Àwọn Ìran àti Ìfihàn Paulu

Paulu sọ pé bí a bá fi ipá mú òun láti ṣògo nítorí wọn, òun yóò ṣògo nípa àwọn ìfihàn àti ìran tí òun ti rí gbà. Ní ti òun fúnra rẹ̀, ó ti pinnu láti ṣògo nípa àìlera àti ìjìyà rẹ̀ nìkan. Bí ó tilẹ̀ lè ṣògo ní òtítọ́ pátápátá, ó dá ara rẹ̀ dúró, kí ẹnikẹ́ni má bàa ka òun sí ẹni tí ó ga ju bí òun ti rí lọ.

58 lẹ́yìn ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

2 Kọrinti 12:1–6

1 Èmi kò lè ṣàì ṣògo bí kò tilẹ̀ ṣe àǹfààní, nítorí èmi ó wà sọ nípa ìran àti ìṣípáyà ti Olúwa fihàn mí. 2 Èmi mọ ọkùnrin kan nínú Kristi ní ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn, yálà nínú ara ni, èmi kò mọ̀; tàbí kúrò nínú ara, èmi kò mọ̀; Ọlọ́run mọ̀: a gbé irú ẹni náà lọ sí ọ̀run kẹta. 3 Bẹ́ẹ̀ ni èmi mọ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, yálà ní ara ni, tàbí kúrò nínú ara ni, èmi kò mọ̀: Ọlọ́run mọ̀. 4  Pé a gbé e lọ sókè sí Paradise, tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí a kò sì lè sọ, tí kò tọ́ fún ènìyàn láti máa sọ. 5 Nípa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni èmi ó máa ṣògo, ṣùgbọ́n nípa ti èmi tìkára mi èmi kì yóò ṣògo, bí kò ṣe nínú àìlera mi. 6 Nítorí pé bi èmi tilẹ̀ ń fẹ́ máa ṣògo, èmi kì yóò jẹ́ òmùgọ̀; nítorí pé èmi yóò sọ òtítọ́: ṣùgbọ́n mo kọ̀, kí ẹnikẹ́ni máa bà à fi mí pè ju ohun tí ó rí tí èmi jẹ́ lọ, tàbí ju èyí tí ó gbọ́ lẹ́nu mi,

Agbára Ọlọ́run Di Pípé Nínú Àìlera

Paulu sọ tẹnumọ́ pé Ọlọ́run ni ó rán àìsàn ara rẹ̀, èyí tí ẹgbẹ́ alátakò náà fi gàn án, kí àwọn ìfihàn ológo tí a fi fún un má bàa mú un gbéra ga jù. A kò ní mú un kúrò, nítorí agbára Ọlọ́run ń di pípé nípasẹ̀ àìlera rẹ̀. Nítorí èyí, ó ní inú dídùn sí inúnibíni, àìlera, àti irú wọn, nítorí bí àìlera rẹ̀ ṣe pọ̀ tó ni oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ń gbé inú rẹ̀ ń fún un ní agbára tó. Ìwà àwọn ará Kọrinti ti fipá mú un láti ṣògo láìfẹ́. Ó yẹ kí wọ́n ti gbèjà iṣẹ́ àpọ́sítélì rẹ̀, níwọ̀n bí wọ́n ti mọ̀ pé kò rẹlẹ̀ sí àwọn àpọ́sítélì tí ó tóbi jù lọ lọ́nà kan.

2 Kọrinti 12:7–11

7  àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣípayá, kí èmi má ba à gbé ara mi ga rékọjá, a sì ti fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ìránṣẹ́ Satani láti pọ́n mi lójú, kí èmi má bá a gbéraga rékọjá. 8 Nítorí nǹkan yìí ni mo ṣe bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta pé, kí ó lé e kúrò lára mi. 9 Òun sì wí fún mi pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ, nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fi ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kristi lè máa gbé inú mi. 10  Nítorí náà èmi ní inú dídùn nínú àìlera gbogbo, nínú ẹ̀gàn gbogbo, nínú àìní gbogbo, nínú inúnibíni gbogbo, nínú wàhálà gbogbo nítorí Kristi. Nítorí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.

