54 Bible Verses About Mother's Day

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Mother's Day
  1. Ìkádìí: Aya oníwà rere

    10 Ta ni ó le rí aya oníwà rere?

    Ó níye lórí ju iyùn lọ.

    11 Ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ nínú rẹ̀

    kò sì ṣí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀.

    12 Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibi

    ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

    13 Ó sa aṣọ irun àgùntàn olówùú àti ọ̀gbọ̀

    Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.

    14 Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò;

    ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn.

    15 Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn;

    ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀

    àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀.

    16 Ó kíyèsi oko kan, ó sì rà á;

    nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin ọgbà àjàrà rẹ̀.

    17 Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbára tagbára

    apá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́.

    18 Ó rí i pé òwò òun pé

    fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú ní òru.

    19 Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú mú

    ó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú.

    20 O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà

    ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.

    21 Nígbà tí òjò-dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀

    nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.

    22 Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀;

    ẹ̀wù dáradára àti elése àlùkò ni aṣọ rẹ̀.

    23 A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibodè ìlú

    níbi tí ó ń jókòó láàrín àwọn àgbàgbà ìlú.

    24 Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́n

    ó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò.

    25 Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọ

    ó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.

    26 A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n

    ìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀

    27 Ó ń bojútó gbogbo ètò ilé rẹ̀

    kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.

    28 Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkún

    ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un.

    29 “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́lá

    ṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ.”

    30 Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán

    nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn.

    31 Sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí i

    kí o sì jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ fún un ní ìyìn ní ẹnu ibodè ìlú.

  2. 25  Ìyá Jesu àti arábìnrin ìyá rẹ̀ Maria aya Kilopa, àti Maria Magdalene sì dúró níbi àgbélébùú, 26  nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ àti ọmọ-ẹ̀yìn náà dúró, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obìnrin, wo ọmọ rẹ!” 27 Lẹ́yìn náà ni ó sì wí fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ!” Láti wákàtí náà lọ ni ọmọ-ẹ̀yìn náà sì ti mú un lọ sí ilé ara rẹ̀.

  3. 1 Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ tí àwọn òbí i yín nínú Olúwa, nítorí pé èyí ní ó tọ́. 2  “Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ,” èyí tí í ṣe òfin kìn-ín-ní pẹ̀lú ìlérí, 3  “ki ó lé dára fún ọ, àti kí ìwọ lè wà pẹ́ ní ayé.”

  4. 22 Fetí sí ti baba rẹ tí ó bí ọ,

    má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí o bá gbó.

    23 Ra òtítọ́, kí o má sì ṣe tà á;

    ra ọgbọ́n pẹ̀lú àti ẹ̀kọ́ àti òye.

    24 Baba olódodo ni yóò yọ̀ gidigidi:

    ẹni tí ó sì bí ọmọ ọlọ́gbọ́n,

    yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀.

    25 Jẹ́ kí baba rẹ àti ìyá rẹ ó yọ̀,

    sì jẹ́ kí inú ẹni tí ó bí ọ dùn.

  5. 12  Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.

  6. 8 Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹ,

    má ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá rẹ sílẹ̀.

    9 Wọn yóò jẹ́ òdòdó ẹ̀yẹ olóòórùn dídùn lórí rẹ

    àti ọ̀ṣọ́ tí ó dára yí ọrùn rẹ ká.

  7. 6 Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀:

    nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.

  8. 3 Bákan náà, ni kí ó kọ́ àwọn àgbà obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti kọ́ bí à a tí gbé ìgbé ayé ẹni ọ̀wọ̀, wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ afọ̀rọ̀kẹ́lẹ́ batẹnijẹ́ tàbí olùfẹ́ ọtí mímu, ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ olùkọ́ni ní ohun rere. 4 Nípa èyí, wọ́n yóò lè máa kọ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn àti àwọn ọmọ wọn, 5 láti jẹ́ ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ọlọ́kàn mímọ́, kí wọ́n máa ṣe ojúṣe wọn nínú ilé, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onínúrere, kí wọ́n sì máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọ́n, kí ẹnikẹ́ni máa ba à sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

  9. 1 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín; pé, bí ẹnikẹ́ni ba tilẹ̀ ń ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láì sọ̀rọ̀ nípa ìwà àwọn aya wọn. 2 Nígbà tí wọ́n bá ń wo ìwà rere pẹ̀lú ẹ̀rù yín. 3 Kí ọ̀ṣọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀ṣọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀; 4 ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó fi ara sin ní ọkàn, nínú ọ̀ṣọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run.

