82 Bible Verses About Fear and Worry

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Fear and Worry
  1. 4 Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀. 5 Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí. 6  Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. 7 Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu.

    8 Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò. 9  Àwọn nǹkan tí ẹ̀yin ti kọ́, tí ẹ̀yin sì ti gbà, tí ẹ̀yin sì ti gbọ́, tí ẹ̀yin sì ti rí lọ́wọ́ mi, ẹ máa ṣe wọ́n: Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.

  2. 6 Nítorí náà, ẹ rẹ ara yin sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kí òun lè gbe yín ga lákokò. 7  Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e; nítorí tí òun ń ṣe ìtọ́jú yín.

  3. 8  “Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ Israẹli, ìránṣẹ́ mi,

    Jakọbu, ẹni tí mo ti yàn,

    ẹ̀yin ìran Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi,

    9 mo mú ọ láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé,

    láti kọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó jìnnà jùlọ ni mo ti pè ọ́.

    Èmi wí pé, ‘Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi’;

    Èmi ti yàn ọ́ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì tí ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

    10  Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;

    má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.

    Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́.

    Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.

    11 “Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọ

    ni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹlẹ́yà;

    àwọn tó ń bá ọ jà

    yóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé.

    12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀tá rẹ,

    ìwọ kì yóò rí wọn.

    Gbogbo àwọn tí ó gbóguntì ọ́

    yóò dàbí ohun tí kò sí.

    13 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,

    tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú

    tí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù;

    Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.

    14 Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò,

    ìwọ Israẹli kékeré,

    nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,”

    ni Olúwa wí,

    olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.

  4. 4 Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;

    Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.

    5 Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;

    ojú kò sì tì wọ́n.

    6 Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn rẹ̀;

    ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.

    7 Angẹli Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká

    ó sì gbà wọ́n.

    8 Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;

    ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.

    9 Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́,

    nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

  5. 26 Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, òun ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yóò sì rán yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín. 27  Àlàáfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín pé, àlàáfíà mi ni mo fi fún yin, kì í ṣe bí ayé ti fi fún ni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ó wárìrì.

    28 “Ẹ̀yin sá ti gbọ́ bí mo ti wí fún yín pé, ‘Èmi ń lọ, èmi ó sì tọ̀ yín wá.’ Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fẹ́ràn mi, ẹ̀yin ìbá yọ̀ nítorí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba; nítorí Baba mi tóbi jù mí lọ.

  6. 26 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí pẹ̀lú sì ń ran àìlera wa lọ́wọ́: nítorí a kò mọ bí a ti ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń fi ìrora tí a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ̀ fún wa. 27  Ẹni tí ó sì ń wá inú ọkàn wò, ó mọ ohun ti ẹ̀mí, nítorí tí ó ń bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run.

    28 Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀.

  7. Fún adarí orin. Ti ohùn “Àdàbà lórí Óákù òkè réré.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí àwọn ará Filistini ka mọ́ ní Gati.

    1 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run,

    nítorí àwọn ènìyàn ń fi ìgbónára lépa mi;

    ní gbogbo ọjọ́ ni wọn ń kọjú ìjà sí mi, wọn ń ni mi lára.

    2 Àwọn ọ̀tá mi ń lé mi ní gbogbo ọjọ́,

    àwọn ènìyàn ń kọjú ìjà sí mi nínú ìgbéraga wọn.

    3 Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bà mí,

    èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.

    4 Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ rẹ,

    nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà mí

    kí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?

  8. 24 “Kò sì í ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀gá méjì. Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fi ara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sí. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀.

    25 “Nítorí náà, mo wí fún yín, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, ohun tí ẹ ó jẹ àti èyí tí ẹ ó mu; tàbí nípa ara yín, ohun tí ẹ ó wọ̀. Ṣé ẹ̀mí kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ tàbí ara ni kò ha ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ? 26 Ẹ wo àwọn ẹyẹ ojú ọrun; wọn kì í gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kójọ sínú àká, síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ̀yin kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí? 27 Ta ni nínú gbogbo yín nípa àníyàn ṣíṣe ti ó lè fi ìṣẹ́jú kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀?

