69 Bible Verses About Hope

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Hope
  1. 1  Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nípa ìgbàgbọ́, àwa ní àlàáfíà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. 2  Nípasẹ̀ ẹni tí àwa sì ti rí ọ̀nà gbà nípa ìgbàgbọ́ sí inú oore-ọ̀fẹ́ yìí nínú èyí tí àwa gbé dúró. Àwa sì ń yọ̀ nínú ìrètí ògo Ọlọ́run. 3  Kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa tún ń ṣògo nínú ìjìyà pẹ̀lú, bí a ti mọ̀ pé ìjìyà ń ṣiṣẹ́ sùúrù; 4 àti pé sùúrù ń ṣiṣẹ́ ìwà rere; àti pé ìwà rere ń ṣiṣẹ́ ìrètí. 5  Ìrètí kì í sì í dójúti ni nítorí a ti dá ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún wa.

  2. 18  Síbẹ̀síbẹ̀, ìyà tí a ń jẹ nísinsin yìí kò jámọ́ nǹkan nígbà tí a bá fiwé ògo tí yóò fún wa ní ìkẹyìn. 19  Nítorí ẹ̀dá ń dúró ní ìfojúsọ́nà de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run. 20  Nítorí a tẹrí ẹ̀dá ba fún asán, kì í ṣe bí òun ti fẹ́, ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ẹni tí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní ìrètí. 21  Nítorí a ó sọ ẹ̀dá tìkára rẹ̀ di òmìnira kúrò nínú ẹrú ìdíbàjẹ́, sí òmìnira ògo àwọn ọmọ Ọlọ́run.

    22  Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ẹ̀dá ni ó jùmọ̀ ń kérora tí ó sì ń rọbí pọ̀ títí di ìsinsin yìí. 23  Kì í ṣe àwọn nìkan, ṣùgbọ́n àwa tìkára wa pẹ̀lú, a ni àkóso ẹ̀mí, àní àwa tìkára wa ń kérora nínú ara wa, àwa ń dúró de ìsọdọmọ àní ìdáǹdè ara wa. 24  Nítorí nípa ìrètí ni a fi gbà wá là, ṣùgbọ́n ìrètí tí a bá rí kì í ṣe ìrètí nítorí ta ni ń retí ohun tí ó bá rí? 25 Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń retí èyí tí àwa kò rí, ǹjẹ́ àwa ń fi sùúrù dúró dè é.

  3. 12  Isaiah sì tún wí pé,

    “Gbòǹgbò Jese kan ń bọ̀ wá,

    òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn Kèfèrí;

    Àwọn Kèfèrí yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.”

    13 Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yin ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrètí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.

  4. 5 Báyìí ni Olúwa wí:

    “Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn,

    tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara,

    àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ Olúwa.

    6 Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá,

    kò ní rí ìre, nígbà tí ó bá dé,

    yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ aginjù,

    ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé.

    7  “Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin

    náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fi

    Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.

    8 Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò

    tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò

    kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru,

    gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù

    kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá

    bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”

  5. 18  Nígbà tí ìrètí kò sí mọ́, Abrahamu gbàgbọ́ nínú ìrètí bẹ́ẹ̀ ni ó sì di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí fún un pé, “Báyìí ni irú-ọmọ rẹ̀ yóò rí.” 19  Ẹni tí kò rẹ̀wẹ̀sì nínú ìgbàgbọ́, nígbà tí ó mọ pe ara òun tìkára rẹ̀ tí ó ti kú tan, nítorí ó tó bí ẹni ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún ọdún, àti nígbà tí ó ro ti yíyàgàn inú Sara. 20 Kò fi àìgbàgbọ́ ṣiyèméjì nípa ìlérí Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ó lágbára sí i nínú ìgbàgbọ́ bí ó ti fi ògo fún Ọlọ́run, 21 pẹ̀lú ìdánilójú kíkún pé, Ọlọ́run lè ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí rẹ̀. 22  Nítorí náà ni a sì ṣe kà á sí òdodo fún un.

