Paulu Kọ̀wé sí Àwọn Ará Romu
Ní ọ̀nà rẹ̀ láti Akaia sí Makedonia, Paulu kọ lẹ́tà rẹ̀ láti Kọrinti sí àwọn Júù àti àwọn aláìkọlà, ìyẹn àwọn tí kì í ṣe Júù, ní Romu. Ó fi hàn àwọn aláìkọlà wọ̀nyí pé kì í ṣe ọgbọ́n ìmọ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń yìn gidigidi, tàbí ìwà rere wọn, tàbí ìmọ́lẹ̀ ọgbọ́n èrò ènìyàn ló lè sọ wọ́n di olódodo níwájú Ọlọ́run. Ó fi hàn àwọn Júù pé kì í ṣe ìmọ̀ wọn nípa Òfin Mose tàbí ìgbọràn wọn sí i ló lè sọ wọ́n di olódodo. Ìgbàgbọ́ nínú Kristi nìkan ni ọ̀nà kan ṣoṣo sí ìgbàlà fún gbogbo ènìyàn, bẹ́ẹ̀ sì ni ó ti rí nígbà gbogbo.
58 lẹ́yìn ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
Paulu Kí Àwọn Ará Romu
Paulu fi ìdí àṣẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì múlẹ̀. Ó fi bí Kristi ṣe jẹ́ ènìyàn hàn nípa ìran rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Dafidi, ó sì fi bí ó ṣe jẹ́ Ọlọ́run hàn nípa àjíǹde rẹ̀. Ó sọ pé òun gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kristi láti wàásù ìhìnrere fún àwọn aláìkọlà, ìyẹn àwọn tí kì í ṣe Júù, tí wọ́n jẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ nínú ìjọ Romu; nítorí náà, ó ní àṣẹ láti bá wọn sọ̀rọ̀.
1 Paulu, ìránṣẹ́ Jesu Kristi, ẹni tí a ti pè láti jẹ́ aposteli, tí a sì ti yà sọ́tọ̀ láti wàásù ìyìnrere Ọlọ́run, 2 ìyìnrere tí ó ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ rí láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́. 3 Ní ti Ọmọ rẹ̀, ẹni tí a bí láti inú irú-ọmọ Dafidi nípa ti ara, 4 ẹni tí a pinnu rẹ̀ láti jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run nínú agbára gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ìwà mímọ́, nípa àjíǹde kúrò nínú òkú, àní Jesu Kristi Olúwa wa. 5 Láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwa rí oore-ọ̀fẹ́ àti jíjẹ́ aposteli gbà, fún ìgbọ́ràn ìgbàgbọ́ láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè, nítorí orúkọ rẹ̀. 6 Ẹ̀yin pẹ̀lú si wa lára àwọn tí a pè sọ́dọ̀ Jesu Kristi.
7 Sí gbogbo àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà ní Romu tí a ti pè láti jẹ́ ènìyàn mímọ́:
Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi.
Paulu Ń Hára Gàgà Láti Bẹ Àwọn Ará Romu Wò
Paulu yọ̀ nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Ó sọ nípa ìfẹ́ ńlá tí ó ní láti bẹ̀ wọ́n wò, kí ó lè fún wọn lókun nípa fífún wọn ní ẹ̀bùn ẹ̀mí kan, ẹ̀rí tí òun àti àwọn yóò fi jọ fún ara wọn lókun, tí wọn yóò sì fi fún ara wọn ní ìtùnú nínú ìgbàgbọ́ Kristi. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a yàn láti wàásù ìyìnrere fún gbogbo orílẹ̀-èdè, ó ṣì fẹ́ wàásù rẹ̀ fún àwọn ará Romu, nítorí ìdí mẹ́ta. Èkínní, ó tẹnumọ́ ọn pé ìyìnrere ni agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà fún Júù, àti fún aláìkọlà pẹ̀lú. Èkejì, nínú ìyìnrere nìkan ni a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn, pẹ̀lú kìkì ìlànà kan ṣoṣo fún dídá ènìyàn láre àti títẹ́wọ́gbà á lọ́dọ̀ rẹ̀, èyí tí í ṣe nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa iṣẹ́. Ẹ̀kẹta, ìyìnrere tóbi ju òfin Mose lọ, tàbí ìmọ́lẹ̀ tàbí òfin ẹ̀rí-ọkàn, àwọn méjèèjì tí ń dá gbogbo àwọn tí ó ti ṣẹ̀ lẹ́bi ikú láìsí ìlànà kankan.