    28 “Kí ni ìdí ti ẹ fi ń ṣe àníyàn ní ti aṣọ? Ẹ wo bí àwọn lílì tí ń bẹ ní igbó ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. 29 Bẹ́ẹ̀ ni mo wí fún yín pé, a kò ṣe Solomoni lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí. 30 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ bẹ́ẹ̀, èyí tí ó wà níhìn-ín lónìí ti a sì gbà sínú iná lọ́la, kò ha ṣe ni ṣe yín lọ́ṣọ̀ọ́ tó bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré? 31 Nítorí náà, ẹ má ṣe ṣe àníyàn kí ẹ sì máa wí pé, ‘Kí ni àwa yóò jẹ?’ tàbí ‘Kí ni àwa yóò mu?’ tàbí ‘Irú aṣọ wo ni àwa yóò wọ̀?’ 32 Nítorí àwọn kèfèrí ń fi ìwọra wá àwọn nǹkan wọ̀nyí bẹ́ẹ̀ ni Baba yín ní ọ̀run mọ̀ dájúdájú pé ẹ ní ìlò àwọn nǹkan wọ̀nyí. 33 Ṣùgbọ́n, ẹ kọ́kọ́ wá ìjọba Ọlọ́run ná àti òdodo rẹ̀, yóò sì fi gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kún un fún yín pẹ̀lú. 34 Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn ọ̀la, ọ̀la ni yóò ṣe àníyàn ara rẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.

  9. 6 Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń ran ọ létí pé kí ó máa rú ẹ̀bùn Ọlọ́run sókè èyí ti ń bẹ nínú rẹ nípa ìgbọ́wọ́lé mi. 7 Nítorí pé Ọlọ́run kò fún wa ni ẹ̀mí ìbẹ̀rù, bí kò ṣe ti agbára, àti ti ìfẹ́, àti ti ìsẹ́ra-ẹni ti ó yè kooro.

  10. 16 Báyìí ni àwa mọ̀, tí a sì gba ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa gbọ́.

    Ìfẹ́ ni Ọlọ́run; ẹni tí ó bá sì ń gbé inú ìfẹ́, ó ń gbé inú Ọlọ́run, àti Ọlọ́run nínú rẹ̀. 17  Nínú èyí ni a mú ìfẹ́ tí ó wà nínú wa pé, kí àwa bà á lè ni ìgboyà ní ọjọ́ ìdájọ́: nítorí pé bí òun tí rí, bẹ́ẹ̀ ni àwa sì rí ni ayé yìí. 18 Ìbẹ̀rù kò sí nínú ìfẹ́; ṣùgbọ́n ìfẹ́ tí ó pé ń lé ìbẹ̀rù jáde; nítorí tí ìbẹ̀rù ni ìyà nínú. Ẹni tí ó bẹ̀rù kò pé nínú ìfẹ́.

    19  Àwa fẹ́ràn rẹ̀ nítorí òun ni ó kọ́ fẹ́ràn wa.

  11. Saamu ti Dafidi.

    1 Olúwa ni olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.

    2  Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù,

    Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́,

    3 Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò.

    Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo

    nítorí orúkọ rẹ̀.

    4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn

    láàrín àfonífojì òjìji ikú,

    èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan,

    nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;

    ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ,

    wọ́n ń tù mí nínú.

  12. 22  Jesu sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Nítorí náà mo wí fún yín pé, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nítorí ẹ̀mí yín pé, kín ni ẹ̀yin yóò jẹ tàbí nípa ara yin pe kín ni ẹyin o fi bora. 23 Ẹ̀mí sá à ju oúnjẹ lọ, ara sì ju aṣọ lọ. 24  Ẹ kíyèsi àwọn ẹyẹ ìwò: wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè: wọn kò ní àká, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà, Ọlọ́run sá à ń bọ́ wọn: mélòó mélòó ni tí ẹ̀yin fi sàn ju ẹyẹ lọ! 25 Ta ni nínú yín nípa àníyàn ṣíṣe tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀? 26 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò ti lè ṣe èyí tí ó kéré bí eléyìí, èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣàníyàn nítorí ìyókù?

