74 Bible Verses About Safety

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Safety
  1. 17 Ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ, ṣùgbọ́n ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

    18 “ ‘Ẹ tẹ̀lé àwọn ìlànà mi, kí ẹ sì kíyèsi láti pa òfin mi mọ́, kí ẹ ba à le máa gbé láìléwu ní ilẹ̀ náà. 19 Nígbà yìí ni ilẹ̀ náà yóò so èso rẹ̀, ẹ ó sì jẹ àjẹyó, ẹ ó sì máa gbé láìléwu.

  2. 1 Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo

    ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.

    2 Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé,

    “Òun ni ààbò àti odi mi,

    Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.

    3 Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú

    ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ

    àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.

    4 Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí,

    àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;

    òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.

    5 Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,

    tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,

    6 tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn,

    tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.

    7 Ẹgbẹ̀rún (1,000) yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,

    ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,

    ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.

    8 Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ

    àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.

    9 Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ,

    ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.

    10 Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́,

    Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.

    11  Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ

    láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ;

    12 wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,

    nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta.

    13  Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;

    ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

    14 “Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́;

    èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.

    15 Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn;

    èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú,

    èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un.

    16 Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn,

    èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”

  3. 10 Orúkọ Olúwa, ilé ìṣọ́ agbára ni;

    olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.

    11 Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn;

    wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.

    12 Ṣáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga,

    ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.

  4. 6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wa?”

    Olúwa, jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,

    7 Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi

    ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.

    8 Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà,

    nítorí ìwọ nìkan, Olúwa,

    ni o mú mi gbé láìléwu.

  5. 25 Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹ̀kùn

    ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù Olúwa wà láìléwu.

  6. 3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;

    ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.

    4 Olúwa ni mo kígbe sókè sí,

    ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.

    5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;

    mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.

    6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn

    tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.

  7. 5 Olúwa ni olùpamọ́ rẹ;

    Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

    6 Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán

    tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.

    7 Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo

    yóò pa ọkàn rẹ mọ́

    8 Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́

    láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.

  8. 2  nítorí ẹ̀yin pàápàá mọ̀ wí pé ọjọ́ Olúwa yóò wá bí olè lóru. 3  Ní àkókò gan an tí àwọn ènìyàn yóò máa wí pé, “Àlàáfíà àti ààbò,” nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìrọbí obìnrin tí ó lóyún, wọn kò sí ni rí ibi ààbò láti sá sí.

  9. 21 Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́,

    má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn.

    22 Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ,

    àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ.

    23 Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu,

    ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀.

    24 Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù,

    nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀.

    25 Má ṣe bẹ̀rù ìdààmú òjijì,

    tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú.

    26 Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ,

    kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.

  10. 27 Àwọn àgùntàn mi ń gbọ́ ohùn mi, èmi sì mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn. 28  Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun; wọn kì yóò sì ṣègbé láéláé, kò sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi. 29 Baba mi, ẹni tí ó fi wọ́n fún mi pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò sì ṣí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba mi. 30  Ọ̀kan ni èmi àti Baba mi.”

  11. 17 Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára; pé nípasẹ̀ mi kí a lè wàásù náà ní àwàjálẹ̀, àti pé kí gbogbo àwọn aláìkọlà lè gbọ́; a sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún náà. 18 Olúwa yóò yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ búburú gbogbo, yóò sì mu mí dé inú ìjọba ọ̀run. Ẹni ti ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.

