Paulu Rọni Láti Fún Judea Ní Ọ̀pọ̀lọpọ̀
Nípa àpẹẹrẹ àwọn ìjọ ní Makedonia, tí wọ́n wà nínú ipò tí ó le gidigidi, Paulu rọ àwọn ará Kọrinti láti fi ọ̀làwọ́ ṣètọrẹ fún ìrànlọ́wọ́ àwọn arákùnrin Kristiani ní Judea. Ó sọ pé òun kò fi èyí lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ, nítorí iṣẹ́ inú rere gbọ́dọ̀ jẹ́ àtinúwá, ṣùgbọ́n ó ní ìrètí pé wọn yóò pọ̀ nínú rẹ̀ nípa àpẹẹrẹ àti ìfẹ́ Kristi. Ó pè wọ́n láti parí àkójọ owó tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ láìjáfara, gẹ́gẹ́ bí agbára wọn ṣe mọ, níwọ̀n bí Ọlọ́run ti ka ìfẹ́ àtinúwá olùfúnni sí pàtàkì ju bí ẹ̀bùn náà ṣe pọ̀ tó lọ. Ohun tí wọ́n bá fúnni ni a ó lò fún àwọn arákùnrin tálákà ní Judea nìkan, àwọn tí àwọn náà lè pèsè fún àìní àwọn ará Kọrinti ní àkókò tiwọn.
58 lẹ́yìn ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
1 Pẹ̀lúpẹ̀lú, ará, àwa ń sọ fún yín ní ti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fífún àwọn ìjọ Makedonia. 2 Bí ó ti jẹ́ pé a dán wọn wò nípa ìpọ́njú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ àti àìlódiwọ̀n àìní wọn ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìlawọ́ wọn. 3 Nítorí mo jẹ́rìí pé gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, àní ju agbára wọn, wọ́n ṣe é láti ìfẹ́ inú ara wọn. 4 Wọ́n ń fi ẹ̀bẹ̀ púpọ̀ rọ̀ wá ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí, láti ba à lè ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́. 5 Àti èyí, kì í ṣe bí àwa tí rò rí, ṣùgbọ́n wọ́n tètè kọ́ fi àwọn fúnra wọn fún Olúwa, àti fún wá, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run. 6 Tó bẹ́ẹ̀ tí àwa fi gba Titu níyànjú pé, bí ó tí bẹ̀rẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kí ó sì parí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí nínú yín pẹ̀lú. 7 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti pọ̀ lóhùn gbogbo, ní ìgbàgbọ́, àti ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀, àti nínú iṣẹ́ ìyìnrere gbogbo, àti ní ìfẹ́ yín sí wa, ẹ rí i wí pé ẹ̀yin pọ̀ sí i nínú ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí pẹ̀lú.
8 Kì í ṣe nípa àṣẹ ni mo fi ń sọ ọ́, ṣùgbọ́n kí a lè rí ìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín pẹ̀lú, nípa iṣẹ́ ìyìnrere ẹlòmíràn. 9 Nítorí ẹ̀yin mọ oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa Jesu Kristi, pé bí òun ti jẹ́ ọlọ́rọ̀ rí ṣùgbọ́n nítorí yín ó di tálákà kí a lè sọ yín di ọlọ́rọ̀ nípa àìní rẹ̀.
10 Àti nínú èyí ni mo fi ìmọ̀ràn mi fún yín, nítorí èyí ṣe àǹfààní fún yín, ẹ̀yin tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ níwọ̀n ọdún tí ó kọjá, kì í ṣe láti ṣe nǹkan, ṣùgbọ́n láti fẹ́ pẹ̀lú. 11 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ parí ṣíṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú; kí ó ba à lè ṣe pé, bí ìpinnu fún ṣíṣe ti wà, bẹ́ẹ̀ ni kí ìparí sì wà láti inú agbára yín. 12 Nítorí bí ìpinnu bá wà ṣáájú, ó jásí ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ènìyàn bá ní, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ní.
