75 Bible Verses About Vanity

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Vanity
  1. 1 Ọ̀rọ̀ Oniwaasu, ọmọ Dafidi, ọba Jerusalẹmu:

    2 “Asán inú asán!”

    Oníwàásù náà wí pé,

    “Asán inú asán!

    Gbogbo rẹ̀ asán ni.”

    3 Kí ni ènìyàn rí jẹ ní èrè lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀,

    lórí èyí tí ó ń ṣe wàhálà sí lábẹ́ oòrùn?

    4 Bí ìran kan ti wá ni ìran mìíràn ń kọjá lọ,

    síbẹ̀ ayé dúró títí láé.

    5 Oòrùn ń ràn, oòrùn sì ń wọ̀,

    ó sì sáré padà sí ibi tí ó ti yọ.

    6 Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ìhà gúúsù,

    Ó sì ń fẹ́ yípo sí ìhà àríwá,

    a sì tún padà sí ọ̀nà rẹ̀.

    7 Gbogbo odò ń sàn sí inú Òkun,

    síbẹ̀síbẹ̀ Òkun kò kún.

    Níbi tí àwọn odò ti wá,

    níbẹ̀ ni wọ́n tún padà sí.

    8 Ohun gbogbo ni ó ń mú àárẹ̀ wá,

    ju èyí tí ẹnu le è sọ.

    Ojú kò tí ì rí ìrírí tí ó tẹ́ ẹ lọ́rùn,

    bẹ́ẹ̀ ni, etí kò tí ì kún fún gbígbọ́.

    9 Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóò sì máa wà, ohun tí a ti ṣe sẹ́yìn

    òun ni a ó tún máa ṣe padà

    kò sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn.

    10 Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ẹnìkan le è sọ wí pé,

    “Wò ó! Ohun tuntun ni èyí”?

    Ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí ní ọjọ́ tó ti pẹ́,

    o ti wà ṣáájú tiwa.

    11 Kò sí ìrántí ohun ìṣáájú

    bẹ́ẹ̀ ni ìrántí kì yóò sí fún

    ohun ìkẹyìn tí ń bọ̀

    lọ́dọ̀ àwọn tí ń bọ̀ ní ìgbà ìkẹyìn.

  2. 12 Èmi, Oniwaasu ti jẹ ọba lórí Israẹli ní Jerusalẹmu rí. 13 Mo fi àsìkò mi sílẹ̀ láti kọ́ àti láti ṣe àwárí pẹ̀lú ọgbọ́n, gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run. Háà! Ẹrù wúwo tí Ọlọ́run ti gbé lé àwọn ènìyàn. 14 Èmi ti rí ohun gbogbo tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, gbogbo rẹ̀ kò ní ìtumọ̀ bí ẹní gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

    15 Ohun tí ó ti wọ́ kò le è ṣe é tọ́ mọ́,

    ohun tí kò sí kò le è ṣe é kà.

    16 Mo rò nínú ara mi, “Wò ó, mo ti dàgbà, ọgbọ́n mi sì ti pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni tí ó ti ṣe alákòóso Jerusalẹmu síwájú mi lọ, mo ti ní ìrírí púpọ̀ nípa ọgbọ́n àti ìmọ̀.” 17 Nígbà náà ni mo fi ara jì láti ní ìmọ̀ nípa ọgbọ́n, àti pàápàá àìgbọ́n àti òmùgọ̀, ṣùgbọ́n mo rí, wí pé èyí pẹ̀lú bí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

    18 Nítorí pé ọgbọ́n púpọ̀ ìbànújẹ́ púpọ̀ ní ń mú wá,

    bí ìmọ̀ bá sì ṣe pọ̀ tó náà ni ìbànújẹ́ ń pọ̀ tó.

  3. 1 Mo rò nínú ọkàn mi, “Wá nísinsin yìí, èmi yóò sì dán ọ wò pẹ̀lú ìgbádùn láti ṣe àwárí ohun tí ó dára.” Ṣùgbọ́n eléyìí náà jásí asán. 2 “Mo wí fún ẹ̀rín pé òmùgọ̀ ni. Àti fún ìre-ayọ̀ pé kí ni ó ń ṣe?” 3 Mo tiraka láti dun ara mi nínú pẹ̀lú ọtí wáìnì, àti láti fi ọwọ́ lé òmùgọ̀—ọkàn mi sì ń tọ́ mi pẹ̀lú ọgbọ́n. Mo fẹ́ wo ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ènìyàn ní abẹ́ ọ̀run ní ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀.

    4  Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá ńlá. Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀. 5 Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn. 6 Mo gbẹ́ adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà. 7  Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi. Mo sì tún ní ẹran ọ̀sìn ju ẹnikẹ́ni ní Jerusalẹmu lọ. 8 Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbèríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin, àti dídùn inú ọmọ ènìyàn, aya àti obìnrin púpọ̀. 9 Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi. Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀.

    10 Èmi kò jẹ́ kí ojú mi ṣe aláìrí ohun tí ó bá ń fẹ́.

    N kò sì jẹ́ kí ọkàn mi ó ṣe aláìní ìgbádùn.

    Ọkàn mi yọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ mi,

    èyí sì ni èrè fún gbogbo wàhálà mi.

    11 Síbẹ̀, nígbà tí mo wo gbogbo ohun tí ọwọ́ mi ti ṣe

    àti ohun tí mo ti ṣe wàhálà láti ní:

    gbogbo rẹ̀, asán ni. Ó dàbí ẹni

    gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́, kò sí èrè kan ní abẹ́ oòrùn;

    ọgbọ́n àti òmùgọ̀, asán ni.

  4. 12 Nígbà náà ni mo tún bẹ̀rẹ̀ sí ọgbọ́n,

    àti ìsínwín àti àìgbọ́n

    kí ni ọba tí ó jẹ lẹ́yìn tí ọba kan kú le è ṣe

    ju èyí tí ọba ìṣáájú ti ṣe lọ.

