36 Bible Verses About Beauty

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Beauty
  1. 1 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín; pé, bí ẹnikẹ́ni ba tilẹ̀ ń ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láì sọ̀rọ̀ nípa ìwà àwọn aya wọn. 2 Nígbà tí wọ́n bá ń wo ìwà rere pẹ̀lú ẹ̀rù yín. 3 Kí ọ̀ṣọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀ṣọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀; 4 ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó fi ara sin ní ọkàn, nínú ọ̀ṣọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run. 5 Nítorí báyìí ni àwọn obìnrin mímọ́ ìgbàanì pẹ̀lú, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, wọn a máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọn. 6  Gẹ́gẹ́ bí Sara ti gbọ́ ti Abrahamu, tí ó ń pè é ní olúwa rẹ̀. Ọmọbìnrin ẹni tí ẹ̀yin jẹ́, bí ẹ̀yin bá ń ṣe rere, tí ohunkóhun kò sí dẹ́rùbà yín.

  2. 7 Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ti ìrísí rẹ̀ tàbí ti gíga rẹ̀, nítorí èmi ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Olúwa kì í wo ohun tí ènìyàn máa ń wò. Ènìyàn máa ń wo òde ara ṣùgbọ́n Olúwa máa ń wo ọkàn.”

  3. 30 Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán

    nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn.

  4. 13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;

    ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.

    14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;

    ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;

    èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú.

    15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,

    nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.

    Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,

    16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi

    nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé,

    àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,

    ní ọjọ́ tí a dá wọn,

    nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.

  5. 9 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí àwọn obìnrin fi aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe ara wọn ní ọ̀ṣọ́, ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti pẹ̀lú ìwà àìrékọjá; kì í ṣe pẹ̀lú irun dídì, tàbí wúrà, tàbí peali, tàbí aṣọ olówó iyebíye, 10 bí kò ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rere, èyí tí ó yẹ fún àwọn obìnrin tó jẹ́wọ́ pé wọ́n sin Ọlọ́run.

  6. 11 Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, síbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.

  7. 2 Òun dàgbàsókè níwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ irúgbìn,

    àti gẹ́gẹ́ bí i gbòǹgbò tí ó jáde láti inú ìyàngbẹ ilẹ̀.

    Òun kò ní ẹwà tàbí ògo láti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀,

    kò sí ohun kankan nínú àbùdá rẹ̀

    tí ó fi yẹ kí a ṣàfẹ́rí i rẹ̀.

    3 A kẹ́gàn rẹ̀ àwọn ènìyàn sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,

    ẹni ìbànújẹ́, tí ó sì mọ bí ìpọ́njú ti rí.

    Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí àwọn ènìyàn ń fojú pamọ́ fún

    a kẹ́gàn rẹ, a kò sì bu ọlá fún un rárá.

    4  Lóòtítọ́ ó ti ru àìlera wa lọ

    ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú,

    síbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù,

    tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú.

    5  Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa

    a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa;

    ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀,

    àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá.

    6 Gbogbo wa bí àgùntàn, ti ṣìnà lọ,

    ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀;

    Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀

    gbogbo àìṣedéédéé wa.

    7  A jẹ ẹ́ ní yà, a sì pọ́n ọn lójú,

    síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀;

    a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà,

    àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀,

    síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.

  8. 8 Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia;

    láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe

    orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn.

    9 Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba

    wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀,

    ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró

    nínú wúrà Ofiri.

    10 Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi

    gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ.

    11 Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà rẹ gidigidi

    nítorí òun ni olúwa rẹ

    kí ìwọ sì máa tẹríba fún un.

  9. 23 Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ fìtílà,

    ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀,

    àti ìtọ́nisọ́nà ti ìbáwí

    ni ọ̀nà sí ìyè.

    24 Yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin búburú,

    kúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn obìnrin àjèjì.

    25 Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ si nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹ

    tàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra.

    26 Nítorí pé nípasẹ̀ àgbèrè obìnrin ni ènìyàn fi ń di oníṣù-àkàrà kan,

    ṣùgbọ́n àyà ènìyàn a máa wá ìyè rẹ̀ dáradára.

  10. 25 “Nítorí náà, mo wí fún yín, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, ohun tí ẹ ó jẹ àti èyí tí ẹ ó mu; tàbí nípa ara yín, ohun tí ẹ ó wọ̀. Ṣé ẹ̀mí kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ tàbí ara ni kò ha ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ? 26 Ẹ wo àwọn ẹyẹ ojú ọrun; wọn kì í gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kójọ sínú àká, síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ̀yin kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí? 27 Ta ni nínú gbogbo yín nípa àníyàn ṣíṣe ti ó lè fi ìṣẹ́jú kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀?

