Search Help

Search the whole Bible in your chosen Translation.

1. Find Verses Using Words

Examples:

Notes:

2. Find Verses Using Advanced Matching

Finds baptism, baptize, baptized, baptizing

Finds love, loved, loving

3. Find a passage

Opens John chapter 3.

Opens John 3, verses 16–17. A book name on its own, such as "John", searches for that word.

Saamu 20

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

1 Kí Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú;

kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.

2 Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́

kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.

3 Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ

kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. Sela.

4 Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹ

kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ.

5 Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun

àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa.

Kí Olúwa kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ.

6 Nísinsin yìí, èmi mọ̀ wí pé,

Olúwa pa ẹni àmì òróró rẹ̀ mọ́.

Yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá

pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.

7 Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin,

ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa.

8 Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọ́n sì ṣubú,

ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.

9 Olúwa, fi ìṣẹ́gun fún ọba!

Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!

Saamu 20