Paulu Tẹ̀ Síwájú Sí Giriki
Paulu tẹ̀ síwájú láti Makedonia lọ sí Giriki, tàbí Akaia, ó sì dúró níbẹ̀ fún oṣù mẹ́ta.
57 lẹ́yìn ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
2 Nígbà tí ó sì tí la apá ìhà wọ̀nyí kọjá, tí ó sì ti fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gbà wọ́n ní ìyànjú, ó wá sí ilẹ̀ Giriki. 3 Ó sì dúró níbẹ̀ ní oṣù mẹ́ta, nígbà tí àwọn Júù sì dènà dè é, bí ó ti ń pète àti bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria, ó pinnu rẹ̀ láti gbà Makedonia padà lọ.
Paulu Tún Kọ̀wé Sí Àwọn ará Kọrinti 58 lẹ́yìn ìbí Kristi
Nígbà tí Paulu ti gbọ́ bí àwọn ará Kọrinti ṣe gba lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́, ó kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì láti Filipi, láti fi hàn pé ìwà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì tọ́ àti láti gbèjà àṣẹ rẹ̀, nítorí olùkọ́ èké kan ti ṣiyèméjì méjèèjì.
Paulu Tún Kí Àwọn ará Kọrinti
Ọ̀rọ̀ ìṣáájú àti ìbùkún Paulu.
1 Paulu aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, àti Timotiu arákùnrin wá,
Sí ìjọ Ọlọ́run tí ó wà ní Kọrinti pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní gbogbo Akaia:
2 Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Jesu Kristi Olúwa.
Paulu Yin Ọlọ́run fún Ìtùnú Rẹ̀
Paulu yin Ọlọ́run fún fífi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ àti gbígbà á sílẹ̀ nínú gbogbo ìpọ́njú àti ewu rẹ̀, nítorí pé nípasẹ̀ àpẹẹrẹ rẹ̀, àwọn ẹlòmíràn lè rí ìtùnú kan náà nínú irú ìjìyà bẹ́ẹ̀.
3 Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo. 4 Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa pẹ̀lú lè máa tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. 5 Nítorí pé bí àwa ti pín nínú ìjìyà Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ̀ pẹ̀lú nípa Kristi. 6 Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín; tàbí bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù láti mú yin ní irú ìfaradà ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́. 7 Àti pé ìrètí wa nípa tiyín dúró ṣinṣin, àwa si mọ̀ pé, bí ẹ̀yin ti jẹ alábápín nínú ìyà wa, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń pín nínú ìtùnú náà pẹ̀lú.
Ọlọ́run Gba Paulu Sílẹ̀ Ní Efesu
Paulu sọ bí agbára Ọlọ́run ṣe gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ewu tí ó sún mọ́ ọn ní Efesu. Ó jẹ́wọ́ àwọn àdúrà wọn fún un.
8 Arákùnrin àti arábìnrin, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè nípa wàhálà tí ó dé bá wa ní agbègbè Asia, ní ti pé a pọ́n wa lójú gidigidi rékọjá agbára ìfaradà wa, tó bẹ́ẹ̀ tí ìrètí kò tilẹ̀ sí fún ẹ̀mí wa mọ́. 9 Nítòótọ́, nínú ọkàn wa a tilẹ̀ ní ìmọ̀lára wí pé a tí gba ìdálẹ́bi ikú, ṣùgbọ́n èyí farahàn láti má mú wa gbẹ́kẹ̀lé ara wa bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń jí òkú dìde. 10 Ẹni tí ó gbà wá kúrò nínú irú ikú tí ó tóbi bẹ́ẹ̀, yóò sí tún gbà wá; òun ní àwa gbẹ́kẹ̀lé pé yóò sí máa gbà wá síbẹ̀síbẹ̀, 11 bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ń fi àdúrà yín ràn wá lọ́wọ́. Àti pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò dúpẹ́ nítorí wa fún oore-ọ̀fẹ́ ojúrere tí a rí gbà nípa ìdáhùn sí àdúrà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.
Òtítọ́ Inú Paulu Sí Àwọn ará Kọrinti
Ní títọ́ka díẹ̀ sí ẹ̀gàn olùkọ́ èké náà, Paulu yọ̀ nínú òtítọ́ inú rẹ̀ àti ìwà mímọ́ rẹ̀ sí àwọn ará Kọrinti, ó sì sọ pé kò sí ète ìmọtara-ẹni-nìkan tàbí wíwá àǹfààní ara ẹni rárá nínú rẹ̀. Ó gbẹ́kẹ̀ lé e pé gbogbo wọn yóò mọyì rẹ̀, wọn yóò sì fi í yangàn, bí àwọn kan ti ṣe tẹ́lẹ̀, nítorí pé wọn yóò jẹ́ ayọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ Olúwa.
