Search Help

Search the whole Bible in your chosen Translation.

1. Find Verses Using Words

Examples:

Notes:

2. Find Verses Using Advanced Matching

Finds baptism, baptize, baptized, baptizing

Finds love, loved, loving

3. Find a passage

Opens John chapter 3.

Opens John 3, verses 16–17. A book name on its own, such as "John", searches for that word.

Saamu 14

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Fún adarí orin. Ti Dafidi.

1  Aṣiwèrè wí nínú ọkàn rẹ̀ pé,

“Ko sí Ọlọ́run.”

Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú;

kò sí ẹnìkan tí yóò ṣe rere.

2 Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá

lórí àwọn ọmọ ènìyàn

bóyá ó le rí ẹni tí òye yé,

ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.

3 Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́;

kò sì ṣí ẹni tí ó ń ṣe rere,

kò sí ẹnìkan.

4 Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní ìmọ̀?

Àwọn tí ó ń pa ènìyàn mi jẹ bí ẹní jẹun;

wọn kò sì ké pe Olúwa?

5 Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù,

nítorí Ọlọ́run wà ní àwùjọ àwọn olódodo.

6 Ẹ̀yin olùṣe búburú da èrò àwọn tálákà rú,

ṣùgbọ́n Olúwa ni ààbò wọn.

7 Ìgbàlà àwọn Israẹli yóò ti Sioni wá!

Nígbà tí Olúwa bá mú ìkólọ àwọn ènìyàn rẹ̀ padà,

jẹ́ kí Jakọbu kí ó yọ̀, kí inú Israẹli kí ó dùn!

Saamu 14