90 Bible Verses About Worshiping God

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Worshiping God
  1. 21  Jesu wí fún un pé, “Gbà mí gbọ́ obìnrin yìí, àkókò náà ń bọ̀, nígbà tí kì yóò ṣe lórí òkè yìí tàbí ní Jerusalẹmu ni ẹ̀yin ó máa sin Baba. 22  Ẹ̀yin ń sin ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀, àwa ń sin ohun tí àwa mọ̀, nítorí ìgbàlà ti ọ̀dọ̀ àwọn Júù wá. 23 Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́, nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun. 24  Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”

  2. 1 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa,

    ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.

    2 Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́

    kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò

    orin àti ìyìn.

    3 Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,

    ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.

    4 Ní ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,

    ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.

    5 Tirẹ̀ ni Òkun, nítorí òun ni ó dá a

    àti ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.

    6 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín,

    ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú

    Olúwa ẹni tí ó dá wa,

    7  nítorí òun ni Ọlọ́run wa,

    àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀,

    àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀.

    Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,

  3. 1  Nítorí náà mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín ará, kí ẹ̀yin kí ó fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè mímọ́, ìtẹ́wọ́gbà, èyí ni iṣẹ́ ìsìn yín tí ó tọ̀nà.

  4. Saamu. Fún ọpẹ́.

    1 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé.

    2 Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa,

    ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn

    3 Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,

    kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé

    tirẹ̀ ni àwa, àwa ní ènìyàn rẹ̀

    àti àgùntàn pápá rẹ̀.

    4 Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́

    àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;

    ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.

  5. Saamu ti Dafidi.

    1 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,

    ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.

    2 Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀;

    sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.

  6. 8 Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;

    ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀.

    9 Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;

    ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.

  7. 8  Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, tí olúkúlùkù wọn ni ìyẹ́ mẹ́fà, kún fún ojú yíká ara àti nínú; wọn kò sì sinmi lọ́sàn àti lóru, láti wí pé:

    “ ‘Mímọ́, mímọ́, mímọ́,

    Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè,’

    tí ó ti wà, tí ó sì ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀ wá!”

    9  Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá sì fi ògo àti ọlá, àti ọpẹ́ fún ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń bẹ láààyè láé àti láéláé. 10 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà yóò sì wólẹ̀ níwájú ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, wọn yóò sì tẹríba fún ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé, wọn yóò sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wí pé:

    11 “Olúwa àti Ọlọ́run, ìwọ ni o yẹ,

    láti gba ògo àti ọlá àti agbára,

    nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo,

    àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ̀ ni

    wọn fi wà tí a sì dá wọn.”

  8. 14 Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé.

    15 Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan; kí ẹ sì máa dúpẹ́. 16  Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ máa kọ́ ọ, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin sí Ọlọ́run ní ọkàn ọpẹ́. 17 Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn ní orúkọ Jesu Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run Baba nípasẹ̀ rẹ̀.

  9. 28 Nítorí náà bí àwa tí ń gbà ilẹ̀ ọba ti a kò lè mì, ẹ jẹ́ kí a dá ọpẹ́ nípa èyí ti a fi lè máa sin Ọlọ́run ni ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù rẹ̀. 29  Nítorí pé, “Ọlọ́run wa, iná ti ń jó ni run ni.”

  10. 15  Ǹjẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyí yìí ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀. 16 Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣoore àti láti máa pín fun ni nítorí irú ẹbọ wọ̀nyí ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.

  11. 5 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Lefi: Jeṣua, Kadmieli, Bani, Haṣbneiah, Ṣerebiah, Hodiah, Ṣebaniah àti Petahiah—wí pé, “Ẹ dìde ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó wà láé àti láéláé.”

    “Ìbùkún ni fún orúkọ rẹ tí ó ní ògo, kí ó sì di gbígbéga ju gbogbo ìbùkún àti ìyìn lọ. 6 Ìwọ nìkan ni Olúwa. Ìwọ ni ó dá ọ̀run, àní àwọn ọ̀run tí ó ga jù pẹ̀lú gbogbo ogun wọn, ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀. Ìwọ sì pa gbogbo wọn mọ́ láàyè, ogun ọ̀run sì ń sìn ọ́.

  12. 29 Fún Olúwa ní ìyìn nítorí orúkọ rẹ̀;

    gbé ọrẹ kí ẹ sì wá síwájú rẹ̀.

    Sìn Olúwa nínú inú dídùn ìwà mímọ́ rẹ̀.

  13. 17 Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòye ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí. 18 Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurùdu wà; ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. 19  Ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin Ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrin dídùn ní ọkàn yín sí Olúwa. 20 Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo fún ohun gbogbo lọ́wọ́ Ọlọ́run, àní Baba, ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wá.

    21 Ẹ máa tẹríba fún ara yín ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

  14. 9  Nítorí náà, Ọlọ́run ti gbé e ga sí ipele tí ó ga jùlọ,

    ó sì ti fi orúkọ kan ti ó borí gbogbo orúkọ fún un,

    10 pé ni orúkọ Jesu ni kí gbogbo eékún máa wólẹ̀,

    ní ọ̀run, àti ní orí ilẹ̀ ayé àti ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,

    11 àti pé kí gbogbo ahọ́n jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi ni Olúwa,

    fún ògo Ọlọ́run Baba.

