54 Bible Verses About Waiting on the Lord

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Waiting on the Lord
  1. 2 Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ;

    má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí

    má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.

    3 Ẹni tí ó dúró tì ọ́

    ojú kì yóò tì í,

    àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí

    ni kí ojú kí ó tì.

    4 Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, Olúwa,

    kọ mi ní ipa tìrẹ;

    5 ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi,

    nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi;

    ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.

    6 Rántí, Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀ ńlá,

    torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́.

    7 Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi

    tàbí ìrékọjá mi;

    gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ rẹ̀ rántí mi

    nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! Olúwa.

    8 Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní Olúwa:

    nítorí náà, ó kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ̀nà náà.

    9 Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára,

    ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀.

  2. Ti Dafidi.

    1 Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú,

    kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;

    2 nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko,

    wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù.

    3 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì máa ṣe rere;

    torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.

    4 Ṣe inú dídùn sí Olúwa;

    òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.

    5 Fi ọ̀nà rẹ lé Olúwa lọ́wọ́;

    gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é.

    6 Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,

    àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.

    7 Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa,

    kí o sì fi sùúrù dúró dè é;

    má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn,

    nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.

    8 Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀,

    má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú.

    9 Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò,

    ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwa àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà.

    10 Síbẹ̀ nígbà díẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ̀;

    nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀.

    11 Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà,

    wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.

  3. 27 Èéṣe tí o fi sọ, ìwọ Jakọbu?

    Àti tí o ṣàròyé, ìwọ Israẹli,

    “Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú Olúwa;

    ìṣe mi ni a kò kọbi ara sí láti ọwọ́ Ọlọ́run mi”?

    28 Ìwọ kò tí ì mọ̀?

    Ìwọ kò tí ì gbọ́?

    Olúwa òun ni Ọlọ́run ayérayé,

    Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé.

    Agara kì yóò da bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣàárẹ̀,

    àti òye rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdínwọ̀n rẹ̀.

    29 Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀

    ó sì fi kún agbára àwọn tí agara dá.

    30 Àní, ó ń rẹ̀ wọ́n àwọn ọ̀dọ́, wọ́n ń rẹ̀wẹ̀sì,

    àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì ń kọsẹ̀ wọ́n ṣubú;

    31 ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa

    yóò sọ agbára wọn di ọ̀tun.

    Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì;

    wọn yóò sáré àárẹ̀ kò ní mú wọn,

    wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn.

  4. 11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,

    kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́jú

    nítorí àwọn ọ̀tá mi.

    12 Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́,

    nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,

    wọ́n sì mí ìmí ìkà.

    13 Èmi ní ìgbàgbọ́ pé,

    èmi yóò rí ìre Olúwa

    ní ilẹ̀ alààyè.

    14 Dúró de Olúwa;

    kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le

    àní dúró de Olúwa.

  5. 21 Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn

    àti nítorí náà ní mo nírètí.

    22 Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé,

    nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.

    23 Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀;

    títóbi ni òdodo rẹ̀.

    24 Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa;

    nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.

    25 Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀,

    sí àwọn tí ó ń wá a.

    26 Ó dára kí a ní sùúrù

    fún ìgbàlà Olúwa.

  6. 5 Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,

    àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí.

    6 Ọkàn mi dúró de Olúwa,

    ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,

    àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.

    7 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:

    nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,

    àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.

    8 Òun ó sì dá Israẹli ní ìdè

    kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.

  7. 18  Síbẹ̀síbẹ̀, ìyà tí a ń jẹ nísinsin yìí kò jámọ́ nǹkan nígbà tí a bá fiwé ògo tí yóò fún wa ní ìkẹyìn. 19  Nítorí ẹ̀dá ń dúró ní ìfojúsọ́nà de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run. 20  Nítorí a tẹrí ẹ̀dá ba fún asán, kì í ṣe bí òun ti fẹ́, ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ẹni tí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní ìrètí. 21  Nítorí a ó sọ ẹ̀dá tìkára rẹ̀ di òmìnira kúrò nínú ẹrú ìdíbàjẹ́, sí òmìnira ògo àwọn ọmọ Ọlọ́run.