    13 Mo sì ri wí pé ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀

    gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ.

    14 Ojú ọlọ́gbọ́n ń bẹ lágbárí rẹ̀,

    nígbà tí aṣiwèrè ń rìn nínú òkùnkùn,

    ṣùgbọ́n mo wá padà mọ̀

    wí pé ìpín kan náà ni ó ń dúró de ìsọ̀rí àwọn ènìyàn méjèèjì.

    15 Nígbà náà ni mo rò nínú ọkàn wí pé,

    “Irú ìpín tí òmùgọ̀ ní yóò bá èmi náà pẹ̀lú

    kí wá ni ohun tí mo jẹ ní èrè nípa ọgbọ́n?”

    Mo sọ nínú ọkàn mi wí pé,

    “Asán ni eléyìí pẹ̀lú.”

    16 Nítorí pé ọlọ́gbọ́n ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí i òmùgọ̀, a kì yóò rántí rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́;

    gbogbo wọn ni yóò di ohun ìgbàgbé ní ọjọ́ tó ń bọ̀.

    Ikú tí ó pa aṣiwèrè náà ni yóò pa ọlọ́gbọ́n ènìyàn.

    17 Nítorí náà, mo kórìíra ìwàláàyè, nítorí pé iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní abẹ́ oòrùn ti mú ìdààmú bá mi. Gbogbo rẹ̀ asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni. 18 Mo kórìíra gbogbo ohun tí mo ti ṣiṣẹ́ fún ní abẹ́ oòrùn, nítorí pé mo ní láti fi wọ́n sílẹ̀ fún ẹni tí ó wà lẹ́yìn mi ni. 19 Ta ni ó wá mọ̀ bóyá ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni yóò jẹ́ tàbí aṣiwèrè? Síbẹ̀ yóò ní láti ṣe àkóso lórí gbogbo iṣẹ́ tí mo tí ṣe yìí pẹ̀lú. 20 Nítorí náà, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí ní kábámọ̀ lórí gbogbo àìsimi iṣẹ́ ṣíṣe mi ní abẹ́ oòrùn. 21 Nítorí pé ènìyàn le è ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní abẹ́ oòrùn, tí ó sì ti kọ́ ṣe iṣẹ́ fúnra rẹ̀. Asán ni eléyìí pẹ̀lú àti àdánù ńlá. 22 Kí ni ohun tí ènìyàn rí gbà fún gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú tí ó fi ṣiṣẹ́ lábẹ́ oòrùn? 23 Gbogbo ọjọ́ rẹ, iṣẹ́ rẹ kún fún ìrora, àti ìbànújẹ́, kódà ọkàn rẹ̀ kì í ní ìsinmi ní alẹ́. Asán ni eléyìí pẹ̀lú.

    24  Ènìyàn kò le è ṣe ohunkóhun tí ó dára jù pé kí ó jẹ kí ó sì mu, kí ó sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ rẹ̀. Mo rí wí pé eléyìí pẹ̀lú wá láti ọwọ́ Ọlọ́run. 25 Nítorí wí pé láìsí òun, ta ni ó le jẹ tàbí kí ó mọ adùn? 26 Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹni dẹ́ṣẹ̀, Ó fún un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Eléyìí pẹ̀lú, asán ni, ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

  5. 1 Mo sì tún wò ó, mo sì rí gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn,

    mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni,

    wọn kò sì ní olùtùnú kankan,

    agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lára,

    wọn kò sì ní olùtùnú kankan.

    2 Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kú

    tí wọ́n sì ti lọ,

    ó sàn fún wọn ju àwọn

    tí wọ́n sì wà láààyè lọ.

    3 Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn ju

    àwọn méjèèjì lọ:

    ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburú

    tí ó ń lọ ní abẹ́ oòrùn.

    4 Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbára tagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùúgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

    5 Aṣiwèrè ká ọwọ́ rẹ̀ kò

    ó sì ba tara rẹ̀ jẹ́.

    6 Oúnjẹ ẹ̀kúnwọ́ kan pẹ̀lú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì pẹ̀lú wàhálà,

    àti gbígba ìyànjú àti lé afẹ́fẹ́ lọ.

    7 Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn.

    8 Ọkùnrin kan ṣoṣo dá wà;

    kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbí.

    Kò sí òpin nínú làálàá rẹ̀ gbogbo,

    síbẹ̀, ọrọ̀ kò tẹ́ ojú rẹ̀ lọ́rùn.

    Bẹ́ẹ̀ ni kò sì wí pé, “Nítorí ta ni èmí ṣe ń ṣe làálàá,

    àti wí pé, èétiṣe tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?”

    Eléyìí náà asán ni,

    iṣẹ́ òsì!

  6. 7 Ìmọ́lẹ̀ dùn;

    Ó sì dára fún ojú láti rí oòrùn.

    8 Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn jẹ̀gbádùn gbogbo iye ọdún

    tí ó le è lò láyé

    ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó rántí ọjọ́ òkùnkùn

    nítorí wọn ó pọ̀.

    Gbogbo ohun tí ó ń bọ̀ asán ni.

    9 Jẹ́ kí inú rẹ dùn, ìwọ ọ̀dọ́mọdé ní ìgbà tí o wà ní èwe

    kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ fún ọ ní ayọ̀ ní ìgbà èwe rẹ.

    Tẹ̀lé ọ̀nà ọkàn rẹ

    àti ohunkóhun tí ojú rẹ rí

    ṣùgbọ́n mọ̀ dájú pé nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni

    Ọlọ́run yóò mú ọ wá sí ìdájọ́.

    10 Nítorí náà, mú ìjayà kúrò ní ọkàn rẹ

    kí o sì lé ìbànújẹ́ ara rẹ kúrò

    nítorí èwe àti kékeré kò ní ìtumọ̀.

  7. 4 “Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi,

    àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí

    kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.