  15. 3  Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kristi. 4 Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́ 5 ẹni tí ò ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jesu Kristi fún ara rẹ̀, ní ìbámu ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀, 6  fún ìyìn ògo oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí ò ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀.

  16. 9 Lẹ́yìn náà, mo ri, sì kíyèsi i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ẹnikẹ́ni kò lè kà, láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo, àti ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti láti inú èdè gbogbo wá, wọn dúró níwájú ìtẹ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, a wọ̀ wọ́n ni aṣọ funfun, imọ̀ ọ̀pẹ si ń bẹ ni ọwọ́ wọn. 10 Wọ́n sì kígbe ní ohùn rara, wí pé:

    “Ìgbàlà ni ti Ọlọ́run wá

    tí o jókòó lórí ìtẹ́,

    àti ti Ọ̀dọ́-àgùntàn!”

    11 Gbogbo àwọn angẹli sì dúró yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn àgbà àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ká, wọn wólẹ̀ wọn si dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà wọ́n sì sin Ọlọ́run. 12 Wí pe:

    “Àmín!

    Ìbùkún, àti ògo,

    àti ọgbọ́n, àti ọpẹ́, àti ọlá,

    àti agbára àti ipá fún Ọlọ́run wa láé àti láéláé!

    Àmín!”

  17. 8 Èmi, Johanu, ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó sì ri nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí mo sì gbọ́ tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti foríbalẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ angẹli náà, tí o fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi. 9 Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Wó ò, má ṣe bẹ́ẹ̀, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ wòlíì, àti ti àwọn tí ń pa ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí mọ́. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run!”

  18. 9  Wọn sì ń kọ orin tuntun kan, wí pé:

    “Ìwọ ní o yẹ láti gba ìwé náà,

    àti láti ṣí èdìdì rẹ̀:

    nítorí tí a tí pa ọ,

    ìwọ sì tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ìràpadà ènìyàn sí Ọlọ́run láti inú ẹ̀yà gbogbo,

    àti èdè gbogbo, àti inú ènìyàn gbogbo, àti orílẹ̀-èdè gbogbo wá.

    10  Ìwọ sì tí ṣe wọ́n ni ọba àti àlùfáà sì Ọlọ́run wá:

    wọ́n sì ń jẹ ọba lórí ilẹ̀ ayé.”

    11  Èmi sì wò, mo sì gbọ́ ohùn àwọn angẹli púpọ̀ yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn ẹ̀dá alààyè náà àti àwọn àgbà náà ká. Iye wọn sì jẹ́ ẹgbàárùn-ún ọ̀nà ẹgbàárùn-ún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún. 12 Wọn ń wí lóhùn rara pé:

    “Yíyẹ ni Ọ̀dọ́-àgùntàn náà tí a tí pa,

    láti gba agbára,

    àti ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n, àti ipá, àti ọlá,

    àti ògo, àti ìbùkún.”

    13 Gbogbo ẹ̀dá tí o sì ń bẹ ni ọ̀run, àti lórí ilẹ̀ ayé, àti nísàlẹ̀ ilẹ̀ àti irú àwọn tí ń bẹ nínú Òkun, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú wọn, ni mo gbọ́ tí ń wí pé,

    “Kí a fi ìbùkún àti ọlá, àti ògo, àti agbára,

    fún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti fún Ọ̀dọ́-àgùntàn

    náà láé àti láéláé.”

    14 Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà wí pé, “Àmín!” Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé.

  19. 7  Olúwa sì farahan Abramu, ó sì wí fún un pé, “Irú-ọmọ rẹ ni Èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu tẹ́ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Olúwa tí ó fi ara hàn án.

    8 Ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè àwọn òkè kan ní ìhà ìlà-oòrùn Beteli, ó sì pàgọ́ rẹ̀ síbẹ̀. Beteli wà ní ìwọ̀-oòrùn, Ai wà ní ìlà-oòrùn. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ó sì ké pe orúkọ Olúwa.

  20. 1 Ọlọ́run sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pé,

    2  “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti, láti oko ẹrú jáde wá.

    3  “Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi.

    4  Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. 5  Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára àwọn ọmọ, láti ìran kẹta títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi. 6 Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.

  21. 1 Nadabu àti Abihu tí í ṣe ọmọ Aaroni sì mú àwo tùràrí kọ̀ọ̀kan, wọ́n fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀, wọ́n sì rú iná àjèjì níwájú Olúwa, èyí tó lòdì sí àṣẹ Olúwa. 2 Torí èyí, iná jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú Olúwa. 3 Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Ohun tí Olúwa ń sọ nípa rẹ̀ nìyìí nígbà tó wí pé,

    “ ‘Ní àárín àwọn tó súnmọ́ mi,

    Èmi yóò fi ara mi hàn ní mímọ́

    ojú gbogbo ènìyàn

    Ní a ó ti bu ọlá fún mi.’ ”

    Aaroni sì dákẹ́.

  22. 1 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kan náà, àwọn ọmọ Israẹli péjọpọ̀, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da eruku sórí ara wọn. 2 Àwọn ọkùnrin Israẹli sì ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú gbogbo àwọn àjèjì. Wọ́n dúró ní ààyè e wọn, wọ́n sì ń jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ wọn àti iṣẹ́ búburú àwọn baba wọn. 3 Wọ́n dúró sí ibi tí wọ́n wà, wọ́n sì fi ìdámẹ́rin ọjọ́ kà nínú ìwé òfin Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì tún fi ìdámẹ́rin mìíràn ní ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ní sí sin Olúwa Ọlọ́run wọn.

  23. Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda.

    1 Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi,

    nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ,

    òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi,

    ara mi fà sí ọ,

    ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀

    níbi tí kò sí omi.

    2 Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́,

    mo rí agbára àti ògo rẹ.

    3 Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ,

    ètè mi yóò fògo fún ọ.

    4 Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè,

    èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ.

  24. 13  Olúwa wí pé:

    “Àwọn ènìyàn yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹnu wọn,

    wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ètè wọn,

    ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi.

    Ìsìn wọn si mi

    ni a gbé ka orí òfin tí àwọn

    ọkùnrin kọ́ ni.

    14  Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò ya

    àwọn ènìyàn yìí lẹ́nu

    pẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu;

    ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé,

    ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.”

  25. 42 Wọ́n sì dúró ṣinṣin nínú ẹ̀kọ́ àwọn aposteli, àti ní ìdàpọ̀, ní bíbu àkàrà àti nínú àdúrà. 43 Ẹ̀rù sí ba gbogbo ọkàn; iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì púpọ̀ ni a ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe. 44  Gbogbo àwọn tí ó sì gbàgbọ́ wà ni ibìkan, wọn ní ohun gbogbo sọ́kàn; 45 Wọn si ń ta ohun ìní àti ẹrù wọn, wọn sì ń pín wọn fún olúkúlùkù, gẹ́gẹ́ bí ẹnikẹ́ni tí í ṣe aláìní sí. 46 Wọ́n fi ọkàn kan dúró lójoojúmọ́ nínú tẹmpili. Wọ́n ń bu àkàrà ní ilé wọn, wọn ń fi inú dídùn àti ọkàn òtítọ́ jẹ oúnjẹ wọn. 47 Wọ́n yín Ọlọ́run, wọn sì rí ojúrere lọ́dọ̀ ènìyàn gbogbo, Olúwa sí ń yàn kún wọn lójoojúmọ́, àwọn tí à ń gbàlà.

  26. 7 Ẹ̀yin àgàbàgebè, ní òtítọ́ ni Wòlíì Isaiah sọtẹ́lẹ̀ nípa yín wí pé:

    8 “ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń fi ẹnu lásán bu ọlá fún mi,

    ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà réré sí mi.

    9 Lásán ni ìsìn wọn;

    nítorí pé wọ́n ń fi òfin ènìyàn kọ́ ni ní ẹ̀kọ́.’ ”

  27. 8  Jesu sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Satani, nítorí tí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ìwọ foríbalẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ kí ó sì máa sìn.’ ”

  28. 29 Mose àti Aaroni pe gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli jọ. 30 Aaroni sọ ohun gbogbo tí Olúwa sọ fún Mose fún wọn, ó sì ṣe iṣẹ́ àmì náà ní ojú àwọn ènìyàn náà. 31 Wọ́n sì gbàgbọ́. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Olúwa ti bẹ àwọn ọmọ Israẹli wò àti pé Olúwa ti gbọ́ nípa ìpọ́njú wọn, wọ́n tẹríba, wọ́n sì sìn ín. Ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ àmì náà níwájú àwọn ènìyàn náà.

  29. 31 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn;

    lẹ́ kí wọn kí ó sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, pé “Olúwa jẹ ọba!”

    32 Jẹ́ kí ọ̀run kí ó tún dún padà, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀;

    Jẹ́ kí àwọn pápá kí ó hó fún ayọ̀, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀!

    33 Nígbà náà ni igi igbó yóò kọrin,

    wọn yóò kọrin fún ayọ̀ níwájú Olúwa,

    nítorí tí ó wá láti ṣèdájọ́ ayé.

    34  Fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára;

    ìfẹ́ ẹ rẹ̀ dúró títí láé.

    35  Ké lóhùn rara, “Gbà wá, Ọlọ́run olùgbàlà a wa;

    kó wa jọ kí o sì gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,

    kí àwa kí ó lè fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ,

    kí àwa kí ó lè yọ̀ nínú ìyìn rẹ̀.”

    36 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli,

    láé àti láéláé.

    Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn ènìyàn wí pé, “Àmín,” wọ́n “Yin Olúwa.”