    22  Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ẹ̀dá ni ó jùmọ̀ ń kérora tí ó sì ń rọbí pọ̀ títí di ìsinsin yìí. 23  Kì í ṣe àwọn nìkan, ṣùgbọ́n àwa tìkára wa pẹ̀lú, a ni àkóso ẹ̀mí, àní àwa tìkára wa ń kérora nínú ara wa, àwa ń dúró de ìsọdọmọ àní ìdáǹdè ara wa. 24  Nítorí nípa ìrètí ni a fi gbà wá là, ṣùgbọ́n ìrètí tí a bá rí kì í ṣe ìrètí nítorí ta ni ń retí ohun tí ó bá rí? 25 Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń retí èyí tí àwa kò rí, ǹjẹ́ àwa ń fi sùúrù dúró dè é.

  8. 5 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi.

    Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.

    6 Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi;

    Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò.

    7 Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run;

    Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.

    8 Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn;

    tú ọkàn rẹ jáde sí i,

    nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.

  9. 7 Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi ní ìwòye ní ìrètí sí Olúwa,

    èmi dúró de Ọlọ́run olùgbàlà mi;

    Ọlọ́run mi yóò sì tẹ́tí sí mi.

  10. 17  Èmi yóò dúró de Olúwa,

    ẹni tí ó ń fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún ilé Jakọbu.

    Mo fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sínú rẹ.

  11. Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

    1 Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa;

    ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.

    2 Ó fà mí yọ gòkè

    láti inú ihò ìparun,

    láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀,

    ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta,

    ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà.

    3 Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu,

    àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa.

    Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù,

    wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

    4 Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì

    tí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn

    tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga,

    tàbí àwọn tí ó yapa

    lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.

  12. 6 Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀;

    di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mú

    kí ẹ sì dúró de Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.

  13. 7 Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadà wá Olúwa. Kíyèsi i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò. 8 Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fi ọkàn yín balẹ̀, nítorí ìpadà wá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀. 9 Ẹ má ṣe kùn sí ọmọnìkejì yín, ará, kí a má ba à dá a yín lẹ́bi: kíyèsi i, onídàájọ́ dúró ní ẹnu ìlẹ̀kùn.

    10 Ará mi, ẹ fi àwọn wòlíì tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa ṣe àpẹẹrẹ ìyà jíjẹ, àti sùúrù. 11  Sá à wò ó, àwa a máa ka àwọn tí ó fi ara dà ìyà sí ẹni ìbùkún. Ẹ̀yin ti gbọ́ ti sùúrù Jobu, ẹ̀yin sì rí ìgbẹ̀yìn tí Olúwa ṣe; pé Olúwa kún fún ìyọ́nú, ó sì ní àánú.

  14. 18 Síbẹ̀síbẹ̀ Olúwa sì fẹ́ síjú àánú wò ọ́;

    ó dìde láti ṣàánú fún ọ.

    Nítorí Olúwa jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́.

    Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é!

  15. 18 “Mo ń dúró de ìtúsílẹ̀ rẹ, Olúwa.

  16. 9 Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn-ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ, ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí tí wọ́n dìímú, 10  Wọ́n kígbe ní ohùn rara, wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa Olódùmarè, ẹni mímọ́ àti olóòtítọ́ ìwọ kì yóò ṣe ìdájọ́ kí o sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa mọ́ lára àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé?” 11 A sì fi aṣọ funfun fún gbogbo wọn; a sì wí fún wọn pé, kí wọn kí ó sinmi fún ìgbà díẹ̀ ná, títí iye àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti arákùnrin wọn tí a o pa bí wọn, yóò fi dé.

  17. 20 Ọkàn wa dúró de Olúwa;

    òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti asà wa.

    21 Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀,

    nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́.

