí ó ti ṣe fún un yín. 25 Síbẹ̀ bí ẹ̀yin bá ń ṣe búburú, ẹ̀yin àti ọba yín ni a ó gbá kúrò.”

  60. 3 Ọlọ́run Israẹli ni,

    àpáta Israẹli sọ fún mi pé,

    ‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo,

    tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

    4 Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là,

    òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu,

    nígbà tí koríko tútù

    bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’

  61. 14 Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run nígbà gbogbo

    ṣùgbọ́n ẹni tí ó sé ọkàn rẹ̀ le bọ́ sínú wàhálà.

  62. 14  Nítorí pé, iye àwọn tí Ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí ni ọmọ Ọlọ́run. 15  Nítorí ẹ̀yin kò tún gba ẹ̀mí ẹrú láti máa bẹ̀rù mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, nípa èyí tí àwa fi ń ké pé “Ábbà, Baba.”

  63. 6 Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń ran ọ létí pé kí ó máa rú ẹ̀bùn Ọlọ́run sókè èyí ti ń bẹ nínú rẹ nípa ìgbọ́wọ́lé mi. 7 Nítorí pé Ọlọ́run kò fún wa ni ẹ̀mí ìbẹ̀rù, bí kò ṣe ti agbára, àti ti ìfẹ́, àti ti ìsẹ́ra-ẹni ti ó yè kooro.

  64. 8 Nígbà náà ni ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ gbọ́ ìró Olúwa Ọlọ́run bí ó ti ń rìn nínú ọgbà, nígbà tí ojú ọjọ́ tura, wọ́n sì fi ara pamọ́ kúrò níwájú Olúwa Ọlọ́run sí àárín àwọn igi inú ọgbà. 9 Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run ké pe ọkùnrin náà pé, “Níbo ni ìwọ wà?”

    10 Ó dáhùn pé, “Mo gbúròó rẹ̀ nínú ọgbà, ẹ̀rù sì bà mí, nítorí pé, mo wà ní ìhòhò, mo sì fi ara pamọ́.”

    11 Ọlọ́run wí pé, “Ta ni ó wí fún ọ pé ìhòhò ni ìwọ wà? Ṣé ìwọ ti jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ ni?”

    12 Ọkùnrin náà wí pé, “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi, ni ó fún mi nínú èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”

    13  Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí?”

    Obìnrin náà dáhùn pé, “Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́.”

  65. 9  Nígbà tí wọn sì dé ibi tí Ọlọ́run sọ fún Abrahamu, ó mọ pẹpẹ kan, ó sì to igi lé e lórí, ó sì di Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì da dùbúlẹ̀ lórí pẹpẹ náà. 10 Abrahamu sì nawọ́ mú ọ̀bẹ, láti dúńbú ọmọ rẹ̀. 11 Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa ké sí i láti ọ̀run wá wí pé “Abrahamu! Abrahamu!”

    Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

    12 Angẹli Olúwa sì wí pé, “Má ṣe fọwọ́ kan ọmọ náà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣe é ni ohun kan. Nísinsin yìí ni mo mọ̀ pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, nítorí pé ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí.”

    13 Abrahamu sì gbójú sókè, ó sì rí àgbò kan tí ó fi ìwo há pàǹtírí, ó sì lọ mú un, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀. 14 Abrahamu sì pe orúkọ ibẹ̀ ni, Jehofah Jire. Bẹ́ẹ̀ ni a sì ń wí títí di òní olónìí pé, “Ní orí òkè Olúwa, ni a ó ti pèsè.”

  66. 17  Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́

    Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

    àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ,

    18 sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́

    àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.

  67. 15 Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa rìn ní ìwà pípé, kì í ṣé bí àwọn òmùgọ̀, ṣùgbọ́n bí àwọn ọlọ́gbọ́n; 16  ẹ máa ra ìgbà padà, nítorí búburú ní àwọn ọjọ́. 17 Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòye ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí. 18 Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurùdu wà; ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. 19  Ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin Ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrin dídùn ní ọkàn yín sí Olúwa. 20 Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo fún ohun gbogbo lọ́wọ́ Ọlọ́run, àní Baba, ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wá.