  30. 3 Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí iná tí ó ń sọ̀kalẹ̀ àti ògo Olúwa lórí ilé Olúwa náà, wọ́n sì kúnlẹ̀ lórí eékún wọn pẹ̀lú ojú ni dídàbolẹ̀, wọ́n sì sin Olúwa, wọ́n sì fi ìyìn fún Olúwa wí pé,

    “Nítorí tí ó dára;

    àánú rẹ̀ sì dúró títí láéláé.”

  31. 22 Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi;

    nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́.

    23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ yìn ín!

    Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un!

    Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli!

  32. Fún adarí orin. Orin. Saamu.

    1 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ilẹ̀ gbogbo!

    2 Ẹ kọrin ọlá orúkọ rẹ̀;

    ẹ kọrin ìyìnsí i.

    3 Ẹ wí fún Ọlọ́run pé, “Ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ rẹ!

    Nípa ọ̀pọ̀ agbára rẹ

    ni àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi sìn ọ́.

    4 Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ;

    wọn ń kọrin ìyìn sí ọ,

    wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.” Sela.

  33. 24 Nígbà tí ó gbọ́ irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ̀ wọ́n sínú túbú tí inú lọ́hùn, ó sí kan àbà mọ wọ́n lẹ́sẹ̀.

    25 Ṣùgbọ́n láàrín ọ̀gànjọ́ Paulu àti Sila ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin ìyìn si Ọlọ́run, àwọn ara túbú sì ń tẹ́tí sí wọn. 26 Lójijì ilẹ̀ mímì ńlá sì mi, tó bẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé túbú mì tìtì: lọ́gán, gbogbo ìlẹ̀kùn sì ṣí, ìdè gbogbo wọn sì tú sílẹ̀.

  34. 14  Ẹ má ṣe sin ọlọ́run mìíràn, nítorí Olúwa, orúkọ ẹni ti ń jẹ́ Òjòwú, Ọlọ́run owú ni.

  35. Saamu ìyìn. Ti Dafidi.

    1 Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi;

    èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé.

    2 Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́

    èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé.

    3 Títóbi ni Olúwa. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀:

    kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀.

    4 Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn;

    wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ.

  36. 3 Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín.

    Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.

    4 Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín

    fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín,

    5 Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè,

    ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.

    6 Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa.

    Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

  37. 8 Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé àti gbogbo ògo wọn hàn án. 9 Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.”

    10  Jesu wí fún un pé, “Padà kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Nítorí a ti kọ ọ́ pé, ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.’ ”

  38. 52  Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì padà lọ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ayọ̀ púpọ̀. 53 Wọ́n sì wà ní tẹmpili nígbà gbogbo, wọ́n ń fi ìyìn, àti ìbùkún fún Ọlọ́run.

  39. 1  Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,

    ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.

    2 Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀

    ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́.

    3 Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè

    àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.

    4 Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;

    òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ.

    5 Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè

    ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run.

    6 Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀

    agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.

  40. 10 Lóòótọ́, Daniẹli mọ̀ pé a ti fi ọwọ́ sí ìwé òfin náà, síbẹ̀ ó wọ ilé e rẹ̀ lọ, nínú yàrá òkè, ó ṣí fèrèsé èyí tí ó kọjú sí Jerusalẹmu sílẹ̀. Ó kúnlẹ̀ lórí orúnkún un rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lójoojúmọ́, ó gbàdúrà, ó fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ tẹ́lẹ̀.

  41. 3  Nítorí àwa ni onílà, tí ń sin Ọlọ́run nípa ti Ẹ̀mí, àwa sì ń ṣògo nínú Kristi Jesu, àwa kò sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹran-ara.

  42. 3  Wọ́n sì ń kọ orin ti Mose, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àti orin ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn, wí pé:

    “Títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ,

    Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè;

    òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀nà rẹ̀,

    ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè.

    4  Ta ni kì yóò bẹ̀rù, Olúwa,

    tí kì yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ̀?

    Nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni mímọ́.

    Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóò sì wá,

    ti yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ,

    nítorí a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn.”

  43. 20 Nígbà náà ni Jobu dìde, ó sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, ó sì fá orí rẹ̀ ó wólẹ̀ ó sì gbàdúrà 21 wí pé,

    “Ní ìhòhò ní mo ti inú ìyá mi jáde wá,

    ni ìhòhò ní èmi yóò sì tún padà lọ.

    Olúwa fi fún ni, Olúwa sì gbà á lọ,

    ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa.”

  44. 8 Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, Olúwa:

    kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ.

    9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dá

    yóò wá láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, Olúwa;

    wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀.

    10 Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu;

    ìwọ nìkan ni Ọlọ́run.

  45. 5 Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa

    ẹ foríbalẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.

  46. 6  Jesu dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹyin àgàbàgebè yìí, òtítọ́ ni wòlíì Isaiah ń sọtẹ́lẹ̀ nípa tí ẹ̀yin àgàbàgebè, bí a ti kọ ọ́ pé:

    “ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún mi

    ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi.

    7 Ìsìn wọn jẹ́ lásán,

    ìkọ́ni wọ́n jẹ́ kìkìdá òfin tí àwọn ènìyàn fi ń kọ́ni.’

