Peteru tún kọ̀wé sí àwọn Kristiani Júù àti aláìkọlà
Peteru, tí ó ń retí láti kú ikú ajẹ́rìíkú láìpẹ́, kọ̀wé sí àwọn Kristiani Júù àti aláìkọlà tí wọ́n fọ́n ká sí Pọntu, Galatia, Kappadokia àti àwọn ilẹ̀ mìíràn. Ó kọ̀wé láti fi ìdí ẹ̀kọ́ àti ìlànà lẹ́tà rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀ múlẹ̀, àti láti kìlọ̀ fún wọn nípa àṣìṣe àwọn olùkọ́ èké, nípa rírán wọn létí ìdájọ́ Ọlọ́run lórí àwọn apẹ̀yìndà. Ó gbà wọ́n níyànjú nínú inúnibíni nípa títọ́ka sí ìdáǹdè ayọ̀ ti àwọn tí wọ́n ti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, àti sí òpin ìkẹyìn ti ayé yìí àti ti ètò ìsìn àwọn Júù.
66 lẹ́yìn ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
Peteru tún kí àwọn Kristiani Júù àti aláìkọlà
Ìkíni àti ìbùkún Peteru. Jesu Kristi ló yan an sípò aposteli fún àwọn Júù àti àwọn kèfèrí, ẹni tí ó ti fún àwọn aposteli ní agbára àtọ̀runwá nípasẹ̀ àwọn ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, kí wọ́n lè mú àwọn ènìyàn wá sínú ìgbésí ayé ìwà-bí-Ọlọ́run. A ń rí èyí gbà nípasẹ̀ ìmọ̀ Kristi Jesu (Johanu 17:3), ẹni tí ó pè wọ́n sí ògo jíjẹ́ aposteli rẹ̀, tí ó fi okun àti ìgboyà kún wọn fún ète yẹn, tí ó sì fi gbogbo ìlérí ológo ti ìhìnrere lé wọn lọ́wọ́, kí ènìyàn lè tún ní ìpín nínú ìṣẹ̀dá mímọ́ tí kì í kú, lẹ́yìn tí ó ti bọ́ lọ́wọ́ ìbàjẹ́ tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ń fà nínú ayé. Wọ́n ní láti fi ìgboyà tòótọ́ àti ìpinnu ọkàn lábẹ́ inúnibíni kún ìgbàgbọ́ wọn, pẹ̀lú ìmọ̀ tí ń dàgbà nípa ẹ̀kọ́ Kristi; kí wọ́n fi ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú gbogbo ìgbádùn ayé, sùúrù nínú ìpọ́njú, àti ìwà-bí-Ọlọ́run sí Ọlọ́run kún ìmọ̀; kí wọ́n sì fi ìfẹ́ sí àwọn arákùnrin wọn tí í ṣe Kristiani kún ìwà-bí-Ọlọ́run, àti ìfẹ́ sí gbogbo ènìyàn kún ìfẹ́ sí àwọn arákùnrin, láì yọ àwọn ọ̀tá wọn sílẹ̀. Bí nǹkan wọ̀nyí bá pọ̀ nínú wọn, wọn kì yóò ṣe ọ̀lẹ tàbí jẹ́ aláìléso nínú iṣẹ́ rere. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí kò ní iṣẹ́ rere àti àwọn ìwà rere Kristiani tí ń hàn nínú ìṣe jẹ́ afọ́jú àfọwọ́fà, tí ó ń pa ojú rẹ̀ mọ́ ìmọ́lẹ̀, tí ó sì yàn láti gbàgbé ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́ nígbà ìbatisí láti wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́. Nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn rí bẹ́ẹ̀, a rọ̀ wọ́n láti túbọ̀ ṣiṣẹ́ takuntakun láti fi ìdí ìpè àti yíyàn wọn nípasẹ̀ ìhìnrere múlẹ̀, láti jẹ́ ọmọ Ọlọ́run àti ìjọ rẹ̀, nípa ṣíṣe iṣẹ́ rere nípasẹ̀ ìgbàgbọ́. Bí wọ́n bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, Ọlọ́run yóò fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ gbé wọn ró, yóò sì fún wọn ní ìwọlé ọlọ́lá àti ti ìṣẹ́gun sínú ìjọba rẹ̀ àìnípẹ̀kun.