13 Nítorí èmi kò fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn wà ní ìrọ̀rùn, kí ó sì jẹ́ ìpọ́njú fún yín, ṣùgbọ́n pé nípa mímú dọ́gba. 14 Ní àkókò yìí, pé kí àníṣẹ́kù yín lè ṣe déédé àìní wọn, kí àníṣẹ́kù tiwọn pẹ̀lú ba à lè ṣe déédé àìní yín, kí ìmúdọ́gba ba à lè wà. 15 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni tí ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù.”
A Rán Titu àti Arákùnrin Méjì Sí Kọrinti
Paulu dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún mímú kí Titu bìkítà fún wọn bí òun náà ti ṣe. Ìtara Titu mú un láti gbé lẹ́tà yìí lọ. Paulu sọ fún wọn pé òun ń rán arákùnrin kan tí ó ní orúkọ rere gidigidi pẹ̀lú Titu, ẹni tí àwọn ìjọ ará Makedonia yàn gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí bí a ṣe ń bójú tó ẹ̀bùn wọn, kí ìfura ẹ̀bi kankan má bàa dìde lórí bí a ṣe ná owó púpọ̀ tí a fi lé wọn lọ́wọ́. A tún rán alábàáṣiṣẹ́ mìíràn, ẹni tí ìtara rẹ̀ pọ̀ ní pàtàkì ní àkókò yìí nítorí ìròyìn ẹ̀mí rere wọn. Paulu kọ́ wọn bí wọ́n yóò ṣe dáhùn ìbéèrè ẹgbẹ́ alátakò, ó sì rọ̀ wọ́n láti fi ẹ̀rí ìfẹ́ wọn àti ìgbẹ́kẹ̀lé tí Paulu ní nínú wọn hàn sí àwọn ońṣẹ́ wọ̀nyí àti àwọn ìjọ.
16 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fi ìtara àníyàn kan náà yìí sí ọkàn Titu fún yín. 17 Nítorí kì í ṣe pé òun gba ọ̀rọ̀ ìyànjú wa nìkan ni; ṣùgbọ́n bí òun ti ní ìtara púpọ̀, òun tìkára rẹ̀ tọ̀ yín wá, fúnra rẹ̀. 18 Àwa ti rán arákùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, ìyìn ẹni tí ó wà nínú ìyìnrere yíká gbogbo ìjọ. 19 Kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ẹni tí a tí yàn wá pẹ̀lú láti ọ̀dọ̀ ìjọ láti máa bá wa rìn kiri nínú ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ yìí, tí àwa ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀ fún ògo Olúwa àti ìmúra ìtara wa. 20 Àwa ń yẹra fún èyí, kí ẹnikẹ́ni má ba à rí wí sí wa ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí tí àwa pín. 21 Àwa ń gbèrò ohun rere, kì í ṣe níwájú Olúwa nìkan, ṣùgbọ́n níwájú ènìyàn pẹ̀lú.
22 Àwa sì ti rán arákùnrin wa pẹ̀lú wọn, ẹni tí àwa rí dájú nígbà púpọ̀ pé ó ní ìtara nínú ohun púpọ̀, ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí ni ìtara rẹ̀ túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ìfọkàntán ńlá tí ó ní sí yín. 23 Bí ẹnikẹ́ni bá béèrè ẹni tí Titu jẹ́, ẹlẹgbẹ́ àti olùbáṣiṣẹ́ mi ni, nítorí yín; tàbí ní ti àwọn arákùnrin wa ni ẹnikẹ́ni ń béèrè, ìránṣẹ́ ìjọ ni wọ́n jẹ́, àti ògo Kristi. 24 Nítorí náà ẹ fi ẹ̀rí ìfẹ́ yín hàn wọ́n níwájú ìjọ, àti ìṣògo wa nítorí yín.
