50 Bible Verses About Comfort

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Comfort
  1. 37  Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwa ju ẹni tí ó ṣẹ́gun lọ nípasẹ̀ Kristi ẹni tí ó fẹ́ wa. 38 Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kì í ṣe ikú tàbí ìyè, kì í ṣe àwọn angẹli tàbí ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe ohun ìgbà ìsinsin yìí tàbí ohun tí ó ń bọ̀, tàbí àwọn agbára, 39 tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun nínú ìṣẹ̀dá ni yóò le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ń bẹ nínú Kristi Jesu, Olúwa wa.

  2. 3  Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo. 4  Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa pẹ̀lú lè máa tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. 5 Nítorí pé bí àwa ti pín nínú ìjìyà Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ̀ pẹ̀lú nípa Kristi. 6 Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín; tàbí bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù láti mú yin ní irú ìfaradà ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́. 7 Àti pé ìrètí wa nípa tiyín dúró ṣinṣin, àwa si mọ̀ pé, bí ẹ̀yin ti jẹ alábápín nínú ìyà wa, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń pín nínú ìtùnú náà pẹ̀lú.

  3. 1 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú, ẹ gba Ọlọ́run gbọ́, kí ẹ sì gbà mí gbọ́ pẹ̀lú. 2  Nínú ilé Baba mi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibùgbé ni ó wà, ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ìbá tí sọ fún yín. Èmi ń lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún yín. 3 Bí mo bá sì lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún un yín, èmi ó tún padà wá, èmi ó sì mú yín lọ sọ́dọ̀ èmi tìkára mi; pé níbi tí èmi gbé wà, kí ẹ̀yin lè wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

  4. 13  Ẹ̀yin ará, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó jẹ́ òpè ní ti àwọn tí ó ti sùn, pé kí ẹ máa banújẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù tí kò ní ìrètí. 14  A gbàgbọ́ pé, Jesu kú, ó sì tún jíǹde, àti pé Ọlọ́run yóò mú gbogbo àwọn tí ó ti sùn nínú rẹ̀ padà wá. 15 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa, pé àwa tí ó wà láààyè, tí a sì kù lẹ́yìn de à ti wá Olúwa, bí ó ti wù kí ó rí, kì yóò ṣáájú àwọn tí ó sùn láti pàdé rẹ̀. 16  Nítorí pé, Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, pẹ̀lú ariwo àṣẹ ńlá àti ohùn àwọn angẹli ti àwọn angẹli ti àwọn ti ìpè Ọlọ́run, àwọn òkú nínú Kristi yóò sì kọ́kọ́ jíǹde. 17 Nígbà náà ni a ó gba àwa tí ó sì wà láààyè sókè nínú àwọsánmọ̀ láti ọwọ́ Olúwa. A ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀ títí láéláé. 18 Nítorí náà, ẹ tu ara yín nínú, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.

  5. 15 “Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́. 16  Nígbà náà èmi yóò wá béèrè lọ́wọ́ Baba. Òun yóò sì fún yín ní olùtùnú mìíràn. Olùtùnú náà yóò máa bá yín gbé títí láé. 17 Òun ni Ẹ̀mí òtítọ́. Ayé kò le gbà á. Nítorí ayé kò mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò rí i rí. Ẹ̀yin mọ̀ ọn nítorí láti ìgbà tí ẹ ti wà pẹ̀lú mí. Òun náà ti wà pẹ̀lú yín. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan yóò wọ inú yín láti máa gbé ibẹ̀. 18 Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìní Olùtùnú, kí ẹ ma dàbí ọmọ tí kò ní òbí. Rárá o! Mo tún ń tọ̀ yín bọ̀.

  6. 24  Nítorí nípa ìrètí ni a fi gbà wá là, ṣùgbọ́n ìrètí tí a bá rí kì í ṣe ìrètí nítorí ta ni ń retí ohun tí ó bá rí? 25 Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń retí èyí tí àwa kò rí, ǹjẹ́ àwa ń fi sùúrù dúró dè é.

    26 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí pẹ̀lú sì ń ran àìlera wa lọ́wọ́: nítorí a kò mọ bí a ti ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń fi ìrora tí a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ̀ fún wa. 27  Ẹni tí ó sì ń wá inú ọkàn wò, ó mọ ohun ti ẹ̀mí, nítorí tí ó ń bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run.

    28 Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀. 29  Nítorí àwọn ẹni tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ni ó sì yàn tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán ọmọ rẹ̀, kí òun lè jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn arákùnrin púpọ̀. 30 Àti pé lẹ́yìn tí òun ti pè wá wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sọ wá di aláìjẹ̀bi lẹ́yìn èyí, ó fi rere Kristi kún inú ọkàn wa. Lékè gbogbo rẹ̀, ó fún wa ní ìdúró rere pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pinu ògo rẹ̀ fún wa.

