Ìdí Tí Paulu Fi Ń Wàásù Pẹ̀lú Ìtara Tó Bẹ́ẹ̀
Níwọ̀n bí Paulu ti mọ bí ìdájọ́ tí ń bọ̀ ṣe bani lẹ́rù tó, ó túbọ̀ fi ìtara wàásù ìhìnrere, ó sì ń yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà láti di Kristiani. Ó ń ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Ọlọ́run mọ̀ kedere, ó sì ní ìrètí pé òun tún hàn kedere sí ẹ̀rí ọkàn àwọn ará Kọrinti. Lẹ́yìn náà, ó gbèjà ara rẹ̀ lòdì sí ìkọlù àwọn olùkọ́ èké, kí àwọn tí ó yí padà sí ìgbàgbọ́ lè ní ìdí láti fi yangàn nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aposteli. Ó sọ pé yálà ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wewu ní wíwàásù ìhìnrere, tí ẹgbẹ́ alátakò sì tipa bẹ́ẹ̀ rò pé ó ya wèrè, tàbí ó fi ìfòyebánilò yàgò fún inúnibíni, nítorí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni.
58 lẹ́yìn ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
11 Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà; ṣùgbọ́n a ń fi wá hàn fún Ọlọ́run; mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hàn ní ọkàn yín pẹ̀lú. 12 Nítorí àwa kò sì ní máa tún yin ara wá sí i yín mọ́, ṣùgbọ́n àwa fi ààyè fún yín láti máa ṣògo nítorí wa, kí ẹ lè ní ohun tí ẹ̀yin yóò fi dá wọn lóhùn, àwọn ti ń ṣògo lóde ara kì í ṣe ní ọkàn. 13 Nítorí náà bí àwa bá ń sínwín, fún Ọlọ́run ni tàbí bí iyè wá bá ṣí pépé, fún yín ni. 14 Nítorí ìfẹ́ Kristi ń rọ̀ wá, nítorí àwa mọ̀ báyìí pé, bí ẹnìkan bá kú fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ nígbà náà, gbogbo wọ́n ni ó ti kú. 15 Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láààyè má sì ṣe wà láààyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde.
Ẹ̀dá Tuntun Tí A Bá Ọlọ́run Làjà
Láti inú òtítọ́ pé Kristi kú fún gbogbo ènìyàn, Paulu tẹ̀síwájú láti ṣàlàyé pé láti ìsinsin yìí lọ, kò sí ìyàtọ̀ láàárín Júù àti kèfèrí, nítorí a kò tún ka Kristi sí Júù nípa ti ara mọ́. Gbogbo àwọn tí a so pọ̀ mọ́ Kristi nípa ìgbàgbọ́ di ẹ̀dá tuntun, ìṣe wọn àtijọ́ àti ẹlẹ́ṣẹ̀ sì ti dópin. Àwọn àǹfààní àti ìbùkún ipò tuntun yìí wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan, ẹni tí ó ti bá ayé làjà sí ara rẹ̀ nípasẹ̀ Kristi Jesu, tí ó sì ti fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé àwọn aposteli lọ́wọ́. Paulu, ní orúkọ Kristi, rọ gbogbo ènìyàn láti wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n sì gba ìdáríjì tí a rà fún wọn nípasẹ̀ ètùtù Ọmọ rẹ̀, ẹni tí a ti sọ di ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo ènìyàn.
16 Nítorí náà láti ìsinsin yìí lọ, àwa kò mọ ẹnìkan nípa ti ara mọ́; bí àwa tilẹ̀ ti mọ Kristi nípa ti ara, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́. 17 Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kristi, ó di ẹ̀dá tuntun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsi i, ohun tuntun ti dé. 18 Ohun gbogbo sì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ẹni tí ó sì tipasẹ̀ Jesu Kristi bá wa làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, tí ó sì ti fi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà fún wa. 19 Èyí ni pé, Ọlọ́run wà nínú Kristi, ó ń bá aráyé làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ka ìrékọjá wọn sí wọn lọ́rùn; ó sì ti fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́. 20 Nítorí náà àwa ni ikọ̀ fún Kristi, bí ẹni pé Ọlọ́run ń ti ọ̀dọ̀ wa ṣìpẹ̀ fún yín: àwa ń bẹ̀ yín ní ipò Kristi, “Ẹ bá Ọlọ́run làjà.” 21 Nítorí ó tí fi í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ nítorí wa, ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ rí, kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nínú rẹ̀.
Àwọn Àmì Ìránṣẹ́ Olóòótọ́
Gẹ́gẹ́ bí aṣojú Kristi, Paulu bẹ àwọn ará Kọrinti pé kí wọ́n má ṣe gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lásán, ṣùgbọ́n kí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí ìhìnrere ń béèrè. Nípa ṣíṣàpèjúwe àwọn ìjìyà tirẹ̀, Paulu fi bí ìránṣẹ́ ìhìnrere olóòótọ́ ṣe rí hàn, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ẹ̀rí hàn pé olùkọ́ èké náà kéré sí i.
1 Gẹ́gẹ́ bí alábáṣiṣẹ́pọ̀ nínú Ọlọ́run, ǹjẹ́, àwa ń rọ̀ yín kí ẹ má ṣe gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lásán. 2 Nítorí o wí pé,
“Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mi, èmi tí gbọ́ ohùn rẹ,
àti ọjọ́ ìgbàlà, èmi sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́.”
Èmi wí fún ọ, nísinsin yìí ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, nísinsin yìí ni ọjọ́ ìgbàlà.
3 Àwa kò sì gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ kankan si ọ̀nà ẹnikẹ́ni, ki iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa má ṣe di ìsọ̀rọ̀-òdì sí. 4 Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ni ọnà gbogbo, àwa ń fi ara wa hàn bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú wàhálà, 5 nípa nínà, nínú túbú, nínú ìrúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìsàn, nínú ìgbààwẹ̀. 6 Nínú ìwà mímọ́, nínú ìmọ̀, nínú ìpamọ́ra, nínú ìṣeun, nínú Ẹ̀mí Mímọ́, nínú ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. 7 Nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run, nínú ìhámọ́ra òdodo ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì. 8 Nípa ọlá àti ẹ̀gàn, nípa ìyìn búburú àti ìyìnrere: bí ẹlẹ́tàn, ṣùgbọ́n a jásí olóòtítọ́, 9 bí ẹni tí a kò mọ̀, ṣùgbọ́n a mọ̀ wá dájúdájú; bí ẹni tí ń kú lọ, ṣùgbọ́n a ṣì wà láààyè; bí ẹni tí a nà, ṣùgbọ́n a kò sì pa wá, 10 bí ẹni tí ó kún fún ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n àwa ń yọ̀ nígbà gbogbo; bí tálákà, ṣùgbọ́n àwa ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dí ọlọ́rọ̀; bí ẹni tí kò ní nǹkan, ṣùgbọ́n àwa ni ohun gbogbo.
Paulu Ka Ìbáṣepọ̀ Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Àwọn Aláìgbàgbọ́ Lẹ́èwọ̀
Paulu sọ bí ìfẹ́ àti ìfọkànsìn rẹ̀ sí àwọn ará Kọrinti ṣe pọ̀ tó. Ó bá wọn wí nítorí àìní ìfẹ́ wọn, ó sì rọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ rẹ̀ pé kí wọ́n ṣí ọkàn wọn sí i sílẹ̀ gbangba gẹ́gẹ́ bí baba wọn nípa ti ẹ̀mí. Ó kọ̀ fún wọn láti fẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́, láti bá wọn ṣọ̀rẹ́, tàbí láti ní irú ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ èyíkéyìí pẹ̀lú wọn. Ìlérí Ọlọ́run fún àwọn tí ó ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú irú àjọṣe àìmọ́ bẹ́ẹ̀ yẹ kí ó jẹ́ ohun tí yóò ru wọn lọ́kàn jù lọ láti lépa pípé.
11 Ẹ̀yin ará Kọrinti, a ti bá yín sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀, a ṣí ọkàn wa páyà sí yín. 12 Àwa kò fa ìfẹ́ wa sẹ́yìn fún yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin fa ìfẹ́ yín sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ wa. 13 Ní sísán padà, ní ọ̀nà tí ó dára, èmi ń sọ bí ẹni pé fún àwọn ọmọdé, ẹ̀yin náà ẹ ṣí ọkàn yín páyà pẹ̀lú.
14 Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́, nítorí ìdàpọ̀ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdàpọ̀ kín ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn? 15 Ìrẹ́pọ̀ kín ni Kristi ní pẹ̀lú Beliali? Tàbí ìpín wó ni ẹni tí ó gbàgbọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́? 16 Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹmpili Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ní tẹmpili Ọlọ́run alààyè; gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé:
“Èmi á gbé inú wọn,
èmi o sì máa rìn láàrín wọn,
èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn,
wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”
17 Nítorí náà,
“Ẹ jáde kúrò láàrín wọn,
kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀,
ni Olúwa wí.
Ki ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́;
Èmi ó sì gbà yín.”
18 Àti,
“Èmi o sì jẹ́ Baba fún yín.
Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi,
ní Olúwa Olódùmarè wí.”
7:1 Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́, bí a ti ní àwọn ìlérí wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí, kí a sọ ìwà mímọ́ dí pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
Paulu Bèèrè Pé Kí A Gbà Òun Gẹ́gẹ́ Bí Aposteli
Paulu bẹ àwọn ará Kọrinti pé kí wọ́n jẹ́wọ́ òun gẹ́gẹ́ bí aposteli, nípa sísọ àwọn ìdí tí òun fi yẹ fún ìfẹ́ wọn, ó sì tọ́ka láìsọ tààrà sí ìwà olùkọ́ èké náà tí ó lòdì sí tirẹ̀. Ó fi dá wọn lójú pé kì í ṣe láti dá wọn lẹ́bi ni òun fi sọ èyí, bí kò ṣe nítorí ìfẹ́ tí ó ga jù lọ tí òun ní sí wọn. Ó yọ̀ nínú ẹ̀mí rere àti ìgbọràn wọn.
2 Ẹ gbà wá tọkàntọkàn; a kò fi ibi ṣe ẹnikẹ́ni, a kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́, a kò rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ. 3 Èmi kò sọ èyí láti dá a yín lẹ́bi; nítorí mo tí wí ṣáájú pé, ẹ̀yin wà nínú ọkàn wa kí a lè jùmọ̀ kú, àti kí a lè jùmọ̀ wà láààyè. 4 Mo ní ìgboyà ńlá láti bá yín sọ̀rọ̀; ìṣògo mí lórí yín pọ̀; mo kún fún ìtùnú, mo sì ń yọ̀ rékọjá nínú gbogbo ìpọ́njú wa.
Ayọ̀ Paulu Sí Ìròyìn Tí Titu Mú Wá
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìfẹ́ rẹ̀, Paulu sọ fún àwọn ará Kọrinti nípa àníyàn rẹ̀ lórí wọn, nítorí ìbẹ̀rù pé olùkọ́ èké náà ti mú wọn ṣìnà. Ó sọ nípa ayọ̀ rẹ̀ nígbà tí Titu dé pẹ̀lú ìròyìn ìtẹríba àti ìfẹ́ wọn. Ó bá wọn sọ̀rọ̀ nípa lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́, ó sì fi dá wọn lójú pé òun pàṣẹ pé kí a yọ ọkùnrin tí ó bá ìbátan rẹ̀ lò pọ̀ náà kúrò nínú ìjọ láti fi bí òun ṣe bìkítà fún wọn tó hàn. Ó yìn ìgbọràn, ìtara àti ìrònúpìwàdà wọn. Ó sọ nípa ìtùnú tí ìwà wọn fún òun, àti ayọ̀ Titu ní rírí ìṣọ̀kan àti ìgbọràn wọn.
5 Nítorí pé nígbà tí àwa tilẹ̀ dé Makedonia, ara wá kò balẹ̀, ṣùgbọ́n a ń pọ́n wá lójú níhà gbogbo, ìjà ń bẹ lóde, ẹ̀rù ń bẹ nínú. 6 Ṣùgbọ́n ẹni tí ń tu àwọn onírẹ̀lẹ̀ nínú, àní Ọlọ́run, ó tù wá nínú nípa dídé tí Titu dé, 7 kì í sì i ṣe nípa dídé rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n nípa ìtùnú náà pẹ̀lú tí ẹ ti tù ú nínú, nígbà tí ó ròyìn fún wa ìfẹ́ àtọkànwá yín, ìbànújẹ́ yín, àti ìtara yín fún mi; bẹ́ẹ̀ ní mo sì túbọ̀ yọ̀.
8 Nítorí pé, bí mo tilẹ̀ ba inú yín jẹ́ nípa ìwé tí mo kọ èmi kò kábámọ̀ mọ́, bí mo tilẹ̀ ti kábámọ̀ tẹ́lẹ̀ rí; nítorí tí mo wòye pé ìwé mi mú yín banújẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún ìgbà díẹ̀. 9 Èmi yọ̀ nísinsin yìí, kì í ṣe nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́, ṣùgbọ́n nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́ sí ìrònúpìwàdà: nítorí ti a mú inú yín bàjẹ́ bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, kí ẹ̀yin má ṣe ti ipasẹ̀ wa pàdánù ní ohunkóhun. 10 Nítorí pé ìbànújẹ́ ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run máa ṣiṣẹ́ ìrònúpìwàdà sí ìgbàlà tí kì í mú àbámọ̀ wá, ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ti ayé a máa ṣiṣẹ́ ikú. 11 Kíyèsi i, nítorí ohun kan náà yìí tí a mú yin banújẹ́ fún bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, irú ìmúraṣíṣẹ́ tí ó mú jáde nínú yín, wíwẹ ara yín mọ́ ń kọ́, ìbànújẹ́ ń kọ́, ìpayà ń kọ́, ìfojúṣọ́nà ń kọ́, ìtara ń kọ́, ìjẹ́ni-níyà ń kọ́. Nínú ohun àmì kọ̀ọ̀kan yìí ni ẹ̀yin ti fi ara yín hàn bí aláìlẹ́bi nínú ọ̀ràn náà. 12 Nítorí náà, bí mo tilẹ̀ tí kọ̀wé sí yín, èmi kò kọ ọ́ nítorí ẹni tí ó ṣe ohun búburú náà tàbí nítorí ẹni ti a fi ohun búburú náà ṣe, ṣùgbọ́n kí àníyàn yín nítorí wá lè farahàn níwájú Ọlọ́run. 13 Nítorí náà, a tí fi ìtùnú yín tù wá nínú.
Àti nínú ìtùnú wa, a yọ̀ gidigidi nítorí pé Titu ní ayọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ gbogbo yín ni a ti tu ẹ̀mí rẹ̀ lára. 14 Bí mo tilẹ̀ ti lérí ohunkóhun fún ún nítorí yín, a kò dójútì mí; ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwa ti sọ ohun gbogbo fún yín ní òtítọ́, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ìlérí wá níwájú Titu sì jásí òtítọ́. 15 Ọkàn rẹ̀ sì fà gidigidi sí yín, bí òun ti ń rántí ìgbọ́ràn gbogbo yín, bí ẹ ti fi ìbẹ̀rù àti ìwárìrì tẹ́wọ́gbà á. 16 Mo yọ̀ nítorí pé ní ohun gbogbo, mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú yín.