78 Bible Verses About Stars

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Stars
  1. 1  Lẹ́yìn ìgbà tí a bí Jesu ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, ni àkókò ọba Herodu, àwọn amòye ti ìlà-oòrùn wá sí Jerusalẹmu. 2  Wọ́n si béèrè pé, “Níbo ni ẹni náà tí a bí tí í ṣe ọba àwọn Júù wà? Àwa ti rí ìràwọ̀ rẹ̀ ní ìlà-oòrùn, a sì wá láti foríbalẹ̀ fún un.”

    3 Nígbà tí ọba Herodu sì gbọ́ èyí, ìdààmú bá a àti gbogbo àwọn ara Jerusalẹmu pẹ̀lú rẹ̀. 4 Nígbà tí ó sì pe àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin jọ, ó bi wọ́n léèrè níbi ti a ó gbé bí Kristi? 5  Wọ́n sì wí pé, “Ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, èyí ni ohun tí wòlíì ti kọ ìwé rẹ̀ pé,

    6  “ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judea,

    ìwọ kò kéré jù láàrín àwọn ọmọ-aládé Juda;

    nítorí láti inú rẹ ni Baálẹ̀ kan yóò ti jáde,

    ẹni ti yóò ṣe ìtọ́jú Israẹli, àwọn ènìyàn mi.’ ”

    7 Nígbà náà ni Herodu ọba pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wádìí ni ọwọ́ wọn, àkókò náà gan an tí wọ́n kọ́kọ́ rí ìràwọ̀. 8 Ó sì rán wọn lọ sí Bẹtilẹhẹmu, ó sì wí pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí fínní fínní ní ti ọmọ náà tí a bí. Lẹ́yìn tí ẹ bá sì rí i, ẹ padà wá sọ fún mi, kí èmi náà le lọ foríbalẹ̀ fún un.”

    9 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, sì wò ó, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí láti ìhà ìlà-oòrùn wá, ó ṣáájú wọn, títí tí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ náà gbé wà. 10 Nígbà tí wọ́n sì rí ìràwọ̀ náà, ayọ̀ kún ọkàn wọn. 11  Bí wọ́n tí wọ inú ilé náà, wọn rí ọmọ ọwọ́ náà pẹ̀lú Maria ìyá rẹ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Nígbà náà ni wọ́n tú ìṣúra wọn, wọ́n sì ta Jesu lọ́rẹ: wúrà, tùràrí àti òjìá. 12  Nítorí pé Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún wọn ní ojú àlá pé kí wọ́n má ṣe padà tọ Herodu lọ mọ́, wọ́n gba ọ̀nà mìíràn lọ sí ìlú wọn.

  2. 14 Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, láti pààlà sí àárín ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún àmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún. 15 Kí wọn ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run láti tan ìmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 16 Ọlọ́run dá ìmọ́lẹ̀ ńlá ńlá méjì, ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbi láti ṣe àkóso ọ̀sán àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéré láti ṣe àkóso òru. Ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú. 17 Ọlọ́run sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ si orí ilẹ̀, 18 láti ṣàkóso ọ̀sán àti òru àti láti pààlà sí àárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. 19 Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kẹrin.

  3. 7 Ó pàṣẹ fún oòrùn kò sì le è ràn,

    kí ó sì dí ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ mọ́.

    8 Òun nìkan ṣoṣo ni ó ta ojú ọ̀run,

    ti ó sì ń rìn lórí ìgbì Òkun.

    9 Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Beari àti Orioni,

    Pleiadesi àti ìràwọ̀ púpọ̀ ti gúúsù.

    10 Ẹni tí ń ṣe ohun tí ó tóbi jù àwárí lọ,

    àní ohun ìyanu láìní iye.

  4. 16  Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; àti láti ẹnu rẹ̀ wá ni idà olójú méjì mímú ti jáde. Ojú rẹ̀ sì dàbí oòrùn tí ó ń fi agbára rẹ̀ hàn.

    17  Nígbà tí mo rí i, mo wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó ń wí fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn. 18 Èmi ni ẹni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì ti kú; sì kíyèsi i, èmi sì ń bẹ láààyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò òkú lọ́wọ́.

    19 “Kọ̀wé nítorí náà ohun tí ìwọ ti rí, àti ti ohun tí ń bẹ, àti ti ohun tí yóò hù lẹ́yìn èyí; 20 ohun ìjìnlẹ̀ tí ìràwọ̀ méje náà tí ìwọ rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, àti ọ̀pá wúrà fìtílà méje náà. Ìràwọ̀ méje ni àwọn angẹli ìjọ méje náà: àti ọ̀pá fìtílà méje náà ní àwọn ìjọ méje.

  5. 9 Kíyèsi i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀

    ọjọ́ búburú, pẹ̀lú ìbínú àti ìrunú gbígbóná—

    láti sọ ilẹ̀ náà dahoro,

    àti láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run.

    10  Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti ìkójọpọ̀ wọn

    kò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn.

    Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn yóò di òkùnkùn

    àti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn.

  6. 2 Ẹ fi ìyìn fún un,

    gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀,

    ẹ fi ìyìn fún un,

    gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀.

    3 Ẹ fi ìyìn fún un,

    oòrùn àti òṣùpá.

    Ẹ fi ìyìn fún un,

    gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.

    4 Ẹ fi ìyìn fún un,

    ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga

    àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.

    5 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa

    nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn

    6 Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé

    ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

  7. 3 Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn

    ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.

    4 Ó ka iye àwọn ìràwọ̀

    ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ.

    5 Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára

    òye rẹ̀ kò sì ní òpin.

  8. 3 Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ,

    iṣẹ́ ìka rẹ,

    òṣùpá àti ìràwọ̀,

    tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,

    4 kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀,

    àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?

