Search Help

Search the whole Bible in your chosen Translation.

1. Find Verses Using Words

Examples:

Notes:

2. Find Verses Using Advanced Matching

Finds baptism, baptize, baptized, baptizing

Finds love, loved, loving

3. Find a passage

Opens John chapter 3.

Opens John 3, verses 16–17. A book name on its own, such as "John", searches for that word.

Saamu 70

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.

1  Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là,

Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.

2 Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi

kí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú;

kí àwọn tó ń wá ìparun mi

yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.

3 Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè

ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!”

4 Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀

kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ,

kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé,

“Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”

5 Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní;

wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run.

Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi;

Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.

Saamu 70