58 Bible Verses About Gratefulness

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Gratefulness
  1. 15 Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan; kí ẹ sì máa dúpẹ́. 16  Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ máa kọ́ ọ, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin sí Ọlọ́run ní ọkàn ọpẹ́. 17 Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn ní orúkọ Jesu Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run Baba nípasẹ̀ rẹ̀.

  2. 15  Ẹ rí i pé kò sí ẹni tí ó fi búburú san búburú, ṣùgbọ́n ẹ máa lépa èyí tí í ṣe rere láàrín ara yín àti sí ènìyàn gbogbo.

    16  Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo. 17  Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo. 18  Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo nínú ipòkípò tí o wù kí ẹ wà; nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kristi Jesu nítòótọ́.

  3. 15 Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa rìn ní ìwà pípé, kì í ṣé bí àwọn òmùgọ̀, ṣùgbọ́n bí àwọn ọlọ́gbọ́n; 16  ẹ máa ra ìgbà padà, nítorí búburú ní àwọn ọjọ́. 17 Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòye ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí. 18 Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurùdu wà; ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. 19  Ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin Ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrin dídùn ní ọkàn yín sí Olúwa. 20 Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo fún ohun gbogbo lọ́wọ́ Ọlọ́run, àní Baba, ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wá.

    21 Ẹ máa tẹríba fún ara yín ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

  4. 6  Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. 7 Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu.

    8 Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò.

  5. 10  Ǹjẹ́ ẹni tí ń fi irúgbìn fún afúnrúgbìn, àti àkàrà fún oúnjẹ, yóò fi irúgbìn fún un yín, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, yóò sì mú èso òdodo yín bí sí i. 11 Bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo, fún ìlawọ́ yín gbogbo tí ń ṣiṣẹ́ ọpẹ́ sí Ọlọ́run nípa wa.

    12 Nítorí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìsìn yìí kò kún ìwọ̀n àìní àwọn ènìyàn mímọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ó túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọpẹ́ sí Ọlọ́run. 13  Nítorí ìdúró yin lábẹ́ ìdánwò iṣẹ́ ìsìn yìí, wọn yóò yin Ọlọ́run lógo fún ìgbọ́ràn yín ní gbígba ìyìnrere Kristi àti nípa ìlawọ́ ìdáwó yín fún wọn àti fún gbogbo ènìyàn. 14 Àti nínú àdúrà fún un yín, ọkàn wọn ń ṣe àfẹ́rí yín nítorí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ti ń bẹ nínú yín. 15  Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nítorí aláìlèfẹnusọ ẹ̀bùn rẹ̀!

  6. 6 Nítorí náà, bí ẹ̀yin ti gba Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin máa gbé nínú rẹ̀. 7 Ẹ fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí a sì gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ yín, bí a ti kọ́ yín, àti kí ẹ sì máa pọ̀ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́.

  7. 1 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa,

    ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.

    2 Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́

    kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò

    orin àti ìyìn.

    3 Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,

    ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.

  8. Ti Dafidi.

    1 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.

    2 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀,

    3 ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́

    tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,

    4 ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú

    ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,

    5 ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn

    kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.

  9. 18  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn. 19 Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn. 20  Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀, bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.

    21  Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn.

  10. 3 Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,

    kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé

    tirẹ̀ ni àwa, àwa ní ènìyàn rẹ̀

    àti àgùntàn pápá rẹ̀.

    4 Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́

    àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;

    ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.

    5 Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore

    ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;

    àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.

  11. ÌWÉ KARÙN-ÚN

    1 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;

    nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

    2 Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí,

    àwọn ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,

    3 àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì,

    láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,

    láti àríwá àti Òkun wá.

  12. 56 Oró ikú ni ẹ̀ṣẹ̀; àti agbára ẹ̀ṣẹ̀ ni òfin. 57 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fì ìṣẹ́gun fún wá nípa Olúwa wá Jesu Kristi!

    58 Nítorí náà ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ẹ máa dúró ṣinṣin, láìyẹsẹ̀, kí ẹ máa pọ̀ si í ní iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo, ní ìwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé iṣẹ́ yin kì í ṣe asán nínú Olúwa.

  13. 17 Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà.