  12. 8 Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣe gẹ́gẹ́ bí a tí ṣe níhìn-ín lónìí yìí, tí olúkúlùkù ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú ara rẹ̀. 9 Níwọ́n ìgbà tí ẹ ti dé ibi ìsinmi, àti ibi ogún tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín. 10 Ṣùgbọ́n ẹ ó la Jordani kọjá, ẹ ó sì máa gbé ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín bí ìní, yóò sì fún un yín ní ìsinmi, kúrò láàrín àwọn ọ̀tá a yín, tí ó yí i yín ká, kí ẹ ba à lè máa gbé láìléwu. 11 Níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ mú gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún un yín wá: àwọn ọrẹ ẹ yín àti àwọn ẹbọ sísun, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àti gbogbo ohun ìní yín tí ẹ ti yàn, èyí tí ẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa. 12 Kí ẹ máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, ẹ̀yin, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, ìránṣẹ́bìnrin àti ìránṣẹ́kùnrin yín, àti àwọn Lefi láti ìlú u yín, tí wọn kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn. 13 Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe rú ẹbọ sísun yín ní ibikíbi tí ẹ̀yin fẹ́. 14 Ibi tí Olúwa yóò yàn láàrín àwọn ẹ̀yà a yín nìkan ni kí ẹ ti máa rú ẹbọ sísun yín, kí ẹ sì máa kíyèsi ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún un yín níbẹ̀.

  13. 33 ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ó bá fetí sí mi, yóò gbé láìléwu

    yóò sì wà nínú ìdẹ̀ra, láìsí ìbẹ̀rù ìpalára.”

  14. 35 Ta ni yóò ha yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ìpọ́njú ni, tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ìyàn, tàbí ìhòhò, tàbí ewu tàbí idà? 36  Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

    “Nítorí rẹ̀ ni a ṣe ń pa wá kú ní gbogbo ọjọ́;

    À ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.”

    37  Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwa ju ẹni tí ó ṣẹ́gun lọ nípasẹ̀ Kristi ẹni tí ó fẹ́ wa. 38 Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kì í ṣe ikú tàbí ìyè, kì í ṣe àwọn angẹli tàbí ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe ohun ìgbà ìsinsin yìí tàbí ohun tí ó ń bọ̀, tàbí àwọn agbára, 39 tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun nínú ìṣẹ̀dá ni yóò le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ń bẹ nínú Kristi Jesu, Olúwa wa.

  15. 12 Ní ti Benjamini ó wí pé,

    “Jẹ́ kí olùfẹ́ Olúwa máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀,

    òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́,

    ẹni tí Olúwa fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrín èjìká rẹ̀.”

  16. 8 “Ṣùgbọ́n bí ó ṣe tèmi, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní èmi yóò ti ṣìpẹ̀,

    ní ọwọ́ Ọlọ́run ní èmi yóò máa fi ọ̀rọ̀ mi lé.

    9 Ẹni tí ó ṣe ohun tí ó tóbi tí a kò lè ṣe àwárí,

    ohun ìyanu láìní iye.

    10 Tí ń rọ̀jò sí orí ilẹ̀ ayé

    tí ó sì ń rán omi sínú ilẹ̀kílẹ̀.

    11 Láti gbé àwọn orílẹ̀-èdè lékè

    kí á lè gbé àwọn ẹni ìbànújẹ́ ga sí ibi aláìléwu.

    12  Ó yí ìmọ̀ àwọn alárékérekè po,

    bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdáwọ́lé wọn ṣẹ.

    13 Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè ara wọn,

    àti ìmọ̀ àwọn òǹrorò ní ó tì ṣubú ní ògèdèǹgbé.

    14 Wọ́n sáré wọ inú òkùnkùn ní ọ̀sán;

    wọ́n sì fọwọ́ tálẹ̀ ní ọ̀sán gangan bí ẹni pé ní òru ni.

    15 Ṣùgbọ́n ó gba tálákà là ní ọwọ́ idà,

    lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára.

    16 Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún tálákà,

    àìṣòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

  17. 14 Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀-èdè ṣubú

    ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú.

  18. 20 “Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí ti a fi ogun yí Jerusalẹmu ká, ẹ mọ̀ nígbà náà pé, ìsọdahoro rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀. 21 Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Judea sálọ sórí òkè; àti àwọn tí ń bẹ láàrín rẹ̀ kí wọn jáde kúrò; kí àwọn tí ó sì ń bọ̀ ní ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀ wá. 22 Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ wọ̀nyí, kì a lè mú ohun gbogbo tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ. 23  Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tí ó lóyún, àti àwọn tí ó fi ọyàn fún ọmọ mu ní ọjọ́ wọ̀nyí! Nítorí tí ìpọ́njú púpọ̀ yóò wà lórí ilẹ̀ àti ìbínú sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí.