12 Nítorí èyí ní ìṣògo wá, ẹ̀rí láti inú ọkàn wa pẹ̀lú si jẹ́rìí wí pé àwa ń gbé ìgbésí ayé tí ó ní ìtumọ̀ pàápàá jùlọ nínú ìbágbépọ̀ wa pẹ̀lú yín, nínú ìwà mímọ́ àti òtítọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Kì í ṣe nípa ọgbọ́n ti ara ni àwa ń ṣe èyí bí kò ṣe nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. 13 Nítorí pé àwa kò kọ̀wé ohun tí eyín kò lè kà àti ni mòye rẹ̀ sí yín. Mo sì tún ní ìrètí wí pé. 14 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ní ìmọ̀ nípa wa ní apá kan, bákan náà ni ẹ ó ní ìmọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́ tí ẹ ó sì fi wá yangàn, bí àwa pẹ̀lú yóò ṣe fi yín yangàn ní ọjọ́ Jesu Olúwa.
Ìdí Tí Paulu Fi Sún Ìbẹ̀wò Rẹ̀ Síwájú
Olùkọ́ èké náà ti fi àìlèpinnu àti ìfẹ́ ayé kan Paulu nítorí pé kò ṣe ìbẹ̀wò tí ó ti ṣèlérí fún àwọn ará Kọrinti. Paulu fi ìdúróṣinṣin rẹ̀ hàn nínú ẹ̀kọ́ tí kò yí padà tí ó kọ́ni, ó sì tọ́ka sí ìfàmì òróró yàn ti Ẹ̀mí Mímọ́, nípasẹ̀ èyí tí Ọlọ́run ti fi àṣẹ rẹ̀ múlẹ̀ láàárín wọn. Ó sọ tọkàntọkàn pé ìdí gidi tí òun fi fa ìbẹ̀wò òun sẹ́yìn ni pé òun fẹ́ dá wọn sí. Ó mú wọn dájú pé, dípò kí òun wá láti fìyà jẹ wọ́n, òun kọ̀wé nínú ìbànújẹ́ jíjinlẹ̀, kí òun lè ní ayọ̀ nínú ìrònúpìwàdà wọn, kí òun sì mú wọn mọ bí ìfẹ́ òun ti tóbi tó.
15 Nítorí mo ní ìdánilójú yìí wí pé, mo pinnu láti kọ́kọ́ bẹ̀ yín wò kí ẹ lè jẹ àǹfààní ìgbà méjì. 16 Mo pinnu láti bẹ̀ yín wò ní ìrìnàjò mi sí Makedonia àti láti tún bẹ̀ yín wò nígbà tí mo bá ń padà bọ̀ láti Makedonia àti wí pé kí ẹ̀yin kí ó lè rán mi láti ọ̀dọ̀ yín ní ìrìnàjò mi sí Judea. 17 Nítorí náà nígbà tí èmi ń gbèrò bẹ́ẹ̀, èmi ha ṣiyèméjì bí? Tàbí àwọn ohun tí mo pinnu, mo ha pinnu wọn gẹ́gẹ́ bí ti ará bí, pé kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ ní, bẹ́ẹ̀ ní” àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bẹ́ẹ̀ kọ́”?
18 Ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run tí jẹ́ olóòtítọ́, ọ̀rọ̀ wa fún yín kí í ṣe bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́. 19 Nítorí pé Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí a tí wàásù rẹ̀ láàrín yín nípasẹ̀ èmí àti Silfanu àti Timotiu, kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n nínú rẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ ní. 20 Nítorí tí gbogbo ìlérí Ọlọ́run dí bẹ́ẹ̀ ni nínú Kristi. Nítorí ìdí èyí ní a ṣe ń wí pé “Àmín” nípasẹ̀ rẹ̀ sí ògo Ọlọ́run. 21 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Ọlọ́run ni ó fi ẹsẹ̀ wa múlẹ̀ pẹ̀lú yín nínú Kristi, Òun ni ó ti fi àmì òróró yàn wá, 22 ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì wá pẹ̀lú, ó sì tí fi Ẹ̀mí rẹ́ sí wa ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ó ń bọ̀.
23 Mo sì pe Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́rìí ọkàn mi pé nítorí àti dá yín sí ní èmi kò ṣe padà sí Kọrinti. 24 Kì í ṣe nítorí tí àwa jẹ gàba lórí ìgbàgbọ́ yín, ṣùgbọ́n àwa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú yín fún ayọ̀ yín nítorí nípa ìgbàgbọ́ ni ẹ̀yin dúró ṣinṣin.