  6. 3 Ìyìn yẹ Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa! Ẹni tí ó tún wa bí gẹ́gẹ́ bí àánú ńlá rẹ̀ sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jesu Kristi kúrò nínú òkú, 4 àti sínú ogún àìdíbàjẹ́, àti àìlábàwọ́n, àti èyí tí kì í ṣá, tí a ti fi pamọ́ ni ọ̀run dè yin, 5 ẹyin tí a ń pamọ́ nípa agbára Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ si ìgbàlà, tí a múra láti fihàn ní ìgbà ìkẹyìn.

  7. 18 Wò ó, ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

    àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin.

    19 Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú

    àti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn.

    20 Ọkàn wa dúró de Olúwa;

    òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti asà wa.

    21 Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀,

    nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́.

    22 Kí àánú rẹ, Olúwa, kí ó wà lára wa,

    àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú rẹ.

  8. 11 Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tó mú ìgbàlà wà ti fi ara hàn fún gbogbo ènìyàn. 12 Ó ń kọ́ wa láti sẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé, kí a sì máa wà ní àìrékọjá, ní òdodo àti ní ìwà-bí-Ọlọ́run ní ayé ìsinsin yìí, 13 bí a ti ń wọ́nà fún ìrètí tó ní bùkún, èyí ń ní ìfarahàn ògo Ọlọ́run wa tí ó tóbi àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi. 14  Ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa láti rà fún ìràpadà kúrò nínú ìwà búburú gbogbo àti kí ó sì le wẹ̀ àwọn ènìyàn kan mọ́ fún ara rẹ̀ fún ìní ohun tìkára rẹ̀, àwọn tó ń ní ìtara fún iṣẹ́ rere.

  9. 15 Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kristi bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń béèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù.

  10. 2 Olùfẹ́, ọmọ Ọlọ́run ni àwa ń ṣe nísinsin yìí, a kò ì tí i fihàn bí àwa ó ti rí: àwa mọ̀ pé, nígbà tí òun ba farahàn, àwa yóò dàbí rẹ̀; nítorí àwa yóò rí i, àní bí òun tí rí. 3 Olúkúlùkù ẹni tí ó ba sì ní ìrètí yìí nínú rẹ̀, ń wẹ ara rẹ̀ mọ́, àní bí òun ti mọ́.

  11. 17 Nínú èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí ń fẹ́ gidigidi láti fi àìlèyípadà ète rẹ̀ hàn fún àwọn ajogún ìlérí náà, ó fi ìbúra sáàrín wọn. 18 Pé, nípa ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò le ṣe é ṣe fún Ọlọ́run láti ṣèké, kí a lè mú àwa tí ó ti sá sábẹ́ ààbò rẹ̀ ní ọkàn lè láti di ìrètí tí a gbé kalẹ̀ níwájú wa mú ṣinṣin. 19  Èyí tí àwa níbi ìdákọ̀ró ọkàn fún ọkàn wa, ìrètí tí ó dájú tí ó sì dúró ṣinṣin, tí ó sì wọ inú ilé lọ lẹ́yìn aṣọ ìkélé; 20  níbi tí Jesu, aṣáájú wa ti wọ̀ lọ fún wa, òun sì ni a fi jẹ alábojútó àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melkisedeki.

  12. 16  Èmi kò sì sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, àti láti máa rántí yín nínú àdúrà mi. 17 Mo sì ń béèrè nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọgbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ ọ́n sí i. 18  Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkàn yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìrètí ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́, 19 àti aláìlẹ́gbẹ́ títóbi agbára rẹ̀ fún àwa tí a gbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀, 20  èyí tí ó fi sínú Kristi, nígbà tí o ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún nínú àwọn ọ̀run. 21  Ó gbéga ju gbogbo ìjọba, àti àṣẹ, àti agbára, àti òye àti gbogbo orúkọ tí a ń dá, kì í ṣe ni ayé yìí nìkan, ṣùgbọ́n ni èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú.

