21 Bible Verses About True Love

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About True Love
  1. Olùfẹ́

    9 Olùfẹ́ mi,

    mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Farao.

    10 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́,

    ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀.

    11 A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ,

    a ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀.

    Olólùfẹ́

    12 Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀,

    òróró ìkunra mi tú òórùn jáde.

    13 Ìdì òjìá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi,

    òun ó sinmi lé àárín ọmú mi.

    14 Bí ìdì ìtànná Henina ni olùfẹ́ mi rí sí mi

    láti inú ọgbà àjàrà ti En-Gedi.

    Olùfẹ́

    15 Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olólùfẹ́ mi!

    Háà, báwo ni o ṣe lẹ́wà tó!

    Ìwọ ní ojú ẹyẹlé.

    Olólùfẹ́

    16 Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi!

    Háà, báwo ni o ṣe wu ni!

    Ibùsùn wa ní ìtura.

    Olùfẹ́

    17 Ìtànṣán ilé wa jẹ́ ti igi kedari

    ẹkẹ́ ilé wa jẹ́ ti igi firi.

  2. 18 “Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi,

    mẹ́rin tí kò yé mi,

    19 ipa ẹyẹ idì ní òfúrufú

    ipa ejò lórí àpáta

    ipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami Òkun

    àti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúńdíá lọ́wọ́.

  3. 6 Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì

    bí èdìdì lé apá rẹ;

    nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú,

    ìjowú sì le bí isà òkú

    jíjò rẹ̀ rí bí jíjò iná,

    gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́-iná Olúwa.

    7 Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́;

    bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ.

    Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́,

    ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀,

    a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátápátá.

  4. Olùfẹ́

    1 Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olólùfẹ́ mi!

    Háà, ìwọ jẹ́ arẹwà!

    Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ

    irun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́.

    Tí ó sọ̀kalẹ̀ lórí òkè Gileadi.

    2 Eyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò

    tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀;

    olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́;

    kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó da dúró.

    3 Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó;

    ẹnu rẹ̀ dùn.

    Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pomegiranate

    lábẹ́ ìbòjú rẹ.

    4 Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi,

    tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra;

    lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún (1,000) àpáta kọ́,

    gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára.

    5 Ọmú rẹ̀ méjèèjì dàbí abo egbin méjì

    tí wọ́n jẹ́ ìbejì

    tí ń jẹ láàrín ìtànná ewéko lílì.

    6 Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀

    tí òjìji yóò fi fò lọ,

    èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjìá

    àti sí òkè kékeré tùràrí.

    7 Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwà, olólùfẹ́ mi;

    kò sì ṣí àbàwọ́n lára rẹ.

    8 Kí a lọ kúrò ní Lebanoni, ìyàwó mi,

    ki a lọ kúrò ní Lebanoni.

    Àwa wò láti orí òkè Amana,

    láti orí òkè ti Seniri, àti téńté Hermoni,

    láti ibi ihò àwọn kìnnìún,

    láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn.

    9 Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;

    ìwọ ti gba ọkàn mi

    pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ,

    pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ.

    10 Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi!

    Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ,

    òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ!

    11 Ètè rẹ ń kan dídùn bí afárá oyin, ìyàwó mi;

    wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ.

    Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lebanoni.

    12 Arábìnrin mi ni ọgbà tí a sọ, arábìnrin mi, ìyàwó mi;

    ìsun tí a sé mọ́, orísun tí a fi èdìdì dì.

    13 Ohun ọ̀gbìn rẹ àgbàlá pomegiranate ni

    ti òun ti àṣàyàn èso; kipiresi àti nadi,

    14 nadi àti Safironi,

    kalamusi àti kinamoni,

    àti gbogbo igi olóòórùn dídùn,

    òjìá àti aloe

    pẹ̀lú irú wọn.

    15 Ìwọ ni ọgbà orísun, kànga omi ìyè,

    ìṣàn omi láti Lebanoni wá.

    Olólùfẹ́

    16 Jí ìwọ afẹ́fẹ́ àríwá

    kí o sì wá, afẹ́fẹ́ gúúsù!

    Fẹ́ lórí ọgbà mi,

    kí àwọn òórùn dídùn inú rẹ lè rùn jáde.

    Jẹ́ kí olùfẹ́ mi wá sínú ọgbà a rẹ̀

    kí ó sì jẹ àṣàyàn èso rẹ̀.

  5. 8 Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi!

    Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀.

    Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá,

    òun bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké.

    9 Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín.

    Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa

    Ó yọjú ní ojú fèrèsé

    Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà.

    10 Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé,

    “Dìde, Olólùfẹ́ mi,

    arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi.

    11 Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá;

    òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ.

    12 Àwọn òdòdó fi ara hàn lórí ilẹ̀

    àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé

    a sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa.

    13 Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde,

    àwọn àjàrà nípa ìtànná wọ́n fún ni ní òórùn dídùn.

    Dìde, wá, Olólùfẹ́ mi,

    Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.”

    Olùfẹ́

    14 Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta,

    ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga,

    fi ojú rẹ hàn mí,

    jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ;

    nítorí tí ohùn rẹ dùn,

    tí ojú rẹ sì ní ẹwà.

