68 Bible Verses About The Tongue

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About The Tongue
  1. 2 Nítorí nínú ohun púpọ̀ ni gbogbo wa ń ṣe àṣìṣe. Bí ẹnìkan kò bá ṣì ṣe nínú ọ̀rọ̀, òun náà ni ẹni pípé, òun ni ó sì le kó gbogbo ara ní ìjánu.

    3 Bí a bá sì fi ìjánu bọ ẹṣin lẹ́nu, kí wọn kí ó le gbọ́ tiwa, gbogbo ara wọn ni àwa sì ń tì kiri pẹ̀lú. 4 Kíyèsi i, àwọn ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú, bí wọ́n ti tóbi tó nì, tí a sì ń ti ọwọ́ ẹ̀fúùfù líle gbá kiri, ìtọ́kọ̀ kékeré ni a fi ń darí wọn kiri, síbikíbi tí ó bá wu ẹni tí ó ń tọ́ ọkọ̀. 5 Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà kékeré, ó sì ń fọhùn ohùn ńlá. Wo igi ńlá tí iná kékeré ń sun jóná! 6 Iná sì ni ahọ́n, ayé ẹ̀ṣẹ̀ sì ni: ní àárín àwọn ẹ̀yà ara wa, ní ahọ́n ti ń bá gbogbo ara jẹ́, tí yóò sì ti iná bọ ipa ayé wa; ọ̀run àpáàdì a sì tiná bọ òun náà.

    7 Nítorí olúkúlùkù ẹ̀dá ẹranko, àti ti ẹyẹ, àti ti ejò, àti ti ohun tí ó ń bẹ ní Òkun, ni à ń tù lójú, tí a sì ti tù lójú láti ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn wá. 8 Ṣùgbọ́n ahọ́n ni ẹnikẹ́ni kò le tù lójú; ohun búburú aláìgbọ́ràn ni, ó kún fún oró ikú tí í pa ni.

    9 Òun ni àwa fi ń yin Olúwa àti Baba, òun ni a sì fi ń bú ènìyàn tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run. 10 Láti ẹnu kan náà ni ìyìn àti èébú ti ń jáde. Ẹ̀yin ará mi, nǹkan wọ̀nyí kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀. 11 Orísun odò kan a ha máa sun omi dídára àti omi iyọ̀ jáde láti orísun kan náà bí? 12 Ẹ̀yin ará mi, igi ọ̀pọ̀tọ́ ha le so èso olifi bí? Tàbí àjàrà ha lè so èso ọ̀pọ̀tọ́? Bẹ́ẹ̀ ni orísun kan kò le sun omíró àti omi tútù.

    13 Ta ni ó gbọ́n tí ó sì ní ìmọ̀ nínú yín? Ẹ jẹ́ kí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nípa ìwà rere, nípa ìwà tútù ti ọgbọ́n. 14 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ní owú kíkorò àti ìjà ní ọkàn yín, ẹ má ṣe ṣe féfé, ẹ má sì ṣèké sí òtítọ́. 15 Ọgbọ́n yìí kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ṣùgbọ́n ti ayé ni, ti ara ni, ti ẹ̀mí èṣù ni. 16 Nítorí níbi tí owú òun ìjà bá gbé wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti iṣẹ́ búburú gbogbo wà.

    17 Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ mímọ́ ní àkọ́kọ́, ti àlàáfíà, àti ti ìrẹ̀lẹ̀, kì í sì í ṣòro láti bẹ̀, ó kún fún àánú àti fún èso rere, kì í ṣe ojúsàájú, a sì máa sọ òtítọ́.

  2. 6 Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá olúkúlùkù ènìyàn lóhùn.

  3. 4 Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyè

    ṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run.

  4. 33 “E sọ igi di rere, èso rẹ̀ a sì di rere tàbí kí ẹ sọ igi di búburú, èso rẹ a sì di búburú, nítorí nípa èso igi ni a ó fi mọ̀ igi. 34 Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, báwo ni ẹ̀yin tí ẹ jẹ búburú ṣe lè sọ̀rọ̀ rere? Ọkàn ènìyàn ni ó ń darí irú ọ̀rọ̀ tí ó lè jáde lẹ́nu rẹ̀. 35 Ẹni rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá, àti ẹni búburú láti inú ìṣúra búburú ni; mu ohun búburú jáde wá. 36 Ṣùgbọ́n, mo sọ èyí fún yín, ẹ̀yin yóò jíyìn gbogbo ìsọkúsọ yín ní ọjọ́ ìdájọ́. 37 Nítorí nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín ni a fi dá yin láre, nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín sì ni a ó fi dá yin lẹ́bi.”