    27 “Ẹ kíyèsi àwọn lílì bí wọ́n ti ń dàgbà; wọn kì í ṣiṣẹ́, wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n kí èmi wí fún yín, a kò ṣe Solomoni pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ ní gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí. 28 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ tó bẹ́ẹ̀ èyí tí ó wà lónìí, tí a sì gbá a sínú iná lọ́la: mélòó mélòó ni yóò wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. 29 Kí ẹ má sì ṣe lé ohun tí ẹ ó jẹ, tàbí ohun tí ẹ ó mu, kí ẹ má sì ṣe ṣe àníyàn nínú ọkàn. 30  Nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè ayé ń wá kiri. Baba yín sì mọ̀ pé, ẹ̀yin ń fẹ́ nǹkan wọ̀nyí. 31 Ṣùgbọ́n ẹ máa wá ìjọba Ọlọ́run, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.

    32 “Má bẹ̀rù, agbo kékeré, nítorí dídùn inú Baba yín ni láti fi ìjọba fún yín. 33  Ẹ ta ohun tí ẹ̀yin ní, kí ẹ sì tọrẹ àánú kí ẹ sì pèsè àpò fún ara yín, tí kì í gbó, ìṣúra ní ọ̀run tí kì í tán, ní ibi tí olè kò lè súnmọ́, àti ibi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́. 34 Nítorí ní ibi tí ìṣúra yín gbé wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín yóò gbé wà pẹ̀lú.

  13. 5  Kí ọkàn yín má ṣe fà sí ìfẹ́ owó, ki ohun tí ẹ ní tó yin; nítorí òun tìkára rẹ̀ ti wí pé,

    “Èmi kò jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀,

    bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”

    6  Nítorí náà ni àwa ṣe ń fi ìgboyà wí pé,

    “Olúwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, èmi kì yóò bẹ̀rù;

    kín ni ènìyàn lè ṣe sí mi?”

  14. 1 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìí,

    ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu,

    ẹni tí ó mọ ọ́, ìwọ Israẹli:

    “Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;

    Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe.

    2 Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,

    Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ;

    àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá

    wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.

    Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,

    kò ní jó ọ;

    ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.

    3 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,

    Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ;

    Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ,

    Kuṣi àti Seba dípò rẹ.

    4 Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi,

    àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ,

    Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ,

    àti ènìyàn dípò ẹ̀mí rẹ.

    5 Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;

    Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà-oòrùn wá

    èmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀-oòrùn.

  15. Ti Dafidi.

    1 Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi;

    ta ni èmi yóò bẹ̀rù?

    Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi,

    ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?

    2 Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi

    láti jẹ ẹran-ara mi,

    àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi,

    wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.

    3 Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,

    ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;

    bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,

    nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.

  16. 17 Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́,

    èmi fẹ́rẹ̀ máa gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́.

    18 Nígbà tí mo sọ pé, “Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀”,

    Olúwa, ìfẹ́ rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn.

    19 Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi,

    ìtùnú rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.

    20 Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú rẹ

    ẹni tí ń fi òfin dì mọ́ ìwà ìkà?

  17. 5  Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mose, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.

    6 “Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le, nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn. 7 Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Mose ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ. 8 Má ṣe jẹ́ kí ìwé òfin yìí kúrò ní ẹnu rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí. 9 Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

  18. 22  Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa

    yóò sì mú ọ dúró;

    òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.

    23 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi

    wá sí ihò ìparun;

    àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn,

    kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn.

    Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.

  19. 28 “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ tí a sì di ẹrù wíwúwo lé lórí, èmi yóò sì fún yín ní ìsinmi. 29 Ẹ gbé àjàgà mi wọ̀. Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi nítorí onínútútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmi, ẹ̀yin yóò sì ri ìsinmi fún ọkàn yín. 30 Nítorí àjàgà mi rọrùn ẹrù mi sì fúyẹ́.”

  20. 5 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ

    má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ.

    6 Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ

    òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ.

    7  Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ

    bẹ̀rù Olúwa kí o sì kórìíra ibi.

    8 Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹ

    àti okun fún àwọn egungun rẹ.

  21. 35 Ta ni yóò ha yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ìpọ́njú ni, tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ìyàn, tàbí ìhòhò, tàbí ewu tàbí idà? 36  Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

    “Nítorí rẹ̀ ni a ṣe ń pa wá kú ní gbogbo ọjọ́;

    À ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.”