1 Simoni Peteru, ìránṣẹ́ àti aposteli Jesu Kristi,
Sí àwọn tí ó gba irú iyebíye ìgbàgbọ́ kan náà pẹ̀lú wá nínú òdodo Ọlọ́run wa àti ti Jesu Kristi Olùgbàlà:
2 Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sí i fún yín nínú ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Jesu Olúwa wa.
3 Bí agbára rẹ̀ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò fún ṣe ti ìyè àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa Ògo àti ìṣeun rẹ̀. 4 Nípa èyí tí ó fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó ṣe iyebíye fún wa: pé nípa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin lè di alábápín nínú àbùdá ti Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yin bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ́ tí ó ń bẹ nínú ayé nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.
5 Àti nítorí ìdí èyí, ẹ máa ṣe àìsimi gbogbo, ẹ fi ìwà rere kún ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ kún ìwà rere; 6 àti àìrékọjá kún ìmọ̀; àti sùúrù kún àìrékọjá; àti ìwà-bí-Ọlọ́run kún sùúrù. 7 Àti ìfẹ́ ọmọnìkejì kún ìwà-bí-Ọlọ́run; àti ìfẹ́ni kún ìfẹ́ ọmọnìkejì. 8 Nítorí bí ẹ̀yin bá ní nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n bá sì pọ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ ṣe ọ̀lẹ tàbí aláìléso nínú ìmọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. 9 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe aláìní nǹkan wọ̀nyí, kò lè ríran ní òkèèrè, ó fọjú, ó sì ti gbàgbé pé a ti wẹ òun nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́.
10 Nítorí náà, ará ẹ túbọ̀ máa ṣe àìsimi láti sọ ìpè àti yíyàn yín di dájúdájú, nítorí bí ẹ̀yin bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ̀yin kì yóò ṣubú. 11 Nítorí báyìí ni a ó pèsè fún yín lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti wọ ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.
Peteru Ti Fojú Rí Ọláńlá Kristi
Níwọ̀n bí ṣíṣe ìwà rere Kristiani nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ti jẹ́ ọ̀nà kan ṣoṣo láti wọ ìjọba Kristi, Peteru kéde pé ó ka a sí ohun tí ó yẹ fún ipò aposteli rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ṣì wà nínú ara, láti máa rán wọn létí òtítọ́ wọ̀nyí, nínú èyí tí wọ́n ti fìdí múlẹ̀ tẹ́lẹ̀, àti láti ru wọ́n sókè láti máa ṣe wọ́n. Ní mímọ̀ pé ikú òun sún mọ́lé (Johanu 21:18–19), ó ń gbìyànjú nípa kíkọ̀wé sí wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa rántí nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo lẹ́yìn tí òun bá ti fi ara sílẹ̀. Nítorí nígbà tí wọ́n sọ agbára àti ìfarahàn Jesu Kristi di mímọ̀ fún wọn, wọn kò kéde “àwọn ìtàn àròsọ tí a fi ọgbọ́n dá,” bí ìtàn àwọn abọ̀rìṣà nípa òrìṣà wọn tí ń farahàn lórí ilẹ̀ ayé ní ìrísí ènìyàn. Peteru fúnra rẹ̀, pẹ̀lú Jakọbu àti Johanu, rí ọláńlá rẹ̀ lórí òkè mímọ́, nígbà tí Ọlọ́run, láti inú ògo ọláńlá rẹ̀, kéde pé ọmọ òun ni. Ohùn yẹn àti ìyípadà ìrísí rẹ̀ fìdí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Májẹ̀mú Láéláé nípa Kristi múlẹ̀. Wọ́n ní láti fiyè sí àwọn wọ̀nyí bí ìmọ́lẹ̀ tí ó ń tọ́ aráyé sọ́nà ní ipò àìmọ̀ wọn nípa ohun ẹ̀mí, títí di ìgbà tí ọjọ́ ìhìnrere yóò mọ́, tí ìràwọ̀ òwúrọ̀ òdodo yóò sì yọ nínú ọkàn wọn. Wọ́n ní láti mọ̀ pé kò sí àsọtẹ́lẹ̀ tí ń wá láti inú ìtara ara ẹni tàbí ohun tí ẹnìkan dá sílẹ̀ fúnra rẹ̀. Nítorí kì í ṣe ìfẹ́ ènìyàn ni ó mú àsọtẹ́lẹ̀ wá sí ọkàn àwọn tí ó sọ ọ́ nígbà àtijọ́, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run kéde àwọn ète ìfẹ́ rẹ̀ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ń darí wọn, tàbí mí sí wọn.
