63 Bible Verses About Being In Love

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Being In Love
  1. 1 Orin, àwọn orin tí í ṣe orin Solomoni.

    Olólùfẹ́

    2 Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu,

    nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ.

    3 Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra.

    Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jáde

    abájọ tí àwọn wúńdíá fi fẹ́ ọ.

    4 Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá

    ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀.

    Ọ̀rẹ́

    Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ;

    a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ.

    Olólùfẹ́

    Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́!

    5 Èmi dúdú mo sì ní ẹwà.

    Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu

    dúdú bí àgọ́ ìlú Kedari,

    bí aṣọ títa ti Solomoni.

    6 Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú,

    nítorí oòrùn mú mi dúdú,

    ọmọkùnrin ìyá mi bínú sí mi

    ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà;

    ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú.

    7 Wí fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́,

    níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ.

    Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán,

    kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin asán

    ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.

    Ọ̀rẹ́

    8 Bí ìwọ kò bá mọ̀,

    ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin.

    Bá ọ̀nà tí agbo ẹran rìn lọ,

    kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ.

    Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn.

  2. Ọ̀rẹ́

    5 Ta ni ẹni tí ń gòkè bọ̀ wá láti aginjù,

    tí ó fi ara ti olùfẹ́ rẹ̀.

    Olólùfẹ́

    Ní abẹ́ igi ápù ni mo ti jí ọ dìde; níbẹ̀ ni ìyá rẹ ti lóyún rẹ

    níbẹ̀ ni ẹni tí ń rọbí bí ọ sí.

    6 Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì

    bí èdìdì lé apá rẹ;

    nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú,

    ìjowú sì le bí isà òkú

    jíjò rẹ̀ rí bí jíjò iná,

    gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́-iná Olúwa.

    7 Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́;

    bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ.

    Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́,

    ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀,

    a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátápátá.

    Ọ̀rẹ́

    8 Àwa ní arábìnrin kékeré kan,

    òun kò sì ní ọmú,

    kí ni àwa yóò fún arábìnrin wa,

    ní ọjọ́ tí a ó bá fẹ́ ẹ?

    9 Bí òun bá jẹ́ ògiri,

    àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí.

    Bí òun bá jẹ́ ìlẹ̀kùn,

    àwa yóò fi pákó kedari dí i.

    Olólùfẹ́

    10 Èmi jẹ́ ògiri,

    ọmú mi sì rí bí ilé ìṣọ́

    bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe rí ní ojú rẹ̀

    bí ẹni tí ń mú àlàáfíà wá.

    11 Solomoni ní ọgbà àjàrà kan ní Baali-Hamoni

    ó gbé ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú

    olúkúlùkù ni ó ń mú èso rẹ̀ wá

    ẹgbẹ̀rún (1,000) fàdákà.

    12 Ṣùgbọ́n ọgbà àjàrà mi jẹ́ tèmi, ó wà fún mi;

    ẹgbẹ̀rún ṣékélì jẹ́ tìrẹ, ìwọ Solomoni,

    igba sì jẹ́ ti àwọn alágbàtọ́jú èso.

  3. 1 Ní orí ibùsùn mi ní òru

    mo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́;

    mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i.

    2 Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú,

    ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde;

    èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́.

    Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i.

    3 Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi

    bí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú.

    “Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”

    4 Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀

    ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.

    Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ

    títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi,

    sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi.

    5 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,

    mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín bú

    kí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè

    kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.

  4. 6 Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá

    bí ọ̀wọ̀n èéfín

    tí a ti fi òjìá àti tùràrí kùn lára

    pẹ̀lú gbogbo ìpara olóòórùn oníṣòwò?

    7 Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Solomoni,

    àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká,

    àwọn akọni Israẹli,

    8 gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́,

    gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun,

    idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,

    wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru

    9 Solomoni ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀;

    o fi igi Lebanoni ṣe é.

    10 Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀,

    o fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀.

    Ó fi elése àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀,

    inú rẹ̀ ni ó ko àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí.

    “Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”

    11 Ẹ jáde wá, ẹ̀yin ọmọbìnrin Sioni,

    kí ẹ sì wo ọba Solomoni tí ó dé adé,

    adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e

    ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀,

    ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.

  5. Olùfẹ́

    4 Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tirsa,

    ìwọ lẹ́wà bí i Jerusalẹmu,

    ìwọ ògo bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun.

    5 Yí ojú rẹ kúrò lára mi;

    nítorí ojú rẹ borí mi.

    Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́

    tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gileadi.

    6 Eyín rẹ rí bí ọ̀wọ́ àgùntàn,

    tí ó gòkè láti ibi ìwẹ̀ rẹ̀ wá,

    gbogbo wọn bí ìbejì,

    kò sì ṣí ọ̀kankan tí ó yàgàn nínú wọn.

    7 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́bàá ìbòjú rẹ,

    rí bí ẹ̀là èso pomegiranate.

    8 Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀,

    àti ọgọ́rin àlè,

    àti àwọn wúńdíá láìníye.

    9 Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni,

    ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ̀,

    ààyò ẹyọ kan ṣoṣo ẹni tí ó bí i.

    Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fún

    àwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fún un.

    Ọ̀rẹ́

    10 Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀,

    tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí oòrùn,

    tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun?

  6. 9 Àti ìfẹnukonu rẹ rí bí ọtí wáìnì tí ó dára jùlọ.

    Olólùfẹ́

    Tí ó kúnná tí ó sì dùn,

    tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀.

    10 Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe,

    èmi sì ni ẹni tí ó wù ú.

    11 Wá, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí a lọ sí ibi pápá,

    jẹ́ kí a lo àṣálẹ́ ní àwọn ìletò.

    12 Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtù

    láti wo bí àjàrà rúwé

    bí ìtànná àjàrà bá là.

    Àti bí pomegiranate bá ti rudi,

    níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.

    13 Àwọn èso mándrákì mú òórùn wọn jáde

    ní ẹnu-ọ̀nà wa ni onírúurú àṣàyàn èso,

    èso tuntun àti ọjọ́ pípẹ́

    tí mo ti kó pamọ́ fún ọ, olùfẹ́ mi.

  7. 10 Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé,

    “Dìde, Olólùfẹ́ mi,

    arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi.

    11 Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá;

    òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ.

    12 Àwọn òdòdó fi ara hàn lórí ilẹ̀

    àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé

    a sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa.

    13 Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde,

    àwọn àjàrà nípa ìtànná wọ́n fún ni ní òórùn dídùn.

    Dìde, wá, Olólùfẹ́ mi,

    Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.”

    Olùfẹ́

    14 Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta,

    ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga,

    fi ojú rẹ hàn mí,

    jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ;

    nítorí tí ohùn rẹ dùn,

    tí ojú rẹ sì ní ẹwà.

    15 Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀,

    àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké

    tí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́,

    àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtànná.

  8. 12 Arábìnrin mi ni ọgbà tí a sọ, arábìnrin mi, ìyàwó mi;

    ìsun tí a sé mọ́, orísun tí a fi èdìdì dì.

    13 Ohun ọ̀gbìn rẹ àgbàlá pomegiranate ni

    ti òun ti àṣàyàn èso; kipiresi àti nadi,

    14 nadi àti Safironi,

    kalamusi àti kinamoni,

    àti gbogbo igi olóòórùn dídùn,

    òjìá àti aloe

    pẹ̀lú irú wọn.

    15 Ìwọ ni ọgbà orísun, kànga omi ìyè,

    ìṣàn omi láti Lebanoni wá.

    Olólùfẹ́

    16 Jí ìwọ afẹ́fẹ́ àríwá

    kí o sì wá, afẹ́fẹ́ gúúsù!

    Fẹ́ lórí ọgbà mi,

    kí àwọn òórùn dídùn inú rẹ lè rùn jáde.

    Jẹ́ kí olùfẹ́ mi wá sínú ọgbà a rẹ̀

    kí ó sì jẹ àṣàyàn èso rẹ̀.

  9. 4 Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ìlẹ̀kùn

    inú mi sì yọ́ sí i.

    5 Èmi dìde láti ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,

    òjìá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi,

    òjìá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń sàn

    sí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn.

    6 Èmi ṣí ìlẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,

    ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọ

    ọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀.

    Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i.

    Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn.

    7 Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi

    bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká.

    Wọ́n nà mí, wọ́n sá mi lọ́gbẹ́;

    wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi.

    Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi!

    8 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo bẹ̀ yín

    bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi,

    kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un?

    Ẹ wí fún un pé àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mi.

  10. Ọ̀rẹ́

    1 Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ,

    ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin?

    Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí,

    kí a lè bá ọ wá a?

    Olólùfẹ́

    2 Olùfẹ́ mi ti sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀,

    sí ibi ibùsùn tùràrí,

    láti máa jẹ nínú ọgbà

    láti kó ìtànná lílì jọ.