  10. 13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;

    ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.

    14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;

    ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;

    èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú.

    15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,

    nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.

    Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,

    16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi

    nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé,

    àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,

    ní ọjọ́ tí a dá wọn,

    nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.

  11. 3 Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa:

    ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.

    4 Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára,

    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe.

    5 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn;

    ojú kì yóò tì wọ́n,

    ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.

  12. 41 Ó sì ṣe, nígbà tí Elisabeti gbọ́ kíkí Maria, ọlẹ̀ sọ nínú rẹ̀; Elisabeti sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, 42  Ó sì ké ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Alábùkún fún ni ìwọ nínú àwọn obìnrin, alábùkún fún sì ni ọmọ tí ìwọ yóò bí. 43 Èéṣe tí èmi fi rí irú ojúrere yìí, tí ìyá Olúwa mi ìbá fi tọ̀ mí wá? 44 Sá wò ó, bí ohùn kíkí rẹ ti bọ́ sí mi ní etí, ọlẹ̀ sọ nínú mi fún ayọ̀. 45 Alábùkún fún sì ni ẹni tí ó gbàgbọ́, nítorí nǹkan wọ̀nyí tí a ti sọ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò ṣẹ.”

    46 Maria sì dáhùn, ó ní:

    “Ọkàn mi yin Olúwa lógo.

    47 Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.

    48 Nítorí tí ó síjú wo ìwà ìrẹ̀lẹ̀

    ọmọbìnrin ọ̀dọ̀ rẹ̀. Sá wò ó,

    láti ìsinsin yìí lọ gbogbo ìran ènìyàn ni yóò máa pè mí ní alábùkún fún.

    49 Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi;

    Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.

  13. 5  Nígbà ti mo bá rántí ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn rẹ, èyí ti ó kọ́kọ́ ń bẹ nínú Loisi ìyá ńlá rẹ, àti nínú Eunike ìyá rẹ̀ àti, èyí tí ó dá mi lójú pé ó ń gbé inú rẹ̀ pẹ̀lú.

  14. 20 Ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́

    má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.

    21 Jẹ́ kí wọn wà nínú ọkàn rẹ láéláé

    so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.

    22 Nígbà tí ìwọ bá ń rìn, wọn yóò ṣe amọ̀nà rẹ;

    nígbà tí ìwọ bá sùn, wọn yóò máa ṣe olùṣọ́ rẹ;

    nígbà tí o bá jí, wọn yóò bá ọ sọ̀rọ̀.

    23 Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ fìtílà,

    ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀,

    àti ìtọ́nisọ́nà ti ìbáwí

    ni ọ̀nà sí ìyè.

  15. 4 Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣeun, ìfẹ́ kì í ṣe ìlara, ìfẹ́ kì í fẹ̀, ìfẹ́ kì í sọ̀rọ̀ ìgbéraga. 5  Ìfẹ́ kì í hùwà àìtọ́, kì í wá ohun ara rẹ̀ nìkan. Ìfẹ́ kì í bínú fùfù, ìfẹ́ kì í fi búburú ọmọ ẹnìkejì sínú. 6 Inú ìfẹ́ kì í dùn sí àìṣòótọ́. Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ a máa dùn nígbà gbogbo. 7  A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo.

  16. 1 Má ṣe bá àgbàlagbà ọkùnrin wí, ṣùgbọ́n kí ó máa gbà á níyànjú bí i baba; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bí arákùnrin. 2 Àwọn àgbàlagbà obìnrin bí ìyá; àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin bí arábìnrin nínú ìwà mímọ́.

  17. 26 Hana sì wí pé, “Olúwa mi, bí ọkàn rẹ ti wà láààyè, Olúwa mi, èmi ni obìnrin náà tí ó dúró lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ níhìn-ín tí ń tọrọ lọ́dọ̀ Olúwa. 27 Ọmọ yìí ni mo ń tọrọ; Olúwa sì fi ìdáhùn ìbéèrè tí mo béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ fún mi. 28 Nítorí náà pẹ̀lú, èmi fi í fún Olúwa; ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀: nítorí tí mo ti béèrè rẹ̀ fún Olúwa.” Wọn si wólẹ̀ sin Olúwa níbẹ̀.