  5. 19 Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù

    ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

    20 Ètè olódodo jẹ́ ààyò fàdákà,

    ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú kò níye lórí.

    21 Ètè olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀,

    ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye.

  6. 18 Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀

    ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá.

    19 Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláé

    ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́.

  7. 26 Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń sin Ọlọ́run nígbà tí kò kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu, ó ń tan ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsìn rẹ̀ sì jẹ́ asán. 27 Ìsìn mímọ́ àti aláìléèérí níwájú Ọlọ́run àti Baba ni èyí, láti máa bojútó àwọn aláìní baba àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara rẹ̀ mọ́ láìlábàwọ́n kúrò nínú ayé.

  8. 20 Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó;

    láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó.

    21 Ikú àti ìyè ń bẹ nípa ahọ́n wọn,

    àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹ ẹ́.

  9. 33  Jesu sì mú ọkùnrin náà kúrò láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ó sì fi àwọn ìka rẹ̀ sí etí ọkùnrin náà, ó tu itọ́ ṣọ́wọ́. Ó sì fi kan ahọ́n rẹ̀. 34 Nígbà náà ni Jesu wòkè ọ̀run, ó sì mí kanlẹ̀, ó sì pàṣẹ wí pé, “Efata!” (èyí ni, “Ìwọ ṣí!”). 35 Lójúkan náà, etí rẹ̀ sì ṣí, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì ń sọ̀rọ̀ ketekete.

  10. 10  Nítorí,

    “Ẹni tí yóò bá fẹ́ ìyè,

    ti yóò sì rí ọjọ́ rere,

    kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi,

    àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

    11 Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere;

    kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.

  11. 1 Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà

    ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè.

    2 Ahọ́n ọlọ́gbọ́n a máa gbé ìmọ̀ jáde

    ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń tú ọ̀rọ̀ ọ òmùgọ̀ jáde.

  12. 28  Ọlọ́run sì gbé àwọn mìíràn kalẹ̀ nínú ìjọ, èkínní àwọn aposteli, èkejì àwọn wòlíì, ẹ̀kẹta àwọn olùkọ́ni, lẹ́yìn náà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìyanu, lẹ́yìn náà àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìmúláradá, àwọn olùrànlọ́wọ́ àti àwọn agbani nímọ̀ràn, àwọn tí ń sọ onírúurú èdè. 29 Ǹjẹ́ gbogbo ènìyàn ni ó jẹ́ aposteli bi? Tàbí gbogbo ènìyàn ni wòlíì bí? Ṣe gbogbo ènìyàn ní olùkọ́ni? Ṣé gbogbo ènìyàn ló ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu bí? 30 Ṣé gbogbo ènìyàn ló lè wonisàn bí? Rárá. Ǹjẹ́ gbogbo wa ni Ọlọ́run fún ní ẹ̀bùn láti le sọ̀rọ̀ ní èdè tí a kò ì tí ì gbọ́ rí bí? Ṣé ẹnikẹ́ni ló lè túmọ̀ èdè tí wọ́n sọ tí kò sì yé àwọn ènìyàn bí? 31 Ṣùgbọ́n, ẹ máa fi ìtara ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn ti ó tóbi jù.

    Síbẹ̀ èmi o fi ọ̀nà kan tí ó tayọ rékọjá hàn yín.

  13. 27 Ènìyàn tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ,

    ènìyàn olóye sì máa ń ní sùúrù.

    28 Kódà aláìgbọ́n máa ń dàbí ọlọ́gbọ́n bí ó bá dákẹ́,

    àti bí olóye bí ó bá fètèmétè.

  14. 23 Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́,

    ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu.

  15. 29 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìdíbàjẹ́ kan ti ẹnu yín jáde, ṣùgbọ́n irú èyí tí ó lè ràn ìdàgbàsókè wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n nílò, kí ó lè máa fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn tí ń gbọ́.

  16. 19 Kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́; jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa yára láti gbọ́, kí ó lọ́ra láti fọhùn, kí ó si lọ́ra láti bínú; 20 nítorí ìbínú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ òdodo irú èyí tí Ọlọ́run ń fẹ́. 21 Nítorí náà, ẹ lépa láti borí gbogbo èérí àti ìwà búburú tí ó gbilẹ̀ yíká, kí ẹ sì fi ọkàn tútù gba ọ̀rọ̀ náà tí a gbìn, tí ó lè gba ọkàn yín là.

    22 Ẹ má kan jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà lásán, kí ẹ má ba à ti ipa èyí tan ara yín jẹ́. Ẹ ṣe ohun tí ó sọ.

  17. 3 Kí Olúwa kí ó gé ètè èké wọn

    àti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu

    4 tí ó wí pé,

    “Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa;

    àwa ní ètè wa, ta ni ọ̀gá wa?”

  18. 12  Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;

    kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?

    13 Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi

    àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.

  19. 3 Fi ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ẹnu mi, Olúwa:

    kí o sì máa pa ìlẹ̀kùn ètè mi mọ́.

    4 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun tí ń ṣe ibi,

    láti máa bá àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ búburú

    má sì ṣe jẹ́ kí èmi jẹ àdídùn wọn.

  20. 171 Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde,

    nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

    172 Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ,

    nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.

  21. 16 Àwọn ohun mẹ́fà wà tí Olúwa kórìíra,

    ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i,

    17 Ojú ìgbéraga,

    ahọ́n tó ń parọ́

    ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,

    18 ọkàn tí ń pète ohun búburú,

    ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà,

    19 ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu

    àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ìyá kan.

  22. 13 Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ́ àwọn olùrékọjá ní ọ̀nà rẹ,

    àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ.

    14 Gbà mí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run,

    ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi,

    ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo rẹ kíkan.

    15 Olúwa, ṣí mi ní ètè mi gbogbo,

    àti ẹnu mi yóò sì máa kéde ìyìn rẹ.

  23. 24 Ahọ́n mi yóò sọ ti òdodo rẹ ní gbogbo ọjọ́,

    fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,

    a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.

  24. 3 Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀

    bí ọfà láti fi pa irọ́;

    kì í ṣe nípa òtítọ́

    ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà.

    Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn;

    wọn kò sì náání mi,

    ní Olúwa wí.

  25. 8 Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró;

    ó ń sọ ẹ̀tàn.

    Oníkálùkù sì ń fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò rẹ̀,

    ní inú ọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀.

  26. 10 Mose sì sọ fún Olúwa pé, “Èmi jẹ́ akólòlò, èmi kì í ṣe ẹni tó lè sọ̀rọ̀ já gaara láti ìgbà àtijọ́ wá tàbí láti ìgbà ti o ti ń bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, mo jẹ́ ẹni ti ahọ́n rẹ̀ lọ́, tí ó sì ń lọ́ra àti sọ̀rọ̀.”

    11 Olúwa sì sọ fún un pé, “Ta ni ó fún ènìyàn ni ẹnu? Ta ni ó mú un ya odi tàbí adití? Ta ni ó mú un ríran, tàbí mú un fọ́jú? Ǹjẹ́ kì í ṣe èmi Olúwa? 12 Lọ nísinsin yìí, Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀. Èmi yóò sì kọ́ ọ ni ohun ti ìwọ yóò sọ.”

  27. 9  Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́;

    ọkàn wọn kún fún ìparun.

    Ọ̀nà ọ̀fun wọn ni isà òkú tí ó ṣí sílẹ̀;

    pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn.

  28. 7  Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ;

    wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.

  29. 2 Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun;

    ó dàbí abẹ mímú,

    ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn.

  30. 2 Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èké

    àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.

    3 Kí ni kí a fi fún ọ?

    Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ,

    ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?

  31. 12 Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀

    ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní òye pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

  32. 18 Bí i asínwín ti ń ju

    ọfà àti ọfà tí ń ṣe kú pa ni

    19 ni ènìyàn tí ń tan aládùúgbò rẹ̀ jẹ

    tí ó sì wí pé, “Àwàdà lásán ni mo ń ṣe.”

    20 Láìsí igi, iná yóò kú

    láìsí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìjà máa ń parí.

    21 Bí èédú ti rí sí ẹyin iná, igi fún iná,

    bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn oníjà fún ìjà dídá sílẹ̀.

    22 Ọ̀rọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn dàbí àṣàyàn òkèlè

    wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.

    23 Ètè jíjóni, àti àyà búburú,

    dà bí ìdàrọ́ fàdákà tí a fi bo ìkòkò.

    24 Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àṣírí ara rẹ̀

    ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà.

    25 Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́

    nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀.

  33. 62 Wọ́n sì ṣe àpẹẹrẹ sí baba rẹ̀, bí ó ti ń fẹ́ kí a pè é. 63 Ó sì béèrè fún wàláà, ó sì kọ ọ wí pé, “Johanu ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn. 64 Ẹnu rẹ̀ sì ṣí lọ́gán, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì sọ̀rọ̀, ó sì ń yin Ọlọ́run.