    21 Ẹ máa tẹríba fún ara yín ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

  68. 7  Nípa ìgbàgbọ́ ni Noa, nígbà ti Ọlọ́run, kìlọ̀ ohun tí a kóò tí ì rí fún un, o bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kan ọkọ̀ fún ìgbàlà ilé rẹ̀, nípa èyí tí ó da ayé lẹ́bi, ó sì di ajogún òdodo tí i ṣe nípa ìgbàgbọ́.

  69. 3  Wọ́n sì ń kọ orin ti Mose, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àti orin ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn, wí pé:

    “Títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ,

    Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè;

    òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀nà rẹ̀,

    ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè.

    4  Ta ni kì yóò bẹ̀rù, Olúwa,

    tí kì yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ̀?

    Nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni mímọ́.

    Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóò sì wá,

    ti yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ,

    nítorí a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn.”

  70. 21 Ṣa àwọn tí ó kún ojú òsùwọ̀n nínú gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti wọ́n jẹ́ olóòtítọ́, tí wọ́n kórìíra ìrẹ́jẹ; yàn wọ́n ṣe olórí, lórí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún, ọgọ́rùn-ún ọgọ́rùn-ún, àádọ́ta-dọ́ta àti mẹ́wàá mẹ́wàá.

  71. 5 Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, Olúwa,

    òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.

    6 Ta ni ó wà ní ọ̀run tí a lè fiwé Olúwa?

    Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fiwé Olúwa?

    7 Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi;

    ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká.

    8 Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ

    ìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa, òtítọ́ rẹ sì yí ọ ká.

  72. 1  Ọkùnrin kan sì wà ni Kesarea ti a ń pè ní Korneliu, balógun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí a ń pè ni Itali. 2 Olùfọkànsìn, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹni tí ó ń tọrẹ àánú púpọ̀ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ń gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo. 3 Níwọ́n wákàtí kẹsànán ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere angẹli Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Korneliu!”

    4 Nígbà tí ó sì tẹjúmọ́ ọn, ti ẹ̀rù sì bà á, ó ní, “Kín ni, Olúwa?”

    Ó sì wí fún un pé, “Àdúrà rẹ àti ọrẹ-àánú, tìrẹ gòkè lọ síwájú Ọlọ́run fún ìrántí. 5 Sì rán ènìyàn nísinsin yìí lọ sí Joppa, kí wọn sì pe Simoni wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru. 6 Ó wọ̀ sí ilé Simoni aláwọ, tí ilé rẹ̀ wà létí Òkun; òun ni yóò sọ fún ọ bí ìwọ ó ti ṣe.”

    7 Nígbà tí angẹli náà tí ó bá Korneliu sọ̀rọ̀ sì fi i sílẹ̀ lọ ó pe méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, àti ọmọ-ogun olùfọkànsìn kan, nínú àwọn ti ó máa ń dúró tì í nígbà gbogbo. 8 Nígbà tí ó sì tí ṣàlàyé ohun gbogbo fún wọn, ó rán wọn lọ sí Joppa.

  73. 34 Peteru sì ya ẹnu rẹ, ó sì wí pé, “Nítòótọ́ mo wòye pé, Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn. 35 Ṣùgbọ́n ni gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, ti ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀.

  74. 5  Ẹ̀yin sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó n ba yin sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé,

    “Ọmọ mi, ma ṣe aláìnání ìbáwí Olúwa,

    kí o má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí a bá ń ti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wí,

    6 nítorí pé ẹni ti Olúwa fẹ́, òun ni i bá wí,

    a sì máa na olúkúlùkù ọmọ tí òun tẹ́wọ́gbà.”