  18. 15 Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́n

    ṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnra rẹ̀ a dójútì ìyá rẹ̀.

    16 Nígbà tí ènìyàn búburú ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀

    ṣùgbọ́n olódodo yóò rí ìṣubú wọn.

    17 Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíà

    yóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ.

  19. 46  Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, wò ó, ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. 47 Nígbà náà ni ẹnìkan wí fún un pé, “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń dúró dè ọ́ lóde wọ́n ń fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”

    48 Ó sì fún ni èsì pé, “Ta ni ìyá mi? Ta ni àwọn arákùnrin mi?” 49 Ó nawọ́ sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí pé, “Wò ó, ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni wọ̀nyí.” 50  Nítorí náà, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”

  20. 35 Nítorí èmi wá láti ya

    “ ‘ọmọkùnrin ní ipa sí baba rẹ̀,

    ọmọbìnrin ní ipa sí ìyá rẹ̀,

    àti aya ọmọ sí ìyakọ rẹ.

    36 Ará ilé ènìyàn ni yóò sì máa ṣe ọ̀tá rẹ̀.’

    37 “Ẹni tí ó bá fẹ́ baba rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi, ẹni tí ó ba fẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi. 38 Ẹni tí kò bá gbé àgbélébùú rẹ̀ kí ó tẹ̀lé mi kò yẹ ní tèmi.

  21. 48  Nígbà tí wọ́n sì rí i, háà ṣe wọ́n, ìyá rẹ̀ sì bi í pé, “Ọmọ, èéṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀? Sá wò ó, baba rẹ̀ àti èmi ti ń fi ìbànújẹ́ wá ọ kiri.”

    49 Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri? Ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?” 50 Ọ̀rọ̀ tí o sọ kò sì yé wọn.

    51  Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí Nasareti, sì fi ara balẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀.

  22. 57  Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan láti Arimatea, tí à ń pè ní Josẹfu, ọ̀kan nínú àwọn tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, 58 lọ sọ́dọ̀ Pilatu, ó sì tọrọ òkú Jesu. Pilatu sì pàṣẹ kí a gbé é fún un. 59 Josẹfu sì gbé òkú náà. Ó fi aṣọ funfun mímọ́ dì í. 60 Ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì òkúta tí ó gbẹ́ nínú àpáta fúnra rẹ̀. Ó sì yí òkúta ńlá dí ẹnu-ọ̀nà ibojì náà, ó sì lọ. 61 Maria Magdalene àti Maria kejì wà níbẹ̀, wọn jókòó òdìkejì ibojì náà.

  23. 16 Ṣùgbọ́n Rutu dáhùn wí pé, “Má ṣe rọ̀ mí láti fi ọ́ sílẹ̀ tàbí láti padà lẹ́yìn rẹ. Ibi tí ìwọ bá lọ ní èmi yóò lọ, ibi ti ìwọ bá dúró ni èmi yóò dúró, àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi. 17 Níbi tí ìwọ bá kú sí ni èmi yóò kú sí, níbẹ̀ ni wọn yóò sì sin mí sí. Kí Olúwa jẹ mí ní ìyà tí ó lágbára, bí ohunkóhun bí kò ṣe ikú bá yà wá.”

  24. 38  Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, o wọ ìletò kan, obìnrin kan tí a ń pè ní Marta sì gbà á sí ilé rẹ̀. 39 Ó sì ní arábìnrin kan tí a ń pè ní Maria tí ó sì jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Olúwa, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. 40 Ṣùgbọ́n Marta ń ṣe ìyọnu ohun púpọ̀, ó sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Olúwa, ìwọ kò sì bìkítà sí ti arábìnrin mi pé ó fi mí sílẹ̀ láti máa nìkan ṣe ìránṣẹ́? Wí fún un kí ó ràn mí lọ́wọ́.”

