41 Bible Verses About Bad Friends

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Bad Friends
  1. 33 Kí a má tàn yín jẹ́, “Ẹgbẹ́ búburú bá ìwà rere jẹ́.”

  2. 12 Èyí ni òfin mi, pé kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn ara yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín. 13  Kò sí ẹnìkan tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé ẹnìkan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. 14  Ọ̀rẹ́ mi ni ẹ̀yin ń ṣe, bí ẹ bá ṣe ohun tí èmi pàṣẹ fún yín. 15 Èmi kò pè yín ní ọmọ ọ̀dọ̀ mọ́; nítorí ọmọ ọ̀dọ̀ kò mọ ohun tí olúwa rẹ̀ ń ṣe, ṣùgbọ́n èmi pè yín ní ọ̀rẹ́ nítorí ohun gbogbo tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá, mo ti fihàn fún yín. 16  Kì í ṣe ẹ̀yin ni ó yàn mí, ṣùgbọ́n èmi ni ó yàn yín, mo sì fi yín sípò, kí ẹ̀yin kí ó lè lọ, kí ẹ sì so èso, àti kí èso yín lè dúró; kí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, kí ó lè fi í fún yín.

  3. 17 Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo,

    arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú.

  4. 24 Má ṣe bá oníbìínú ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́;

    má sì ṣe bá ọkùnrin onínú-fùfù rìn.

    25 Kí ìwọ má ba à kọ́ ìwà rẹ̀, ìwọ a sì gba ìkẹ́kùn fún ara rẹ.

    26 Má ṣe wà nínú àwọn tí ń ṣe ìgbọ̀nwọ́,

    tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè.

    27 Bí ìwọ kò bá ní nǹkan tí ìwọ ó fi san,

    nítorí kín ni yóò ṣe gba ẹni rẹ kúrò lábẹ́ rẹ?

  5. 19 Ìfẹ́ tí a mú ṣẹ dùn mọ́ ọkàn

    ṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi.

    20 Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n

    ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.

    21 Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀,

    ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo.

  6. 5 Ìbániwí gbangba sàn

    ju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.

    6 Òtítọ́ ni ọgbẹ́ ọ̀rẹ́,

    ṣùgbọ́n ìfẹnukonu ọ̀tá ni ẹ̀tàn.

  7. 24 Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parun,

    ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó súnmọ́ ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin.

  8. 26 Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́

    ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà.

  9. 28 Aláyídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀

    olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ní yà.

    29 Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀

    ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára.

  10. 9 Ìpara olóòórùn dídùn àti tùràrí ń mú ayọ̀ wá sínú ọkàn

    bẹ́ẹ̀ ni inú dídùn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń wá láti inú ìmọ̀ràn tí ó ṣàkóso.

    10 Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀,

    má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdààmú dé bá ọ

    ó sàn kí o jẹ́ aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà sí ni.

  11. 17 Bí irin tí ń pọ́n irin mú

    bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú.

  12. 9 Ẹni méjì sàn ju ẹnìkan,

    nítorí wọ́n ní èrè rere fún làálàá wọn.

    10 Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀,

    ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fà á sókè,

    ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubú

    tí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn án lọ́wọ́!

    11 Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá sùn pọ̀, wọn yóò móoru.

    Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru?

    12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan,

    àwọn méjì le è gbìjà ara wọn,

    ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn ún yára fà já.

  13. 9 Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i.

    Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì ní yà.

  14. 4 Ẹ̀yin panṣágà ọkùnrin, àti panṣágà obìnrin, ẹ kò mọ̀ pé ìbárẹ́ ayé ìṣọ̀tá Ọlọ́run ni? Nítorí náà ẹni tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé di ọ̀tá Ọlọ́run.

  15. 12 Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi,

    èmi yóò fi ara mọ́ ọn;

    tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi,

    èmi ìbá sá pamọ́ fún un.

    13 Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi,

    ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi,

    14 pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀,

    bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run.

  16. 6 Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá,

    ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye.

    7 Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn,

    nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀.

  17. 5 Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé,

    “Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”

    6 Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,

    wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀;

    nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.

    7 Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;

    èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,

    8 wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin

    àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,

    kì yóò dìde mọ́.”

    9  Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,

    ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,

    tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.

  18. 20 Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ rẹ̀;

    ó ti ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́.

    21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́,

    ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀;

    ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ,

    ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn.

  19. 16 Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀, àdúrà mi ni kí a má ṣe kà á sí wọn lọ́rùn.

  20. 5 Ẹ má ṣe gba ọ̀rẹ́ kan gbọ́;

    ẹ má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé amọ̀nà kankan.

