Search Help

Search the whole Bible in your chosen Translation.

1. Find Verses Using Words

Examples:

Notes:

2. Find Verses Using Advanced Matching

Finds baptism, baptize, baptized, baptizing

Finds love, loved, loving

3. Find a passage

Opens John chapter 3.

Opens John 3, verses 16–17. A book name on its own, such as "John", searches for that word.

Saamu 43

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

1 Dá mi láre, Ọlọ́run mi,

kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn aláìláàánú orílẹ̀-èdè:

yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.

2 Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi.

Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀?

Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́,

nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?

3 Rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ jáde,

jẹ́ kí wọn ó máa dáàbò bò mí;

jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ rẹ,

sí ibi tí ìwọ ń gbé.

4 Nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run,

sí Ọlọ́run ayọ̀ mi àti ìdùnnú mi,

èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú dùùrù,

ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.

5 Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí?

Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi?

Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,

nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun ni

Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

Saamu 43