    5 Ìwọ ti ṣe ayé mi

    bí ìbú àtẹ́lẹwọ́,

    ọjọ́ orí mi sì dàbí asán

    ní iwájú rẹ.

    Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú

    ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela.

    6 “Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.

    Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;

    wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,

    wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.

  8. 18  Síbẹ̀síbẹ̀, ìyà tí a ń jẹ nísinsin yìí kò jámọ́ nǹkan nígbà tí a bá fiwé ògo tí yóò fún wa ní ìkẹyìn. 19  Nítorí ẹ̀dá ń dúró ní ìfojúsọ́nà de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run. 20  Nítorí a tẹrí ẹ̀dá ba fún asán, kì í ṣe bí òun ti fẹ́, ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ẹni tí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní ìrètí. 21  Nítorí a ó sọ ẹ̀dá tìkára rẹ̀ di òmìnira kúrò nínú ẹrú ìdíbàjẹ́, sí òmìnira ògo àwọn ọmọ Ọlọ́run.

    22  Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ẹ̀dá ni ó jùmọ̀ ń kérora tí ó sì ń rọbí pọ̀ títí di ìsinsin yìí. 23  Kì í ṣe àwọn nìkan, ṣùgbọ́n àwa tìkára wa pẹ̀lú, a ni àkóso ẹ̀mí, àní àwa tìkára wa ń kérora nínú ara wa, àwa ń dúró de ìsọdọmọ àní ìdáǹdè ara wa.

  9. 1 Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ

    ní ọjọ́ èwe rẹ,

    nígbà tí ọjọ́ ibi kò tí ì dé

    àti tí ọdún kò tí ì ní súnmọ́ etílé, nígbà tí ìwọ yóò wí pé,

    “Èmi kò ní ìdùnnú nínú wọn,”

    2 kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀

    àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn,

    àti kí àwọsánmọ̀ tó padà lẹ́yìn òjò;

    3 nígbà tí olùṣọ́ ilé yóò wárìrì

    tí àwọn ọkùnrin alágbára yóò tẹríba,

    nígbà tí àwọn tí ó ń lọ dákẹ́ nítorí pé wọn kò pọ̀,

    tí àwọn tí ń wo òde láti ojú fèrèsé yóò ṣókùnkùn;

    4 nígbà tí ìlẹ̀kùn sí ìgboro yóò tì

    tí ariwo ọlọ yóò dákẹ́;

    nígbà tí àwọn ènìyàn yóò dìde sí ariwo àwọn ẹyẹ

    ṣùgbọ́n gbogbo orin wọn yóò máa lọ ilẹ̀.

    5 Nígbà tí ènìyàn yóò bẹ̀rù ibi gíga

    àti ti ìfarapa ní ìgboro;

    nígbà tí igi almondi yóò tanná

    àti tí ẹlẹ́ǹgà yóò wọ́ ara rẹ̀ lọ

    tí ìfẹ́ kò sì ní ru sókè mọ́

    nígbà náà ni ènìyàn yóò lọ ilé rẹ́ ayérayé

    tí àwọn aṣọ̀fọ̀ yóò máa rìn kiri ìgboro.

    6 Rántí rẹ̀ kí okùn fàdákà tó já,

    tàbí kí ọpọ́n wúrà tó fọ́;

    kí iṣà tó fọ́ níbi ìsun,

    tàbí kí àyíká kẹ̀kẹ́ kí ó tó kán níbi kànga.

    7 Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà,

    tí ẹ̀mí yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni.

    8 “Asán! Asán!” ni Oniwaasu wí.

    “Gbogbo rẹ̀ asán ni!”

    9 Kì í ṣe wí pé Oniwaasu jẹ́ ọlọ́gbọ́n nìkan, ṣùgbọ́n ó tún kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀. Ó rò ó dáradára ó sì ṣe àwárí, ó sì gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe kalẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ. 10 Oniwaasu wádìí láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀nà, ohun tí ó kọ sì dúró ṣinṣin ó sì jẹ́ òtítọ́.

    11 Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ wọn sì dàbí ìṣó tí a kàn pọ̀ dáradára, tí olùṣọ́-àgùntàn kan fi fún ni. 12 Àti síwájú láti inú èyí, ọmọ mi, gba ìmọ̀ràn.

    Nínú ìwé púpọ̀, òpin kò sí, ìwé kíkà púpọ̀ a máa mú ara ṣàárẹ̀.

    13 Nísinsin yìí,

    òpin gbogbo ọ̀rọ̀ tí a gbọ́ ni pé,

    bẹ̀rù Ọlọ́run, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́,

    nítorí èyí ni ojúṣe gbogbo ènìyàn.

    14 Nítorí Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ olúkúlùkù iṣẹ́

    àti ohun ìkọ̀kọ̀,

    kì bá à ṣe rere kì bá à ṣe búburú.

  10. 1 Mo ti rí ibi mìíràn lábẹ́ oòrùn. 2 Ọlọ́run fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀, ọlá àti ọlà kí ó má ba à ṣe aláìní ohunkóhun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kò fún un ní àǹfààní láti gbádùn wọn, dípò èyí, àlejò ni ó ń gbádùn wọn. Asán ni èyí, ààrùn búburú gbá à ni.

    3 Ọkùnrin kan le è ní ọgọ́rùn-ún ọmọ kí ó sì wà láààyè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, síbẹ̀ kò sí bí ó ti le wà láààyè pẹ́ tó, bí kò bá le è gbádùn ohun ìní rẹ̀ kí ó sì gba ìsìnkú tí ó tọ́, mo sọ wí pé ọlẹ̀ ọmọ tí a sin sàn jù ú lọ. 4 Ó wà láìní ìtumọ̀, ó lọ nínú òkùnkùn, nínú òkùnkùn sì ni orúkọ rẹ̀ fi ara pamọ́ sí. 5 Bí ó ti jẹ́ wí pé kò rí oòrùn tàbí mọ ohunkóhun, ó ní ọ̀pọ̀ ìsinmi ju ti ọkùnrin náà lọ. 6 Kódà, bí ó wà láààyè fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún méjì yípo ṣùgbọ́n tí ó kùnà láti gbádùn ohun ìní rẹ̀. Kì í ṣe ibìkan ni gbogbo wọn ń lọ?