11  Mo di òmùgọ̀ nípa ṣíṣògo; ẹ̀yin ní ó fi ipá mú mi ṣe é, nítorí tí ó tọ́ tí ẹ bá yìn mí, nítorí tí èmi kò rẹ̀yìn lóhunkóhun sí àwọn àgbà aposteli bí èmi kò tilẹ̀ jámọ́ nǹkan kan.

Ìbẹ̀wò Paulu Tí Ń Bọ̀ àti Àwọn Ìbẹ̀rù Rẹ̀

Paulu ń bá a lọ láti fi àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí tí ó fi fún wọn fìdí iṣẹ́ àpọ́sítélì rẹ̀ múlẹ̀. Ó bi wọ́n pé ọ̀nà wo ni òun gbà mú wọn rẹlẹ̀ sí àwọn ìjọ mìíràn, bí kò ṣe pé òun fúnra rẹ̀ kò di ẹrù lé wọn. Ó sọ èrò rẹ̀ láti bẹ̀ wọ́n wò, láìdi ẹrù lé wọn síbẹ̀, nítorí gẹ́gẹ́ bí baba wọn nípa ẹ̀mí, kì í ṣe dúkìá àwọn ọmọ rẹ̀ nípa ẹ̀mí ni ó ń wá bí kò ṣe ìgbàlà wọn. Ó tako àwọn ọ̀rọ̀ abẹ́nú àwọn alátakò rẹ̀ tó ń fi hàn pé pẹ̀lú àrékérekè ni òun fi kọ̀ láti gba owó lọ́wọ́ wọn, nípa títọ́ka sí ìwà àìmọtara-ẹni-nìkan ti Titu àti olùrànlọ́wọ́ rẹ̀. Ó sọ dájú pé òun kò rán Titu sí wọn gẹ́gẹ́ bí àwáwí fún àìwá òun fúnra rẹ̀ (2 Kọrinti 1:23), bí kò ṣe láti fún àwọn aláìgbọràn ní àkókò láti tún ìgbésí ayé wọn ṣe. Ó bẹ̀rù pé nígbà tí òun bá bẹ̀ wọ́n wò, òun yóò ní láti ṣọ̀fọ̀ lórí àwọn tí kò ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ àti ìwà àìmọ́ tí wọ́n ti dá, kí òun sì fìyà jẹ wọ́n.

2 Kọrinti 12:12–21

12 Ohun kan tí ó ṣe àmì aposteli, iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ agbára ni wọ́n ṣe ní àárín yín pẹ̀lú sùúrù tó ga. 13 Nítorí nínú kín ni ohun tí ẹ̀yin ṣe rẹ̀yìn sí ìjọ mìíràn, bí kò ṣe ní ti pé èmi fúnra mi kó jẹ́ oníyọnu fún yín? Ẹ dárí àṣìṣe yìí jì mí.

14 Kíyèsi i, ìgbà kẹta yìí ni mo múra tan láti tọ̀ yín wá, èmi kì yóò sì jẹ́ oníyọnu fún yín nítorí tí èmi kò wá nǹkan yín, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnra yín; nítorí tí kò tọ́ fún àwọn ọmọ láti máa to ìṣúra jọ fún àwọn òbí wọn, bí kò ṣe àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn. 15 Èmi ó sì fi ayọ̀ ná ohun gbogbo tí mo bá ní, èmi ó sì ná ara mi fún ọkàn yín nítòótọ́; bí mo bá fẹ́ yín lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ó ha tọ́ kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn mi díẹ̀ bí? 16  Ṣùgbọ́n ó dára bẹ́ẹ̀ tí èmi kò dẹ́rùbà yín, ṣùgbọ́n bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, èmi ń fi ọwọ́ ẹ̀rọ̀ mú yín. 17 Èmi ha rẹ́ yín jẹ nípa ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí mo rán sí yín bi? 18  Mo bẹ Titu, mo sì rán arákùnrin kan pẹ̀lú rẹ̀; Titu ha rẹ́ yín jẹ bí? Nípa ẹ̀mí kan náà kọ́ ni àwa rìn bí? Ọ̀nà kan náà kọ́ ni àwa tọ̀ bí?

19 Ẹ̀yin ha rò pé àwa ń sọ nǹkan wọ̀nyí láti gbèjà ara wa níwájú yín bí? Ní iwájú Ọlọ́run ni àwa ń sọ̀rọ̀ nínú Kristi; ṣùgbọ́n àwa ń ṣe ohun gbogbo, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, láti gbé yín ró ni. 20  Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé, nígbà tí mo bá dé, èmi kì yóò bá yín gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí mo fẹ́, àti pé ẹ̀yin yóò sì rí mi gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí ẹ̀yin kò fẹ́: kí ìjà, owú jíjẹ, ìbínú, ìpinyà, ìṣọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, òfófó, ìgbéraga, ìrúkèrúdò, má ba à wà. 21 Àti nígbà tí mo bá sì padà dé, kí Ọlọ́run mí má bà à rẹ̀ mí sílẹ̀ lójú yín, àti kí èmi má ba à sọkún nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó tí ṣẹ̀ náà tí kò sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ ìwà èérí, àgbèrè, àti wọ̀bìà tí wọ́n ti hù.

Paulu Kì Yóò Dá Àwọn Tí Ń Dẹ́ṣẹ̀ Sí

Paulu ń bá a lọ láti fi dá àwọn ará Kọrinti lójú pé nígbà tí òun bá tún bẹ̀ wọ́n wò, a ó dá wọn lẹ́jọ́ lórí ẹ̀rí ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí Òfin àti ìhìnrere. Ó rán wọn létí ìkìlọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ àti ìyà tí a fi jẹ ọkùnrin tí ó bá ìbátan rẹ̀ lòpọ̀. Ó fi dá gbogbo àwọn tí ó ti dẹ́ṣẹ̀ àti gbogbo àwọn tí ó ń tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ lójú pé òun kì yóò dá àwọn náà sí, pàápàá níwọ̀n bí wọ́n ti ń béèrè ẹ̀rí pé Kristi ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ òun; Kristi ti fi ara rẹ̀ hàn nípasẹ̀ Paulu, kì í ṣe nínú àìlera bí kò ṣe nínú agbára, nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ ńlá tí ó fún un lágbára láti ṣe. Bí a tilẹ̀ kan Kristi mọ́ àgbélébùú nínú àìlera ìwà ẹ̀dá ènìyàn rẹ̀, ó ṣì wà láàyè nípa agbára Ọlọ́run. Àwa náà jẹ́ aláìlera ní ara pẹ̀lú rẹ̀, ṣùgbọ́n Paulu yóò fi hàn pé àwọn wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run, tí yóò farahàn nínú ìyà tí wọ́n ó fi jẹ wọ́n.

2 Kọrinti 13:1–4

1  Èyí ni ó dí ìgbà kẹta tí èmi ń tọ̀ yín wá. Ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó fi ìdí ọ̀rọ̀ gbogbo múlẹ̀. 2 Mo ti sọ fún yín ṣáájú, mo sì ń sọ fún yín tẹ́lẹ̀, bí ẹni pé mo wà pẹ̀lú yín nígbà kejì, àti bí èmi kò ti sí lọ́dọ̀ yín ní ìsinsin yìí, mo kọ̀wé sí àwọn tí ó ti ṣẹ̀ náà, àti sí gbogbo àwọn ẹlòmíràn, pé bí mo bá tún padà wá, èmi kì yóò dá wọn sí. 3 Níwọ́n bí ẹ̀yin tí ń wá àmì Kristi ti ń sọ̀rọ̀ nínú mi, ẹni tí kì í ṣe àìlera sí yin, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ agbára nínú yín. 4  Nítorí pé a kàn án mọ́ àgbélébùú nípa àìlera, ṣùgbọ́n òun wà láààyè nípa agbára Ọlọ́run. Nítorí àwa pẹ̀lú jásí aláìlera nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run sí yín.

A Sọ fún Àwọn Ará Kọrinti Láti Yẹ Ara Wọn Wò

Níwọ̀n bí ẹgbẹ́ alátakò náà ti fẹ́ ẹ̀rí pé Kristi wà pẹ̀lú Paulu, ó pè wọ́n báyìí láti yẹ ara wọn wò kí wọ́n sì rí i bóyá wọ́n ní àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí tí ń fi ìwàníhìn-ín Kristi hàn. Ó ní ìrètí pé, bí wọn kò tilẹ̀ ní ẹ̀rí yìí, a kì yóò rí òun ní aláìní agbára tí ó ju ti ẹ̀dá lọ, bí ó bá di dandan fún òun láti lò ó láti fìyà jẹ wọ́n nígbà tí òun bá dé. Ó gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí wọ́n máa hùwà títọ́, nítorí ó ń fẹ́ ìrònúpìwàdà wọn gidigidi ju àǹfààní láti lo àwọn ẹ̀rí rẹ̀ àti láti fi agbára rẹ̀ hàn lọ. Ó sọ dájú pé a lè lo agbára tí ó ju ti ẹ̀dá lọ láti ṣètìlẹ́yìn fún òtítọ́ nìkan. Paulu kọ àwọn nǹkan wọ̀nyí kí wọ́n lè di pípé, kí ó má bàa di dandan láti lo agbára iṣẹ́ ìyanu tí a fi fún un láti gbé ìjọ ró lọ́nà líle nígbà tí ó bá wà pẹ̀lú wọn.

2 Kọrinti 13:5–10

5 Ẹ máa wádìí ara yín, bí ẹ̀yin bá wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa dán ara yín wò. Tàbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ ara yín pé Jesu Kristi wá nínú yín? Àfi bí ẹ̀yin bá jẹ́ àwọn tí a tanù. 6 Ṣùgbọ́n mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, àwa kì í ṣe àwọn tí a tanù. 7 Ǹjẹ́ àwa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí kí àwa lè farahàn bí àwọn ti ó tayọ̀, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè máa ṣe èyí tí ó dára bí àwa tilẹ̀ dàbí àwọn tí a tanù. 8 Nítorí àwa kò lè ṣe ohun kan lòdì sí òtítọ́, bí kò ṣe fún òtítọ́. 9 Nítorí àwa ń yọ̀, nígbà ti àwa jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yin sì jẹ́ alágbára; èyí ni àwa sì ń gbàdúrà fún pẹ̀lú, àní pípé yín. 10 Ìdí nìyí ti mo ṣe kọ̀wé àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, pé nígbà tí mo bá dé kí èmi má ba à lo ìkanra ní lílo àṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa ti fi fún mí, láti mú ìdàgbàsókè, kì í ṣe láti fà yín ṣubú.

Ìdágbére àti Ìbùkún Paulu

Lẹ́yìn tí Paulu ti parí ìbáwí rẹ̀ sí ẹgbẹ́ alátakò náà, ó bá gbogbo ìjọ sọ̀rọ̀, ó sì fún wọn ní onírúurú ìtọ́ni. Ó fi ìkíni àti ìbùkún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì parí.

2 Kọrinti 13:11–14

11 Ní àkótán, ará ó dì gbòóṣe, ẹ ṣe àtúnṣe ọ̀nà yín, ẹ tújúká, ẹ jẹ́ onínú kan, ẹ máa wà ní àlàáfíà, Ọlọ́run ìfẹ́ àti ti àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú yín.

12  Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.

13  Gbogbo àwọn ènìyàn Ọlọ́run níbi kí i yín.

14  Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa, àti ìfẹ́ Ọlọ́run, àti ìdàpọ̀ ti Èmí Mímọ́, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín.

Paulu Padà Láti Kọrinti sí Makedonia

Paulu padà láti Akaia àti Kọrinti sí Makedonia, ó sì rán àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ síwájú sí Troasi.

Ìṣe àwọn Aposteli 20:4–5

4 Sopateru ará Berea ọmọ Pirusi sì bá a lọ dé Asia, àti nínú àwọn ará Tẹsalonika, Aristarku àti Sekundu, àti Gaiusi ará Dabe, àti Timotiu; Tikiku àti Tirofimu ará Asia.

5 Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí tí lọ síwájú, wọ́n dúró dè wá ni Troasi.