    37  Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwa ju ẹni tí ó ṣẹ́gun lọ nípasẹ̀ Kristi ẹni tí ó fẹ́ wa. 38 Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kì í ṣe ikú tàbí ìyè, kì í ṣe àwọn angẹli tàbí ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe ohun ìgbà ìsinsin yìí tàbí ohun tí ó ń bọ̀, tàbí àwọn agbára, 39 tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun nínú ìṣẹ̀dá ni yóò le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ń bẹ nínú Kristi Jesu, Olúwa wa.

  22. 25 Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò

    ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.

  23. Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. Orin.

    1 Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa

    ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.

    2 Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,

    tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.

    3 Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì

    tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela.

  24. 12 Nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo,

    etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ wọn,

    ṣùgbọ́n ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú.”

    13 Tá nì yóò sì ṣe yín ní ibi, bí ẹ̀yin bá jẹ́ onítara sí ohun rere? 14  Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, a ti bùkún yín. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù ìhàlẹ̀ wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú.” 15 Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kristi bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń béèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù. 16 Kí ẹ máa ni ẹ̀rí ọkàn rere bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kristi. 17 Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣíṣe búburú lọ.

  25. 26 “Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí kò sí ohun tó ń bọ̀ tí kò ní í fi ara hàn, tàbí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ tí a kò ní mọ̀ ni gbangba. 27 Ohun tí mo bá wí fún yín ní òkùnkùn, òun ni kí ẹ sọ ní ìmọ́lẹ̀. Èyí tí mo sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sì etí yín ni kí ẹ kéde rẹ́ lórí òrùlé. 28 Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó le pa ara nìkan; ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ẹ̀mí. Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí ó le pa ẹ̀mí àti ara run ní ọ̀run àpáàdì. 29 Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan? Síbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lu ilẹ̀ lẹ́yìn Baba yin. 30 Àti pé gbogbo irun orí yín ni a ti kà pé. 31 Nítorí náà, ẹ má ṣe fòyà; ẹ̀yin ní iye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.

  26. Ti Dafidi.

    1 Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú,

    kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;

    2 nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko,

    wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù.

    3 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì máa ṣe rere;

    torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.

    4 Ṣe inú dídùn sí Olúwa;

    òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.

    5 Fi ọ̀nà rẹ lé Olúwa lọ́wọ́;

    gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é.

    6 Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,

    àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.

    7 Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa,

    kí o sì fi sùúrù dúró dè é;

    má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn,

    nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.

    8 Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀,

    má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú.

    9 Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò,

    ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwa àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà.

  27. 3  Fún ọwọ́ àìlera lókun,

    mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun.

    4 Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé,

    “Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù;

    Ọlọ́run yín yóò wá,

    òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san;

    pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́

    òun yóò wá láti gbà yín là.”

  28. 5 Nínú ìrora mi, mo sọkún sí Olúwa,

    ó sì dá mi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀.

    6 Olúwa ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù.

    Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?

    7 Olúwa ń bẹ fún mi; òun ni olùrànlọ́wọ́ mi.

    Nítorí náà ni èmi ó ṣe rí ìṣẹ́gun mi lórí àwọn tí ó kórìíra mi.

    8 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa

    ju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ.

  29. 11 Nítorí mo mọ èrò tí mo rò sí yín,” ni Olúwa wí, “àní èrò àlàáfíà, kì í sì ṣe fún ibi, èrò láti fún un yín ní ìgbà ìkẹyìn àti ìrètí ọjọ́ iwájú. 12 Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò ké pè mí, tí ẹ̀yin yóò sì gbàdúrà sí mi, tí èmi yóò sì gbọ́ àdúrà yín. 13 Ẹ̀yin yóò wá mi, bí ẹ̀yin bá sì fi gbogbo ọkàn yín wá mi: ẹ̀yin yóò rí mi ni Olúwa Ọlọ́run wí. 14 Èmi yóò di rí rí fún yín ni Olúwa wí, Èmi yóò sì mú yín padà kúrò ní ìgbèkùn. Èmi yóò ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè àti ibi gbogbo tí Èmi ti lé yín jáde, ni Olúwa wí. Èmi yóò sì kó yín padà sí ibi tí mo ti mú kí a kó yín ní ìgbèkùn lọ.”