    3 Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi,

    Ó ń jẹ láàrín ìtànná lílì.

  11. Olùfẹ́

    11 Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igi

    láti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì,

    láti rí i bí àjàrà rúwé,

    tàbí bí pomegiranate ti rudi.

    12 Kí èmi tó mọ̀,

    àárẹ̀ ọkàn mú mi, mo sì fẹ́ kí ń wà láàrín àwọn ènìyàn mi.

    Ọ̀rẹ́

    13 Padà wá, padà wá, ìwọ ọmọ Ṣulamati;

    padà wá, padà wá, kí àwa kí ó lè yọ́ ọ wò.

    Olùfẹ́

    Èéṣe tí ẹ̀yin fẹ́ yọ́ Ṣulamati wò,

    bí ẹni pé orin ijó Mahanaimu?

  12. 1 Ìwọ ìbá rí bí arákùnrin mi si mi,

    èyí tí ó mú ọmú ìyá mi dàgbà!

    Èmi ìbá rí ọ ní òde,

    èmi ìbá fi ẹnu kò ọ́ ní ẹnu,

    wọn kì bá fi mí ṣe ẹlẹ́yà.

    2 Èmi ìbá fi ọ̀nà hàn ọ́

    èmi ìbá mú ọ wá sínú ilé ìyá mi,

    ìwọ ìbá kọ́ mi.

    Èmi ìbá fi ọtí wáìnì olóòórùn dídùn fún ọ mu,

    àti oje èso pomegiranate mi.

    3 Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní abẹ́ orí mi,

    ọwọ́ ọ̀tún rẹ ìbá sì gbà mí mọ́ra.

    4 Ọmọbìnrin Jerusalẹmu, èmi pè yín ní ìjà.

    Ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè.

    Ẹ má ṣe jí i títí tí yóò fi wù ú.

  13. 29 Ọlọ́run sì fún Solomoni ní ọgbọ́n, àti òye ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, àti ìmọ̀ gbígbòòrò òye tí a kò le è fiwé iyanrìn tí ó wà létí Òkun. 30 Ọgbọ́n Solomoni sì pọ̀ ju ọgbọ́n ọkùnrin ìlà-oòrùn lọ, ó sì pọ̀ ju gbogbo ọgbọ́n Ejibiti lọ. 31 Ó sì ní òye ju gbogbo ènìyàn lọ, ju Etani, ará Esra, àti Hemani àti Kalkoli, àti Darda àwọn ọmọ Maholi lọ. Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè yíká. 32 Ó sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) òwe, àwọn orin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé márùn-ún (1,005). 33 Ó sì sọ̀rọ̀ ti igi, láti kedari tí ń bẹ ní Lebanoni dé Hísópù tí ń dàgbà lára ògiri. Ó sì tún sọ ti àwọn ẹranko àti ti àwọn ẹyẹ, àti ohun tí ń rákò àti ti ẹja. 34 Àwọn ènìyàn sì ń wá láti gbogbo orílẹ̀-èdè láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọba ayé láti wá gbọ́ nípa ọgbọ́n rẹ̀.

  14. Olùfẹ́

    9 Olùfẹ́ mi,

    mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Farao.

    10 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́,

    ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀.

    11 A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ,

    a ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀.

    Olólùfẹ́

    12 Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀,

    òróró ìkunra mi tú òórùn jáde.

    13 Ìdì òjìá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi,

    òun ó sinmi lé àárín ọmú mi.

    14 Bí ìdì ìtànná Henina ni olùfẹ́ mi rí sí mi

    láti inú ọgbà àjàrà ti En-Gedi.

  15. 4 Ó mú mi lọ sí ibi gbọ̀ngàn àsè,

    ìfẹ́ sì ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi.

    5 Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró.

    Fi èso ápù tù mi lára

    nítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.

  16. Olólùfẹ́

    16 Olùfẹ́ mi ni tèmi èmi sì ni tirẹ̀;

    Ó ń jẹ láàrín àwọn koríko lílì.

    17 Títí ìgbà ìtura ọjọ́

    títí òjìji yóò fi fò lọ,

    yípadà, olùfẹ́ mi,

    kí o sì dàbí abo egbin

    tàbí ọmọ àgbọ̀nrín

    lórí òkè Beteri.

  17. Olùfẹ́

    1 Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olólùfẹ́ mi!

