48 Bible Verses About God's Holiness

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About God's Holiness
  1. 13 Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀, ẹ kó ara yín ní ìjánu, kí ẹ sì fi ìrètí yín ní kíkún sí oore-ọ̀fẹ́, èyí tí a ń mu bọ̀ fún yin ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. 14 Bí àwọn ọmọ tí ń gbọ́rọ̀, ẹ ma ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ́. 15 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o pè yin ti jẹ mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ mímọ́. 16  Nítorí a ti kọ ọ pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́: nítorí tí Èmi jẹ mímọ́!”

    17 Níwọ́n bí ẹ̀yin ti ń ké pe Baba, ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù láìṣe ojúsàájú, ẹ máa lo ìgbà àtìpó yin ni ìbẹ̀rù. 18 Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín padà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín. 19 Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí i ti ọ̀dọ́-àgùntàn ti kò lábùkù, tí kò sì lábàwọ́n, àní, ẹ̀jẹ̀ Kristi. 20 Ẹni tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nítòótọ́ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn ní ìgbà ìkẹyìn wọ̀nyí nítorí yín. 21 Àní ẹ̀yin tí o tipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni ti ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì fi ògo fún un; kí ìgbàgbọ́ àti ìrètí yín lè wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

    22 Níwọ́n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnìkejì yín gidigidi láti ọkàn wá. 23 Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láààyè tí ó sì dúró. 24  Nítorí pé,

    “Gbogbo ènìyàn dàbí koríko,

    àti gbogbo ògo rẹ̀ bi ìtànná koríko.

    Koríko á máa gbẹ ìtànná a sì máa rẹ̀ dànù,

    25 ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé.”

    Ọ̀rọ̀ náà yìí sì ni ìyìnrere tí a wàásù fún yín.

  2. 1 Ní ọdún tí ọba Ussiah kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ìṣẹ́tí aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. 2 Àwọn Serafu wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò. 3  Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé,

    “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun

    gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”

    4  Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹmpili sì kún fún èéfín.

  3. 11 Ta ni nínú àwọn òrìṣà

    tó dàbí rẹ, Olúwa?

    Ta ló dàbí rẹ:

    ní títóbi,

    ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìn,

    tí ń ṣe ohun ìyanu?

    12 “Ìwọ na apá ọ̀tún rẹ,

    ilẹ̀ si gbé wọn mì.

    13 Nínú ìfẹ́ rẹ ti kì í sákí Ìwọ ṣe amọ̀nà

    àwọn ènìyàn náà tí Ìwọ ti rà padà.

    Nínú agbára rẹ Ìwọ yóò tọ́ wọn,

    lọ sí ibi ìjókòó rẹ mímọ́.

  4. 1 Hana sì gbàdúrà pé,

    “Ọkàn mi yọ̀ sí Olúwa;

    ìwo agbára mi ni a sì gbé sókè sí Olúwa.

    Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀tá mi,

    nítorí ti èmi yọ̀ ni ìgbàlà rẹ̀.

    2 “Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi Olúwa;

    kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe ìwọ;

    kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa.

  5. 44  Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ torí pé mo jẹ́ mímọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ ohunkóhun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀. 45 Èmi ni Olúwa tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín torí náà, ẹ jẹ́ mímọ́ torí pé mímọ́ ni èmi.

    46  “ ‘Àwọn wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹranko, ẹyẹ, gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi àti àwọn ẹ̀dá tí ó ń rìn lórí ilẹ̀. 47 Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrín àìmọ́ àti mímọ́ láàrín ẹ̀dá alààyè, tí ẹ le jẹ àti èyí tí ẹ kò le jẹ.’ ”

  6. 2  “Bá gbogbo àpéjọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ jẹ́ mímọ́ nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.

  7. 3  Wọ́n sì ń kọ orin ti Mose, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àti orin ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn, wí pé:

    “Títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ,

    Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè;

    òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀nà rẹ̀,

    ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè.

    4  Ta ni kì yóò bẹ̀rù, Olúwa,

    tí kì yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ̀?

    Nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni mímọ́.

    Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóò sì wá,

    ti yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ,

    nítorí a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn.”