12 Nítorí náà, èmi ó máa rán yin létí àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ti mọ̀ wọ́n, tí ẹsẹ̀ yín sì múlẹ̀ nínú òtítọ́ tí ẹ ní báyìí. 13 Èmi sì rò pé ó tọ́ láti máa mú wọn wá sí ìrántí yín, níwọ̀n ìgbà tí èmí ba ń bẹ nínú àgọ́ ara yìí. 14 Bí èmi ti mọ̀ pé, bíbọ́ àgọ́ ara mi yìí sílẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀, àní, bí Olúwa wa Jesu Kristi ti fihàn mí. 15 Èmi ó sì máa ṣaápọn pẹ̀lú, kí ẹ̀yin lè máa rántí nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo lẹ́yìn ikú mi.
16 Nítorí kì í ṣe bí ẹni tí ó ń tọ ìtàn asán lẹ́yìn tí a fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n là sílẹ̀, nígbà tí àwa sọ fún yín ní ti agbára àti wíwá Jesu Kristi Olúwa, ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí ọláńlá rẹ̀ ni àwa jẹ́. 17 Nítorí tí Ó gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, nígbà tí irú ohùn yìí fọ̀ sí i láti inú ògo ńlá náà wá pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.” 18 Àwa pẹ̀lú sì gbọ́ ohun yìí tí ó ti ọ̀run wá nígbà tí àwa wà pẹ̀lú rẹ̀ ní orí òkè mímọ́ náà.
19 Àwa sì ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì dunjúdunjú sí i, èyí tí ó yẹ kí ẹ kíyèsi gẹ́gẹ́ bí fìtílà tó ń mọ́lẹ̀ níbi tí òkùnkùn gbé wà, títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóò sì yọ lọ́kàn yín. 20 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kí ẹ ní òye yìí pé kò sí àsọtẹ́lẹ̀ ìwé mímọ́ kankan tí ó wáyé nípa ìtumọ̀ wòlíì fún rara rẹ̀. 21 Nítorí àsọtẹ́lẹ̀ kan kò ti ipá ìfẹ́ ènìyàn wá rí; ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí a ti ń darí wọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá.