    Háà, ìwọ jẹ́ arẹwà!

    Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ

    irun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́.

    Tí ó sọ̀kalẹ̀ lórí òkè Gileadi.

    2 Eyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò

    tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀;

    olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́;

    kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó da dúró.

    3 Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó;

    ẹnu rẹ̀ dùn.

    Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pomegiranate

    lábẹ́ ìbòjú rẹ.

    4 Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi,

    tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra;

    lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún (1,000) àpáta kọ́,

    gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára.

    5 Ọmú rẹ̀ méjèèjì dàbí abo egbin méjì

    tí wọ́n jẹ́ ìbejì

    tí ń jẹ láàrín ìtànná ewéko lílì.

  18. 1 Báwo ni ẹsẹ̀ rẹ ti ní ẹwà tó nínú bàtà.

    Ìwọ ọmọbìnrin ọba!

    Oríkèé itan rẹ rí bí ohun ọ̀ṣọ́

    iṣẹ́ ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà

    2 Ìdodo rẹ rí bí àwo

    tí kì í ṣe aláìní ọtí,

    ìbàdí rẹ bí òkìtì alikama

    tí a fi lílì yíká.

    3 Ọmú rẹ rí bí abo egbin méjì

    tí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín.

    4 Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín erin.

    Ojú rẹ rí bí adágún ní Heṣboni

    ní ẹ̀bá ẹnu ibodè Bati-Rabbimu.

    Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lebanoni

    tí ó kọ ojú sí Damasku.

    5 Bí òkè Karmeli ṣe ṣe adé yí àwọn òkè ká,

    bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ ṣe adé yí orí rẹ ká

    a fi àìdi irun rẹ mú ọba ní ìgbèkùn.

    6 Báwo ni ẹwà rẹ ti pọ̀ tó

    báwo ni o sì ti dára tó ìwọ olùfẹ́ mi nínú ìfẹ́?

    7 Ìdúró rẹ rí bí igi ọ̀pẹ,

    àti ọmú rẹ bí ìdì èso àjàrà.

    8 Mo ní, “Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ,

    èmi yóò di ẹ̀ka rẹ̀ mú.”

    Kí ọmú rẹ rí bí ìdì èso àjàrà,

    àti èémí imú rẹ bí i ápù.

  19. 10 Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi!

    Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ,

    òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ!

    11 Ètè rẹ ń kan dídùn bí afárá oyin, ìyàwó mi;

    wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ.

    Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lebanoni.

  20. Olùfẹ́

    13 Ìwọ tí ń gbé inú ọgbà,

    àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dẹtí sí ohùn rẹ,

    jẹ́ kí èmi náà gbọ́ ohùn rẹ!

    Olólùfẹ́

    14 Yára wá, Olùfẹ́ mi,

    kí ìwọ kí ó sì rí bí abo egbin,

    tàbí gẹ́gẹ́ bí ọmọ àgbọ̀nrín,

    lórí òkè òórùn dídùn.

  21. 16 “Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. 17  Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n kí a le ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là.

  22. 1 Solomoni ọba fẹ́ ọ̀pọ̀ àjèjì obìnrin yàtọ̀ sí ọmọbìnrin Farao, àwọn ọmọbìnrin Moabu, àti ti Ammoni, ti Edomu, ti Sidoni àti ti àwọn ọmọ Hiti. 2 Wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fẹ́ wọn níyàwó tàbí ní ọkọ, nítorí wọn yóò yí ọkàn yín padà sí òrìṣà wọn.” Síbẹ̀síbẹ̀ Solomoni fàmọ́ wọn ní ìfẹ́. 3 Ó sì ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) obìnrin, àwọn ọmọ ọba àti ọ̀ọ́dúnrún (300) àlè, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà. 4 Bí Solomoni sì ti di arúgbó, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà sí ọlọ́run mìíràn, ọkàn rẹ̀ kò sì ṣe déédé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe.

  23. Olólùfẹ́

    1 Èmi ni ìtànná Ṣaroni

    bí ìtànná lílì àwọn àfonífojì.

    Olùfẹ́

    2 Bí ìtànná lílì ní àárín ẹ̀gún

    ni olólùfẹ́ mi ní àárín àwọn wúńdíá.

  24. 7 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,

    mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú

    kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè

    kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.