  30. 1 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú, ẹ gba Ọlọ́run gbọ́, kí ẹ sì gbà mí gbọ́ pẹ̀lú. 2  Nínú ilé Baba mi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibùgbé ni ó wà, ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ìbá tí sọ fún yín. Èmi ń lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún yín. 3 Bí mo bá sì lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún un yín, èmi ó tún padà wá, èmi ó sì mú yín lọ sọ́dọ̀ èmi tìkára mi; pé níbi tí èmi gbé wà, kí ẹ̀yin lè wà níbẹ̀ pẹ̀lú. 4 Ẹ̀yin mọ ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ sì mọ ọ̀nà náà.”

  31. 6  Jẹ́ alágbára kí o sì ní ìgboyà. Má ṣe bẹ̀rù tàbí jáyà nítorí i wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń lọ pẹ̀lú rẹ, Òun kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”

  32. 5 Báyìí ni Olúwa wí:

    “Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn,

    tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara,

    àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ Olúwa.

    6 Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá,

    kò ní rí ìre, nígbà tí ó bá dé,

    yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ aginjù,

    ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé.

    7  “Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin

    náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fi

    Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.

    8 Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò

    tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò

    kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru,

    gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù

    kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá

    bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”

  33. 11 Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní: nítorí pé ni ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀. 12 Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní. 13  Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi.

  34. 23  Nígbà náà ni ó bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé e. 24 Ní àìròtẹ́lẹ̀, ìjì líle dìde lórí Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí rírú omi fi bò ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n Jesu ń sùn. 25 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn jí i, wọ́n wí pe, “Olúwa, gbà wá! Àwa yóò rì!”

    26  Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bẹ̀rù?” Nígbà náà ní ó dìde dúró, ó sì bá ìjì àti rírú Òkun náà wí, gbogbo rẹ̀ sì parọ́rọ́.

    27 Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni èyí? Kódà ìjì líle àti rírú omi Òkun gbọ́ tirẹ̀?”

  35. 14  Nítorí pé, iye àwọn tí Ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí ni ọmọ Ọlọ́run. 15  Nítorí ẹ̀yin kò tún gba ẹ̀mí ẹrú láti máa bẹ̀rù mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, nípa èyí tí àwa fi ń ké pé “Ábbà, Baba.” 16  Nítorí Ẹ̀mí mímọ́ ń sọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ọkàn wa, ó sì ń sọ fún wa pé, nítòótọ́, àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. 17  Níwọ́n ìgbà tí a jẹ́ ọmọ rẹ̀, ǹjẹ́ ajogún ni àwa, ajogún Ọlọ́run, àti àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, bí ó bá ṣe àwa jìyà, kí a sì le ṣe wá lógo pẹ̀lú rẹ̀.

    18  Síbẹ̀síbẹ̀, ìyà tí a ń jẹ nísinsin yìí kò jámọ́ nǹkan nígbà tí a bá fiwé ògo tí yóò fún wa ní ìkẹyìn. 19  Nítorí ẹ̀dá ń dúró ní ìfojúsọ́nà de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run.

  36. 4 “Èmi sì wí fún yín ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó ń pa ara ènìyàn kú, lẹ́yìn èyí, wọn kò sì ní èyí tí wọ́n lè ṣe mọ́. 5  Ṣùgbọ́n èmi ó sì sọ ẹni tí ẹ̀yin ó bẹ̀rù fún yín: Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lágbára lẹ́yìn tí ó bá pànìyàn tan, láti wọ́ ni lọ sí ọ̀run àpáàdì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín òun ni kí ẹ bẹ̀rù. 6 Ológoṣẹ́ márùn-ún sá à ni a ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì? A kò sì gbàgbé ọ̀kan nínú wọn níwájú Ọlọ́run? 7  Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín ni a kà pé ṣánṣán. Nítorí náà kí ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ̀yin ní iye lórí ju ológoṣẹ́ púpọ̀ lọ.

    8 “Mo sì wí fún yín pẹ̀lú, Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú àwọn ènìyàn. Ọmọ Ènìyàn yóò sì jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run. 9  Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mi níwájú ènìyàn, a ó sẹ́ ẹ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run.

  37. 7 Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú:

    ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.

    8 Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á,

    títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.

  38. 18 Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n ṣìgàṣìgà fún ìbẹ̀rù. 19 Wọ́n wí fún Mose pé, “Ìwọ fúnra rẹ̀ máa bá wa sọ̀rọ̀, àwa yóò sì gbọ́. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kí ó bá wa sọ̀rọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò kú.”