  8. 1  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí èmi wò, sì kíyèsi i, ìlẹ̀kùn kan ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run, ohùn kìn-ín-ní tí mo gbọ́ bí ohùn ìpè tí ń bá mi sọ̀rọ̀, tí ó wí pé, “Gòkè wá níhìn-ín, èmi ó sì fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí hàn ọ́.” 2  Lójúkan náà, mo sì wà nínú Ẹ̀mí, sì kíyèsi i, a tẹ́ ìtẹ́ kan ní ọ̀run, ẹnìkan sì jókòó lórí ìtẹ́ náà. 3 Ẹni tí ó sì jókòó náà dàbí òkúta jasperi àti kaneliani lójú. Ni àyíká ìtẹ́ náà ni òṣùmàrè kan wà tí ó dàbí òkúta emeradi lójú. 4 Yí ìtẹ́ náà ká sì ni ìtẹ́ mẹ́rìnlélógún mìíràn; àti lórí àwọn ìtẹ́ náà mo rí àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún jókòó, tí a wọ̀ ni aṣọ àlà; adé wúrà sì wà ni orí wọn. 5  Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni ìró mọ̀nàmọ́ná àti ohùn àti àrá ti jáde wá: níwájú ìtẹ́ náà ni fìtílà iná méje sì ń tàn, èyí tí ń ṣe Ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run. 6  Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni òkun bi dígí wà tí o dàbí kristali.

    Àti yí ìtẹ́ náà ká ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí ó kún fún ojú níwájú àti lẹ́yìn wọn. 7  Ẹ̀dá kìn-ín-ní sì dàbí kìnnìún, ẹ̀dá kejì si dàbí ọmọ màlúù, ẹ̀dá kẹta sì ni ojú bi ti ènìyàn, ẹ̀dá kẹrin sì dàbí idì tí ń fò. 8  Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, tí olúkúlùkù wọn ni ìyẹ́ mẹ́fà, kún fún ojú yíká ara àti nínú; wọn kò sì sinmi lọ́sàn àti lóru, láti wí pé:

    “ ‘Mímọ́, mímọ́, mímọ́,

    Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè,’

    tí ó ti wà, tí ó sì ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀ wá!”

  9. 15  Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí

    ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́:

    “Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́,

    ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,

    láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí

    àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.

  10. 5 Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa

    ẹ foríbalẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.

  11. 9  Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn olú àlùfáà, Orílẹ̀-èdè mímọ́, ènìyàn ọ̀tọ̀ ki ẹ̀yin lè fi ọláńlá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn.

  12. 1  Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba fi fẹ́ wa, tí a fi ń pè wá ní ọmọ Ọlọ́run; bẹ́ẹ̀ ni a sá à jẹ́. Nítorí èyí ni ayé kò ṣe mọ̀ wá, nítorí tí kò mọ̀ ọ́n. 2 Olùfẹ́, ọmọ Ọlọ́run ni àwa ń ṣe nísinsin yìí, a kò ì tí i fihàn bí àwa ó ti rí: àwa mọ̀ pé, nígbà tí òun ba farahàn, àwa yóò dàbí rẹ̀; nítorí àwa yóò rí i, àní bí òun tí rí. 3 Olúkúlùkù ẹni tí ó ba sì ní ìrètí yìí nínú rẹ̀, ń wẹ ara rẹ̀ mọ́, àní bí òun ti mọ́.

    4 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ó ń rú òfin pẹ̀lú, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ni rírú òfin. 5  Ẹ̀yin sì mọ̀ pé, òun farahàn láti mu ẹ̀ṣẹ̀ kúrò; ẹ̀ṣẹ̀ kò sì ṣí nínú rẹ̀. 6 Ẹnikẹ́ni tí ó ba ń gbé inú rẹ̀ kì í dẹ́ṣẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń dẹ́ṣẹ̀ kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n.