  13. 8  Ṣùgbọ́n àwa jẹ́ ti ìmọ́lẹ̀, ẹ jẹ́ kí a pa ara wa mọ́, ní gbígbé ìgbàgbọ́ wọ̀ àti ìfẹ́ bí ìgbàyà ni òru àti ìrètí ìgbàlà bí àṣíborí.

  14. 13  Ẹ̀yin ará, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó jẹ́ òpè ní ti àwọn tí ó ti sùn, pé kí ẹ máa banújẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù tí kò ní ìrètí. 14  A gbàgbọ́ pé, Jesu kú, ó sì tún jíǹde, àti pé Ọlọ́run yóò mú gbogbo àwọn tí ó ti sùn nínú rẹ̀ padà wá.

  15. 23 Ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mu ṣinṣin ni àìṣiyèméjì, nítorí pé olóòtítọ́ ní ẹni tí o ṣe ìlérí.

  16. 5 Nítorí nípa Ẹ̀mí àwa ń fi ìgbàgbọ́ dúró de ìrètí òdodo. 6  Nítorí nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà; ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ti ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.

  17. 13 Ǹjẹ́ nísinsin yìí àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí dúró: ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́. Ṣùgbọ́n èyí tí o tóbi jù nínú wọn ni ìfẹ́.

  18. 4  Nítorí ohun gbogbo tí a kọ tẹ́lẹ̀, ni a kọ láti fi kọ́ wa pé, nípa sùúrù àti ìtùnú ìwé mímọ́, kí àwa lè ní ìrètí.

  19. 28 Ìrètí olódodo ni ayọ̀,

    ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú jásí òfo.

  20. 11 Nítorí mo mọ èrò tí mo rò sí yín,” ni Olúwa wí, “àní èrò àlàáfíà, kì í sì ṣe fún ibi, èrò láti fún un yín ní ìgbà ìkẹyìn àti ìrètí ọjọ́ iwájú. 12 Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò ké pè mí, tí ẹ̀yin yóò sì gbàdúrà sí mi, tí èmi yóò sì gbọ́ àdúrà yín.

  21. 10 Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ. 11 Nítorí pé bí èyí ti ń kọjá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo!

    12 Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fi ìgboyà púpọ̀ sọ̀rọ̀. 13 Kì í sì í ṣe bí Mose, ẹni tí ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Israẹli má ba à lè tẹjúmọ́ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ. 14 Ṣùgbọ́n ojú inú wọn fọ́; nítorí pé títí fi di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mú láéláé, ìbòjú kan náà ṣì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kristi ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò.

  22. 4 Ara kan ni ń bẹ, àti Ẹ̀mí kan, àní bí a ti pè yín sínú ìrètí kan nígbà tí a pè yín.

  23. 1 Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ ní ìdánilójú ohun tí o ń retí, ìjẹ́rìí ohun tí a kò rí. 2 Nítorí nínú rẹ ni àwọn alàgbà àtijọ́ ní ẹ̀rí rere.

  24. 11 Nítorí náà ẹ rántí pé, nígbà àtijọ́ rí, ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ Kèfèrí nípa ti ìbí, tí àwọn tí a ń pè ní “aláìkọlà” láti ọwọ́ àwọn tí ń pe ara wọn “akọlà” (èyí ti a fi ọwọ́ ènìyàn ṣe sí ni ní ara). 12  Ẹ rántí pé ni àkókò náà ẹ̀yin wà láìní Kristi, ẹ jẹ́ àjèjì sí Israẹli, àti àjèjì sí àwọn májẹ̀mú ìlérí náà, láìní ìrètí, àti láìní Ọlọ́run ni ayé. 13 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nínú Kristi Jesu ẹ̀yin tí ó ti jìnà réré nígbà àtijọ́ rí ni a mú súnmọ́ tòsí, nípa ẹ̀jẹ̀ Kristi.