    7 Gbogbo wàhálà tí ènìyàn ń ṣe nítorí àtijẹ ni

    síbẹ̀ ikùn rẹ̀ kò yó rí.

    8 Kí ni àǹfààní tí ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní lórí aṣiwèrè?

    Kí ni èrè tálákà ènìyàn

    nípa mímọ bí yóò ṣe hùwà níwájú àwọn tókù?

    9 Ohun tí ojú rí sàn

    ju ìfẹnuwákiri lọ.

    Asán ni eléyìí pẹ̀lú

    ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

    10 Ohunkóhun tí ó bá ti wà ti ní orúkọ,

    ohun tí ènìyàn jẹ́ sì ti di mí mọ̀;

    kò sí ènìyàn tí ó le è ja ìjàkadì

    pẹ̀lú ẹni tí ó lágbára jù ú lọ.

    11 Ọ̀rọ̀ púpọ̀,

    kì í ní ìtumọ̀

    èrè wo ni ènìyàn ń rí nínú rẹ̀?

    12 Àbí, ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún ènìyàn ní ayé fún ọjọ́ ayé kúkúrú àti asán tí ó ń là kọjá gẹ́gẹ́ bí òjìji? Ta ni ó le è sọ fún mi, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn lẹ́yìn tí ó bá lọ tán? Kò sí!

  11. 10 Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító,

    ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùn

    pẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún un.

  12. 11 Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀

    fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀,

    ìwọ a mú ẹwà rẹ parun

    bí kòkòrò aṣọ;

    nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.

  13. 30 Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán

    nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn.

  14. 17 Ǹjẹ́ èyí ni mo ń wí, tí mo sì ń jẹ́rìí nínú Olúwa pé, láti ìsinsin yìí lọ, kí ẹ̀yin má ṣe rìn mọ́, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà ti ń rìn nínú ìrònú asán wọn. 18 Òye àwọn ẹni tí ó ṣókùnkùn, a sì yà wọ́n nínú ìyè Ọlọ́run nítorí àìmọ̀ tí ń bẹ nínú wọn, nítorí líle ọkàn wọn.

  15. 3 Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún un,

    tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa rẹ̀?

    4 Ènìyàn rí bí èmi;

    ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.

  16. 15 Wọ́n kọ̀ ìlànà rẹ̀ àti májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú baba wọn àti ìkìlọ̀ tí ó ti fi fún wọn. Wọ́n tẹ̀lé òrìṣà aláìníláárí, àwọn fún rara wọn sì jẹ́ aláìníláárí. Wọ́n tẹ̀lé orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti kìlọ̀ fún wọn pé, “Má ṣe ṣe gẹ́gẹ́ bí wọn tí ń ṣe,” wọ́n sì ṣe ohun tí Olúwa ti kà léèwọ̀ fún wọn láti ṣe.

  17. 37 Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán:

    pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.

  18. 11 Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ,

    ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i.

    12 Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀

    ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.

  19. 5 Báyìí ni Olúwa wí:

    “Irú àìṣedéédéé wo ni baba yín rí lọ́wọ́ mi,

    tí wọ́n fi jìnnà sí mi?

    Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán,

    àwọn fúnra wọn sì di asán.

  20. 17 Àwọn wọ̀nyí ni kànga tí kò ní omi, ìkùùkuu tí ẹ̀fúùfù ń gbá kiri; àwọn ẹni tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè títí láé. 18 Nítorí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ asán, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, wọn a máa tan àwọn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ má tí ì bọ́ tán kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n wà nínú ìṣìnà. 19 Wọn a máa ṣe ìlérí òmìnira fún wọn, nígbà tí àwọn pàápàá jẹ́ ẹrú ìdíbàjẹ́; nítorí ènìyàn tí di ẹrú ohunkóhun tí ó bá ṣe ọ̀gá rẹ̀. 20 Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ tán kúrò nínú èérí ayé nípa mímọ́ Olúwa àti Olùgbàlà wá Jesu Kristi, bí wọn bá sì tún fi ara kó o, tí a sì ṣẹ́gun wọn, ìgbẹ̀yìn wọn a burú jú ti ìṣáájú lọ. 21 Nítorí ìbá sàn fún wọn, kí wọn má mọ́ ọ̀nà òdodo, jù pé lẹ́yìn tí wọ́n mọ̀ ọ́n tán, kí wọn yípadà kúrò nínú òfin mímọ́ tí a fi fún wọn. 22  Òwe òtítọ́ náà ṣẹ sí wọn lára, “Ajá tún padà sí èébì ara rẹ̀; àti ẹlẹ́dẹ̀ tí a ti wẹ̀mọ́ tún padà ń yíràá nínú ẹrọ̀fọ̀.”

  21. 2 Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú?

    Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké?

  22. 8 Kíyèsi i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyàn;

    ẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?

    9 Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bí?

    Ẹni tí ó dá ojú?

    Ó ha lè ṣe aláìríran bí?

    10 Ẹni tí ń bá orílẹ̀-èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni ṣọ́nà bí?

    Ẹni tí ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?

    11 Olúwa mọ èrò inú ènìyàn;

    ó mọ̀ pé asán ni wọ́n.

  23. 8 Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi;

    má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀,

    ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan.

  24. 19 Olúwa, alágbára àti okun mi,

    ẹni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú,

    àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá láti

    òpin ayé wí pé,

    “Àwọn baba ńlá wa kò ní ohun kan bí kò ṣe ẹ̀gbin òrìṣà,

    ìríra tí kò dára fún wọn nínú rẹ̀.

