90 Bible Verses About Wisdom

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Wisdom
  1. 18 Nítorí pé òmùgọ̀ ni ọ̀rọ̀ àgbélébùú jẹ́ sí àwọn tí ń ṣègbé, ṣùgbọ́n fún àwa tí a ń gbàlà ó jẹ́ agbára Ọlọ́run. 19  Nítorí a tí kọ ọ́ pé:

    “Èmi yóò pa ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n run,

    òye àwọn olóye ni Èmi yóò sọ di asán.”

    20 Àwọn ọlọ́gbọ́n náà ha dá? Àwọn akọ̀wé náà ha dà? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ayé yìí ha dà? Ọlọ́run kò ha ti sọ ọgbọ́n ayé yìí di aṣiwèrè? 21 Nítorí pé, nínú ọgbọ́n Ọlọ́run, ayé kò le mọ̀ òun nípa ọgbọ́n àti ìṣeféfé wọn. Ó sì gba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ là nípa ìwàásù tí àwọn aráyé pè ní òmùgọ̀ àti ọ̀rọ̀ ọ yẹ̀yẹ́. 22  Nítorí pé àwọn Júù ń béèrè àmì, àwọn Helleni sí ń ṣàfẹ́rí ọgbọ́n, 23  ṣùgbọ́n àwa ń wàásù Kristi ti a kàn mọ́ àgbélébùú, òkúta ìkọ̀sẹ̀ àwọn Júù àti òmùgọ̀ fún àwọn kèfèrí. 24 Ṣùgbọ́n sí àwọn tí Ọlọ́run tí pè, àti àwọn Júù àti àwọn Giriki, Kristi ni agbára Ọlọ́run, àti ọgbọ́n Ọlọ́run. 25 Nítorí pé òmùgọ̀ Ọlọ́run jù ọgbọ́n ènìyàn lọ; àti aláìlera Ọlọ́run ni agbára jù ìlera ènìyàn lọ.

    26 Ará, ẹ kíyèsi ohun tí ẹ jẹ́ nígbà tí a pè yín. Kì í ṣe ọ̀pọ̀ yín jẹ ọlọ́gbọ́n nípa àgbékalẹ̀ ti ènìyàn, tàbí ọ̀pọ̀ nínú yín jẹ́ ènìyàn pàtàkì, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọ̀pọ̀ nínú yín jẹ́ ọlọ́lá nípa ibi tí a gbé bí i. 27  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tí yàn àwọn òmùgọ̀ ayé láti fi dààmú àwọn ọlọ́gbọ́n; Ọlọ́run sì ti yàn àwọn ohun aláìlera ayé láti fi dààmú àwọn ohun tí ó ni agbára.

  2. 2 Ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírúurú ìdánwò, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀; 3 nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìdánwò ìgbàgbọ́ yín ń ṣiṣẹ́ sùúrù. 4 Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù kí ó ṣiṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti aláìlábùkù tí kò ṣe aláìní ohunkóhun. 5 Bí ó bá ku ọgbọ́n fún ẹnikẹ́ni, kí ó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ẹni tí fi fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí kì í sì ka àlébù sí; a ó sì fi fún un. 6 Ṣùgbọ́n nígbà tí òun bá béèrè ní ìgbàgbọ́, ní àìṣiyèméjì rárá. Nítorí ẹni tí ó ń sé iyèméjì dàbí ìgbì omi Òkun, tí à ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ bì síwá bì sẹ́yìn, tí a sì ń rú u sókè. 7 Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ má ṣe rò pé, òun yóò rí ohunkóhun gbà lọ́wọ́ Olúwa; 8 Ó jẹ ènìyàn oníyèméjì aláìlèdúró ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo.

  3. 13 Ta ni ó gbọ́n tí ó sì ní ìmọ̀ nínú yín? Ẹ jẹ́ kí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nípa ìwà rere, nípa ìwà tútù ti ọgbọ́n. 14 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ní owú kíkorò àti ìjà ní ọkàn yín, ẹ má ṣe ṣe féfé, ẹ má sì ṣèké sí òtítọ́. 15 Ọgbọ́n yìí kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ṣùgbọ́n ti ayé ni, ti ara ni, ti ẹ̀mí èṣù ni. 16 Nítorí níbi tí owú òun ìjà bá gbé wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti iṣẹ́ búburú gbogbo wà.

    17 Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ mímọ́ ní àkọ́kọ́, ti àlàáfíà, àti ti ìrẹ̀lẹ̀, kì í sì í ṣòro láti bẹ̀, ó kún fún àánú àti fún èso rere, kì í ṣe ojúsàájú, a sì máa sọ òtítọ́. 18 Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ àlàáfíà a sì máa gbin èso àlàáfíà ní àlàáfíà.

  4. 1 Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi,

    tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ,

    2 tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n

    tí ìwọ sì fi ọkàn rẹ sí òye,

    3 àní, bí ìwọ bá ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn,

    tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye

    4 bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bí i fàdákà

    tí ìwọ sì wa kiri bí ìṣúra tí a fi pamọ́.

    5 Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù Olúwa,

    ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.

