25 Bible Verses About Fall

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Fall
  1. 12 Àwọn wọ̀nyí ní ó jẹ́ àbàwọ́n nínú àsè ìfẹ́ yín, nígbà tí wọ́n ń bá yín jẹ àsè, àwọn olùṣọ́-àgùntàn ti ń bọ́ ara wọn láìbẹ̀rù. Wọ́n jẹ́ ìkùùkuu láìrọ òjò, tí a ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ gbá kiri; àwọn igi aláìléso ní àkókò èso, wọ́n kú lẹ́ẹ̀méjì, a sì fà wọ́n tú tigbòǹgbò tigbòǹgbò. 13 Wọ́n jẹ́ ìjì líle ti ń ru ní ojú omi Òkun, ti ń hó ìfófó ìtìjú wọn jáde; alárìnkiri ìràwọ̀, àwọn tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè láéláé.

  2. 24 Wọn kò sọ fún ara wọn pé,

    ‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,

    ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀,

    tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédé.’

    25 Àìṣedéédéé yín mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí kúrò,

    ẹ̀ṣẹ̀ yín sì mú kí a fi nǹkan rere dù yín.

  3. 1 Àsìkò wà fún ohun gbogbo,

    àti ìgbà fún gbogbo nǹkan ní abẹ́ ọ̀run.

    2 Ìgbà láti bí àti ìgbà kíkú,

    ìgbà láti gbìn àti ìgbà láti fàtu.

  4. 5 Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ

    àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.

    6 Àwọn tí ń la àfonífojì omijé lọ

    wọn sọ ọ́ di kànga

    àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó.

  5. 13  Nítorí náà, bí ẹ bá gbọ́rọ̀ sí àṣẹ tí mo fún un yín lónìí tọkàntọkàn: tí ẹ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì sìn ín, pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn yín: 14 nígbà náà, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ ẹ yín lákòókò rẹ̀, àti òjò àkọ́rọ̀ àti ti àrọ̀kẹ́yìn, kí ẹ ba à lè kórè oúnjẹ yín wọlé àní wáìnì tuntun àti òróró. 15 Èmi yóò mú kí koríko hù lórí ilẹ̀ yín fún àwọn ohun ọ̀sìn in yín, ẹ ó sì jẹ, ẹ ó sì yó.

  6. 22 “Níwọ́n ìgbà tí ayé bá sì wà,

    ìgbà ọ̀gbìn àti ìgbà ìkórè

    ìgbà òtútù àti ìgbà ooru,

    ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òjò,

    ìgbà ọ̀sán àti ìgbà òru,

    yóò wà títí láé.”

  7. 1  “ ‘Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù keje, kí ẹ ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Ọjọ́ ìfùnpè ni ó jẹ́ fún yín.

  8. 19 Òṣùpá jẹ́ àmì fún àkókò

    oòrùn sì mọ ìgbà tí yóò wọ̀.

  9. 4 Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ,

    nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.

  10. 27 “Ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí ni ọjọ́ ètùtù. Ẹ ni ìpàdé àjọ mímọ́, kí ẹ sì ṣẹ́ ara yín kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa.

  11. 34 “Sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje ni kí àjọ̀dún ọdún àgọ́ ti Olúwa bẹ̀rẹ̀ kí ó sì wà títí di ọjọ́ méje.

  12. 7  “ ‘Ní ọjọ́ kẹwàá nínú oṣù keje, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́. Kí ẹ̀yin kí ó sẹ́ ara yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.

  13. 12  “ ‘Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Kí ẹ̀yin kí ó sì ṣe àjọyọ̀ fún Olúwa fún ọjọ́ méje.

  14. 7 Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadà wá Olúwa. Kíyèsi i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò. 8 Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fi ọkàn yín balẹ̀, nítorí ìpadà wá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀.

  15. 23 Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Sioni,

    ẹ sì yọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run yín,

    nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́,

    Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín,

    àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní.

  16. 37  Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni ìkórè pọ̀ ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan. 38 Nítorí náà, ẹ gbàdúrà sí Olúwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.”

  17. 9 Ẹ má sì jẹ́ kí àárẹ̀ ọkàn mú wa ní ṣíṣe rere, nítorí tí a ó kórè nígbà tí àkókò bá dé, bí a kò bá ṣe àárẹ̀.

  18. 14 Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, láti pààlà sí àárín ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún àmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún.

  19. 26 Èmi yóò bùkún wọn àti ibi agbègbè ti ó yí òkè mi ká. Èmi yóò rán ọ̀wààrà òjò ni àkókò; òjò ìbùkún yóò sì wà.

  20. 21  “Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ keje ìwọ yóò sinmi; kódà ní àkókò ìfúnrúgbìn àti ní àkókò ìkórè ìwọ gbọdọ̀ sinmi.

  21. 37 Ní ọdún kẹrin ni a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lé ilẹ̀, ní oṣù Sifi. 38 Ní ọdún kọkànlá ní oṣù Bulu, oṣù kẹjọ, a sì parí ilé náà jálẹ̀ jálẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìpín rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó yẹ. Ó sì lo ọdún méje ní kíkọ́ ilé náà.

  22. 9 Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá,

    àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká.

  23. 17 Ṣùgbọ́n kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní àìní ẹ̀rí, ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín lójò láti ọ̀run wá, àti ni àkókò èso, ó ń fi oúnjẹ àti ayọ̀ kún ọkàn yín.”

  24. 6 Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa.

    Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

  25. 5 Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ,

    ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.