  25. 16 O sú mi, èmi kò le wà títí:

    jọ̀wọ́ mi jẹ́, nítorí pé asán ni ọjọ́ mi.

  26. 7  Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ;

    wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.

  27. 6 Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí;

    ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

  28. 16 Gbogbo àwọn tí ó wà níwájú wọn kò sì lópin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ní ó jẹ ọba lé lórí, ẹni tí ó wà ní ipò yìí kò dùn mọ́ àwọn tí ó tẹ̀lé wọn nínú. Asán ni eléyìí pẹ̀lú jẹ́, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

  29. 9 Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán,

    àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́

    kò jámọ́ nǹkan kan.

    Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú;

    wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan sí ìtìjú ara wọn.

    10 Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère,

    tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?

    11 Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójútì;

    àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n.

    Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sì

    fi ìdúró wọn hàn;

    gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú ìpayà àti àbùkù.

  30. 6 Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,

    wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀;

    nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.

  31. 9 Nítòótọ́, asán ni àwọn ọmọ ènìyàn,

    èké sì ni àwọn olóyè,

    wọ́n gòkè nínú ìwọ̀n,

    lápapọ̀ wọ́n jẹ́ èémí.

  32. 33 O fi òpin sí ayé wọn nínú asán

    àti ọdún wọn nínú ìpayà.

  33. 6 Ìṣúra tí a kójọ nípasẹ̀ ahọ́n tí ń parọ́

    jẹ́ ìrì lásán àti ìkẹ́kùn ikú.

  34. 13 Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́

    ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín!

    Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ,

    èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ.

    Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀

    ni yóò jogún ilẹ̀ náà

    yóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”

  35. 6 Àwọn ẹlòmíràn ti yapa kúrò tí wọ́n sì yà sápá kan sí ọ̀rọ̀ asán. 7 Wọ́n ń fẹ́ ṣe olùkọ́ òfin; òye ohun tí wọ́n ń wí kò yé wọn tàbí ti ohun tí wọ́n ń fi ìgboyà tẹnumọ́.

  36. 31 Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀lé asán, kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ.

    Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀.

  37. 1  Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀,

    àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?

  38. 7 Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìsinsin yìí ni Ọlọ́run síjú àánú wo ohun tí o ṣe. 8 Máa wọ aṣọ funfun nígbàkígbà kí o sì máa fi òróró yan orí rẹ nígbà gbogbo. 9 Máa jẹ ayé pẹ̀lú ìyàwó rẹ, ẹni tí o fẹ́ràn, ní gbogbo ọjọ́ ayé àìní ìtumọ̀ yí tí Ọlọ́run ti fi fún ọ lábẹ́ oòrùn—gbogbo ọjọ́ àìní ìtumọ̀ rẹ. Nítorí èyí ni ìpín tìrẹ ní ayé àti nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ ní abẹ́ oòrùn. 10 Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, ṣe é pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, nítorí kò sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ìpinnu tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú isà òkú níbi tí ò ń lọ.

  39. 29 Kíyèsi i, irọ́ ni gbogbo wọn!

    Gbogbo ìṣe wọn jásí asán;

    àwọn ère wọn kò ṣé kò yà fún afẹ́fẹ́ àti dàrúdàpọ̀.

  40. 18  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn. 19 Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn. 20  Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀, bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.

    21  Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn. 22 Níwọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá, 23  wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kì í díbàjẹ́ sí àwọn àwòrán ère bí i ti ènìyàn tí í díbàjẹ́ àti ti ẹyẹ, àti ti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti ti ẹranko afàyàfà.

  41. 8 Nítorí ṣíṣe eré-ìdárayá ni èrè fún ohun díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run ni èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti ìgbé ayé ìsinsin yìí àti ti èyí tí ń bọ̀.

  42. 2 Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù

    láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá;

    bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.

  43. 19 Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀

    ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun asán yóò kún fún òsì.

  44. 13 Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe:

    “Ta ni ó le è to

    ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?”

    14 Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn,

    ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó:

    Ọlọ́run tí ó dá èkínní

    náà ni ó dá èkejì.

    Nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwárí

    ohun kankan nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀.

    15 Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí

    ènìyàn olóòtítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀

    ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀.

  45. 10 Nígbà náà ni mo tún rí ìsìnkú ènìyàn búburú—àwọn tí wọ́n máa ń wá tí wọ́n sì ń lọ láti ibi mímọ́ kí wọn sì gba ìyìn ní ìlú tàbí tí wọ́n ti ṣe èyí. Eléyìí pẹ̀lú kò ní ìtumọ̀.

    11 Nígbà tí a kò bá tètè ṣe ìdájọ́ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kíákíá, ọkàn àwọn ènìyàn a máa kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ láti ṣe ibi. 12 Bí ènìyàn búburú tó dẹ́ṣẹ̀ nígbà ọgọ́rùn-ún tilẹ̀ wà láààyè fún ìgbà pípẹ́, mo mọ̀ wí pé yóò dára fún ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó bẹ̀rù níwájú rẹ̀. 13 Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dára fún ènìyàn búburú, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fa ọjọ́ rẹ̀ gún tí ó dà bí òjìji, nítorí tí kò bẹ̀rù níwájú Ọlọ́run.

    14 Ohun mìíràn tún wà tí kò ní ìtumọ̀, tí ó ń ṣẹlẹ̀ láyé olódodo tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí òṣìkà àti ènìyàn búburú tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí olódodo. Mo sọ wí pé eléyìí gan an kò ní ìtumọ̀. 15 Nítorí náà mo kan sáárá sí ìgbádùn ayé, nítorí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ní abẹ́ oòrùn ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí inú rẹ̀ sì dùn lọ. Nígbà náà ni ìdùnnú yóò bá a rìn nínú iṣẹ́ ẹ rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé ti Ọlọ́run tí fi fún un lábẹ́ oòrùn.