8 Ní àkọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi fún gbogbo yín, nítorí a ń ròyìn ìgbàgbọ́ yin káàkiri gbogbo ayé. 9 Ọlọ́run ṣá à ni ẹlẹ́rìí mi, ẹni tí èmí ń fi gbogbo ẹ̀mí mi sìn nínú ìyìnrere Ọmọ rẹ̀, bí ó ti ṣe pé ní àìsimi ni èmí ń rántí yín nígbà gbogbo nínú àdúrà mi 10 nínú àdúrà mi ìgbà gbogbo; mo tún ń gbàdúrà wí pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run kí ọ̀nà ó ṣí fún mi láti wá sọ́dọ̀ yín.
11 Nítorí èmi ń fẹ́ gidigidi láti tọ̀ yín wá, kí èmi lè fún yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀, kí a bá a le sọ yín di alágbára nínú Olúwa, 12 èyí nì ni pé, kí a lè jẹ́ ìwúrí fún ara wa nípa ìgbàgbọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. 13 Mo fẹ́ kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi, pé mo ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti tọ̀ yín wá (ṣùgbọ́n ìdíwọ́ wà fún mi), kí èmi ki ó lè jèrè ọkàn díẹ̀ láàrín yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ní láàrín àwọn aláìkọlà yòókù.
14 Nítorí mo jẹ́ ajigbèsè sí Giriki àti sí àwọn aláìgbédè tí kì í ṣe Giriki, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti sí àwọn aṣiwèrè. 15 Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń làkàkà láti wá sí Romu àti láti fi gbogbo agbára mi wàásù ìyìnrere Ọlọ́run sí i yín.
16 Èmi kò tijú ìyìnrere Jesu, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún àwọn Helleni pẹ̀lú. 17 Nítorí nínú ìyìnrere ni òdodo Ọlọ́run ti farahàn, òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú Ìwé Mímọ́ pé, “Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.”
18 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn.
Àwọn aláìkọlà mọ Ọlọ́run ṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀
Paulu fihàn pé àwọn aláìkọlà ní ẹ̀rí tí ó tó nípa Ọlọ́run àti nípa àwọn ìwà pípé rẹ̀ tí ó lógo nínú àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀dá. Láti fihàn pé kò sí ẹni tí ó lè rí ìgbàlà gbà nípa òfin àdánidá, ó ka àwọn ìwà búburú àwọn Giriki sílẹ̀, àwọn tí wọ́n ti dé òkè ìmọ̀ àti ọgbọ́n ènìyàn jùlọ. Ó tẹnumọ́ ọn pé wọ́n mọ Ọlọ́run ṣùgbọ́n wọ́n fi ìmọ̀ wọn nípa rẹ̀ pamọ́, títí ọkàn wọn fúnra wọn kò fi rí òtítọ́ mọ́, tí wọ́n sì gbé ìsìn ẹ̀dá kalẹ̀ dípò ẹlẹ́dàá. Ìmọ̀ wọn nípa Ọlọ́run mú un dá wọn lójú pé ìjìyà ń dúró de ìwà ọ̀daràn wọn, síbẹ̀ wọ́n ń bá a lọ nínú rẹ̀, wọ́n sì ń gba àwọn ẹlòmíràn níyànjú láti ṣe bákan náà.
19 Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn. 20 Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀, bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.
21 Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn. 22 Níwọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá, 23 wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kì í díbàjẹ́ sí àwọn àwòrán ère bí i ti ènìyàn tí í díbàjẹ́ àti ti ẹyẹ, àti ti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti ti ẹranko afàyàfà.
24 Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́. 25 Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé. Àmín.
26 Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ ń yí ìṣẹ̀dá ìbáṣepọ̀ tí ó tọ̀nà, sí èyí tí kò tọ̀nà. 27 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìbálòpọ̀ obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ǹ jẹ èrè ìṣìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí.
28 Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe. 29 Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àrankàn; wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà búburú; wọ́n jẹ́ afọ̀rọ̀kẹ́lẹ́ ba ni jẹ́. 30 Asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, akórìíra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, ahalẹ̀, aláròṣe ohun búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, 31 aláìníyè nínú, ọ̀dàlẹ̀, aláìnígbàgbọ́, ọ̀dájú, aláìláàánú. 32 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run pé, ẹni tí ó bá ṣe irú nǹkan wọ̀nyí yẹ sí ikú, wọn kò ní inú dídùn sí àwọn nǹkan wọ̀nyí nìkan ṣùgbọ́n wọ́n ní inú dídùn sí àwọn tí ń ṣe wọ́n.
Àwọn Júù Jẹ̀bi Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Kan Náà
Paulu mọ̀ dáadáa bí àwọn Júù ṣe múra tán láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹlòmíràn láti dá àwọn aláìkọlà tí kì í ṣe Júù lẹ́bi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó wá ń gbìyànjú láti fi yé àwọn Júù pé àwọn náà jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń kéde pé àwọn náà jẹ̀bi àwọn ìwà ọ̀daràn kan náà. A mọ̀ pé ìdájọ́ Ọlọ́run lórí irú àwọn ìwà ọ̀daràn bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nínú Òfin tiwọn fúnra wọn, jẹ́ òtítọ́, gbogbo àwọn tí ń ṣe wọ́n, yálà Júù tàbí àwọn aláìkọlà tí kì í ṣe Júù, kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ ìkẹyìn Ọlọ́run.