    5 Ìwọ ṣe é ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju Ọlọ́run lọ,

    ìwọ sì dé e ní adé ògo àti ọlá.

  9. 3  Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé.

  10. 17 “Mo rí i, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìsinsin yìí.

    Mo kíyèsi, ṣùgbọ́n kò súnmọ́.

    Ìràwọ̀ kan yóò jáde láti ọ̀dọ̀ Jakọbu;

    yóò yọ jáde láti Israẹli.

    Yóò tẹ̀ fọ́ orí Moabu,

    yóò sì fọ́ agbárí gbogbo ọmọ Seti.

  11. 6  Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    7  Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    8 Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    9 Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  12. 1 Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Abramu wá lójú ìran pé,

    “Abramu má ṣe bẹ̀rù.

    Èmi ni ààbò rẹ,

    Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.”

    2 Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Elieseri ará Damasku ni yóò sì jogún mi,” 3 Abramu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ìwọ kò fún mi ní ọmọ, nítorí náà ẹrú nínú ilé mi sì ni yóò jẹ́ àrólé mi.”

    4  Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ ọ́ wá pé, “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnra rẹ̀ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.” 5  Olúwa sì mú Abramu jáde sí ìta ó sì wí fún un pé, “Gbé ojú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.”

    6  Abramu gba Olúwa gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.

  13. 16 “Èmi, Jesu, ni ó rán angẹli mi láti jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí fún yin ní tí àwọn ìjọ. Èmi ni gbòǹgbò àti irú-ọmọ Dafidi, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tí ń tàn.”

  14. 8 Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Pleiadesi àti Orioni

    ẹni tí ó sọ òru dúdú di òwúrọ̀

    tí ó sọ ọjọ́ dúdú di ìmọ́lẹ̀

    ẹni tí ó wọ́ omi Òkun jọ pọ̀

    tí ó sì rọ̀ wọ́n sí orí ilẹ̀

    Olúwa ni orúkọ rẹ̀,

    9 Ó fọ́n ìparun sí ìlú olódi

    tí ó sì sọ àwọn ibùgbé àwọn ọmọ-aládé di ahoro.

  15. 39 Gbogbo ẹran-ara kì í ṣe ẹran-ara kan náà, ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ènìyàn, ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ̀ ní ti ẹja, ọ̀tọ̀ sì ní tí ẹyẹ. 40 Ará ti òkè ọ̀run ń bẹ, ara ti ayé pẹ̀lú sì ń bẹ, ṣùgbọ́n ògo ti òkè ọ̀run ọ̀tọ̀, àti ògo ti ayé ọ̀tọ̀. 41 Ọ̀tọ̀ ni ògo ti oòrùn, ọ̀tọ̀ ni ògo ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ sì ni ògo ti ìràwọ̀; ìràwọ̀ ṣá yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ni ògo.

  16. 10  Angẹli kẹta sì fún ìpè tirẹ̀, ìràwọ̀ ńlá kan tí ń jó bí fìtílà sì bọ́ láti ọ̀run wá, ó sì bọ́ sórí ìdámẹ́ta àwọn odò ṣíṣàn, àti sórí àwọn orísun omi. 11 A sì ń pe orúkọ ìràwọ̀ náà ní Iwọ, ìdámẹ́ta àwọn omi sì di iwọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì tí ipa àwọn omi náà kú, nítorí tí a sọ wọn di kíkorò.

    12 Angẹli kẹrin sì fún ìpè tirẹ̀, a sì kọlu ìdámẹ́ta oòrùn, àti ìdámẹ́ta òṣùpá, àti ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀, ki ìdámẹ́ta wọn lè ṣókùnkùn, kí ọjọ́ má ṣe mọ́lẹ̀ fún ìdámẹ́ta rẹ̀, àti òru bákan náà.

  17. 15 Ẹ kíyèsára gidigidi, torí pé, ẹ kò rí ìrísí ohunkóhun ní ọjọ́ tí Olúwa bá yín sọ̀rọ̀ ní Horebu láti àárín iná wá. Torí náà ẹ ṣọ́ra yín gidigidi, 16 kí ẹ ma ba à ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe ère fún ara yín, àní ère lóríṣìíríṣìí yálà èyí tí ó ní ìrísí ọkùnrin tàbí tí obìnrin, 17 tàbí ti ẹranko orí ilẹ̀, tàbí ti ẹyẹ tí ń fò ní òfúrufú, 18 tàbí ti àwòrán onírúurú ẹ̀dá tí ń fà lórí ilẹ̀, tàbí ti ẹja nínú omi. 19 Bí ẹ bá wòkè tí ẹ rí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀: àwọn ohun tí a ṣe lọ́jọ̀ sójú ọ̀run, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ dé bi pé ẹ̀yin yóò foríbalẹ̀ fún wọn, àti láti máa sin ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín dá fún gbogbo orílẹ̀-èdè lábẹ́ ọ̀run. 20 Olúwa Ọlọ́run yín sì ti mú ẹ̀yin jáde kúrò nínú iná ìléru ńlá, àní ní Ejibiti, láti lè jẹ́ ènìyàn ìní i rẹ̀, bí ẹ̀yin ti jẹ́ báyìí.

  18. 1 Àmì ńlá kan sì hàn ni ọ̀run; obìnrin kan tí a fi oòrùn wọ̀ ní aṣọ, òṣùpá sì ń bẹ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, adé oníràwọ̀ méjìlá sì ń bẹ lórí rẹ̀. 2  Ó sì lóyún, ó sì kígbe ni ìrọbí, ó sì wà ni ìrora àti bímọ. 3  Àmì mìíràn sì hàn ní ọ̀run; sì kíyèsi i, dragoni pupa ńlá kan, tí ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá, àti adé méje ní orí rẹ̀. 4  Ìrù rẹ̀ sì wọ́ ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀ ní ojú ọ̀run, ó sì jù wọ́n sí ilẹ̀ ayé, dragoni náà sì dúró níwájú obìnrin náà tí ó fẹ́ bímọ, pé nígbà tí o bá bí i, kí òun lè pa ọmọ rẹ̀ jẹ.