    16 Nígbà tí mo lo ọkàn mi láti mọ ọgbọ́n àti láti wo wàhálà ènìyàn ní ayé. 17 Nígbà náà ni mo rí gbogbo ohun tí Ọlọ́run tí ṣe, kò sí ẹnìkan tí ó le è mòye ohun tí ó ń lọ lábẹ́ oòrùn. Láìbìkítà gbogbo ìyànjú rẹ̀ láti wá rí jáde, ènìyàn kò le è mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kódà bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn rò wí pé òun mọ̀ ọ́n, kò le è ní òye rẹ̀ ní pàtó.

  46. 13 Àlìkámà ni wọn yóò gbìn, ṣùgbọ́n ẹ̀gún ni wọn yóò ká,

    wọn yóò fi ara wọn ṣe wàhálà, ṣùgbọ́n òfo ni èrè wọn.

    Kí ojú kí ó tì yín nítorí èrè yín,

    nítorí ìbínú gbígbóná Olúwa.

  47. 20  lẹ́ẹ̀kan sí i, “Olúwa mọ̀ èrò inú àwọn ọlọ́gbọ́n pé asán ní wọn.”

  48. 3 Bí mo bá fi gbogbo nǹkan tí mo ní tọrẹ fún àwọn aláìní, tí mo sì fi ara mi fún ni láti sùn ṣùgbọ́n tí n kò ní ìfẹ́, kò ní èrè kan fún mi.

  49. 20 Timotiu, máa ṣọ ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ, yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán àti ìjiyàn ohun tí a ń fi èké pè ni ìmọ̀; 21 èyí tí àwọn ẹlòmíràn jẹ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ṣìnà ìgbàgbọ́.

    Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú rẹ.

  50. 14 Nǹkan wọ̀nyí ni ki ó máa rán wọn létí. Máa kìlọ̀ fún wọn níwájú Olúwa pé, ki wọn ó yẹra kúrò nínú jíjiyàn ọ̀rọ̀ tí kò léèrè, bí kò ṣe ìparun fún àwọn tí ń gbọ́. 15 Ṣaápọn láti fi ara rẹ̀ hàn níwájú Ọlọ́run bi ẹni tí ó yege àti òṣìṣẹ́ tí kò ní láti tijú, tí ó ń pín ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ. 16 Yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán, nítorí tiwọn máa síwájú nínú àìwà-bí-Ọlọ́run. 17 Ọ̀rọ̀ wọn yóò sì máa fẹ́ bí egbò kíkẹ̀; nínú àwọn ẹni tí Himeneu àti Filetu wà; 18 àwọn ẹni tí ó ti ṣìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ń wí pé àjíǹde ti kọjá ná; tí wọ́n sì ń bi ìgbàgbọ́ àwọn mìíràn ṣubú. 19  Ṣùgbọ́n ìpìlẹ̀ Ọlọ́run tí ó dájú dúró ṣinṣin, ó ní èdìdì yìí, pé, “Olúwa mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” Àti pẹ̀lú, “Kí olúkúlùkù ẹni tí ń pé orúkọ Olúwa kúrò nínú àìṣòdodo.”

    20 Ṣùgbọ́n nínú ilé ńlá, kì í ṣe kìkì ohun èlò wúrà àti ti fàdákà nìkan ni ń bẹ, ṣùgbọ́n ti igi àti amọ̀ pẹ̀lú; àti òmíràn sí ọlá, àti òmíràn sí àìlọ́lá. 21 Bí ẹnikẹ́ni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìwọ̀nyí, òun yóò jẹ́ ohun èlò sí ọlá, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó sì yẹ fún ìlò baálé, tí a sì ti pèsè sílẹ̀ fún iṣẹ́ rere gbogbo.

    22 Máa sá fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ èwe, sì máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn tí ń ké pe Olúwa láti inú ọkàn funfun wá. 23 Ìbéèrè òmùgọ̀ àti aláìní ẹ̀kọ́ nínú ni kí o kọ̀, bí o ti mọ̀ pe wọn máa dá ìjà sílẹ̀. 24 Ìránṣẹ́, Olúwa kò sì gbọdọ̀ jà; bí kò ṣe kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí ènìyàn gbogbo ẹni tí ó lè kọ́ni, àti onísùúrù. 25 Ẹni tí yóò máa kọ́ àwọn alátakò pẹ̀lú ìwà tútù, ní ìrètí pé Ọlọ́run lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà sí ìmọ̀ òtítọ́, 26 wọn ó sì lè bọ́ kúrò nínú ìdẹ̀kùn èṣù, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti mú wọn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

  51. 9 Ṣùgbọ́n yẹra kúrò nínú àwọn ìbéèrè òmùgọ̀, àti ìtàn ìran, àti àríyànjiyàn àti ìjà nípa ti òfin, nítorí pé àwọn nǹkan báyìí jẹ́ aláìlérè àti asán. 10 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ dá ìyapa sílẹ̀ láàrín yín, ẹ bá a wí lẹ́ẹ̀kínní àti lẹ́ẹ̀kejì. Lẹ́yìn náà, ẹ má ṣe ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú rẹ̀. 11 Kí ó dá ọ lójú wí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti yapa, ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì dá ara rẹ̀ lẹ́bi.

  52. 13 Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀, ẹ kó ara yín ní ìjánu, kí ẹ sì fi ìrètí yín ní kíkún sí oore-ọ̀fẹ́, èyí tí a ń mu bọ̀ fún yin ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. 14 Bí àwọn ọmọ tí ń gbọ́rọ̀, ẹ ma ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ́. 15 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o pè yin ti jẹ mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ mímọ́. 16  Nítorí a ti kọ ọ pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́: nítorí tí Èmi jẹ mímọ́!”

    17 Níwọ́n bí ẹ̀yin ti ń ké pe Baba, ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù láìṣe ojúsàájú, ẹ máa lo ìgbà àtìpó yin ni ìbẹ̀rù. 18 Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín padà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín. 19 Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí i ti ọ̀dọ́-àgùntàn ti kò lábùkù, tí kò sì lábàwọ́n, àní, ẹ̀jẹ̀ Kristi. 20 Ẹni tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nítòótọ́ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn ní ìgbà ìkẹyìn wọ̀nyí nítorí yín. 21 Àní ẹ̀yin tí o tipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni ti ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì fi ògo fún un; kí ìgbàgbọ́ àti ìrètí yín lè wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

    22 Níwọ́n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnìkejì yín gidigidi láti ọkàn wá. 23 Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láààyè tí ó sì dúró. 24  Nítorí pé,

    “Gbogbo ènìyàn dàbí koríko,

    àti gbogbo ògo rẹ̀ bi ìtànná koríko.

    Koríko á máa gbẹ ìtànná a sì máa rẹ̀ dànù,

    25 ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé.”

    Ọ̀rọ̀ náà yìí sì ni ìyìnrere tí a wàásù fún yín.

  53. 15 Ẹ má ṣe fẹ́ràn ayé tàbí ohunkóhun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn ayé, ìfẹ́ tí Baba kò sí nínú rẹ̀. 16 Nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ojú, àti ìgbéraga ti ohun ti ó ní àti ohun tí ó ṣe kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bí kò ṣe láti ọwọ́ ayé. 17 Ayé sì ń kọjá lọ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò wà títí láéláé.

  54. 11 Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá,

    nítorí asán ni ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.

  55. 11 Ẹni tí ó bá dá oko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,

    ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásán làsàn kò gbọ́n.

  56. 16 Mo sì tún rí ohun mìíràn ní

    abẹ́ ọ̀run dípò ìdájọ́,

    òdodo ni ó wà níbẹ̀ dípò ètò òtítọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ni o wà níbẹ̀.

    17 Mo wí nínú ọkàn mi,

    “Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́

    olódodo àti ènìyàn búburú,

    nítorí pé àsìkò yóò wà fún gbogbo iṣẹ́,

    àti àsìkò ṣe ìdájọ́ gbogbo ìṣe.”

    18 Mo tún rò pé “Ọlọ́run ń dán wa wò láti fihàn wá wí pé bí ẹranko ni ènìyàn rí. 19 Ó ní láti jẹ́ ohun ìrántí pé ìpín ènìyàn rí bí i tẹranko ìpín kan náà ń dúró dè wọ́n. Bí ọ̀kan ti ń kú náà ni èkejì yóò kú. Àwọn méjèèjì ni irú èémí kan náà, ènìyàn kò sàn ju ẹranko lọ, nítorí pé asán ni yíyè jẹ́ fún wọn. 20 Ibìkan náà ni gbogbo wọn ń lọ, wọ́n wá láti inú erùpẹ̀, inú erùpẹ̀ náà ni wọn yóò tún padà sí. 21 Ta ni ó mọ̀ bóyá ẹ̀mí ènìyàn ń lọ sí òkè tí ẹ̀mí ẹranko sì ń lọ sí ìsàlẹ̀ nínú ilẹ̀ ni?”

    22 Nígbà náà, ni mo wá rí i wí pé, kò sí ohun tí ó sàn fún ènìyàn ju kí ó gbádùn iṣẹ́ rẹ̀, nítorí pé ìpín tirẹ̀ ni èyí. Tàbí ta ni ó le è mú kí ó rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ kò sí!

  57. 6 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkò

    ni ẹ̀rín òmùgọ̀.

    Asán sì ni eléyìí pẹ̀lú.

  58. 13 Ẹ má mú ọrẹ asán wá mọ́!

    Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi,

    oṣù tuntun àti ọjọ́ ìsinmi àti àwọn àpéjọ,

    Èmi kò lè faradà á, ẹ̀ṣẹ̀ ni àpéjọ yín wọ̀nyí.

  59. 32 Nítòótọ́, mo lòdì sí àwọn tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àlá èké,” ni Olúwa wí. “Wọ́n ń sọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń mú àwọn ènìyàn mi ṣìnà nípa onírúurú èké wọn, síbẹ̀ èmi kò rán wọn tàbí yàn wọ́n. Wọn kò sì ran àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ́wọ́ bí ó ti wù kí ó kéré mọ,” ni Olúwa wí.

  60. 13 “Ẹ̀yin ti sọ ọ̀rọ̀ líle sí mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

    “Síbẹ̀ ẹ̀yin béèrè pé, ‘Ọ̀rọ̀ kín ni àwa sọ sí ọ?’

    14 “Ẹ̀yin ti wí pé, ‘Asán ni láti sin Ọlọ́run. Kí ni àwa jẹ ní èrè, nígbà tí àwa ti pa ìlànà rẹ mọ́, tí àwa sì ń rìn kiri bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ní iwájú Olúwa àwọn ọmọ-ogun? 15 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí àwa pé agbéraga ni alábùkún fún. Ní òtítọ́ ni àwọn ti ń ṣe búburú ń gbèrú sí i, kódà àwọn ti ó dán Ọlọ́run wò ni a dá sí.’ ”

    16 Nígbà náà ni àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa ń ba ara wọn sọ̀rọ̀, Olúwa sì tẹ́tí sí i, ó sì gbọ́. A sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀, fún àwọn tí o bẹ̀rù Olúwa, tiwọn sì bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀.

    17 “Wọn yóò sì jẹ́ tèmi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “ni ọjọ́ náà, tí èmi ó dá; èmi yóò sì da wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí máa ń dá ọmọ rẹ̀ tí yóò sìn ín sí. 18 Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rí ìyàtọ̀, ìyàtọ̀ láàrín olódodo àti ẹni búburú, láàrín ẹni tí ń sìn Ọlọ́run, àti ẹni tí kò sìn ín.