    15 Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀,

    àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké

    tí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́,

    àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtànná.

    Olólùfẹ́

    16 Olùfẹ́ mi ni tèmi èmi sì ni tirẹ̀;

    Ó ń jẹ láàrín àwọn koríko lílì.

    17 Títí ìgbà ìtura ọjọ́

    títí òjìji yóò fi fò lọ,

    yípadà, olùfẹ́ mi,

    kí o sì dàbí abo egbin

    tàbí ọmọ àgbọ̀nrín

    lórí òkè Beteri.

  6. Olólùfẹ́

    2 Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí.

    Gbọ́! Olólùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn.

    “Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi,

    àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi,

    orí mi kún fún omi ìrì,

    irun mi kún fún òtútù òru.”

    3 Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà mi

    ṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀?

    Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi

    ṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku?

    4 Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ìlẹ̀kùn

    inú mi sì yọ́ sí i.

    5 Èmi dìde láti ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,

    òjìá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi,

    òjìá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń sàn

    sí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn.

    6 Èmi ṣí ìlẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,

    ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọ

    ọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀.

    Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i.

    Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn.

    7 Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi

    bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká.

    Wọ́n nà mí, wọ́n sá mi lọ́gbẹ́;

    wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi.

    Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi!

    8 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo bẹ̀ yín

    bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi,

    kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un?

    Ẹ wí fún un pé àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mi.

    Ọ̀rẹ́

    9 Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ,

    ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin?

    Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ

    tí ìwọ fi ń fi wá bú bẹ́ẹ̀?

    Olólùfẹ́

    10 Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́n

    ó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lọ.

    11 Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọ

    ìdì irun rẹ̀ rí bí i imọ̀ ọ̀pẹ

    ó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò.

    12 Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbà

    ní ẹ̀bá odò tí ń sàn,

    tí a fi wàrà wẹ̀,

    tí ó jì, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́.

    13 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràrí

    tí ó sun òórùn tùràrí dídùn

    Ètè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílì

    ó ń kán òjìá olóòórùn dídùn.

    14 Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà,

    tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíká.

    Ara rẹ̀ rí bí i eyín erin dídán

    tí a fi safire ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.

    15 Ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí i òpó mabu

    tí a gbé ka ihò ìtẹ̀bọ̀ wúrà dáradára.

    Ìrísí rẹ̀ rí bí igi kedari Lebanoni,

    tí dídára rẹ̀ kò ní ẹgbẹ́.

  7. Olólùfẹ́

    1 Èmi ni ìtànná Ṣaroni

    bí ìtànná lílì àwọn àfonífojì.

    Olùfẹ́

    2 Bí ìtànná lílì ní àárín ẹ̀gún

    ni olólùfẹ́ mi ní àárín àwọn wúńdíá.

    Olólùfẹ́

    3 Bí igi ápù láàrín àwọn igi inú igbó,

    ni olólùfẹ́ mí láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin.

    Mo fi ayọ̀ jókòó ní abẹ́ òjìji rẹ̀,

    èso rẹ̀ sì dùn mọ́ mi ní ẹnu.

    4 Ó mú mi lọ sí ibi gbọ̀ngàn àsè,

    ìfẹ́ sì ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi.

    5 Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró.

    Fi èso ápù tù mi lára

    nítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.

  8. 7 Ìdúró rẹ rí bí igi ọ̀pẹ,

    àti ọmú rẹ bí ìdì èso àjàrà.

    8 Mo ní, “Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ,

    èmi yóò di ẹ̀ka rẹ̀ mú.”

    Kí ọmú rẹ rí bí ìdì èso àjàrà,

    àti èémí imú rẹ bí i ápù.

    9 Àti ìfẹnukonu rẹ rí bí ọtí wáìnì tí ó dára jùlọ.

    Olólùfẹ́

    Tí ó kúnná tí ó sì dùn,

    tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀.

    10 Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe,

    èmi sì ni ẹni tí ó wù ú.

    11 Wá, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí a lọ sí ibi pápá,

    jẹ́ kí a lo àṣálẹ́ ní àwọn ìletò.

    12 Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtù

    láti wo bí àjàrà rúwé

    bí ìtànná àjàrà bá là.

    Àti bí pomegiranate bá ti rudi,

    níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.

    13 Àwọn èso mándrákì mú òórùn wọn jáde

    ní ẹnu-ọ̀nà wa ni onírúurú àṣàyàn èso,

    èso tuntun àti ọjọ́ pípẹ́

    tí mo ti kó pamọ́ fún ọ, olùfẹ́ mi.

  9. 1 Báwo ni ẹsẹ̀ rẹ ti ní ẹwà tó nínú bàtà.

    Ìwọ ọmọbìnrin ọba!

    Oríkèé itan rẹ rí bí ohun ọ̀ṣọ́

    iṣẹ́ ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà

    2 Ìdodo rẹ rí bí àwo

    tí kì í ṣe aláìní ọtí,

    ìbàdí rẹ bí òkìtì alikama

    tí a fi lílì yíká.