  19. 42 Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run: òòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé:

    “ ‘Ẹ̀yin ha mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún mi

    ní ogójì ọdún ní ijù bí, ìwọ ilé Israẹli?

    43 Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gbà àgọ́ Moleki,

    àti ìràwọ̀ Refani òrìṣà yín,

    àwòrán tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ wọ́n.

    Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Babeli.’

  20. 26 Ẹni tí ó bá sì ṣẹ́gun, àti tí ó sì ṣe ìfẹ́ mi títí dé òpin, èmi ó fún un láṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè: 27 ‘Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn; gẹ́gẹ́ bí a ti ń fọ́ ohun èlò amọ̀kòkò ni a ó fọ́ wọn túútúú,’ gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú tí gbà àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Baba mi. 28 Èmi yóò sì fi ìràwọ̀ òwúrọ̀ fún un.

  21. 31 “Ìwọ ha le fi ọ̀já de àwọn ìràwọ̀ Pleiadesi dáradára?

    Tàbí ìwọ le tún di ìràwọ̀ Orioni?

    32 Ìwọ le mú àwọn àmì méjìlá ìràwọ̀ Masaroti jáde wá nígbà àkókò wọn?

    Tàbí ìwọ le ṣe amọ̀nà Beari pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀?

    33 Ǹjẹ́ ìwọ mọ ìlànà ọ̀run?

    Ìwọ le fi ìjọba Ọlọ́run lélẹ̀ lórí ayé?

  22. 26 Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wo àwọn ọ̀run.

    Ta ni ó dá àwọn wọ̀nyí?

    Ẹni tí ó mú àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ jáde wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan

    tí ó sì pè wọ́n ní orúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan.

    Nítorí agbára ńlá àti ipá rẹ̀,

    ọ̀kan ṣoṣo nínú wọn kò sọnù.

    27 Èéṣe tí o fi sọ, ìwọ Jakọbu?

    Àti tí o ṣàròyé, ìwọ Israẹli,

    “Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú Olúwa;

    ìṣe mi ni a kò kọbi ara sí láti ọwọ́ Ọlọ́run mi”?

    28 Ìwọ kò tí ì mọ̀?

    Ìwọ kò tí ì gbọ́?

    Olúwa òun ni Ọlọ́run ayérayé,

    Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé.

    Agara kì yóò da bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣàárẹ̀,

    àti òye rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdínwọ̀n rẹ̀.

    29 Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀

    ó sì fi kún agbára àwọn tí agara dá.

  23. 25  “Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wá

    ní ogójì ọdún ní aginjù ìwọ ilé Israẹli?

    26 Ẹ̀yin ti gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yín sókè,

    ibùgbé àwọn òrìṣà yín,

    àní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ,

    èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe.

    27 Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Damasku,”

    ni Olúwa wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára.

  24. Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

    1 Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run;

    àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

    2 Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́;

    wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.

    3 Kò sí ohùn tàbí èdè

    níbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn.

    4  Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayé,

    ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé.

    Ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.

    5 Tí ó dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá rẹ̀ wá,

    òun yọ bí alágbára ọkùnrin tí ó ń sáré ìje.

    6 Ìjáde lọ rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wá

    àti àyíká rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ rẹ̀;

    kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore rẹ̀.

  25. 12 Báwo ni ìwọ ṣe ṣubú lulẹ̀ láti ọ̀run wá,

    ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà!

    A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayé,

    ìwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba rí!

    13 Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé,

    “Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run;

    èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókè

    ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run,

    Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpéjọ

    ní ṣóńṣó orí òkè mímọ́.

  26. 13 Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà ni

    ó ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀!

    Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú,

    àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀

    láti oṣù dé oṣù,

    jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ.

    14 Lóòótọ́ wọ́n dàbí ìṣẹ́pẹ́ igi;

    iná ni yóò jó wọn dànù.

    Wọn kò kúkú lè gba ara wọn là

    lọ́wọ́ agbára iná náà.

    Kò sí èédú láti mú ara ẹnikẹ́ni gbóná

    níhìn-ín kò sí iná tí ènìyàn le jókòó tì.

    15 Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún ọ nìyìí

    gbogbo èyí ní o tí ṣíṣẹ́ pẹ̀lú u rẹ̀

    tí o sì ti ń rù kiri láti ìgbà èwe.

    Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń lọ nínú àṣìṣe rẹ̀;

    kò sí ẹyọ ẹnìkan tí ó lè gbà ọ́.

  27. 4 “Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀?

    Wí bí ìwọ bá mòye.

    5 Ta ni ó fi ìwọ̀n rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọ bá mọ̀ ọ́n?

    Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ?

    6 Lórí ibo ni a gbé kan ìpìlẹ̀ rẹ̀ mọ́,

    tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀,

    7 nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀,

    tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run hó ìhó ayọ̀?

  28. 8 Bákan náà ni àwọn wọ̀nyí ń sọ ara wọn di èérí nínú àlá wọn, wọ́n ń gan ìjòyè, wọn sì ń sọ̀rọ̀ búburú sí àwọn ọlọ́lá. 9  Ṣùgbọ́n Mikaeli, olórí àwọn angẹli, nígbà tí ó ń bá Èṣù jiyàn nítorí òkú Mose, kò sọ ọ̀rọ̀-òdì sí i; ṣùgbọ́n ó wí pé, “Olúwa bá ọ wí.” 10 Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí n sọ̀rọ̀-òdì sí ohun gbogbo ti kò yé wọn: ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí wọn mọ̀ nípa èrò ara ni, bí ẹranko tí kò ní ìyè, nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n di ẹni ìparun.