  14. 14 Nítorí pé àwa kò ní ìlú tí o wa títí níhìn-ín, ṣùgbọ́n àwa ń wá èyí tí ń bọ.

    15  Ǹjẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyí yìí ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀. 16 Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣoore àti láti máa pín fun ni nítorí irú ẹbọ wọ̀nyí ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.

  15. Fún adarí orin. Ní ti ohun orin. “Ní ti ikú ọmọ.” Saamu ti Dafidi.

    1 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;

    èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo.

    2 Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ;

    èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.

  16. 15 Nítorí tiyín ní gbogbo rẹ̀, ki ọ̀pẹ lè dí púpọ̀ fún ògo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ ti ń gbòòrò sí i fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.

    16 Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, síbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di tuntun lójoojúmọ́.

  17. 2 Ẹ fi ara yín jì fún àdúrà gbígbà, kí ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì máa dúpẹ́;

  18. 25  Kíyèsi i, kí ẹ má ṣe kọ̀ ẹni tí ń kìlọ̀. Nítorí bí àwọn wọ̀nyí kò bá bọ́ nígbà tí wọn kọ̀ ẹni ti ń kìlọ̀ ni ayé, mélòó mélòó ni àwa kì yóò bọ́, bí àwa ba pẹ̀yìndà sí ẹni tí ń kìlọ̀ láti ọ̀run wá, 26  ohùn ẹni tí ó mi ayé nígbà náà, ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti ṣe ìlérí, wí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi ki yóò mi kìkì ayé nìkan, ṣùgbọ́n ọ̀run pẹ̀lú.” 27 Àti ọ̀rọ̀ yìí, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ìtumọ̀ rẹ̀ ni, mímú àwọn ohun wọ̀nyí ti a ń mì kúrò, bí ohun tí a ti dá, kí àwọn ohun tí a kò lè mì lè wà síbẹ̀.

    28 Nítorí náà bí àwa tí ń gbà ilẹ̀ ọba ti a kò lè mì, ẹ jẹ́ kí a dá ọpẹ́ nípa èyí ti a fi lè máa sin Ọlọ́run ni ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù rẹ̀. 29  Nítorí pé, “Ọlọ́run wa, iná ti ń jó ni run ni.”

  19. 30 Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga

    èmi yóò fi ọpẹ́ gbé orúkọ rẹ̀ ga.

    31 Eléyìí tẹ́ Olúwa lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọ

    ju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo rẹ̀ àti bàtà rẹ̀.

    32 Àwọn òtòṣì yóò rí, wọn yóò sì yọ̀:

    ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yín yóò sì wà láààyè!

  20. 14 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí wá nígbà gbogbo nínú Kristi, tí a sì ń fi òórùn dídùn ìmọ̀ rẹ̀ hàn nípa wa níbi gbogbo. 15 Nítorí òórùn dídùn Kristi ni àwa jẹ́ fún Ọlọ́run, nínú àwọn tí a ń gbàlà àti nínú àwọn tí ó ń ṣègbé. 16 Fún àwọn kan, àwa jẹ́ òórùn sí ikú, àti fún àwọn mìíràn òórùn ìyè sí ìyè. Ta ni ó ha si tọ́ fún nǹkan wọ̀nyí?

  21. 34  Fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára;

    ìfẹ́ ẹ rẹ̀ dúró títí láé.

  22. 1 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    2 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run:

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    3 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa,

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    4 Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    5 Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    6  Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    7  Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    8 Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    9 Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    10  Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    11  Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    12 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    13  Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    14 Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    15 Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    16 Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    17 Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    18 Ó sì pa àwọn ọba olókìkí

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    19 Sihoni, ọba àwọn ará Amori

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    20 Àti Ogu, ọba Baṣani;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    21 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    22 Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀,

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    23 Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    24 Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    25 Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

    26 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  23. Saamu. Orin. Fún Ọjọ́ Ìsinmi.

    1 Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa

    àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,

    2 láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀

    àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́,

    3 lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá

    àti lára ohun èlò orin haapu.