  25. 4 Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣeun, ìfẹ́ kì í ṣe ìlara, ìfẹ́ kì í fẹ̀, ìfẹ́ kì í sọ̀rọ̀ ìgbéraga. 5  Ìfẹ́ kì í hùwà àìtọ́, kì í wá ohun ara rẹ̀ nìkan. Ìfẹ́ kì í bínú fùfù, ìfẹ́ kì í fi búburú ọmọ ẹnìkejì sínú. 6 Inú ìfẹ́ kì í dùn sí àìṣòótọ́. Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ a máa dùn nígbà gbogbo. 7  A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo.

    8 Ìfẹ́ kì í kùnà láé, kì í sì í yẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, wọn yóò dópin, bí ó bá ṣe ẹ̀bùn ahọ́n ni, wọn yóò dákẹ́, bí ó bá ṣe pé ìmọ̀ ni yóò di asán.

  26. 25 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un. 26 Kí òun lè sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó tí fi ọ̀rọ̀ wẹ̀ ẹ́ nínú agbada omí. 27 Kí òun lé mú un wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó ní ògo ní àìlábàwọ́n, tàbí àlébù kan, tàbí irú nǹkan bá-wọ̀n-ọn-nì: ṣùgbọ́n kí ó lè jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù. 28 Bẹ́ẹ̀ ní ó tọ́ kí àwọn ọkùnrin máa fẹ́ràn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. 29 Nítorí kò sì ẹnìkan tí ó ti kórìíra ara rẹ̀; bí kò ṣe pé kí ó máa bọ́ ọ kí ó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi sì ti ń ṣe sí ìjọ. 30 Nítorí pé àwa ni ẹ̀yà ara rẹ̀, àti tí ẹran-ara rẹ̀, àti egungun ara rẹ̀. 31  Nítorí èyí ní ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan. 32 Àṣírí ńlá ní èyí: ṣùgbọ́n èmí ń sọ nípá ti Kristi àti tí ìjọ. 33 Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yín fẹ́ràn aya rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun fúnra rẹ̀; kí aya kí ó sì bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀.

  27. 12  Nítorí náà, bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, ẹni mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nú wọ̀, ìṣoore, ìrẹ̀lẹ̀, inú tútù àti sùúrù. 13 Ẹ máa fi ara dà á fún ara yín, ẹ sì máa dáríjì ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkan: bí Kristi ti dáríjì yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó máa ṣe pẹ̀lú. 14 Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé.

    15 Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan; kí ẹ sì máa dúpẹ́. 16  Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ máa kọ́ ọ, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin sí Ọlọ́run ní ọkàn ọpẹ́. 17 Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn ní orúkọ Jesu Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run Baba nípasẹ̀ rẹ̀.

  28. 8 Kí a lọ kúrò ní Lebanoni, ìyàwó mi,

    ki a lọ kúrò ní Lebanoni.

    Àwa wò láti orí òkè Amana,

    láti orí òkè ti Seniri, àti téńté Hermoni,

    láti ibi ihò àwọn kìnnìún,

    láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn.

    9 Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;

    ìwọ ti gba ọkàn mi

    pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ,

    pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ.

  29. Olólùfẹ́

    2 Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí.

    Gbọ́! Olólùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn.

    “Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi,

    àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi,

    orí mi kún fún omi ìrì,

    irun mi kún fún òtútù òru.”

    3 Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà mi

    ṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀?

    Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi

    ṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku?

  30. 16 Báyìí ni àwa mọ̀, tí a sì gba ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa gbọ́.

    Ìfẹ́ ni Ọlọ́run; ẹni tí ó bá sì ń gbé inú ìfẹ́, ó ń gbé inú Ọlọ́run, àti Ọlọ́run nínú rẹ̀. 17  Nínú èyí ni a mú ìfẹ́ tí ó wà nínú wa pé, kí àwa bà á lè ni ìgboyà ní ọjọ́ ìdájọ́: nítorí pé bí òun tí rí, bẹ́ẹ̀ ni àwa sì rí ni ayé yìí. 18 Ìbẹ̀rù kò sí nínú ìfẹ́; ṣùgbọ́n ìfẹ́ tí ó pé ń lé ìbẹ̀rù jáde; nítorí tí ìbẹ̀rù ni ìyà nínú. Ẹni tí ó bẹ̀rù kò pé nínú ìfẹ́.

