46 Bible Verses About Happiness

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Happiness
  1. 4 Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀. 5 Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí. 6  Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. 7 Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu.

    8 Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò. 9  Àwọn nǹkan tí ẹ̀yin ti kọ́, tí ẹ̀yin sì ti gbà, tí ẹ̀yin sì ti gbọ́, tí ẹ̀yin sì ti rí lọ́wọ́ mi, ẹ máa ṣe wọ́n: Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.

  2. 8  Mo ti gbé Olúwa síwájú mi ní ìgbà gbogbo.

    Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.

    9 Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;

    ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,

    10  nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú,

    tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.

    11 Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí;

    Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ,

    pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

  3. 12 Olùfẹ́, ẹ má ṣe ka ìdánwò gbígbóná ti ń bẹ láàrín yín láti dán yín wò bi ẹni pé ohun àjèjì ni ó dé bá yín. 13 Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábápín ìyà Kristi, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn. 14  Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹni ìbùkún ni yín: nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín.

  4. 3 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì máa ṣe rere;

    torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.

    4 Ṣe inú dídùn sí Olúwa;

    òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.

  5. 22 Ṣùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́, 23 ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni níjanu, òfin kan kò lòdì sí irú wọ̀nyí,

  6. 13 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,

    ẹni tí ó tún ní òye sí i,

    14 nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ

    ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.

    15 Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;

    kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.

    16 Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;

    ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.

    17 Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura,

    òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà.

    18 Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á;

    àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.

  7. 12 Kí àwọn ọmọkùnrin wa

    kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn,

    àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé

    tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.

    13 Àká wa yóò kún

    pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ

    àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún,

    ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:

    14 àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo

    kí ó má sí ìkọlù,

    kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn,

    kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.

    15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀,

    ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà,

    tí ẹni tí Ọlọ́run Olúwa ń ṣe.

  8. 2 Ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírúurú ìdánwò, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀; 3 nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìdánwò ìgbàgbọ́ yín ń ṣiṣẹ́ sùúrù. 4 Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù kí ó ṣiṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti aláìlábùkù tí kò ṣe aláìní ohunkóhun.

  9. 9 Máa jẹ ayé pẹ̀lú ìyàwó rẹ, ẹni tí o fẹ́ràn, ní gbogbo ọjọ́ ayé àìní ìtumọ̀ yí tí Ọlọ́run ti fi fún ọ lábẹ́ oòrùn—gbogbo ọjọ́ àìní ìtumọ̀ rẹ. Nítorí èyí ni ìpín tìrẹ ní ayé àti nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ ní abẹ́ oòrùn. 10 Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, ṣe é pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, nítorí kò sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ìpinnu tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú isà òkú níbi tí ò ń lọ.

  10. 2 Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi,

    èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù.

    Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi,

    òun ti di ìgbàlà mi.”

    3 Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi

    láti inú kànga ìgbàlà.

    4 Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé,

    “Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,

    jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,

    ohun tí ó ti ṣe

    kí o sì kéde pé a ti gbé

    orúkọ rẹ̀ ga.

    5 Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo,

    jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé.

    6 Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni,

    nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo

    ti Israẹli láàrín yín.”

  11. 9 “Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì fẹ́ yín, ẹ dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀. 10  Bí ẹ̀yin bá pa òfin mi mọ́, ẹ ó dúró nínú ìfẹ́ mi; gẹ́gẹ́ bí èmi ti pa òfin Baba mi mọ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀. 11 Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí ayọ̀ mi kí ó lè wà nínú yín, àti kí ayọ̀ yín kí ó lè kún.

  12. 22 Ọkàn tí ó túká jẹ́ oògùn gidi,

    ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ.

  13. 13 Inú dídùn máa ń mú kí ojú túká

    ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ọkàn máa ń pa ẹ̀mí run.

  14. 13 Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yin ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrètí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.

  15. 6 Ẹ yọ̀ nínú èyí púpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe nísinsin yìí fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀n bí ó ti yẹ, a ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánwò bá yín nínú jẹ́. 7 Àwọn wọ̀nyí sì wáyé ki ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. 8 Ẹni tí ẹ̀yin fẹ́ láìrí, ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i nísinsin yìí ẹ̀yin sì ń yọ ayọ̀ tí a kò lè fi ẹnu sọ, tí ó sì kún fún ògo; 9 ẹyin sì ń gba ìlépa ìgbàgbọ́ yín, àní ìgbàlà ọkàn yín.