2:1 Nítorí náà mo tí pinnu nínú ara mí pé, èmi kì yóò tún fi ìbànújẹ́ tọ̀ yin wá. 2 Nítorí pé bí èmi bá mú inú yín bàjẹ́, ǹjẹ́ ta ni ẹni ti ìbá mú inú mí dùn ní àkókò tí inú mi bá bàjẹ́ bí kò ṣe ẹni tí mo ti ba nínú jẹ́? 3 Èmi sì kọ̀wé bí mo tí kọ sí yín pé, nígbà tí mo bá sì de, kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lọ́dọ̀ àwọn ti ìbá mú mi ní ayọ̀, nítorí tí mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú gbogbo yín, wí pé ẹ̀yin yóò jẹ́ alábápín ayọ̀ mi. 4 Nítorí pé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà àti ìrora ọkàn mí ni mo ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ omijé kọ̀wé sí yín; kì í ṣe nítorí kí a lè bà yín nínú jẹ́, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin bá a lè mọ bí ìfẹ́ tí mo ní sí yín ṣe jinlẹ̀ tó.
Dárí Ji Ẹlẹ́ṣẹ̀ Kí Ẹ Sì Gbà Á Padà
Paulu pàṣẹ fún wọn láti gba ọkùnrin tí a lé jáde kúrò nínú ìjọ, tí wọ́n ti banújẹ́ lórí rẹ̀, padà, nísinsìnyí tí ó ti ronúpìwàdà tọkàntọkàn, àti láti fi ìfẹ́ wọn hàn sí i pẹ̀lú inú rere àti ìwà ọ̀rẹ́, kí Satani má bàa mú kí ó sọ ìrètí nù. Paulu retí kí wọ́n ṣègbọràn sí òun ní yíyọ ìdájọ́ náà kúrò, bí wọ́n ti ṣègbọràn sí i ní fífi í lélẹ̀. Ó sọ pé nínú méjèèjì, òun ṣe é ní orúkọ àti àṣẹ Kristi.
5 Bí ẹnikẹ́ni bá fa ohun ìbànújẹ́ kì í ṣe èmi ni ó bà nínú jẹ́, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnra yín, níwọ̀n ìyówù kí ó jẹ́; n kò fẹ́ sọ ọ́ lọ́nà líle jù. 6 Ìyà náà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fi jẹ́ irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ tó fún un. 7 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ìbá kúkú dáríjì í, kí ẹ sí tù ú nínú ní gbogbo ọ̀nà, kí ìbànújẹ́ má bà á bo irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀. 8 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìdánilójú ìfẹ́ yín hàn sí irú ẹni náà. 9 Ìdí tí mo ṣe kọ̀wé ni kí èmi ba à lè rí ẹ̀rí dìímú nípa ìgbọ́ràn yín nínú ohun gbogbo. 10 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá dáríjì ẹnikẹ́ni, èmi pẹ̀lú dáríjì í. Ohun tí èmi pẹ̀lú bá fi jì, nítorí tiyín ní mo fi jì níwájú Kristi. 11 Kí Satani má ba à rẹ́ wa jẹ. Nítorí àwa kò ṣe aláìmọ́ àrékérekè rẹ̀.
Àníyàn Paulu Nípa Titu
Gẹ́gẹ́ bí ìdí mìíràn tí kò fi wá sí Kọrinti ní àkókò tí a yàn, Paulu sọ àníyàn rẹ̀ nípa Titu. Ó sọ nípa àṣeyọrí rẹ̀ ní Makedonia, ó sì kéde àwọn èsì ńlá ìwàásù rẹ̀, fún àwọn tí ó gba ìhìnrere àti fún àwọn tí ó kọ̀ ọ́. Ó parí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ líle kan nípa olùkọ́ èké náà àti ìkéde òtítọ́ inú rẹ̀ àti àìmọtara-ẹni-nìkan rẹ̀.
12 Ṣùgbọ́n nígbà ti mo dé Troasi láti wàásù ìyìnrere Kristi, tí mo sì rí i wí pé Olúwa ti ṣí ìlẹ̀kùn fún mi, 13 síbẹ̀ èmi kò ní àlàáfíà lọ́kàn mi, nítorí tí èmi kò rí Titu arákùnrin mi níbẹ̀. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe dágbére fún wọn, mo si rékọjá lọ sí Makedonia.
14 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí wá nígbà gbogbo nínú Kristi, tí a sì ń fi òórùn dídùn ìmọ̀ rẹ̀ hàn nípa wa níbi gbogbo. 15 Nítorí òórùn dídùn Kristi ni àwa jẹ́ fún Ọlọ́run, nínú àwọn tí a ń gbàlà àti nínú àwọn tí ó ń ṣègbé. 16 Fún àwọn kan, àwa jẹ́ òórùn sí ikú, àti fún àwọn mìíràn òórùn ìyè sí ìyè. Ta ni ó ha si tọ́ fún nǹkan wọ̀nyí? 17 Nítorí àwa kò dàbí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣòwò jẹun; ṣùgbọ́n nínú òtítọ́ inú àwa ń sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọ́run nínú Kristi gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.