    19  Àwa fẹ́ràn rẹ̀ nítorí òun ni ó kọ́ fẹ́ràn wa. 20  Bí ẹnikẹ́ni bá wí pé, “Èmi fẹ́ràn Ọlọ́run,” tí ó sì kórìíra arákùnrin rẹ̀, èké ni: nítorí ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ tí ó rí, báwo ni yóò tí ṣe lè fẹ́ràn Ọlọ́run tí òun kò rí? 21 Òfin yìí ni àwa sì rí gbà láti ọwọ́ rẹ̀ wá, pé ẹni tí ó bá fẹ́ràn Ọlọ́run kí ó fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.

  31. Olùfẹ́

    1 Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;

    mo ti kó òjìá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ.

    Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi;

    mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi.

    Ọ̀rẹ́

    Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu,

    àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́.

  32. 37  Jesu dáhùn pé, “ ‘Fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ẹ̀mí rẹ àti gbogbo inú rẹ.’ 38 Èyí ni òfin àkọ́kọ́ àti èyí tí ó tóbi jùlọ. 39 Èkejì tí ó tún dàbí rẹ̀ ní pé, ‘Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ 40 Lórí àwọn òfin méjèèjì yìí ni gbogbo òfin àti àwọn wòlíì rọ̀ mọ́.”

  33. 16  Nípa èyí ni àwa mọ ìfẹ́ nítorí tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa, ó sì yẹ kí àwa fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará. 17 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀? 18  Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bí kò ṣe ni ìṣe àti ní òtítọ́.

    19 Àti nípa èyí ni àwa ó mọ̀ pé àwa jẹ́ ti òtítọ́, àti pé àwa ó sì fi ọkàn ara wa balẹ̀ níwájú rẹ̀.

  34. 7  Olùfẹ́, ẹ jẹ́ kí a fẹ́ràn ara wa, nítorí ìfẹ́ ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àti gbogbo ẹni tí ó bá ní ìfẹ́, a bí i nípa ti Ọlọ́run, ó sì mọ Ọlọ́run. 8 Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ kò mọ Ọlọ́run: nítorí pé ìfẹ́ ni Ọlọ́run.

  35. Olùfẹ́

    15 Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olólùfẹ́ mi!

    Háà, báwo ni o ṣe lẹ́wà tó!

    Ìwọ ní ojú ẹyẹlé.

    Olólùfẹ́

    16 Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi!

    Háà, báwo ni o ṣe wu ni!

    Ibùsùn wa ní ìtura.

    Olùfẹ́

    17 Ìtànṣán ilé wa jẹ́ ti igi kedari

    ẹkẹ́ ilé wa jẹ́ ti igi firi.

  36. 6 Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀

    tí òjìji yóò fi fò lọ,

    èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjìá

    àti sí òkè kékeré tùràrí.

    7 Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwà, olólùfẹ́ mi;

    kò sì ṣí àbàwọ́n lára rẹ.

  37. 12 Èyí ni òfin mi, pé kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn ara yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín. 13  Kò sí ẹnìkan tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé ẹnìkan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.

  38. 6 Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńlá ńlá, ń wí pé:

    “Haleluya!

    Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba.

    7  Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi,

    kí a sì fi ògo fún un.

    Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé,

    aya rẹ̀ sì ti múra tán.

    8 Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀

    wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.”

    (Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)

    9 Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”

  39. 23 Ọkùnrin náà sì wí pé,

    “Èyí ni egungun láti inú egungun mi

    àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi;

    ‘obìnrin’ ni a ó máa pè é,

    nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.”

    24  Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.

  40. 15 Ìdí àwọn asìnrú ti Solomoni ọba kójọ ni èyí; láti kọ́ ilé Olúwa àti ààfin òun tìkára rẹ̀; Millo, odi Jerusalẹmu, Hasori, Megido àti Geseri. 16 Farao ọba Ejibiti sì ti kọlu Geseri, ó sì ti fi iná sun ún, ó sì pa àwọn ará Kenaani tí ń gbé ìlú náà, ó sì fi ta ọmọbìnrin rẹ̀, aya Solomoni lọ́rẹ. 17 Solomoni sì tún Geseri kọ́, àti Beti-Horoni ìsàlẹ̀, 18 àti Baalati àti Tadmori ní aginjù, láàrín rẹ̀, 19 àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti ìlú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ìlú fún àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, àti èyí tí ó ń fẹ́ láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ tí ó ń ṣe àkóso.

  41. Olólùfẹ́

    3 Bí igi ápù láàrín àwọn igi inú igbó,

    ni olólùfẹ́ mí láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin.

    Mo fi ayọ̀ jókòó ní abẹ́ òjìji rẹ̀,

    èso rẹ̀ sì dùn mọ́ mi ní ẹnu.

  42. 8 Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi!

    Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀.

    Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá,

    òun bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké.

    9 Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín.

    Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa

    Ó yọjú ní ojú fèrèsé

    Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà.

  43. 16 Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀

    ó wu ni pátápátá.

    Háà! Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu.

    Èyí ni olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi.

  44. 30 Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ẹ̀mí rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, èyí ní òfin kìn-ín-ní.’ 31  Èkejì ni pé: ‘Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tó ga ju méjèèjì yìí lọ.”

    32 Olùkọ́ òfin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, ìwọ sọ òtítọ́ nípa pé Ọlọ́run kan ni ó ń bẹ, àti pé kò sí òmíràn àfi òun nìkan. 33  Àti kí a fi gbogbo àyà, àti gbogbo òye, àti gbogbo ọkàn àti gbogbo agbára fẹ́ ẹ, àti fẹ́ ọmọnìkejì ẹni bí ara ẹni, ó ju gbogbo ẹbọ sísun, àti ẹbọ lọ.”

  45. 2  Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo àti inú tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ẹ máa fi ìfẹ́ faradà fún ẹnìkejì yín. 3 Kí ẹ sì máa làkàkà láti pa ìṣọ̀kan Ẹ̀mí mọ́ ni ìdàpọ̀ àlàáfíà.

  46. 8 Nítorí Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí mi, bí mo ti ń ṣàfẹ́rí yín gidigidi nínú ìfẹ́ Jesu Kristi.

    9 Èyí sì ni àdúrà mi: pé kí ìfẹ́ yín lè máa pọ̀ síwájú àti síwájú sí i nínú ìfẹ́ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀,

  47. 1 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín; pé, bí ẹnikẹ́ni ba tilẹ̀ ń ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láì sọ̀rọ̀ nípa ìwà àwọn aya wọn. 2 Nígbà tí wọ́n bá ń wo ìwà rere pẹ̀lú ẹ̀rù yín. 3 Kí ọ̀ṣọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀ṣọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀; 4 ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó fi ara sin ní ọkàn, nínú ọ̀ṣọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run. 5 Nítorí báyìí ni àwọn obìnrin mímọ́ ìgbàanì pẹ̀lú, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, wọn a máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọn. 6  Gẹ́gẹ́ bí Sara ti gbọ́ ti Abrahamu, tí ó ń pè é ní olúwa rẹ̀. Ọmọbìnrin ẹni tí ẹ̀yin jẹ́, bí ẹ̀yin bá ń ṣe rere, tí ohunkóhun kò sí dẹ́rùbà yín.

  48. 20 Jakọbu sì ṣiṣẹ́ sin Labani fún ọdún méje láti fẹ́ Rakeli. Àwọn ọdún wọ̀nyí sì dàbí ọjọ́ díẹ̀ lára rẹ̀, nítorí ó fẹ́ràn rẹ̀.

  49. 18  “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ. Èmi ni Olúwa.

  50. 26 Solomoni ọba sì túnṣe òwò ọkọ̀ ní Esioni-Geberi, tí ó wà ní ẹ̀bá Elati ní Edomu, létí Òkun Pupa. 27 Hiramu sì rán àwọn ènìyàn rẹ̀, àwọn atukọ̀ tí ó mọ Òkun, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Solomoni. 28 Wọ́n sì dé Ofiri, wọ́n sì mú irinwó ó lé ogún (420) tálẹ́ǹtì wúrà, tí wọ́n ti gbà wá fún Solomoni ọba.

  51. 1 Benjamini jẹ́ baba:

    Bela àkọ́bí rẹ̀,

    Aṣbeli ọmọkùnrin ni ẹ̀ẹ̀kejì, Ahara ẹ̀ẹ̀kẹ́ta,

    2 Noha ẹ̀ẹ̀kẹrin àti Rafa ẹ̀karùnún.

    3 Àwọn ọmọ Bela ni,

    Adari, Gera, Abihudi, 4 Abiṣua, Naamani, Ahoa, 5 Gera, Ṣefufani àti Huramu.

    6 Wọ̀nyí ni àwọn ìran ọmọ Ehudu, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé tí ó ń gbé ní Geba tí a sì lé kúrò lọ sí Manahati:

  52. 15 Mu omi láti inú kànga tìrẹ,

    omi tí ń sàn láti inú kànga rẹ.