    7 Ẹ máa ní sùúrù lábẹ́ ìbáwí, Ọlọ́run bá wa lò bí ọmọ ni; nítorí pé ọmọ wo ni ń bẹ ti baba kì í bá wí? 8 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, ǹjẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ. 9 Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríba fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè? 10 Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o bá ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n Òun tọ́ wa fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀. 11 Gbogbo ìbáwí kò dàbí ohun ayọ̀ nísinsin yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹyìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo.

  75. 17 Níwọ́n bí ẹ̀yin ti ń ké pe Baba, ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù láìṣe ojúsàájú, ẹ máa lo ìgbà àtìpó yin ni ìbẹ̀rù. 18 Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín padà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín. 19 Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí i ti ọ̀dọ́-àgùntàn ti kò lábùkù, tí kò sì lábàwọ́n, àní, ẹ̀jẹ̀ Kristi. 20 Ẹni tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nítòótọ́ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn ní ìgbà ìkẹyìn wọ̀nyí nítorí yín. 21 Àní ẹ̀yin tí o tipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni ti ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì fi ògo fún un; kí ìgbàgbọ́ àti ìrètí yín lè wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

  76. 1 Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí Olúwa Ọlọ́run yín pàṣẹ fún mi láti kọ́ ọ yín kí ẹ lè kíyèsi i, ní ilẹ̀ náà tí ẹ ó ni lẹ́yìn tí ẹ bá kọjá a Jordani. 2 Kí ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn, lẹ́yìn wọn bá à lè bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín, ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá wà láyé, nípa pípa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ tí mo fún un yín mọ́, kí ẹ bá à lè pẹ́ lórí ilẹ̀.

  77. 1  Báyìí ni Olúwa wí:

    “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,

    ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.

    Níbo ni ilé tí ẹ ó kọ́ fún mi wà?

    Níbo ní ibi ìsinmi mi yóò gbé wà?

    2 Kì í ha á ṣe ọwọ́ mi ló tí ṣe nǹkan wọ̀nyí,

    bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì wà?”

    ni Olúwa wí.

    “Eléyìí ni ẹni tí mo kà sí:

    ẹni náà tí ó rẹra rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì kẹ́dùn ní ọkàn rẹ̀,

    tí ó sì wárìrì sí ọ̀rọ̀ mi.

  78. 18 Ní ọjọ́ kẹta, Josẹfu wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe kí ẹ̀yin ba à le yè nítorí mo bẹ̀rù Ọlọ́run.

  79. 4 Olúwa Ọlọ́run yín ni kí ẹ tẹ̀lé, Òun ni kí ẹ bu ọlá fún, ẹ pa òfin rẹ̀ mọ́ kí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀, ẹ sìn ín, kí ẹ sì dìímú ṣinṣin.

  80. 1 Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Usi, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Jobu; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́, ó dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó kórìíra ìwà búburú.

  81. 19 Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó,

    èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,

    èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn

    tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn.

    20 Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí

    kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn;

    ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu

    kúrò nínú ìjà ahọ́n.

  82. 25 Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹ̀kùn

    ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù Olúwa wà láìléwu.

  83. 19 Àwọn ènìyàn yóò sálọ sínú ihò àpáta

    àti sínú ihò ilẹ̀

    kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa

    àti ògo ọláńlá rẹ̀,

    nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.

    20 Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò máa sọ

    àwọn ère fàdákà àti ère wúrà

    tí wọ́n ti yá fún bíbọ

    sí èkúté àti àwọn àdán.

    21 Wọn yóò sálọ sínú ihò ìsàlẹ̀ àpáta

    àti sínú ihò pàlàpálá àpáta

    kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa

    àti ògo ọláńlá rẹ̀,

    nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.

