89 Bible Verses About God's Sovereignty

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About God's Sovereignty
  1. 14  Ǹjẹ́ àwa yóò ha ti wí? Àìṣòdodo ha wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run bí? Kí a má ri! 15  Nítorí ó wí fún Mose pé,

    “Èmi ó ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún,

    èmi yóò sì ṣe ìyọ́nú fún ẹni tí èmi yóò ṣe ìyọ́nú fún.”

    16 Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ti ẹni tí ó fẹ́, kì í sì í ṣe ti ẹni tí ń sáré, bí kò ṣe ti Ọlọ́run tí ń ṣàánú. 17  Nítorí ìwé mímọ́ wí fún Farao pé, “Nítorí èyí náà ni mo ṣe gbé ọ dìde, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.” 18  Nítorí náà ni ó ṣe ń ṣàánú fún ẹni tí ó wù ú, ẹni tí ó wù ú a sì mú ní ọkàn le.

    19 Ìwọ ó sì wí fún mi pé, “Kín ni ó ha tún bá ni wí sí? Nítorí ta ni ó ń de ìfẹ́ rẹ lọ́nà?” 20  Bẹ́ẹ̀ kọ́, ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn? “Ohun tí a mọ, a ha máa wí fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé, ‘Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyìí?’ ” 21  Amọ̀kòkò kò ha ni agbára lórí amọ̀, nínú ìṣù kan náà láti ṣe apá kan nínú ohun èlò sí ọlá, àti apá kan nínú ohun èlò sí àìlọ́lá?

    22  Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ń kọ́? Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mí mọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun. 23  Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mí mọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣáájú fún ògo. 24  Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn Kèfèrí pẹ̀lú? 25  Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hosea pé,

    “Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ‘ènìyàn mi’,

    àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní ‘àyànfẹ́.’ ”

    26  Yóò sì ṣe,

    “Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé,

    ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’

    níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ”

  2. 28 Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀. 29  Nítorí àwọn ẹni tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ni ó sì yàn tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán ọmọ rẹ̀, kí òun lè jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn arákùnrin púpọ̀. 30 Àti pé lẹ́yìn tí òun ti pè wá wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sọ wá di aláìjẹ̀bi lẹ́yìn èyí, ó fi rere Kristi kún inú ọkàn wa. Lékè gbogbo rẹ̀, ó fún wa ní ìdúró rere pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pinu ògo rẹ̀ fún wa.

    31  Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa? 32  Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti fi Ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le ṣòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí?

  3. 7  Nínú rẹ̀ ni àwa rí ìràpadà gba nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run 8 èyí tí ó fún wa lọ́pọ̀lọ́pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye, 9 Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mí mọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bí ìdùnnú rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kristi, 10  èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ Kristi.

    11 Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́yìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀, 12 kí àwa kí ó le wà fún ìyìn ògo rẹ̀, àwa tí a ti ni ìrètí ṣáájú nínú Kristi.

  4. 8 “Rántí èyí, fi í sí ọkàn rẹ,

    fi sí ọkàn rẹ, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀.

    9 Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́-tijọ́;

    Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn;

    Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíràn bí ì mi.

    10 Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá,

    láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá.

    Mo wí pé, Ète mi yóò dúró,

    àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí.

    11 Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá;

    láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ.

    Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò mú ṣẹ;

    èyí tí mo ti gbèrò, òun ni èmi yóò ṣe.

  5. 11 Tìrẹ Olúwa ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìn

    àti ọláńlá àti dídán,

    nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ.

    Tìrẹ Olúwa ni ìjọba;

    a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo.

    12 Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ;

    ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan.

    Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àti

    láti fi agbára fún ohun gbogbo.

  6. 32 A ó lé ọ kúrò láàrín àwọn ènìyàn, ìwọ yóò sì lọ máa gbé àárín àwọn ẹranko igbó; ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìgbà méje yóò kọjá lórí i rẹ títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé, Ọ̀gá-ògo jẹ ọba lórí ìjọba ènìyàn àti pé ó ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.”

    33 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ohun tí a sọ nípa Nebukadnessari ṣẹlẹ̀ sí i. A lé e kúrò láàrín ènìyàn, ó sì ń jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run sì ń sẹ̀ sí ara rẹ̀, títí irun orí rẹ̀ fi gùn bí i ti ìyẹ́ ẹyẹ idì, tí èékánná rẹ̀ sì dàbí i ti ẹyẹ.

    34 Ní òpin ìgbà náà, èmi, Nebukadnessari gbé ojú mi sókè sí ọ̀run, iyè mi sì sọjí. Mo fi ọpẹ́ fún Ọ̀gá-ògo; mo fi ọlá àti ògo fún ẹni tí ó wà láéláé.

    Ìjọba rẹ̀ ìjọba títí ayé ni

    ìjọba rẹ̀ wà láti ìran dé ìran.