    31  Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa? 32  Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti fi Ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le ṣòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí?

  7. Ti Dafidi.

    1 Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi;

    ta ni èmi yóò bẹ̀rù?

    Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi,

    ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?

    2 Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi

    láti jẹ ẹran-ara mi,

    àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi,

    wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.

    3 Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,

    ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;

    bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,

    nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.

    4 Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa,

    òhun ni èmi yóò máa wá kiri:

    kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa

    ní ọjọ́ ayé mi gbogbo,

    kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa,

    kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.

    5 Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú

    òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀;

    níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;

    yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.

  8. 12 Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní. 13  Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi.

  9. 48 Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn,

    èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.

    49 Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,

    nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.

    50 Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí:

    ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́.

    51 Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró,

    ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ.

    52 Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, Olúwa,

    èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.

  10. 4 Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀. 5 Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí. 6  Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. 7 Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu.

  11. Saamu ti Dafidi.

    1 Olúwa ni olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.

    2  Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù,

    Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́,

    3 Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò.

    Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo

    nítorí orúkọ rẹ̀.

    4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn

    láàrín àfonífojì òjìji ikú,

    èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan,

    nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;

    ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ,

    wọ́n ń tù mí nínú.

  12. 26 Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, òun ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yóò sì rán yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín. 27  Àlàáfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín pé, àlàáfíà mi ni mo fi fún yin, kì í ṣe bí ayé ti fi fún ni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ó wárìrì.

  13. 28 “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ tí a sì di ẹrù wíwúwo lé lórí, èmi yóò sì fún yín ní ìsinmi. 29 Ẹ gbé àjàgà mi wọ̀. Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi nítorí onínútútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmi, ẹ̀yin yóò sì ri ìsinmi fún ọkàn yín. 30 Nítorí àjàgà mi rọrùn ẹrù mi sì fúyẹ́.”

  14. 10  Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;

    má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.

    Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́.

    Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.

  15. Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. Orin.

    1 Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa

    ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.

    2 Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,

    tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.

    3 Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì

    tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela.

  16. 4 Alábùkún fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀,

    nítorí a ó tù wọ́n nínú.

  17. 6 Nítorí náà, ẹ rẹ ara yin sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kí òun lè gbe yín ga lákokò. 7  Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e; nítorí tí òun ń ṣe ìtọ́jú yín.

  18. 76 Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi,

    gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ.

    77 Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè,

    nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi.

  19. 27 Èéṣe tí o fi sọ, ìwọ Jakọbu?

    Àti tí o ṣàròyé, ìwọ Israẹli,

    “Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú Olúwa;

    ìṣe mi ni a kò kọbi ara sí láti ọwọ́ Ọlọ́run mi”?

    28 Ìwọ kò tí ì mọ̀?

    Ìwọ kò tí ì gbọ́?

    Olúwa òun ni Ọlọ́run ayérayé,

    Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé.

    Agara kì yóò da bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣàárẹ̀,

    àti òye rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdínwọ̀n rẹ̀.

    29 Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀

    ó sì fi kún agbára àwọn tí agara dá.

    30 Àní, ó ń rẹ̀ wọ́n àwọn ọ̀dọ́, wọ́n ń rẹ̀wẹ̀sì,

    àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì ń kọsẹ̀ wọ́n ṣubú;

    31 ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa

    yóò sọ agbára wọn di ọ̀tun.

    Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì;

    wọn yóò sáré àárẹ̀ kò ní mú wọn,

    wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn.

  20. 6  Ṣùgbọ́n ẹni tí ń tu àwọn onírẹ̀lẹ̀ nínú, àní Ọlọ́run, ó tù wá nínú nípa dídé tí Titu dé, 7 kì í sì i ṣe nípa dídé rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n nípa ìtùnú náà pẹ̀lú tí ẹ ti tù ú nínú, nígbà tí ó ròyìn fún wa ìfẹ́ àtọkànwá yín, ìbànújẹ́ yín, àti ìtara yín fún mi; bẹ́ẹ̀ ní mo sì túbọ̀ yọ̀.

  21. 1 Ẹ tù ú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú,

    ni Ọlọ́run yín wí.

    2 Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu

    kí o sì kéde fún un

    pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí,

    pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,

    pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ Olúwa

    ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

    3  Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù:

    “Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,

    ṣe òpópó tí ó tọ́ ní aginjù fún Ọlọ́run wa.

    4  Gbogbo àfonífojì ni a ó gbé sókè,

    gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀;

    wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àti

    ọ̀nà pálapàla ni a óò sọ di títẹ́jú pẹrẹsẹ.

    5 Ògo Olúwa yóò sì di mí mọ̀,

    gbogbo ènìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rí i.

