108 Bible Verses About Protection

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Protection
  1. 1 Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo

    ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.

    2 Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé,

    “Òun ni ààbò àti odi mi,

    Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.

    3 Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú

    ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ

    àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.

    4 Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí,

    àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;

    òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.

    5 Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,

    tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,

    6 tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn,

    tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.

    7 Ẹgbẹ̀rún (1,000) yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,

    ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,

    ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.

    8 Ìwọ yóò máa wò ó pẹ̀lú ojú rẹ

    àti wo ìjìyà àwọn ẹni búburú.

    9 Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ,

    ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.

    10 Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́,

    Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.

    11  Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ

    láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ;

    12 wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,

    nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta.

  2. Saamu ti Dafidi.

    1 Olúwa ni olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.

    2  Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù,

    Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́,

    3 Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò.

    Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo

    nítorí orúkọ rẹ̀.

    4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn

    láàrín àfonífojì òjìji ikú,

    èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan,

    nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;

    ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ,

    wọ́n ń tù mí nínú.

  3. Orin fún ìgòkè.

    1 Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—

    níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá?

    2 Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wá,

    ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

    3 Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀;

    ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.

    4 Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́,

    kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.

    5 Olúwa ni olùpamọ́ rẹ;

    Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

    6 Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán

    tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.

    7 Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo

    yóò pa ọkàn rẹ mọ́

    8 Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́

    láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.

  4. 10 Ní àkótán, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀. 11 Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè kọ ojú ìjà sí àrékérekè èṣù. 12 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara ní àwa ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àti àwọn ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run. 13 Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè dúró tiiri sí ọjọ́ ibi, nígbà tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ohun gbogbo tan kí ẹ sì dúró. 14  Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra. 15  Tí ẹ sì ti fi ìmúra ìyìnrere àlàáfíà wọ ẹsẹ̀ yín ní bàtà. 16 Ní àfikún, ẹ mú àpáta ìgbàgbọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin lè máa fi paná gbogbo ọfà iná ẹni ibi náà. 17 Kí ẹ sì mú àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

  5. 3  Ṣùgbọ́n olódodo ni Olúwa, ẹni tí yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóò sì pa yín mọ́ kúrò nínú ibi. 4 Àwa sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ní ti ohun tí ẹ ń ṣe, àti pé àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a pàṣẹ fún un yín ni ẹ̀yin ń ṣe. 5 Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín ṣọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kristi.

  6. Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. Orin.

    1 Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa

    ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.

    2 Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,

    tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.

  7. 3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;

    ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.

    4 Olúwa ni mo kígbe sókè sí,

    ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.

    5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;

    mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.

  8. 10  Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;

    má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.

    Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́.

    Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.

    11 “Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọ

    ni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹlẹ́yà;

    àwọn tó ń bá ọ jà

    yóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé.

    12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀tá rẹ,

    ìwọ kì yóò rí wọn.

    Gbogbo àwọn tí ó gbóguntì ọ́

    yóò dàbí ohun tí kò sí.

  9. 11 Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀;

    jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí.

    Tan ààbò rẹ sórí wọn,

    àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ.

  10. 7 Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;

    ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;

    ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.

  11. 10 Orúkọ Olúwa, ilé ìṣọ́ agbára ni;

    olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.

    11 Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn;

    wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.

    12 Ṣáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga,

    ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.

  12. 17 kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò lè ṣe nǹkan,

    àti gbogbo ahọ́n tí ó dìde sí ọ ní ìdájọ́ ni ìwọ ó dá ní ẹ̀bi.

    Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ Olúwa,

    èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,”

    ni Olúwa wí.

  13. 28  Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun; wọn kì yóò sì ṣègbé láéláé, kò sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi. 29 Baba mi, ẹni tí ó fi wọ́n fún mi pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò sì ṣí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba mi. 30  Ọ̀kan ni èmi àti Baba mi.”

  14. 16 Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀, àdúrà mi ni kí a má ṣe kà á sí wọn lọ́rùn. 17 Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára; pé nípasẹ̀ mi kí a lè wàásù náà ní àwàjálẹ̀, àti pé kí gbogbo àwọn aláìkọlà lè gbọ́; a sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún náà. 18 Olúwa yóò yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ búburú gbogbo, yóò sì mu mí dé inú ìjọba ọ̀run. Ẹni ti ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.

  15. 13  Kò sí ìdánwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọ́run, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin ba à lè faradà á.