  16. Orin fún ìgòkè.

    1 Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa:

    tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

    2 Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ

    ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ.

  17. 16 Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. 17 Ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èmi ó ti ṣe, nítorí tí èmi kò ní ibi tí èmi ó gbé kó èso mi jọ sí.’

    18 “Ó sì wí pé, ‘Èyí ni èmi ó ṣe: èmi ó wó àká mi palẹ̀, èmi ó sì kọ́ èyí tí ó tóbi; níbẹ̀ ni èmi ó gbé to gbogbo èso àti ọrọ̀ mi jọ sí. 19 Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; sinmi, máa jẹ, máa mu, máa yọ̀.’

    20 “Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè, lóru yìí ni a ó béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ; ǹjẹ́ ti ta ni nǹkan wọ̀nyí yóò ha ṣe, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀?’

  18. 1  Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nípa ìgbàgbọ́, àwa ní àlàáfíà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. 2  Nípasẹ̀ ẹni tí àwa sì ti rí ọ̀nà gbà nípa ìgbàgbọ́ sí inú oore-ọ̀fẹ́ yìí nínú èyí tí àwa gbé dúró. Àwa sì ń yọ̀ nínú ìrètí ògo Ọlọ́run. 3  Kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa tún ń ṣògo nínú ìjìyà pẹ̀lú, bí a ti mọ̀ pé ìjìyà ń ṣiṣẹ́ sùúrù; 4 àti pé sùúrù ń ṣiṣẹ́ ìwà rere; àti pé ìwà rere ń ṣiṣẹ́ ìrètí. 5  Ìrètí kì í sì í dójúti ni nítorí a ti dá ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún wa.

  19. 11 Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní: nítorí pé ni ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀. 12 Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní. 13  Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi.

  20. 5 Bí ọkùnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, o kò gbọdọ̀ ran lọ sí ogun tàbí kí ó ní iṣẹ́ kan láti ṣe. Ó ní láti ní òmìnira fún ọdún kan kí ó dúró sílé kí ó sì mú inú dídùn bá ìyàwó rẹ̀ tí ó fẹ́.

  21. 17 “Kíyèsi i, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí,

    nítorí náà, má ṣe gan ìbáwí Olódùmarè.

  22. 20  Nígbà tí ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní:

    “Alábùkún fún ni ẹ̀yin òtòṣì,

    nítorí tiyín ni ìjọba Ọlọ́run.

    21 Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ebi ń pa

    nísinsin yìí; nítorí tí ẹ ó yóò.

    Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ń

    sọkún nísinsin yìí: nítorí tí ẹ̀yin ó rẹ́rìn-ín.

    22 Alábùkún fún ni ẹ̀yin, nígbà tí àwọn ènìyàn bá kórìíra yín,

    tí wọ́n bá yà yín kúrò nínú ẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n bá gàn yín,

    tí wọ́n bá ta orúkọ yín nù bí ohun búburú,

    nítorí Ọmọ Ènìyàn.

    23 “Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, kí ẹ sì fò fún ayọ̀, nítorí púpọ̀ ní èrè yín ni ọ̀run. Báyìí ni àwọn baba yín ṣe ṣe sí àwọn wòlíì.

  23. 26 Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹni dẹ́ṣẹ̀, Ó fún un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Eléyìí pẹ̀lú, asán ni, ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

  24. Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

    1 Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ,

    àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!

    2 Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un,

    bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. Sela.

    3 Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà

    ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.

    4 Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un,

    àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.

    5 Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un;

    ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ.

    6 Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un:

    ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.

  25. 13 Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìn-ín, ọkàn le è máa kérora;

    ayọ̀ sì le è yọrí sí ìbànújẹ́.

  26. 1 Ní àkótán ará, ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa wa. Kì í ṣe ìnira fún mi láti kọ̀wé ohun kan náà sí yín, ṣùgbọ́n fún yín ó jẹ́ ohun ààbò.

  27. 15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì,

    Olúwa wọ́n ó máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.

    16 Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,

    wọn ń yin òdodo rẹ.

