61 Bible Verses About Feeling Alone

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Bible Verses About Feeling Alone
  1. 5 Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé

    rẹ̀ mímọ́

    6 Ọlọ́run gbé aláìlera

    kalẹ̀ nínú ìdílé,

    ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin,

    ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.

  2. 5  Kí ọkàn yín má ṣe fà sí ìfẹ́ owó, ki ohun tí ẹ ní tó yin; nítorí òun tìkára rẹ̀ ti wí pé,

    “Èmi kò jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀,

    bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”

    6  Nítorí náà ni àwa ṣe ń fi ìgboyà wí pé,

    “Olúwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, èmi kì yóò bẹ̀rù;

    kín ni ènìyàn lè ṣe sí mi?”

  3. 9 Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi,

    má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì;

    ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi,

    Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí,

    háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.

    10 Bí ìyá àti baba bá kọ̀ mí sílẹ̀,

    Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.

  4. 35 Ta ni yóò ha yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ìpọ́njú ni, tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ìyàn, tàbí ìhòhò, tàbí ewu tàbí idà? 36  Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

    “Nítorí rẹ̀ ni a ṣe ń pa wá kú ní gbogbo ọjọ́;

    À ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.”

    37  Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwa ju ẹni tí ó ṣẹ́gun lọ nípasẹ̀ Kristi ẹni tí ó fẹ́ wa. 38 Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kì í ṣe ikú tàbí ìyè, kì í ṣe àwọn angẹli tàbí ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe ohun ìgbà ìsinsin yìí tàbí ohun tí ó ń bọ̀, tàbí àwọn agbára, 39 tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun nínú ìṣẹ̀dá ni yóò le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ń bẹ nínú Kristi Jesu, Olúwa wa.

  5. 18  Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi. 19 Nítorí náà, ẹ lọ, ẹ sọ wọ́n di ọmọ-ẹ̀yìn orílẹ̀-èdè gbogbo, ẹ máa bamitiisi wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti Ẹ̀mí Mímọ́. 20 Ẹ kọ́ wọn láti máa kíyèsi ohun gbogbo èyí tí mo ti pàṣẹ fún yín. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín ní ìgbà gbogbo títí tí ó fi dé òpin ayé.”

  6. 18 Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un.”

  7. 6 Nítorí náà, ẹ rẹ ara yin sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kí òun lè gbe yín ga lákokò. 7  Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e; nítorí tí òun ń ṣe ìtọ́jú yín.

  8. 15 Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa,

    nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.

    16 Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi;

    nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú.

    17 Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi;

    kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi.

    18 Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi,

    kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.

    19 Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi,

    tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.

    20 Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀;

    má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú,

    nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.

    21 Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́;

    nítorí pé mo dúró tì ọ́.

  9. 6  Jẹ́ alágbára kí o sì ní ìgboyà. Má ṣe bẹ̀rù tàbí jáyà nítorí i wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń lọ pẹ̀lú rẹ, Òun kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”

  10. 4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn

    láàrín àfonífojì òjìji ikú,

    èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan,

    nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;

    ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ,

    wọ́n ń tù mí nínú.

    5 Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi

    ní ojú àwọn ọ̀tá à mi.

    Ìwọ ta òróró sí mi ní orí;

    ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.

    6 Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn

    ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,

    èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa

    títí láéláé.

  11. 7 Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn.

    8 Ọkùnrin kan ṣoṣo dá wà;

    kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbí.

    Kò sí òpin nínú làálàá rẹ̀ gbogbo,

    síbẹ̀, ọrọ̀ kò tẹ́ ojú rẹ̀ lọ́rùn.

    Bẹ́ẹ̀ ni kò sì wí pé, “Nítorí ta ni èmí ṣe ń ṣe làálàá,

    àti wí pé, èétiṣe tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?”

    Eléyìí náà asán ni,

    iṣẹ́ òsì!

    9 Ẹni méjì sàn ju ẹnìkan,

    nítorí wọ́n ní èrè rere fún làálàá wọn.

    10 Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀,

    ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fà á sókè,

    ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubú

    tí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn án lọ́wọ́!

    11 Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá sùn pọ̀, wọn yóò móoru.

    Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru?

    12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan,

    àwọn méjì le è gbìjà ara wọn,

    ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn ún yára fà já.