  47. 9  Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn olú àlùfáà, Orílẹ̀-èdè mímọ́, ènìyàn ọ̀tọ̀ ki ẹ̀yin lè fi ọláńlá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn.

  48. 4 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé:

    “Àmín, Haleluya!”

    5  Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé:

    “Ẹ máa yin Ọlọ́run wa,

    ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo,

    ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

    àti èwe àti àgbà!”

    6 Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńlá ńlá, ń wí pé:

    “Haleluya!

    Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba.

    7  Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi,

    kí a sì fi ògo fún un.

    Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé,

    aya rẹ̀ sì ti múra tán.

  49. 20 Miriamu wòlíì obìnrin, arábìnrin Aaroni, mú ohun èlò orin ni ọwọ́ rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin sì jáde tẹ̀lé e pẹ̀lú ìlù òun ijó. 21 Miriamu kọrin sí wọn báyìí pé,

    “Ẹ kọrin sí Olúwa,

    nítorí òun ni ológo jùlọ.

    Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún,

    ni òun bi ṣubú sínú Òkun.”

  50. 27 Hesekiah sì pa á láṣẹ láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ, bí ẹbọ sísun náà ti bẹ̀rẹ̀, orin sí Olúwa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú ohun èlò orin Dafidi ọba Israẹli. 28 Gbogbo ìjọ ènìyàn náà sì wólẹ̀ sìn, àwọn akọrin kọrin, àwọn afùnpè sì fọn ìpè, gbogbo wọ̀nyí sì wà bẹ́ẹ̀ títí ẹbọ sísun náà fi parí tán.

    29 Nígbà tí wọ́n sì ṣe ìparí ẹbọ rírú, ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tẹ ara wọn ba, wọ́n sì sìn. 30 Pẹ̀lúpẹ̀lú Hesekiah ọba, àti àwọn ìjòyè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi, láti fi ọ̀rọ̀ Dafidi àti ti Asafu aríran, kọrin ìyìn sí Olúwa: wọ́n sì fi inú dídùn kọrin ìyìn, wọ́n sì tẹrí wọn ba, wọ́n sì sìn.

  51. Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ.

    1 Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo;

    ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.

    2 Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa;

    jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.

    3 Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi;

    kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.

  52. 3 Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀

    jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.

  53. 20 Nígbà tí ẹ bá pàdé láti jẹun, kì í ṣe oúnjẹ alẹ́ Olúwa ni ẹ máa ń jẹ. 21 Ṣùgbọ́n tí ara yín, nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹun, olúkúlùkù yín a máa sáré jẹ oúnjẹ rẹ̀ láìdúró de ẹnìkejì rẹ̀. Ebi a sì máa pa wọ́n, ẹlòmíràn wọ́n sì ń mu àmuyó àti àmupara. 22 Ṣé ẹ̀yin kò ní ilé tí ẹ ti lè jẹ, tí ẹ sì ti lè mu ni? Tàbí ẹ̀yin ń gan ìjọ Ọlọ́run ni? Ẹ̀yin sì ń dójútì àwọn aláìní? Kín ni kí èmi ó wí fún un yín? Èmi yóò ha yìn yín nítorí èyí? A! Rárá o. Èmi kọ́, n kò ní yìn yín.

    23 Nítorí èyí tí èmi gbà lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti fi fún un yin. Ní alẹ́ ọjọ́ tí Judasi fihàn, Olúwa Jesu Kristi mú àkàrà. 24 Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àkàrà náà tan, ó bù ú, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ gbà kí ẹ sì jẹ, èyí ní ara mi tí a fi fún un yín. Ẹ máa ṣe eléyìí ni rántí mi.” 25  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó sì wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, ẹ máa ṣe èyí, nígbàkígbà ti ẹ̀yìn bá ń mu ú, ní ìrántí mi.” 26  Nítorí nígbàkígbà tí ẹ bá ń jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ǹ mu nínú ago yìí, ni ẹ tún sọ nípa ikú Olúwa. Ẹ máa ṣe eléyìí títí yóò fi padà dé.

    27 Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú ago Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa. 28 Ìdí nìyìí tí ó fi yẹ kí ènìyàn yẹ ara rẹ̀ wò dáradára kí ó tó jẹ lára àkàrà nà án àti kí ó tó mu nínú ago náà.

  54. 6 Mo sì rí angẹli mìíràn ń fò ní àárín méjì ọ̀run, pẹ̀lú ìyìnrere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn. 7 Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti Òkun, àti àwọn orísun omi!”

  55. 9 Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”

    10 Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jesu mú. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jesu ni ìsọtẹ́lẹ̀.”

  56. 9 Bí Mose ṣe wọ inú àgọ́ náà, ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀ yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì dúró sí ẹnu ọnà, nígbà tí Olúwa ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Mose. 10 Nígbàkígbà tí àwọn ènìyàn bá rí i ti ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀ bá dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, gbogbo wọn yóò dìde wọn yóò sì sìn, olúkúlùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ rẹ̀.

  57. 4  Gbọ́ ìwọ Israẹli, Olúwa Ọlọ́run wa, Olúwa kan ni. 5 Fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ. 6  Àwọn àṣẹ tí mo fún un yín lónìí gbọdọ̀ máa wà lóókan àyà yín. 7 Ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín gidigidi. Bí ẹ bá jókòó nínú ilé, ẹ jíròrò nípa wọn, àti nígbà tí ẹ bá ń rìn ní ojú ọ̀nà, bí ẹ bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí ẹ bá dìde. 8  Ẹ so wọ́n sí ọwọ́ yín fún àmì, ẹ so ó mọ́ iwájú orí yín. 9 Kí ìwọ kí ó kọ wọ́n sára òpó ilé rẹ̀, àti sí ara ìlẹ̀kùn ọ̀nà òde rẹ.

  58. 22  Ṣùgbọ́n Samuẹli dáhùn pé,

    “Olúwa ha ní inú dídùn sí ẹbọ sísun àti ẹbọ

    ju kí a gba ohùn Olúwa gbọ́?

    Ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ,

    ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ.

  59. Fún adarí orin. Ní ti ohun orin. “Ní ti ikú ọmọ.” Saamu ti Dafidi.

    1 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;

    èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo.

    2 Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ;

    èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.

  60. 11 Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi;

    ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,

    12 nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́.

    Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.

  61. 4 Nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run,

    sí Ọlọ́run ayọ̀ mi àti ìdùnnú mi,

    èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú dùùrù,

    ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.

  62. Ti Dafidi.

    1 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.

  63. 16  Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo. 17  Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo. 18  Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo nínú ipòkípò tí o wù kí ẹ wà; nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kristi Jesu nítòótọ́.

  64. 12 Nísinsin yìí ìwọ Israẹli, kín ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ọkàn àti àyà rẹ, 13 àti láti máa kíyèsi àṣẹ àti ìlànà Olúwa tí mo ń fún ọ lónìí, fún ìre ara à rẹ.

  65. 15 Nígbà tí Gideoni gbọ́ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ sin Ọlọ́run: lẹ́yìn náà ni ó padà sí ibùdó àwọn ọmọ Israẹli ó sì pè wọ́n pé, “Ẹ dìde! Nítorí pé Olúwa yóò lò yín láti ṣẹ́gun gbogbo ogun Midiani.”

  66. 11 Lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà jáde wá láti Ibi Mímọ́. Gbogbo àwọn àlùfáà tí ó wà níbẹ̀ ni ó ya ara wọn sí mímọ́ láìbìkítà fún ìpín wọn. 12 Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ akọrin: Asafu, Hemani, Jedutuni àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ẹbí wọn, wọ́n dúró ní igun ìlà-oòrùn pẹpẹ náà wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tuntun wọ́n ń lo kimbali, dùùrù àti ohun èlò orin olókùn. Ìwọ̀n ọgọ́fà àwọn àlùfáà tí wọ́n ń fun ìpè ni wọ́n tẹ̀lé wọn. 13  Àwọn afùnpè àti àwọn akọrin pa ohùn wọn pọ̀ sí ọ̀kan ṣoṣo, láti fi ìyìn àti ọpẹ́ fun Olúwa. Wọ́n fi ìpè, kimbali àti àwọn ohun èlò orin mìíràn mọ́ ọn, wọ́n gbé ohùn wọn sókè láti fi yin Olúwa, wọ́n ń kọrin pé,

    “Ó dára;

    ìfẹ́ rẹ̀ wà títí láéláé.”

    Nígbà náà ni ìkùùkuu ojú ọ̀run kún inú tẹmpili Olúwa, 14 tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn àlùfáà kò le è ṣiṣẹ́ ìsìn wọn nítorí ìkùùkuu náà, nítorí ògo Olúwa kún inú tẹmpili Ọlọ́run.

  67. 15 Nísinsin yìí, ojú mi yóò sì là etí mi yóò sì là, sí àdúrà ọrẹ níbí yìí. 16 Èmi sì ti yàn, èmi sì ti ya ilé yìí sí mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni kí orúkọ mi kí ó le wà níbẹ̀ títí láéláé.

  68. 5 Esra ṣí ìwé náà, gbogbo ènìyàn sì le rí í nítorí ó dúró níbi tí ó ga ju gbogbo ènìyàn lọ; bí ó sì ti ṣí ìwé náà, gbogbo ènìyàn dìde dúró. 6 Esra yin Olúwa, Ọlọ́run alágbára; gbogbo ènìyàn gbé ọwọ́ wọn sókè, wọ́n sì wí pé, “Àmín! Àmín!” Nígbà náà ni wọ́n wólẹ̀ wọ́n sì sin Olúwa ní ìdojúbolẹ̀.

  69. 25 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá;

    ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀

    26 tálákà yóò jẹ yóò sì yó;

    àwọn tí n wá Olúwa yóò yin

    jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé!

    27 Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí

    wọn yóò sì yípadà sí Olúwa,

    àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè

    ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀,

    28 nítorí ìjọba ni ti Olúwa.

    Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè.

  70. 3 Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ?

    Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?

    4  Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,

    ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán

    tí kò sì búra èké.

