23 Bible Verses About Summer

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Summer
  1. 22 “Níwọ́n ìgbà tí ayé bá sì wà,

    ìgbà ọ̀gbìn àti ìgbà ìkórè

    ìgbà òtútù àti ìgbà ooru,

    ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òjò,

    ìgbà ọ̀sán àti ìgbà òru,

    yóò wà títí láé.”

  2. 5 Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ,

    ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.

  3. 12 Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́;

    Ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé.

    13 Ìwọ ni ó la òkun sílẹ̀ nípa agbára rẹ;

    ìwọ fọ́ orí ẹ̀mí búburú nínú omi.

    14 Ìwọ fọ́ orí Lefitani túútúú, o sì fi ṣe oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá tí ń gbé inú ijù

    tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú;

    ìwọ fi ìdí oòrùn àti òṣùpá lélẹ̀.

    15 Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi;

    Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ.

    16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;

    ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá.

    17 Ìwọ pààlà etí ayé;

    Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.

  4. 6 Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ;

    kíyèsi ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n!

    7 Kò ní olùdarí,

    kò sí alábojútó tàbí ọba,

    8 síbẹ̀, a kó ìpèsè rẹ̀ jọ ní àsìkò òjò

    yóò sì kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní àsìkò ìkórè.

  5. 32 “Nísinsin yìí, ẹ kọ́ òwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ti ń yọ tuntun tí ó bá sì ń ru ewé, ẹ̀yin mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí. 33 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí i tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìpadàbọ̀ mi dé tán lẹ́yìn ìlẹ̀kùn.

  6. 18 Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mi,

    rẹ̀wẹ̀sì nínú mi.

    19 Fetí sí ẹkún àwọn ènìyàn mi

    láti ilẹ̀ jíjìnnà wá:

    “Olúwa kò ha sí ní Sioni bí?

    Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?”

    “Èéṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn,

    pẹ̀lú àwọn òrìṣà àjèjì tí wọn kò níláárí?”

    20 “Ìkórè ti rékọjá,

    ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti parí,

    síbẹ̀ a kò gbà wá là.”

    21 Níwọ́n ìgbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run, èmi náà run pẹ̀lú,

    èmi ṣọ̀fọ̀, ìrora sì mú mi káká.

    22 Kò ha sí ìkunra ní Gileadi bí?

    Kò ha sí àwọn oníṣègùn níbẹ̀?

    Kí ló ha dé tí kò fi sí ìwòsàn

    fún ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi?

  7. 25 Àwọn èèrà jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá,

    síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò.

  8. 29  Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ẹ kíyèsi igi ọ̀pọ̀tọ́, àti sí gbogbo igi. 30 Nígbà tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin rí i, ẹ sì mọ̀ fúnra ara yín pé, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kù fẹ́ẹ́rẹ́. 31 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, nígbà tí ẹ̀yin bá rí nǹkan wọ̀nyí tí o ṣẹ, kí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.

  9. 1 Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè fihàn mi: agbọ̀n èso pípọ́n. 2 Ó béèrè pé, “Amosi kí ni ìwọ rí.”

    Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso pípọ́n.”

    Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Àsìkò náà pọ́n tó fún àwọn ènìyàn mi Israẹli; Èmi kì yóò dá wọn sí mọ́.”

    3 Olúwa Olódùmarè wí pé, “Ní ọjọ́ náà, àwọn orin tẹmpili yóò yí padà sí ohùn réré ẹkún. Ọ̀pọ̀, àní ọ̀pọ̀ ara òkú ni yóò wà ni ibi gbogbo! Àní ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́!”

    4 Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ń tẹ aláìní lórí ba,

    tí ẹ sì ń sọ tálákà di ilẹ̀.

    5 Tí ẹ ń wí pé,

    “Nígbà wo ni oṣù tuntun yóò parí

    kí àwa bá à lè ta ọkà

    kí ọjọ́ ìsinmi kí ó lè dópin

    kí àwa bá à le ta jéró?”

    Kí a sì dín ìwọ̀n wa kù

    kí a gbéraga lórí iye tí a ó tà á

    kí a sì fi òsùwọ̀n èké yàn wọ́n jẹ,

    6 kí àwa lè fi fàdákà ra àwọn tálákà,

    kí a sì fi bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì ra aláìní,

    kí a sì ta jéró tí a kó mọ́ ilẹ̀.