  28. 21 “Olúwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́: ìwọ ṣe olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí ohun púpọ̀, bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’

  29. 52 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn si kún fún ayọ̀ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́.

  30. 6 Ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn èrè ńlá ni. 7 Nítorí a kò mú ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ. 8 Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yẹ́ kí ó tẹ́ wa lọ́rùn.

  31. 13 Nígbà náà ni Lea wí pé, “Mo ní ayọ̀ gidigidi! Àwọn ọmọbìnrin yóò sì máa pe mí ní Alábùkún fún.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Aṣeri.

  32. 9 Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú ọ ṣe rere nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ, àti nínú gbogbo ọmọ inú rẹ, agbo ẹran ọ̀sìn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ. Olúwa yóò tún mú inú dídùn sínú rẹ yóò sì mú ọ ṣe déédé, gẹ́gẹ́ bí ó ti fi inú dídùn sínú àwọn baba rẹ. 10 Bí o bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ tí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́ àti àṣẹ tí a kọ sínú ìwé òfin yìí kí o sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.

  33. 4 Nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run,

    sí Ọlọ́run ayọ̀ mi àti ìdùnnú mi,

    èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú dùùrù,

    ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.

    5 Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí?

    Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi?

    Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,

    nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun ni

    Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

  34. 24 Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá:

    ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.

  35. 2 Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,

    àti ahọ́n wa kọ orin;

    nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,

    Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.

  36. 10 Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa;

    ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi.

    Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlà

    ó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo;

    gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe orí rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà,

    àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.

  37. 10 Angẹli náà sì wí fún wọn pé, “Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìyìnrere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo. 11  Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónìí ní ìlú Dafidi, tí í ṣe Kristi Olúwa.

  38. 28 Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀. 29  Nítorí àwọn ẹni tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ni ó sì yàn tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán ọmọ rẹ̀, kí òun lè jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn arákùnrin púpọ̀. 30 Àti pé lẹ́yìn tí òun ti pè wá wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sọ wá di aláìjẹ̀bi lẹ́yìn èyí, ó fi rere Kristi kún inú ọkàn wa. Lékè gbogbo rẹ̀, ó fún wa ní ìdúró rere pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pinu ògo rẹ̀ fún wa.

  39. 22  Nítorí náà, ohun tí ìwọ bá gbàgbọ́ nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí, pa á mọ́ ní àárín ìwọ àti Ọlọ́run. Alábùkún fún ni ẹni náà tí kò dá ara rẹ̀ lẹ́bi nínú ohun tí ó yàn. 23 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ṣe iyèméjì, ó jẹ̀bi bí ó ba jẹ ẹ́, nítorí jíjẹ ẹ́ rẹ̀ kò ti inú ìgbàgbọ́ wá; bẹ́ẹ̀ sì ni, ohun gbogbo tí kò bá ti inú ìgbàgbọ́ wá, ẹ̀ṣẹ̀ ni.

  40. 9 Kò ṣe é ṣe fún wa láti dá ọpẹ́ tán lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ayọ̀ àti ìfẹ́ tí ó máa ń kún ọkàn wa nípa àdúrà wa fún un yín.

  41. 13 Inú ẹnikẹ́ni ha bàjẹ́ nínú yín bí? Jẹ́ kí ó gbàdúrà. Inú ẹnikẹ́ni ha dùn? Jẹ́ kí ó kọrin mímọ́.

  42. 8 Báwo ni inú àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe dùn tó! Báwo ni inú dídùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n sì ń gbọ́ ọgbọ́n rẹ!

  43. 6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wa?”

    Olúwa, jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,

    7 Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi

    ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.

  44. 5 Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn

    yóò fi ayọ̀ ka.

  45. 1 Mo rò nínú ọkàn mi, “Wá nísinsin yìí, èmi yóò sì dán ọ wò pẹ̀lú ìgbádùn láti ṣe àwárí ohun tí ó dára.” Ṣùgbọ́n eléyìí náà jásí asán.

  46. 19  Kí ni ìrètí wa, ayọ̀ wa, tàbí adé wa nínú èyí tí a ó ṣògo níwájú Jesu Olúwa nígbà tí òun bá dé? Ṣé ẹ̀yin kọ́ ni? 20  Nítòótọ́, ẹ̀yin ni ògo àti ayọ̀ wa.