Àwọn Olùkọ́ Èké àti Ìdájọ́ Ọlọ́run Tí Ó Dájú
Peteru sọ tẹ́lẹ̀ pé bí àwọn wòlíì èké ṣe wà láàárín àwọn Júù, tí wọ́n ṣi ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́nà, tí wọ́n sì sẹ́ Ọlọ́run tí ó rà wọ́n padà kúrò ní oko ẹrú ní Ejibiti, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn olùkọ́ èké yóò wà nínú ìjọ Kristiani. Wọn yóò yọ́ mú àwọn ẹ̀kọ́ àdámọ̀ tí ń pani run wọlé, wọn yóò sẹ́ Olúwa tí ó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ rà wọ́n kúrò nínú ìsìnrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú (Eksodu 15:16; Deuteronomi 32:6), wọn yóò sì mú ìparun wá sórí ara wọn. Ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò tẹ̀lé wọn, wọn yóò sì fi ìgbésí ayé búburú wọn mú kí a sọ̀rọ̀ òdì sí ìhìnrere, ní ṣíṣe òwò ẹ̀mí ènìyàn. Ìjìyà wọn, tí a ti kéde lòdì sí ẹ̀ṣẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀, kò jáfara, ṣùgbọ́n yóò dé bá wọn láìpẹ́. Nítorí Ọlọ́run kò dá àwọn angẹli tí ó ṣẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó sọ wọ́n sí ọ̀run àpáàdì, ó ń pa wọ́n mọ́ títí di ọjọ́ ìdájọ́ ní ibi ìjìyà àti òkùnkùn tí wọn kò lè bọ́ kúrò. Kò dá ayé àtijọ́ sí, bẹ́ẹ̀ ni kò dá àwọn ìlú Sodomu àti Gomorra sí, ṣùgbọ́n ó fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ ìjìyà tí yóò dé bá àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run ní ọjọ́ ìkẹyìn. Láti inú ìgbàlà iṣẹ́ ìyanu ti Noa àti Lọti, Peteru fi hàn pé bí ó ti dájú pé Ọlọ́run yóò gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé e tí wọ́n sì jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòtítọ́ kúrò nínú àdánwò àti ewu, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò fi ìparun àìnípẹ̀kun pa àwọn olùkọ́ èké àti àwọn aláìgbọ́ràn run.
1 Ṣùgbọ́n àwọn wòlíì èké wà láàrín àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ni èké yóò ti wà láàrín yín. Wọn yóò yọ́ kẹ́lẹ́ mú ẹ̀kọ́ òdì àti ègbé tọ̀ yín wa, àní tí yóò sẹ́ Olúwa tí ó rà wọ́n padà, wọ́n ó sì mú ìparun ti o yára kánkán wá sórí ara wọn. 2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò si máa tẹ̀lé ọ̀nà ìtìjú wọn, tí wọn yóò sì mú kí ọ̀nà òtítọ́ di ìsọ̀rọ̀-òdì sí. 3 Nínú ìwà wọ̀bìà wọn, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ òdì wọ̀nyí yóò máa rẹ́ ẹ yín jẹ nípa ìtàn asán. Ìdájọ́ ẹni tí kò falẹ̀ láti ìgbà yìí wá àti ìparun wọn tí kò sí tòògbé.
4 Nítorí pé bi Ọlọ́run kò bá dá àwọn angẹli si nígbà tí wọn ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ti ó sọ wọ́n sí ìsàlẹ̀ ọ̀run àpáàdì tí ó sì fi wọ́n sínú ọ̀gbun òkùnkùn biribiri nínú ìfipamọ́ títí dé ìdájọ́. 5 Bí òun kò si dá ayé ìgbàanì sí, nígbà tí ó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó pa Noa mọ́, oníwàásù òdodo, pẹ̀lú àwọn ọmọ méje mìíràn. 6 Tí ó sọ àwọn ìlú Sodomu àti Gomorra di eérú, nígbà tí ó fi ìparun pátápátá dá wọn lẹ́bi, tí ó fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò jẹ́ aláìwà-bí-Ọlọ́run. 7 Tí ó sì yọ Lọti olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí ìwà ẹ̀gbin àwọn ènìyàn láìlófin bà nínú jẹ́; 8 (nítorí ọkùnrin olóòtítọ́ náà bí ó ti ń gbé àárín wọn, tí ó ń rí, tí ó sì ń gbọ́, lójoojúmọ́ ni ìwà búburú wọn ń bá ọkàn òtítọ́ rẹ̀ jẹ́). 9 Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Olúwa mọ bí a tí ń yọ àwọn ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kúrò nínú ìdánwò àti bí a ti ń pa àwọn aláìṣòótọ́ mo fún ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí wọn yóò tẹ̀síwájú nínú ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Àwọn Olùkọ́ Èké ní Ọ̀nà Balaamu
Peteru ṣàpèjúwe ìwà àwọn olùkọ́ èké. Bí àwọn ẹranko tí kò ní làákàyè, tí ń tẹ̀lé ìsúnniṣe ẹ̀dá ẹranko wọn, tí a dá láti mú àti láti parun nítorí pé wọ́n ń pani run, wọ́n ń sọ̀rọ̀ òdì sí ohun tí kò yé wọn, wọn yóò sì ṣègbé nínú ẹ̀kọ́ àti ìṣe ìbàjẹ́ tiwọn. Wọ́n ń fi ìwà búburú wọn hàn ní gbangba. Wọ́n jẹ̀bi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ní àsè ìfẹ́ wọn. Wọ́n ń fi èrò pé a dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀ láti gbé ìfẹ́ ti ara lárugẹ tan àwọn ọkàn tí kò tíì fìdí múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ jẹ, wọ́n sì jẹ́ ògbóǹkangí nínú gbogbo ọgbọ́n ìtannijẹ àti jìbìtì. Wọ́n ń tẹ̀lé ọ̀nà Balaamu, ẹni tí (Numeri 31:16; Ìfihàn 2:14) ṣe lòdì sí ìmọ̀ àti ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ kí ó lè rí èrè ìwà búburú tí a ṣèlérí gbà.