    5 Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa,

    àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.

    6 Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀,

    tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.

  71. 1  Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,

    jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

    2 Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;

    sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.

    3 Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀,

    jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.

    4 Wá Olúwa àti ipá rẹ̀;

    wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.

    5 Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,

    ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,

    6 ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀,

    ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.

  72. 1 Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run mi;

    èmi yóò gbé ọ ga èmi ó sì

    fi ìyìn fún orúkọ rẹ

    nítorí nínú òtítọ́ aláìlẹ́gbẹ́

    o ti ṣe ohun ńlá,

    àwọn ohun tí o ti gbèrò o rẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́.

  73. 6 Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ Olúwa

    láti sìn ín,

    láti fẹ́ orúkọ Olúwa

    àti láti foríbalẹ̀ fún un

    gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́

    àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin—

    7  àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi,

    èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi.

    Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn,

    ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi;

    nítorí a ó máa pe ilé mi ní

    ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”

  74. 28 Nígbà náà, ni Nebukadnessari sọ wí pé, “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ẹni tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, wọn kọ àṣẹ ọba, dípò èyí, wọ́n fi ara wọn lélẹ̀ ju kí wọn sìn tàbí foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọ́run wọn.

  75. 5 Ẹ̀yin pẹ̀lú, bí òkúta ààyè, ni a kọ́ ní ilé ẹ̀mí, àlùfáà mímọ́, láti máa rú ẹbọ ẹ̀mí, tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa Jesu Kristi.

  76. 10 Nígbà tí àwọn ọ̀mọ̀lé gbé ìpìlẹ̀ ilé Olúwa kalẹ̀, àwọn àlùfáà nínú aṣọ iṣẹ́ àlùfáà wọn pẹ̀lú fèrè, àti àwọn ará Lefi (àwọn ọmọ Asafu) pẹ̀lú símbálì, dúró ní ipò wọn láti yin Olúwa, bí Dafidi ọba Israẹli ti fi lélẹ̀. 11 Pẹ̀lú ìyìn àti ọpẹ́ ni wọ́n kọrin sí Olúwa:

    “Ó dára;

    ìfẹ́ rẹ̀ sí Israẹli dúró títí láé.”

    Gbogbo àwọn ènìyàn sì fi ohùn ariwo ńlá yin Olúwa, nítorí tí a ti fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀. 12 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ lára àwọn àgbà àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti àwọn olórí ìdílé, tí ó ti rí tẹmpili Olúwa ti tẹ́lẹ̀, wọ́n sọkún kíkorò nígbà tí wọ́n rí ìpìlẹ̀ tẹmpili Olúwa yìí tí wọ́n fi lélẹ̀, nígbà tí ọ̀pọ̀ kígbe fún ayọ̀. 13 Kò sí ẹni tí ó le mọ ìyàtọ̀ láàrín igbe ayọ̀ àti ẹkún, nítorí tí ariwo àwọn ènìyàn náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. Wọ́n sì gbọ́ igbe náà ní ọ̀nà jíjìn réré.

  77. 2 Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀

    èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ

    nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;

    nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.

  78. 21 “Mo kórìíra, mo kẹ́gàn àwọn àsè ẹ̀sìn in yín,

    Èmi kò sì ní inú dídùn sí àpéjọ yín.

    22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wá.

    Èmi kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n.

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú àṣàyàn ọrẹ àlàáfíà wá.

    Èmi kò ní náání wọn.

    23 Ẹ gbé ariwo orin yín sẹ́yìn!

    Èmi kò ní fetísí ohun èlò orin yín.

    24 Jẹ́ kí òtítọ́ sàn bí odò

    àti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ!

  79. 6 Kí ni èmi yóò ha mú wá síwájú Olúwa

    tí èmi ó fi tẹ ara mi ba níwájú Ọlọ́run gíga?

    Kí èmi ha wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun,

    pẹ̀lú ọmọ màlúù ọlọ́dún kan?

    7 Ǹjẹ́ Olúwa yóò ní inú dídùn sí ẹgbẹgbàarùn-ún àgbò,

    tàbí sí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìṣàn òróró?

    Èmi yóò ha fi àkọ́bí mi sílẹ̀ fún ìré-òfin-kọjá mi,

    èso inú ara mi fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi?

    8 Ó ti fihàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí ó dára,

    àti ohun tí Olúwa ń béèrè lọ́wọ́ rẹ?

    Bí kò ṣe láti ṣe òtítọ́, kí o sì fẹ́ràn àánú,

    àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.

  80. 16 Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì,

    ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà;

    ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ,

    ẹsẹ̀ mi sì wárìrì,

    mo dúró ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú

    láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá.

    17 Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná,

    tí èso kò sí nínú àjàrà;

    tí igi olifi ko le so,

    àwọn oko ko sì mú oúnjẹ wá;

    tí a sì ké agbo ẹran kúrò nínú agbo,

    tí kò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùso mọ́,

    18 síbẹ̀, èmi ó láyọ̀ nínú Olúwa,

    èmi yóò sí máa yọ nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.