    35 Gbogbo àwọn ènìyàn ayé

    ni a kà sí asán.

    Ó ń ṣe bí ó ti wù ú,

    pẹ̀lú àwọn ogun ọ̀run,

    àti gbogbo àwọn ènìyàn ayé

    tí kò sì ṣí ẹnìkankan tí ó lè dí i lọ́wọ́

    tàbí sọ fún un wí pé: “Kí ni ìwọ ń ṣe?”

  7. 3 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run:

    tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.

  8. 15  Kristi ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá. 16 Nítorí nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo: àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ìbá ṣe ìtẹ́, tàbí agbára, tàbí àṣẹ, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo àti fún un. 17  Ó ti wà ṣáájú kí ohunkóhun tó wà, nínú rẹ̀ ni a sì so ohun gbogbo papọ̀ ṣọ̀kan. 18  Òun ni orí fún ara, èyí tí í ṣe ìjọ; òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti àkọ́bí nínú àwọn òkú, pé nínú ohun gbogbo kí òun lè ní ipò tí ó ga jùlọ nínú ohunkóhun. 19 Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun tìkára rẹ̀ lè máa gbé nínú rẹ̀. 20 Àti nípasẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà àwọn nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ ní ọ̀run, nípa mímú àlàáfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélébùú.

  9. 1 Ọkàn ọba ń bẹ lọ́wọ́ Olúwa;

    a máa darí rẹ̀ lọ ibi tí ó fẹ́ bí ipa omi.

  10. 1 Nígbà náà ní Jobu dá Olúwa lóhùn, ó sì wí pé,

    2 “Èmi mọ̀ pé, ìwọ lè e ṣe ohun gbogbo,

    àti pé, kò si ìrò inú tí a lè fa sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ.

    3 Ìwọ béèrè, ta ni ẹni tí ń fi ìgbìmọ̀ pamọ́ láìní ìmọ̀?

    Nítorí náà ní èmi ṣe ń sọ èyí tí èmi kò mọ̀,

    ohun tí ó ṣe ìyanu jọjọ níwájú mi, ti èmi kò mòye.

    4 “Ìwọ wí pé, ‘Gbọ́ tèmi báyìí,

    èmi ó sì sọ; èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ,

    ìwọ yóò sì dá mi lóhùn.’

    5 Etí mi sì ti gbọ́ nípa rẹ,

    ṣùgbọ́n nísinsin yìí ojú mi ti rí ọ.

    6 Ǹjẹ́ nítorí náà èmi kórìíra ara mi,

    mo sì ronúpìwàdà nínú ekuru àti eérú.”

  11. 6 Olúwa ṣe ohunkóhun tí ó wù ú,

    ní ọ̀run àti ní ayé,

    ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.

    7 Ó mú ìkùùkuu gòkè láti òpin ilẹ̀ wá:

    ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjò:

    ó ń mú afẹ́fẹ́ ti inú ilẹ̀ ìṣúra rẹ̀ wá.

  12. 23 Nítorí bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo wo àwọn ohun tí ẹ̀yin ń sìn, mo sì rí pẹpẹ kan tí a kọ àkọlé yìí sí:

    Fún Ọlọ́run àìmọ̀.

    Ǹjẹ́ ẹni tí ẹ̀yin ń sìn ni àìmọ̀ òun náà ni èmi ń sọ fún yin.

    24  “Ọlọ́run náà tí ó dá ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òun náà tí í ṣe Olúwa ọ̀run àti ayé, kì í gbé tẹmpili tí a fi ọwọ́ kọ́. 25 Bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ènìyàn sìn ín, bí ẹni pé ó ń fẹ́ nǹkan, òun ni ó fi ìyè àti èémí àti ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn. 26 Ó sì tí tipasẹ̀ ẹnìkan dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti tẹ̀dó sí ojú àgbáyé, ó sì ti pinnu àkókò tí a yàn tẹ́lẹ̀, àti ààlà ibùgbé wọn; 27 Ọlọ́run ṣe eléyìí kí wọn bá le máa wa, bóyá wọn yóò lè ṣàfẹ́rí rẹ̀, kí wọn sì rí í. Bí ó tilẹ̀ jẹ pé kò jìnnà sí olúkúlùkù wa. 28 Nítorí nínú rẹ̀ ni àwa wà láààyè, tí a ń rìn kiri, tí a sì ní ẹ̀mí wa, bí àwọn kan nínú àwọn akéwì tí ẹ̀yin tìkára yín tí wí pé, ‘Àwa pẹ̀lú sì jẹ́ ọmọ rẹ̀.’