10 Ṣùgbọ́n pàápàá àwọn tí ó ń tọ ẹran-ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìwà èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè.
Àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo. 11 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn angẹli bí wọ́n ti pọ̀ ní agbára àti ipá tó o nì, wọn kò dá wọ́n lẹ́jọ́ ẹ̀gàn níwájú Olúwa. 12 Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí, bí ẹranko igbó tí kò ní èrò, ẹranko sá á tí a dá láti máa mú pa, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nínú ọ̀rọ̀ tí kò yé wọn, a ó pa wọn run pátápátá nínú ìbàjẹ́ ara wọn.
13 Wọn yóò gba ibi padà bí ibi tí wọ́n ti ṣe. Òye ìgbafẹ́ tí wọ́n ní láti máa jẹ adùn ayé. Wọ́n jẹ́ àbàwọ́n àti àbùkù, wọ́n ń jayé nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn nígbà tí wọ́n bá ń jẹ àsè pẹ̀lú yín. 14 Ojú wọn kún fún panṣágà, wọn kò sì dẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀ dídá; wọ́n ń tan àwọn tí ọkàn kò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ jẹ; àwọn tí wọ́n ní ọkàn tí ó ti yege nínú wọ̀bìà, ọmọ ègún ni wọ́n. 15 Wọ́n kọ ọ̀nà tí ó tọ́ sílẹ̀, wọ́n sì ṣáko lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀nà Balaamu ọmọ Beori, ẹni tó fẹ́ràn èrè àìṣòdodo. 16 Ṣùgbọ́n a bá a wí nítorí ìrékọjá rẹ̀, odi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ fi ohùn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó sì fi òpin sí ìṣiwèrè wòlíì náà.
Àwọn Orísun Aláìlómi, Ẹrú Ìbàjẹ́
Peteru fi àwọn olùkọ́ èké wé àwọn orísun tí kò ní omi, àti àwọn àwọsánmà tí ó ṣe ìlérí òjò ṣùgbọ́n tí ó di ìjì níkẹyìn, tí ó sì ń fa ìparun dípò kí ó mú ìrètí ènìyàn ṣẹ. Nípa fífàyè gba gbogbo onírúurú ìwà ìṣekúṣe, wọ́n ń tan àwọn tí ó ti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn abọ̀rìṣà láti di ọmọ ẹ̀yìn wọn. Wọ́n ṣèlérí òmìnira láti tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn lọ́rùn láìsí ìkálọ́wọ́kò, nígbà tí ìwà àwọn fúnra wọn fi hàn pé ẹrú ìbàjẹ́ ni wọ́n. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ bá borí jẹ́ ẹrú rẹ̀. Fún àwọn tí ìmọ̀ ìhìnrere ti yí padà kúrò nínú ìbọ̀rìṣà àti ìwà ìṣekúṣe ti ayé àwọn abọ̀rìṣà, tí wọ́n sì tún kó sínú wọn, àwọn ẹ̀gbin wọn ìkẹyìn yóò mú ikú wá ju ti àkọ́kọ́ lọ, nítorí wọ́n ti ṣẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀ àti àǹfààní ẹ̀mí tí ó pọ̀ sí i.