    Nítorí ẹnu Olúwa ni ó ti sọ ọ́.”

  22. 13  Ẹ hó fún ayọ̀, ẹyin ọ̀run;

    yọ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé;

    bú sórin, ẹ̀yin òkè ńlá!

    Nítorí Olúwa tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú

    yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni

    tí a ń pọ́n lójú.

  23. 3 Dájúdájú, Olúwa yóò tu Sioni nínú

    yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀;

    Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni,

    àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà Olúwa.

    Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀,

    ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ.

  24. 12 “Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú.

    Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran ara,

    àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,

  25. 16  Ǹjẹ́ kí Jesu Kristi Olúwa wa tìkálára rẹ̀, àti Ọlọ́run Baba wa, ẹni to ti fẹ́ wa, tí ó sì ti fi ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí rere nípa oore-ọ̀fẹ́ fún wa. 17 Kí ó mú ọkàn yín le, kí ó sì kún yín pẹ̀lú agbára nínú iṣẹ́ gbogbo àti ọ̀rọ̀ rere gbogbo.

  26. 8 Olúwa fúnra rẹ̀ ń lọ níwájú rẹ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ; kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù má sì ṣe fòyà.”

    9 Nígbà náà ni Mose kọ òfin yìí kalẹ̀ ó sì fi fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, tí ń gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa, àti fún gbogbo àwọn àgbàgbà ní Israẹli.

  27. 1 Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé,

    “Èmi ó yìn ọ́, Olúwa.

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi

    ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀

    ìwọ sì ti tù mí nínú.

  28. 4  Nítorí ohun gbogbo tí a kọ tẹ́lẹ̀, ni a kọ láti fi kọ́ wa pé, nípa sùúrù àti ìtùnú ìwé mímọ́, kí àwa lè ní ìrètí.

    5  Kí Ọlọ́run, ẹni tí ń fún ni ní sùúrù àti ìtùnú fún yin láti ní inú kan sí ara yín gẹ́gẹ́ bí i Jesu Kristi,

  29. 33 “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àlàáfíà nínú mi. Nínú ayé, ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú; ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”

  30. 9 Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

    10 Báyìí ni Joṣua pàṣẹ fún olórí àwọn ènìyàn rẹ̀,

  31. 18 Olúwa súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn;

    ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.

  32. 1  Ẹ̀mí Olúwa Olódùmarè wà lára mi

    nítorí Olúwa ti fi àmì òróró yàn mí

    láti wàásù ìyìnrere fún àwọn tálákà.

    Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́

    láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn

    àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,

    2 láti kéde ọdún ojúrere Olúwa

    àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa,

    láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,

    3 àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni

    láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú,

    òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,

    àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn.

    A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo,

    irúgbìn Olúwa

    láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.

  33. 20 Mo ṣèrántí wọn,

    ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.

    21 Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn

    àti nítorí náà ní mo nírètí.

    22 Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé,

    nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.

    23 Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀;

    títóbi ni òdodo rẹ̀.

  34. 23 Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo;

    ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.

    24 Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi

    ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo.

    25 Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ?

    Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ.

    26 Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà

    ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi

    àti ìpín mi títí láé.

  35. 16 “Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. 17  Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n kí a le ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là.

  36. 7 Nítorí pé Ọlọ́run kò fún wa ni ẹ̀mí ìbẹ̀rù, bí kò ṣe ti agbára, àti ti ìfẹ́, àti ti ìsẹ́ra-ẹni ti ó yè kooro.

  37. 10 Ọlọ́run oore-ọ̀fẹ́ gbogbo, tí ó ti pè yín sínú ògo rẹ̀ tí kò nípẹ̀kun nínú Kristi Jesu, nígbà tí ẹ̀yin bá ti jìyà díẹ̀, òun tìkára rẹ̀, yóò sì ṣe yín ní àṣepé, yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóò fún yín lágbára, yóò fi ìdí yín kalẹ̀.

  38. 29 Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Noa, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Olúwa ti fi gégùn ún.”

  39. 11 Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹ́ta gbúròó gbogbo ibi tí ó bá a, wọ́n wá, olúkúlùkù láti ibùjókòó rẹ̀; Elifasi, ara Temani àti Bilidadi, ará Ṣuhi, àti Sofari, ará Naama: nítorí pé wọ́n ti dájọ́ ìpàdé pọ̀ láti bá a ṣọ̀fọ̀, àti láti ṣìpẹ̀ fún un.

