15 Bible Verses About Creativity

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Creativity
  1. 30  Nígbà náà ni Mose wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Wò ó, Olúwa ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, 31 Ó sì ti fi Ẹ̀mí Ọlọ́run kún un, pẹ̀lú ọgbọ́n, òye, ìmọ̀ àti gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 32 Láti máa ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ, 33 láti gbẹ́ òkúta àti láti tò ó, láti fún igi àti láti ṣiṣẹ́ ni gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 34 Ó sì fún òun àti Oholiabu ọmọ Ahisamaki ti ẹ̀yà Dani, ni agbára láti kọ́ àwọn tókù. 35 Ó sì fi ọgbọ́n kún wọn láti ṣe gbogbo onírúurú iṣẹ́, ti oníṣọ̀nà, ti ayàwòrán, ti aránsọ, ti aláṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ní ọ̀gbọ̀ dáradára àti ti ahunṣọ, gbogbo èyí tí ọ̀gá oníṣẹ́-ọnà àti ayàwòrán ń ṣe.

  2. 26  Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a dá ènìyàn ní àwòrán ara wa, gẹ́gẹ́ bí àwa ti rí, kí wọn kí ó jẹ ọba lórí ẹja òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, ẹran ọ̀sìn, gbogbo ilẹ̀ àti lórí ohun gbogbo tí ń rìn lórí ilẹ̀.”

    27  Nítorí náà, Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀,

    ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a,

    akọ àti abo ni ó dá wọn.

    28 Ọlọ́run sì súre fún wọn, Ọlọ́run sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ ṣe ìkápá ayé. Ẹ ṣe àkóso àwọn ẹja inú òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó ń rìn ní orí ilẹ̀.”

    29 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, “Mo fi gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ń so èso fún un yín bí oúnjẹ àti àwọn igi eléso pẹ̀lú. Gbogbo rẹ̀ yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín. 30 Àti fún àwọn ẹranko inú igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ohun afàyàfà, gbogbo ohun tó ní èémí ìyè nínú ni mo fi ewéko fún bí oúnjẹ.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

  3. 15 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti,

    tí mo dá pẹ̀lú rẹ,

    òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.

    16 Wò o nísinsin yìí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,

    àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.

    17 Òun a máa jù ìrù rẹ̀ bí i igi kedari,

    iṣan itan rẹ̀ dìjọ pọ̀.

    18 Egungun rẹ̀ ní ògùṣọ̀ idẹ,

    Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.

    19 Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run;

    síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.

    20 Nítòótọ́ òkè ńlá ńlá ní i mu ohun jíjẹ fún un wá,

    níbi tí gbogbo ẹranko igbó máa ṣiré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀.

    21 Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótusì,

    lábẹ́ eèsún àti ẹrẹ̀.

    22 Igi lótusì síji wọn bò o;

    igi arọrọ odò yí i káàkiri.

    23 Kíyèsi i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ;

    ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jordani ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀.

    24 Ẹnìkan ha lè mú un ní ojú rẹ̀,

    tàbí dẹkùn fún tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?

  4. 1  Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé. 2 Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rábàbà lójú omi.

    3  Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà. 4 Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn. 5 Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “ọ̀sán,” àti òkùnkùn ní “òru.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní.

    6  Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí òfúrufú kí ó wà ní àárín àwọn omi, láti pààlà sí àárín àwọn omi.” 7 Ọlọ́run sì dá òfúrufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfúrufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

  5. 13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;

    ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.

    14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;

    ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;

    èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú.

    15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,

    nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.

    Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,

    16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi

    nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé,

    àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,

    ní ọjọ́ tí a dá wọn,

    nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.

    17 Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,

    iye wọn ti pọ̀ tó!

    18 Èmi ìbá kà wọ́n,

    wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye:

    nígbà tí mo bá jí,

    èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.

  6. 10 Nítorí àwa ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tí a ti dá nínú Kristi Jesu fún àwọn iṣẹ́ rere, èyí tí Ọlọ́run ti pèsè tẹ́lẹ̀, fún wa láti ṣe.

  7. 7 Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn,

    Mo mú àlàáfíà wá, Mo sì dá àjálù;

    Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.

    8 “Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀;

    jẹ́ kí àwọsánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀.

    Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbagada,

    jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè,

    jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀;

    Èmi Olúwa ni ó ti dá a.