    20 Mose sì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run wá láti dán an yín wò, kí ẹ̀rù Ọlọ́run kí ó lè máa wà ní ara yín, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣẹ̀.”

  39. 10 Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.

    A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè,

    a ó gbé mi ga ní ayé.

    11 Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa;

    Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.

  40. Orin fún ìgòkè.

    1 Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—

    níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá?

    2 Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wá,

    ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

  41. 30 Àní, ó ń rẹ̀ wọ́n àwọn ọ̀dọ́, wọ́n ń rẹ̀wẹ̀sì,

    àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì ń kọsẹ̀ wọ́n ṣubú;

    31 ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa

    yóò sọ agbára wọn di ọ̀tun.

    Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì;

    wọn yóò sáré àárẹ̀ kò ní mú wọn,

    wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn.

  42. 22 Ẹni tí ó si gba irúgbìn tí ó bọ́ sí àárín ẹ̀gún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n àwọn àníyàn ayé yìí, ìtànjẹ, ọrọ̀ sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ọ̀rọ̀ náà kò so èso nínú rẹ̀.

  43. 7 Nígbà náà ni Mose pe Joṣua ó sì wí fún un níwájú gbogbo Israẹli pé, “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí o ní láti lọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fún wọn, kí o sì pín ilẹ̀ náà láàrín wọn bí ogún wọn. 8 Olúwa fúnra rẹ̀ ń lọ níwájú rẹ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ; kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù má sì ṣe fòyà.”

  44. 1 Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo

    ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.

    2 Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé,

    “Òun ni ààbò àti odi mi,

    Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.

    3 Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú

    ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ

    àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú.

    4 Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí,

    àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò;

    òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.

    5 Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru,

    tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán,

    6 tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn,

    tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan.

  45. 16  Ǹjẹ́ kí Olúwa àlàáfíà, fúnra rẹ̀ máa fún yín ní àlàáfíà nígbà gbogbo. Kí Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín.

  46. 13  Bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ, Òun nìkan ni kí o sì máa sìn, búra ní orúkọ rẹ̀ nìkan. 14 Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run àwọn tí ó yí i yín ká; 15 torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrín yín, Ọlọ́run owú ni, ìbínú rẹ̀ yóò sì run yín kúrò ní ilẹ̀ náà.

  47. 39 Ó dìde, ó bá ìjì líle náà wí, ó sì wí fún òkun pé, “Dákẹ́! Jẹ́ẹ́!” Ìjì náà sì dá, ìparọ́rọ́ ńlá sì wà.

    40 Lẹ́yìn náà, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣojo bẹ́ẹ̀? Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ì ní ìgbàgbọ́ síbẹ̀síbẹ̀?”

    41 Ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni èyí, tí ìjì àti Òkun ń gbọ́ tirẹ̀!”

  48. 32  Kíyèsi i, wákàtí ń bọ̀, àní ó dé tan nísinsin yìí, tí a ó fọ́n yín ká kiri, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀; ẹ ó sì fi èmi nìkan sílẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò sì ṣe èmi nìkan, nítorí tí Baba ń bẹ pẹ̀lú mi.

    33 “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àlàáfíà nínú mi. Nínú ayé, ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú; ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”

  49. 17  Nígbà tí mo rí i, mo wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó ń wí fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn. 18 Èmi ni ẹni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì ti kú; sì kíyèsi i, èmi sì ń bẹ láààyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò òkú lọ́wọ́.

  50. 40 Ṣùgbọ́n Marta ń ṣe ìyọnu ohun púpọ̀, ó sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Olúwa, ìwọ kò sì bìkítà sí ti arábìnrin mi pé ó fi mí sílẹ̀ láti máa nìkan ṣe ìránṣẹ́? Wí fún un kí ó ràn mí lọ́wọ́.”

    41  Ṣùgbọ́n Olúwa sì dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Marta, Marta, ìwọ ń ṣe àníyàn àti làálàá nítorí ohun púpọ̀. 42 Ṣùgbọ́n ohun kan ni a kò lè ṣe aláìní, Maria sì ti yan ipa rere náà tí a kò lè gbà lọ́wọ́ rẹ̀.”