    6 Nítorí Olúwa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n,

    láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá.

    7 Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo,

    Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé,

    8 Ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́

    Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.

    9 Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ òdodo àti ìdájọ́,

    àti àìṣègbè—gbogbo ipa ọ̀nà rere.

    10 Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹ

    ìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ.

  5. 7 “Nísinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run mi, o ti mú ìránṣẹ́ rẹ jẹ ọba ní ipò Dafidi baba mi. Ṣùgbọ́n ọmọ kékeré ni mí, èmi kò sì mọ jíjáde àti wíwọlé mi. 8 Ìránṣẹ́ rẹ nìyí láàrín àwọn ènìyàn tí o ti yàn, àwọn ènìyàn ńlá, wọ́n pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò sì lè kà wọ́n tàbí mọye wọn. 9 Nítorí náà fi ọkàn ìmòye fún ìránṣẹ́ rẹ láti le ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ àti láti mọ ìyàtọ̀ láàrín rere àti búburú. Nítorí ta ni ó lè ṣe àkóso àwọn ènìyàn ńlá rẹ yìí?”

    10 Inú Olúwa sì dùn pé Solomoni béèrè nǹkan yìí. 11 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ ti béèrè fún èyí, tí kì í ṣe ẹ̀mí gígùn tàbí ọrọ̀ fún ara rẹ, tàbí béèrè fún ikú àwọn ọ̀tá rẹ, ṣùgbọ́n fún òye láti mọ ẹjọ́ dá, 12 èmi yóò ṣe ohun tí ìwọ ti béèrè. Èmi yóò fún ọ ní ọgbọ́n àti ọkàn ìmòye, tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ẹnìkan tí ó dàbí rẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò dìde tí yóò dàbí rẹ lẹ́yìn rẹ. 13 Síwájú sí i, èmi yóò fi ohun tí ìwọ kò béèrè fún ọ: ọrọ̀ àti ọlá ní gbogbo ayé rẹ, tí kì yóò sí ẹnìkan nínú àwọn ọba tí yóò dàbí rẹ. 14 Àti bí ìwọ bá rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin àti àṣẹ mi mọ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.”

  6. 2 Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́,

    láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀.

    3 Láti gba ẹ̀kọ́ ọgbọ́n, òdodo,

    àti ìdájọ́, àti àìṣègbè;

    4 láti fi òye fún onírẹ̀lẹ̀,

    ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe.

    5 Jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀,

    sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà.

    6 Láti mọ ìtumọ̀ òwe àti ìtán-dòwe,

    àwọn ọ̀rọ̀ àti àlọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n.

    7 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀,

    ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́.

  7. 1  Nígbà tí èmí tọ̀ yín wá, ẹ̀yin ará, kì í ṣe nípa ọ̀rọ̀ gíga àti ọgbọ́n gíga ni mo fi bá yín sọ̀rọ̀, nígbà tí èmi ń sọ̀rọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run fún un yín. 2  Èmi ti pinnu láti má mọ ohunkóhun nígbà ti mo wà láàrín yín bí kò ṣe Jesu Kristi, ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú. 3  Èmi sì tọ̀ yín wá ni àìlera, àti ní ẹ̀rù, àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwárìrì. 4  Ìwàásù mi àti ẹ̀kọ́ mi, kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn àti ọ̀rọ̀ tí a fi ń yí ènìyàn lọ́kàn padà, bí kò ṣe nípa ìfihàn agbára Ẹ̀mí. 5  Kí ìgbàgbọ́ yín kí ó má ṣe dúró lórí ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ó dúró lórí agbára Ọlọ́run.

    6  Ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàrín àwọn tí a pè, ṣùgbọ́n kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí tàbí ti àwọn olórí ayé yìí, èyí tí yóò di asán. 7  Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó fi ara sin, ọgbọ́n tí ó ti fi ara pamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa. 8  Èyí ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí kò mọ̀. Ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọn kì bá tún kan Olúwa ògo mọ́ àgbélébùú. 9  Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

    “Ojú kò tí ì rí,

    etí kò tí í gbọ́,

    kò sì ọkàn ènìyàn tí ó tí í mọ̀

    ohun tí Ọlọ́run tí pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí o fẹ́ ẹ.”

    10  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í hàn fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ̀.

    Ẹ̀mí á máa wádìí ohun gbogbo, kódà àwọn àṣírí Ọlọ́run tó jinlẹ̀ jùlọ. 11 Ta ni nínú ènìyàn tí ó mọ èrò ọkàn ènìyàn kan, bí kò ṣe ẹ̀mí ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀? Bákan náà, kò sí ẹni ti ó mọ àwọn èrò Ọlọ́run, bí kò ṣe Ẹ̀mí Ọlọ́run fúnra rẹ̀. 12  Àwa kò gbà ẹ̀mí ti ayé yìí, bí kò ṣe Ẹ̀mí ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí a lè ní òye ohun tí Ọlọ́run fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́. 13  Èyí ni àwa ń wí, kì í ṣe èyí tí a ń kọ nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi ń kọ ènìyàn, èyí tí a ń fi ohun Ẹ̀mí wé ohun Ẹ̀mí. 14  Ṣùgbọ́n ènìyàn nípa ti ara kò gba ohun ti Ẹ̀mí Ọlọ́run wọ̀n-ọn-nì, nítorí pé wèrè ni wọ́n jásí fún un, òun kò sì le mọ̀ wọ́n, nítorí nípa tí Ẹ̀mí ní a fi ń wádìí wọn. 15  Ṣùgbọ́n ẹni tí ó wà nípa ti ẹ̀mí ń wádìí ohun gbogbo, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tí í wádìí rẹ̀.

  8. 10 Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà,

    ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,

    11 nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ,

    kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e.

    12 “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye;

    mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.

    13 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkórìíra ibi

    mo kórìíra ìgbéraga àti agídí,

    ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

    14 Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi

    mo ní òye àti agbára.

    15 Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso

    tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára.

    16 Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso,

    àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.

    17 Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi,

    àwọn tí ó sì wá mi rí mi.

    18 Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà,

    ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.

    19 Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ;

    ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.

    20 Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,

    ní ojú ọ̀nà òtítọ́,

    21 mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi

    mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.

    22 “Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀.

    Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;

    23 a ti yàn mí láti ayérayé,

    láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.

  9. 8 Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ.

    Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;

    9 kọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i

    kọ́ olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀.

    10 “Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,

    ìmọ̀ nípa Ẹni Mímọ́ ni òye.

    11 Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùn

    ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.

    12 Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè:

    bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”

  10. 13 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,

    ẹni tí ó tún ní òye sí i,

    14 nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ

    ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.

    15 Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;

    kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.

    16 Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;

    ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.

    17 Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura,

    òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà.

    18 Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á;

    àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.

    19 Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn;

    20 nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà,

    àwọsánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.

    21 Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́,

    má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn.

    22 Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ,

    àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ.

    23 Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu,

    ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀.

  11. 29 Ọlọ́run sì fún Solomoni ní ọgbọ́n, àti òye ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, àti ìmọ̀ gbígbòòrò òye tí a kò le è fiwé iyanrìn tí ó wà létí Òkun. 30 Ọgbọ́n Solomoni sì pọ̀ ju ọgbọ́n ọkùnrin ìlà-oòrùn lọ, ó sì pọ̀ ju gbogbo ọgbọ́n Ejibiti lọ. 31 Ó sì ní òye ju gbogbo ènìyàn lọ, ju Etani, ará Esra, àti Hemani àti Kalkoli, àti Darda àwọn ọmọ Maholi lọ. Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè yíká. 32 Ó sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) òwe, àwọn orin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé márùn-ún (1,005). 33 Ó sì sọ̀rọ̀ ti igi, láti kedari tí ń bẹ ní Lebanoni dé Hísópù tí ń dàgbà lára ògiri. Ó sì tún sọ ti àwọn ẹranko àti ti àwọn ẹyẹ, àti ohun tí ń rákò àti ti ẹja. 34 Àwọn ènìyàn sì ń wá láti gbogbo orílẹ̀-èdè láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọba ayé láti wá gbọ́ nípa ọgbọ́n rẹ̀.

  12. 9  Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò sinmi láti máa gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípasẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí. 10 Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹ lè gbé irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run,

  13. 20  Ọgbọ́n kígbe sókè ní pópó

    ó gbé ohùn rẹ̀ sókè láàrín ọjà;

    21 láàrín ọjà ni ó ti kígbe jáde

    ní ibodè ìlú ni ó ti sọ̀rọ̀ ọ rẹ̀:

    22 “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìmọ̀kan yóò fi fẹ́ àìmọ̀kan yín tó?

    Yóò ha ti pẹ́ tó tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò ṣe inú dídùn sí ìpẹ̀gàn tó?

    Àwọn aláìgbọ́n kórìíra ìmọ̀?

    23 Bí ẹ bá ti gbọ́ ìbáwí ì mi ni,

    ǹ bá ti tú ohun tí ó wà nínú ọkàn mi jáde fún yín

    kí n sì fi inú mi hàn sí i yín.

    24 Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pè

    kò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo na ọwọ́ sí wọn,

    25 níwọ́n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi,

    tí ẹ̀yin kò sì gba ìbáwí mi,

    26 Èmi pẹ̀lú yóò fi ìdààmú yín rẹ́rìn-ín;

    èmi yóò ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín.

  14. 5 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ

    má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ.

    6 Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ

    òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ.

    7  Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ

    bẹ̀rù Olúwa kí o sì kórìíra ibi.

    8 Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹ

    àti okun fún àwọn egungun rẹ.

  15. 19 Ní òru, àṣírí náà hàn sí Daniẹli ní ojú ìran. Nígbà náà ni Daniẹli fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run 20 Daniẹli wí pé:

    “Ọpẹ́ ni fún orúkọ Ọlọ́run láé àti láéláé;

    tirẹ̀ ni ọgbọ́n àti agbára.

    21 Ó yí ìgbà àti àkókò padà;

    ó mú ọba jẹ, ó ń mú wọn kúrò.

    Ó fún àwọn amòye ní ọgbọ́n

    àti ìmọ̀ fún àwọn tí ó ní òye.

    22 Ó fi ohun ìjìnlẹ̀ àti àṣírí hàn;

    ó mọ ohun tí ó pamọ́ nínú òkùnkùn

    àti ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ wà.

    23 Mo dúpẹ́, mo sì fi ìyìn fún ọ, ìwọ Ọlọ́run àwọn baba mi:

    ó ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbára

    ó ti fi àwọn nǹkan tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ hàn fún mi

    nítorí tí ìwọ ti fi àlá ọba hàn wá.”

  16. 30  Nítorí rẹ̀ ni ẹ̀yin ṣe wà nínú Kristi Jesu ẹni ti ó jásí ọgbọ́n fún wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—èyí ń ni, òdodo, ìwà mímọ́ àti ìràpadà wa. 31  Nítorí náà, bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni ti ó bá ń ṣògo kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.”

  17. 16  Èmi kò sì sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, àti láti máa rántí yín nínú àdúrà mi. 17 Mo sì ń béèrè nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọgbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ ọ́n sí i. 18  Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkàn yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìrètí ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́, 19 àti aláìlẹ́gbẹ́ títóbi agbára rẹ̀ fún àwa tí a gbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀,

  18. 1 Olúwa wí fún Mose pé, 2 “Wò ó, Èmi ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, 3 Èmi sì ti fi Ẹ̀mí Ọlọ́run kún un pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 4 Láti ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní wúrà, fàdákà àti idẹ, 5 láti gbẹ́ òkúta àti láti tò wọ́n, láti ṣiṣẹ́ ní igi, àti láti ṣiṣẹ́ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà.

  19. 1  Èèkàn kan yóò sọ láti ibi kùkùté Jese,

    láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan yóò ti so èso.

    2  Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé e,

    ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye,

    ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára,

    ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa.

    3 Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa.

    Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí,

    tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́,

  20. 10 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:

    òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,

    ìyìn rẹ̀ dúró láé.

  21. 28 Àti fún ènìyàn ni ó wí pé,

    “Kíyèsi i, ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n,

    àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.”

  22. 1 Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀,

    ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì,

    2 ó ti fi ilé pọn tí, ó ti fọ̀nà rokà.

    Ó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀

    3 ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè,

    láti ibi tí ó ga jù láàrín ìlú.

    4 “Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá!”

    Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé,

    5 “Wá, ẹ wá jẹ́ oúnjẹ mi

    sì mu wáìnì tí mo ti pò.

    6 Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè;

    rìn ní ọ̀nà òye.

  23. 6 Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá,

    ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye.

    7 Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn,

    nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀.

    8 Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà wọn

    ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ aṣiwèrè ni ìtànjẹ.

  24. 18  Kí ẹnikẹ́ni, má ṣe tan ara rẹ̀ jẹ mọ́. Bí ẹnikẹ́ni yín nínú ayé yìí ba rò pé òun gbọ́n, ẹ jẹ́ kí ó di òmùgọ̀ kí ó bá a le è gbọ́n. 19  Nítorí ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú Ìwé Mímọ́ pé, “Ẹni ti tí ó mu àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè wọn”; 20  lẹ́ẹ̀kan sí i, “Olúwa mọ̀ èrò inú àwọn ọlọ́gbọ́n pé asán ní wọn.”

  25. 12 Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára,

    kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.

  26. 97 Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó!

    Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀

    ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.

    98 Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,

    nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.

    99 Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ,

    nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ.

    100 Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ,

    nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.

  27. 5 Gba ọgbọ́n, gba òye,

    má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀.

    6 Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́,

    fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojútó ọ.

    7 Ọgbọ́n ni ó ga jù; nítorí náà gba ọgbọ́n.

    Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye.

  28. 33  A! Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run!

    Àwámárídìí ìdájọ́ rẹ̀ ti rí,

    ọ̀nà rẹ̀ sì jù àwárí lọ!

    34  “Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa?

    Tàbí ta ni í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀?”

    35  “Tàbí ta ni ó kọ́ fi fún un,

    tí a kò sì san padà fún un?”

    36  Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti nípa rẹ̀, àti fún un ni ohun gbogbo;

    ẹni tí ògo wà fún láéláé! Àmín.

  29. 12 Àwọn arúgbó ni ọgbọ́n wà fún,

    àti nínú gígùn ọjọ́ ni òye.

    13 “Ti Ọlọ́run ni ọgbọ́n àti agbára;

    òun ló ni ìmọ̀ àti òye.

  30. 16 Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ

    àti láti yan òye dípò o fàdákà!

  31. 16  Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ máa kọ́ ọ, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin sí Ọlọ́run ní ọkàn ọpẹ́.

  32. 1  Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta?

    Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?

    2 Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà,

    ní ìkóríta, ní ó dúró;

    3 ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú,

    ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:

    4 “Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè;

    mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn.

    5 Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n;

    ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye.

    6 Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye;

    Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́,

  33. 1 Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú

    má ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́;

    2 nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ohun búburú,

    ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ nípa dídá rúgúdù sílẹ̀.

    3 Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́

    nípa òye sì ni ó ti fìdímúlẹ̀;

    4 nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún

    pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n.

    5 Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀,

    ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń ní agbára sí i.

    6 Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà:

    nínú ìṣẹ́gun ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀.

    7 Ọgbọ́n ga ju fún aṣiwèrè

    àti gbọ̀ngàn ìlú níbi ibodè kò ní ohun tí yóò wí.

  34. 12 Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí,

    níbo sì ni òye ń gbe?

    13 Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀,

    bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.

    14 Ọ̀gbun wí pé, “Kò sí nínú mi”;

    omi òkun sì wí pé, “Kò si nínú mi.”

    15 A kò le è fi wúrà rà á,

    bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òsùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.

    16 A kò le è fi wúrà Ofiri, tàbí òkúta óníkìsì iyebíye,

    tàbí òkúta safire díye lé e.

    17 Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;

    bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀.

  35. 2 Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé,

    ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá.

  36. 24 “Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí ó bá sì ṣe wọn, èmi ó fiwé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, ti ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta. 25 Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sí bì lu ilé náà; síbẹ̀síbẹ̀ náà kò sì wó, nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta. 26 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí kò bá sì ṣe wọ́n, òun ni èmi yóò fiwé aṣiwèrè ènìyàn kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí iyanrìn. 27 Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ilé náà sì wó; wíwó rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ.”

  37. 30 Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,

    ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.

  38. 24 Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa!

    Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:

    ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ.

  39. 20 Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ìre,

    ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

    21 Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóye

    ọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú.

    22 Òye jẹ́ orísun ìyè fún àwọn tí ó ní i,

    ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ ń kó ìyà jẹ aláìgbọ́n.

    23 Ọkàn ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀

    ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ dàgbà.

    24 Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyin

    ó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun.

  40. 12 Nígbà náà ni mo tún bẹ̀rẹ̀ sí ọgbọ́n,

    àti ìsínwín àti àìgbọ́n

    kí ni ọba tí ó jẹ lẹ́yìn tí ọba kan kú le è ṣe

    ju èyí tí ọba ìṣáájú ti ṣe lọ.

    13 Mo sì ri wí pé ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀

    gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ.

    14 Ojú ọlọ́gbọ́n ń bẹ lágbárí rẹ̀,

    nígbà tí aṣiwèrè ń rìn nínú òkùnkùn,

    ṣùgbọ́n mo wá padà mọ̀

    wí pé ìpín kan náà ni ó ń dúró de ìsọ̀rí àwọn ènìyàn méjèèjì.

    15 Nígbà náà ni mo rò nínú ọkàn wí pé,

    “Irú ìpín tí òmùgọ̀ ní yóò bá èmi náà pẹ̀lú

    kí wá ni ohun tí mo jẹ ní èrè nípa ọgbọ́n?”

    Mo sọ nínú ọkàn mi wí pé,

    “Asán ni eléyìí pẹ̀lú.”

    16 Nítorí pé ọlọ́gbọ́n ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí i òmùgọ̀, a kì yóò rántí rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́;

    gbogbo wọn ni yóò di ohun ìgbàgbé ní ọjọ́ tó ń bọ̀.

    Ikú tí ó pa aṣiwèrè náà ni yóò pa ọlọ́gbọ́n ènìyàn.

  41. 26 Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹni dẹ́ṣẹ̀, Ó fún un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Eléyìí pẹ̀lú, asán ni, ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

  42. 1 Ta ni ó dàbí ọlọ́gbọ́n ènìyàn?

    Ta ni ó mọ ìtumọ̀ ohun gbogbo?

    Ọgbọ́n a máa mú ojú ènìyàn dán

    ó sì máa ń pààrọ̀ ìrínisí rẹ̀.

  43. 13 Mo sì tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n tí ó dùn mọ́ mi lábẹ́ oòrùn. 14 Ìlú kékeré kan tí ènìyàn díẹ̀ wà nínú rẹ̀ wà ní ìgbà kan rí. Ọba alágbára kan sì ṣígun tọ ìlú náà lọ, ó yí i po, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ tí ó tóbi lòdì sí i. 15 Ṣùgbọ́n, tálákà ọkùnrin tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n kan ń gbé ní ìlú náà, ó sì gba gbogbo ìlú u rẹ̀ là pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó rántí ọkùnrin tálákà náà. 16 Nítorí náà mo sọ wí pé, “Ọgbọ́n dára ju agbára.” Ṣùgbọ́n a kẹ́gàn ọgbọ́n ọkùnrin tálákà náà, wọn kò sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe.

    17 Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa wà ní ìmúṣẹ

    ju igbe òmùgọ̀ alákòóso lọ.

    18 Ọgbọ́n dára ju ohun èlò ogun lọ,

    ṣùgbọ́n ẹnìkan tó dẹ́ṣẹ̀ a máa ba ohun dídára púpọ̀ jẹ́.

  44. 18  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn. 19 Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn. 20  Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀, bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.

    21  Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn. 22 Níwọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá, 23  wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kì í díbàjẹ́ sí àwọn àwòrán ère bí i ti ènìyàn tí í díbàjẹ́ àti ti ẹyẹ, àti ti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti ti ẹranko afàyàfà.