17 Àwọn wọ̀nyí ni kànga tí kò ní omi, ìkùùkuu tí ẹ̀fúùfù ń gbá kiri; àwọn ẹni tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè títí láé. 18 Nítorí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ asán, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, wọn a máa tan àwọn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ má tí ì bọ́ tán kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n wà nínú ìṣìnà. 19 Wọn a máa ṣe ìlérí òmìnira fún wọn, nígbà tí àwọn pàápàá jẹ́ ẹrú ìdíbàjẹ́; nítorí ènìyàn tí di ẹrú ohunkóhun tí ó bá ṣe ọ̀gá rẹ̀. 20 Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ tán kúrò nínú èérí ayé nípa mímọ́ Olúwa àti Olùgbàlà wá Jesu Kristi, bí wọn bá sì tún fi ara kó o, tí a sì ṣẹ́gun wọn, ìgbẹ̀yìn wọn a burú jú ti ìṣáájú lọ. 21 Nítorí ìbá sàn fún wọn, kí wọn má mọ́ ọ̀nà òdodo, jù pé lẹ́yìn tí wọ́n mọ̀ ọ́n tán, kí wọn yípadà kúrò nínú òfin mímọ́ tí a fi fún wọn. 22 Òwe òtítọ́ náà ṣẹ sí wọn lára, “Ajá tún padà sí èébì ara rẹ̀; àti ẹlẹ́dẹ̀ tí a ti wẹ̀mọ́ tún padà ń yíràá nínú ẹrọ̀fọ̀.”
Àwọn Olùkọ́ Èké Tí Ó Sẹ́ Wíwá Kristi
Peteru fi hàn pé ète òun ní kíkọ lẹ́tà méjèèjì ni láti rán wọn létí àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wòlíì àtijọ́ (Saamu 1:1; Daniẹli 12:2) àti ẹ̀kọ́ àti ìtọ́ni àwọn aposteli tí a gbé karí wọn. Ó mọ̀ pé àwọn wòlíì ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìfarahàn àwọn olùkọ́ èké tí yóò sẹ́ pé Kristi yóò wá láti ṣèdájọ́ ayé (Jeremiah 17:15; Esekiẹli 12:22–27; Juda 1:14–15; Daniẹli 12:2). Wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìmọ̀ pé ọ̀run, tàbí afẹ́fẹ́ àyíká, àti ilẹ̀ ayé ni a dá nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti inú omi, èyí tí a ti lò láti pa á run tẹ́lẹ̀ nítorí ìwà búburú ènìyàn. Ilẹ̀ ayé àti afẹ́fẹ́ àyíká rẹ̀ ti ìsinsìnyí, tí ó wà nípasẹ̀ ọ̀nà kan náà, lè dojú kọ ìparun kan náà nítorí ìdí kan náà. Ṣùgbọ́n a fi wọ́n pamọ́, a sì ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ìkún omi, kí ìkún iná lè jó wọn run ní ọjọ́ ẹ̀san àti ìdájọ́.
1 Olùfẹ́, èyí ni ìwé kejì tí mo ń kọ sí yín, nínú méjèèjì náà ni èmi ń ru èrò inú yín sókè nípa rírán yín létí; 2 kí ẹ̀yin lè máa rántí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì mímọ́ sọ ṣáájú, àti òfin Olúwa àti Olùgbàlà wa láti ọ̀dọ̀ àwọn aposteli yín.