  19. 10 Nítorí tí ìwọ tí pa ọ̀rọ̀ sùúrù mi mọ́, èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, tí ń bọ̀ wá dé bá gbogbo ayé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò.

    11 Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán, di èyí ti ìwọ ní mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gba adé rẹ.

  20. 3 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì máa ṣe rere;

    torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.

  21. 15 “ ‘Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ní àkókò náà,

    Èmi ó gbé olódodo dìde láti ẹ̀ka Dafidi.

    Yóò ṣe ìdájọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ilẹ̀ náà.

    16 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Juda yóò di ẹni ìgbàlà.

    Jerusalẹmu yóò sì máa gbé láìséwu.

    Orúkọ yìí ni a ó máa pè é

    Olúwa wa olódodo.’

  22. 11 “Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 12 Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́-àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkookò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri. 13 Òun sálọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn.

    14 “Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí. 15  Gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi sì mọ Baba, mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.

  23. 3  Ṣùgbọ́n olódodo ni Olúwa, ẹni tí yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóò sì pa yín mọ́ kúrò nínú ibi. 4 Àwa sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ní ti ohun tí ẹ ń ṣe, àti pé àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a pàṣẹ fún un yín ni ẹ̀yin ń ṣe. 5 Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín ṣọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kristi.

  24. 18  Àwa mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí a bí nípa ti Ọlọ́run kì í dẹ́ṣẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run a pa ara rẹ̀ mọ́, ẹni búburú kò ní lè fọwọ́ kàn án.

  25. 1 “ ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mọ ère òrìṣà, tàbí kí ẹ̀yin gbe ère kalẹ̀ tàbí kí ẹ̀yin gbẹ́ ère òkúta: kí ẹ̀yin má sì gbẹ́ òkúta tí ẹ̀yin yóò gbé kalẹ̀ láti sìn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

    2  “ ‘Ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́ kí ẹ̀yin sì bọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi. Èmi ni Olúwa.

    3  “ ‘Bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ẹ̀yin sì ṣọ́ra láti pa òfin mi mọ́. 4 Èmi yóò rọ̀jò fún yín ní àkókò rẹ̀, kí ilẹ̀ yín le mú èso rẹ̀ jáde bí ó tí yẹ kí àwọn igi eléso yín so èso. 5 Èrè oko yín yóò pọ̀ dé bi pé ẹ ó máa pa ọkà títí di àsìkò ìkórè igi eléso, ẹ̀yin yóò sì máa gbé ní ilẹ̀ yín láìléwu.

    6 “ ‘Èmi yóò fún yín ní àlàáfíà ní ilẹ̀ yín, ẹ̀yin yóò sì sùn láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Èmi yóò mú kí gbogbo ẹranko búburú kúrò ní ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni idà kì yóò la ilẹ̀ yín já.

  26. 4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn

    láàrín àfonífojì òjìji ikú,

    èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan,

    nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;

    ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ,

    wọ́n ń tù mí nínú.

  27. 7 Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;

    ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;

    ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.

  28. 53 Ó dáàbò bò wọ́n dáradára, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n

    ṣùgbọ́n òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

  29. 7 Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;

    ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,

    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.

    8 Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé;

    Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé;

    má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.

  30. Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

    1 Olúwa, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì,

    yọ mí lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì,

    2 ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn;

    nígbà gbogbo ni wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi.

    3 Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò,

    oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.

    4 Olúwa, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú;

    yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì

    ẹni tí ó ti pinnu rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú.

  31. 7 Rere ni Olúwa,

    òun ni ààbò ní ọjọ́ ìpọ́njú.

    Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e,

  32. 9 Èṣù sì mú un lọ sí Jerusalẹmu, ó sì gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili, ó sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ láti ibí yìí. 10  A sá ti kọ̀wé rẹ̀ pé,

    “ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ,

    láti máa ṣe ìtọ́jú rẹ;

    11 àti pé ní ọwọ́ wọn ni wọn ó gbé ọ sókè,

    kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”

    12  Jesu sì dáhùn ó wí fún un pé, “A ti kọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”

    13  Nígbà tí èṣù sì parí ìdánwò náà gbogbo, ó fi í sílẹ̀ lọ fun sá à kan.

  33. 31  Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa?

  34. 2 Mo sì rí angẹli mìíràn tí ó ń ti ìhà ìlà-oòrùn gòkè wá, ti òun ti èdìdì Ọlọ́run alààyè lọ́wọ́ rẹ. Ó sì kígbe ní ohùn rara sí àwọn angẹli mẹ́rin náà tí a fi fún un láti pa ayé, àti Òkun, lára, 3  wí pé, “Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí Òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn.”

  35. 25 Nígbà ayé Solomoni, Juda àti Israẹli, láti Dani títí dé Beerṣeba, wọ́n ń gbé ní àlàáfíà, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀.

  36. 7 Olúwa, ìwọ yóò pa wá mọ́

    kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé.

  37. Miktamu ti Dafidi.

    1 Pa mí mọ́, Ọlọ́run,

    nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.

  38. 13 Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdánwò,

    ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi.

    Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín.’

  39. 15 “Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ‘ìsọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Daniẹli sọ,’ tí ó bá dúró ní ibi mímọ́ (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á kí ó yé e), 16 nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Judea sálọ sí orí òkè. 17 Kí ẹni tí ó wà lórí ilé rẹ̀ má ṣe sọ̀kalẹ̀ wá mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀. 18 Kí àwọn tí ó sì wà lóko má ṣe darí wá sí ilé láti mú àwọn aṣọ wọn. 19 Ṣùgbọ́n àánú ṣe mí fún àwọn obìnrin ti ó lóyún, àti fún àwọn tí ó ń fún ọmọ loyan ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì! 20 Ẹ sì máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣe jẹ́ ìgbà òtútù, tàbí ọjọ́ ìsinmi. 21 Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wá títí di ìsinsin yìí irú rẹ̀ kì yóò sì ṣí.

    22 “Lóòótọ́, àfi bí a ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú, gbogbo ẹ̀dá alààyè yóò ṣègbé. Ṣùgbọ́n nítorí ti àwọn àyànfẹ́ ni a ó fi ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú. 23 Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Wo Kristi náà,’ tàbí pé ó ti farahàn níhìn-ín tàbí lọ́hùn ún, ẹ má ṣe gbà á gbọ́. 24 Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn èké wòlíì yóò dìde. Wọn yóò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti ìyanu. Bí ó bá lè ṣe é ṣe wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run pàápàá jẹ. 25 Wò ó, mo ti kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀.

    26 “Nítorí náà, bí ẹnìkan bá sọ fún yín pé, ‘Olùgbàlà ti dé,’ àti pé, ‘Ó wà ní aginjù,’ ẹ má ṣe wàhálà láti lọ wò ó, tàbí tí wọ́n bá ní, ó ń fi ara pamọ́ sí iyàrá,” ẹ má ṣe gbà wọn gbọ́. 27 Nítorí bí mọ̀nàmọ́ná ti ń tàn láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́. 28 Nítorí ibikíbi tí òkú bá gbé wà, ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ igún ń kójọpọ̀ sí.

  40. 12  Nígbà tí mo wà pẹ̀lú wọn ní ayé, mo pa wọ́n mọ́ ní orúkọ rẹ; àwọn tí ìwọ fi fún mi, ni mo ti pamọ́, ẹnìkan nínú wọn kò sọnù bí kò ṣe ọmọ ègbé; kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ.