    29 “Ǹjẹ́ bí àwa bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, kò yẹ fún wa láti rò pé, ẹni tí a wa n sìn dàbí wúrà, tàbí fàdákà, tàbí òkúta, tí a fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ ènìyàn ya ère àwòrán rẹ̀. 30 Pẹ̀lúpẹ̀lú ìgbà àìmọ̀ yìí ni Ọlọ́run tí fojú fò dá; ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti ronúpìwàdà. 31 Níwọ́n bí ó ti dá ọjọ́ kan, nínú èyí tí yóò ṣe ìdájọ́ ayé lódodo nípasẹ̀ ọkùnrin náà tí ó ti yàn, nígbà tí ó ti fi ohun ìdánilójú fún gbogbo ènìyàn, ní ti pé ó jí dìde kúrò nínú òkú.”

  13. 33  A! Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run!

    Àwámárídìí ìdájọ́ rẹ̀ ti rí,

    ọ̀nà rẹ̀ sì jù àwárí lọ!

    34  “Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa?

    Tàbí ta ni í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀?”

    35  “Tàbí ta ni ó kọ́ fi fún un,

    tí a kò sì san padà fún un?”

    36  Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti nípa rẹ̀, àti fún un ni ohun gbogbo;

    ẹni tí ògo wà fún láéláé! Àmín.

  14. 6 tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùn

    títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀

    kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi.

    Èmi ni Olúwa, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́.

    7 Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn,

    Mo mú àlàáfíà wá, Mo sì dá àjálù;

    Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.

    8 “Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀;

    jẹ́ kí àwọsánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀.

    Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbagada,

    jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè,

    jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀;

    Èmi Olúwa ni ó ti dá a.

    9  “Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà,

    ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀.

    Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé:

    ‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’

    Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé,

    ‘Òun kò ní ọwọ́?’

    10 Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé,

    ‘Kí ni o bí?’

    tàbí sí ìyá rẹ̀,

    ‘Kí ni ìwọ ti bí?’

    11 “Ohun tí Olúwa wí nìyìí,

    Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀.

    Nípa ohun tí ó ń bọ̀,

    ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi,

    tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí?

    12 Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé

    tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀.

    Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run;

    mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta.

    13 Èmi yóò gbé Kirusi sókè nínú òdodo mi.

    Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.

    Òun yóò tún ìlú mi kọ́

    yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀,

    ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan,

    ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

  15. 26 “Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí kò sí ohun tó ń bọ̀ tí kò ní í fi ara hàn, tàbí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ tí a kò ní mọ̀ ni gbangba. 27 Ohun tí mo bá wí fún yín ní òkùnkùn, òun ni kí ẹ sọ ní ìmọ́lẹ̀. Èyí tí mo sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sì etí yín ni kí ẹ kéde rẹ́ lórí òrùlé. 28 Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó le pa ara nìkan; ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ẹ̀mí. Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí ó le pa ẹ̀mí àti ara run ní ọ̀run àpáàdì. 29 Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan? Síbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lu ilẹ̀ lẹ́yìn Baba yin. 30 Àti pé gbogbo irun orí yín ni a ti kà pé. 31 Nítorí náà, ẹ má ṣe fòyà; ẹ̀yin ní iye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.

    32 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú ènìyàn, òun náà ni èmi yóò jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run. 33 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mí níwájú àwọn ènìyàn, òun náà ni èmi náà yóò sọ wí pé n kò mọ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run.

  16. 13 Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin tí ó ń wí pé, “Lónìí tàbí lọ́la àwa ó lọ sí ìlú báyìí, a ó sì ṣe ọdún kan níbẹ̀, a ó sì ṣòwò, a ó sì jèrè.” 14 Nígbà tí ẹ̀yin kò mọ ohun tí yóò hù lọ́la. Kí ni ẹ̀mí yín? Ìkùùkuu sá à ni yín, tí ó hàn nígbà díẹ̀, lẹ́yìn náà a sì túká lọ. 15 Èyí tí ẹ̀ bá fi wí pé, “Bí Olúwa bá fẹ́, àwa yóò wà láààyè, àwa ó sì ṣe èyí tàbí èyí i nì.” 16 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ń gbéraga nínú ìfọ́nnu yín, gbogbo irú ìfọ́nnu bẹ́ẹ̀, ibi ni.

  17. 20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbèrò láti ṣe mi ní ibi, ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbèrò láti fi ṣe rere tí ń ṣe lọ́wọ́ yìí; ni gbígba ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn là.

  18. 5 Nígbà náà Jehoṣafati dìde dúró níwájú àpéjọ Juda àti Jerusalẹmu ní ilé Olúwa níwájú àgbàlá tuntun. 6 O sì wí pé,

    “Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóso lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú.

  19. 33 A ṣẹ́ kèké si ìṣẹ́po aṣọ,

    ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.

  20. 3  Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kristi. 4 Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́ 5 ẹni tí ò ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jesu Kristi fún ara rẹ̀, ní ìbámu ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀, 6  fún ìyìn ògo oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí ò ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀.

