32 Bible Verses About Winter

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Winter
  1. 5 Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu;

    ohùn ńlá ńlá ni í ṣe tí àwa kò le mọ̀.

    6 Nítorí tí ó wí fún yìnyín pé, ‘Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé,’

    àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, ‘Fún òjò ńlá agbára rẹ̀.’

    7 Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀,

    ó sì tún dá olúkúlùkù ènìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.

    8 Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inú ihò lọ,

    wọn a sì wà ni ipò wọn.

    9 Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá,

    àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká.

    10 Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fi ìdí omi fún ni,

    ibú omi á sì súnkì.

    11 Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo,

    a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.

    12 Àwọn wọ̀nyí yí káàkiri nípa ìlànà rẹ̀,

    kí wọn kí ó lè ṣe ohunkóhun

    tí ó pàṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.

    13 Ó mú àwọsánmọ̀ wá, ìbá ṣe fún ìkìlọ̀,

    tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.

  2. 16 “Wẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ara yín mọ́.

    Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi!

    Dáwọ́ àìṣedéédéé dúró,

    17 kọ́ láti ṣe rere!

    Wá ìdájọ́ òtítọ́,

    tu àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú.

    Ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,

    gbà ẹjọ́ opó rò.

    18 “Ẹ wá ní ìsinsin yìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàṣàrò,”

    ni Olúwa wí.

    “Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn,

    wọn ó sì funfun bí i yìnyín,

    bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀,

    wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n òwú.

  3. 12 Yin Olúwa, ìwọ Jerusalẹmu;

    yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni.

    13 Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára,

    Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú rẹ

    14 Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀,

    òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.

    15 Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayé

    ọ̀rọ̀ rẹ̀ sáré tete.

    16 Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntàn

    ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú

    17 Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́

    ta ni ó lè dúró níwájú òtútù rẹ̀

    18 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀

    ó mú kí afẹ́fẹ́ rẹ̀ fẹ́

    ó sì mú odò rẹ̀ sàn.

    19 Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbu

    àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ fún Israẹli.

    20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀

    wọn ko mọ òfin rẹ̀.

    Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

  4. 10  Gẹ́gẹ́ bí òjò àti yìnyín

    ti wálẹ̀ láti ọ̀run

    tí kì í sì padà sí ibẹ̀

    láì bomirin ilẹ̀

    kí ó sì mú kí ó tanná kí ó sì rudi,

    tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi mú irúgbìn fún afúnrúgbìn

    àti àkàrà fún ọ̀jẹun,

    11 bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó jáde láti ẹnu mi wá;

    kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo,

    ṣùgbọ́n yóò ṣe ohun tí mo fẹ́,

    yóò sì mú ète mi tí mo fi rán an wá sí ìmúṣẹ.

    12 Ẹ̀yin yóò jáde lọ ní ayọ̀

    a ó sì darí i yín lọ ní àlàáfíà;

    òkè ńlá ńlá àti kéékèèké

    yóò bú sí orin níwájú yín

    àti gbogbo igi inú pápá

    yóò máa pàtẹ́wọ́.

  5. 6 Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;

    ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀.

    7 Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́;

    fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ.

  6. 20 Noa sì mọ pẹpẹ fún Olúwa, ó sì mú lára àwọn ẹran tí ó mọ́ àti ẹyẹ tí ó mọ́, ó sì fi rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. 21 Olúwa sì gbọ́ òórùn dídùn; ó sì wí ní ọkàn rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò tún fi ilẹ̀ ré nítorí ènìyàn mọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èrò inú rẹ̀ jẹ́ ibi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, èmi kì yóò pa gbogbo ohun alààyè run mọ́ láé, bí mo ti ṣe.

    22 “Níwọ́n ìgbà tí ayé bá sì wà,

    ìgbà ọ̀gbìn àti ìgbà ìkórè

    ìgbà òtútù àti ìgbà ooru,

    ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òjò,

    ìgbà ọ̀sán àti ìgbà òru,

    yóò wà títí láé.”

  7. 20 Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkùnrin kan tí Kabṣeeli, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu; ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjò-dídì.

  8. 9  “Bí mo ṣe ń wò,

    “a gbé ìtẹ́ ọba kan kalẹ̀,

    ẹni ìgbàanì jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀.

    Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú;

    irun orí rẹ̀ funfun bí òwú,

    ìtẹ́ ọba rẹ̀ rí bí ọwọ́ iná.

    Àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ ń jó bí i iná.

  9. 11 Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹ

    ó dàbí èso wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà.

    12 Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradára

    ni ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀.

    13 Bí títutù òjò yìnyín ní àsìkò ìkórè

    ni ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí àwọn tí ó rán an

    ó ń tu ọ̀gá rẹ̀ nínú.

  10. 20 O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà

    ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.

    21 Nígbà tí òjò-dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀

    nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.

  11. 22 “Ìwọ ha wọ inú ìṣúra ìdì òjò lọ rí bí,

    ìwọ sì rí ilé ìṣúra yìnyín rí,

    23 tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu,

    dé ọjọ́ ogun àti ìjà?

    24 Ọ̀nà wo ni ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ń la,

    tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé?

    25 Ta ni ó la ipadò fún ẹ̀kún omi,

    àti ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,

    26 láti mú u rọ̀jò sórí ayé níbi tí ènìyàn kò sí,

    ní aginjù níbi tí ènìyàn kò sí;

    27 láti mú ilẹ̀ tútù, ijù àti aláìro

    láti mú àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ewéko rú jáde?

  12. 16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;

    ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá.

    17 Ìwọ pààlà etí ayé;

    Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.

  13. 11 Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá;

    òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ.

    12 Àwọn òdòdó fi ara hàn lórí ilẹ̀

    àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé

    a sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa.

  14. 22 Ó sì jẹ́ ìgbà òtútù nínú oṣù kẹsànán, ọba sì jókòó ní ẹ̀bá iná ààrò, iná náà sì ń jó ní iwájú rẹ̀.

  15. 16 Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀, àdúrà mi ni kí a má ṣe kà á sí wọn lọ́rùn. 17 Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára; pé nípasẹ̀ mi kí a lè wàásù náà ní àwàjálẹ̀, àti pé kí gbogbo àwọn aláìkọlà lè gbọ́; a sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún náà. 18 Olúwa yóò yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ búburú gbogbo, yóò sì mu mí dé inú ìjọba ọ̀run. Ẹni ti ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.

    19 Kí Priska àti Akuila, àti ilé Onesiforu.

    20 Erastu wà ní Kọrinti: ṣùgbọ́n mo fi Tirofimu sílẹ̀ ni Miletu nínú àìsàn. 21 Sa ipá rẹ láti tètè wá ṣáájú ìgbà òtútù.

    Eubulu kí ọ, àti Pudeni, àti Linu, Klaudia, àti gbogbo àwọn arákùnrin.

    22 Kí Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú yín.

  16. 1  Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, bí ilẹ̀ ti ń mọ́, Maria Magdalene àti Maria kejì lọ sí ibojì.

    2  Wọ́n rí i pé, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ṣẹ̀ tí ó mú gbogbo ilẹ̀ mì tìtì. Nítorí angẹli Olúwa ti sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Ó ti yí òkúta ibojì kúrò. Ó sì jókòó lé e lórí. 3 Ojú rẹ̀ tàn bí mọ̀nàmọ́ná. Aṣọ rẹ̀ sì jẹ́ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. 4  Ẹ̀rù ba àwọn olùṣọ́, wọ́n sì wárìrì wọn sì dàbí òkú.

    5 Nígbà náà ni angẹli náà wí fún àwọn obìnrin náà pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé ẹ̀yin ń wá Jesu tí a kàn mọ́ àgbélébùú. 6 Ṣùgbọ́n kò sí níhìn-ín. Nítorí pé ó ti jíǹde, gẹ́gẹ́ bí òun ti wí. Ẹ wọlé wá wo ibi ti wọ́n tẹ́ ẹ sí.

  17. 14 Ǹjẹ́ omi ojo dídì Lebanoni

    yóò ha dá láti máa sàn láti ibi àpáta?

    Tàbí odò tí ó jìnnà, tí ó tútù,

    tí ó ń sàn, yóò ha gbẹ bí?

  18. 7 Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá

    ẹ̀yin ẹ̀dá inú òkun títóbi

    àti ẹ̀yin ibú òkun,

    8 mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín

    ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,

    ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,

  19. 15 Èmi yóò wó ilé òtútù

    lulẹ̀ pẹ̀lú ilé ooru;

    ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbé

    a ó sì pa ilé ńlá náà run,”

    ni Olúwa wí.

  20. 12 Àti nítorí pé èbúté náà kò rọrùn láti lo àkókò òtútù níbẹ̀, àwọn púpọ̀ sí dámọ̀ràn pé, kí a lọ kúrò níbẹ̀, bóyá wọn ó lè làkàkà dé Fonike, tí i ṣe èbúté Krete ti ó kọjú sí òsì ìwọ̀-oòrùn, àti ọ̀tún ìwọ̀-oòrùn, láti lo àkókò òtútù níbẹ̀.

  21. 15 Àwọn ará mi dàbí odò tí kò ṣe gbẹ́kẹ̀lé

    bí ìṣàn omi odò, wọ́n sàn kọjá lọ.

    16 Tí ó dúdú nítorí omi dídì,

    àti níbi tí yìnyín dídì gbé di yíyọ́.

  22. 20 Ẹ sì máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣe jẹ́ ìgbà òtútù, tàbí ọjọ́ ìsinmi. 21 Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wá títí di ìsinsin yìí irú rẹ̀ kì yóò sì ṣí.

  23. 2  Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà tí Jesu sọ̀rọ̀ yìí, Jesu mú Peteru, Jakọbu àti Johanu lọ sí orí òkè gíga ní apá kan. Kò sí ẹlòmíràn pẹ̀lú wọn, ara rẹ̀ sì yípadà níwájú wọn. 3  Aṣọ rẹ̀ sì di dídán, ó sì funfun gbòò, tí alágbàfọ̀ kan ní ayé kò lè sọ di funfun bẹ́ẹ̀. 4 Nígbà náà ni Elijah àti Mose farahàn fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Jesu.

  24. 22 Benaiah ọmọ Jehoiada ó sì jẹ́ akọni oníjà láti Kabṣeeli, ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ agbára ńlá. Ó sì pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu, ó sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ihò lákokò yìnyín dídì, ó sì pa kìnnìún kan

  25. 1 Bí òjò-dídì tàbí òjò ní ìgbà ìkórè

    ọlá kò yẹ aláìgbọ́n ènìyàn.

  26. 8 Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, omi ìyè yóò tí Jerusalẹmu sàn lọ; ìdajì wọn síhà Òkun ìlà-oòrùn, àti ìdajì wọn síhà okùn ẹ̀yìn: nígbà ẹ̀rùn àti nígbà òtútù ni yóò rí bẹ́ẹ̀.

  27. 4 Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ,

    nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.

  28. 6 A ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ẹyẹ òkè ńlá

    àti fún àwọn ẹranko búburú;

    àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣe oúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùn

    àti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò.

  29. 12 Ní kété tí mo bá ti rán Artema tàbí Tikiku sí ọ, sa gbogbo ipá rẹ láti tọ̀ mí wá ní Nikopoli, nítorí mo ti pinnu láti lo ìgbà òtútù mi níbẹ̀.

  30. 18 Kí ẹ sì máa gbàdúrà pé èyí ṣẹlẹ̀ ní àkókò òtútù.

  31. 9 Sa ipá rẹ láti tètè tọ̀ mí wá. 10  Nítorí Dema ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí ó ń fẹ́ ayé yìí, ó sì lọ sí Tẹsalonika; Kreskeni sí Galatia, Titu sí Dalimatia. 11 Luku nìkan ni ó wà pẹ̀lú mi, mú Marku wá pẹ̀lú rẹ: nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́. 12 Mo rán Tikiku ní iṣẹ́ lọ sí Efesu. 13 Aṣọ òtútù tí mo fi sílẹ̀ ní Troasi lọ́dọ̀ Karpu, nígbà tí ìwọ bá ń bọ̀ mú un wa, àti àwọn ìwé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìwé-awọ.

  32. 11 Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, a wọ ọkọ̀ ojú omi kan èyí tí ó lo àkókò òtútù ní erékùṣù náà. Ó jẹ́ ọkọ̀ ojú omi ti Alekisandiria, èyí tí àmì rẹ̀ jẹ́ tí òrìṣà ìbejì ti Kasitoru òun Polukisu.