    28 “Kí ni ìdí ti ẹ fi ń ṣe àníyàn ní ti aṣọ? Ẹ wo bí àwọn lílì tí ń bẹ ní igbó ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. 29 Bẹ́ẹ̀ ni mo wí fún yín pé, a kò ṣe Solomoni lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí.

  11. 25 Kó sì sí arẹwà kan ní gbogbo Israẹli tí à bá yìn bí Absalomu: láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀ kò sí àbùkù kan lára rẹ̀.

  12. 15 Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;

    kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.

    16 Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;

    ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.

    17 Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura,

    òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà.

    18 Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á;

    àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.

  13. 7 Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwà, olólùfẹ́ mi;

    kò sì ṣí àbàwọ́n lára rẹ.

  14. 7  Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè

    ẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìyìnrere ayọ̀ wá,

    tí wọ́n kéde àlàáfíà,

    tí ó mú ìyìnrere wá,

    tí ó kéde ìgbàlà,

    tí ó sọ fún Sioni pé,

    “Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!”

  15. 10 Nítorí àwa ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tí a ti dá nínú Kristi Jesu fún àwọn iṣẹ́ rere, èyí tí Ọlọ́run ti pèsè tẹ́lẹ̀, fún wa láti ṣe.

  16. 1  Ẹ̀mí Olúwa Olódùmarè wà lára mi

    nítorí Olúwa ti fi àmì òróró yàn mí

    láti wàásù ìyìnrere fún àwọn tálákà.

    Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́

    láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn

    àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,

    2 láti kéde ọdún ojúrere Olúwa

    àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa,

    láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,

    3 àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni

    láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú,

    òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,

    àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn.

    A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo,

    irúgbìn Olúwa

    láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.

    4 Wọn yóò tún àwọn ahoro àtijọ́ kọ́

    wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́-tijọ́ náà bọ̀ sípò;

    wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padà

    tí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn.

  17. 17 Ọkàn rẹ gbéraga,

    nítorí ẹwà rẹ.

    Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́,

    nítorí dídára rẹ.

    Nítorí náà mo le ọ sórí ayé;

    mo sọ ọ di awòojú níwájú àwọn ọba.

    18 Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìṣòótọ́ rẹ,

    ìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́.

    Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá,

    láti inú rẹ, yóò sì jó ọ run,

    èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀,

    lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́.

  18. 17 Lea kò ní ẹwà púpọ̀, ṣùgbọ́n Rakeli ní ẹwà gidigidi. Ojú rẹ̀ sì fanimọ́ra.

  19. 2 Láti Sioni wá, pípé ni ẹwà,

    Ọlọ́run tí ń tan ìmọ́lẹ̀

  20. 16 Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, síbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di tuntun lójoojúmọ́.

  21. 27  Nítorí náà, Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀,

    ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a,

    akọ àti abo ni ó dá wọn.

  22. 5 Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;

    ojú kò sì tì wọ́n.

  23. 1  Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,

    ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.

    2 Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀

    ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́.

    3 Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè

    àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.

    4 Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;

    òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ.

    5 Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè

    ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run.

    6 Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀

    agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.

  24. 25 Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọ

    ó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.

    26 A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n

    ìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀

  25. 5 Ní ọjọ́ náà Olúwa àwọn ọmọ-ogun

    yóò jẹ́ adé tí ó lógo,

    àti adé tí ó lẹ́wà

    fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù.

  26. 8 Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,

    ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”

  27. 13 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, nǹkan wọ̀nyí ni mo sì ń sọ ní ayé, kí wọn kí ó lè ní ayọ̀ mi ní kíkún nínú àwọn tìkára wọn.

  28. 9 Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

  29. 4 Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa,

    òhun ni èmi yóò máa wá kiri:

    kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa

    ní ọjọ́ ayé mi gbogbo,

    kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa,

    kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.

  30. 17 Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa;

    fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa,

    bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.

  31. Olùfẹ́

    15 Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olólùfẹ́ mi!

    Háà, báwo ni o ṣe lẹ́wà tó!

    Ìwọ ní ojú ẹyẹlé.

    Olólùfẹ́

    16 Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi!

    Háà, báwo ni o ṣe wu ni!

    Ibùsùn wa ní ìtura.

  32. 17 Ojú rẹ yóò rí ọba nínú ẹwà rẹ̀

    yóò sì rí ilẹ̀ kan tí ó tẹ́ lọ rẹrẹẹrẹ.

  33. 17 Nítorí oore rẹ̀ tí tóbi tó, ẹwà rẹ̀ sì tí pọ̀!

    Ọkà yóò mú ọ̀dọ́mọkùnrin dárayá,

    àti ọtí wáìnì tuntun yóò mú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.

  34. 8 Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́,

    nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run.

  35. 8  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.

  36. 8 Nítorí ṣíṣe eré-ìdárayá ni èrè fún ohun díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run ni èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti ìgbé ayé ìsinsin yìí àti ti èyí tí ń bọ̀.