  40. 10 Olúwa sì yí ìgbèkùn Jobu padà, nígbà tí ó gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀; Olúwa sì bùsi ohun gbogbo ti Jobu ní rí ní ìṣẹ́po méjì ohun tí ó ní tẹ́lẹ̀ rí. 11 Nígbà náà ní gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ó ti ṣe ojúlùmọ̀ rẹ̀ rí; wọ́n bá a jẹun nínú ilé rẹ̀. Wọ́n sì ṣe ìdárò rẹ̀, wọ́n sì ṣìpẹ̀ fún un nítorí ibi gbogbo tí Olúwa ti mú bá a. Olúkúlùkù ènìyàn pẹ̀lú sì fún un ní ẹyọ owó kọ̀ọ̀kan àti olúkúlùkù ni òrùka wúrà etí kọ̀ọ̀kan.

  41. 11 Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn:

    Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀.

    Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan àyà rẹ̀;

    ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ darí àwọn tí ó ní.

    12 Ta ni ó tiwọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀,

    tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀

    tí ó wọn àwọn ọ̀run?

    Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀,

    tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀n

    àti òkè kéékèèké nínú òsùwọ̀n?

    13  Ta ni ó ti mọ ọkàn Olúwa,

    tàbí tí ó ti tọ́ ọ ṣọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀?

  42. 1 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìí,

    ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu,

    ẹni tí ó mọ ọ́, ìwọ Israẹli:

    “Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;

    Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe.

    2 Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,

    Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ;

    àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá

    wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.

    Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,

    kò ní jó ọ;

    ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.

    3 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,

    Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ;

    Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ,

    Kuṣi àti Seba dípò rẹ.

  43. 16 “Ìdí nìyí tí mo fi ń sọkún

    tí omijé sì ń dà lójú mi.

    Olùtùnú àti ẹni tí ó le mú ọkàn mi sọjí jìnnà sí mi,

    kò sí ẹni tí yóò dá ẹ̀mí mi padà.

    Àwọn ọmọ mi di aláìní

    nítorí ọ̀tá ti borí.”

    17 Sioni na ọwọ́ jáde,

    ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún un.

    Olúwa ti pàṣẹ fún Jakọbu

    pé àwọn ará ilé rẹ̀ di ọ̀tá fún un

    Jerusalẹmu ti di

    ohun aláìmọ́ láàrín wọn.

    18 “Olóòtítọ́ ni Olúwa,

    ṣùgbọ́n mo ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀.

    Ẹ gbọ́, gbogbo ènìyàn;

    ẹ wò mí wò ìyà mi.

    Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi

    ni a ti kó lọ sí ìgbèkùn.

    19 “Mo pe àwọn ọ̀rẹ́ mi

    ṣùgbọ́n wọ́n dà mí.

    Àwọn olórí àlùfáà àti àgbàgbà mi

    ṣègbé sínú ìlú

    nígbà tí wọ́n ń wá oúnjẹ

    tí yóò mú wọn wà láààyè.

    20 “Olúwa, wò ó, bí mo ti wà nínú ìnira!

    Tí mo sì ń jẹ̀rora nínú mi,

    ìdààmú dé bá ọkàn mi

    nítorí pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi gidigidi.

    Ní gbangba ni idà ń parun;

    ikú wà nínú ilé pẹ̀lú.

    21 “Àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìrora mi,

    ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún mi.

    Àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ ìparun mi;

    wọ́n yọ̀ sí ohun tí o ṣe.

    Kí o mú ọjọ́ tí o ti kéde,

    kí wọ́n le dàbí tèmi.

  44. 19  Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Marta àti Maria láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn.

  45. 7  Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni èmi ń sọ fún yín; àǹfààní ni yóò jẹ́ fún yín bí èmi bá lọ, nítorí bí èmi kò bá lọ, Olùtùnú kì yóò tọ̀ yín wá; ṣùgbọ́n bí mo bá lọ, èmi ó rán an sí yín.

  46. 31 Nígbà náà ni ìjọ wà ni àlàáfíà yíká gbogbo Judea àti ni Galili àti ni Samaria, wọn ń fẹsẹ̀múlẹ̀, wọn ń rìn ní ìbẹ̀rù Olúwa, àti ni ìtùnú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn ń pọ̀ sí i.

  47. 13 Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yin ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrètí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.

  48. 3  Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Olúwa wa tí í ṣe Jesu Kristi.

    4  Nígbà gbogbo ni mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó fi fún un yín nínú Kristi Jesu. 5 Nítorí nínú rẹ̀ ni a ti sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ yín gbogbo àti nínú ìmọ̀ yín gbogbo. 6 Nítorí ẹ̀rí wa nínú Kristi ni a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú yín. 7 Nítorí náà ẹ̀yin kò ṣe aláìní nínú èyíkéyìí ẹ̀bùn ẹ̀mí, bí ẹ̀yin ṣe ń retí ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi.

  49. 13  Kò sí ìdánwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọ́run, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin ba à lè faradà á.

  50. 9 Òun sì wí fún mi pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ, nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fi ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kristi lè máa gbé inú mi.