  45. 15 Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa rìn ní ìwà pípé, kì í ṣé bí àwọn òmùgọ̀, ṣùgbọ́n bí àwọn ọlọ́gbọ́n; 16  ẹ máa ra ìgbà padà, nítorí búburú ní àwọn ọjọ́. 17 Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòye ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí.

  46. 33 Ìbẹ̀rù Olúwa kọ́ ènìyàn ní ọgbọ́n,

    ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ọlá.

  47. 8 Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀;

    ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.

  48. 26 Ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀ jẹ́ aláìgbọ́n

    ṣùgbọ́n ẹni tí ń rìn nínú ọgbọ́n wà láìléwu.

  49. 16 Nígbà tí mo lo ọkàn mi láti mọ ọgbọ́n àti láti wo wàhálà ènìyàn ní ayé. 17 Nígbà náà ni mo rí gbogbo ohun tí Ọlọ́run tí ṣe, kò sí ẹnìkan tí ó le è mòye ohun tí ó ń lọ lábẹ́ oòrùn. Láìbìkítà gbogbo ìyànjú rẹ̀ láti wá rí jáde, ènìyàn kò le è mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kódà bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn rò wí pé òun mọ̀ ọ́n, kò le è ní òye rẹ̀ ní pàtó.

  50. 4 Ǹjẹ́ onírúurú ẹ̀bùn ni ó wà, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí kan náà ni o ń pín wọn. 5 Onírúurú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà sì ni. 6 Onírúurú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà ni ẹni tí ń ṣiṣẹ́ gbogbo wọn nínú gbogbo wọn.

    7 Ṣùgbọ́n à ń fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fún olúkúlùkù ènìyàn láti fi jèrè. 8 Ẹ̀mí Mímọ́ lè fún ẹnìkan ní ọgbọ́n láti lè fún ènìyàn nímọ̀ràn, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ ńlá. Láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà ni èyí ti wá. 9 Ó fi ẹ̀bùn ìgbàgbọ́ fún ẹlòmíràn, ẹlòmíràn ló sì fi agbára ìwòsàn fún nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà. 10  Ó fi agbára fún àwọn mìíràn láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. Ó fún àwọn mìíràn lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àti láti wàásù pẹ̀lú ìmísí. Bákan náà ló fún àwọn kan lẹ́bùn láti mọ ìyàtọ̀ láàrín àwọn ẹ̀mí. Ó fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn àti agbára láti lè sọ èdè tí wọn kò mọ̀. Bákan náà ó fún àwọn ẹlòmíràn lágbára láti mọ̀ àti láti túmọ̀ èdè tí wọn kò gbọ́ rí. 11 Àní, Ẹ̀mí kan ṣoṣo ní ń fún ni ní gbogbo ẹ̀bùn àti agbára wọ̀nyí. Òun ni ẹni tí ń ṣe ìpinnu ẹ̀bùn tí ó yẹ láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan.

  51. 12  Ó yí ìmọ̀ àwọn alárékérekè po,

    bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdáwọ́lé wọn ṣẹ.

    13 Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè ara wọn,

    àti ìmọ̀ àwọn òǹrorò ní ó tì ṣubú ní ògèdèǹgbé.

  52. 8 Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹ,

    ṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun.

    9 Ẹni tí ó ń rìn déédé, ń rìn láìléwu,

    ṣùgbọ́n àṣírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú.

  53. 13 Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára,

    oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu.

    14 Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹ

    bí ìwọ bá rí i ìrètí ọjọ́ iwájú wà fún ọ

    ìrètí rẹ kì yóò sì já ṣófo.

  54. 10 Má ṣe sọ wí pé, “Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí?”

    Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀.

    11 Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún ìní jẹ́ ohun tí ó dára

    ó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní.

    12 Ọgbọ́n jẹ́ ààbò

    gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbò

    ṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyí

    pé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá ní.

    13 Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe:

    “Ta ni ó le è to

    ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?”

    14 Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn,

    ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó:

    Ọlọ́run tí ó dá èkínní

    náà ni ó dá èkejì.

    Nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwárí

    ohun kankan nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀.

  55. 21 Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn

    tí wọ́n jáfáfá lójú ara wọn.

  56. 13  Olúwa wí pé:

    “Àwọn ènìyàn yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹnu wọn,

    wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ètè wọn,

    ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi.

    Ìsìn wọn si mi

    ni a gbé ka orí òfin tí àwọn

    ọkùnrin kọ́ ni.

    14  Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò ya

    àwọn ènìyàn yìí lẹ́nu

    pẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu;

    ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé,

    ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.”

  57. 23 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

    “Má ṣe jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yangàn nítorí agbára ọgbọ́n rẹ̀,

    tàbí alágbára nítorí agbára rẹ̀,

    tàbí ọlọ́rọ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀.

    24  Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé:

    òun ní òye, òun sì mọ̀ mí wí pé,

    Èmi ni Olúwa tí ń ṣe òtítọ́,

    ìdájọ́ àti òdodo ní ayé,

    nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí,”

    Olúwa wí.

  58. 9  Ta ni ọlọ́gbọ́n? Òun yóò mòye àwọn nǹkan wọ̀nyí.

    Ta a ní ó mọ̀? Òun yóò ní ìmọ̀ wọn.