  16. 6  Jẹ́ alágbára kí o sì ní ìgboyà. Má ṣe bẹ̀rù tàbí jáyà nítorí i wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń lọ pẹ̀lú rẹ, Òun kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”

  17. 7 Angẹli Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká

    ó sì gbà wọ́n.

    8 Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;

    ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.

    9 Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́,

    nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

  18. 23  Kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀, Ọlọ́run àlàáfíà, sọ yín di mímọ́ pátápátá. Kí Ọlọ́run pa ẹ̀mí àti ọkàn pẹ̀lú ara yín mọ́ pátápátá ní àìlábùkù, títí di ìgbà wíwá Jesu Kristi Olúwa wa. 24 Olóòtítọ́ ni ẹni tí ó pè yín, yóò sì ṣe.

  19. 13 Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró ṣinṣin kí ẹ sì rí ìdáǹdè tí Olúwa yóò fi fún un yín lónìí, àwọn ará Ejibiti ti ẹ̀yin rí lónìí ni ẹ kò ni tún padà rí wọn mọ́. 14 Olúwa yóò jà fún un yín; kí ẹ̀yin kí ó sá à mu sùúrù.”

  20. 1 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìí,

    ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu,

    ẹni tí ó mọ ọ́, ìwọ Israẹli:

    “Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;

    Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe.

    2 Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,

    Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ;

    àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá

    wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.

    Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,

    kò ní jó ọ;

    ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.

    3 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,

    Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ;

    Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ,

    Kuṣi àti Seba dípò rẹ.

  21. 6 Olúwa ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù.

    Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?

    7 Olúwa ń bẹ fún mi; òun ni olùrànlọ́wọ́ mi.

    Nítorí náà ni èmi ó ṣe rí ìṣẹ́gun mi lórí àwọn tí ó kórìíra mi.

    8 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa

    ju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ.

    9 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa

    ju à ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ-aládé lọ.

  22. 7 Fi ìṣeun ìyanu ìfẹ́ ńlá rẹ hàn

    ìwọ tí ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là

    lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn.

    8 Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú rẹ;

    fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ,

    9 lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú tí ń fóròó mi,

    kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.

    10 Wọ́n pa ọkàn aláìláàánú wọn mọ́,

    wọ́n sì fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìgbéraga.

  23. 17 Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́,

    Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.

    18 Olúwa súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn;

    ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.

    19 Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀,

    ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.

    20 Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́;

    kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.

  24. 7 Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;

    ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,

    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.

  25. 3 Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò,

    àti ìwo ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi.

    Àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi;

    ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá.

    4 “Èmi ké pe Olúwa, tí ó yẹ láti máa yìn,

    ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

  26. Fún adarí orin. Ní ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí ó sá níwájú Saulu lọ sínú ihò òkúta.

    1 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi,

    nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà.

    Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ

    títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.

  27. 114 Ìwọ ni ààbò mi àti asà mi;

    èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.

  28. 1 Ní àkótán ará, ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa wa. Kì í ṣe ìnira fún mi láti kọ̀wé ohun kan náà sí yín, ṣùgbọ́n fún yín ó jẹ́ ohun ààbò. 2 Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn ajá, ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn oníṣẹ́ búburú, ẹ sì kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn onílà. 3  Nítorí àwa ni onílà, tí ń sin Ọlọ́run nípa ti Ẹ̀mí, àwa sì ń ṣògo nínú Kristi Jesu, àwa kò sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹran-ara.

  29. 14 “Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́;

    èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.

    15 Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn;

    èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú,

    èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un.

    16 Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn,

    èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”

  30. Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa tí ó kọ sí Olúwa, ọ̀rọ̀ orin tí ó kọ sí Olúwa fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ Saulu ọ̀tá rẹ̀. Ó wí pé.

    1  Mo fẹ́ ọ, Olúwa, agbára mi.

    2 Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi;

    Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi.

    Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.

  31. 16 Ṣùgbọ́n èmi ó kọrin agbára rẹ,

    n ó kọrin ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀;

    nítorí ìwọ ni ààbò mi,

    ibi ìsádi mi ní ìgbà ìpọ́njú.

  32. 4 Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú orí yín,

    Èmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró.

    Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ;

    Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀.

  33. 31  Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa? 32  Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti fi Ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le ṣòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí? 33  Ta ni ẹni náà tí ó lè dá wa lẹ́bi, àwa ẹni tí Ọlọ́run ti yàn fún ara rẹ̀. Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ẹni tí ó dáríjì wá, tí ó sì fi wá sípò tí ó dára lọ́dọ̀ rẹ̀.