  84. 17 Ṣùgbọ́n bí a bá ya nínú àwọn ẹ̀ka kúrò, tí a sì lọ́ ìwọ, tí í ṣe igi òróró igbó sára wọn, tí ìwọ sì ń bá wọn pín nínú gbòǹgbò àti ọ̀rá igi olifi náà, 18 má ṣe ṣe féfé sí àwọn ẹ̀ka igi náà. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ṣe féfé, ìwọ kọ́ ni ó rù gbòǹgbò, ṣùgbọ́n gbòǹgbò ni ó rù ìwọ. 19 Ǹjẹ́ ìwọ ó wí pé, “A ti fa àwọn ẹ̀ka náà ya, nítorí kí a lè lọ́ mi sínú rẹ̀.” 20  Ó dára; nítorí àìgbàgbọ́ ni a ṣe fà wọn ya kúrò, ìwọ sì dúró nípa ìgbàgbọ́ rẹ. Má ṣe gbé ara rẹ ga, ṣùgbọ́n bẹ̀rù. 21 Nítorí bí Ọlọ́run kò bá dá ẹ̀ka-ìyẹ́ka sí, kíyèsára kí ó má ṣe ṣe àìdá ìwọ náà sí.

    22 Nítorí náà wo oore àti ìkáàánú Ọlọ́run; lórí àwọn tí ó ṣubú, ìkáàánú; ṣùgbọ́n lórí ìwọ, oore, bi ìwọ bá dúró nínú oore rẹ̀; kí a má bá ké ìwọ náà kúrò. 23 Àti àwọn pẹ̀lú, bí wọn kò bá jókòó sínú àìgbàgbọ́, a ó lọ́ wọn sínú rẹ̀, nítorí Ọlọ́run le tún wọn lọ́ sínú rẹ̀. 24 Nítorí bí a bá ti ké ìwọ kúrò lára igi òróró igbó nípa ẹ̀dá rẹ̀, tí a sì lọ́ ìwọ sínú igi òróró rere lòdì sí ti ẹ̀dá; mélòó mélòó ni a ó lọ́ àwọn wọ̀nyí, tí í ṣe ẹ̀ka-ìyẹ́ka sára igi òróró wọn?

  85. 22 Ẹ̀yin ẹrú, ẹ gbọ́ ti àwọn olówó yín nípa ti ara ní ohun gbogbo; kì í ṣe ní àrọ́júṣe, bí àwọn aláṣehàn ènìyàn; ṣùgbọ́n ní òtítọ́ inú, ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

  86. 19 Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ; ó dára! Àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ̀lú gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì wárìrì.

  87. 13 Tá nì yóò sì ṣe yín ní ibi, bí ẹ̀yin bá jẹ́ onítara sí ohun rere? 14  Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, a ti bùkún yín. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù ìhàlẹ̀ wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú.” 15 Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kristi bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń béèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù. 16 Kí ẹ máa ni ẹ̀rí ọkàn rere bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kristi. 17 Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣíṣe búburú lọ.

  88. 14  “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣépè lé adití, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ fi ohun ìdìgbòlù sí iwájú afọ́jú, ṣùgbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run rẹ. Èmi ni Olúwa.

  89. 29 ìbá ti dára tó, bí ọkàn wọn bá lè bẹ̀rù mi, tí ó sì ń pa gbogbo òfin mi mọ́ nígbà gbogbo, kí ó bá à lè dára fún wọn, àti àwọn ọmọ wọn láéláé.

  90. 20 Ẹ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ sì máa sìn ín. Ẹ dìímú ṣinṣin, kí ẹ sì búra ní orúkọ rẹ̀. 21 Òun ni ìyìn in yín, Òun sì ni Ọlọ́run yín, tí ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá àti ohun ẹ̀rù, tí ẹ fojú ara yín rí.

  91. Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa.

    1  Ìré-òfin-kọjá ènìyàn búburú

    jẹ́ kí n mọ̀ nínú ọkàn mi pé,

    ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí

    níwájú wọn.

    2 Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọn

    títí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra.

    3 Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òhun ẹ̀tàn;

    wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀.

    4 Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn:

    wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára

    wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.