    14 Nítorí òun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórìíra èyí tí ń bẹ láàrín yín. 15 Ó sì ti fi òpin sí ọ̀tá náà nínú ara rẹ̀, àní sí òfin àti àṣẹ wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ nínú ìlànà, kí ó lè sọ àwọn méjèèjì di ẹni tuntun kan nínú ara rẹ̀, kí ó sì ṣe ìlàjà 16 àti kí ó lè mú àwọn méjèèjì bá Ọlọ́run làjà nínú ara kan nípa àgbélébùú; nípa èyí tí yóò fi pa ìṣọ̀tá náà run.

  25. 9 Ṣùgbọ́n olùfẹ́, àwa ní ohun tí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní tiyín, àti ohun tí ó fi ara mọ́ ìgbàlà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń ṣe báyìí sọ̀rọ̀. 10 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yin àti ìfẹ́ tí ẹ̀yin fihàn sí orúkọ rẹ̀, nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ẹ ti ṣe fún àwọn ènìyàn mímọ́, tí ẹ sì tún ń ṣe. 11 Àwa sì fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi irú àìsimi kan náà hàn, fún ẹ̀kún ìdánilójú ìrètí títí dé òpin. 12 Kí ẹ má ṣe di onílọ̀ra, ṣùgbọ́n aláfarawé àwọn tí wọn ti ipa ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí.

  26. 7 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:

    nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,

    àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.

    8 Òun ó sì dá Israẹli ní ìdè

    kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.

  27. 24 Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le

    gbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de Olúwa.

  28. 3 Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé,

    àní, ọmọ ènìyàn,

    lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.

    4 Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀,

    ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo.

  29. 6 Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu ṣàkíyèsí pé, apá kan wọn jẹ́ Sadusi, apá kan sì jẹ́ Farisi, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi jẹ́ Farisi, ọmọ Farisi sì ni èmi. Mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú.”

  30. 19 Bí ó bá ṣe pé kìkì ayé yìí nìkan ní àwa ní ìrètí nínú Kristi, àwa jásí òtòṣì jùlọ nínú gbogbo ènìyàn.

  31. 11 Papirusi ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀

    tàbí eèsún ha lè dàgbà láìlómi?

    12 Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò ké e lulẹ̀,

    ó rọ dànù, ewéko gbogbo mìíràn hù dípò rẹ̀.

    13 Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run,

    bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn àgàbàgebè yóò di òfo.

    14 Àbá ẹni tí a ó kèé kúrò,

    àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dàbí ilé aláǹtakùn.

    15 Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró,

    yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́.

  32. 10 Nítorí fún èyí ni àwa ń ṣe làálàá tí a sì ń jìjàkadì, nítorí àwa ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè, ẹni tí í ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyàn, pẹ̀lúpẹ̀lú ti àwọn ti ó gbàgbọ́.

  33. 18 Nítorí a mú òfin ìṣáájú kúrò nítorí àìlera àti àìlérè rẹ̀. 19 (Nítorí òfin kò mú ohunkóhun pé), a sì mú ìrètí tí ó dára jù wá nípa èyí tí àwa ń súnmọ́ Ọlọ́run.

    20 Níwọ́n bí ó sì ti ṣe pé kì í ṣe ní àìbúra ni. Nítorí àwọn àlùfáà tẹ́lẹ̀ jẹ oyè láìsí ìbúra, 21 ṣùgbọ́n ti òun jẹ́ pẹ̀lú ìbúra nígbà tí Ọlọ́run wí fún un pé,

    “Olúwa búra,

    kí yóò sì yí padà:

    ‘Ìwọ ni àlùfáà kan títí láé.’ ”

    22 Níwọ́n bẹ́ẹ̀ ni Jesu ti di onígbọ̀wọ́ májẹ̀mú tí ó dára jù.

  34. 13 Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀, ẹ kó ara yín ní ìjánu, kí ẹ sì fi ìrètí yín ní kíkún sí oore-ọ̀fẹ́, èyí tí a ń mu bọ̀ fún yin ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. 14 Bí àwọn ọmọ tí ń gbọ́rọ̀, ẹ ma ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ́.

  35. 7 “Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí,

    Olúwa,

    kín ni mo ń dúró dè?

    Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ.

  36. 14 Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi;

    èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i.

  37. 17 Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìsinsin yìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti lò; 18 kí wọn máa ṣoore, kí wọn máa pọ̀ ní iṣẹ́ rere, kí wọn múra láti pín fún ni, kí wọn ni ẹ̀mí ìbá kẹ́dùn; 19 kí wọn máa to ìṣúra ìpìlẹ̀ rere jọ fún ara wọn dé ìgbà tí ń bọ̀, kí wọn lè di ìyè tòótọ́ mú.

  38. 11 Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

    sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.

  39. 12 Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀

    ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.

  40. 5 Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè,

    ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.

  41. 17 Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ ó ṣe ìlara sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,

    ṣùgbọ́n kí ìwọ ó wà ní ìbẹ̀rù Olúwa,

    ní ọjọ́ gbogbo.

    18 Nítorí pé ìgbẹ̀yìn ń bẹ nítòótọ́;

    ìrètí rẹ̀ kì yóò sì gé kúrò.

  42. 20 Ẹni tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nítòótọ́ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn ní ìgbà ìkẹyìn wọ̀nyí nítorí yín. 21 Àní ẹ̀yin tí o tipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni ti ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì fi ògo fún un; kí ìgbàgbọ́ àti ìrètí yín lè wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

  43. 18 Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé,

    ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé.

  44. 9 Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;

    ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,

    10  nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú,

    tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.

  45. 2 Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ;

    má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí

    má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.

    3 Ẹni tí ó dúró tì ọ́

    ojú kì yóò tì í,

    àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí

    ni kí ojú kí ó tì.

  46. 11 Èéṣe tí ìwọ fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?

    Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?

    Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,

    nítorí èmi yóò sì máa yìn ín, Òun ni

    Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

  47. 5 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi.

    Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.

  48. 5 Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,

    àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí.

  49. 4 Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrín alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá sàn dáradára ju òkú kìnnìún lọ!

    5 Nítorí pé ẹni tí ó wà láààyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kú

    ṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kan

    wọn kò ní èrè kankan mọ́,

    àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé.

    6 Ìfẹ́ wọn, ìríra wọn,

    àti ìlara wọn ti parẹ́:

    láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpín

    nínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn.

  50. 16 Olúwa yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá,

    yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá;

    àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì.

    Ṣùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀,

    àti agbára àwọn ọmọ Israẹli.

  51. 26 Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀,

    pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí.

    27 Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà òkú,

    bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.

  52. 13 Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kristi nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìyìnrere ìgbàlà yin. Nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe èdìdì ayé yin nínú rẹ, èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀, 14  èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àṣansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ti Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀.

  53. 18 Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà;

    àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.

    19 Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́,

    àní ènìyàn yóò máa wá ojúrere rẹ.

  54. 8 Nítorí kí ni ìrètí àgàbàgebè,

    nígbà tí Ọlọ́run bá ké ẹ̀mí rẹ̀ kúrò, nígbà tí ó sì fà á jáde?

  55. 24 “Bí ó bá ṣe pé mo fi wúrà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé mi,

    tàbí tí mo bá wí fún fàdákà dídára pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi,’

    25 bí mo bá yọ̀ nítorí ọrọ̀ mí pọ̀,

    àti nítorí ọwọ́ mi dara lọ́pọ̀lọ́pọ̀,

    26 bí mo bá bojú wo oòrùn nígbà tí ń ràn,

    tàbí òṣùpá tí ń ràn nínú ìtànmọ́lẹ̀,

    27 bí a bá tàn ọkàn mi jẹ

    láti fi ẹnu mi kò ọwọ́ mi,

    28 èyí pẹ̀lú ni ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn onídàájọ́ ní láti bẹ̀wò,

    nítorí pé èmí yóò jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run tí ó wà lókè.

  56. 19 Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi,

    tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.

    20 Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀;

    má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú,

    nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.

    21 Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́;

    nítorí pé mo dúró tì ọ́.

  57. 16 Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, síbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di tuntun lójoojúmọ́. 17 Nítorí ìpọ́njú díẹ̀ yìí ń pèsè ògo tí ó ní ìwọ̀n ayérayé tí ó pọ̀ rékọjá sílẹ̀ fún wa. 18 Níwọ́n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí; nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé.