  12. 31 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ wàyí? 32  Kíyèsi i, wákàtí ń bọ̀, àní ó dé tan nísinsin yìí, tí a ó fọ́n yín ká kiri, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀; ẹ ó sì fi èmi nìkan sílẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò sì ṣe èmi nìkan, nítorí tí Baba ń bẹ pẹ̀lú mi.

    33 “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àlàáfíà nínú mi. Nínú ayé, ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú; ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”

  13. 7 Eléyìí sì máa ń ṣẹlẹ̀ ní ọdọọdún. Nígbàkígbà tí Hana bá gòkè lọ sí ilé Olúwa, orogún rẹ̀ a máa fín níràn títí tí yóò fi máa sọkún tí kò sì ní lè jẹun.

  14. 10  Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;

    má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.

    Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́.

    Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.

  15. 15 “Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́. 16  Nígbà náà èmi yóò wá béèrè lọ́wọ́ Baba. Òun yóò sì fún yín ní olùtùnú mìíràn. Olùtùnú náà yóò máa bá yín gbé títí láé. 17 Òun ni Ẹ̀mí òtítọ́. Ayé kò le gbà á. Nítorí ayé kò mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò rí i rí. Ẹ̀yin mọ̀ ọn nítorí láti ìgbà tí ẹ ti wà pẹ̀lú mí. Òun náà ti wà pẹ̀lú yín. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan yóò wọ inú yín láti máa gbé ibẹ̀. 18 Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìní Olùtùnú, kí ẹ ma dàbí ọmọ tí kò ní òbí. Rárá o! Mo tún ń tọ̀ yín bọ̀.

  16. 16 Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀, àdúrà mi ni kí a má ṣe kà á sí wọn lọ́rùn. 17 Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára; pé nípasẹ̀ mi kí a lè wàásù náà ní àwàjálẹ̀, àti pé kí gbogbo àwọn aláìkọlà lè gbọ́; a sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún náà. 18 Olúwa yóò yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ búburú gbogbo, yóò sì mu mí dé inú ìjọba ọ̀run. Ẹni ti ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.

  17. 14 Ǹjẹ́ bí a ti ní olórí àlùfáà ńlá kan, tí ó ti la àwọn ọ̀run kọjá lọ, Jesu Ọmọ Ọlọ́run, ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ wa mú ṣinṣin. 15 Nítorí a kò ní olórí àlùfáà tí kò lè ṣàì ba ni kẹ́dùn nínú àìlera wa, ẹni tí a ti dánwò lọ́nà gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwa, ṣùgbọ́n òun kò dẹ́ṣẹ̀. 16 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a wá si ibi ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́ pẹ̀lú ìgboyà, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí oore-ọ̀fẹ́ láti máa ran ni lọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀.

  18. 3 Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn

    ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.

    4 Ó ka iye àwọn ìràwọ̀

    ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ.

    5 Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára

    òye rẹ̀ kò sì ní òpin.

  19. 5  Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mose, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.

    6 “Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le, nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn. 7 Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Mose ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.

  20. 3 A kẹ́gàn rẹ̀ àwọn ènìyàn sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,

    ẹni ìbànújẹ́, tí ó sì mọ bí ìpọ́njú ti rí.

    Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí àwọn ènìyàn ń fojú pamọ́ fún

    a kẹ́gàn rẹ, a kò sì bu ọlá fún un rárá.

    4  Lóòtítọ́ ó ti ru àìlera wa lọ

    ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú,

    síbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù,

    tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú.

    5  Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa

    a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa;

    ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀,

    àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá.

  21. 28 “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ tí a sì di ẹrù wíwúwo lé lórí, èmi yóò sì fún yín ní ìsinmi. 29 Ẹ gbé àjàgà mi wọ̀. Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi nítorí onínútútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmi, ẹ̀yin yóò sì ri ìsinmi fún ọkàn yín. 30 Nítorí àjàgà mi rọrùn ẹrù mi sì fúyẹ́.”

  22. 23 Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo;

    ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.

    24 Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi

    ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo.

    25 Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ?

    Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ.

    26 Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà

    ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi

    àti ìpín mi títí láé.

  23. 2 Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀,

    bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀.

    3 Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi,

    ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi.

    Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn

    ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀.

    4 Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì i

    kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mi

    èmi kò ní ààbò;

    kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi.

    5 Èmi kígbe sí ọ, Olúwa:

    èmi wí pé, “Ìwọ ni ààbò mi,

    ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.”

    6 Fi etí sí igbe mi,

    nítorí tí èmi wà nínú àìnírètí

    gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi,

    nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ.

    7 Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú,

    kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ.

    Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkiri

    nítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.

  24. 45  Láti wákàtí kẹfà ni òkùnkùn fi ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí dé wákàtí kẹsànán ọjọ́. 46  Níwọ̀n wákàtí kẹsànán ní Jesu sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Eli, Eli, lama sabakitani” (ní èdè Heberu). Ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”

  25. 4 Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko;

    mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.

    5 Nítorí ohùn ìkérora mi,

    egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran-ara mi.

    6 Èmi dàbí ẹyẹ igún ní ijù:

    èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.

    7 Èmi dìde; èmi dàbí ẹyẹ lórí ilé.

  26. 29  Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n ń mi orí wọn pẹ̀lú, wọ́n sì ké pé, “Háà! Ìwọ tí yóò wó tẹmpili tí yóò sì tún un kọ́ láàrín ọjọ́ mẹ́ta, 30 sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú wá, kí o sì gba ara rẹ là!” 31  Bákan náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin fi í ṣẹ̀sín láàrín ara wọn, wọ́n wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là ṣùgbọ́n, ara rẹ̀ ni kò lè gbàlà. 32 Jẹ́ kí Kristi, ọba Israẹli, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀.

    33  Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsànán. 34  Ní wákàtí kẹsànán ni Jesu kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, “Eli, Eli, lama sabakitani?” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”).

  27. 3  Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo. 4  Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa pẹ̀lú lè máa tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. 5 Nítorí pé bí àwa ti pín nínú ìjìyà Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ̀ pẹ̀lú nípa Kristi. 6 Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín; tàbí bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù láti mú yin ní irú ìfaradà ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́.

  28. 4 Ìrora ikú yí mi kà,

    àti ìṣàn omi àwọn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.

    5 Okùn isà òkú yí mi ká,

    ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.

    6 Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa;

    mo sọkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́.

    Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi;

    ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀.

  29. 1 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìí,

    ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu,

    ẹni tí ó mọ ọ́, ìwọ Israẹli:

    “Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;

    Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe.

    2 Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,

    Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ;

    àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá

    wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.

    Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,

    kò ní jó ọ;

    ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.

    3 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,

    Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ;

    Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ,

    Kuṣi àti Seba dípò rẹ.

    4 Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi,

    àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ,

    Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ,

    àti ènìyàn dípò ẹ̀mí rẹ.

    5 Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;

    Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà-oòrùn wá

    èmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀-oòrùn.

  30. 6  Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. 7 Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu.

  31. 10 Mose sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọkún ní gbogbo ìdílé wọn, oníkálùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tirẹ̀. Olúwa sì bínú gidigidi. Inú Mose sì bàjẹ́ pẹ̀lú. 11 Mose sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé, “Kí ló dé tí o fi mú wàhálà yìí bá ìránṣẹ́ rẹ? Kí ni mo ṣe tí n kò fi tẹ ọ lọ́rùn tí ìwọ fi di ẹrù àwọn ènìyàn wọ̀nyí lé mi lórí. 12 Èmi ni mo ha lóyún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí bí? Àbí èmi ló bí wọn? Tí ìwọ fi sọ fún mi pé, máa gbé wọn sí oókan àyà rẹ, gẹ́gẹ́ bí abiyamọ ti máa ń gbe ọmọ ọmú lọ sí ilẹ̀ tí o ti búra láti fún àwọn baba ńlá wọn. 13 Níbo ni n ó ti rí ẹran fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Nítorí wọ́n ń sọkún sí mi pé, ‘Fún wa lẹ́ran jẹ́!’ 14 Èmi nìkan kò lè dágbé wàhálà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹrù wọn ti wúwo jù fún mi. 15 Bí ó bá sì ṣe pé báyìí ni ìwọ ó ṣe máa ṣe fún mi, kúkú pa mí báyìí, tí mo bá ti bá ojúrere rẹ pàdé—kí ojú mi má ba à rí ìparun mi.”

  32. Fún adarí orin. Tí ohùn orin “àgbọ̀nrín òwúrọ̀.” Saamu ti Dafidi.

    1  Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?

    Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là,

    àní sí igbe ìkérora mi?

    2 Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn:

    àti ní òru èmi kò dákẹ́.

  33. 17 Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́,

    Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.

    18 Olúwa súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn;

    ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.

    19 Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀,

    ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.

  34. 8 Olúwa fúnra rẹ̀ ń lọ níwájú rẹ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ; kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù má sì ṣe fòyà.”

  35. 5 Nígbà tí Saulu sì rí ogun àwọn Filistini náà òun sì bẹ̀rù, àyà rẹ̀ sì wárìrì gidigidi. 6 Nígbà tí Saulu sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa kò dá a lóhùn nípa àlá, nípa Urimu tàbí nípa àwọn wòlíì. 7 Saulu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ èmi yóò sì tọ̀ ọ́ lọ, èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”

    Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, obìnrin kan wà ní Endori tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀.”

  36. Saamu ti Dafidi.

    1 Olúwa ni olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.

    2  Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù,

    Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́,

  37. 11 “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;

    Israẹli kò ní tẹríba fún mi.

    12 Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn

    láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.

  38. 7 Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ?

    Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ?

    8 Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀;

    bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú,

    kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

    9 Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀,

    kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun,

    10 àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí

    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú.

  39. 15 “Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀

    kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí?

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé,

    Èmi kì yóò gbàgbé rẹ!

    16 Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi

    ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo.

  40. 3  Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi í hàn, rí i wí pé a ti dá a lẹ́bi ikú, ó yí ọkàn rẹ̀ padà, ó sì káàánú nípa ohun tí ó ṣe. Ó sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí ó gba náà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù. 4 Ó wí pé, “Mo ti ṣẹ̀ nítorí tí mo ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀.”

    Wọ́n dá a lóhùn pẹ̀lú ìbínú pé, “Èyí kò kàn wá! Wàhálà tìrẹ ni!”

    5 Nígbà náà ni Judasi da owó náà sílẹ̀ nínú tẹmpili. Ó jáde, ó sì lọ pokùnso.

  41. 17 Àna Mose dá a lóhùn pé, “Ohun tí o ń ṣe yìí kò dára. 18 Ìwọ àti àwọn ènìyàn ti ń tọ̀ ọ́ wá yìí yóò dá ara yín ní agara; iṣẹ́ yìí pọ̀jù fún ọ, ìwọ nìkan kò lè dá a ṣe.

  42. 9 Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

  43. 22 Nítorí orúkọ ńlá rẹ̀ Olúwa kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀, nítorí tí inú Olúwa dùn láti fi yín ṣe ènìyàn rẹ̀.

  44. 24 Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parun,

    ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó súnmọ́ ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin.

  45. 27  Àlàáfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín pé, àlàáfíà mi ni mo fi fún yin, kì í ṣe bí ayé ti fi fún ni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ó wárìrì.

  46. 13  Kò sí ẹnìkan tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé ẹnìkan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. 14  Ọ̀rẹ́ mi ni ẹ̀yin ń ṣe, bí ẹ bá ṣe ohun tí èmi pàṣẹ fún yín. 15 Èmi kò pè yín ní ọmọ ọ̀dọ̀ mọ́; nítorí ọmọ ọ̀dọ̀ kò mọ ohun tí olúwa rẹ̀ ń ṣe, ṣùgbọ́n èmi pè yín ní ọ̀rẹ́ nítorí ohun gbogbo tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá, mo ti fihàn fún yín.

  47. 24 Ẹ jẹ́ kí a yẹ ara wa wò láti ru ara wa sí ìfẹ́ àti sí iṣẹ́ rere, 25 kí a ma máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bi àṣà àwọn ẹlòmíràn; ṣùgbọ́n kí a máa gba ara ẹni níyànjú pẹ̀lúpẹ̀lú bí ẹ̀yin ti rí i pé ọjọ́ náà ń súnmọ́ etílé.

  48. 7 Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú;

    ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.

    8  Mo ti gbé Olúwa síwájú mi ní ìgbà gbogbo.

    Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.

    9 Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;

    ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,

    10  nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú,

    tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.

    11 Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí;

    Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ,

    pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

  49. 1 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú, ẹ gba Ọlọ́run gbọ́, kí ẹ sì gbà mí gbọ́ pẹ̀lú. 2  Nínú ilé Baba mi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibùgbé ni ó wà, ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ìbá tí sọ fún yín. Èmi ń lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún yín. 3 Bí mo bá sì lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún un yín, èmi ó tún padà wá, èmi ó sì mú yín lọ sọ́dọ̀ èmi tìkára mi; pé níbi tí èmi gbé wà, kí ẹ̀yin lè wà níbẹ̀ pẹ̀lú. 4 Ẹ̀yin mọ ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ sì mọ ọ̀nà náà.”

  50. 10 Olúwa wí pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ṣe yìí? Gbọ́! Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń kígbe pè mí láti ilẹ̀ wá. 11 Láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ ti wà lábẹ́ ègún, a sì ti lé ọ lórí ilẹ̀ tí ó ya ẹnu gba ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ lọ́wọ́ rẹ. 12 Bí ìwọ bá ro ilẹ̀, ilẹ̀ kì yóò fi agbára rẹ̀ so èso rẹ̀ fún ọ mọ́. Ìwọ yóò sì jẹ́ ìsáǹsá àti alárìnkiri ni orí ilẹ̀ ayé.”

  51. 5 Ọkùnrin kan wà níbẹ̀, ẹni tí ó tí wà ní àìlera fún ọdún méjìdínlógójì. 6 Bí Jesu ti rí i ní ìdùbúlẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó pẹ́ tí ó ti wà bẹ́ẹ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ fẹ́ kí a mú ọ láradá bí?”

    7 Abirùn náà dá a lóhùn wí pé, “Arákùnrin, èmi kò ní ẹni tí ìbá gbé mi sínú adágún, nígbà tí a bá ń rú omi náà, bí èmi bá ti ń bọ̀ wá, ẹlòmíràn a sọ̀kalẹ̀ sínú rẹ̀ síwájú mi.”

    8  Jesu wí fún un pé, “Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.” 9 Lọ́gán, a sì mú ọkùnrin náà láradá, ó sì gbé àkéte rẹ̀, ó sì ń rìn.

    Ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ ìsinmi.

  52. 15 Nígbà tí omi inú ìgò náà tan, ó gbé ọmọ náà sí abẹ́ igbó. 16 Ó sì lọ, ó sì jókòó nítòsí ibẹ̀, níwọ̀n bí ìtafà kan, nítorí, ó rò ó nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi kò fẹ́ wo bí ọmọ náà yóò ṣe kú.” Bí ó sì ti jókòó sí tòsí ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún.

  53. 6 Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn;

    mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn, ẹlẹ́yà àwọn ènìyàn.

    7 Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà;

    wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé.

    8 “Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa;

    jẹ́ kí Olúwa gbà á là.

    Jẹ́ kí ó gbà á là,

    nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.”

    9 Síbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú;

    ìwọ ni ó mú mi wà láìléwu, nígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi.

    10 Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wá,

    nígbà tí ìyá mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi.

    11 Má ṣe jìnnà sí mi,

    nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsí

    kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.

  54. 9 Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú;

    ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn,

    ọkàn àti ara mi pẹ̀lú.

    10 Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi

    àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn;

    agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi,

    egungun mi sì ti rún dànù.

    11 Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo,

    pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi,

    mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi;

    àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi.

    12 Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú;

    èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́.

  55. 13  Kò sí ìdánwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọ́run, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin ba à lè faradà á.

  56. 5 Ǹjẹ́ ẹni ti í ṣe opó nítòótọ́, ti ó ṣe òun nìkan, a máa gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, a sì máa dúró nínú ẹ̀bẹ̀ àti nínú àdúrà lọ́sàn àti lóru.

  57. 10 Háà! Ó ṣe tí ìyá mi bí mi,

    ọkùnrin tí gbogbo ilẹ̀ dojúkọ tí wọ́n sì bá jà!

    Èmi kò wínni, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yá lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni,

    síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré.

  58. 10  Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti ń jowú fún Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi láti gbà á kúrò báyìí.”

  59. 21 Ọba Ussiah sì ní ẹ̀tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Ó sì gbé ní ilé àwọn adẹ́tẹ̀, a sì ké e kúrò ní ilé Olúwa. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.

  60. 11 Nítorí mo mọ èrò tí mo rò sí yín,” ni Olúwa wí, “àní èrò àlàáfíà, kì í sì ṣe fún ibi, èrò láti fún un yín ní ìgbà ìkẹyìn àti ìrètí ọjọ́ iwájú.

  61. 75  Nígbà náà ni Peteru rántí nǹkan tí Jesu ti sọ pé, “Kí àkùkọ tó ó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta.” Òun sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.