1 Nítorí náà, aláìríwí ni ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́ tí ń dá ni lẹ́jọ́, nítorí nínú ohun tí ìwọ ń ṣe ìdájọ́ ẹlòmíràn, ìwọ ń dá ara rẹ lẹ́bi; nítorí ìwọ tí ń dájọ́ ń ṣe ohun kan náà nínú èyí tí ìwọ ń dá ni lẹ́jọ́. 2 Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé ìdájọ́ Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́ si gbogbo àwọn tí ó ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí. 3 Nítorí bí ìwọ tí ń ṣe ènìyàn lásán bá ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí, tí ìwọ tìkára rẹ ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ ro èyí pé ìwọ o yọ nínú ìdájọ́ Ọlọ́run bí?
Ọlọ́run Ṣe Ìdájọ́ Júù àti Helleni Bákan Náà
Paulu kìlọ̀ fún àwọn Júù pé àwọn àǹfààní tí wọ́n ní yóò mú kí ìdálẹ́bi wọn pọ̀ sí i bí wọn kò bá ronúpìwàdà. Ó sọ pé Ọlọ́run kò ṣe ìyàtọ̀ láàárín àwọn Júù àti àwọn aláìkọlà nínú ìdájọ́ rẹ̀, ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìjìyà kan náà àti èrè kan náà ni a ó fi fún Júù àti Helleni ní ìwọ̀n kan náà, nítorí Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.
4 Tàbí ìwọ ń gàn ọrọ̀ oore àti ìpamọ́ra àti sùúrù rẹ̀? Ìwọ kò ha mọ̀ pé oore Ọlọ́run ni ó ń fà ọ́ lọ sì ìrònúpìwàdà?
5 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí líle àti àìronúpìwàdà ọkàn rẹ̀, ìwọ ń to ìbínú jọ fún ara rẹ de ọjọ́ ìbínú àti ìfihàn ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run. 6 Ọlọ́run yóò san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀. 7 Àwọn ẹni tí ń fi sùúrù nínú rere ṣíṣe, wá ògo àti ọlá àti àìdíbàjẹ́ ni yóò fi ìyè àìnípẹ̀kun fún. 8 Ṣùgbọ́n fún àwọn onímọ̀-tara-ẹni-nìkan, tí wọn kò sì gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọn ń tẹ̀lé ọ̀nà búburú, wọn yóò ní ìrírí ìrunú àti ìbínú rẹ̀. 9 Ìpọ́njú àti ìrora, yóò wà lórí olúkúlùkù ọkàn ènìyàn tí ń hùwà ibi: ti Júù ṣáájú, àti àwọn Helleni pẹ̀lú; 10 ṣùgbọ́n ògo, àti ọlá, àti àlàáfíà, fún olúkúlùkù ẹni tí ń hùwà rere, fún Júù, ṣáájú àti fún àwọn Helleni pẹ̀lú. 11 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn.
Ìdájọ́ Nípa Ìmọ́lẹ̀ Tí Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Ti Gbà
Paulu tún sọ pé a ó ṣe ìdájọ́ gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀ tí wọ́n ti gbà. Kì í ṣe àwọn Júù tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn gba Òfin ṣùgbọ́n tí wọn kò ṣe ohun tí ó sọ ni yóò rí ojúrere Ọlọ́run, bí kò ṣe àwọn aláìkọlà tí kì í ṣe Júù àti gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú Òfin láìjẹ́ pé wọ́n ti gba ìmọ̀ rẹ̀ tí ó dé lẹ́yìn náà. Wọ́n yóò rí ojúrere Ọlọ́run ní ọjọ́ ńlá náà, nígbà tí a ó ṣe ìdájọ́ gbogbo ènìyàn nípa òfin ẹ̀rí ọkàn àti ti ìgbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere Ọlọ́run.
12 Gbogbo àwọn tí ó ṣẹ̀ ní àìlófin wọn ó sì ṣègbé láìlófin, àti iye àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn ni a ó fi òfin dá lẹ́jọ́. 13 Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ òfin ni ẹni ìdáláre lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe òfin ni a ó dá láre. 14 Nítorí nígbà tí àwọn aláìkọlà, tí kò ní òfin, bá ṣe ohun tí ó wà nínú òfin nípa ìwà ẹ̀dá, àwọn wọ̀nyí, jẹ́ òfin fún ara wọn bí wọn kò tilẹ̀ ní òfin. 15 Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsin yìí. 16 Èyí yóò farahàn ní ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Jesu Kristi ṣe ìdájọ́ àwọn àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere mi.