Àwọn ará Kọrinti Ni Lẹ́tà Paulu
Paulu fi ọ̀rọ̀ ìyọṣùtì béèrè bóyá òun pẹ̀lú, bí olùkọ́ èké náà, nílò láti wá sí ọ̀dọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn lẹ́tà ìṣeduro. Ó sọ pé àwọn fúnra wọn ni lẹ́tà ìṣeduro òun, tí a kò kọ pẹ̀lú tàdáwà bí kò ṣe pẹ̀lú Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè, nítorí náà wọ́n jẹ́ ẹ̀rí àṣẹ tí Ọlọ́run fi lé òun lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun.
58 lẹ́yìn ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
1 Àwa ha tún bẹ̀rẹ̀ láti máa yín ara wá bí? Tàbí àwa ha ń fẹ́ ìwé ìyìn sọ́dọ̀ yín, tàbí láti ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ẹlòmíràn tí ń ṣe? 2 Ẹ̀yin fúnra yín ni ìwé ìyìn wa, tí a ti kọ sí yín ní ọkàn, ti gbogbo ènìyàn mọ̀, tí wọ́n sì ń kà. 3 Ẹ̀yin sì ń fihàn pé ìwé tí a gbà sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kristi ni yín, kì í ṣe èyí tí a sì fi jẹ́lú kọ, bí kò sẹ Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè, kì í ṣe nínú wàláà òkúta bí kò ṣe nínú wàláà ọkàn ẹran.
4 Irú ìgbẹ́kẹ̀lé yìí ni àwa ní nípasẹ̀ Kristi sọ́dọ̀ Ọlọ́run, 5 kì í ṣe pé àwa tó fún ara wa láti ṣírò ohunkóhun bí ẹni pé láti ọ̀dọ̀ àwa tìkára wa; ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní tító wà, 6 Ẹni tí ó mú wa yẹ bí ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun; kì í ṣe ní ti ìwé àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí, nítorí ìwé a máa pa ni, ṣùgbọ́n ẹ̀mí a máa sọ ní di ààyè.
Ògo Ìhìnrere Tí Ó Túbọ̀ Tóbi
Ní ìtakò sí olùkọ́ èké náà, Paulu kéde ipò gíga àti ògo tí ìhìnrere ní ju májẹ̀mú àtijọ́ lọ. Ìbòjú tí ó bo ògo òde ara Mose tí ń kọjá lọ jẹ́ àmì bí májẹ̀mú ikú ṣe ṣókùnkùn tó àti bí ó ṣe ń lo àwọn ohun àpẹẹrẹ láti tọ́ka sí òtítọ́. Nípasẹ̀ ògo tí ó wà pẹ́ tí ó sì túbọ̀ tóbi nínú àwọn ẹ̀bùn àti ìmísí Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó wà títí, a fún àwọn ìránṣẹ́ májẹ̀mú Ẹ̀mí ní agbára láti ṣí ìbòjú kúrò, láti ṣàlàyé, àti láti wàásù májẹ̀mú òdodo tí ó túbọ̀ ní ògo níbi gbogbo.
7 Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ikú, tí a tí kọ tí a sì ti gbẹ́ sí ara òkúta bá jẹ́ ológo tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè tẹjúmọ́ wíwo ojú Mose nítorí ògo ojú rẹ̀ (ògo ti ń kọjá lọ); 8 yóò ha ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù? 9 Nítorí pé bi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo. 10 Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ. 11 Nítorí pé bí èyí ti ń kọjá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo!
12 Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fi ìgboyà púpọ̀ sọ̀rọ̀. 13 Kì í sì í ṣe bí Mose, ẹni tí ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Israẹli má ba à lè tẹjúmọ́ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ. 14 Ṣùgbọ́n ojú inú wọn fọ́; nítorí pé títí fi di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mú láéláé, ìbòjú kan náà ṣì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kristi ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò. 15 Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbàkígbà ti a bá ń ka Mose, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kàn wọn. 16 Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò. 17 Ǹjẹ́ Olúwa ni Ẹ̀mí náà: níbi tí Ẹ̀mí Olúwa bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira gbé wà. 18 Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjìji, a sì ń pa wa dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.