    11  Ègbé ni fún wọn! Nítorí tí wọ́n ti rìn ní ọ̀nà Kaini, wọ́n sì fi ìwọra súré sínú ìṣìnà Balaamu nítorí ère, wọn ṣègbé nínú ìṣọ̀tẹ̀ Kora.

    12 Àwọn wọ̀nyí ní ó jẹ́ àbàwọ́n nínú àsè ìfẹ́ yín, nígbà tí wọ́n ń bá yín jẹ àsè, àwọn olùṣọ́-àgùntàn ti ń bọ́ ara wọn láìbẹ̀rù. Wọ́n jẹ́ ìkùùkuu láìrọ òjò, tí a ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ gbá kiri; àwọn igi aláìléso ní àkókò èso, wọ́n kú lẹ́ẹ̀méjì, a sì fà wọ́n tú tigbòǹgbò tigbòǹgbò. 13 Wọ́n jẹ́ ìjì líle ti ń ru ní ojú omi Òkun, ti ń hó ìfófó ìtìjú wọn jáde; alárìnkiri ìràwọ̀, àwọn tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè láéláé.

  29. 7 Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run dé

    àwọn ìràwọ̀ wọn yóò sì ṣókùnkùn;

    èmi yóò sì fi ìkùùkuu bo oòrùn

    òṣùpá kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

    8 Gbogbo ìmọ́lẹ̀ títàn ní ojú ọ̀run

    ni èmi yóò mú ṣókùnkùn lórí rẹ;

    èmi yóò mú òkùnkùn wá sórí ilẹ̀ rẹ,

    ni Olúwa Olódùmarè wí.

  30. 29 “Lójúkan náà, lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,

    “ ‘ni oòrùn yóò ṣókùnkùn,

    òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn;

    àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò já sílẹ̀,

    agbára ojú ọ̀run ni a ó mì tìtì.’

    30 “Nígbà náà ni àmì Ọmọ Ènìyàn yóò sì fi ara hàn ní ọ̀run, nígbà náà ni gbogbo ẹ̀yà ayé yóò káàánú, wọn yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa ti ojú ọ̀run bọ̀ ti òun ti ògo àti agbára ńlá.

  31. 10  Ayé yóò mì níwájú wọn;

    àwọn ọ̀run yóò wárìrì;

    oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn,

    àwọn ìràwọ̀ yóò sì fà ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn.

    11 Olúwa yóò sì bú ramúramù

    jáde níwájú ogun rẹ̀:

    nítorí ibùdó rẹ̀ tóbi gidigidi;

    nítorí alágbára ní òun, tí n mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;

    nítorí ọjọ́ Olúwa tóbi ó sì ní ẹ̀rù gidigidi;

    ara ta ni ó lè gbà á?

  32. 24 “Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ wọ̀nyí lẹ́yìn ìpọ́njú tí mo sọ yìí,

    “ ‘oòrùn yóò ṣókùnkùn,

    òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

    25 Àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú yóò já lulẹ̀ láti ojú ọ̀run,

    àti agbára tí ń bẹ ní ọ̀run ni a ó sì mì tìtì.’

    26 “Nígbà náà ni gbogbo ayé yóò sì rí i tí èmi Ọmọ Ènìyàn yóò máa bọ̀ wá láti inú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. 27 Nígbà náà ni yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ láti kó àwọn àyànfẹ́ ní gbogbo ayé jọ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé láti ìkangun ayé títí dé ìkangun ọ̀run.

  33. 19 Àwa sì ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì dunjúdunjú sí i, èyí tí ó yẹ kí ẹ kíyèsi gẹ́gẹ́ bí fìtílà tó ń mọ́lẹ̀ níbi tí òkùnkùn gbé wà, títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóò sì yọ lọ́kàn yín. 20 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kí ẹ ní òye yìí pé kò sí àsọtẹ́lẹ̀ ìwé mímọ́ kankan tí ó wáyé nípa ìtumọ̀ wòlíì fún rara rẹ̀. 21 Nítorí àsọtẹ́lẹ̀ kan kò ti ipá ìfẹ́ ènìyàn wá rí; ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí a ti ń darí wọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá.

  34. 4  Ọba sì pàṣẹ fún Hilkiah olórí àlùfáà àti àwọn, àlùfáà tí ó tẹ̀lé e ní ipò àti àwọn olùṣọ́nà láti yọ kúrò nínú ilé Olúwa gbogbo ohun èlò tí a ṣe fún Baali àti Aṣerah àti gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run. Ó sì sun wọ́n ní ìta Jerusalẹmu ní pápá àfonífojì Kidironi. Ó sì kó eérú wọn jọ sí Beteli. 5 Ó sì kúrò pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà tí a yàn láti ọwọ́ ọba Juda láti sun tùràrí ní ibi gíga ti ìlú Juda àti àwọn tí ó yí Jerusalẹmu ká. Àwọn tí ó ń sun tùràrí sí Baali, sí oòrùn àti òṣùpá, sí àwọn àmì ìràwọ̀ àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run.

  35. 12  Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹfà mo sì rí i, sì kíyèsi i, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá kan ṣẹ̀; oòrùn sì dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀ onírun, òṣùpá sì dàbí ẹ̀jẹ̀; 13  àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run sì ṣubú sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń rẹ̀ àìgbó èso rẹ̀ dànù, nígbà tí ẹ̀fúùfù ńlá bá mì í. 14 A sì ká ọ̀run kúrò bí ìwé tí a ká, àti olúkúlùkù òkè àti erékùṣù ní a sì ṣí kúrò ní ipò wọn.