    4 Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn

    nípa iṣẹ́ rẹ Olúwa;

    èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

  24. 15  Nítorí ìdí èyí, nígbà tí mo ti gbúròó ìgbàgbọ́ ti ń bẹ láàrín yín nínú Jesu Olúwa, àti ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. 16  Èmi kò sì sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, àti láti máa rántí yín nínú àdúrà mi. 17 Mo sì ń béèrè nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọgbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ ọ́n sí i. 18  Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkàn yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìrètí ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́, 19 àti aláìlẹ́gbẹ́ títóbi agbára rẹ̀ fún àwa tí a gbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀, 20  èyí tí ó fi sínú Kristi, nígbà tí o ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún nínú àwọn ọ̀run. 21  Ó gbéga ju gbogbo ìjọba, àti àṣẹ, àti agbára, àti òye àti gbogbo orúkọ tí a ń dá, kì í ṣe ni ayé yìí nìkan, ṣùgbọ́n ni èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú. 22  Ọlọ́run sì ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ, 23  èyí tí i ṣe ara rẹ̀, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹni tí ó kún ohun gbogbo ní gbogbo ọ̀nà.

  25. 9 Ṣùgbọ́n èmi yóò fi orin ọpẹ́, rú ẹbọ sí ọ.

    Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́.

    ‘Ìgbàlà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.’ ”

  26. 3  Ó yẹ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, nítorí pé ìgbàgbọ́ yín ń dàgbà gidigidi, àti ìfẹ́ olúkúlùkù yín sí ara yín ń di púpọ̀. 4 Nítorí náà, àwa tìkára wa ń fi yín ṣògo nínú ìjọ Ọlọ́run, nítorí sùúrù àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni àti wàhálà yín tí ẹ̀yin náà ń fi ara dà.

  27. 16 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà tí wọn jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn, dojúbolẹ̀, wọn sì sin Ọlọ́run, 17 wí pé:

    “Àwa fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè,

    tí ń bẹ, tí ó sì ti wà,

    nítorí pé ìwọ ti gba agbára ńlá rẹ̀,

    ìwọ sì ti jẹ ọba.

  28. 41  Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò (níbi tí a tẹ́ ẹ sí). Jesu sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi. 42  Èmi sì ti mọ̀ pé, ìwọ a máa gbọ́ ti èmi nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n nítorí ìjọ ènìyàn tí ó dúró yìí ni mo ṣe wí i, kí wọn ba à lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.”

  29. 1 Jakọbu, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti ti Jesu Kristi Olúwa,

    Sí àwọn ẹ̀yà méjìlá tí ó fọ́n káàkiri, orílẹ̀-èdè:

    Àlàáfíà.

    2 Ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírúurú ìdánwò, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀; 3 nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìdánwò ìgbàgbọ́ yín ń ṣiṣẹ́ sùúrù. 4 Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù kí ó ṣiṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti aláìlábùkù tí kò ṣe aláìní ohunkóhun.

  30. 6 Alábùkún fún ni Olúwa!

    Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

    7 Olúwa ni agbára mi àti asà mi;

    nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́.

    Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀

    àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.

  31. 23 Mo dúpẹ́, mo sì fi ìyìn fún ọ, ìwọ Ọlọ́run àwọn baba mi:

    ó ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbára

    ó ti fi àwọn nǹkan tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ hàn fún mi

    nítorí tí ìwọ ti fi àlá ọba hàn wá.”

  32. 11  Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu, ó kọjá láàrín Samaria Galili. 12  Bí ó sì ti ń wọ inú ìletò kan lọ, àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá pàdé rẹ̀, wọ́n dúró ní òkèrè, 13  wọ́n sì kígbe sókè wí pé, “Jesu, Olùkọ́, ṣàánú fún wa.”

    14  Nígbà tí ó rí wọn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ í fi ara yín hàn fún àwọn àlùfáà.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n sì di mímọ́.

    15 Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé a mú òun láradá ó padà, ó sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo. 16 Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń dúpẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀: ará Samaria ni òun í ṣe.

    17 Jesu sì dáhùn wí pé, “Àwọn mẹ́wàá kí a sọ di mímọ́? Àwọn mẹ́sàn-án ìyókù ha dà? 18 A kò rí ẹnìkan tí ó padà wá fi ògo fún Ọlọ́run, bí kò ṣe àlejò yìí?” 19  Ó sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.”