Paulu Wàásù Kristi, Kì Í Ṣe Ara Rẹ̀
Paulu fi hàn pé iṣẹ́ ìránṣẹ́ ológo tí a fi lé òun lọ́wọ́ kún òun fún ìrètí àti ìtara nínú iṣẹ́. Ó fẹ́ fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó yẹ nípa ṣíṣàlàyé àwọn òtítọ́ ìhìnrere ní kíkún, èyí tí ó lè fara sin fún kìkì àwọn tí ọkàn wọn wà nínú ayé, tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti àwọn ìmọ̀lára líle wọn ti fọ́ lójú. Paulu sọ pé òun kò wá ògo ara òun, nítorí Ọlọ́run ti tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn òun kí òun lè fi ìmọ̀ àti ògo Ọlọ́run hàn fún àwọn ẹlòmíràn, èyí tí a ti fi hàn nínú Jesu Kristi.
1 Nítorí náà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé nípa àánú Ọlọ́run ni a rí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí gba, àárẹ̀ kò mú ọkàn wa rara, 2 ṣùgbọ́n àwa tí kọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ tí ó ní ìtìjú sílẹ̀, àwa kò rìn ní ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò fi ọwọ́ ẹ̀tàn mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n nípa fífi òtítọ́ hàn, àwa ń fi ara wa le ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù ènìyàn lọ́wọ́ níwájú Ọlọ́run. 3 Ṣùgbọ́n báyìí, bí ìyìnrere wa bá sí fi ara sin, ó fi ara sin fún àwọn tí ó ń ṣègbé. 4 Nínú àwọn ẹni tí ọlọ́run ayé yìí ti sọ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ dí afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìyìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tí í ṣe àwòrán Ọlọ́run, má ṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn. 5 Nítorí àwa kò wàásù àwa tìkára wa, bí kò ṣe Kristi Jesu Olúwa; àwa tìkára wa sì jẹ́ ẹrú yín nítorí Jesu. 6 Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé, “Kí ìmọ́lẹ̀ ó tan láti inú òkùnkùn jáde,” òun ní ó ti ń tan mọ́lẹ̀ lọ́kàn wa, láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọ́run ní ojú Jesu Kristi.
Àwọn Àpọ́sítélì Bí Ìkòkò Amọ̀
Ní fífi àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wé ìkòkò amọ̀, Paulu sọ pé Ọlọ́run yan àwọn ọkùnrin tí kò kàwé, tí a kò sì kà sí pàtàkì gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli rẹ̀, láti fi hàn pé agbára títóbi gidigidi tí ẹ̀sìn rẹ̀ fi tàn káàkiri wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn. Ó ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìṣòro tí wọ́n dojú kọ, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé ìdáǹdè wọn kúrò nínú wọn kò ti ọwọ́ ara wọn wá bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
7 Ṣùgbọ́n àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun èlò amọ̀, kí ọláńlá agbára náà lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má ṣe ti ọ̀dọ̀ wa wá. 8 A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá: a ń dààmú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù. 9 A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run. 10 Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jesu Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jesu hàn pẹ̀lú lára wa. 11 Nítorí pé nígbà gbogbo ní a ń fi àwa tí ó wà láààyè fún ikú nítorí Jesu, kí a lè fi ìyè hàn nínú ara kíkú wa pẹ̀lú. 12 Bẹ́ẹ̀ ni ikú ń ṣiṣẹ́ nínú wa, ṣùgbọ́n ìyè ṣiṣẹ́ nínú yín.
Ìgbàgbọ́ àti Ìrètí Ran Paulu Lọ́wọ́ Láti Borí
Paulu fi hàn pé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi àti ìrètí àìkú ológo, òun lè borí gbogbo ìṣòro àti ewu iṣẹ́ ìránṣẹ́ Kristiani rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé ó fara da àwọn ìjìyà wọ̀nyí nítorí wọn, kí wọ́n lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí ó bá dá wọn lójú pé òun ní inú òtítọ́. Ó sọ ìdánilójú rẹ̀ pé ìjìyà òun nítorí ìhìnrere yóò mú èrè tí ó bá a mu wá fún òun ní ọ̀run. Nítorí èyí, kì í wá àwọn àǹfààní ayé yìí tí ń kọjá lọ, bí kò ṣe ògo ayérayé ti ayé àìrí.
