Search Help

Search the whole Bible in your chosen Translation.

1. Find Verses Using Words

Examples:

Notes:

2. Find Verses Using Advanced Matching

Finds baptism, baptize, baptized, baptizing

Finds love, loved, loving

3. Find a passage

Opens John chapter 3.

Opens John 3, verses 16–17. A book name on its own, such as "John", searches for that word.

Saamu 67

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu. Orin.

1 Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa,

kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,

2 kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé,

ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

3 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;

kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!

4 Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀,

nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn,

ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.

5 Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;

kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela.

6 Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run,

Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa.

7 Ọlọ́run yóò bùkún fún wa,

àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.

Saamu 67