3 Kí ẹ kọ́ mọ èyí pé, nígbà ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ẹlẹ́gàn yóò dé pẹ̀lú ẹ̀gàn wọn. Wọn ó máa rìn nípa ìfẹ́ ara wọn. 4 Wọn ó sì máa wí pé, “Níbo ni ìlérí wíwà rẹ̀ gbé wà? Láti ìgbà tí àwọn baba ti sùn, ohun gbogbo ń lọ bí wọ́n ti wà rí láti ìgbà ọjọ́ yìí wá.” 5 Nítorí èyí ni wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ ṣe àìfẹ́ ẹ́ mọ̀ pé nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àwọn ọ̀run ti wà láti ìgbà àtijọ́ àti tí ilẹ̀ yọrí jáde nínú omi, tí ó sì dúró nínú omi. 6 Nípa èyí tí omi bo ayé tí ó wà nígbà náà tí ó sì ṣègbé. 7 Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀run àti ayé, tí ó ń bẹ nísinsin yìí, nípa ọ̀rọ̀ kan náà ni ó ti tò jọ bí ìṣúra fún iná, a pa wọ́n mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ìparun àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run.
Ọjọ́ Olúwa Yóò Dé Bí Olè
Peteru rọ àwọn arákùnrin Kristiani pé kí àwọn ẹlẹ́gàn má ṣe tàn wọ́n jẹ, àwọn tí ó pinnu láti inú ìjáfara Ọlọ́run pé kò ní agbára tàbí ìfẹ́ láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Wọ́n ní láti rántí pé kò sí àkókò kankan, bí ó ti wù kí ó gùn tó, tí a lè fi wé àìnípẹ̀kun Ọlọ́run, àti pé kò sí àkókò tí ó lè yí àwọn ète rẹ̀ padà (Saamu 90:4). Wíwá Olúwa kò jáfara nítorí ìdí tí àwọn olùkọ́ wọ̀nyí sọ, ṣùgbọ́n nítorí sùúrù rẹ̀ àti nítorí tí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé. Ṣùgbọ́n ọjọ́ Olúwa, bí ó ti wù kí ó pẹ́ tó, yóò dé dájúdájú àti lójijì, yóò dé bá àwọn ènìyàn bí olè ní òru (Matiu 24:43). Nígbà náà, gbogbo afẹ́fẹ́ àyíká pẹ̀lú èéfín omi rẹ̀ yóò kọjá lọ nípasẹ̀ iná, pẹ̀lú ariwo ńlá àti àwọn ìbúgbàù, àwọn èròjà tí a fi dá wọn ni a ó dáná sí, wọn yóò sì tú ká, gbogbo ìṣẹ̀dá tí a lè fọwọ́ kàn, pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ àdáyébá àti ti ọgbọ́n ènìyàn rẹ̀, ni a ó jó run pátápátá. Níwọ̀n bí gbogbo ohun ayé yóò ti tú ká, wọ́n ní ìdí tí ó lágbára jù lọ láti gbé ìgbésí ayé mímọ́ àti ìwà-bí-Ọlọ́run sí Ọlọ́run, ní fífẹ́ kí ọjọ́ Ọlọ́run dé dípò kí wọ́n máa bẹ̀rù rẹ̀, nígbà tí ètò ayé yìí yóò yọ́. Nítorí, nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Abrahamu àti irú-ọmọ rẹ̀ nípa ẹ̀mí (ará Romu 4:13–16; Isaiah 65:17–23; 66:22), wọ́n ní láti máa retí “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” (Ìfihàn 21:27; 22:14–15), ilé àìnípẹ̀kun àwọn ẹ̀mí alábùkún.
8 Ṣùgbọ́n, olùfẹ́, ẹ má ṣe gbàgbé ohun kan yìí, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa bí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún ni ó rí, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún bí ọjọ́ kan. 9 Olúwa kò fi ìlérí rẹ̀ jáfara, bí àwọn ẹlòmíràn ti ka ìjáfara sí; ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, bí kò ṣe kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.
10 Ṣùgbọ́n ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá bí olè ní òru; nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo ńlá, àti àwọn ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́, ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ó wà nínú rẹ̀ yóò sì jóná túútúú.
11 Ǹjẹ́ bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti yọ́ bẹ́ẹ̀, irú ènìyàn wo ni ẹ̀yin ìbá jẹ́ nínú ìwà mímọ́ gbogbo àti ìwà-bí-Ọlọ́run. 12 Kí ẹ máa retí, kí ẹ sì máa múra gírí de dídé ọjọ́ Ọlọ́run, nítorí èyí tí àwọn ọ̀run yóò gbiná, tí wọn yóò di yíyọ́, tí àwọn ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́. 13 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, àwa ń retí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé títún nínú èyí tí òdodo ń gbé.