A Rán Titu Síwájú Láti Pèsè Àkójọ Owó Sílẹ̀
Paulu tẹ̀síwájú láti rán àwọn ará Kọrinti létí pé òun ti yangàn fún àwọn ará Makedonia nípa ìfẹ́ àtinúwá wọn ní ọdún kan sẹ́yìn. Láti ìgbà náà, níwọ̀n bí ó ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Titu pé wọ́n ti ṣe àìbìkítà nínú èyí, ó ń rán Titu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti pèsè àkójọ owó náà sílẹ̀ kí òun tó dé, kí ojú má bàa tì í nítorí yíyángàn rẹ̀ nípa wọn, kí ohun tí wọ́n sì fúnni lè jẹ́ àtinúwá, kì í ṣe bí ohun tí a fi tipátipá gbà lọ́wọ́ àwọn olójúkòkòrò.
1 Nísinsin yìí, nípa ti ìpín fún ni fún àwọn ènìyàn mímọ́, kò tún yẹ mọ́ fún mi láti kọ̀wé sí yin ju bẹ́ẹ̀ lọ. 2 Nítorí mo mọ ìtara láti ṣe ìrànlọ́wọ́ yín, èyí tí mo ti ṣògo fún àwọn ará Makedonia nítorí yín, pé, àwọn ara Akaia ti múra tan níwọ̀n ọdún kan tí ó kọjá ìtara yín sì ti rú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sókè. 3 Ṣùgbọ́n mo ti rán àwọn arákùnrin, kí ìṣògo wa nítorí yín má ṣe jásí asán ní ti ọ̀ràn yìí; pé gẹ́gẹ́ bí mó ti wí, kí ẹ̀yin lè múra tẹ́lẹ̀. 4 Kí ó má ba à jẹ́ pé, bí àwọn nínú ara Makedonia bá bá mi wá, tí wọ́n sì bá yín ní àìmúra sílẹ̀, ojú a sì tì wá kì í ṣe ẹ̀yin, ní ti ìgbẹ́kẹ̀lé yìí. 5 Nítorí náà ni mo ṣe rò pé ó yẹ láti gba àwọn arákùnrin níyànjú, kí wọn kọ́kọ́ tọ̀ yín wá, kí ẹ sì múra ẹ̀bùn yín, tí ẹ ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè ti wà ní lẹ́bi ẹ̀bùn gidi, kí ó má sì ṣe dàbí ohun ti a fi ìkùnsínú ṣe.
Fúnrúgbìn Lọ́pọ̀lọpọ̀, Fúnni Pẹ̀lú Ayọ̀
Paulu rọ àwọn ará Kọrinti láti jẹ́ ọ̀làwọ́, níwọ̀n bí a ó ti san èrè fún wa ní ayé mìíràn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa níhìn-ín. Ó rọ̀ wọ́n láti fúnni pẹ̀lú ayọ̀. Ọlọ́run ní agbára láti bùkún iṣẹ́ wọn, kí ó sì pèsè ohun ìní ayé yìí fún wọn ní ìwọ̀n tí ó tó fún àìní àwọn fúnra wọn àti fún iṣẹ́ ìrànwọ́ wọn. Àwọn tí a ràn lọ́wọ́ ń yọ̀, wọ́n ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, wọ́n sì ń gbàdúrà fún àwọn tí ó fúnni.
6 Ṣùgbọ́n èyí ni mo wí pé, ẹni tí ó bá fúnrúgbìn kín ún, kín ún ni yóò ká; ẹni tí ó bá sì fúnrúgbìn púpọ̀, púpọ̀ ni yóò ká. 7 Kí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọkàn rẹ̀; kì í ṣe àfi ìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọdọ̀ má ṣe; nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ. 8 Ọlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore-ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín; kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo. 9 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ pé:
“Ó tí fọ́nká; ó ti fi fún àwọn tálákà,
òdodo rẹ̀ dúró láéláé.”
10 Ǹjẹ́ ẹni tí ń fi irúgbìn fún afúnrúgbìn, àti àkàrà fún oúnjẹ, yóò fi irúgbìn fún un yín, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, yóò sì mú èso òdodo yín bí sí i. 11 Bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo, fún ìlawọ́ yín gbogbo tí ń ṣiṣẹ́ ọpẹ́ sí Ọlọ́run nípa wa.
12 Nítorí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìsìn yìí kò kún ìwọ̀n àìní àwọn ènìyàn mímọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ó túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọpẹ́ sí Ọlọ́run. 13 Nítorí ìdúró yin lábẹ́ ìdánwò iṣẹ́ ìsìn yìí, wọn yóò yin Ọlọ́run lógo fún ìgbọ́ràn yín ní gbígba ìyìnrere Kristi àti nípa ìlawọ́ ìdáwó yín fún wọn àti fún gbogbo ènìyàn. 14 Àti nínú àdúrà fún un yín, ọkàn wọn ń ṣe àfẹ́rí yín nítorí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ti ń bẹ nínú yín. 15 Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nítorí aláìlèfẹnusọ ẹ̀bùn rẹ̀!
Paulu Kìlọ̀ Pé Òun Lè Ní Ìgboyà Lójúkojú
Ní báyìí Paulu sọ̀rọ̀ ní pàtàkì sí olùkọ́ èké náà àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, tí wọ́n ti ba orúkọ rẹ̀ jẹ́ nípa sísọ pé ó máa ń jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́ nígbà tí ó bá wà lọ́dọ̀ wọn nìkan, ṣùgbọ́n ó máa ń ní ìgboyà nínú lẹ́tà rẹ̀ nígbà tí kò sí níbẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí níbẹ̀, ó fi ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn bẹ àwọn tí ń fi ẹ̀sùn kàn án pé ó ń gbé nípa ti ara pé kí wọ́n má ṣe fún òun ní ìdí láti fi ìgboyà òun hàn nígbà tí òun bá wà níbẹ̀. Ó sọ nípa àwọn agbára àrà ọ̀tọ̀ tí Ọlọ́run fún un láti wó gbogbo ohun tí ó lòdì sí ìhìnrere lulẹ̀, ó sì tẹnumọ́ pé òun ti múra láti fi agbára iṣẹ́ ìyanu òun hàn láti fi ìyà jẹ àìgbọràn ní kété tí ìgbọràn àwọn tí ó ronúpìwàdà láàárín wọn bá pé.
1 Ṣùgbọ́n èmi Paulu fúnra mi fi inú tútù àti ìwà pẹ̀lẹ́ Kristi bẹ̀ yín, èmi ẹni ìrẹ̀lẹ̀ lójú yín nígbà tí mo wà láàrín yín, ṣùgbọ́n nígbà tí èmi kò sí, mo di ẹni ìgboyà sí yín. 2 Ṣùgbọ́n èmi bẹ̀ yín pé nígbà tí mo wà láàrín yín, kí èmi ba à lè lo ìgboyà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé náà, eléyìí tí mo ti fọkàn sí láti fi dojúkọ àwọn kan, ti ń funra sí wa bí ẹni tí ń rìn nípa ìlànà ti ayé yìí. 3 Nítorí pé, bí àwa tilẹ̀ n gbé nínú ayé, ṣùgbọ́n àwa kò jagun nípa ti ara. 4 Nítorí ohun ìjà wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n ó lágbára nínú Ọlọ́run láti wó ibi gíga palẹ̀. 5 Àwa ń sọ gbogbo èrò àti gbogbo ohun gíga ti ń gbe ara rẹ̀ ga sí ìmọ̀ Ọlọ́run kalẹ̀, àwa sì ń di gbogbo èrò ní ìgbèkùn wá sí ìtẹríba fún Kristi. 6 Àwa sì ti murá tan láti jẹ gbogbo àìgbọ́ràn ní yà, nígbà tí ìgbọ́ràn yín bá pé.