  21. 16 Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ àìkú, tí ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí a kò lè súnmọ́, ẹni tí ènìyàn kan kò rí rí, tí a kò sì lè rí: ẹni tí ọlá àti agbára títí láé ń ṣe tirẹ̀. Àmín.

  22. 14 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ni ọ̀run àní àwọn ọ̀run tó ga ju ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀. 15 Síbẹ̀ Olúwa sì tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún àwọn baba ńlá a yín, Ó sì fẹ́ wọn Ó sì yan ẹ̀yin ọmọ wọn láti borí gbogbo orílẹ̀-èdè títí di òní. 16 Ẹ kọ ọkàn yín ní ilà, kí ẹ má sì ṣe jẹ́ olórí kunkun mọ́ láti òní lọ. 17  Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa. Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojúsàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

  23. 9  Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá sì fi ògo àti ọlá, àti ọpẹ́ fún ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń bẹ láààyè láé àti láéláé. 10 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà yóò sì wólẹ̀ níwájú ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, wọn yóò sì tẹríba fún ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé, wọn yóò sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wí pé:

    11 “Olúwa àti Ọlọ́run, ìwọ ni o yẹ,

    láti gba ògo àti ọlá àti agbára,

    nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo,

    àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ̀ ni

    wọn fi wà tí a sì dá wọn.”

  24. 1  Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé. 2 Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rábàbà lójú omi.

    3  Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà.

  25. 9 Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀

    ṣùgbọ́n Olúwa ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.

  26. 21 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn,

    ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí.

  27. 13 Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe:

    “Ta ni ó le è to

    ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?”

    14 Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn,

    ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó:

    Ọlọ́run tí ó dá èkínní

    náà ni ó dá èkejì.

    Nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwárí

    ohun kankan nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀.

  28. 24 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra,

    “Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí,

    àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró.

    25 Èmi yóò run Asiria ní ilẹ̀ mi,

    ní àwọn orí òkè mi ni èmi yóò ti rún un mọ́lẹ̀.

    Àjàgà rẹ̀ ni a ó mú kúrò lọ́rùn àwọn ènìyàn mi,

    ẹrù u rẹ̀ ni ó mú kúrò ní èjìká wọn.”

    26 Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé,

    èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè.

    27 Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pète,

    ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò?

    Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà?

  29. 26  Ṣùgbọ́n Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ni èyí ṣòro fún; ṣùgbọ́n fún Ọlọ́run ohun gbogbo ni ṣíṣe.”

  30. 13 Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà.

    Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi.

    Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”

  31. 37 Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀

    tí Olúwa kò bá fi àṣẹ sí i.

    38 Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá-ògo jùlọ

    ni rere àti búburú tí ń wá?

    39 Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè ṣe ń kùn

    nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?

    40 Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò,

    kí a sì tọ Olúwa lọ.

  32. 8  Nítorí oore-ọ̀fẹ́ ní a fi gbà yín là nípa ìgbàgbọ́. Èyí kì í ṣe nípa agbára ẹ̀yin fúnra yín: ẹ̀bùn Ọlọ́run ni, 9 kì í ṣe nípa àwọn iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣògo. 10 Nítorí àwa ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tí a ti dá nínú Kristi Jesu fún àwọn iṣẹ́ rere, èyí tí Ọlọ́run ti pèsè tẹ́lẹ̀, fún wa láti ṣe.

  33. 12 Nítorí náà ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ń gbọ́rọ̀ nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà ti mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n pàápàá nísinsin yìí tí èmi kò sí ni àárín yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì, 13  nítorí pé Ọlọ́run ni ó n ṣiṣẹ́ nínú yín, láti fẹ́ àti láti ṣiṣẹ́ fún ète rere rẹ̀.

  34. 19 Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run,

    ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.

    20 Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,

    tí ó ní ipá,

    tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, tì ó sì ń se ìfẹ́ rẹ̀.

    21 Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo,

    ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

    22 Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní

    ibi gbogbo ìjọba rẹ̀.

    Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

  35. 51 Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀;

    o ti tú àwọn onígbèéraga ká ní ìrònú ọkàn wọn.

    52 Ó ti mú àwọn alágbára kúrò lórí ìtẹ́ wọn,

    o sì gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ lékè.

    53 Ó ti fi ohun tí ó dára kún àwọn tí ebi ń pa

    ó sì rán àwọn ọlọ́rọ̀ padà ní òfo.

  36. 44  Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, bí kò ṣe pé Baba tí ó rán mi fà á, Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́.

  37. 65  Ó sì wí pé, “Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, kò sí ẹni tí ó lè tọ̀ mí wá, bí kò ṣe pé a fi fún un láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá.”

  38. 10 Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi;

    Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.

  39. 1 Ní ọdún tí ọba Ussiah kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ìṣẹ́tí aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. 2 Àwọn Serafu wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò. 3  Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé,

    “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun

    gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”

    4  Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹmpili sì kún fún èéfín.