  36. 15 Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn,

    àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́.

  37. 10 “Nígbà náà ni ìwọ yóò fọ́ ìkòkò náà ní ojú àwọn tí ó bá ọ lọ. 11 Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Èmi a fọ́ orílẹ̀-èdè yìí àti ìlú yìí gẹ́gẹ́ bí ìkòkò amọ̀ yìí ṣe fọ́ tí kò sì ní sí àtúnṣe. Wọn a sì sin àwọn òkú sí Tofeti títí tí kò fi ní sí ààyè mọ́. 12 Èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí ibí yìí àti àwọn tí ń gbé ní ibí yìí ni Olúwa wí. Èmi yóò mú ìlú yìí dàbí Tofeti. 13  Àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu àti ti ọba ìlú Juda ni a ó sọ di àìmọ́ bí Tofeti, gbogbo ilé tí wọ́n ti ń sun tùràrí ni orí òrùlé sí gbogbo ogun ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ mímu sí ọlọ́run mìíràn.’ ”

  38. 35 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

    ẹni tí ó mú oòrùn

    tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán,

    tí ó mú òṣùpá àti ìràwọ̀

    ràn ní òru;

    tí ó rú omi Òkun sókè

    tó bẹ́ẹ̀ tí ìjì rẹ̀ fi ń hó

    Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

    36 “Àyàfi tí ìlànà yìí bá kúrò níwájú mi,”

    ni Olúwa wí.

    “Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Israẹli yóò dẹ́kun

    láti jẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú mi láéláé.”

    37 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

    “Àyàfi tí a bá lé àwọn ọ̀run lókè

    tí ìpìlẹ̀ ayé sì di àwárí ní ìsàlẹ̀,

    ni èmi yóò kọ àwọn Israẹli

    nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe,”

    ni Olúwa wí.

  39. 5 Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;

    ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa.

    6 Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run,

    àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀.

    7 Ó kó àwọn omi òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò;

    ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo.

    8 Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa:

    jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀.

  40. 1  Súnmọ́ tòsí,

    ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti gbọ́,

    tẹ́tí sílẹ̀ ẹ̀yin ènìyàn

    jẹ́ kí ayé gbọ́,

    àti ẹ̀kún rẹ̀,

    ayé àti ohun gbogbo tí ó ti inú rẹ̀ jáde.

    2 Nítorí ìbínú Olúwa ń bẹ

    lára gbogbo orílẹ̀-èdè,

    àti ìrunú rẹ̀ lórí gbogbo ogun wọn:

    o ti fi wọ́n fún pípa.

    3 Àwọn ti a pa nínú wọn

    ni a ó sì jù sóde,

    òórùn wọn yóò ti inú òkú wọn jáde,

    àwọn òkè ńlá yóò sì yọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ wọn.

    4  Gbogbo àwọn ogun ọ̀run ni yóò di yíyọ́,

    a ó sì ká àwọn ọ̀run jọ bí i tákàdá,

    gbogbo ogun wọn yóò si ṣubú lulẹ̀,

    bí ewé ti n bọ́ kúrò lára àjàrà,

    àti bí i bíbọ́ èso lára igi ọ̀pọ̀tọ́.

  41. 16 Wọ́n kọ̀ gbogbo òfin Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọ́n sì ṣe òrìṣà méjì fún ara wọn, wọ́n sì gbẹ́ ẹ ọ̀kan ní ère ẹgbọrọ màlúù, àti ọ̀kan ní ère òrìṣà Aṣerah. Wọ́n sì tẹrí wọn ba sí gbogbo ogun ọ̀run, wọ́n sì sin Baali. 17 Wọ́n sì fi àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn rú ẹbọ nínú iná. Wọ́n sì ń fọ àfọ̀ṣẹ, wọ́n sì ń ṣe àlúpàyídà wọ́n sì ta ara wọn láti ṣe ohun búburú níwájú Olúwa, wọ́n sì mú un bínú.

    18 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì bínú gidigidi pẹ̀lú Israẹli ó sì mú wọn kúrò níwájú rẹ̀. Ẹ̀yà Juda nìkan ṣoṣo ni ó kù, 19 àti pẹ̀lú, Juda kò pa òfin Olúwa Ọlọ́run wọn mọ́. Wọ́n tẹ̀lé ìhùwàsí àwọn Israẹli tí wọ́n ṣe. 20 Nítorí náà Olúwa kọ gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli; ó sì jẹ wọ́n ní yà. Ó sì fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn olè títí tí ó fi ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀.

  42. 1 “ ‘Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, wọn yóò mú egungun àwọn ọba Juda àti egungun àwọn ìjòyè, egungun àwọn àlùfáà àti egungun àwọn wòlíì àti egungun àwọn olùgbé Jerusalẹmu kúrò nínú ibojì. 2 A ó yọ wọ́n síta fún oòrùn àti òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tí wọ́n ti fẹ́ràn tí wọ́n sì ti sìn, àti àwọn tí wọ́n ti tọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì ti foríbalẹ̀ fún. Kì yóò ṣà wọ́n jọ tàbí sìn wọ́n, wọn yóò dàbí ìdọ̀tí tó wà lórí ilẹ̀. 3 Níbikíbi tí mo bá lé wọn lọ, gbogbo àwọn ìyókù wọn yóò fẹ́ ikú ju ìyè lọ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.’

  43. 10  Ó sì dàgbà títí ó fi kan ẹgbẹ́ ogun ọ̀run, ó sì jù lára àwọn ẹgbẹ́ ogun ọ̀run sí ayé ó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀,

  44. 15 Angẹli Olúwa sì tún pe Abrahamu láti ọ̀run wá lẹ́ẹ̀kejì. 16  Ó sì wí pé, Olúwa wí pé, “Mo fi ara mi búra, níwọ̀n bí ìwọ ti ṣe èyí, tí ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí, 17  nítòótọ́, ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí iyanrìn etí Òkun. Irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀tá wọn, 18  àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nítorí tí ìwọ gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu.”

  45. 1 Nígbà náà ní Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn wí pé,

    2 “Ìjọba àti ẹ̀rù ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀,

    òun ní i ṣe ìlàjà ní ibi gíga gíga ọ̀run.

    3 Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí,

    tàbí ara ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí?

    4 Èéha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run?

    Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́?

    5 Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀,

    àní àwọn ìràwọ̀ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀,

    6 kí a má sọ ènìyàn tí i ṣe ìdin,

    àti ọmọ ènìyàn tí í ṣe kòkòrò!”

  46. 4 “Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Juda

    àti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu.

    Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín yìí ìyókù àwọn Baali, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣà

    pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà,

    5 àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ lórí òrùlé,

    àwọn tí ń sin ogun ọ̀run,

    àwọn tó ń foríbalẹ̀, tí wọ́n sì ń fi Olúwa búra,

    tí wọ́n sì ń fi Moleki búra.

    6 Àwọn tí ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa;

    àti àwọn tí kò tí wá Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀.”

  47. 12 Nítorí náà ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ń gbọ́rọ̀ nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà ti mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n pàápàá nísinsin yìí tí èmi kò sí ni àárín yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì, 13  nítorí pé Ọlọ́run ni ó n ṣiṣẹ́ nínú yín, láti fẹ́ àti láti ṣiṣẹ́ fún ète rere rẹ̀.

    14 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú àti ìjiyàn. 15  Kí ẹ̀yin lè jẹ́ aláìlẹ́gàn àti oníwà mímọ́, ọmọ Ọlọ́run, aláìlábàwọ́n, láàrín oníwà wíwọ́ àti alárékérekè orílẹ̀-èdè láàrín àwọn ẹni tí a ń rí yín bí ìmọ́lẹ̀ ní ayé. 16 Bí ẹ sì ṣe di ọ̀rọ̀ ìyè mú gírígírí, kí èmi lè ṣògo ni ọjọ́ Kristi pé èmi kò sáré lásán, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ṣe làálàá lásán.

  48. 22  Àádọ́rin péré ni àwọn baba ńlá a yín tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run yín ti mú un yín pọ̀ sí i ní iye bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run.

  49. 2  Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó ń gbé láàrín yín ní èyíkéyìí ìlú wọ̀n-ọn-nì, tí Olúwa fún un yín bá ń ṣe ibi ní ojú Olúwa Ọlọ́run yín, ní ríré májẹ̀mú rẹ̀ kọjá, 3 èyí tí ó lòdì sí òfin mi, ó ń sin ọlọ́run mìíràn, ó ń foríbalẹ̀ fún wọn: àní sí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, 4 tí èyí sì dé etí ìgbọ́ ọ yín, kí ẹ wádìí ọ̀rọ̀ náà dájúdájú. Bí ó bá jẹ́ òtítọ́ tí ó sì hàn gbangba pé ó ti ṣe ohun ìríra yìí, ní Israẹli. 5 Ẹ mú ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó ti ṣe ibi yìí wá sí ẹnu-ọ̀nà ibodè ìlú u yín, kí ẹ sọ ọ́ ní òkúta pa. 6  Lénu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó pa ọkùnrin náà tí ó yẹ láti kú, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe pànìyàn nípasẹ̀ ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo. 7  Àwọn ẹlẹ́rìí ni kí ó kọ́kọ́ gbọ́wọ́ lé e láti pa á. Lẹ́yìn èyí ni kí gbogbo ènìyàn dáwọ́jọ láti pa á. Nípa báyìí, ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní àárín yín.

  50. 1  Manase jẹ́ ẹni ọdún méjìlá nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún márùndínlọ́gọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Hẹfisiba. 2 Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, ó sì tẹ̀lé iṣẹ́ ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli. 3 Ó sì tún ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekiah tí ó parun kọ́. Ó sì tún gbé pẹpẹ Baali dìde, ó sì ṣe ère òrìṣà Aṣerah, gẹ́gẹ́ bí Ahabu ọba Israẹli ti ṣe. Ó sì tẹríba sí gbogbo ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n. 4 Ó sì kọ́ pẹpẹ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ní Jerusalẹmu ni èmi yóò kọ orúkọ mi sí.” 5 Ní àgbàlá méjèèjì ilé Olúwa, ó sì kọ́ pẹpẹ fún gbogbo àwọn ìrúbọ nínú ilé, ṣe iṣẹ́ àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì béèrè lọ́wọ́ àwọn òkú àti àwọn oṣó. Ó sì ṣe ọ̀pọ̀ búburú ní ojú Olúwa, ó sì mú un bínú. 6 Ó fi àwọn ọmọ ara rẹ̀ rú ẹbọ nínú iná, ó ń ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì ń lo àlúpàyídà, ó sì ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó ṣe ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú Olúwa láti mú un bínú.

  51. 23 Dafidi kò kọ iye àwọn ọkùnrin náà ní ogún ọdún sẹ́yìn tàbí dín nítorí Olúwa ti ṣe ìlérí láti ṣe Israẹli gẹ́gẹ́ bí iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run.

  52. 6 Ìwọ nìkan ni Olúwa. Ìwọ ni ó dá ọ̀run, àní àwọn ọ̀run tí ó ga jù pẹ̀lú gbogbo ogun wọn, ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀. Ìwọ sì pa gbogbo wọn mọ́ láàyè, ogun ọ̀run sì ń sìn ọ́.

  53. 8  Nípa ìgbàgbọ́ ní Abrahamu, nígbà tí a ti pé e láti jáde lọ sí ibi tí òun yóò gbà fún ilẹ̀ ìní, ó gbọ́, ó sì jáde lọ, láì mọ ibi tí òun ń rè. 9 Nípa ìgbàgbọ́ ní o ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí, bí ẹni pé ni ilẹ̀ àjèjì, o ń gbé inú àgọ́, pẹ̀lú Isaaki àti Jakọbu, àwọn ajogún ìlérí kan náà pẹ̀lú rẹ̀, 10 nítorí tí ó ń retí ìlú tí ó ní ìpìlẹ̀; èyí tí Ọlọ́run tẹ̀dó tí ó sì kọ́. 11  Nípa ìgbàgbọ́ ni Sara tìkára rẹ̀ pẹ̀lú fi gba agbára láti lóyún, nígbà tí ó kọjá ìgbà rẹ̀, nítorí tí o ka ẹni tí o ṣe ìlérí sí olóòótọ́. 12  Nítorí náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe ti ara ọkùnrin kan jáde, àní ara ẹni tí o dàbí òkú, ọmọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ́pọ̀lọ́pọ̀, àti bí iyanrìn etí Òkun láìníye.

  54. 9 O sì tún lá àlá mìíràn, ó sì tún sọ ọ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó wí pé, ẹ tẹ́tí sí mi, “Mo tún lá àlá mìíràn, wò ó, oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá ń foríbalẹ̀ fún mi.”

    10 Nígbà tí ó sọ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú, baba rẹ̀ bá a wí pé, “Irú àlá wo ni ìwọ lá yìí? Ṣé ìyá rẹ, pẹ̀lú èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ yóò wá foríbalẹ̀ níwájú rẹ ni?”

  55. 1 Angẹli karùn-ún sì fún ìpè tirẹ̀, mo sì rí, ìràwọ̀ kan bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run wá, a sì fi kọ́kọ́rọ́ ihò ọ̀gbun fún un.

  56. 11 “Ohun tí Olúwa wí nìyìí,

    Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀.

    Nípa ohun tí ó ń bọ̀,

    ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi,

    tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí?

    12 Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé

    tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀.

    Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run;

    mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta.

  57. 1 “Sí angẹli ìjọ ní Efesu kọ̀wé:

    Nǹkan wọ̀nyí ní ẹni tí ó mú ìràwọ̀ méje náà ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ wí, ẹni tí ń rìn ní àárín ọ̀pá wúrà fìtílà méje.

    2 Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti làálàá rẹ, àti ìfaradà rẹ, àti bí ara rẹ kò ti gba àwọn ẹni búburú, àti bí ìwọ sì ti dán àwọn tí ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọ́n kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ wo, tí ìwọ sì rí pé èké ni wọ́n, 3 tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọ́jú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ.

    4 Síbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹ sílẹ̀. 5 Rántí ibi tí ìwọ ti gbé ṣubú! Ronúpìwàdà, kí ó sì ṣe iṣẹ́ ìṣáájú; bí kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó sì tọ̀ ọ́ wá, èmi ó sì ṣí ọ̀pá fìtílà rẹ̀ kúrò ní ipò rẹ̀, bí kò ṣe bí ìwọ bá ronúpìwàdà. 6 Ṣùgbọ́n èyí ni ìwọ ní, pé ìwọ kórìíra ìṣe àwọn Nikolatani, èyí tí èmi pẹ̀lú sì kórìíra.

    7 Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi èso igi ìyè nì fún jẹ, tí ń bẹ láàrín Paradise Ọlọ́run.

  58. 21 Bẹ́ẹ̀ ni àwa ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àwọn ìdajì ènìyàn tí ó di ọ̀kọ̀ mú, láti òwúrọ̀ kùtùkùtù títí di ìgbà tí ìràwọ̀ yóò fi yọ. 22 Ní ìgbà náà mo tún sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn àti olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ dúró ní Jerusalẹmu ní òru, nítorí kí wọn le jẹ́ ẹ̀ṣọ́ fún wa ní òru, kí wọn sì le ṣe iṣẹ́ ní ọ̀sán.” 23 Bẹ́ẹ̀ ni èmi àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn ènìyàn mi àti àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó wà pẹ̀lú mi kò bọ́ aṣọ wa, olúkúlùkù wa ní ohun ìjà tirẹ̀, kódà nígbà tí wọ́n bá ń lọ pọn omi.

  59. 9 Kí ìràwọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ rẹ̀ kí ó ṣókùnkùn;

    kí ó má wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó máa mọ́ sí i,

    bẹ́ẹ̀ ni kí ó má ṣe rí àfẹ̀mọ́júmọ́

  60. 12 “Ọlọ́run kò ha jẹ́ ẹni gíga ọ̀run?

    Sá wo orí àwọn ìràwọ̀ bí wọ́n ti ga tó!

  61. 22 Èmi ó mú àwọn ọmọ lẹ́yìn Dafidi ìránṣẹ́ mi àti Lefi tí ó jẹ́ oníwàásù níwájú mi di bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí kò ṣe é kà àti bí iyẹ̀pẹ̀ ojú Òkun tí kò ṣe é wọ́n.’ ”

  62. 25 “Àmì yóò sì wà ní oorun, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀; àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpayà híhó Òkun àti ìgbì omi. 26 Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì. 27  Nígbà náà ni wọn ó sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.

  63. 20 Nígbà tí oòrùn àti ìràwọ̀ kò si hàn lọ́jọ́ púpọ̀, tí ìjì náà kò sì mọ níwọ̀n fún wa, àbá àti là kò sí fún wa mọ́.

  64. 4 Èmi yóò sọ ìran rẹ di púpọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, èmi yóò sì fi gbogbo ilẹ̀ yìí fún irú àwọn ọmọ rẹ, àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé,

  65. 1 Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ

    ní ọjọ́ èwe rẹ,

    nígbà tí ọjọ́ ibi kò tí ì dé

    àti tí ọdún kò tí ì ní súnmọ́ etílé, nígbà tí ìwọ yóò wí pé,

    “Èmi kò ní ìdùnnú nínú wọn,”

    2 kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀

    àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn,

    àti kí àwọsánmọ̀ tó padà lẹ́yìn òjò;

    3 nígbà tí olùṣọ́ ilé yóò wárìrì

    tí àwọn ọkùnrin alágbára yóò tẹríba,

    nígbà tí àwọn tí ó ń lọ dákẹ́ nítorí pé wọn kò pọ̀,

    tí àwọn tí ń wo òde láti ojú fèrèsé yóò ṣókùnkùn;

    4 nígbà tí ìlẹ̀kùn sí ìgboro yóò tì

    tí ariwo ọlọ yóò dákẹ́;

    nígbà tí àwọn ènìyàn yóò dìde sí ariwo àwọn ẹyẹ

    ṣùgbọ́n gbogbo orin wọn yóò máa lọ ilẹ̀.

    5 Nígbà tí ènìyàn yóò bẹ̀rù ibi gíga

    àti ti ìfarapa ní ìgboro;

    nígbà tí igi almondi yóò tanná

    àti tí ẹlẹ́ǹgà yóò wọ́ ara rẹ̀ lọ

    tí ìfẹ́ kò sì ní ru sókè mọ́

    nígbà náà ni ènìyàn yóò lọ ilé rẹ́ ayérayé

    tí àwọn aṣọ̀fọ̀ yóò máa rìn kiri ìgboro.

    6 Rántí rẹ̀ kí okùn fàdákà tó já,

    tàbí kí ọpọ́n wúrà tó fọ́;

    kí iṣà tó fọ́ níbi ìsun,

    tàbí kí àyíká kẹ̀kẹ́ kí ó tó kán níbi kànga.

    7 Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà,

    tí ẹ̀mí yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni.

    8 “Asán! Asán!” ni Oniwaasu wí.

    “Gbogbo rẹ̀ asán ni!”

  66. 13 Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, ẹni tí ìwọ búra fún fúnra rẹ̀, ‘Tí o wí fún wọn pé, Èmi yóò mú irú-ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, Èmi yóò sì fún irú-ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé.’ ”

  67. 1 “Àti sí angẹli ìjọ ni Sardi kọ̀wé:

    Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ni Ẹ̀mí méje Ọlọ́run, àti ìràwọ̀ méje wí pé.

    Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀, àti pé ìwọ ní orúkọ pé ìwọ ń bẹ láààyè, ṣùgbọ́n ìwọ ti kú.

  68. 10 Olúwa Ọlọ́run yín ti sọ yín di púpọ̀ lónìí, ẹ̀yin sì ti pọ̀ bí ìràwọ̀ ní ojú ọ̀run.

  69. 1  Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé.

  70. 16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;

    ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá.

  71. 19 Òṣùpá jẹ́ àmì fún àkókò

    oòrùn sì mọ ìgbà tí yóò wọ̀.

  72. 16 Ó mú mi wá sí ibi àgbàlá ilé Olúwa, ní ẹnu-ọ̀nà tẹmpili Olúwa, láàrín ìloro àti pẹpẹ, ni ìwọ̀n ọkùnrin mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25) wà, tí wọ́n kẹ́yìn sí tẹmpili Olúwa tí wọn sì kọjú sí ìlà-oòrùn, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún oòrùn ní apá ìlà-oòrùn.

    17 Ó sì wí fún mi, “Ṣé ìwọ ti rí èyí ọmọ ènìyàn? Ǹjẹ́ ohun kékeré ni fún ilé Juda láti ṣe àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe níbi yìí? Ṣé o tún yẹ kí wọ́n fi ìwà ipá kún ilẹ̀ kí wọn sì máa mú mi bínú ní gbogbo ìgbà? Wò wọn bi wọn ṣe n fi ẹ̀ka wọn sínú inú wọn. 18 Nítorí náà, èmi yóò fi ìbínú bá wọn wí; èmi kò ní i dá wọn sí bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ní fojú àánú wò wọ́n. Bí wọ́n tilẹ̀ ń pariwo sí mi létí, èmi kò ní fetí sí wọn.”

  73. 3  Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà. 4 Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn. 5 Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “ọ̀sán,” àti òkùnkùn ní “òru.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní.

  74. 1  Báyìí ni Ọlọ́run parí dídá àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.

    2  Ní ọjọ́ keje Ọlọ́run sì parí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ń ṣe; ó sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo tí ó ti ń ṣe. 3 Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe.

  75. 26 bí mo bá bojú wo oòrùn nígbà tí ń ràn,

    tàbí òṣùpá tí ń ràn nínú ìtànmọ́lẹ̀,

    27 bí a bá tàn ọkàn mi jẹ

    láti fi ẹnu mi kò ọwọ́ mi,

    28 èyí pẹ̀lú ni ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn onídàájọ́ ní láti bẹ̀wò,

    nítorí pé èmí yóò jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run tí ó wà lókè.

  76. 5 Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, Olúwa,

    òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.

  77. 31  A á sọ oòrùn di òkùnkùn,

    àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀,

    kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ẹ̀rù Olúwa tó dé.

  78. 1  Ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ni Ọ̀rọ̀ náà. 2 Òun ni ó sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní àtètèkọ́ṣe. 3  Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo; lẹ́yìn rẹ̀ a kò sì dá ohun kan nínú ohun tí a ti dá.