  61. 7 Ṣùgbọ́n nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán bí àwọn aláìkọlà, nítorí wọn rò pé a ó tìtorí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ gbọ́ tiwọn.

  62. 23 Nígbà tí wọ́n sì ti fi wọ́n sílẹ̀ wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà sọ fún wọn. 24  Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n fi ọkàn kan gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run, wọ́n sì wí pé, “Olúwa Olódùmarè, ìwọ tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn. 25  Ìwọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ti ẹnu Dafidi baba wa ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé:

    “ ‘E é ṣe tí àwọn kèfèrí fi ń bínú,

    àti tí àwọn ènìyàn ń gbèrò ohun asán?

    26 Àwọn ọba ayé dìde,

    àti àwọn ìjòyè kó ara wọn

    jọ sí Olúwa,

    àti sí ẹni àmì òróró rẹ̀.’

    27  Àní nítòótọ́ ní Herodu àti Pọntiu Pilatu, pẹ̀lú àwọn aláìkọlà àti àwọn ènìyàn Israẹli kó ara wọn jọ ní ìlú yìí láti dìtẹ̀ sí Jesu Ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ, ẹni tí ìwọ ti fi àmì òróró yàn, 28 láti ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ rẹ̀ ti pinnu ṣáájú pé yóò ṣe. 29 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Olúwa, kíyèsi ìhàlẹ̀ wọn; kí ó sì fi fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ láti máa fi ìgboyà ńlá sọ ọ̀rọ̀ rẹ. 30 Kí ìwọ sì fi nína ọwọ́ rẹ ṣe ìmúláradá, àti kí iṣẹ́ ìyanu máa ṣẹ̀ ní orúkọ Jesu ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ.”

    31 Nígbà tí wọ́n gbàdúrà tan, ibi tí wọ́n gbé péjọpọ̀ sí mì tìtì; gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n sì ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

  63. 1  Nítorí náà mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín ará, kí ẹ̀yin kí ó fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè mímọ́, ìtẹ́wọ́gbà, èyí ni iṣẹ́ ìsìn yín tí ó tọ̀nà. 2  Kí ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí; ṣùgbọ́n kí ẹ paradà láti di tuntun ní èrò inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọ́run, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ti ó sì pé.

  64. 9 Ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbá yin kiri. Nítorí ó dára kí a mú yin lọ́kàn le nípa oore-ọ̀fẹ́, kì í ṣe nípa oúnjẹ nínú èyí tí àwọn tí ó ti rìn nínú wọn kò ní èrè.

  65. 14 Èrè kí ni ó jẹ́, ará mi, bí ẹni kan wí pé òun ní ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí kò ní àwọn iṣẹ́ láti fihan? Ìgbàgbọ́ náà lè gbà á là bí?

  66. 2 Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè,

    ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.

  67. 12 Èmi yóò ṣí òdodo yín páyà àti iṣẹ́ yín,

    wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.

  68. 8 Ẹ wò ó, ẹ ń gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí kò níláárí gbọ́.

  69. 14  Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí,

    “Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn

    àti gbogbo ẹranko igbó tókù lọ!

    Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́,

    ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀

    ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

    15  Èmi yóò sì fi ọ̀tá

    sí àárín ìwọ àti obìnrin náà,

    àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà;

    òun yóò fọ́ orí rẹ,

    ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”

    16 Ọlọ́run wí fún obìnrin náà pé,

    “Èmi yóò fi kún ìrora rẹ ní àkókò ìbímọ;

    ni ìrora ni ìwọ yóò máa bí ọmọ.

    Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí,

    òun ni yóò sì máa ṣe àkóso rẹ.”

    17  Ọlọ́run sì wí fún Adamu pé, “Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’

    “Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ;

    nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀,

    ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

    18 Ilẹ̀ yóò sì hu ẹ̀gún àti èṣùṣú fún ọ,

    ewéko igbó ni ìwọ yóò sì máa jẹ.

    19 Nínú òógùn ojú rẹ

    ni ìwọ yóò máa jẹun

    títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀,

    nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá;

    erùpẹ̀ ilẹ̀ sá à ni ìwọ,

    ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀.”

  70. 47 Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tó

    nítorí asán ha ni ìwọ fi ṣẹ̀dá àwọn ènìyàn!

  71. 3 Nítorí pé asán ni àṣà àwọn ènìyàn,

    wọ́n gé igi láti inú igbó,

    oníṣọ̀nà sì gbẹ́ ẹ pẹ̀lú àáké rẹ̀.

    4 Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́.

    Wọ́n fi òòlù kàn án àti ìṣó

    kí ó má ba à ṣubú.

    5 Wọ́n wé mọ́ igi bí ẹ̀gúnsí inú oko,

    òrìṣà wọn kò le è fọhùn.

    Wọ́n gbọdọ̀ máa gbé

    wọn nítorí pé wọn kò lè rìn.

    Má ṣe bẹ̀rù wọn;

    wọn kò le è ṣe ibi kankan

    bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si lè ṣe rere kan.”

  72. 15  “Ará, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ènìyàn bí ẹ̀yin náà ni àwa ń ṣe pẹ̀lú, ti a sì ń wàásù ìyìnrere fún yín, kí ẹ̀yin ba à lè yípadà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sí Ọlọ́run alààyè, tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn. 16 Ní ìran tí ó ti kọjá, ó faradà á fún gbogbo orílẹ̀-èdè, láti máa rìn ni ọ̀nà tiwọn.

  73. 10 Ṣùgbọ́n nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run mo rí bí mo ti rí: oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí a fi fún mi kò sì jẹ́ asán; ṣùgbọ́n mó ṣiṣẹ́ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ jú gbogbo wọn lọ, ṣùgbọ́n kì í ṣe èmi, bí kò ṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ó wà pẹ̀lú mi.

  74. 17  Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kristi, ó di ẹ̀dá tuntun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsi i, ohun tuntun ti dé.

  75. 15 Nítorí pé nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà, bí kò ṣe ẹ̀dá tuntun.