    5 Mo kígbe pé, “Ègbé ni fún mi! Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ.

    6 Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn Serafu wọ̀nyí fò wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀yín iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú ní orí pẹpẹ. 7 Èyí ni ó fi kàn mí ní ẹnu tí ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ti kan ètè rẹ; a ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù.”

  40. 27  Àní nítòótọ́ ní Herodu àti Pọntiu Pilatu, pẹ̀lú àwọn aláìkọlà àti àwọn ènìyàn Israẹli kó ara wọn jọ ní ìlú yìí láti dìtẹ̀ sí Jesu Ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ, ẹni tí ìwọ ti fi àmì òróró yàn, 28 láti ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ rẹ̀ ti pinnu ṣáájú pé yóò ṣe.

  41. 38 Ǹjẹ́ èmi wí fún un yín nísinsin yìí, ṣọ́ra fún àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, kí ẹ sí fi wọn sílẹ̀, nítorí bí ìmọ̀ tàbí iṣẹ́ yìí bá jẹ́ ti ènìyàn, a ó bì í ṣubú. 39 Ṣùgbọ́n bí ti Ọlọ́run bá ní, ẹ̀yin kì yóò lè bì í ṣubú; kí ó má ba à jẹ́ pé, a rí yín bí ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà.”

  42. 26 Ará, ẹ kíyèsi ohun tí ẹ jẹ́ nígbà tí a pè yín. Kì í ṣe ọ̀pọ̀ yín jẹ ọlọ́gbọ́n nípa àgbékalẹ̀ ti ènìyàn, tàbí ọ̀pọ̀ nínú yín jẹ́ ènìyàn pàtàkì, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọ̀pọ̀ nínú yín jẹ́ ọlọ́lá nípa ibi tí a gbé bí i. 27  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tí yàn àwọn òmùgọ̀ ayé láti fi dààmú àwọn ọlọ́gbọ́n; Ọlọ́run sì ti yàn àwọn ohun aláìlera ayé láti fi dààmú àwọn ohun tí ó ni agbára. 28  Àti àwọn ohun tí ayé tí kò ní ìyìn, àti àwọn ohun tí a kẹ́gàn, ni Ọlọ́run sì ti yàn, àní àwọn ohun tí kò sí, láti sọ àwọn ohun tí ó wà di asán. 29  Nítorí kí ó má ba à sí ẹnìkan tí yóò ṣògo níwájú rẹ̀. 30  Nítorí rẹ̀ ni ẹ̀yin ṣe wà nínú Kristi Jesu ẹni ti ó jásí ọgbọ́n fún wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—èyí ń ni, òdodo, ìwà mímọ́ àti ìràpadà wa. 31  Nítorí náà, bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni ti ó bá ń ṣògo kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.”

  43. 1 Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti ní onírúurú ọ̀nà, 2 ṣùgbọ́n ní ìgbà ìkẹyìn yìí Ọlọ́run ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tí ó fi ṣe ajogún ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá gbogbo ayé yìí àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀. 3 Ọmọ tí í ṣe ìtànṣán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkára rẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró. Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọláńlá ní òkè. 4 Nítorí náà, ó sì ti fi bẹ́ẹ̀ di ẹni tí ó ga ní ipò ju angẹli lọ, bí ó ti jogún orúkọ èyí tí ó tayọ̀ tiwọn.

  44. 11  Mo sì rí ìtẹ́ funfun ńlá kan, àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, níwájú ẹni tí ayé àti ọ̀run fò lọ; a kò sì rí ààyè fún wọn mọ́. 12 Mo sì rí àwọn òkú, àti èwe àti àgbà, wọn dúró níwájú ìtẹ́; a sì ṣí àwọn ìwé sílẹ̀; a sì ṣí àwọn ìwé mìíràn kan sílẹ̀ tí í ṣe ìwé ìyè: a sì ṣe ìdájọ́ fún àwọn òkú láti inú ohun tí a ti kọ sínú àwọn ìwé náà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn. 13 Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́; àti òkú àti ipò òkú sì jọ̀wọ́ òkú tí ó wà nínú wọn pẹ̀lú: a sì ṣe ìdájọ́ wọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn. 14 Àti ikú àti ipò òkú ni a sì sọ sínú adágún iná. Èyí ni ikú kejì. 15  Bí a bá sì rí ẹnikẹ́ni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìyè, a ó sọ ọ́ sínú adágún iná.

  45. 39 Ẹ gbà kí ẹ sì fi sọ́kàn lónìí pé Olúwa ni Ọlọ́run lókè ọ̀run lọ́hùn ún àti ní ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ níhìn-ín. Kò sí òmíràn mọ́.

  46. 10 A ó fọ́ àwọn ọ̀tá Olúwa túútúú;

    láti ọ̀run wá ni yóò sán àrá sí wọn;

    Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé.