  33. 47 “Olúwa ń bẹ́; olùbùkún sì ni àpáta mi!

    Gbígbéga sì ni Ọlọ́run àpáta ìgbàlà mi.

    48 Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbẹ̀san mi,

    àti ẹni tí ń rẹ àwọn ènìyàn sílẹ̀ lábẹ́ mi.

    49 Àti ẹni tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

    Ìwọ sì gbé mi sókè ju àwọn tí ó kórìíra mi lọ;

    ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin oníwà ipá.

    50  Nítorí náà èmi ó fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa,

    láàrín àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè, èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.

    51 “Òun ni ilé ìṣọ́ ìgbàlà fún ọba rẹ̀;

    ó sì fi àánú hàn fún ẹni àmì òróró rẹ̀,

    fún Dafidi, àti fún irú-ọmọ rẹ̀ títí láéláé.”

  34. 1  Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fún

    Olúwa, nítorí tí ó ṣeun.

    Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun,

    nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

  35. 21 Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn

    àti nítorí náà ní mo nírètí.

    22 Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé,

    nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.

    23 Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀;

    títóbi ni òdodo rẹ̀.

    24 Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa;

    nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.

    25 Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀,

    sí àwọn tí ó ń wá a.

  36. 16 “Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. 17  Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n kí a le ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là.

  37. 8  Ní àkọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi fún gbogbo yín, nítorí a ń ròyìn ìgbàgbọ́ yin káàkiri gbogbo ayé.

  38. 3 Mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín. 4 Nínú gbogbo àdúrà mi fún un yín, èmi ń fi ayọ̀ gbàdúrà, 5 nítorí ìdàpọ̀ yín nínú ìyìnrere láti ọjọ́ kìn-ín-ní wá títí di ìsinsin yìí. 6  Ohun kan yìí sá à dá mi lójú pé, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín, yóò ṣe àṣepé rẹ̀ títí di ọjọ́ náà tí Jesu Kristi yóò dé.

  39. 1  Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,

    jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

    2 Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;

    sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.

    3 Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀,

    jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.

  40. 24 Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá:

    ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.

  41. 28 Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ;

    ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga.

    29 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;

    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  42. 1 Mo fi Febe arábìnrin wa le yin lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ díákónì nínú ìjọ tí ó wà ní Kenkerea. 2 Mo rọ̀ yín kí ẹ gbà á ní orúkọ Olúwa, bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn mímọ́, kí ẹ̀yin kí ó sì ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà, nítorí pé òun jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti fún èmi náà pẹ̀lú.

    3  Ẹ kí Priskilla àti Akuila, àwọn tí ó ti jẹ́ alábáṣiṣẹ́pọ̀ mi nínú Kristi Jesu. 4 Àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn wéwu nítorí mi. Kì í ṣe èmi nìkan àti gbogbo àwọn ìjọ àwọn aláìkọlà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn.

  43. 11 Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní: nítorí pé ni ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀. 12 Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní. 13  Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi.

  44. 12 Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ;

    ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan.

    Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àti

    láti fi agbára fún ohun gbogbo.

    13 Nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, àwa fi ọpẹ́ fún Ọ,

    a sì fi ìyìn fún orúkọ rẹ̀ tí ó lógo.

    14 “Ṣùgbọ́n ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tinútinú bí irú èyí? Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ti wá, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ.

  45. 17 Èmi ó fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí òdodo rẹ̀,

    èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa Ọ̀gá-ògo jùlọ.

  46. 18 Nígbà náà ni èmi yóò ṣọpẹ́ fún Ọ nínú àjọ ńlá;

    èmi yóò máa yìn Ọ́ ní àwùjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn.

  47. 14 “Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run,

    kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ọ̀gá-ògo.

    15 Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú,

    èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”

  48. 6 Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọ,

    èmi yóò yin orúkọ rẹ, Olúwa,

    nítorí tí ó dára.

    7 Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogbo

    ojú mi ti wo ìṣẹ́gun lórí ọ̀tá mi.

  49. 21 Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.

    22 Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́

    kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ̀.

  50. 62 Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ

    nítorí òfin òdodo rẹ.