  34. 6  Nítorí náà ni àwa ṣe ń fi ìgboyà wí pé,

    “Olúwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, èmi kì yóò bẹ̀rù;

    kín ni ènìyàn lè ṣe sí mi?”

  35. 7 Nítorí náà, ẹ tẹríba fún Ọlọ́run. Ẹ kọ ojú ìjà sí èṣù, òun ó sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín. 8 Ẹ súnmọ́ Ọlọ́run, òun ó sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀; ẹ sì ṣe ọkàn yín ní mímọ́, ẹ̀yin oníyèméjì.

  36. Fún adarí orin. Tí ohùn orin “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí Saulu rán àwọn olùṣọ́ sí ilé Dafidi kí òun bá le rí i pa.

    1 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi, Ọlọ́run;

    dáàbò bò mí kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó dìde sí mi.

  37. 7 Rere ni Olúwa,

    òun ni ààbò ní ọjọ́ ìpọ́njú.

    Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e,

  38. 15 Èmi kò gbàdúrà pé, kí ìwọ kí ó mú wọn kúrò ní ayé, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó pa wọ́n mọ́ kúrò nínú ibi.

  39. Miktamu ti Dafidi.

    1 Pa mí mọ́, Ọlọ́run,

    nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.

    2 Mo sọ fún Olúwa, “Ìwọ ni Olúwa mi,

    lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan.”

  40. 30 Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà rẹ̀ pé,

    a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwa

    òun ni àpáta ààbò fún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.

    31 Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa?

    Ta ní àpáta bí kò ṣe Olúwa wa?

    32 Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrè

    ó sì mú ọ̀nà mi pé.

  41. 22 Olúwa ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà;

    kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé tí yóò jẹ̀bi.

  42. 7  àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣípayá, kí èmi má ba à gbé ara mi ga rékọjá, a sì ti fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ìránṣẹ́ Satani láti pọ́n mi lójú, kí èmi má bá a gbéraga rékọjá. 8 Nítorí nǹkan yìí ni mo ṣe bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta pé, kí ó lé e kúrò lára mi. 9 Òun sì wí fún mi pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ, nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fi ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kristi lè máa gbé inú mi. 10  Nítorí náà èmi ní inú dídùn nínú àìlera gbogbo, nínú ẹ̀gàn gbogbo, nínú àìní gbogbo, nínú inúnibíni gbogbo, nínú wàhálà gbogbo nítorí Kristi. Nítorí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.

  43. 5  Kí ọkàn yín má ṣe fà sí ìfẹ́ owó, ki ohun tí ẹ ní tó yin; nítorí òun tìkára rẹ̀ ti wí pé,

    “Èmi kò jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀,

    bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”

  44. 5  Lẹ́yìn èyí ni èṣù gbé e lọ sí ìlú mímọ́ náà; ó gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili. 6  Ó wí pé, “Bí ìwọ̀ bá jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ. A sá à ti kọ̀wé rẹ̀ pé,

    “ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí tìrẹ

    wọn yóò sì gbé ọ sókè ni ọwọ́ wọn

    kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”

    7  Jesu sì dalóhùn, “A sá à ti kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”

  45. 42 Nígbà tí Filistini náà sì wo Dafidi láti òkè délẹ̀, ó sì rí i wí pé ọmọ kékeré kùnrin ni, ó pọ́n ó sì lẹ́wà lójú, ó sì kẹ́gàn an rẹ̀. 43 Ó sì wí fún Dafidi pé, “Ṣé ajá ni mí ni? Tí o fi tọ̀ mí wá pẹ̀lú ọ̀pá?” Filistini sì fi Dafidi bú pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀. 44 Filistini náà sì wí Dafidi pé, “Wá níbí, èmi yóò fi ẹran-ara rẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run jẹ àti fún àwọn ẹranko tí ó wà nínú igbó!”

    45 Dafidi sì wí fún Filistini pé, “Ìwọ dojú ìjà kọ mí pẹ̀lú idà, ọ̀kọ̀ àti ọfà, ṣùgbọ́n èmi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli tí ìwọ tí gàn. 46 Lónìí yìí ni Olúwa yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, èmi yóò sì pa ọ́, èmi yóò sì gé orí rẹ. Lónìí èmi yóò fi òkú ogun Filistini fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko igbó, gbogbo ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run wà ní Israẹli. 47 Gbogbo àwọn tí ó péjọ níbí ni yóò mọ̀ pé kì í ṣe nípa ọ̀kọ̀ tàbí idà ni Olúwa fi ń gbàlà; ogun náà ti Olúwa ni, yóò sì fi gbogbo yín lé ọwọ́ wa.”