  41. 10 Ní àkótán, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀. 11 Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè kọ ojú ìjà sí àrékérekè èṣù. 12 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara ní àwa ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àti àwọn ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run. 13 Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè dúró tiiri sí ọjọ́ ibi, nígbà tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ohun gbogbo tan kí ẹ sì dúró. 14  Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra. 15  Tí ẹ sì ti fi ìmúra ìyìnrere àlàáfíà wọ ẹsẹ̀ yín ní bàtà. 16 Ní àfikún, ẹ mú àpáta ìgbàgbọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin lè máa fi paná gbogbo ọfà iná ẹni ibi náà. 17 Kí ẹ sì mú àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

    18 Pẹ̀lú gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ni kí ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo nínú Ẹ̀mí, kí ẹ sì máa ṣọ́ra sí i nínú ìdúró ṣinṣin gbogbo àti ẹ̀bẹ̀ fún gbogbo ènìyàn mímọ́. 19 Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún mí pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè fún mí ní ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí èmi lè máa fì ìgboyà sọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ìyìnrere náà. 20 Nítorí èyí tí èmí jẹ́ ikọ̀ nínú ẹ̀wọ̀n, kí èmi lè máa fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mí láti máa sọ.

  42. 1 Ní àkótán ará, ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa wa. Kì í ṣe ìnira fún mi láti kọ̀wé ohun kan náà sí yín, ṣùgbọ́n fún yín ó jẹ́ ohun ààbò.

  43. 15 Ní àfẹ̀mọ́júmọ́, àwọn angẹli náà rọ Lọti pé, “Ṣe wéré, mú aya rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì tí ó wà níhìn-ín, àìṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò parun pẹ̀lú ìlú yìí nígbà tí wọ́n bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

    16  Nígbà tí ó ń jáfara, àwọn ọkùnrin náà nawọ́ mú un lọ́wọ́, wọ́n sì nawọ́ mú aya rẹ̀ náà lọ́wọ́ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì, wọ́n sì mú wọn jáde sẹ́yìn odi ìlú, nítorí Olúwa ṣàánú fún wọn. 17 Ní kété tí wọ́n mú wọn jáde sẹ́yìn odi tán, ọ̀kan nínú wọn wí pé, “Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Má ṣe wo ẹ̀yìn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó má ṣe dúró ní gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀! Sá àsálà lọ sí orí òkè, kí ìwọ ó má ba ṣègbé!”

  44. 8 Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú rẹ;

    fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ,

    9 lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú tí ń fóròó mi,

    kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.

    10 Wọ́n pa ọkàn aláìláàánú wọn mọ́,

    wọ́n sì fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìgbéraga.

  45. 4 Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa,

    òhun ni èmi yóò máa wá kiri:

    kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa

    ní ọjọ́ ayé mi gbogbo,

    kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa,

    kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.

    5 Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú

    òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀;

    níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;

    yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.

  46. 19 Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó,

    èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,

    èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn

    tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn.

    20 Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí

    kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn;

    ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu

    kúrò nínú ìjà ahọ́n.

    21 Olùbùkún ni Olúwa,

    nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn,

    nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká.

  47. 8 Ṣùgbọ́n ojú mi ń bẹ lára rẹ, Olúwa Olódùmarè;

    nínú rẹ̀ ni èmi ti rí ààbò, má ṣe fà mi fún ikú.

    9 Pa mí mọ́ kúrò nínú okùn tí wọn ti dẹ sílẹ̀ fún mi,

    kúrò nínú ìkẹ́kùn àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

    10 Jẹ́ kí àwọn ẹni búburú ṣubú sínú àwọ̀n ara wọn,

    nígbà tí èmi bá kọjá lọ láìléwu.

  48. 28 Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́,

    nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu.

  49. 18 Ẹni tí ń rìn déédéé ní yóò là,

    ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà ni yóò ṣubú lójijì.

  50. 26 Ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀ jẹ́ aláìgbọ́n

    ṣùgbọ́n ẹni tí ń rìn nínú ọgbọ́n wà láìléwu.

  51. 1 Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Juda.

    Àwa ní ìlú alágbára kan,

    Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣe

    ògiri àti ààbò rẹ̀.

    2 Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn

    kí àwọn olódodo orílẹ̀-èdè kí ó lè wọlé,

    orílẹ̀-èdè tí ó pa ìgbàgbọ́ mọ́.