  51. 17 Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìsinsin yìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti lò; 18 kí wọn máa ṣoore, kí wọn máa pọ̀ ní iṣẹ́ rere, kí wọn múra láti pín fún ni, kí wọn ni ẹ̀mí ìbá kẹ́dùn; 19 kí wọn máa to ìṣúra ìpìlẹ̀ rere jọ fún ara wọn dé ìgbà tí ń bọ̀, kí wọn lè di ìyè tòótọ́ mú.

  52. 4  Èmi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi, 5 nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jesu Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́. 6 Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ́ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọingbọin, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kristi wá. 7 Ìfẹ́ rẹ ti fún mi ní ayọ̀ púpọ̀ àti ìgboyà, nítorí ìwọ, arákùnrin ti tu ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ lára.

  53. 8 Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́

    ìyanu rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn,

    9 nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́run

    ó sì fi ìre fún ọkàn tí ebi ń pa.

  54. Orin fún ìgòkè.

    1 Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà,

    àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.

    2 Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,

    àti ahọ́n wa kọ orin;

    nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,

    Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.

    3 Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;

    nítorí náà àwa ń yọ̀.

  55. Ti Dafidi.

    1 Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;

    níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.

    2 Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀

    èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ

    nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;

    nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.

    3 Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,

    ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.

    4 Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́,

    Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.

    5 Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa;

    nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.

  56. 30 Bí èmi ba fi ọpẹ́ jẹ ẹ́, èéṣe tí a fì ń sọ̀rọ̀ mi ní búburú nítorí ohun tí èmi dúpẹ́ fún.

    31 Nítorí náà tí ẹ̀yin bá jẹ tàbí tí ẹ bá mu tàbí ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sè, e máa ṣe gbogbo rẹ̀ fún ògo Ọlọ́run.

  57. 12 Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tí ó fún mi ní agbára, àní Kristi Jesu Olúwa wa, nítorí tí ó kà mí sí olóòtítọ́ ní yíyànmí sí iṣẹ́ rẹ̀. 13 Bí mo tilẹ̀ jẹ́ asọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run rí, àti onínúnibíni àti ìkà ènìyàn, ṣùgbọ́n mo rí àánú gbà, nítorí tí mo ṣe é nínú àìmọ̀ àti àìgbàgbọ́. 14 Oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa sì pọ̀ rékọjá pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́, tí ń bẹ nínú Kristi Jesu.

    15 Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà, pé Jesu Kristi wá sí ayé láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là; nínú àwọn ẹni tí èmi jẹ́ búburú jùlọ. 16 Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe rí àánú gbà, pé lára mi, bí olórí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni kí Jesu Kristi fi gbogbo ìpamọ́ra rẹ̀ hàn bí àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò gbà á gbọ́ sí ìyè àìnípẹ̀kun ìkẹyìn. 17 Ǹjẹ́ fún ọba ayérayé, àìdíbàjẹ́, àìrí, Ọlọ́run kan ṣoṣo, ni ọlá àti ògo wà fún láéláé. Àmín.

  58. 3 Ìyìn yẹ Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa! Ẹni tí ó tún wa bí gẹ́gẹ́ bí àánú ńlá rẹ̀ sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jesu Kristi kúrò nínú òkú, 4 àti sínú ogún àìdíbàjẹ́, àti àìlábàwọ́n, àti èyí tí kì í ṣá, tí a ti fi pamọ́ ni ọ̀run dè yin, 5 ẹyin tí a ń pamọ́ nípa agbára Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ si ìgbàlà, tí a múra láti fihàn ní ìgbà ìkẹyìn. 6 Ẹ yọ̀ nínú èyí púpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe nísinsin yìí fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀n bí ó ti yẹ, a ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánwò bá yín nínú jẹ́. 7 Àwọn wọ̀nyí sì wáyé ki ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. 8 Ẹni tí ẹ̀yin fẹ́ láìrí, ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i nísinsin yìí ẹ̀yin sì ń yọ ayọ̀ tí a kò lè fi ẹnu sọ, tí ó sì kún fún ògo; 9 ẹyin sì ń gba ìlépa ìgbàgbọ́ yín, àní ìgbàlà ọkàn yín.