    “Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀,

    yóò si gbé ìwo ẹni àmì òróró rẹ̀ sókè.”

  47. 31 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn;

    lẹ́ kí wọn kí ó sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, pé “Olúwa jẹ ọba!”

  48. 28 nítorí ìjọba ni ti Olúwa.

    Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè.

  49. 9 Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀;

    ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin.

    10 Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán;

    ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í.

    11 Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé,

    àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni.

  50. 2 Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wá,

    ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

  51. 4 Olúwa ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́

    kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú.

  52. 21 Ǹjẹ́ o kò tí ì mọ̀

    ìwọ kò tí ì gbọ́?

    A kò tí ì sọ fún ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá?

    Ìwọ kò tí ì mọ láti ìgbà ìpìlẹ̀ ayé?

    22 Òun jókòó lórí ìtẹ́ ní òkè òbírí ilẹ̀ ayé,

    àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata.

    Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà,

    ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé.

    23 Ó sọ àwọn ọmọ ọba di asán

    àti àwọn aláṣẹ ayé yìí ni ó ti sọ dòfo.

    24 Gẹ́rẹ́ tí a ti gbìn wọ́n,

    kété tí a gbìn wọ́n,

    kété tí wọ́n fi gbòǹgbò múlẹ̀,

    bẹ́ẹ̀ ni ó fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n gbogbo wọn sì gbẹ,

    bẹ́ ni ìjì líle sì gbá wọn lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò.

    25 “Ta ni ẹ ó fi mi wé?

    Tàbí ta ni ó bá mi dọ́gba?” ni Ẹni Mímọ́ wí.

    26 Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wo àwọn ọ̀run.

    Ta ni ó dá àwọn wọ̀nyí?

    Ẹni tí ó mú àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ jáde wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan

    tí ó sì pè wọ́n ní orúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan.

    Nítorí agbára ńlá àti ipá rẹ̀,

    ọ̀kan ṣoṣo nínú wọn kò sọnù.

  53. 15 Èmi ni Olúwa, Ẹni Mímọ́ rẹ,

    Ẹlẹ́dàá Israẹli, ọba rẹ.”

  54. 37  Nítorí kò sí ohun tí Ọlọ́run kò le ṣe.”

  55. 17 Ǹjẹ́ fún ọba ayérayé, àìdíbàjẹ́, àìrí, Ọlọ́run kan ṣoṣo, ni ọlá àti ògo wà fún láéláé. Àmín.

  56. 11  Mo sì rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó, ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòtítọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun. 12  Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkára rẹ̀. 13 A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀, a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 14 Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọ̀run tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lórí ẹṣin funfun. 15  Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi sá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn.” Ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè. 16  Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ:

    Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa.

    17  Mo sì rí angẹli kan dúró nínú oòrùn; ó sì fi ohùn rara kígbe, ó ń wí fún gbogbo àwọn ẹyẹ tí ń fò ní agbede-méjì ọ̀run pé, “Ẹ wá ẹ sì kó ara yín jọ pọ̀ sí àsè ńlá Ọlọ́run; 18 kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba, àti ẹran-ara àwọn olórí ogun àti ẹran-ara àwọn ènìyàn alágbára, àti ẹran àwọn ẹṣin, àti ti àwọn tí ó jókòó lórí wọn, àti ẹran-ara ènìyàn gbogbo, àti ti òmìnira, àti ti ẹrú, àti ti èwe àti ti àgbà.”

    19 Mo sì rí ẹranko náà àti àwọn ọba ayé, àti àwọn ogun wọn tí a gbá jọ láti bá ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà àti ogun rẹ̀ jagun. 20 A sì mú ẹranko náà, àti wòlíì èké nì pẹ̀lú rẹ̀, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ń tan àwọn tí ó gba àmì ẹranko náà àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀ jẹ. Àwọn méjèèjì yìí ni a sọ láààyè sínú adágún iná tí ń fi sulfuru jó. 21 Àwọn ìyókù ni a sì fi idà ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà pa, àní idà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde, gbogbo àwọn ẹyẹ sì ti ipa ẹran-ara wọn yó.

  57. 11 Olúwa sì sọ fún un pé, “Ta ni ó fún ènìyàn ni ẹnu? Ta ni ó mú un ya odi tàbí adití? Ta ni ó mú un ríran, tàbí mú un fọ́jú? Ǹjẹ́ kì í ṣe èmi Olúwa?

  58. 39 “Wò ó báyìí pé, Èmi fúnra à mi, Èmi ni!

    Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi.

    Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè.

    Mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná,

    kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi.

  59. 11 Bí a ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ọkàn wa pami kò sì sí okun kankan fún wa mọ́ nítorí i yín, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run ní òkè ọ̀run àti ní ayé.