    22 Kí àánú rẹ, Olúwa, kí ó wà lára wa,

    àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú rẹ.

  18. 7 “Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí,

    Olúwa,

    kín ni mo ń dúró dè?

    Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ.

    8 Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.

    Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn

    àwọn ènìyàn búburú.

  19. 6 Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù

    wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé,

    7 “Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀,

    bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé,

    ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”

    8 Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifi

    tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;

    èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà

    láé àti láéláé.

    9 Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe;

    èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ,

    nítorí orúkọ rẹ dára.

    Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.

  20. Orin fún ìgòkè.

    1 Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí,

    ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run.

    2 Kíyèsi, bí ojú àwọn

    ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn,

    àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀

    bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa,

    títí yóò fi ṣàánú fún wa.

  21. 14 Olúwa mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú ró

    ó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde.

    15 Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́,

    ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ.

    16 Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ

    ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.

  22. 35 “Ẹ di àmùrè yín, kí fìtílà yín sì máa jó. 36 Kí ẹ̀yin tìkára yín dàbí ẹni tí ń retí olúwa wọn, nígbà tí òun ó padà ti ibi ìgbéyàwó dé, pé nígbà tí ó bá dé, tí ó sì kànkùn, kí wọn lè ṣí i sílẹ̀ fún un lọ́gán. 37  Ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà nígbà tí olúwa náà bá dé tí yóò bá wọn tí wọn ń ṣọ́nà; lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò di ara rẹ̀ ní àmùrè yóò sì mú wọn jókòó láti jẹun, yóò sì jáde wá láti ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. 38 Bí olúwa wọn bá sì dé nígbà ìṣọ́ kejì, tàbí tí ó sì dé nígbà ìṣọ́ kẹta, tí ó sì bá wọn bẹ́ẹ̀, ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà. 39  Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí tí olè yóò wá, òun ìbá máa ṣọ́nà, kì bá tí jẹ́ kí a já wọ inú ilé òun. 40 Nítorí náà, kí ẹ̀yin múra pẹ̀lú, nítorí Ọmọ Ènìyàn ń bọ̀ ní wákàtí tí ẹ̀yin kò nírètí.”

  23. Fún adarí orin. Fun Jedutuni. Saamu Dafidi.

    1 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi;

    ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.

    2 Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi;

    Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.

  24. 22 Má ṣe wí pé, “N ó sẹ̀san àṣìṣe rẹ yìí fún ọ.”

    Dúró de Olúwa yóò sì gbà ọ́ là.

  25. 5 Nítorí nípa Ẹ̀mí àwa ń fi ìgbàgbọ́ dúró de ìrètí òdodo.

  26. 4  Ní àkókò kan bí ó sì ti ń jẹun pẹ̀lú wọn, ó pàṣẹ yìí fún wọn, “Ẹ má ṣe kúrò ní Jerusalẹmu, ṣùgbọ́n ẹ dúró de ìlérí tí Baba mi ṣe ìlérí, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ lẹ́nu mi. 5 Nítorí Johanu fi omi bamitiisi yín, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ díẹ̀ sí i, a o fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.”

  27. 5  Nítorí náà, kí ẹ má ṣe ṣe ìdájọ́ ohunkóhun, kí Olúwa tó padà dé, ẹni tí yóò mú ohunkóhun tí ó fi ara sin wá sí ìmọ́lẹ̀, tí yóò sì fi ìmọ̀ ọkàn ènìyàn hàn, nígbà náà ni olúkúlùkù yóò sì ní ìyìn tirẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

  28. 11 Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tó mú ìgbàlà wà ti fi ara hàn fún gbogbo ènìyàn. 12 Ó ń kọ́ wa láti sẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé, kí a sì máa wà ní àìrékọjá, ní òdodo àti ní ìwà-bí-Ọlọ́run ní ayé ìsinsin yìí, 13 bí a ti ń wọ́nà fún ìrètí tó ní bùkún, èyí ń ní ìfarahàn ògo Ọlọ́run wa tí ó tóbi àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi. 14  Ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa láti rà fún ìràpadà kúrò nínú ìwà búburú gbogbo àti kí ó sì le wẹ̀ àwọn ènìyàn kan mọ́ fún ara rẹ̀ fún ìní ohun tìkára rẹ̀, àwọn tó ń ní ìtara fún iṣẹ́ rere.

  29. 9 Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ;

    nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi,

    10 Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi.

    Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi.

    Yóò sì jẹ́ kí n yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi.

  30. 4  Láti ìgbà àtijọ́ kò sí ẹni tí ó gbọ́ rí

    kò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ,

    kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ,

    tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.

  31. 34 Dúró de Olúwa,

    kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́.

    Yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà;

    nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri.

  32. 7 Ní orí òkè yìí ni yóò pa

    aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn,

    abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,

    8  Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé.

    Olúwa Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù,

    kúrò ní ojú gbogbo wọn,

    Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò

    ní gbogbo ilẹ̀ ayé.

    Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

    9 Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé,

    “Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa;

    àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là.

    Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e,

    ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”

  33. 1  Èmi yóò dúró lórí ibusọ́ mi láti máa wòye,

    èmi yóò sì gbé ara mi ka orí alóre,

    èmi yóò si ṣọ́ láti gbọ́ ohun tí yóò sọ fún mi

    àti èsì ti èmi yóò fún ẹ̀sùn yìí nígbà tó bá ń bá mi wí.

    2 Nígbà náà ni Olúwa dáhùn pé,

    “Kọ ìṣípayá náà sílẹ̀

    kí o sì fi hàn ketekete lórí wàláà

    kí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré.

    3  Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè;

    yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn

    kí yóò sìsọ èké.

    Bí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é;

    nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́.”

  34. 3 Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́;

    ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú,

    nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi.

  35. 21 Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́;

    nítorí pé mo dúró tì ọ́.

  36. 23 Àwọn ọba ni yóò jẹ́ alágbàtọ́ baba fún ọ,

    àwọn ayaba wọn ni yóò sì jẹ́ ìyá-alágbàtọ́.

    Wọn yóò foríbalẹ̀ ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀;

    wọn yóò máa lá erùpẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ.

    Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa;

    gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí nínú mi

    ni a kì yóò jákulẹ̀.”

  37. 27 Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́

    láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀.

    28 Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn,

    wọn yóò kó jọ;

    nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀,

    a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.

  38. 2 Olúwa ṣàánú fún wa

    àwa ń ṣàfẹ́rí i rẹ.

    Máa jẹ́ agbára wa ní òròòwúrọ̀

    ìgbàlà wa ní àsìkò ìpọ́njú.

  39. 5 Òdodo mi ń bọ̀ wá kíkankíkan,

    ìgbàlà mi ń bọ̀ lójú ọ̀nà,

    àti apá mi yóò sì mú ìdájọ́ wá

    sí àwọn orílẹ̀-èdè.

    Àwọn erékùṣù yóò wò mí

    wọn yóò sì dúró ní ìrètí fún apá mi.

  40. 8 Nítorí náà ẹ dúró dè mí,” ni Olúwa wí,

    “títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò fi jẹ́rìí sí yin.

    Nítorí ìpinnu mi ni láti kó orílẹ̀-èdè jọ

    kí èmi kí ó lè kó ilẹ̀ ọba jọ

    àti láti da ìbínú mi jáde sórí wọn,

    àní gbogbo ìbínú gbígbóná mi.

    Nítorí gbogbo ayé

    ni a ó fi iná owú mi jẹ run.

  41. 28 bẹ́ẹ̀ ni Kristi pẹ̀lú lẹ́yìn tí a ti fi rú ẹbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láti ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, yóò farahàn ní ìgbà kejì láìsí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí n wo ọ̀nà rẹ̀ fún ìgbàlà.

  42. 8  Ṣùgbọ́n, olùfẹ́, ẹ má ṣe gbàgbé ohun kan yìí, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa bí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún ni ó rí, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún bí ọjọ́ kan. 9 Olúwa kò fi ìlérí rẹ̀ jáfara, bí àwọn ẹlòmíràn ti ka ìjáfara sí; ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, bí kò ṣe kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.

  43. 3 Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi;

    ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀

    èmi yóò sì dúró ní ìrètí.

  44. 13 Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe

    wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ.

    14 Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́,

    nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò.

    15 Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún

    ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.

  45. 7 Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú,

    ìwọ tó dúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà

    àwọn olódodo ṣe geere.

    8 Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹ

    àwa dúró dè ọ́;

    orúkọ rẹ àti òkìkí rẹ

    àwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́.

    9 Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru;

    ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ.

    Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé

    àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.

  46. 4 òun kì yóò kọsẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sì

    títí tí yóò fi fi ìdájọ́ múlẹ̀ ní ayé.

    Nínú òfin rẹ̀ ni àwọn erékùṣù yóò fi ìrètí wọn sí.”

  47. 20 Nítorí ìlú ìbílẹ̀ wá ń bẹ̀ ní ọ̀run, láti ibi ti àwa pẹ̀lú gbé ń fojúsọ́nà fún Olùgbàlà, Jesu Kristi Olúwa. 21  Ẹni tí yóò sọ ara ìrẹ̀lẹ̀ wa di ọ̀tún kí ó lè bá ara ògo rẹ̀ mu, nípa agbára tí ó mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti tẹ orí ohun gbogbo bá fún ara rẹ̀.

  48. 12 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó dúró, ti ó sì di òpin ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé àrùndínlógójì (1,335) ọjọ́.

  49. 28 Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀.

  50. 12 Ìbùkún ni fún ọkùnrin tí ó fi ọkàn rán ìdánwò; nítorí nígbà tí ó bá yege, yóò gba adé ìyè, tí Olúwa ti ṣèlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ.

  51. 24 Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le

    gbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de Olúwa.

  52. 13 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni

    ìwọ ni èmi ń gbàdúrà mi sí Olúwa,

    ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà

    Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi rẹ,

    dá mi lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà rẹ tí ó dájú.

  53. 10 Báyìí ni Olúwa wí: “Nígbà tí ẹ bá lo àádọ́rin ọdún pé ní Babeli, èmi yóò tọ̀ yín wá láti ṣe àmúṣẹ ìlérí ńlá mi fún un yín, àní láti kó o yín padà sí Jerusalẹmu. 11 Nítorí mo mọ èrò tí mo rò sí yín,” ni Olúwa wí, “àní èrò àlàáfíà, kì í sì ṣe fún ibi, èrò láti fún un yín ní ìgbà ìkẹyìn àti ìrètí ọjọ́ iwájú. 12 Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò ké pè mí, tí ẹ̀yin yóò sì gbàdúrà sí mi, tí èmi yóò sì gbọ́ àdúrà yín. 13 Ẹ̀yin yóò wá mi, bí ẹ̀yin bá sì fi gbogbo ọkàn yín wá mi: ẹ̀yin yóò rí mi ni Olúwa Ọlọ́run wí.

  54. 7 “Béèrè, a ó sì fi fún yín; wá kiri, ẹ̀yin yóò sì rí; kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín. 8 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó béèrè ń rí gbà, ẹni tí ó bá sì wà kiri ń rí, ẹni bá sì kànkùn ni a yóò ṣi sílẹ̀ fún.

    9 “Ta ni ọkùnrin náà tí ń bẹ nínú yín, bí ọmọ rẹ̀ béèrè àkàrà, tí yóò jẹ́ fi òkúta fún un? 10 Tàbí bí ó béèrè ẹja, tí yóò jẹ́ fún un ní ejò? 11 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí í ṣe ènìyàn búburú bá mọ̀ bí a ti í fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòó mélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ohun rere fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?