Search Help

Search the whole Bible in your chosen Translation.

1. Find Verses Using Words

Examples:

Notes:

2. Find Verses Using Advanced Matching

Finds baptism, baptize, baptized, baptizing

Finds love, loved, loving

3. Find a passage

Opens John chapter 3.

Opens John 3, verses 16–17. A book name on its own, such as "John", searches for that word.

Saamu 3

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu.

1 Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí!

Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!

2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé

“Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela.

3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;

ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.

4 Olúwa ni mo kígbe sókè sí,

ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.

5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;

mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.

6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn

tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.

7 Dìde, Olúwa!

Gbà mí, Ọlọ́run mi!

Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n;

kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.

8 Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá.

Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.

Saamu 3