    48 Bí Filistini ṣe súnmọ́ iwájú láti pàdé e rẹ̀. Dafidi yára sáré sí òun náà láti pàdé e rẹ̀. 49 Dafidi ti ọwọ́ sí àpò rẹ̀, ó sì mú òkúta jáde wá ó sì fì í, ó sì jù ú sí ọ̀kọ́kán iwájú orí Filistini. Òkúta náà sì wọ̀ ọ́ níwájú orí, ó sì ṣubú ó sì dojúbolẹ̀ ní orí ilẹ̀.

  46. 9 Nítorí ojú Olúwa yí gbogbo ayé ká láti fi agbára fún àwọn ẹni tí ó ní ọkàn pípé sí i. Ìwọ ti ṣe ohun aṣiwèrè, láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ yóò wà lójú ogun.”

  47. 5 “Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkérora àwọn aláìní,

    Èmi yóò dìde nísinsin yìí,” ni Olúwa wí.

    “Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn.”

  48. 35 Ìwọ fi asà ìṣẹ́gun rẹ̀ fún mi,

    ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé mí dúró;

    àti ìwà pẹ̀lẹ́ rẹ̀ sọ mí di ńlá.

    36 Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ̀ mi di ńlá ní ìsàlẹ̀ mi,

    kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀.

  49. 7 Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi,

    mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ.

    8 Ọkàn mí fà sí ọ:

    ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.

    9 Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ni a ó parun;

    wọn ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.

  50. 4 Olúwa, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú;

    yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì

    ẹni tí ó ti pinnu rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú.

  51. 3 “Ẹ múra àpáta, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré,

    kí ẹ sì súnmọ́ ojú ìjà!

    4 Ẹ di ẹṣin ní gàárì,

    kí ẹ sì gùn ún.

    Ẹ dúró lẹ́sẹẹsẹ

    pẹ̀lú àṣíborí yín!

    Ẹ dán ọ̀kọ̀ yín,

    kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin.

  52. 28 Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀.

  53. 4 Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀. 5 Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí. 6  Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. 7 Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu.

  54. 4 Ẹ̀yin ọmọ mi, ti Ọlọ́run ni yín, ẹ̀yin sì tí ṣẹ́gun wọn, nítorí ẹni tí ń bẹ nínú yin tóbi jú ẹni tí ń bẹ nínú ayé lọ.

  55. 10 Nítorí tí ìwọ tí pa ọ̀rọ̀ sùúrù mi mọ́, èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, tí ń bọ̀ wá dé bá gbogbo ayé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò.

  56. 1 Nígbà tí o bá lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀tá rẹ, tí o sì rí ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ológun tí ó jù ọ́ lọ, má ṣe bẹ̀rù u wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ń mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, yóò wà pẹ̀lú rẹ. 2 Nígbà tí o bá fẹ́ lọ jagun, àlùfáà yóò wá síwájú, yóò sì bá ọmọ-ogun sọ̀rọ̀, 3 yóò sì wí pé, “Gbọ́, ìwọ Israẹli, lónìí ò ń jáde lọ sójú ogun sí ọ̀tá rẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín ṣojo tàbí bẹ̀rù; ẹ má ṣe jáyà tàbí kí ẹ fi ààyè fún ìjayà níwájú u wọn. 4 Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín ní bá yín lọ, láti bá àwọn ọ̀tá yín jà fún yín, láti gbà yín là.”

  57. 5  Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mose, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.

  58. 9 Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

  59. 8  Mo ti gbé Olúwa síwájú mi ní ìgbà gbogbo.

    Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.

  60. Fún adarí orin. Saamu Dafidi.

    1 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní:

    Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú.

    2 Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́:

    yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀

    kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.

  61. Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi.

    1 Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;

    tẹ́tí sí àdúrà mi.

    2 Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,

    mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;

    mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.

    3 Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,

    ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.

    4 Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé

    kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.

  62. 2 Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi;

    Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.

  63. 25 Má ṣe bẹ̀rù ìdààmú òjijì,

    tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú.

    26 Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ,

    kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.

  64. 5 Gba ọgbọ́n, gba òye,

    má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀.

    6 Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́,

    fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojútó ọ.