    16 Ó ha yẹ kí omi ìsun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nà

    àti odò tí ń sàn lọ sí àárín ọjà?

    17 Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan,

    má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjèjì láéláé.

    18 Jẹ́ kí orísun rẹ kí ó ní ìbùkún;

    kí ìwọ ó sì máa yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ.

    19 Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ,

    jẹ́ kí ọmú rẹ̀ kí ó máa fi ayọ̀ fún ọ nígbà gbogbo,

    kí o sì máa yọ̀ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbàkígbà.

    20 Ọmọ mi, èéṣe tí ìwọ ó fi máa yọ̀ nínú ìfẹ́ obìnrin panṣágà,

    tí ìwọ ó sì fi dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn?

  53. 13 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràrí

    tí ó sun òórùn tùràrí dídùn

    Ètè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílì

    ó ń kán òjìá olóòórùn dídùn.

  54. 37 “Ẹni tí ó bá fẹ́ baba rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi, ẹni tí ó ba fẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi. 38 Ẹni tí kò bá gbé àgbélébùú rẹ̀ kí ó tẹ̀lé mi kò yẹ ní tèmi. 39 Ẹni tí ó bá wa ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nú nítorí tèmi ni yóò rí i.

  55. 15 “Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́.

  56. 6 Nítorí ìgbà tí àwa jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó yẹ, Kristi kú fún àwa aláìwà-bí-Ọlọ́run. 7 Nítorí ó ṣọ̀wọ́n kí ẹnìkan tó kú fún olódodo, ṣùgbọ́n fún ènìyàn rere bóyá ẹlòmíràn tilẹ̀ lè dábàá láti kú. 8  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.

    9  Mélòó mélòó sì ni tí a dá wa láre nísinsin yìí nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ó gbà wá là kúrò nínú ìbínú nípasẹ̀ rẹ̀. 10  Ǹjẹ́, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀. 11  Kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa ń ṣògo nínú Ọlọ́run nípa Olúwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí àwa ti rí ìlàjà gbà nísinsin yìí.

  57. 9 Kí ìfẹ́ kí ó wà ní àìṣẹ̀tàn. Ẹ máa takété sí ohun tí í ṣe búburú; ẹ fi ara mọ́ ohun tí í ṣe rere. 10 Ní ti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín; ní ti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣáájú.

  58. 9  Ṣùgbọ́n bí wọ́n kò bá lè mú ara dúró, kí wọ́n gbéyàwó tàbí kí wọ́n fẹ́ ọkọ, nítorí pé ó sàn láti gbéyàwó jù láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ.

  59. 23 Ṣùgbọ́n èmi n ṣiyèméjì, nítorí ti èmi fẹ́ láti lọ kúrò nínú ayé yìí, láti wà lọ́dọ̀ Kristi; nítorí ó dára púpọ̀ jù: 24 síbẹ̀ láti wà láààyè jẹ́ àǹfààní nítorí tiyín. 25 Bí èyí sì ti dá mi lójú, mo mọ̀ pé èmi ó dúró, èmi ó sì máa wà pẹ̀lú yín fún ìtẹ̀síwájú àti ayọ̀ yín nínú ìgbàgbọ́, 26 kí ìṣògo yín kí ó lè di púpọ̀ gidigidi nínú Jesu Kristi, àti nínú mi nípa ìpadà wá mi sọ́dọ̀ yín.

  60. 12 A sì béèrè pé, kí Ọlọ́run ràn yín lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ìfẹ́ yín yóò fi gbòòrò tí yóò sì sàn kan olúkúlùkù yín. Èyí yóò jẹ́ àpẹẹrẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ àwa náà ṣe sàn kan ẹ̀yin náà. 13  Kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀ ní àìlábùkù nínú ìwà mímọ́ níwájú Ọlọ́run àti Baba wa. Nígbà náà, ẹ ó ní ìgboyà láti dúró níwájú rẹ̀ láìṣẹ̀, ní ọjọ́ tí Olúwa wa Jesu Kristi yóò padà wá pẹ̀lú àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀.

  61. 8 Ẹni tí ẹ̀yin fẹ́ láìrí, ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i nísinsin yìí ẹ̀yin sì ń yọ ayọ̀ tí a kò lè fi ẹnu sọ, tí ó sì kún fún ògo;

  62. 8 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrín ara yín, nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.

  63. 4 Síbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹ sílẹ̀.