Paulu Bá Dídájọ́ Nípa Ìrísí Òde Wí
Paulu bá olùkọ́ èké náà wí fún dídájọ́ nípa ìrísí òde. Ó tún béèrè pé kí a jẹ́wọ́ òun gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Kristi, ó sì yangàn nípa agbára tí a fún un láti gbé wọn ró. Ó tún fi ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn tọ́ka sí àwọn ìròyìn ìbanijẹ́ ọ̀tá rẹ̀, ó sì pè é láti fi àbájáde agbára Paulu tí a ti rí nígbà tí kò sí níbẹ̀ nínú ìjìyà ọkùnrin tí ó bá ìbátan rẹ̀ lò pọ̀ náà mọ̀ pé agbára náà yóò tóbi bákan náà nígbà tí ó bá wà níbẹ̀.
58 lẹ́yìn ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
7 Ẹ̀yin sì ń wo nǹkan gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fihàn lóde. Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìgboyà nínú ara rẹ̀, ti Kristi ni òun, kí ó tún rò lẹ́ẹ̀kan si pé, bí òun ti jẹ́ ti Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwa pẹ̀lú jẹ́ ti Kristi. 8 Nítorí bí mo tilẹ̀ ń ṣògo bí ó ti wù mi nítorí agbára, tí Olúwa ti fi fún wá fún ìdàgbàsókè, dípò fífà yín ṣubú, ojú kí yóò tì mí. 9 Kí ó má ṣe dàbí ẹni pé èmi ń fi ìwé kíkọ dẹ́rùbà yín. 10 Nítorí wọ́n wí pé, “Ìwé rẹ wúwo, wọn sì lágbára; ṣùgbọ́n ní ti ara ìrísí rẹ̀ jẹ aláìlera, ọ̀rọ̀ rẹ kò níláárí.” 11 Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé, irú ẹni tí àwa jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ nípa ìwé kíkọ nígbà tí àwa kò sí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa sì jẹ́ nínú iṣẹ́ pẹ̀lú nígbà ti àwa bá wà.
Yíyángàn Láàárín Ààlà Tí Ọlọ́run Fi Lélẹ̀
Bí Paulu ti ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó ń fi òdì kejì ohun tí ó ní lọ́kàn sọ lọ, ó sọ pé òun kò gbójúgbóyà láti fi ara òun wé olùkọ́ èké náà, tí ó ń fi ara rẹ̀ nìkan wọn ara rẹ̀, tí ó sì ń yin ara rẹ̀ fún ohun tí ó ti ṣe ní Kọrinti. Ní ìdàkejì, Paulu fẹ́ yọ̀ láàárín ààlà tí Ọlọ́run là fún un nìkan, èyí tí ó ṣègbọràn sí tí ó fi dé ọ̀dọ̀ àwọn ará Kọrinti báyìí. Ó kọ̀ láti máa ṣògo nípa iṣẹ́ àwọn ẹlòmíràn bí olùkọ́ èké náà, ó sì ń retí láti wàásù ìhìnrere ní àwọn ilẹ̀ tí a kò tíì wàásù rẹ̀ rí. Nítorí kì í ṣe ẹni tí ń ṣògo nínú iṣẹ́ àwọn ẹlòmíràn ni a tẹ́wọ́ gbà, bí kò ṣe ẹni tí ń wàásù fún ògo Ọlọ́run, tí ó sì rí ìyìn gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀bùn Ẹ̀mí ti fi hàn.
12 Nítorí pé àwa kò dáṣà láti ka ara wa mọ́, tàbí láti fi ara wa wé àwọn mìíràn nínú wọn tí ń yin ara wọn; ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn jẹ́ aláìlóye bí wọn ti ń fi ara wọn díwọ̀n ara wọ́n, tí wọ́n sì ń fi ara wọn wé ara wọn. 13 Ṣùgbọ́n àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, ṣùgbọ́n nípa ààlà ìwọ̀n tí Ọlọ́run ti pín fún wa, èyí tí ó mú kí ó ṣe é ṣe láti dé ọ̀dọ̀ yín. 14 Nítorí àwa kò nawọ́ wa rékọjá rárá, bí ẹni pé àwa kò dé ọ̀dọ̀ yín: nítorí àwa tilẹ̀ dé ọ̀dọ̀ yín pẹ̀lú nínú ìyìnrere Kristi. 15 Àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, èyí nì, lórí iṣẹ́ ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n àwa ní ìrètí pé, bí ìgbàgbọ́ yín ti ń dàgbà sí i, gẹ́gẹ́ bí ààlà wa, àwa ó dí gbígbéga lọ́dọ̀ yín sí i lọ́pọ̀lọ́pọ̀. 16 Kí a bá à lè wàásù ìyìnrere ní àwọn ìlú tí ń bẹ níwájú yín, kí a má sì ṣògo nínú ààlà ẹlòmíràn nípa ohun tí ó wà ní àrọ́wọ́tó. 17 “Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.” 18 Nítorí kì í ṣe ẹni tí ń yin ara rẹ̀ ni ó ní ìtẹ́wọ́gbà, bí kò ṣe ẹni tí Olúwa bá yìn.
Paulu Bẹ̀rù Pé A Ń Ṣì Àwọn Ará Kọrinti Lọ́nà
Bí a ti fẹ̀sùn kan Paulu pé ó ń yin ara rẹ̀, ó bẹ àwọn ará Kọrinti pé kí wọ́n fi ààyè gba èyí ní àkókò yìí, nítorí ó bẹ̀rù pé olùkọ́ èké náà ti mú àwọn tí òun jèrè sí Kristi kúrò lọ́dọ̀ òun; àwọn tí ó ń hára gàgà láti fi hàn ní ìdájọ́ bí wúńdíá mímọ́ fún ọkọ tí a ti ṣèlérí wọn fún. Ó ṣàlàyé pé bí ẹni tí wọ́n ń pè ní àpọ́sítélì wọn bá wàásù Olùgbàlà mìíràn tàbí ìhìnrere mìíràn fún wọn, tàbí tí ó fún wọn ní Ẹ̀mí mìíràn, wọ́n lè fi ààyè gba àwọn ohun tí òun Paulu sọ nípa ara rẹ̀. Ó fi dá wọn lójú pé òun dọ́gba pẹ̀lú àwọn olórí àpọ́sítélì Kristi, àti pé láìka àìjáfáfá òun nínú ọ̀rọ̀ sísọ sí, òun ti fi hàn wọ́n pé òun kò ṣe aláìní ìmọ̀ tí ìránṣẹ́ ìhìnrere nílò.
1 Mo rò wí pé ẹ ó faradà díẹ̀ nínú ìwà òmùgọ̀ mi ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ ni, mo fẹ́ kí ẹ gbà mí láàyè. 2 Nítorí pé èmi ń jowú lórí i yín bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, nítorí tí mo ti fì yín fún ọkọ kan, kí èmi bà á lè mú yín wá bí wúńdíá tí ó mọ́ sọ́dọ̀ Kristi. 3 Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Efa jẹ́ nípasẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín ṣáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajì fún Kristi. 4 Nítorí bí ẹnìkan bá wá tí ó sì wàásù Jesu mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù rí tàbí bí ẹ̀yin bá gba ẹ̀mí mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí ìyìnrere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà, tí ẹ sì ti yára tẹ́wọ́ gbà á.
5 Nítorí mo rò pé èmi kò rẹ̀yìn nínú ohunkóhun sí àwọn àgbà Aposteli. 6 Bí mo tilẹ̀ jẹ́ òpè nínú ọ̀rọ̀ sísọ, kì í ṣe nínú ìmọ̀; ní ọ̀nàkọnà ni àwa ti fi èyí hàn dájúdájú fún yín nínú ohun gbogbo.
Ìdí Tí Paulu Kò Fi Gba Owó Iṣẹ́ Láti Kọrinti
Paulu ṣàlàyé ìdí tí òun kò fi gba ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn ará Kọrinti. Ó sọ pé kì í ṣe àìní inú rere ló fà á, bí àwọn ọ̀tá rẹ̀ ti sọ, bí kò ṣe ìfẹ́ rẹ̀ fún wọn, àti láti dènà olùkọ́ èké náà láti sọ pé Paulu ń ṣiṣẹ́ fún èrè ayé. Ó tún ṣe èyí láti fipá mú olùkọ́ èké náà, tí ó ń gba ẹ̀bùn ní ìkọ̀kọ̀, láti fi ìwà náà sílẹ̀, kí ó sì tẹ̀lé àpẹẹrẹ Paulu. Níwọ̀n bí Satani fúnra rẹ̀ ti ń fara hàn bí angẹli ìmọ́lẹ̀, kò yẹ kí ó yani lẹ́nu pé àwọn ìránṣẹ́ Satani ń gba ipò àwọn ìránṣẹ́ tàbí àpọ́sítélì Kristi sí ara wọn.
7 Tàbí ẹ̀ṣẹ̀ ni mo dá bí èmi ti ń rẹ ara mí sílẹ̀ kí a lè gbé yín ga, nítorí tí mo wàásù ìyìnrere Ọlọ́run fún un yín lọ́fẹ̀ẹ́. 8 Èmí ń ja ìjọ mìíràn ni olè nípa gbígba ìpèsè owó ki èmi bà á lè sìn yín. 9 Nígbà tí mo sì wà pẹ̀lú yín, tí mo sì ṣe aláìní, èmi kò dẹ́rù pa ẹnikẹ́ni, nítorí ohun tí mo ṣe aláìní ni àwọn ará tí ó ti Makedonia wá ti mú wá. Bẹ́ẹ̀ ni nínú ohun gbogbo mo pa ara mi mọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹrù fún yín, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀. 10 Ó jẹ́ òtítọ́, Kristi tí ń bẹ nínú mi pé kò sí ẹni tí ó lè dá mi lẹ́kun ìṣògo yìí ni gbogbo ẹkùn Akaia. 11 Nítorí kín ni? Nítorí èmi kò fẹ́ràn yín ni bí? Ọlọ́run mọ̀.
12 Èmi yóò tẹ̀síwájú láti máa ṣe ohun ti èmi ń ṣe láti le mú ìjákulẹ̀ bá àwọn tí wọn ń wá ọ̀nà láti bá wa dọ́gba nínú èyí ti àwa ń ṣògo lé lórí. 13 Nítorí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn èké Aposteli àwọn ẹni ti ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn, tí ń pa wọ́n dà di aposteli Kristi. 14 Kì í sì í ṣe ohun ìyanu; nítorí Satani, tìkára rẹ̀ ń pa ara rẹ̀ dàbí angẹli ìmọ́lẹ̀. 15 Nítorí náà kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá pa ara wọn dàbí àwọn ìránṣẹ́ òdodo; ìgbẹ̀yìn àwọn ẹni tí yóò rí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.
Paulu Ṣògo Nípa Iṣẹ́ àti Ìjìyà Rẹ̀
Paulu tún bẹ àwọn ará Kọrinti pé kí wọ́n fi ààyè gba ìṣògo òun. Níwọ̀n bí àwọn tí kì í ṣe àpọ́sítélì ti ń ṣògo nínú ara, òun náà gbọ́dọ̀ ṣògo nípa ìkọlà rẹ̀ àti ìran Júù tí ó ti wá láti gbèjà ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì. Ó fi hàn pé àwọn ará Kọrinti ti fi sùúrù tí ó pọ̀ jù tẹríba fún bí àwọn ẹlòmíràn ṣe ń jẹ gàba lé wọn lórí, ó sì ṣàpèjúwe ìwà olùkọ́ èké náà sí wọn. Láti tako ẹ̀sùn pé ó jẹ́ ẹni ìran rírẹlẹ̀, aláìlera, tí kò sì yẹ láti jẹ́ àpọ́sítélì, ó sọ pé bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí láti ṣògo, òun náà ní í. Ó fi ara rẹ̀ wé olùkọ́ èké náà nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí, ó sì fi bí òun ṣe ga jù ú lọ hàn nípa títọ́ka sí iṣẹ́ àti ìjìyà rẹ̀, àti sí àníyàn ńlá rẹ̀ fún àwọn ìjọ àti fún olúkúlùkù, bí ó ṣe ń bá àwọn aláìlera kẹ́dùn, tí ó sì ń fi ìtara ṣiṣẹ́ láti mú àwọn tí a ṣì lọ́nà padà. Ó ń ṣògo nínú àìlera rẹ̀, pàápàá nínú bí ó ṣe sá àsálà láti Damasku, kí agbára Ọlọ́run lè farahàn.
16 Mo sì tún wí pé, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé òmùgọ̀ ni mí; ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ẹ gbà mí bí òmùgọ̀ kí èmi lè gbé ara mi ga díẹ̀. 17 Ohun tí èmi ń sọ, èmi kò sọ ọ́ nípa ti Olúwa, ṣùgbọ́n bí òmùgọ̀ nínú ìgbẹ́kẹ̀lé ìṣògo yìí. 18 Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ni ó ń ṣògo nípa ti ara, èmi ó ṣògo pẹ̀lú. 19 Nítorí ẹ̀yin fi inú dídùn gba àwọn òmùgọ̀ nígbà tí ẹ̀yin tìkára yín jẹ́ ọlọ́gbọ́n. 20 Nítorí ẹ̀yin faradà á bí ẹnìkan bá sọ yín dí òǹdè, bí ẹnìkan bá jẹ́ yín run, bí ẹnìkan bá gbà lọ́wọ́ yín, bí ẹnìkan bá gbé ara rẹ̀ ga, bí ẹnìkan bá gbá yín lójú. 21 Èmi ń wí lọ́nà ẹ̀gàn, bí ẹni pé àwa jẹ́ aláìlera!
Ṣùgbọ́n nínú ohunkóhun tí ẹnìkan ti ní ìgboyà, èmi ń sọ̀rọ̀ bí òmùgọ̀, èmi ní ìgboyà pẹ̀lú. 22 Heberu ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Israẹli ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Irú-ọmọ Abrahamu ní òun bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. 23 Ìránṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbàkígbà, ní ti fífẹ́rẹ kú nígbà púpọ̀. 24 Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù. 25 Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú. 26 Ní ìrìnàjò nígbàkígbà, nínú ewu omi, nínú ewu àwọn ọlọ́ṣà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn aláìkọlà, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu ní aginjù, nínú ewu lójú Òkun, nínú ewu láàrín àwọn èké arákùnrin. 27 Nínú làálàá àti ìrora, nínú ìṣọ́ òru nígbàkígbà, nínú ebi àti òǹgbẹ, nínú àwẹ̀ nígbàkígbà, nínú òtútù àti ìhòhò. 28 Pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí tí ó jẹ́ tí òde, ọ̀pọ̀ ni èyí tí ń wọn n dúró tì mí lójoojúmọ́, àní àníyàn fún gbogbo ìjọ. 29 Ta ni ó ṣe àìlera, tí èmi kò ṣe àìlera? Tàbí a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò gbiná?
30 Bí èmi yóò bá ṣògo, èmi ó kúkú máa ṣògo nípa àwọn nǹkan tí ó jẹ́ ti àìlera mi. 31 Ọlọ́run àti Baba Olúwa wá Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́ olùbùkún jùlọ láéláé mọ̀ pé èmi kò ṣèké. 32 Ní Damasku, baálẹ̀ tí ó wà lábẹ́ ọba Areta fi ẹgbẹ́ ogun ká ìlú àwọn ará Damasku mọ́, ó ń fẹ́ láti mú mi bí arúfin. 33 Láti ojú fèrèsé nínú agbọ̀n ni a sì ti sọ̀ mí kalẹ̀ lẹ́yìn odi, tí mo sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.