  58. 18 Kí ló tún kù? Kìkì í pé níbi gbogbo, ìbá à ní ìfẹ̀tànṣe tàbí ni ti òtítọ́ a sá à n wàásù Kristi, èmi sì ń yọ̀ nítorí èyí.

    Nítòótọ́, èmi ó sì máa yọ̀, 19  nítorí tí mo mọ̀ pé èyí ni yóò yọrí sí ìgbàlà fún mi láti inú àdúrà yín wá, àti ìfikún ẹ̀mí Jesu Kristi. 20  Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn àti ìrètí mi pé kí ojú kí ó má ṣe ti mi ní ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí èmi kí ó le máa ni ìgboyà ní ìgbà gbogbo àti nísinsin yìí, kí a lè ti ipasẹ̀ mi gbé Kristi ga lára mi, ìbá à ṣe pé mo wà láààyè, tàbí mo kú.

  59. 15 Ṣùgbọ́n ó gba tálákà là ní ọwọ́ idà,

    lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára.

    16 Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún tálákà,

    àìṣòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

  60. 13 Bí mo tilẹ̀ ní ìrètí, ipò òku ní ilé mi;

    mo ti tẹ́ ibùsùn mi sínú òkùnkùn.

    14 Èmi ti wí fún ìdíbàjẹ́ pé, ìwọ ni baba mi,

    àti fún kòkòrò pé, ìwọ ni ìyá mi àti arábìnrin mi,

    15 ìrètí mi ha dà nísinsin yìí?

    Bí ó ṣe ti ìrètí mi ni, ta ni yóò rí i?

  61. 5 Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?

    Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?

    Ìwọ ṣe ìrètí ní ti Ọlọ́run,

    nítorí èmi yóò sá à máa yìn ín,

    Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

  62. 11 Nítorí Olúwa Ọlọ́run jẹ́ òòrùn àti asà;

    Olúwa fún ni ní ojúrere àti ọlá;

    kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn

    fún àwọn tí ó rìn ní àìlábùkù.

  63. 4 òun kì yóò kọsẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sì

    títí tí yóò fi fi ìdájọ́ múlẹ̀ ní ayé.

    Nínú òfin rẹ̀ ni àwọn erékùṣù yóò fi ìrètí wọn sí.”

  64. 13 Olúwa ìwọ ni ìrètí Israẹli;

    gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì.

    Àwọn tí ó padà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ

    ni a ó kọ orúkọ wọn sínú ekuru,

    nítorí wọ́n ti kọ Olúwa,

    orísun omi ìyè sílẹ̀.

  65. 18 Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ

    àti ìrètí mi nínú Olúwa.”

  66. 21 Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn

    àti nítorí náà ní mo nírètí.

    22 Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé,

    nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.

    23 Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀;

    títóbi ni òdodo rẹ̀.

  67. 7 Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi ní ìwòye ní ìrètí sí Olúwa,

    èmi dúró de Ọlọ́run olùgbàlà mi;

    Ọlọ́run mi yóò sì tẹ́tí sí mi.

  68. 21 Ní orúkọ rẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò fi ìrètí wọn sí.”

  69. 1  Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ayé tuntun kan, nítorí pé ọ̀run ti ìṣáájú àti ayé ìṣáájú ti kọjá lọ; Òkun kò sì ṣí mọ́. 2  Mo sì rí ìlú mímọ́, Jerusalẹmu tuntun ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí a ti múra sílẹ̀ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀. 3  Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti orí ìtẹ́ náà wá, ń wí pé, “Kíyèsi i, àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn, òun ó sì máa bá wọn gbé, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀, àti Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wọn, yóò sì máa jẹ́ Ọlọ́run wọn. 4  Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn; kì yóò sì ṣí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kí yóò sí ìrora mọ́, nítorí pé ohun àtijọ́ tí kọjá lọ.”

    5  Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, sì wí pé, “Kíyèsi i, mo sọ ohun gbogbo di ọ̀tun!” Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí òdodo àti òtítọ́ ni wọ́n.”