  34. 28 Nígbà náà ni ahọ́n mi yóò máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ,

    àti ìyìn rẹ ní gbogbo ọjọ́.

  35. Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Saamu Dafidi.

    1 Mo wí pé, “Èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi

    kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀;

    èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu

    níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.”

  36. 1 Nígbà tí ọjọ́ Pentikosti sì dé, gbogbo wọn fi ọkàn kan wà ní ibìkan. 2 Lójijì ìró sì ti ọ̀run wá, gẹ́gẹ́ bí ìró ẹ̀fúùfù líle, ó sì kún gbogbo ilé níbi tí wọ́n gbé jókòó. 3 Ẹ̀là ahọ́n bí i iná sì yọ sí wọn, ó pín, ó sì bà lé olúkúlùkù wọn. 4 Gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti fi fún wọn ni ohùn.

    5 Àwọn Júù olùfọkànsìn láti orílẹ̀-èdè gbogbo lábẹ́ ọ̀run sì ń gbé Jerusalẹmu. 6 Nígbà tí wọn sì gbọ́ ìró yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ pẹ̀lú ìyàlẹ́nu, nítorí tí olúkúlùkù gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní èdè rẹ̀. 7 Ẹnu sì yà wọ́n, wọn ń wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ara Galili kọ́ ni gbogbo àwọn tí ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́? 8 Èéha sì tí ṣe ti olúkúlùkù wa fi ń gbọ́ bí wọ́n tí ń fi èdè sọ̀rọ̀? 9 Àwọn ará Partia, àti Media, àti Elamu; àti àwọn tí ń gbé Mesopotamia, Judea, àti Kappadokia, Pọntu àti Asia. 10 Frigia, àti Pamfilia, Ejibiti, àti agbègbè Libia níhà Kirene; àti àwọn àtìpó Romu, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù 11 (àti àwọn Júù àti àwọn tí a ti ipa ẹ̀sìn sọ di Júù); àwọn ará Krete àti Arabia; àwa gbọ́ tí wọ́n sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu ńlá Ọlọ́run ni èdè wa.” 12 Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì wárìrì. Wọn wí fún ara wọn pé, “Kí ni èyí túmọ̀ sí?”

  37. 13  “Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀fun wọn:

    ahọ́n wọn n sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.”

    “Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.”

    14  “Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.”

  38. Saamu ti Dafidi.

    1 Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ?

    Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?

    2 Ẹni tí ń rìn déédé

    tí ó sì ń sọ òtítọ́,

    láti inú ọkàn rẹ̀;

    3 tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn,

    tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀

    tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀,

  39. 30 Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,

    ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.

  40. 19 Ìwọ lo ẹnu rẹ fún aburú,

    ìwọ sì ń fi ahọ́n rẹ pète ẹ̀tàn.

  41. 23 Inú ènìyàn a máa dùn nígbà tí ó bá fèsì tó yẹ

    ọ̀rọ̀ tí ó bá sì wá lásìkò tó yẹ dára púpọ̀!

  42. 1 Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkàn

    ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá.

  43. 23 Ọkàn ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀

    ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ dàgbà.

    24 Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyin

    ó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun.

  44. 4 Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,

    ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!

  45. 31 Ẹnu olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá,

    ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò.

  46. 3 Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́,

    ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù gbàù yóò parun.

  47. 6 Ìṣúra tí a kójọ nípasẹ̀ ahọ́n tí ń parọ́

    jẹ́ ìrì lásán àti ìkẹ́kùn ikú.

  48. 27 Bí ènìyàn kan bá gbẹ́ kòtò, yóò ṣubú sínú rẹ̀.

    Bí ẹnìkan bá ju òkúta, yóò padà sọ́dọ̀ òun tìkára rẹ̀.

    28 Ahọ́n ẹ̀tàn máa ń kórìíra àwọn tí ó ṣe ní ìkà,

    ẹnu ìtànjẹ sì máa ń pa ni run.

  49. 20 Ǹjẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀?

    Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ.

  50. 18 Ṣùgbọ́n ohun tí a ń sọ jáde láti ẹnu, inú ọkàn ni ó ti ń wá, èyí sì ni ó ń sọ ènìyàn di aláìmọ́. 19 Ṣùgbọ́n láti ọkàn ni èrò búburú ti wá, bí ìpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, irọ́ àti ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́.