    Títọ́ ni ọ̀nà Olúwa

    àwọn olódodo si ń rìn nínú wọn,

    ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ni yóò kọsẹ̀ nínú wọn.

  59. 54  Ó wá sí ìlú òun tìkára rẹ̀, níbẹ̀ ni ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú Sinagọgu, ẹnu sì yà wọ́n. Wọ́n béèrè pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí ti mú ọgbọ́n yìí àti iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí wá?

  60. 14  Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ ní ọkàn yín pé ẹ ko ronú ṣáájú, bí ẹ ó ti dáhùn. 15 Nítorí tí èmi ó fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn ọ̀tá yín kì yóò lè sọ̀rọ̀-òdì sí, tí wọn kì yóò sì lè kò lójú.

  61. 4 Nígbà tí ayaba Ṣeba sì rí gbogbo ọgbọ́n Solomoni àti ààfin tí ó ti kọ́. 5 Oúnjẹ tí ó wà lórí i tábìlì rẹ̀, ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti ìdúró àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀, àti ẹbọ sísun tí ó sun ní ilé Olúwa, kò sì sí ẹ̀mí kan nínú rẹ̀ mọ́!

    6 Ó sì wí fún ọba pé, “Òtítọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní orílẹ̀-èdè mi ní ti iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ. 7 Ṣùgbọ́n èmi kò sì gba nǹkan wọ̀nyí gbọ́ títí ìgbà tí mo wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Sì kíyèsi i, a kò sọ ìdajì wọn fún mi; ìwọ sì ti fi ọgbọ́n àti ìrora kọjá òkìkí tí mo gbọ́. 8 Báwo ni inú àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe dùn tó! Báwo ni inú dídùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n sì ń gbọ́ ọgbọ́n rẹ!

  62. 36 Ta ni ó fi ọgbọ́n pamọ́ sí odò ikùn

    tàbí tí ó fi òye sínú àyà?

    37 Ta ni ó fi ọgbọ́n ka iye àwọsánmọ̀?

    Ta ni ó sì mú ìgò ọ̀run dà jáde,

  63. 33 Kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ;

    nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.

    34 Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́

    èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.

    35 Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí,

    nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.

  64. 1 Ọmọ mi, fiyèsí ọgbọ́n mi,

    kí o sì dẹtí rẹ sí òye mi,

    2 kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́ra

    kí ètè rẹ sì le pa ìmọ̀ mọ́.

  65. 10 Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni

    ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.

  66. 20 Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n;

    ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn n bà á jẹ́.

    21 Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè,

    òdodo, àti ọlá.

  67. 30 Kò sí ọgbọ́n, kò sí ìmòye,

    tàbí ìmọ̀ràn tí ó le mókè níwájú Olúwa.

  68. 16 Mo rò nínú ara mi, “Wò ó, mo ti dàgbà, ọgbọ́n mi sì ti pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni tí ó ti ṣe alákòóso Jerusalẹmu síwájú mi lọ, mo ti ní ìrírí púpọ̀ nípa ọgbọ́n àti ìmọ̀.” 17 Nígbà náà ni mo fi ara jì láti ní ìmọ̀ nípa ọgbọ́n, àti pàápàá àìgbọ́n àti òmùgọ̀, ṣùgbọ́n mo rí, wí pé èyí pẹ̀lú bí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

    18 Nítorí pé ọgbọ́n púpọ̀ ìbànújẹ́ púpọ̀ ní ń mú wá,

    bí ìmọ̀ bá sì ṣe pọ̀ tó náà ni ìbànújẹ́ ń pọ̀ tó.

  69. 5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò ní wá sí ìpalára kankan,

    àyà ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò sì mọ àsìkò tí ó tọ́ àti ọ̀nà tí yóò gbà ṣe é.

  70. 52  Jesu sì ń pọ̀ ní ọgbọ́n, sì ń dàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.

  71. 2 Ẹ fi ara yín jì fún àdúrà gbígbà, kí ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì máa dúpẹ́; 3 ẹ máa gbàdúrà fún wa pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè ṣí ìlẹ̀kùn fún wa fún ọ̀rọ̀ náà, láti máa sọ ohun ìjìnlẹ̀ Kristi, nítorí èyí tí mo ṣe wà nínú ìdè pẹ̀lú. 4 Ẹ gbàdúrà pé kí èmi le è máa kéde rẹ̀ kedere gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi. 5  Ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti bí ẹ ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí ń bẹ lóde, kí ẹ sì máa ṣe ṣí àǹfààní tí ẹ bá nílò. 6 Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá olúkúlùkù ènìyàn lóhùn.

  72. 6 Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;

    ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀.

  73. 43 Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsi nǹkan wọ̀nyí

    kí ó wo títóbi ìfẹ́ Olúwa.

  74. 32 “Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi,

    ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́.

    33 Fetí sí ìtọ́sọ́nà mi kí o sì gbọ́n;

    má ṣe pa á tì sápá kan.

    34 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetísílẹ̀ sí mi,

    tí ń ṣọ́nà ní ẹnu-ọ̀nà mi lójoojúmọ́,

    tí ń dúró ní ẹnu-ọ̀nà mi.

    35 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyè

    ó sì rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ Olúwa.

    36 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára

    gbogbo ẹni tí ó kórìíra mi fẹ́ ikú.”

  75. 30 Èso òdodo ni igi ìyè

    ẹni tí ó sì jèrè ọkàn jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

  76. 33 Ọgbọ́n wà nínú ọkàn olóye

    kódà láàrín àwọn aláìlóye, ó jẹ́ kí wọn mọ òun.

  77. 3 Ènìyàn tí ó fẹ́ràn ọgbọ́n mú kí baba rẹ̀ láyọ̀

    ṣùgbọ́n ẹni ti ń bá panṣágà kẹ́gbẹ́ ba ọrọ̀ ọ rẹ̀ jẹ́.

  78. 15 Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́n

    ṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnra rẹ̀ a dójútì ìyá rẹ̀.

  79. 11 Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ wọn sì dàbí ìṣó tí a kàn pọ̀ dáradára, tí olùṣọ́-àgùntàn kan fi fún ni.

  80. 8 “Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín,

    tàbí ọ̀nà yín a ha máa ṣe ọ̀nà mi,”

    ni Olúwa wí.

    9 “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ,

    bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ

    àti èrò mi ju èrò yín lọ.

  81. 7 Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run

    mọ ìgbà tirẹ̀,

    àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé

    mọ àkókò ìṣípò padà wọn.

    Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò mọ

    ohun tí Olúwa wọn fẹ́.

    8 “ ‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n,

    nítorí a ní òfin Olúwa,”

    nígbà tí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọn akọ̀wé

    ti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn.

    9 Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n,

    a ó dà wọ́n láàmú, wọn yóò sì kó sí ìgbèkùn.

    Nítorí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa,

    irú ọgbọ́n wo ló kù tí wọ́n ní?

  82. 20 Nínú gbogbo ọ̀ràn ọgbọ́n àti òye tí ọba ń béèrè lọ́wọ́ wọn, ó rí i pé wọ́n sàn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju gbogbo àwọn amòye àti ọlọ́gbọ́n tí ó wà ní gbogbo ìjọba rẹ̀.

  83. 11 Ọkùnrin kan wà ní ìjọba à rẹ, ẹni tí ẹ̀mí ọlọ́run mímọ́ ń gbé inú rẹ̀. Ní ìgbà ayé e baba à rẹ, òun ni ó ní ojú inú, òye àti ìmọ̀ bí i ti ọlọ́run òun ni ọba Nebukadnessari, baba rẹ̀ fi jẹ olórí àwọn apidán, awòràwọ̀, apògèdè àti aláfọ̀ṣẹ. 12 Ọkùnrin náà ni Daniẹli ẹni tí ọba ń pè ní Belṣassari, ó ní ẹ̀mí tí ó tayọ, ìmọ̀ àti òye, àti agbára láti túmọ̀ àlá, ó máa ń ṣe àlàyé àlá àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá da ojú rú, ránṣẹ́ pè é, yóò sì sọ nǹkan tí àkọsílẹ̀ ìwé náà túmọ̀ sí.”

  84. 3  Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé. 4  Ṣùgbọ́n ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀.”

  85. 25  Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Mo yìn ọ Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, nítorí ìwọ ti fi òtítọ́ yìí pamọ́ fún àwọn tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti amòye, Ìwọ sì ti fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́. 26 Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí ó wù ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

    27 “Ohun gbogbo ni Baba mi ti fi sí ìkáwọ́ mi. Kò sí ẹni tí ó mọ ọmọ bí kò ṣe Baba, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí ó mọ Baba, bí kò ṣe ọmọ, àti àwọn tí ọmọ yan láti fi ara hàn fún.

  86. 21  Ní wákàtí kan náà Jesu yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sá à yẹ ní ojú rẹ.

  87. 23 Solomoni ọba sì pọ̀ ní ọrọ̀ àti ní ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba ayé lọ. 24 Gbogbo ayé sì ń wá ojú Solomoni láti gbọ́ ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sí i ní ọkàn.

  88. 13 Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye,

    ṣùgbọ́n kùmọ̀ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye.

    14 Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ,

    ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun.

  89. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n

    17 Dẹtí rẹ sílẹ̀,

    kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n,

    kí o sì fi àyà rẹ sí ẹ̀kọ́ mi.

    18 Nítorí ohun dídùn ni bí ìwọ bá pa wọ́n mọ́ ní inú rẹ;

    nígbà tí a sì pèsè wọn tán ní ètè rẹ.

    19 Kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lè wà ní ti Olúwa,

    èmi fihàn ọ́ lónìí, àní fún ọ.

    20 Èmi kò ha ti kọ̀wé ohun dáradára

    sí ọ ní ti ìmọ̀ràn àti ní ti ẹ̀kọ́,

    21 kí ó lè mú ọ mọ ìdájú ọ̀rọ̀ òtítọ́;

    kí ìwọ le máa fi ìdáhùn òtítọ́

    fún àwọn tí ó rán ọ?

  90. 12 Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀,

    ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,

    ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ síta nípa òye rẹ̀.