    3 Ọmú rẹ rí bí abo egbin méjì

    tí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín.

    4 Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín erin.

    Ojú rẹ rí bí adágún ní Heṣboni

    ní ẹ̀bá ẹnu ibodè Bati-Rabbimu.

    Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lebanoni

    tí ó kọ ojú sí Damasku.

    5 Bí òkè Karmeli ṣe ṣe adé yí àwọn òkè ká,

    bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ ṣe adé yí orí rẹ ká

    a fi àìdi irun rẹ mú ọba ní ìgbèkùn.

  10. 1  Bí èmi tilẹ̀ lè sọ oríṣìíríṣìí èdè tí ènìyàn àti ti angẹli, tí n kò bá sì ní ìfẹ́, mo kàn ń pariwo bí ago lásán ni tàbí bí i kimbali olóhùn gooro. 2  Bí mo bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo sì ní òye gbogbo ohun ìjìnlẹ̀, àti gbogbo ìmọ̀, bí mo sì ni gbogbo ìgbàgbọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè ṣí àwọn òkè ńlá nídìí, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi kò jẹ nǹkan kan. 3 Bí mo bá fi gbogbo nǹkan tí mo ní tọrẹ fún àwọn aláìní, tí mo sì fi ara mi fún ni láti sùn ṣùgbọ́n tí n kò ní ìfẹ́, kò ní èrè kan fún mi.

    4 Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣeun, ìfẹ́ kì í ṣe ìlara, ìfẹ́ kì í fẹ̀, ìfẹ́ kì í sọ̀rọ̀ ìgbéraga. 5  Ìfẹ́ kì í hùwà àìtọ́, kì í wá ohun ara rẹ̀ nìkan. Ìfẹ́ kì í bínú fùfù, ìfẹ́ kì í fi búburú ọmọ ẹnìkejì sínú. 6 Inú ìfẹ́ kì í dùn sí àìṣòótọ́. Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ a máa dùn nígbà gbogbo. 7  A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo.

    8 Ìfẹ́ kì í kùnà láé, kì í sì í yẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, wọn yóò dópin, bí ó bá ṣe ẹ̀bùn ahọ́n ni, wọn yóò dákẹ́, bí ó bá ṣe pé ìmọ̀ ni yóò di asán.

  11. 7 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,

    mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú

    kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè

    kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.

  12. 21 Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran-ara bò ó padà. 22 Olúwa Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, Ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá.

    23 Ọkùnrin náà sì wí pé,

    “Èyí ni egungun láti inú egungun mi

    àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi;

    ‘obìnrin’ ni a ó máa pè é,

    nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.”

    24  Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.

    25 Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì wà ní ìhòhò, ojú kò sì tì wọ́n.

  13. 16 Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀

    ó wu ni pátápátá.

    Háà! Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu.

    Èyí ni olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi.

  14. 6 Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńlá ńlá, ń wí pé:

    “Haleluya!

    Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba.

    7  Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi,

    kí a sì fi ògo fún un.

    Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé,

    aya rẹ̀ sì ti múra tán.

    8 Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀

    wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.”

    (Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)

    9 Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”

    10 Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jesu mú. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jesu ni ìsọtẹ́lẹ̀.”

  15. 18 Ìbẹ̀rù kò sí nínú ìfẹ́; ṣùgbọ́n ìfẹ́ tí ó pé ń lé ìbẹ̀rù jáde; nítorí tí ìbẹ̀rù ni ìyà nínú. Ẹni tí ó bẹ̀rù kò pé nínú ìfẹ́.

    19  Àwa fẹ́ràn rẹ̀ nítorí òun ni ó kọ́ fẹ́ràn wa.

  16. 6 Báwo ni ẹwà rẹ ti pọ̀ tó

    báwo ni o sì ti dára tó ìwọ olùfẹ́ mi nínú ìfẹ́?

  17. 1  Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn

    orin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀.

    Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan

    ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú.

  18. 16  Nípa èyí ni àwa mọ ìfẹ́ nítorí tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa, ó sì yẹ kí àwa fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará. 17 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀? 18  Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bí kò ṣe ni ìṣe àti ní òtítọ́.

    19 Àti nípa èyí ni àwa ó mọ̀ pé àwa jẹ́ ti òtítọ́, àti pé àwa ó sì fi ọkàn ara wa balẹ̀ níwájú rẹ̀. 20 Nínú ohunkóhun tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi; nítorí pé Ọlọ́run tóbi ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.

  19. 8 Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ kò mọ Ọlọ́run: nítorí pé ìfẹ́ ni Ọlọ́run.

  20. 36 Ó wí pé, “Olùkọ́ èwo ni ó ga jùlọ nínú àwọn òfin?”

    37  Jesu dáhùn pé, “ ‘Fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ẹ̀mí rẹ àti gbogbo inú rẹ.’ 38 Èyí ni òfin àkọ́kọ́ àti èyí tí ó tóbi jùlọ. 39 Èkejì tí ó tún dàbí rẹ̀ ní pé, ‘Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’

  21. 8 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrín ara yín, nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.