    7 Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín, ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo, ó jásí olódodo, gẹ́gẹ́ bí òun tí jẹ olódodo. 8  Ẹni tí ó ba ń dẹ́ṣẹ̀ tí èṣù ni; nítorí láti àtètèkọ́ṣe ni èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí ni Ọmọ Ọlọ́run ṣe farahàn, kí ó lè pa iṣẹ́ èṣù run. 9  Ẹnikẹ́ni tí a ti ipa Ọlọ́run bí, kì í dẹ́ṣẹ̀; nítorí tí irú rẹ̀ ń gbé inú rẹ̀, kò sì lè dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé a ti ti ipa Ọlọ́run bí i. 10 Nínú èyí ni àwọn ọmọ Ọlọ́run ń farahàn, àti àwọn ọmọ èṣù; ẹnikẹ́ni tí kò ba ń ṣe òdodo, àti ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọ́run.

  13. 43 “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ, kí ìwọ sì kórìíra ọ̀tá rẹ̀.’ 44 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín. 45 Kí ẹ̀yin lè jẹ́ ọmọ Baba yín ti ń bẹ ní ọ̀run. Ó mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sára ènìyàn búburú àti ènìyàn rere, ó rọ̀jò fún àwọn olódodo àti fún àwọn aláìṣòdodo. 46 Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan, èrè kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn agbowó òde kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́? 47 Àti bí ó bá sì jẹ́ pé kìkì àwọn arákùnrin yín nìkan ni ẹ̀yin ń kí, kín ni ẹ̀yin ń ṣe ju àwọn mìíràn lọ? Àwọn kèfèrí kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí? 48 Nítorí náà, ẹ jẹ́ pípé, gẹ́gẹ́ bí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ṣe jẹ́ pípé.

  14. 25 “Ta ni ẹ ó fi mi wé?

    Tàbí ta ni ó bá mi dọ́gba?” ni Ẹni Mímọ́ wí.

  15. 5  Olúwa sì wí fún Mose pé, “Má ṣe súnmọ́ ìhín yìí, bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni.”

  16. 8 Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí;

    Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀.

  17. Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora.

    1 Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn

    ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.

  18. 21 Orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mi lógún, èyí tí ilé Israẹli sọ di aláìmọ́ ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti lọ.

    22 “Nítorí náà, sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kì í ṣe nítorí rẹ, ìwọ ilé Israẹli, ni èmi yóò ṣe ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mímọ́ mi, èyí ti ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti lọ. 23 Èmi yóò fi jíjẹ́ mímọ́ orúkọ ńlá mi, èyí tí a ti sọ di aláìmọ́ hàn ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè, orúkọ tí ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ni àárín wọn. Nígbà náà àwọn orílẹ̀-èdè yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa, ni Olúwa Olódùmarè wí, nígbà tí mo bá fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ yín ni iwájú wọn.

  19. 49 Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi;

    Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.

  20. 29 Fún Olúwa ní ìyìn nítorí orúkọ rẹ̀;

    gbé ọrẹ kí ẹ sì wá síwájú rẹ̀.

    Sìn Olúwa nínú inú dídùn ìwà mímọ́ rẹ̀.

  21. 3 Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni Ìwọ;

    ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó.

  22. Ti Dafidi.

    1 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.

  23. 26 Nítorí pé irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀ ni o yẹ wá, mímọ́, àìlẹ́gàn, àìléèérí, tí a yà sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí a sì gbéga ju àwọn ọ̀run lọ. 27 Ẹni tí kò ní láti máa rú ẹbọ lójoojúmọ́, bí àwọn olórí àlùfáà, fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀ náà, àti lẹ́yìn náà fún tí àwọn ènìyàn; nítorí èyí ni tí ó ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ. 28 Nítorí pé òfin a máa fi àwọn ènìyàn tí ó ní àìlera jẹ olórí àlùfáà; ṣùgbọ́n nípa ọ̀rọ̀ ti ìbúra, tí ó ṣe lẹ́yìn òfin, ó fi ọmọ jẹ; ẹni tí a sọ di pípé títí láé.

  24. 26  Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún mi torí pé, Èmi Olúwa fẹ́ mímọ́. Mó sì ti yà yín kúrò nínú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kí ẹ le jẹ́ tèmi.

  25. 19 Joṣua sì wí fún àwọn ènìyàn náà, pé, “Ẹ̀yin kò le sin Olúwa, nítorí Ọlọ́run mímọ́ ni òun; Ọlọ́run owú ni òun, kì yóò dárí ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. 20 Bí ẹ bá kọ Olúwa tí ẹ sì sin òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn òun yóò padà yóò sì mú ibi bá a yín, yóò sì pa yín run, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣe rere fún un yín tan.”