  60. 1  Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi, ọba Persia, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí Jeremiah sọ ṣẹ, Olúwa ru ọkàn Kirusi ọba Persia sókè láti ṣe ìkéde jákèjádò gbogbo agbègbè ìjọba rẹ̀, kí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé,

    2 “Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia wí pé:

    “ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹmpili Olúwa fún un ní Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda. 3 Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda, láti kọ́ tẹmpili Olúwa Ọlọ́run Israẹli, Ọlọ́run tí ó wà ní Jerusalẹmu. 4 Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni náà bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu.’ ”

  61. 6 Ìwọ nìkan ni Olúwa. Ìwọ ni ó dá ọ̀run, àní àwọn ọ̀run tí ó ga jù pẹ̀lú gbogbo ogun wọn, ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀. Ìwọ sì pa gbogbo wọn mọ́ láàyè, ogun ọ̀run sì ń sìn ọ́.

  62. Ti Dafidi. Saamu.

    1  Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀,

    ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;

    2 nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí òkun

    ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.

  63. 6  Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ,

    ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni.

  64. 2 Báwo ni Olúwa Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó

    ọba ńlá lórí gbogbo ayé.

  65. 1 Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ;

    ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ

    àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára.

    Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;

    kò sì le è yí.

  66. 2 Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;

    ìwọ wà títí ayérayé.

  67. Orin fún ìgòkè.

    1 Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí,

    ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run.

  68. 3 Olúwa tí ó dá ọ̀run òun ayé,

    kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá.

  69. 16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi

    nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé,

    àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,

    ní ọjọ́ tí a dá wọn,

    nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.

  70. 8 “Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín,

    tàbí ọ̀nà yín a ha máa ṣe ọ̀nà mi,”

    ni Olúwa wí.

    9 “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ,

    bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ

    àti èrò mi ju èrò yín lọ.

  71. 1  Báyìí ni Olúwa wí:

    “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,

    ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.

    Níbo ni ilé tí ẹ ó kọ́ fún mi wà?

    Níbo ní ibi ìsinmi mi yóò gbé wà?

  72. 7 Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ?

    Ọba àwọn orílẹ̀-èdè?

    Nítorí tìrẹ ni.

    Láàrín àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní orílẹ̀-èdè

    àti gbogbo ìjọba wọn,

    kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ.

  73. 7 Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun, 8 tí orílẹ̀-èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà nínú àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn. 9 Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan. 10 Bí ó bá sì ṣe búburú níwájú mi, tí kò sì gba ohùn mi gbọ́, nígbà náà ni èmi yóò yí ọkàn mi padà ní ti rere, èyí tí mo wí pé, èmi ó ṣe fún wọn.

  74. 17 “Háà! Olúwa Olódùmarè, ìwọ tí o dá ọ̀run àti ayé pẹ̀lú títóbi agbára rẹ àti gbogbo ọ̀rọ̀ apá rẹ. Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ láti ṣe.

  75. 27 “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run gbogbo ẹran-ara. Ǹjẹ́ ohun kan ha a ṣòro fún mi bí?

  76. 19 Ìwọ, Olúwa, jẹ ọba títí láé;

    ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn.

  77. 26  Lókè àwọ̀ òfúrufú tó borí wọn yìí ni ohun tí ó ní ìrísí ìtẹ́. Ìtẹ́ náà dàbí òkúta safire, lókè ní orí ìtẹ́ ní ohun tó dàbí ènìyàn wà. 27 Láti ibi ìbàdí ènìyàn náà dé òkè, o dàbí irin tí ń kọ yànrànyànràn. O dàbí pe kìkì iná ni, láti ibi ìbàdí rẹ dé ìsàlẹ̀ dàbí iná tó mọ́lẹ̀ yí i ká. 28 Ìmọ́lẹ̀ tó yí i ká yìí dàbí ìrísí òṣùmàrè tó yọ nínú àwọsánmọ̀ ní ọjọ́ òjò, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ tò yí i ká.

    Báyìí ni ìrísí ògo Olúwa. Nígbà tí mo rí i, mo dojúbolẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn ẹnìkan tó ń sọ̀rọ̀.

  78. 19 Ní òru, àṣírí náà hàn sí Daniẹli ní ojú ìran. Nígbà náà ni Daniẹli fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run 20 Daniẹli wí pé:

    “Ọpẹ́ ni fún orúkọ Ọlọ́run láé àti láéláé;

    tirẹ̀ ni ọgbọ́n àti agbára.

    21 Ó yí ìgbà àti àkókò padà;

    ó mú ọba jẹ, ó ń mú wọn kúrò.

    Ó fún àwọn amòye ní ọgbọ́n

    àti ìmọ̀ fún àwọn tí ó ní òye.

    22 Ó fi ohun ìjìnlẹ̀ àti àṣírí hàn;

    ó mọ ohun tí ó pamọ́ nínú òkùnkùn

    àti ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ wà.

    23 Mo dúpẹ́, mo sì fi ìyìn fún ọ, ìwọ Ọlọ́run àwọn baba mi:

    ó ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbára

    ó ti fi àwọn nǹkan tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ hàn fún mi

    nítorí tí ìwọ ti fi àlá ọba hàn wá.”

  79. 9  “Bí mo ṣe ń wò,

    “a gbé ìtẹ́ ọba kan kalẹ̀,

    ẹni ìgbàanì jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀.

    Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú;

    irun orí rẹ̀ funfun bí òwú,

    ìtẹ́ ọba rẹ̀ rí bí ọwọ́ iná.

    Àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ ń jó bí i iná.

    10  Odò iná ń sàn,

    ó ń jáde ní iwájú rẹ̀ wá.

    Àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un;

    ọ̀nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún nígbà ẹgbàárùn-ún dúró níwájú rẹ̀.

    Àwọn onídàájọ́ jókòó,

    a sì ṣí ìwé wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀.

  80. 9 Olúwa yóò sì jẹ ọba lórí gbogbo ayé; ni ọjọ́ náà ni Olúwa kan yóò wa orúkọ rẹ̀ nìkan náà ni orúkọ.

  81. 6 Ológoṣẹ́ márùn-ún sá à ni a ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì? A kò sì gbàgbé ọ̀kan nínú wọn níwájú Ọlọ́run? 7  Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín ni a kà pé ṣánṣán. Nítorí náà kí ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ̀yin ní iye lórí ju ológoṣẹ́ púpọ̀ lọ.

  82. 3  Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo; lẹ́yìn rẹ̀ a kò sì dá ohun kan nínú ohun tí a ti dá. 4  Nínú rẹ̀ ni ìyè wà, ìyè yìí náà sì ni ìmọ́lẹ̀ aráyé,

  83. 12  Ṣùgbọ́n iye àwọn tí ó gbà á, àní àwọn náà tí ó gbà orúkọ rẹ̀ gbọ́, àwọn ni ó fi ẹ̀tọ́ fún láti di ọmọ Ọlọ́run. 13  Àwọn ọmọ tí kì í ṣe nípa ẹ̀jẹ̀, tàbí nípa ti ìfẹ́ ara, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípa ìfẹ́ ti ènìyàn, bí kò ṣe láti ọwọ́ Ọlọ́run.

  84. 1 “Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni olùṣọ́gbà. 2 Gbogbo ẹ̀ka nínú mi tí kò bá so èso, òun a mú kúrò, gbogbo ẹ̀ka tí ó bá sì so èso, òun a wẹ̀ ẹ́ mọ́, kí ó lè so èso sí i. 3  Ẹ̀yin mọ́ nísinsin yìí nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín. 4  Ẹ máa gbé inú mi, èmi ó sì máa gbé inú yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fún ara rẹ̀ bí kò ṣe pé ó ba ń gbé inú àjàrà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹ bá ń gbé inú mi.

    5 “Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó ń gbé inú mi, àti èmi nínú rẹ̀, òun ni yóò so èso lọ́pọ̀lọ́pọ̀, nítorí ní yíya ara yín kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ kò lè ṣe ohun kan. 6 Bí ẹnìkan kò bá gbé inú mi, a gbé e sọnù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka, a sì gbẹ; wọn a sì kó wọn jọ, wọn a sì sọ wọ́n sínú iná, wọn a sì jóná.

  85. 10 Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò fọhùn sí? Ìwọ kò mọ̀ pé, èmi ní agbára láti dá ọ sílẹ̀, èmi sì ní agbára láti kàn ọ́ mọ́ àgbélébùú?”

    11  Jesu dá a lóhùn pé, “Ìwọ kì bá tí ní agbára kan lórí mi, bí kò ṣe pé a fi í fún ọ láti òkè wá, nítorí náà ẹni tí ó fi mí lé ọ lọ́wọ́ ni ó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀jù.”

  86. 5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, à ní ọ̀pọ̀ ọlọ́run kéékèèké mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé (gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ “ọlọ́run” ṣe wa náà ní ọ̀pọ̀ “olúwa” wa). 6  Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan ṣoṣo Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípasẹ̀ rẹ̀.

  87. 8  Ṣùgbọ́n ó sọ nípa tí Ọmọ rẹ̀ pé,

    “Ìtẹ́ rẹ, Ọlọ́run, láé àti láéláé ni,

    ọ̀pá aládé òdodo ni ọ̀pá ìjọba rẹ.

  88. 17 Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣíṣe búburú lọ.

  89. 6 Àti àwọn angẹli tí kò tọ́jú ipò ọlá wọn, ṣùgbọ́n tí wọn fi ipò wọn sílẹ̀, àwọn tí ó pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n àìnípẹ̀kun ní ìsàlẹ̀ òkùnkùn de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá nì.