    3 Ìwọ yóò pa á mọ́ ní àlàáfíà pípé

    ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin,

    nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.

    4 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa títí láé,

    nítorí Olúwa, Olúwa ni àpáta ayérayé náà.

    5 Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀

    ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀;

    ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹsẹ

    ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.

    6 Ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀

    ẹsẹ̀ aninilára n nì,

    ipasẹ̀ àwọn òtòṣì.

  52. 10  Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;

    má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.

    Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́.

    Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.

    11 “Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọ

    ni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹlẹ́yà;

    àwọn tó ń bá ọ jà

    yóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé.

    12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀tá rẹ,

    ìwọ kì yóò rí wọn.

    Gbogbo àwọn tí ó gbóguntì ọ́

    yóò dàbí ohun tí kò sí.

  53. 2 Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,

    Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ;

    àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá

    wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.

    Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,

    kò ní jó ọ;

    ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.

  54. 5  “Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí,

    “tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dafidi,

    ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́n

    tí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà.

    6 Ní ọjọ́ rẹ̀ ni a ó gba Juda là,

    Israẹli yóò sì máa gbé ní aláìléwu.

    Èyí ni orúkọ tí a ó fi máa pè é:

    Olúwa Òdodo wa.

  55. 37 Èmi ó kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti lé wọn kúrò ní ìgbà ìbínú àti ìkáàánú ńlá mi. Èmi yóò mú wọn padà wá sí ilẹ̀ yìí; èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó máa gbé láìléwu. 38  Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.

  56. 13 Nígbà tí wọn ti lọ, angẹli Olúwa fi ara hàn Josẹfu ní ojú àlá pé, “Dìde, gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀, kí ó sì sálọ sí Ejibiti. Dúró níbẹ̀ títí tí èmi yóò fi sọ fún ọ, nítorí Herodu yóò wá ọ̀nà láti pa ọmọ ọwọ́ náà.”

    14 Nígbà náà ni ó sì dìde, ó mú ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Ejibiti, 15  ó sì wà níbẹ̀ títí tí Herodu fi kú. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé, “Mo pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.”

  57. 27 Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbéyàwó, wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí ó fi di ọjọ́ ti Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, kíkún omi sì dé, ó sì run gbogbo wọn.

    28 “Bí ó sì ti rí ní ọjọ́ Lọti; wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé, 29 ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà tí Lọti jáde kúrò ní Sodomu, òjò iná àti sulfuru rọ̀ láti ọ̀run wá, ó sì run gbogbo wọn.

    30 “Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ náà tí Ọmọ Ènìyàn yóò farahàn. 31  Ní ọjọ́ náà, ẹni tí ó bá wà lórí ilé, tí ẹrù rẹ̀ sì ń bẹ ní ilẹ̀, kí ó má ṣe sọ̀kalẹ̀ láti wá kó o; ẹni tí ó bá sì wà ní oko, kí ó má ṣe padà sẹ́yìn. 32  Ẹ rántí aya Lọti. 33  Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wá àti gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóò sọ ọ́ nù; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì sọ ọ́ nù yóò gbà á là. 34  Mo wí fún yín, ní òru ọjọ́ náà, ènìyàn méjì yóò wà lórí àkéte kan; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀. 35 Ènìyàn méjì yóò sì máa lọ ọlọ pọ̀; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀.”

    37  Wọ́n sì dá a lóhùn, wọ́n bi í pé, “Níbo, Olúwa?”

    Ó sì wí fún wọn pé, “Níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ pẹ̀lú ni igún ìkójọpọ̀ sí.”

  58. 13  Kò sí ìdánwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọ́run, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin ba à lè faradà á.

  59. 7 Nítorí náà, ẹ tẹríba fún Ọlọ́run. Ẹ kọ ojú ìjà sí èṣù, òun ó sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.

  60. 11 Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun kì yóò fi ara pa nínú ikú kejì.

  61. 13 Nígbà tí dragoni náà rí pé a lé òun lọ sí ilẹ̀ ayé, ó ṣe inúnibíni sì obìnrin tí ó bí ọmọkùnrin náà. 14  A sì fi apá ìyẹ́ méjì tí idì ńlá náà fún obìnrin náà, pé kí ó fò lọ sí aginjù, sí ipò rẹ̀, níbi tí a ó gbe bọ ọ fún àkókò kan àti fún àwọn àkókò, àti fún ìdajì àkókò kúrò lọ́dọ̀ ejò náà. 15 Ejò náà sì tu omi jáde láti ẹnu rẹ̀ wá bí odò ńlá sẹ́yìn obìnrin náà, kí ó lè fi ìṣàn omi náà gbà á lọ. 16 Ilẹ̀ sì ran obìnrin náà lọ́wọ́, ilẹ̀ sì ya ẹnu rẹ̀, ó sì fi ìṣàn omi náà mú, tí dragoni náà tu jáde láti ẹnu rẹ̀ wá. 17 Dragoni náà sì bínú gidigidi sí obìnrin náà, ó sì lọ bá àwọn irú-ọmọ rẹ̀ ìyókù jagun, tí wọ́n ń pa òfin Ọlọ́run mọ̀, tí wọn sì di ẹ̀rí Jesu mú, Ó sì dúró lórí iyanrìn Òkun.

  62. 18 Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà;

    àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.

  63. 8  Mo ti gbé Olúwa síwájú mi ní ìgbà gbogbo.

    Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.

    9 Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;

    ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,

  64. 8 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́,

    bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,

    ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun

    ní ìlú Ọlọ́run wa,

    Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela.

  65. 22  Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa

    yóò sì mú ọ dúró;

    òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.

  66. 2 Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi;

    Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.

  67. 8 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa

    ju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ.

  68. Orin fún ìgòkè.

    1 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni,

    tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé.

    2 Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,

    bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká

    láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

  69. 26 Nínú ìbẹ̀rù Olúwa ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára,

    yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.

  70. 10 Kọ orin tuntun sí Olúwa

    ìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá,

    ẹ̀yin tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú Òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀,

    ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú wọn.

    11 Jẹ́ kí aginjù àti àwọn ìlú rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn sókè;

    jẹ́ kí ibùdó ti àwọn ìlú Kedari ń gbé máa yọ̀.

    Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Sela kọrin fún ayọ̀;

    jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè.

    12 Jẹ́ kí wọn fi ògo fún Olúwa

    àti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù.

    13 Olúwa yóò rìn jáde gẹ́gẹ́ bí i ọkùnrin alágbára,

    yóò ru owú sókè bí ológun;

    yóò kígbe nítòótọ́, òun yóò ké igbe ogun,

    òun yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀.

  71. 18 Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú

    fún wọn àti àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti

    àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀.

    Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́.

    Ọfà, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà

    kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu.

  72. 11  Ènìyàn yóò sì máa gbé ibẹ̀, kì yóò sì sí ìparun mọ́; ṣùgbọ́n a ó máa gbé Jerusalẹmu láìléwu.

  73. 16 Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. 17 Ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èmi ó ti ṣe, nítorí tí èmi kò ní ibi tí èmi ó gbé kó èso mi jọ sí.’

    18 “Ó sì wí pé, ‘Èyí ni èmi ó ṣe: èmi ó wó àká mi palẹ̀, èmi ó sì kọ́ èyí tí ó tóbi; níbẹ̀ ni èmi ó gbé to gbogbo èso àti ọrọ̀ mi jọ sí. 19 Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; sinmi, máa jẹ, máa mu, máa yọ̀.’

    20 “Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè, lóru yìí ni a ó béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ; ǹjẹ́ ti ta ni nǹkan wọ̀nyí yóò ha ṣe, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀?’

    21 “Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó to ìṣúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò sì ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”

  74. 15 Èmi kò gbàdúrà pé, kí ìwọ kí ó mú wọn kúrò ní ayé, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó pa wọ́n mọ́ kúrò nínú ibi.