    7 Ọgbọ́n ni ó ga jù; nítorí náà gba ọgbọ́n.

    Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye.

    8 Gbé e ga, yóò sì gbé ọ ga

    dìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ.

    9 Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹ

    yóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.”

  65. 23 Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá;

    nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láìsí ewu.

  66. 5 “Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù;

    òun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn.

  67. 17 kọ́ láti ṣe rere!

    Wá ìdájọ́ òtítọ́,

    tu àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú.

    Ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,

    gbà ẹjọ́ opó rò.

  68. 17 Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ,

    Ó ní agbára láti gbà ọ là.

    Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀;

    Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀,

    Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”

  69. 19 Kíyèsi i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá, kò sì ṣí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára.

  70. 16 “Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. 17  Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n kí a le ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là.

  71. 24 Ǹjẹ́ mo fi yín lé ẹni tí o lè pa yín mọ́ kúrò nínú ìkọ̀sẹ̀, tí o sì lè mú yín wá síwájú ògo rẹ̀ láìlábùkù pẹ̀lú ayọ̀ ńlá lọ́wọ́— 25 tí Ọlọ́run ọlọ́gbọ́n nìkan ṣoṣo, Olùgbàlà wa, ní ògo àti ọláńlá, ìjọba àti agbára, nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, kí gbogbo ayé tó wà, nísinsin yìí àti títí láéláé! Àmín.

  72. Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni.

    1 Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà

    àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni;

    bí kò ṣe pé Olúwa bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.

  73. 15 Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà. Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.”

  74. 37 Yóò wí pé, “Òrìṣà wọn dà báyìí,

    àpáta tí wọ́n fi ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé e wọn,

    38 ọlọ́run tí ó jẹ ọ̀rá ẹran ẹbọ wọn

    tí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn?

    Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n!

    Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín!

    39 “Wò ó báyìí pé, Èmi fúnra à mi, Èmi ni!

    Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi.

    Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè.

    Mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná,

    kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi.

  75. 38 Saulu fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ wọ Dafidi, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ìhámọ́ra ogun, ó sì fi ìbòrí idẹ kan bò ó ní orí.

  76. Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

    1 Kí Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú;

    kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.

  77. 15 Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo;

    etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn.

  78. 3 Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bà mí,

    èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.

    4 Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ rẹ,

    nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà mí

    kí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?

  79. Orin fún ìgòkè.

    1 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni,

    tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé.

    2 Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,

    bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká

    láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

  80. 19 Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ;

    ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.

  81. 33 ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ó bá fetí sí mi, yóò gbé láìléwu

    yóò sì wà nínú ìdẹ̀ra, láìsí ìbẹ̀rù ìpalára.”

  82. 21 Ibi kì í ṣubú lu olódodo rárá

    ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn.

  83. 26 Nínú ìbẹ̀rù Olúwa ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára,

    yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.

  84. 12 Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fi ara pamọ́

    ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí, kàkà kí ó dúró ó tẹ̀síwájú, ó sì jìyà rẹ̀.

  85. 1 Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Juda.

    Àwa ní ìlú alágbára kan,

    Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣe

    ògiri àti ààbò rẹ̀.

    2 Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn

    kí àwọn olódodo orílẹ̀-èdè kí ó lè wọlé,

    orílẹ̀-èdè tí ó pa ìgbàgbọ́ mọ́.

    3 Ìwọ yóò pa á mọ́ ní àlàáfíà pípé

    ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin,

    nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.

    4 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa títí láé,

    nítorí Olúwa, Olúwa ni àpáta ayérayé náà.

    5 Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀

    ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀;

    ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹsẹ

    ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.

    6 Ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀

    ẹsẹ̀ aninilára n nì,

    ipasẹ̀ àwọn òtòṣì.

  86. 16  A ó sì fi yín hàn láti ọwọ́ àwọn òbí yín wá, àti àwọn arákùnrin, àti àwọn ìbátan, àti àwọn ọ̀rẹ́; òun ó sì mú kì a pa nínú yín. 17  A ó sì kórìíra yín lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi. 18  Ṣùgbọ́n irun orí yín kan kì yóò ṣègbé. 19  Nínú ìdúró ṣinṣin yín ni ẹ̀yin ó jèrè ọkàn yín.