    Pa ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ fún ẹni

    tí ó sùn ní oókan àyà rẹ.

    6  Nítorí tí ọmọkùnrin kò bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀,

    ọmọbìnrin sì dìde sí ìyá rẹ̀,

    aya ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀,

    ọ̀tá olúkúlùkù ni àwọn ará ilé rẹ̀.

  21. 16 Ǹjẹ́ mo ha di ọ̀tá yín nítorí mo sọ òtítọ́ fún yín bí?

    17 Wọ́n ń fi ìtara wá yin, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún rere; wọ́n ń fẹ́ já yin kúrò, kí ẹ̀yin lè máa wá wọn. 18 Ṣùgbọ́n ó dára láti máa fi ìtara wá ni fún ohun rere nígbà gbogbo, kì í sì í ṣe nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín nìkan. 19  Ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèké, ẹ̀yin tí mo tún ń rọbí títí a ó fi ṣe ẹ̀dá Kristi nínú yín. 20 Ìbá wù mí láti wà lọ́dọ̀ yín nísinsin yìí, kí èmi sì yí ohùn mi padà nítorí pé mo dààmú nítorí yín.

  22. 10  Nítorí Dema ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí ó ń fẹ́ ayé yìí, ó sì lọ sí Tẹsalonika; Kreskeni sí Galatia, Titu sí Dalimatia.

  23. 16  Nípa èyí ni àwa mọ ìfẹ́ nítorí tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa, ó sì yẹ kí àwa fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará. 17 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀? 18  Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bí kò ṣe ni ìṣe àti ní òtítọ́.

  24. 6 Bí arákùnrin tìrẹ gan an ọmọ ìyá rẹ tàbí ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí obìnrin, aya tí o fẹ́ràn jù, tàbí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ bá tàn ọ́ jẹ níkọ̀kọ̀ wí pé, “Jẹ́ kí a lọ sin ọlọ́run mìíràn” (ọlọ́run tí ìwọ tàbí baba rẹ kò mọ̀, 7 ọlọ́run àwọn tí ó wà láyìíká yín, yálà wọ́n jìnnà tàbí wọ́n wà nítòsí, láti òpin ilẹ̀ kan dé òmíràn), 8 má ṣe fetí sí i, má sì dá sí i, má ṣe dáàbò bò ó. 9 Ṣùgbọ́n pípa ni kí o pa á. Ọwọ́ rẹ ni yóò kọ́kọ́ wà lára rẹ̀ láti pa á, lẹ́yìn náà ọwọ́ gbogbo ènìyàn. 10 Sọ ọ́ ní òkúta pa nítorí pé ó gbìyànjú láti fà ọ́ kúrò lẹ́yìn Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó mú ọ jáde ti Ejibiti wá kúrò ní oko ẹrú. 11 Gbogbo Israẹli yóò sì gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n, kò sì sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí yóò dán irú ibi bẹ́ẹ̀ wò mọ́.

  25. 11 Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹ́ta gbúròó gbogbo ibi tí ó bá a, wọ́n wá, olúkúlùkù láti ibùjókòó rẹ̀; Elifasi, ara Temani àti Bilidadi, ará Ṣuhi, àti Sofari, ará Naama: nítorí pé wọ́n ti dájọ́ ìpàdé pọ̀ láti bá a ṣọ̀fọ̀, àti láti ṣìpẹ̀ fún un. 12 Nígbà tí wọ́n gbójú wọn wò ní òkèrè réré, tí wọ́n kò sì mọ̀ ọ́n, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sọkún: olúkúlùkù sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, wọ́n sì ku erùpẹ̀ sí ojú ọ̀run, wọ́n sì tẹ́ orí gbà á. 13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jókòó tì í ní inú erùpẹ̀ ní ọjọ́ méje ti ọ̀sán ti òru, ẹnikẹ́ni kò sì bá a sọ ọ̀rọ̀ kan, nítorí tí wọ́n ti rí i pé ìbànújẹ́ rẹ̀ pọ̀ jọjọ.

  26. 29 Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè fún ọ kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé, ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì. 30 Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì.

  27. 14 “Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá,

    kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódùmarè sílẹ̀?

    15 Àwọn ará mi dàbí odò tí kò ṣe gbẹ́kẹ̀lé

    bí ìṣàn omi odò, wọ́n sàn kọjá lọ.

    16 Tí ó dúdú nítorí omi dídì,

    àti níbi tí yìnyín dídì gbé di yíyọ́.