  92. 30 Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán

    nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn.

  93. 14 Mo mọ̀ wí pé ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe ni yóò wà títí láé, kò sí ohun tí a lè fi kún un tàbí kí a yọ kúrò nínú rẹ̀. Ọlọ́run ṣe èyí kí ènìyàn le è ní ìbẹ̀rù rẹ̀ ni.

  94. 10 Wọ inú àpáta lọ,

    fi ara pamọ́ nínú erùpẹ̀

    kúrò nínú ìpayà Olúwa,

    àti ògo ọláńlá rẹ̀!

  95. 1 Ní ọdún tí ọba Ussiah kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ìṣẹ́tí aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. 2 Àwọn Serafu wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò. 3  Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé,

    “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun

    gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”

    4  Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹmpili sì kún fún èéfín.

    5 Mo kígbe pé, “Ègbé ni fún mi! Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ.

  96. 40 Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà?

  97. 5  Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé:

    “Ẹ máa yin Ọlọ́run wa,

    ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo,

    ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

    àti èwe àti àgbà!”

    6 Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńlá ńlá, ń wí pé:

    “Haleluya!

    Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba.

    7  Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi,

    kí a sì fi ògo fún un.

    Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé,

    aya rẹ̀ sì ti múra tán.

    8 Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀

    wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.”

    (Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)

    9 Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”

  98. 17 Ṣùgbọ́n àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọba Ejibiti ti wí fún wọn; wọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wà láààyè.

  99. 18 Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó ṣe àdàkọ àwọn òfin wọ̀nyí sí inú ìwé fún ara rẹ̀, láti inú ti àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi. 19 Èyí yóò sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun ó sì máa kà nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, kí ó lè máa kọ́ àti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, láti máa tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí àti àwọn ìlànà rẹ̀ tọkàntọkàn. 20 Kí ó má ba à lérò pé òun sàn ju àwọn arákùnrin rẹ̀ yòókù lọ, kí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ yípadà kúrò nínú òfin wọ̀nyí sí ọ̀tún tàbí sí òsì. Bẹ́ẹ̀ ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jẹ ọba pẹ́ títí ní Israẹli.

  100. 14 “Nísinsin yìí ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì máa sìn ín ní òtítọ́ àti òdodo. Kí ẹ sì mú òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò Eufurate àti ní Ejibiti kúrò, kí ẹ sì máa sin Olúwa. 15 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fẹ́ láti sin Olúwa, nígbà náà ẹ yàn fún ara yín ní òní ẹni tí ẹ̀yin yóò sìn bóyá òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò Eufurate, tàbí òrìṣà àwọn ará Amori, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé. Ṣùgbọ́n ní ti èmi àti ilé mi, Olúwa ni àwa yóò máa sìn.”

  101. 14 Bí ẹ̀yin bá bẹ̀rù Olúwa àti bí ẹ̀yin bá ń sìn ín, tí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ̀yin kò sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, àti tí ẹ̀yin àti ọba tí ó jẹ lórí yín bá ń tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run yín: ó dára 15 ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gbọ́ tí Olúwa, tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára yín sí ibi, bí ó ti wà lára baba yín.

  102. 9 Nítòótọ́ ìgbàlà rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

    pé kí ògo rẹ̀ kí ó lè gbé ní ilẹ̀ wa.

  103. 19 Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yín

    ìpadàsẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wí

    mọ̀ kí o sì rí i wí pé ibi àti

    ohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹ

    nígbà tí o ti kọ Olúwa Ọlọ́run sílẹ̀,

    ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,”

    ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  104. 22 Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?”

    ni Olúwa wí.

    “Kò ha yẹ kí ẹ̀yin ó wárìrì níwájú mi bí?

    Mo fi yanrìn pààlà òkun,

    èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé.

    Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀;

    wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀.

    23 Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀,

    wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ.

    24 Wọn kò sọ fún ara wọn pé,

    ‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,

    ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀,

    tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédé.’