  51. 32  Nínú gbogbo nǹkan tí ẹ bá ń ṣe ni mo tí fẹ́ kí ẹ sọ ara yín di òmìnira lọ́wọ́ àníyàn. Ọkùnrin tí kò ní ìyàwó le lo àkókò rẹ̀ láti fi ṣiṣẹ́ fún Olúwa, yóò sì má ronú bí ó ti ṣe le tẹ́ Olúwa lọ́rùn. 33 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó bá tí ṣe ìgbéyàwó kò le ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó ní láti ronú àwọn nǹkan rẹ̀ nínú ayé yìí àti bí ó ti ṣe le tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn, 34 dájúdájú, ìfẹ́ rẹ̀ pín sí ọ̀nà méjì. Bákan náà ló rí fún obìnrin tí a gbé ní ìyàwó àti wúńdíá. Obìnrin tí kò bá tí ì délé ọkọ a máa tọ́jú ohun tí ṣe ti Olúwa, kí òun lè jẹ́ mímọ́ ní ara àti ní ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin tí a bá ti gbé níyàwó, a máa ṣe ìtọ́jú ohun tí ṣe ti ayé, bí yóò ti ṣe le tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn.

  52. 12 Àwọn wo ni ó bẹ̀rù Olúwa?

    Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.

    13 Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà,

    àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.

    14 Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀;

    ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.

  53. 10 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:

    òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,

    ìyìn rẹ̀ dúró láé.

  54. 26 Nínú ìbẹ̀rù Olúwa ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára,

    yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.

    27 Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ orísun ìyè,

    tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.

  55. 15 Olúwa ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nì kúrò,

    ó sì ti ti àwọn ọ̀tá rẹ padà sẹ́yìn.

    Olúwa, ọba Israẹli wà pẹ̀lú rẹ;

    ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́.

    16 Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jerusalẹmu pé,

    “Má ṣe bẹ̀rù Sioni;

    má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀.

    17 Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ,

    Ó ní agbára láti gbà ọ là.

    Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀;

    Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀,

    Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”

  56. 36 Ṣùgbọ́n bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jairu pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbàgbọ́ nìkan.”

  57. 48  Ó rí i wí pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà nínú wàhálà púpọ̀ ní wíwa ọkọ̀ náà nítorí ti ìjì líle ṣe ọwọ́ òdì sí wọn, nígbà tí ó sì dì ìwọ̀n ìṣọ́ kẹrin òru, ó tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi Òkun, òun sì fẹ́ ré wọn kọjá, 49 ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí i tí ó ń rìn, wọ́n rò pé iwin ni. Wọ́n sì kígbe sókè lóhùn rara, 50  nítorí gbogbo wọn ni ó rí i, tí ẹ̀rù sì bà wọ́n.

    Ṣùgbọ́n òun sọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù.” 51 Nígbà náà ni ó gòkè sínú ọkọ̀ pẹ̀lú wọn, ìjì líle náà sì dáwọ́ dúró. Ẹ̀rù sì bà wọ́n rékọjá gidigidi, ẹnu sì yà wọ́n.

  58. 22 Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, Olúwa Ọlọ́run yín tìkára rẹ̀ ni yóò jà fún un yín.”

  59. 1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

    Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,

    tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀.

  60. 10 “Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,

    ìmọ̀ nípa Ẹni Mímọ́ ni òye.

  61. 11 “Nígbà tí wọ́n bá sì mú yin wá sí Sinagọgu, àti síwájú àwọn olórí, àti àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣe ṣàníyàn pé, báwo tàbí ohun kín ni ẹ̀yin yóò fèsì rẹ̀ tàbí kín ni ẹ̀yin ó wí. 12 Nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ yóò kọ́ yín ní wákàtí kan náà ní ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ.”

  62. 22 Kí ni ohun tí ènìyàn rí gbà fún gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú tí ó fi ṣiṣẹ́ lábẹ́ oòrùn? 23 Gbogbo ọjọ́ rẹ, iṣẹ́ rẹ kún fún ìrora, àti ìbànújẹ́, kódà ọkàn rẹ̀ kì í ní ìsinmi ní alẹ́. Asán ni eléyìí pẹ̀lú.

