Search Help

Search the whole Bible in your chosen Translation.

1. Find Verses Using Words

Examples:

Notes:

2. Find Verses Using Advanced Matching

Finds baptism, baptize, baptized, baptizing

Finds love, loved, loving

3. Find a passage

Opens John chapter 3.

Opens John 3, verses 16–17. A book name on its own, such as "John", searches for that word.

Saamu 114

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

1 Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti,

ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè

2 Juda wà ní ibi mímọ́,

Israẹli wà ní ìjọba.

3  Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:

Jordani sì padà sẹ́yìn.

4 Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti

òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn.

5 Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì?

Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?

6 Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò,

àti ẹ̀yin òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn?

7 Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa;

ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu

8 tí ó sọ àpáta di adágún omi,

àti òkúta-ìbọn di orísun omi.

Saamu 114