13 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ pé, “Èmi gbàgbọ́, nítorí náà ni èmi ṣe sọ,” pẹ̀lú ẹ̀mí ìgbàgbọ́ kan náà, a tún gbàgbọ́ àti nítorí náà ni àwa sì ṣe ń sọ. 14 Àwa mọ̀ pé, ẹni tí o jí Jesu Olúwa dìde yóò sì jí wa dìde pẹ̀lú nípa Jesu, yóò sì mú wa wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú yín, 15 Nítorí tiyín ní gbogbo rẹ̀, ki ọ̀pẹ lè dí púpọ̀ fún ògo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ ti ń gbòòrò sí i fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.
16 Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, síbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di tuntun lójoojúmọ́. 17 Nítorí ìpọ́njú díẹ̀ yìí ń pèsè ògo tí ó ní ìwọ̀n ayérayé tí ó pọ̀ rékọjá sílẹ̀ fún wa. 18 Níwọ́n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí; nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé.
Ibugbe Ọ̀run Tí Ń Bọ̀
Paulu tẹ̀síwájú nínú àlàyé rẹ̀ nípa fífi hàn bí ibugbe wa ní ọ̀run yóò ṣe ju èyí tí à ń gbé nísinsin yìí lọ tó. Ó tẹnumọ́ pé Ọlọ́run ń pèsè wa sílẹ̀ fún ipò àìkú yìí, ó sì fún wa ní Ẹ̀mí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìdánilójú rẹ̀. Èyí fún un ní ìgboyà nínú ìwàásù rẹ̀, ó sì mú kí ó múra tán láti fi ara yìí sílẹ̀ láti wà lọ́dọ̀ Olúwa. Ṣùgbọ́n yálà ó wà láàyè tàbí ó kú, ète rẹ̀ ni láti jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ jíhìn fún.
1 Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run. 2 Nítorí nítòótọ́ àwa ń kérora nínú èyí, àwa sì ń fẹ́ gidigidi láti fi ilé wa ti ọ̀run wọ̀ wá. 3 Bí ó bá ṣe pé a ti fi wọ̀ wá, a kì yóò bá wa ní ìhòhò. 4 Nítorí àwa tí a ń bẹ nínú àgọ́ yìí ń kérora nítòótọ́, kì í ṣe nítorí tí àwa fẹ́ jẹ́ aláìwọṣọ, ṣùgbọ́n pé a ó wọ̀ wá ní aṣọ sí i, kí ìyè ba à lè gbé ara kíkú mì. 5 Ǹjẹ́ ẹni tí ó ti pèsè wa fún nǹkan yìí ni Ọlọ́run, ẹni tí o sì ti fi Ẹ̀mí fún wa pẹ̀lú ni ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ń bọ̀.
6 Nítorí náà àwa ní ìgboyà nígbà gbogbo, àwa sì mọ̀ pé, nígbà tí àwa ń bẹ ní ilé nínú ara, àwa kò sí lọ́dọ̀ Olúwa. 7 Àwa ń gbé nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa rí rí. 8 Mo ní, àwa ní ìgboyà, àwa sì ń fẹ́ kí a kúkú ti inú ara kúrò, kí a sì lè wà ní ilé lọ́dọ̀ Olúwa. 9 Nítorí náà àwa ń ṣakitiyan, pé, bí àwa bá wà ní ilé tàbí bí a kò sí, kí àwa lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. 10 Nítorí pé gbogbo wa ni ó gbọdọ̀ fi ara hàn níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi; kí olúkúlùkù lè gbà èyí tí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó tọ́ sí i nígbà tí ó wà nínú ara ìbá à ṣe rere tàbí búburú.