    41  Ṣùgbọ́n Olúwa sì dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Marta, Marta, ìwọ ń ṣe àníyàn àti làálàá nítorí ohun púpọ̀. 42 Ṣùgbọ́n ohun kan ni a kò lè ṣe aláìní, Maria sì ti yan ipa rere náà tí a kò lè gbà lọ́wọ́ rẹ̀.”

  25. 20  Ìwọ mọ̀ àwọn òfin: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà, ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jalè, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jẹ́rìí èké, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.’ ”

  26. 14 Gbogbo àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn obìnrin àti Maria ìyá Jesu àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ọkàn kan dúró láti máa gbàdúrà.

  27. 13 Ǹjẹ́ nísinsin yìí àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí dúró: ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́. Ṣùgbọ́n èyí tí o tóbi jù nínú wọn ni ìfẹ́.

  28. 8 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrín ara yín, nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.

  29. 4 Èmi ni ayọ̀ tí ó tayọ, láti máa gbọ́ pé, àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́.

  30. 5 Fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ. 6  Àwọn àṣẹ tí mo fún un yín lónìí gbọdọ̀ máa wà lóókan àyà yín. 7 Ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín gidigidi. Bí ẹ bá jókòó nínú ilé, ẹ jíròrò nípa wọn, àti nígbà tí ẹ bá ń rìn ní ojú ọ̀nà, bí ẹ bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí ẹ bá dìde. 8  Ẹ so wọ́n sí ọwọ́ yín fún àmì, ẹ so ó mọ́ iwájú orí yín. 9 Kí ìwọ kí ó kọ wọ́n sára òpó ilé rẹ̀, àti sí ara ìlẹ̀kùn ọ̀nà òde rẹ.

  31. 18  Bí ọkùnrin kan bá ní aláìgbọ́ràn tàbí ọlọ̀tẹ̀ ọmọ tí kò gbọ́rọ̀ sí baba àti ìyá rẹ̀ tí kò sì ní í gbà tí wọ́n bá ń bá a wí, 19 baba àti ìyá rẹ̀ yóò gbá a mú, wọn yóò mu wá fún àwọn àgbàgbà ní ẹnu-bodè ìlú u rẹ̀. 20 Wọn yóò sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Ọmọ wa yìí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀. Kò ní gbọ́rọ̀ sí wa lẹ́nu. Ọ̀jẹun àti ọ̀mùtípara ni.” 21 Nígbà náà ni gbogbo ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò sọ ọ́ ní òkúta pa. Ìwọ yóò sì mú ìwà ibi kúrò láàrín yín, gbogbo Israẹli yóò gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n.

  32. Àwọn òwe Solomoni

    1 Àwọn òwe Solomoni.

    Ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn,

    ṣùgbọ́n aṣiwèrè ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́.

  33. 6 Ọmọ ọmọ ni adé orí arúgbó,

    ògo àwọn ọmọ sì ni òbí jẹ.

  34. 16 “Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. 17  Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n kí a le ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là.

  35. 22 Ṣùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́, 23 ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni níjanu, òfin kan kò lòdì sí irú wọ̀nyí,

  36. 22 Olúwa Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, Ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá.

    23 Ọkùnrin náà sì wí pé,

    “Èyí ni egungun láti inú egungun mi

    àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi;

    ‘obìnrin’ ni a ó máa pè é,

    nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.”

    24  Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.

  37. 15  Èmi yóò sì fi ọ̀tá

    sí àárín ìwọ àti obìnrin náà,

    àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà;

    òun yóò fọ́ orí rẹ,

    ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”

    16 Ọlọ́run wí fún obìnrin náà pé,

    “Èmi yóò fi kún ìrora rẹ ní àkókò ìbímọ;

    ni ìrora ni ìwọ yóò máa bí ọmọ.

    Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí,

    òun ni yóò sì máa ṣe àkóso rẹ.”

  38. 20 Adamu sì sọ aya rẹ̀ ní Efa nítorí òun ni yóò di ìyá gbogbo alààyè.

  39. 16 Obìnrin oníwà rere gba ìyìn

    ṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan.

  40. 22 Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere,

    o sì gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa.

  41. 20 Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀,

    ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri.

  42. 1  Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, bí ilẹ̀ ti ń mọ́, Maria Magdalene àti Maria kejì lọ sí ibojì.

  43. 29 Jesu dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó fi ohunkóhun sílẹ̀ bí: ilé, tàbí àwọn arákùnrin, tàbí àwọn arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí baba, tàbí àwọn ọmọ tàbí ohun ìní nítorí mi àti nítorí ìyìnrere, 30  tí a kì yóò fún padà ní ọgọọgọ́rùn-ún àwọn ilé, tàbí arákùnrin, tàbí arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí ọmọ, tàbí ilẹ̀, àti inúnibíni pẹ̀lú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò jẹ́ tirẹ̀ ní ayé yìí àti pé ní ayé tó ń bọ̀ yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun.

  44. 34  Nígbà náà ni Maria béèrè lọ́wọ́ angẹli náà pé, “Èyí yóò ha ti ṣe rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí èmi kò tí ì mọ ọkùnrin.”

    35  Angẹli náà sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóò tọ̀ ọ́ wá, agbára Ọ̀gá-ògo jùlọ yóò síji bò ọ́. Nítorí náà ohun mímọ́ tí a ó ti inú rẹ bí, Ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè é. 36 Sì kíyèsi i, Elisabeti ìbátan rẹ náà yóò sì ní ọmọkùnrin kan ní ògbólógbòó rẹ̀, èyí sì ni oṣù kẹfà fún ẹni tí à ń pè ní àgàn. 37  Nítorí kò sí ohun tí Ọlọ́run kò le ṣe.”

    38 Maria sì dáhùn wí pé, “Wò ó ọmọ ọ̀dọ̀ Olúwa; kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ.

  45. 38 Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kì í ṣe ikú tàbí ìyè, kì í ṣe àwọn angẹli tàbí ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe ohun ìgbà ìsinsin yìí tàbí ohun tí ó ń bọ̀, tàbí àwọn agbára, 39 tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun nínú ìṣẹ̀dá ni yóò le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ń bẹ nínú Kristi Jesu, Olúwa wa.

  46. 4 Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀. 5 Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí. 6  Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. 7 Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu.

    8 Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò.

  47. 11 Bí idì ti í ru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ń

    rábàbà sórí ọmọ rẹ̀,

    tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sì

    gbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀.

  48. Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

    1 Olúwa àyà mi kò gbéga,

    bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè:

    bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá,

    tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ.

    2 Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi,

    mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́,

    bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú:

    ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú.

  49. 14 A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí,

    ṣùgbọ́n aya olóye láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni.

  50. 20  Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sebede bá àwọn ọmọ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jesu, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, o béèrè fún ojúrere rẹ̀.

    21  Jesu béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”

    Ó sì dáhùn pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ mi méjèèjì jókòó ní apá ọ̀tún àti apá òsì lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ?”

    22  Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn ó sì wí pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀yin ń béèrè, ẹ̀yin ha le mu nínú ago tí èmi ó mu?”

    Wọ́n dáhùn pé, “Àwa lè mu ún.”

    23  Jesu sì wí fún wọn pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin yóò mu nínú ago mi, ṣùgbọ́n èmi kò ní àṣẹ láti sọ irú ènìyàn tí yóò jókòó ní apá ọ̀tún tàbí apá òsì. Baba mi ti pèsè ààyè wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ fún kìkì àwọn tí ó yàn.”

  51. 29  Nígbà tí wọn sì jáde kúrò nínú Sinagọgu, wọ́n lọ pẹ̀lú Jakọbu àti Johanu sí ilé Simoni àti Anderu. 30 Ìyá ìyàwó Simoni tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jesu nípa rẹ̀. 31 Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde; lójúkan náà ibà náà fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.

  52. 27  Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, obìnrin kan gbóhùn rẹ̀ sókè nínú ìjọ, ó sì wí fún un pé, “Ìbùkún ni fún inú tí ó bí ọ, àti ọmú tí ìwọ mu!”

    28 Ṣùgbọ́n òun wí pé, nítòótọ́, kí ó kúkú wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì pa á mọ́!”

  53. 34 “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́!

  54. 2 Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀. Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́, ṣùgbọ́n Lasaru jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀. 3 Nígbà náà ni Maria mú òróró ìkunra nadi, òsùwọ̀n lita kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jesu ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ nù. Ilé sì kún fún òórùn ìkunra náà.