  10. 1 Ègbé ni fún mi!

    Nítorí èmi sì dàbí ẹni tí ń kó èso ẹ̀ẹ̀rùn jọ,

    ìpèsè ọgbà àjàrà;

    kò sì ṣí odidi àjàrà kankan láti jẹ,

    kò sì ṣí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ nítorí tí ebi ń pa mí.

  11. 1 Bí òjò-dídì tàbí òjò ní ìgbà ìkórè

    ọlá kò yẹ aláìgbọ́n ènìyàn.

  12. 15 Èmi yóò wó ilé òtútù

    lulẹ̀ pẹ̀lú ilé ooru;

    ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbé

    a ó sì pa ilé ńlá náà run,”

    ni Olúwa wí.

  13. 28 “Nísinsin yìí, ẹ kọ́ òwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́, nígbà tí ẹ̀ka rẹ bá ń yọ tuntun, tí ó bá sì ń rú ewé, èyí fihàn pé àkókò ẹ̀rùn ti dé. 29 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ ba ri àwọn ohun wọ̀nyí ti n ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ó súnmọ́ etílé tán, bi ìgbà tí ó wà lẹ́yìn ìlẹ̀kùn.

  14. 35 Nígbà náà ni irin, amọ̀, idẹ, fàdákà àti wúrà fọ́ sí wẹ́wẹ́ lẹ́sẹ̀kan náà, ó sì dàbí ìyàngbò tí a fẹ́ kúrò lórí ọkà ní àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn. Afẹ́fẹ́ gbé gbogbo rẹ̀ lọ láìṣẹ́ku ọ̀kan mọ́, òkúta tí ó fọ́ ère náà sì di òkè ńlá, ó sì gba gbogbo ayé.

  15. 4 Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀,

    tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú,

    yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkórè

    bí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ rẹ̀,

    òun a sì mì ín.

  16. 8 Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò

    tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò

    kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru,

    gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù

    kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá

    bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”

  17. 6 A ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ẹyẹ òkè ńlá

    àti fún àwọn ẹranko búburú;

    àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣe oúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùn

    àti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò.

  18. 14 “Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá,

    kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódùmarè sílẹ̀?

    15 Àwọn ará mi dàbí odò tí kò ṣe gbẹ́kẹ̀lé

    bí ìṣàn omi odò, wọ́n sàn kọjá lọ.

    16 Tí ó dúdú nítorí omi dídì,

    àti níbi tí yìnyín dídì gbé di yíyọ́.

    17 Nígbàkígbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ sàn lọ,

    nígbà tí oòrùn bá mú, wọn a sì gbẹ kúrò ni ipò wọn.

  19. 4 Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru

    ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára;

    agbára mi gbẹ tán

    gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.

  20. 4 Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:

    “Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́, èmi yóò sì máa wo òréré

    láti ibùgbé e mi wá,

    gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànṣán oòrùn,

    gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárín gbùngbùn ìkórè.”

  21. 17 Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà.

  22. 10 Èmi fúnra mi yóò dúró ní Mispa láti ṣojú yín níwájú Babeli tí wọ́n tọ̀ wá wá. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni yóò máa kórè ọtí wáìnì, èso igi àti òróró; kí ẹ sì kó wọn sí inú àpò àpamọ́wọ́ yín; kí ẹ̀yin sì máa gbé ní ìlú tí ẹ ti gbà.”

    11 Nígbà tí gbogbo àwọn Juda ní Moabu, Ammoni, Edomu àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ pé ọba Babeli ti fi ohun tókù sílẹ̀ ní Juda, àti pé ó ti yan Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu ọmọkùnrin Ṣafani gẹ́gẹ́ bí gómìnà lórí wọn. 12 Gbogbo wọn padà wá sí ilẹ̀ Juda sọ́dọ̀ Gedaliah ní Mispa láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí a ti lé wọn sí. Wọ́n sì kórè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọtí wáìnì àti èso igi.

  23. 8 Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, omi ìyè yóò tí Jerusalẹmu sàn lọ; ìdajì wọn síhà Òkun ìlà-oòrùn, àti ìdajì wọn síhà okùn ẹ̀yìn: nígbà ẹ̀rùn àti nígbà òtútù ni yóò rí bẹ́ẹ̀.