  87. 33 “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àlàáfíà nínú mi. Nínú ayé, ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú; ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”

  88. 11  Èmi kò sí ní ayé mọ́, àwọn wọ̀nyí sì ń bẹ ní ayé, èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́, ní orúkọ rẹ, kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, àní gẹ́gẹ́ bí àwa. 12  Nígbà tí mo wà pẹ̀lú wọn ní ayé, mo pa wọ́n mọ́ ní orúkọ rẹ; àwọn tí ìwọ fi fún mi, ni mo ti pamọ́, ẹnìkan nínú wọn kò sọnù bí kò ṣe ọmọ ègbé; kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ.

  89. 19  Olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ṣùgbọ́n ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìbínú Ọlọ́run; nítorí a ti kọ ọ́ pé, Olúwa wí pé, “Tèmi ni ẹ̀san, èmi ó gbẹ̀san.”

  90. 13  Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi.

  91. 8 Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún àwọn ará ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ.

  92. 19 Àwa mọ̀ pé tí Ọlọ́run ni wá, àti gbogbo ayé ni ó wà lábẹ́ agbára ẹni búburú náà.

  93. 32 Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe Olúwa?

    Ta ni àpáta, bí kò ṣe Ọlọ́run wa.

  94. Ṣiggaioni ti Dafidi, èyí tí ó kọ sí Olúwa nípa Kuṣi, ará Benjamini.

    1 Olúwa Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú rẹ;

    gba mí là kí o sì tú mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi,

  95. 9  Ọlọ́run Olódodo,

    Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn,

    tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú

    tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́.

  96. 9 Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,

    ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.

    10 Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ,

    nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.

  97. Ti Dafidi.

    1 Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi;

    ta ni èmi yóò bẹ̀rù?

    Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi,

    ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?

  98. 19 Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó,

    èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,

    èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn

    tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn.

  99. 11 Ìwọ má ṣe, fa àánú rẹ tí ó rọ́nú sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa;

    jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ

    kí ó máa pa mi mọ́ títí ayérayé.

    12 Nítorí pé àìníye ibi

    ni ó yí mi káàkiri,

    ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi,

    títí tí èmi kò fi ríran mọ́;

    wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,

    àti wí pé àyà mí ti kùnà.

    13  Jẹ́ kí ó wù ọ́,

    ìwọ Olúwa,

    láti gbà mí là;

    Olúwa,

    yára láti ràn mí lọ́wọ́.

  100. 7 Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run;

    Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.

    8 Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn;

    tú ọkàn rẹ jáde sí i,

    nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.

  101. 12 Nítorí yóò gba àwọn aláìní

    nígbà tí ó bá ń ké,

    tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.

    13 Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní

    yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.

    14 Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá

    nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀.

  102. 10 Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́

    Olúwa, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́

    ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.

  103. Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

    1 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa,”

    kí ni Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;

    2 ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,

    nígbà tí àwọn ènìyàn gbógun sí wa,

    3 nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè

    nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa,

    4 nígbà náà ni omi

    wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀,

    5 nígbà náà ni agbéraga

    omi ìbá borí ọkàn wa.

  104. 7 Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo,

    Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé,

    8 Ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́

    Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.

  105. 5 Ní ìsinsin yìí, èmi yóò wí fún ọ

    ohun tí n ó ṣe sí ọgbà àjàrà mi.

    Èmi yóò gé igi inú rẹ̀ kúrò,

    a ó sì pa á run,

    Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀

    yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.

    6 Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro

    láì kọ ọ́ láì ro ó,

    ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀.

    Èmi yóò sì pàṣẹ fún kurukuru

    láti má ṣe rọ̀jò sórí i rẹ̀.”

    7 Ọgbà àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogun

    ni ilé Israẹli

    àwọn ọkùnrin Juda

    sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀.

    Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí.

    Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke.

  106. 1  “Ní àkókò náà, ni Mikaeli, ọmọ-aládé ńlá, ẹni tí o ń dáàbò bo àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò dìde. Àkókò ìpọ́njú yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè títí di àkókò náà. Ṣùgbọ́n ní àkókò náà àwọn ènìyàn rẹ̀, gbogbo àwọn tí a bá ti rí orúkọ wọn nínú ìwé ni a ó gbàlà.

  107. 13 Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdánwò,

    ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi.

    Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín.’

  108. 28 Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó le pa ara nìkan; ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ẹ̀mí. Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí ó le pa ẹ̀mí àti ara run ní ọ̀run àpáàdì. 29 Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan? Síbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lu ilẹ̀ lẹ́yìn Baba yin. 30 Àti pé gbogbo irun orí yín ni a ti kà pé. 31 Nítorí náà, ẹ má ṣe fòyà; ẹ̀yin ní iye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.