  81. 18  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn. 19 Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn. 20  Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀, bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.

    21  Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn. 22 Níwọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá, 23  wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kì í díbàjẹ́ sí àwọn àwòrán ère bí i ti ènìyàn tí í díbàjẹ́ àti ti ẹyẹ, àti ti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti ti ẹranko afàyàfà.

    24 Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́. 25 Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé. Àmín.

  82. 26  Ǹjẹ́ èéha ti ṣe, kín ni àwa yóò sọ ẹ̀yin ará? Nígbà tí ẹ̀yin péjọpọ̀, tí olúkúlùkù yín ni Saamu kan tàbí ẹ̀kọ́ kan, èdè kan, ìfihàn kan àti ìtumọ̀ kan. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láti gbé ìjọ ró. 27 Bí ẹnìkan bá fi èdè fọ̀, kí ó jẹ ènìyàn méjì, tàbí bí ó pọ̀ tán, kí ó jẹ́ mẹ́ta, kí ó sọ̀rọ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí ẹnìkan sì túmọ̀ rẹ̀. 28 Ṣùgbọ́n bí kò bá sí ògbufọ̀, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ nínú ìjọ; sì jẹ́ kí ó máa bá ara rẹ̀ àti Ọlọ́run sọ̀rọ̀.

    29 Jẹ́ kí àwọn wòlíì méjì tàbí mẹ́ta sọ̀rọ̀, ki àwọn ìyókù sì wòye ìtumọ̀ ohun tí a sọ. 30 Bí a bá sì fi ohunkóhun hàn ẹni tí ó jókòó níbẹ̀, jẹ́ kí ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ ṣáájú dákẹ́. 31 Nítorí gbogbo yín lè sọtẹ́lẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo yín lè kọ́ ẹ̀kọ́, kí a lè tu gbogbo yín nínú. 32 Ẹ̀mí àwọn wòlíì a sí máa tẹríba fún àwọn wòlíì. 33 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run ohun rúdurùdu, ṣùgbọ́n ti àlàáfíà. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ nínú gbogbo ìjọ ènìyàn mímọ́.

    34  Jẹ́ ki àwọn obìnrin yín dákẹ́ nínú ìjọ, nítorí a kò fi fún wọn láti sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọn wà lábẹ́ ìtẹríba, gẹ́gẹ́ bí òfin pẹ̀lú ti wí. 35 Bí wọ́n bá sì fẹ́ mọ̀ nípa ohunkóhun, kí wọn béèrè lọ́wọ́ ọkọ wọn ní ilé; nítorí ohun ìtìjú ni fún àwọn obìnrin láti máa sọ̀rọ̀ nínú ìjọ.

    36 Kín ni? Ṣe lọ́dọ̀ yín ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jáde ni, tàbí ẹ̀yin nìkan ni o tọ̀ wá? 37 Bí ẹnikẹ́ni bá ró ará rẹ̀ pé òun jẹ́ wòlíì, tàbí òun jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, jẹ́ kí nǹkan wọ̀nyí ti mo kọ sí yin yé e dájú pé òfin Olúwa ni wọ́n. 38 Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá fi ojú fo èyí dá, òun fúnra rẹ̀ ní a ó fi ojú fò dá.

    39 Nítorí náà ará, ẹ máa fi ìtara ṣàfẹ́rí láti sọtẹ́lẹ̀, kí ẹ má sì ṣe dánilẹ́kun láti fi èdè fọ̀. 40 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo tẹ̀yẹtẹ̀yẹ àti lẹ́sẹẹsẹ.

  83. 25 Nítorí títóbi ni Olúwa òun sì ni ìyìn yẹ jùlọ;

    òun ni kí a bẹ̀rù ju gbogbo àwọn Ọlọ́run lọ.

  84. 3 Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni Ìwọ;

    ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó.

  85. Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora.

    1 Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn

    ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.

  86. 9 Èmi ó máa yìn ọ́, Olúwa, láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;

    èmi ó máa kọrin sí ọ láàrín àwọn ènìyàn.

  87. 4 Ẹ kọrin sí Ọlọ́run,

    ẹ kọrin ìyìn sí i,

    ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń rékọjá ní aginjù.

    Olúwa ni orúkọ rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀.

    5 Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé

    rẹ̀ mímọ́

  88. 8 Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi,

    ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.

  89. 1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

    Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,

    ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.

    2 Ẹ fi ìyìn fún un,

    gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀,

    ẹ fi ìyìn fún un,

    gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀.

    3 Ẹ fi ìyìn fún un,

    oòrùn àti òṣùpá.

    Ẹ fi ìyìn fún un,

    gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.

    4 Ẹ fi ìyìn fún un,

    ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga

    àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.

    5 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa

    nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn

  90. 37  Jesu dáhùn pé, “ ‘Fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ẹ̀mí rẹ àti gbogbo inú rẹ.’ 38 Èyí ni òfin àkọ́kọ́ àti èyí tí ó tóbi jùlọ. 39 Èkejì tí ó tún dàbí rẹ̀ ní pé, ‘Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’