    9  “Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà,

    ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀.

    Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé:

    ‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’

    Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé,

    ‘Òun kò ní ọwọ́?’

    10 Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé,

    ‘Kí ni o bí?’

    tàbí sí ìyá rẹ̀,

    ‘Kí ni ìwọ ti bí?’

    11 “Ohun tí Olúwa wí nìyìí,

    Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀.

    Nípa ohun tí ó ń bọ̀,

    ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi,

    tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí?

    12 Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé

    tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀.

    Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run;

    mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta.

  8. 29 Ìwọ ha rí ènìyàn tí ó ń fi àìṣe ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀?

    Òun yóò dúró níwájú àwọn ọba;

    òun kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn lásán.

  9. 15 Ìwọ sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníṣẹ́ ènìyàn: àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn oníṣọ̀nà òkúta àti àwọn agbẹ́-òkúta, àti gẹ́gẹ́ bí onírúurú ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní gbogbo onírúurú iṣẹ́. 16 Nínú wúrà, fàdákà àti idẹ àti irin oníṣọ̀nà tí kò ní ìwọ̀n. Nísinsin yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”

  10. 7  Olúwa Ọlọ́run sì fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ ènìyàn, ó si mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, ènìyàn sì di alààyè ọkàn.

  11. 1  Nítorí náà mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín ará, kí ẹ̀yin kí ó fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè mímọ́, ìtẹ́wọ́gbà, èyí ni iṣẹ́ ìsìn yín tí ó tọ̀nà. 2  Kí ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí; ṣùgbọ́n kí ẹ paradà láti di tuntun ní èrò inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọ́run, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ti ó sì pé.

    3 Ǹjẹ́ mo wí fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wà nínú yín, nípa oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n kí ó le rò níwọ́ntúnwọ́nsì, bí Ọlọ́run ti fi ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún olúkúlùkù. 4  Nítorí gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ẹ̀yà púpọ̀ nínú ara kan, tí gbogbo ẹ̀yà kò sì ní iṣẹ́ kan náà, 5  bẹ́ẹ̀ ni àwa, tí a jẹ́ púpọ̀, a jẹ́ ara kan nínú Kristi, àti olúkúlùkù ẹ̀yà ara ọmọnìkejì rẹ̀. 6  Ǹjẹ́ bí àwa sì ti ń rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn gbà gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún wa, bí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, kí a máa sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìgbàgbọ́; 7 tàbí iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí a kọjú sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa tàbí ẹni tí ń kọ́ni, kí ó kọjú sí kíkọ́. 8 Tàbí ẹni tí ó ń gbani níyànjú, sí ìgbìyànjú; ẹni tí ń fi fún ni kí ó máa fi inú kan ṣe é; ẹni tí ń ṣe olórí, kí ó máa ṣe é ní ojú méjèèjì; ẹni tí ń ṣàánú, kí ó máa fi inú dídùn ṣe é.

  12. 14 Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà.

    15 Máa fiyèsí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá; kí ìlọsíwájú rẹ lè hàn gbangba fún gbogbo ènìyàn.

  13. 19 Ní ti ère, oníṣọ̀nà ni ó dà á,

    ti alágbẹ̀dẹ wúrà sì fi wúrà bò ó

    tí a sì ṣe ẹ̀wọ̀n ọ̀nà sílífà fún un.

    20 Ọkùnrin kan tí ó tálákà jù kí ó lè mú

    irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá,

    wá igi tí kò le è rà.

    Ó wá oníṣọ̀nà tí ó

    láti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú.

  14. 10 Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère,

    tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?

    11 Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójútì;

    àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n.

    Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sì

    fi ìdúró wọn hàn;

    gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú ìpayà àti àbùkù.

    12 Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò,

    ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú;

    ó fi òòlù ya ère kan,

    ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀,

    ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un;

    kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a.

    13 Gbẹ́nàgbẹ́nà fi ìwọ̀n wọ́n ọ́n

    ó sì fi lẹ́ẹ̀dì ṣe àmì sí ara rẹ̀,

    Ó tún fi ìfà fá a jáde

    ó tún fi òsùwọ̀n ṣe àmì sí i.

    Ó gbẹ́ ẹ ní ìrí ènìyàn

    gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nínú ògo rẹ̀,

    kí ó lè máa gbé nínú ilé òrìṣà.

  15. 20  Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀, bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.