    17 Nígbàkígbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ sàn lọ,

    nígbà tí oòrùn bá mú, wọn a sì gbẹ kúrò ni ipò wọn.

  28. 19 Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi kórìíra mi,

    àwọn olùfẹ́ mi sì kẹ̀yìndà mí.

  29. 8 Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹ,

    má ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá rẹ sílẹ̀.

    9 Wọn yóò jẹ́ òdòdó ẹ̀yẹ olóòórùn dídùn lórí rẹ

    àti ọ̀ṣọ́ tí ó dára yí ọrùn rẹ ká.

    10 Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́,

    má ṣe gbà fún wọn.

    11 Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa;

    jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan,

    jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí;

    12 jẹ́ ká gbé wọn mì láààyè, bí ibojì òkú,

    àti lódidi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò;

    13 a ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí

    a ó sì fi ìkógun kún inú ilé wa,

    14 da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ àárín wa,

    a ó sì jọ pawó sínú àpò kan náà,”

  30. 1 Háà! Orí ìbá jẹ́ orísun omi

    kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé!

    Èmi yóò sì sọkún tọ̀sán tòru

    nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.

    2 Háà, èmi ìbá ní ni aginjù

    ilé àgbàwọ̀ fún àwọn arìnrìn-àjò,

    kí n ba à lè fi àwọn ènìyàn mi sílẹ̀

    kí n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn:

    nítorí gbogbo wọn jẹ́ panṣágà

    àjọ aláìṣòótọ́ ènìyàn.

    3 Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀

    bí ọfà láti fi pa irọ́;

    kì í ṣe nípa òtítọ́

    ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà.

    Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn;

    wọn kò sì náání mi,

    ní Olúwa wí.

    4 “Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ;

    má ṣe gbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹ.

    Nítorí pé oníkálùkù arákùnrin jẹ́ atannijẹ,

    oníkálùkù ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́.

    5 Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì ṣí ẹni

    tó sọ òtítọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn

    láti máa purọ́. Wọ́n sọ ara wọn

    di onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀

  31. 14  Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn aposteli méjìlá ti à ń pè ní Judasi Iskariotu lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 15  Òun sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin yóò san fún mi bí mo bá fi Jesu lé yín lọ́wọ́?” Wọ́n sì fún un ní ọgbọ́n owó fàdákà. Ó sì gbà á. 16 Láti ìgbà náà lọ ni Judasi ti bẹ̀rẹ̀ sí i wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.

  32. 11  Ṣùgbọ́n nísinsin yìí mo kọ̀wé sí i yín pé, bí ẹnikẹ́ni tí a pe rẹ̀ ni arákùnrin bá jẹ́ àgbèrè, tàbí wọ̀bìà, tàbí abọ̀rìṣà, àti ẹlẹ́gàn, tàbí ọ̀mùtípara, tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà. Kí ẹ tilẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.

    12  Nítorí èwo ni tèmi láti máa ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń bẹ lóde? Kì í ha ṣe àwọn tí ó wà nínú ni ẹ̀yin ṣe ìdájọ́ wọn?

  33. 29 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìdíbàjẹ́ kan ti ẹnu yín jáde, ṣùgbọ́n irú èyí tí ó lè ràn ìdàgbàsókè wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n nílò, kí ó lè máa fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn tí ń gbọ́. 30 Ẹ má sì ṣe mú Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run bínú, ẹni tí a fi ṣe èdìdì yín dé ọjọ́ ìdáǹdè. 31 Gbogbo ìwà kíkorò àti ìbínú, àti ìrunú, àti ariwo, àti ọ̀rọ̀ búburú ni kí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, pẹ̀lú gbogbo àrankàn. 32 Ẹ máa ṣoore fún ọmọnìkejì yín, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run nínú Kristi ti dáríjì yín.

  34. ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ

    1  Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,

    tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,

    ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,

    tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.

    2 Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa

    àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.

    3 Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,

    tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀

    tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.

    Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

    4 Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!

    Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà

    tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.

  35. 11 Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi,

    àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè.

  36. 6 Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè;

    rìn ní ọ̀nà òye.

  37. 4 Ọrọ̀ máa ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀;

    ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ tálákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

  38. 16 “Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. 17  Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n kí a le ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là.

  39. 13  Kò sí ìdánwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọ́run, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin ba à lè faradà á.

  40. 7 Kí a má ṣe tàn yín jẹ; a kò lè gan Ọlọ́run: nítorí ohunkóhun tí ènìyàn bá fúnrúgbìn, òhun ni yóò sì ká.

  41. 6 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ: nítorí nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ní ìbínú Ọlọ́run fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn.