22 Bible Verses About Spring
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
-
10 Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé,
“Dìde, Olólùfẹ́ mi,
arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi.
11 Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá;
òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ.
12 Àwọn òdòdó fi ara hàn lórí ilẹ̀
àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé
a sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa.
13 Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde,
àwọn àjàrà nípa ìtànná wọ́n fún ni ní òórùn dídùn.
Dìde, wá, Olólùfẹ́ mi,
Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.”
-
23 Wọn a sì dúró dè mí bí ẹni wí pé wọ́n dúró fún ọ̀wọ́ òjò;
wọn a sì mu nínú ọ̀rọ̀ mi bí ẹní mu nínú òjò àrọ̀kúrò.
-
3 Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa;
ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n.
Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ,
yóò jáde;
yóò tọ̀ wá wá bí òjò,
bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”
-
1 Ẹ béèrè òjò nígbà àrọ̀kúrò ni ọwọ́ Olúwa;
Olúwa tí o dá mọ̀nàmọ́ná,
tí ó sì fi ọ̀pọ̀ òjò fún ènìyàn,
fún olúkúlùkù koríko ní pápá.
-
22 Ẹ má bẹ̀rù, ẹranko igbó,
nítorí pápá oko aginjù ń rú.
Nítorí igi ń so èso rẹ̀,
igi ọ̀pọ̀tọ́ àti àjàrà ń so èso ọ̀rọ̀ wọn.
23 Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Sioni,
ẹ sì yọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run yín,
nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́,
Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín,
àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní.
-
7 Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadà wá Olúwa. Kíyèsi i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò.
-
1 Àsìkò wà fún ohun gbogbo,
àti ìgbà fún gbogbo nǹkan ní abẹ́ ọ̀run.
2 Ìgbà láti bí àti ìgbà kíkú,
ìgbà láti gbìn àti ìgbà láti fàtu.
3 Ìgbà láti pa àti ìgbà láti mú láradá
ìgbà láti wó lulẹ̀ àti ìgbà láti kọ́.
4 Ìgbà láti sọkún àti ìgbà láti rín ẹ̀rín
ìgbà láti ṣọ̀fọ̀ àti ìgbà láti jó,
5 ìgbà láti tú òkúta ká àti ìgbà láti ṣà wọ́n jọ
ìgbà láti súnmọ́ àti ìgbà láti fàsẹ́yìn,
6 ìgbà láti wá kiri àti ìgbà láti ṣàì wá kiri
ìgbà láti pamọ́ àti ìgbà láti jù nù,
7 ìgbà láti ya àti ìgbà láti rán
ìgbà láti dákẹ́ àti ìgbà láti sọ̀rọ̀,
8 ìgbà láti ní ìfẹ́ àti ìgbà láti kórìíra
ìgbà fún ogun àti ìgbà fún àlàáfíà.
-
7 Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín ń mú un yín bọ̀ wá sí ilẹ̀ rere ilẹ̀ tí ó kún fún odò àti ibú omi, pẹ̀lú àwọn ìsun tí ń sàn jáde láti orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀. 8 Ilẹ̀ tí ó kún fún jéró àti ọkà barle, tí ó sì kún fún àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́, igi pomegiranate, òróró olifi àti oyin. 9 Ilẹ̀ tí oúnjẹ kò ti wọ́n, kò sí ohun tí ẹ̀yin yóò ṣe aláìní, ilẹ̀ tí irin ti pọ̀ bí òkúta, ẹ̀yin sì lè wa idẹ jáde láti inú òkè rẹ̀ wá.
-
13 Nítorí náà, bí ẹ bá gbọ́rọ̀ sí àṣẹ tí mo fún un yín lónìí tọkàntọkàn: tí ẹ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì sìn ín, pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn yín: 14 nígbà náà, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ ẹ yín lákòókò rẹ̀, àti òjò àkọ́rọ̀ àti ti àrọ̀kẹ́yìn, kí ẹ ba à lè kórè oúnjẹ yín wọlé àní wáìnì tuntun àti òróró.
-
ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ
1 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,
tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
2 Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa
àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
3 Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,
tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀
tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.
Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.
-
15 Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè;
ojúrere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.
-
2 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ ọ̀ mi máa rọ̀ bí òjò,
kí àwọn ọ̀rọ̀ mi máa sọ̀kalẹ̀ bí ìrì,
bí òjò wíníwíní sára ewéko tuntun,
bí ọ̀wààrà òjò sára ohun ọ̀gbìn.
-
11 Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú irúgbìn jáde
àti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà,
bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè yóò ṣe mú òdodo àti ìyìn
kí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.
-
26 Bí ìsun tí ó di àbàtà tàbí kànga tí omi rẹ̀ bàjẹ́
ni olódodo tí ó fi ààyè gba ènìyàn búburú.
-
28 “Kí ni ìdí ti ẹ fi ń ṣe àníyàn ní ti aṣọ? Ẹ wo bí àwọn lílì tí ń bẹ ní igbó ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. 29 Bẹ́ẹ̀ ni mo wí fún yín pé, a kò ṣe Solomoni lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí. 30 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ bẹ́ẹ̀, èyí tí ó wà níhìn-ín lónìí ti a sì gbà sínú iná lọ́la, kò ha ṣe ni ṣe yín lọ́ṣọ̀ọ́ tó bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré?
-
14 Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, láti pààlà sí àárín ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún àmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún. 15 Kí wọn ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run láti tan ìmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.
-
9 Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà:
nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.
-
10 Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn àfonífojì;
tí ó ń sàn láàrín àwọn òkè.
11 Wọ́n fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omi
àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òǹgbẹ wọn.
12 Àwọn ẹyẹ ojú òfúrufú tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi
wọ́n ń kọrin láàrín àwọn ẹ̀ka.
13 Ó bu omi rin àwọn òkè láti ìyẹ̀wù rẹ̀ wá;
a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
-
14 Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè,
tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹ̀kùn ikú.
-
27 Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ orísun ìyè,
tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.
-
13 “Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì,
wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀,
Èmi orísun omi ìyè,
wọ́n sì ti ṣe àmù,
àmù fífọ́ tí kò lè gba omi dúró.
-
23 Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀,
wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ.
24 Wọn kò sọ fún ara wọn pé,
‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,
ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀,
tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédé.’
25 Àìṣedéédéé yín mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí kúrò,
ẹ̀ṣẹ̀ yín sì mú kí a fi nǹkan rere dù yín.
Shows Read in context, Share and Copy.