  26. 3 Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ?

    Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?

    4  Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,

    ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán

    tí kò sì búra èké.

    5 Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa,

    àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.

  27. 9 Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;

    ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.

  28. 35 Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ni èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra;

    èmi kì yóò purọ́ fún Dafidi.

  29. 8 Àti òpópónà kan yóò wà níbẹ̀:

    a ó sì máa pè é ní ọ̀nà ìwà mímọ́.

    Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà;

    yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà,

    àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá.

  30. 15 Èmi ni Olúwa, Ẹni Mímọ́ rẹ,

    Ẹlẹ́dàá Israẹli, ọba rẹ.”

  31. 5  Èyí sì ni iṣẹ́ tí àwa ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, tí àwa sì ń jẹ́ fún yín pé, ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọ́run; ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì òkùnkùn rárá.

  32. Saamu ti Dafidi.

    1 Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ?

    Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?

  33. 12 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo,

    kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.

  34. 1 Olúwa jẹ ọba;

    jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì

    Ó jókòó lórí ìtẹ́ kérúbù

    jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.

    2 Olúwa tóbi ní Sioni;

    Ó sì ga jù gbogbo orílẹ̀-èdè lọ.

    3 Kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó tóbi

    tí ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni Òun.

  35. 19  Tàbí, ẹ̀yin kò mọ̀ pé ara yín ni tẹmpili Ẹ̀mí Mímọ́, ti ń bẹ nínú yín, ti ẹ̀yin ti gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run? Ẹ̀yin kì í ṣe ti ara yín, 20  nítorí a ti rà yín ni iye kan. Nítorí náà ẹ yìn Ọlọ́run lógo nínú ara yín, àti nínú ẹ̀mí yín, tì í ṣe ti Ọlọ́run.

  36. 6 Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún Ọlọ́run, kí wọ́n má ba à sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di àìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń fi iná sun ẹbọ sí Olúwa wọn, ti ó jẹ oúnjẹ Ọlọ́run wọn. Nítorí náà wọn gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́.

    7 “ ‘Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ fẹ́ panṣágà tàbí obìnrin tí ó ti fi ọkùnrin ba ara rẹ̀ jẹ́ tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ti kọ̀sílẹ̀ nítorí pé àwọn àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn. 8 Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ máa kà wọ́n sí mímọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ oúnjẹ fún mi. Èmi ni Olúwa, mo jẹ́ mímọ́, mo sì ya àwọn ènìyàn mi sí mímọ́.

  37. 4 Olúwa ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;

    Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run.

    Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn;

    ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.

  38. 22 Èmi yóò fi dùùrù mi yìn

    fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi;

    èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù

    ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.

  39. 32 Ẹ má ṣe ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Àwọn ọmọ Israẹli gbọdọ̀ mọ̀ mí ní mímọ́. Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́.

  40. 10 Ìyìn nínú orúkọ rẹ̀ mímọ́;

    jẹ kí ọkàn àwọn tí ó yin Olúwa kí ó yọ̀.

  41. 10 Nígbà náà ní èmi ìbá ní ìtùnú síbẹ̀,

    àní, èmi ìbá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí:

    nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí.

  42. 21 Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀,

    nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́.

  43. 41 Síwájú àti síwájú wọ́n dán Ọlọ́run wò;

    wọ́n mú ẹni mímọ́ Israẹli bínú.

  44. 16 Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀,

    Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀.

  45. 14 Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò,

    ìwọ Israẹli kékeré,

    nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,”

    ni Olúwa wí,

    olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.

  46. 15 Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì rí i

    láti ìtẹ́ ògo rẹ, mímọ́ àti ológo.

    Níbo ni ìtara àti agbára rẹ wà?

    Ìwà jẹ́ẹ́jẹ́ rẹ àti àánú rẹ ni a

    ti mú kúrò níwájú wa.

  47. 20  Ṣùgbọ́n Olúwa wà nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;

    ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ.

  48. 13  Ẹ̀ dákẹ́, gbogbo ẹran-ara níwájú Olúwa: nítorí a jí i láti ibùgbé mímọ́ rẹ̀ wá.”