29 Bible Verses About Sleep

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Sleep
  1. 8 Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà,

    nítorí ìwọ nìkan, Olúwa,

    ni o mú mi gbé láìléwu.

  2. Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni.

    1 Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà

    àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni;

    bí kò ṣe pé Olúwa bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.

    2 Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù

    láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá;

    bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.

  3. 2 Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wá,

    ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

    3 Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀;

    ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.

    4 Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́,

    kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.

    5 Olúwa ni olùpamọ́ rẹ;

    Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

    6 Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán

    tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.

  4. 11  Àti èyí, bí ẹ̀yin ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsin yìí fún yín láti jí lójú orun, nítorí nísinsin yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ. 12  Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́: nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀. 13  Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmutípara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì í ṣe ní ìjà àti ìlara. 14  Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jesu Kristi Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti máa mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.

  5. 11  Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ, lẹ́yìn èyí nì ó sì wí fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa sùn; ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú orun rẹ̀.”

    12 Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, bí ó bá ṣe pé ó sùn, yóò sàn.” 13 Ṣùgbọ́n Jesu ń sọ ti ikú rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n rò pé, ó ń sọ ti orun sísùn.

    14 Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn gbangba pé, “Lasaru ti kú.

  6. 21 Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́,

    má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn.

    22 Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ,

    àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ.

    23 Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu,

    ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀.

    24 Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù,

    nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀.

    25 Má ṣe bẹ̀rù ìdààmú òjijì,

    tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú.

  7. 1  Nísinsin yìí, ará, a kò nílò láti kọ ìwé sí i yín mọ́ nípa àkókò àti ìgbà, 2  nítorí ẹ̀yin pàápàá mọ̀ wí pé ọjọ́ Olúwa yóò wá bí olè lóru. 3  Ní àkókò gan an tí àwọn ènìyàn yóò máa wí pé, “Àlàáfíà àti ààbò,” nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìrọbí obìnrin tí ó lóyún, wọn kò sí ni rí ibi ààbò láti sá sí.

    4  Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ará, kò sí nínú òkùnkùn nípa nǹkan wọ̀nyí tí ọjọ́ Olúwa yóò fi dé bá yín bí olè. 5  Nítorí gbogbo yín ni ọmọ ìmọ́lẹ̀ àti ọmọ ọ̀sán gangan. Ẹ kì í ṣe tí òru tàbí tí òkùnkùn mọ́. 6  Nítorí náà, ẹ kíyèsára yín kí ẹ má ṣe sùn bí àwọn ẹlòmíràn. Ẹ máa ṣọ́nà kí ẹ sì máa pa ara yín mọ́. 7  Nítorí àwọn tí wọ́n ń sùn, a máa sùn ní òru, àwọn ẹni tí ń mu àmupara, a máa mú un ní òru. 8  Ṣùgbọ́n àwa jẹ́ ti ìmọ́lẹ̀, ẹ jẹ́ kí a pa ara wa mọ́, ní gbígbé ìgbàgbọ́ wọ̀ àti ìfẹ́ bí ìgbàyà ni òru àti ìrètí ìgbàlà bí àṣíborí. 9  Nítorí pé, Ọlọ́run kò yàn wa láti da ìbínú rẹ̀ gbígbóná sí orí wa, ṣùgbọ́n ó yàn láti gbà wá là nípasẹ̀ Olúwa wa, Jesu Kristi. 10 Jesu kú fún wa kí a lè ba à gbé títí láéláé. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ yálà a sùn tàbí a wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀. 11 Nítorí náà, ẹ máa gba ara yín níyànjú, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe.

  8. 3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;

    ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.

    4 Olúwa ni mo kígbe sókè sí,

    ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.

    5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;

    mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.

    6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn

    tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.

  9. 7 Ọjọ́ èkínní ọ̀sẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn péjọ láti bu àkàrà, Paulu sì wàásù fún wọn, ó múra láti lọ ní ọjọ́ kejì: ó sì fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di àárín ọ̀gànjọ́. 8 Fìtílà púpọ̀ sì wà ní iyàrá òkè náà, níbi tí wọn gbé péjọ sí. 9 Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a ń pè ní Eutiku sì jókòó lójú fèrèsé, oorun sì wọ̀ ọ́ lára; bí Paulu sì ti pẹ́ ní ìwàásù, ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lójú oorun, ó ṣubú láti òkè kẹta wá sílẹ̀, a sì gbé e dìde ní òkú. 10 Nígbà tí Paulu sì sọ̀kalẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ tì i, ó sì gbé e mọ́ra, ó ní, “Ẹ má ṣe yọ ara yín lẹ́nu; nítorí tí òun wà láààyè.” 11 Nígbà tí ó sì tún gòkè lọ, ó sì jẹ oúnjẹ Olúwa, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ́ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́, nígbà náà ni ó sì lọ. 12 Wọ́n sì mú ọmọkùnrin náà lọ sílẹ̀ láààyè, inú gbogbo wọn sì dùn lọ́pọ̀lọ́pọ̀.

  10. 28 “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ tí a sì di ẹrù wíwúwo lé lórí, èmi yóò sì fún yín ní ìsinmi. 29 Ẹ gbé àjàgà mi wọ̀. Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi nítorí onínútútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmi, ẹ̀yin yóò sì ri ìsinmi fún ọkàn yín. 30 Nítorí àjàgà mi rọrùn ẹrù mi sì fúyẹ́.”

  11. 9 Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò dùbúlẹ̀, ìwọ ọ̀lẹ?

    Nígbà wo ni ìwọ yóò jí kúrò lójú oorun rẹ?

    10 Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,

    ìkáwọ́gbera láti sinmi díẹ̀.

    11 Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣà

    àti àìní bí adigunjalè.

  12. 5 Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ bẹ̀rù, olúkúlùkù sì ń kígbe sí ọlọ́run rẹ̀, wọ́n kó ẹrù tí ó wà nínú ọkọ̀ dà sínú Òkun, kí ó bá à lè fúyẹ́.

    Ṣùgbọ́n Jona sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀ ó sì dùbúlẹ̀, ó sùn wọra. 6 Bẹ́ẹ̀ ni olórí ọkọ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi sùn, ìwọ olóòórùn? Dìde kí o ké pe Ọlọ́run rẹ! Bóyá yóò ro tiwa, kí àwa má ba à ṣègbé.”

  13. 35 “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin pẹ̀lú ní láti máa fi ìrètí ṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ àkókò tí baálé ilé yóò dé. Bóyá ní ìrọ̀lẹ́ ni o, tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru, tàbí nígbà tí àkùkọ máa ń kọ, tàbí ní òwúrọ̀. 36 Àti wí pé nígbà tí ó bá dé lójijì, kó má ṣe bá yín lójú oorun. 37 Ohun tí mo wí fún un yín, mo wí fun gbogbo ènìyàn: ‘Ẹ máa ṣọ́nà!’ ”

  14. 6  Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. 7 Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu.

  15. 20 Gbogbo ohun ọ̀sìn, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹranko igbó ni ọkùnrin náà sọ ní orúkọ.

    Ṣùgbọ́n fún Adamu ni a kò rí olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀. 21 Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran-ara bò ó padà. 22 Olúwa Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, Ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá.

  16. 14 Nítorí pe Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan,

    àní, lẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n ènìyàn kò róye rẹ̀.

    15 Nínú àlá, ní ojúran òru,

    nígbà tí orun èjìká bá kùn ènìyàn lọ,

    ní sísùn lórí ibùsùn,

    16 nígbà náà ni ó lè sọ̀rọ̀ ní etí wọn,

    yóò sì dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìbáwí,

    17 kí ó lè fa ènìyàn sẹ́yìn kúrò nínú ètè rẹ̀;

    kí ó sì pa ìgbéraga mọ́ kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn;

    18 Ó sì fa ọkàn rẹ̀ padà kúrò nínú isà òkú,

    àti ẹ̀mí rẹ̀ láti ṣègbé lọ́wọ́ idà.

  17. 14 Nítorí náà ni ó ṣe wí pé,

    “Jí, ìwọ̀ ẹni tí ó sun,

    sí jíǹde kúrò nínú òkú

    Kristi yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”

    15 Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa rìn ní ìwà pípé, kì í ṣé bí àwọn òmùgọ̀, ṣùgbọ́n bí àwọn ọlọ́gbọ́n; 16  ẹ máa ra ìgbà padà, nítorí búburú ní àwọn ọjọ́.

  18. 13 Má ṣe fẹ́ràn oorun, àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di tálákà.

    Ma ṣe sùn ìwọ yóò sì ní oúnjẹ láti tún fi tọrọ.

  19. 22  Ní ọjọ́ kan, ó sì wọ ọkọ̀ ojú omi kan lọ òun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. O sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìhà kejì adágún.” Wọ́n sì ṣíkọ̀ láti lọ. 23 Bí wọ́n sì ti ń lọ, ó sùn; ìjì ńlá sì dé, ó ń fẹ́ lójú adágún; omi si wọ inú ọkọ, wọ́n sì wà nínú ewu.

    24  Wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá wọ́n sì jí i, wí pé, “Olùkọ́, Olùkọ́, àwa yóò ṣègbé!”

    Nígbà náà ni ó dìde, ó sì bá ìjì líle àti ríru omi wí; wọ́n sì dúró, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì dé. 25 Ó sì wí fún wọn pé, “Ìgbàgbọ́ yín dà?”

    Bí ẹ̀rù ti ń ba gbogbo wọn, tí hà sì ń ṣe wọ́n, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni èyí, nítorí ó bá ìjì líle àti ríru omi wí, wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀?”

  20. 6 Ní òru náà gan an ti Herodu ìbá sì mú un jáde, Peteru ń sùn láàrín àwọn ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é, ẹ̀ṣọ́ sí wà ní ẹnu-ọ̀nà, wọ́n ń ṣọ́ túbú náà. 7 Sì wò ó, angẹli Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Peteru pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Peteru.

  21. 15 Ọ̀lẹ ṣíṣe máa ń fa oorun sísùn fọnfọn,

    ebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.

  22. 5 Nígbà tí ọkọ ìyàwó pẹ́, gbogbo wọn tòògbé wọn sì sùn.

  23. 36  Nígbà náà ni Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibi kan ti à ń pè ní ọgbà Getsemane, ó wí fún wọn pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí mo bá lọ gbàdúrà lọ́hùn ún ni.” 37 Ó sì mú Peteru àti àwọn ọmọ Sebede méjèèjì Jakọbu àti Johanu pẹ̀lú rẹ̀, ìrora àti ìbànújẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí gba ọkàn rẹ̀. 38  Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi gbọgbẹ́ pẹ̀lú ìbànújẹ́ títí dé ojú ikú, ẹ dúró níhìn-ín yìí, kí ẹ máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.”

    39  Òun lọ sí iwájú díẹ̀ sí i, ó sì dojúbolẹ̀, ó sì gbàdúrà pé, “Baba mi, bí ó bá ṣe é ṣe, jẹ́ kí a mú ago yìí ré mi lórí kọjá, ṣùgbọ́n ìfẹ́ tìrẹ ni mo fẹ́ kí ó ṣẹ, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi.”

    40 Bí ó ti padà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó bá wọn, wọ́n ń sùn. Ó kígbe pé, “Peteru, ẹ̀yin kò tilẹ̀ lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan? 41 Ẹ máa ṣọ́ra, kí ẹ sì máa gbàdúrà kí ẹ̀yin má ba à bọ́ sínú ìdẹwò. Nítorí ẹ̀mí ń fẹ́ nítòótọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.”

  24. 1 Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo

    ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.

    2 Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé,

    “Òun ni ààbò àti odi mi,

    Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.

    3 Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú

    ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ

    àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.

    4 Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí,

    àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;

    òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.

    5 Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,

    tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,

    6 tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn,

    tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.

    7 Ẹgbẹ̀rún (1,000) yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,

    ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,

    ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.

    8 Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ

    àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.

    9 Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ,

    ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.

    10 Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́,

    Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.

  25. 12 Oorun alágbàṣe a máa dùn,

    yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀,

    ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀

    kì í jẹ́ kí ó sùn rárá.

  26. 33 Ṣùgbọ́n, ẹ kọ́kọ́ wá ìjọba Ọlọ́run ná àti òdodo rẹ̀, yóò sì fi gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kún un fún yín pẹ̀lú. 34 Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn ọ̀la, ọ̀la ni yóò ṣe àníyàn ara rẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.

  27. 3 Ìwọ yóò pa á mọ́ ní àlàáfíà pípé

    ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin,

    nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.

    4 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa títí láé,

    nítorí Olúwa, Olúwa ni àpáta ayérayé náà.

  28. 25 Èmi yóò sọ aláàárẹ̀ di ọ̀tun, èmi yóò sì tẹ́ gbogbo ọkàn tí ń káàánú lọ́rùn.”

    26 Lórí èyí ni mo jí, mo sì wò yíká, oorun mi sì dùn mọ́ mi.

  29. 16 Ó sì ṣe nígbà tí ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ ọ́ ní ojoojúmọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí dé bi pé ó sú dé òpin ẹ̀mí rẹ̀.

    17 Òun sì sọ ohun gbogbo tí ó wà ní ọkàn rẹ̀ fún un. Ó ní, “Abẹ kò tí ì kan orí mi rí, nítorí pé Nasiri, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run ni mo jẹ́ láti ìgbà ìbí mi wá. Bí a bá fá irun orí mi, agbára mi yóò fi mí sílẹ̀, èmi yóò sì di aláìlágbára bí àwọn ọkùnrin yòókù.”

    18 Nígbà tí Dẹlila rí i pé ó ti sọ ohun gbogbo fún òun tan, Dẹlila ránṣẹ́ sí àwọn ìjòyè Filistini pé, “Ẹ wá lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ti sọ ohun gbogbo fún mi.” Torí náà àwọn olóyè Filistini padà, wọ́n sì mú owó ìpinnu náà lọ́wọ́. 19 Òun sì mú kí Samsoni sùn lórí itan rẹ̀, òun sì pe ọkùnrin kan láti fá àwọn ìdì irun orí rẹ̀ méjèèje, òun sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun rẹ̀. Agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ.

    20 Òun pè é wí pé, “Samsoni àwọn Filistini dé láti mú ọ.”

    Òun jí ní ojú oorun rẹ̀, ó sì sọ pé, “Èmi yóò jáde lọ bí í ti àtẹ̀yìnwá, kí èmi sì gba ara mi, kí n di òmìnira.” Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ pé Olúwa ti fi òun sílẹ̀.

    21 Nígbà náà ni àwọn Filistini mú un, wọ́n yọ ojú rẹ̀ méjèèjì wọ́n sì mú un lọ sí Gasa. Wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ dè é, wọ́n sì fi sí ibi iṣẹ́ ọlọ lílọ̀ nínú ilé túbú.