Kí A Rí Yín ní Mímọ́ Nígbà Tí Kristi Bá Dé
Níwọ̀n bí a ti ṣèlérí ogún Kenaani ayérayé, ọ̀run tuntun àti ayé tuntun fún gbogbo Kristiani (Luku 20:35), Peteru rọ̀ wọ́n láti sapá gidigidi kí Kristi, Onídàájọ́ àwọn alààyè àti òkú, lè bá wọn ní mímọ́, láìlẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì wúlò nínú ìgbésí ayé wọn, tí wọ́n sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀. Kí wọ́n ka ìdádúró wíwá rẹ̀ sí ẹ̀rí ète rẹ̀ pé kí gbogbo ènìyàn rí ìgbàlà, gẹ́gẹ́ bí Paulu, nípasẹ̀ ìmísí Ọlọ́run, ti kọ sí wọn (ará Efesu 2:3, 4, 5; Kolosse 1:21; 1 àwọn tí Tẹsalonika 3:13; 4:14–18; 2 àwọn tí Tẹsalonika 1:7–10; Titu 2:13). Paulu tún kọ nípa àjíǹde àwọn òkú (1 ará Kọrinti 15:22; ará Filipi 3:20–21), fífi iná sun ayé (2 àwọn tí Tẹsalonika 1:8), ilẹ̀ ọ̀run níbi tí àwọn olódodo ń gbé (1 àwọn tí Tẹsalonika 4:17; ará Heberu 4:9; 12:14, 18, 24) àti ìdájọ́ gbogbo ènìyàn (ará Romu 14:10). Díẹ̀ lára àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣòro fún ènìyàn láti lóye, àwọn aláìkọ́ àti àwọn tí kò fìdí múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ sì ń yí wọn po, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe sí àwọn apá mìíràn nínú ìwé mímọ́, sí ìparun ara wọn, tí wọ́n sì ń ba ìwà àwọn ènìyàn jẹ́. Ṣùgbọ́n àwọn tí àwọn aposteli àti wòlíì ti kìlọ̀ fún ṣáájú nípa àwọn ẹ̀kọ́ èké wọ̀nyí gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún wọn, kí wọ́n máa dàgbà lójoojúmọ́ nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Jesu Kristi, kí wọ́n sì máa fi ògo fún un nísinsin yìí àti títí dé ọjọ́ ayérayé.
14 Nítorí náà, olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti ń retí irú nǹkan wọ̀nyí, ẹ múra gírí, kí a lè bá yín ní àlàáfíà ní àìlábàwọ́n, àti ní àìlábùkù lójú rẹ̀. 15 Kí ẹ sì máa kà á sí pé, sùúrù Olúwa wa ìgbàlà ni; bí Paulu pẹ̀lú arákùnrin wa olùfẹ́, ti kọ̀wé sí yín gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n tí a fi fún un. 16 Bí ó tí ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú nínú ìwé rẹ̀ gbogbo nínú èyí ti ohun mìíràn sọ̀rọ̀ láti yé ni gbé wà, èyí ti àwọn òpè àti àwọn aláìdúró níbìkan ń lo, bí wọ́n ti ń lo ìwé mímọ́ ìyókù, sí ìparun ara wọn.
17 Nítorí náà ẹ̀yin olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti mọ nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀, ẹ máa kíyèsára, kí a má ba à fi ìṣìnà àwọn ènìyàn búburú fà yín lọ, kí ẹ sì ṣubú kúrò ní ìdúró ṣinṣin yín. 18 Ṣùgbọ́n ẹ máa dàgbà nínú oore-ọ̀fẹ́ àti nínú ìmọ̀ Olúwa àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.
Ẹni tí ògo wà fún nísinsin yìí àti títí láé! Àmín.