  63. 12 Nítorí náà ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ń gbọ́rọ̀ nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà ti mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n pàápàá nísinsin yìí tí èmi kò sí ni àárín yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì,

  64. 26 Nítorí bí àwa ba mọ̀ ọ́n mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 27  Bí kò ṣe ìrètí ìdájọ́ tí ó ba ni lẹ́rù, àti ti ìbínú ti o múná, tí yóò pa àwọn ọ̀tá run.

  65. 15 Nígbà tí ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run dìde ó sì jáde lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, ogun pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ wọn ti yí ìlú náà ká. “Yé è, olúwa mi! Kí ni kí àwa kí ó ṣe?” ìránṣẹ́ náà béèrè.

    16 “Má ṣe bẹ̀rù,” wòlíì náà dáhùn, “Àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa, wọ́n pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.”

    17 Eliṣa sì gbàdúrà, “Olúwa, la ojú rẹ̀ kí ó ba à lè ríran.” Nígbà náà Olúwa la ojú ìránṣẹ́ náà, ó sì wò, ó sì rí òkè ńlá tí ó kún fún ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ iná gbogbo yí Eliṣa ká.

  66. 26  Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù ba wọn gidigidi, wọ́n rò pé “iwin ni,” wọ́n kígbe tìbẹ̀rù tìbẹ̀rù.

    27 Lójúkan náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù.”

  67. 3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;

    ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.

    4 Olúwa ni mo kígbe sókè sí,

    ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.

    5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;

    mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.

    6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn

    tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.

  68. 13 Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀,

    bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

  69. 13 Nísinsin yìí,

    òpin gbogbo ọ̀rọ̀ tí a gbọ́ ni pé,

    bẹ̀rù Ọlọ́run, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́,

    nítorí èyí ni ojúṣe gbogbo ènìyàn.

    14 Nítorí Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ olúkúlùkù iṣẹ́

    àti ohun ìkọ̀kọ̀,

    kì bá à ṣe rere kì bá à ṣe búburú.

  70. 14  Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ ní ọkàn yín pé ẹ ko ronú ṣáájú, bí ẹ ó ti dáhùn. 15 Nítorí tí èmi ó fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn ọ̀tá yín kì yóò lè sọ̀rọ̀-òdì sí, tí wọn kì yóò sì lè kò lójú.

  71. 19 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní yín, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ògo nínú Kristi Jesu.

  72. 1 Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Abramu wá lójú ìran pé,

    “Abramu má ṣe bẹ̀rù.

    Èmi ni ààbò rẹ,

    Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.”

  73. 12 Nígbà tí Sekariah sì rí i, orí rẹ̀ wú, ẹ̀rù sì bà á. 13  Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sekariah: nítorí tí àdúrà rẹ gbà; Elisabeti aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Johanu.

  74. 28 Pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí tí ó jẹ́ tí òde, ọ̀pọ̀ ni èyí tí ń wọn n dúró tì mí lójoojúmọ́, àní àníyàn fún gbogbo ìjọ.

  75. 10 Ní àkótán, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀. 11 Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè kọ ojú ìjà sí àrékérekè èṣù. 12 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara ní àwa ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àti àwọn ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run. 13 Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè dúró tiiri sí ọjọ́ ibi, nígbà tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ohun gbogbo tan kí ẹ sì dúró.

  76. 11 Ẹ sin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rù

    ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.

  77. 4  Ẹ̀rù ba àwọn olùṣọ́, wọ́n sì wárìrì wọn sì dàbí òkú.

  78. 23 Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá;

    nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láìsí ewu.

  79. 57 O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́,

    o sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù.”

    58 Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò,

    o ra ẹ̀mí mi padà.

  80. 20 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ro èrò yìí tán, angẹli Olúwa yọ sí i ní ojú àlá, ó wí pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má fòyà láti fi Maria ṣe aya rẹ, nítorí oyún tí ó wà nínú rẹ̀ láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni.

  81. 5 Àwọn erékùṣù ti rí i wọ́n bẹ̀rù;

    ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé wárìrì.

    Wọ́n súnmọ́ tòsí wọ́n sì wá síwájú;

  82. 25 “Àmì yóò sì wà ní oorun, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀; àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpayà híhó Òkun àti ìgbì omi. 26 Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì. 27  Nígbà náà ni wọn ó sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. 28  Ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè; nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀.”