  51. 11  A ti kọ ìwé rẹ̀ pé:

    “ ‘Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè,’ ni Olúwa wí,

    ‘gbogbo eékún ni yóò wólẹ̀ fún mi;

    gbogbo ahọ́n ni yóò jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run.’ ”

  52. 16 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olóòfófó láàrín àwọn ènìyàn rẹ.

    “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun tí yóò fi ẹ̀mí aládùúgbò rẹ wéwu. Èmi ni Olúwa.

    17 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládùúgbò rẹ wí, kí o má ba à jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀.

    18  “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ. Èmi ni Olúwa.

  53. 2 Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín;

    ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojú u rẹ̀ pamọ́ fún un yín

    tó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́.

    3 Nítorí ọwọ́ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀,

    àti ìka ọwọ́ yín fún ẹ̀bi.

    Ètè yín ń pa irọ́ púpọ̀,

    ahọ́n yín sì ń sọ̀rọ̀ nǹkan ibi.

  54. 4 Nítorí òǹgbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́

    lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn;

    àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ,

    ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó fi fún wọn.

  55. 12 Àwọn ọlọ́rọ̀ inú rẹ̀ kún fún ìwà ipá;

    àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ti ọ̀rọ̀ èké

    àti ahọ́n wọn ń sọ ẹ̀tàn?

  56. 24 Ó sì ké, ó wí pé, ‘Baba Abrahamu, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lasaru, kí ó tẹ orí ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.’

  57. 1  Bí èmi tilẹ̀ lè sọ oríṣìíríṣìí èdè tí ènìyàn àti ti angẹli, tí n kò bá sì ní ìfẹ́, mo kàn ń pariwo bí ago lásán ni tàbí bí i kimbali olóhùn gooro. 2  Bí mo bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo sì ní òye gbogbo ohun ìjìnlẹ̀, àti gbogbo ìmọ̀, bí mo sì ni gbogbo ìgbàgbọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè ṣí àwọn òkè ńlá nídìí, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi kò jẹ nǹkan kan. 3 Bí mo bá fi gbogbo nǹkan tí mo ní tọrẹ fún àwọn aláìní, tí mo sì fi ara mi fún ni láti sùn ṣùgbọ́n tí n kò ní ìfẹ́, kò ní èrè kan fún mi.

  58. 14 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi

    kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ,

    Ìwọ Olúwa àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.

  59. 2 nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tàn

    ti ya ẹnu wọn sí mi

    wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi.

  60. 4 Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,

    kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.

  61. 11 Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè,

    ṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú.

  62. 25 Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò

    ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.

  63. 28 Ọkàn olódodo ń wọn ìdáhùn wò

    ṣùgbọ́n ẹnu ènìyàn búburú ń tú ibi jáde.

    29 Olúwa jìnnà sí ènìyàn búburú

    ṣùgbọ́n ó ń gbọ́ àdúrà olódodo.

  64. 20 Ènìyàn aláyídáyidà ọkàn kì í gbèrú,

    ẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu.

  65. 23  Nípa èmi tìkára mi ni mo ti búra,

    ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lú gbogbo ipá mi,

    ọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́.

    Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀;

    nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra.

  66. 20 Sì kíyèsi i, ìwọ ó yadi, ìwọ kì yóò sì le fọhùn, títí ọjọ́ náà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ, nítorí ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ tí yóò ṣẹ ní àkókò wọn.”

    21 Àwọn ènìyàn sì ń dúró de Sekariah, ẹnu sì yà wọ́n nítorí tí ó pẹ́ nínú tẹmpili. 22 Nígbà tí ó sì jáde wá, òun kò le bá wọn sọ̀rọ̀. Wọn sì kíyèsi wí pé ó ti rí ìran nínú tẹmpili, ó sì ń ṣe àpẹẹrẹ sí wọn, nítorí tí ó yadi.

  67. 8 Ìfẹ́ kì í kùnà láé, kì í sì í yẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, wọn yóò dópin, bí ó bá ṣe ẹ̀bùn ahọ́n ni, wọn yóò dákẹ́, bí ó bá ṣe pé ìmọ̀ ni yóò di asán.

  68. 10  Ẹ̀karùnún sì tú ago tirẹ̀ sórí ìtẹ́ ẹranko náà; ilẹ̀ ọba rẹ̀ sì ṣókùnkùn; wọ́n sì ń gé ahọ́n wọn jẹ́ nítorí ìrora. 11 Wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti nítorí egbò wọn, wọ́n kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn.