Peka Pa Juda Run

741 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

2 Kronika 28:4–19

4 Ó sì rú ẹbọ, ó sì sun tùràrí ní ibi gíga wọ́n nì lórí òkè kékeré àti lábẹ́ gbogbo igi tútù.

5 Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fi lé ọba Siria lọ́wọ́. Àwọn ará Siria sì pa á run, wọ́n sì kó púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n sì kó wọn wá sí Damasku.

Ó sì tún fi lé ọwọ́ ọba Israẹli pẹ̀lú, ẹni tí ó kó wọn ní ìgbèkùn púpọ̀ tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa. 6 Ní ọjọ́ kan Peka, ọmọ Remaliah, pa ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àwọn ọmọ-ogun ní Juda nítorí Juda ti kọ Olúwa Ọlọ́run baba wọn sílẹ̀. 7 Sikri àti Efraimu alágbára sì pa Maaseiah ọmọ ọba, Aṣrikamu ìjòyè tí ó wà ní ìkáwọ́ ilé ọba, àti Elkana igbákejì ọba. 8 Àwọn ọmọ Israẹli sì kó ní ìgbèkùn lára àwọn arákùnrin wọn ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn aya wọn, àwọn ọmọkùnrin àti obìnrin wọn sì tún kó ọ̀pọ̀ ìkógun, èyí tí wọn kó padà lọ sí Samaria.

9 Ṣùgbọ́n wòlíì Olúwa tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Odedi wà níbẹ̀, ó sì jáde lọ láti lọ pàdé ogun nígbà tí ó padà sí Samaria. Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí Olúwa, Ọlọ́run baba yín bínú sí Juda ó sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin pa wọ́n ní ìpa oró tí ó de òkè ọ̀run. 10 Nísinsin yìí, ẹ̀yin ń pète láti mú ọkùnrin àti obìnrin Juda àti Jerusalẹmu ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú yín, ẹ̀yin kò ha jẹ̀bi Olúwa Ọlọ́run yín, àní ẹ̀yin? 11 Nísinsin yìí ẹ gbọ́ tèmi! Ẹ rán àwọn ìgbèkùn tí ẹ̀yin ti mú gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹ́wọ̀n padà nítorí ìbínú kíkan Olúwa ń bẹ lórí yín.”

12 Lẹ́yìn náà, díẹ̀ nínú àwọn olórí ní Efraimu, Asariah ọmọ Jehohanani, Berekiah ọmọ Meṣilemoti, Jehiskiah ọmọ Ṣallumu, àti Amasa ọmọ Hadlai, dìde sí àwọn tí o ti ogun náà bọ̀. 13 Wọn si wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n wá síbí,” “tàbí àwa ti jẹ̀bi níwájú Olúwa, ṣe ẹ̀yin ń gbèrò láti fi kún ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹ̀bi wa ni: nítorí tí ẹ̀bi wa ti tóbi púpọ̀, ìbínú rẹ̀ kíkan sì wà lórí Israẹli.”

14 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ológun tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti ìkógun sílẹ̀ níwájú àwọn ìjòyè àti gbogbo ìjọ ènìyàn. 15 Àwọn ọkùnrin tí a pè pẹ̀lú orúkọ náà sì dìde, wọn sì mú àwọn ìgbèkùn náà, wọ́n sì fi ìkógun náà wọ̀ gbogbo àwọn tí ó wà ní ìhòhò nínú wọn, wọ́n sì wọ̀ wọ́n ní aṣọ, wọ́n sì bọ̀ wọ́n ní bàtà, wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ àti ohun mímu, wọ́n sì fi òróró kùn wọ́n ní ara, wọ́n sì kó gbogbo àwọn tí ó jẹ́ aláìlera nínú wọ́n sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kó wọn padà sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Jeriko, ìlú ọ̀pẹ, wọ́n sì padà sí Samaria.

16 Ní àkókò ìgbà náà, ọba Ahasi ránṣẹ́ sí ọba Asiria fún ìrànlọ́wọ́. 17 Àwọn ará Edomu sì tún padà wá láti kọlu Juda kí wọn sì kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ. 18 Nígbà tí àwọn ará Filistini sì ti jagun ní ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n nì àti síhà gúúsù Juda. Wọ́n ṣẹ́gun wọ́n sì gba Beti-Ṣemeṣi, Aijaloni àti Gederoti, àti Soko, Timna, a ri Gimiso, pẹ̀lú ìletò wọn. 19 Olúwa sì rẹ Juda sílẹ̀ nítorí Ahasi ọba Israẹli, nítorí ó sọ Juda di aláìní ìrànlọ́wọ́, ó sì ṣe ìrékọjá gidigidi sí Olúwa.

Obadiah 1

1 Ìran ti Obadiah.

Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí nípa Edomu.

Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,

a sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo kèfèrí láti sọ pé,

“Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i.”

2 “Kíyèsi i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín àwọn kèfèrí;

ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀.

3 Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ,

ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta,

tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga,

ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé,

‘Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’

4 Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì,

bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárín àwọn ìràwọ̀,

láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,”

ni Olúwa wí.

5 “Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá,

bí àwọn ọlọ́ṣà ní òru,

Háà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́,

wọn kò ha jalè tó bí wọ́n ti fẹ́?

Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá,

wọn kò ha ni fi èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀?

6 Báwo ni a ṣe ṣe àwárí nǹkan Esau,

tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde.

7 Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹ

ti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ,

àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ;

àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́,

ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.”

8 Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà,

Èmi kì yóò ha pa àwọn ọlọ́gbọ́n Edomu run,

àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Esau?

9 A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, ìwọ Temani,

gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Esau

ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà.

10 Nítorí ìwà ipá sí Jakọbu arákùnrin rẹ,

ìtìjú yóò bò ọ,

a ó sì pa ọ run títí láé.

11 Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apá kan,

ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ,

tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ,

tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jerusalẹmu,

ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.

12 Ìwọ kì bá tí fi ojú kéré arákùnrin rẹ,

ní àkókò ìbànújẹ́ rẹ̀

ìwọ kì bá tí yọ̀ lórí àwọn ọmọ Juda,

ní ọjọ́ ìparun wọn

ìwọ kì bá tí gbéraga púpọ̀

ní ọjọ́ wàhálà wọn.

13 Ìwọ kì bá tí wọ inú ibodè àwọn ènìyàn mi lọ,

ní ọjọ́ àjálù wọn.

Ìwọ kì bá tí fojú kó wọn mọ́lẹ̀

nínú ìdààmú wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn.

Ìwọ kì bá tí jí ẹrù wọn kó,

ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn.

14 Ìwọ kì bá tí dúró ní ìkóríta ọ̀nà

láti ké àwọn tirẹ̀ tó ti sálà kúrò.

Ìwọ kì bá tí fa àwọn tó ṣẹ́kù nínú

wọn lélẹ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn.

15 “Nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ etílé

lórí gbogbo àwọn kèfèrí.

Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ìwọ náà;

ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ.

16 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀ ṣe mu lórí òkè mímọ́ mi,

bẹ́ẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò máa mu títí;

wọn yóò mu ún ní àmutẹ́rùn

wọn yóò sì wà bí ẹni pé wọn kò mu ún rí.

17 Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Sioni,

wọn yóò sì jẹ́ mímọ́,

àti ilé Jakọbu yóò sì ní ìní wọn.

18 Ilé Jakọbu yóò sì jẹ́ iná

àti ilé Josẹfu ọwọ́ iná

ilé Esau yóò jẹ àgékù koríko

wọn yóò fi iná sí i,

wọn yóò jo run.

Kì yóò sí ẹni tí yóò kù ní ilé Esau.”

Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

19 Àwọn ará gúúsù yóò ni òkè Esau,

àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò ni

ilẹ̀ àwọn ará Filistini ní ìní.

Wọn yóò sì ni oko Efraimu àti Samaria;

Benjamini yóò ní Gileadi ní ìní.

20 Àwọn ìgbèkùn Israẹli tí ó wà ní Kenaani

yóò ni ilẹ̀ títí dé Sarefati;

àwọn ìgbèkùn láti Jerusalẹmu tí ó wà ní Sefaredi

yóò ni àwọn ìlú gúúsù ní ìní.

21 Àwọn tó ń gba ni là yóò sì gòkè Sioni wá

láti jẹ ọba lé orí àwọn òkè Esau.

Ìjọba náà yóò sì jẹ́ ti Olúwa.

Isaiah 1:2–31

2 Gbọ́ ẹ̀yin ọ̀run! Fi etí sílẹ̀, ìwọ ayé!

Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀:

“Mo tọ́ àwọn ọmọ dàgbà,

ṣùgbọ́n wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.

3 Màlúù mọ olówó rẹ̀,

kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀,

ṣùgbọ́n Israẹli kò mọ̀,

òye kò yé àwọn ènìyàn mi.”

4 Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀,

àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù,

ìran àwọn aṣebi,

àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́!

Wọn ti kọ Olúwa sílẹ̀

wọn ti gan Ẹni Mímọ́ Israẹli,

wọn sì ti kẹ̀yìn sí i.

5 Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́?

Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe?

Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́,

gbogbo ọkàn yín sì ti pòruurù.

6 Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín dé àtàrí yín

kò sí àlàáfíà rárá,

àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapa

àti ojú egbò,

tí a kò nù kúrò tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró.

7 Orílẹ̀-èdè yín dahoro,

a dáná sun àwọn ìlú yín,

oko yín ni àwọn àjèjì ti jẹ run

lójú ara yín náà,

ni gbogbo rẹ̀ ṣòfò bí èyí tí

àwọn àjèjì borí rẹ̀.

8 Ọmọbìnrin Sioni ni a fi sílẹ̀

gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà,

gẹ́gẹ́ bí abà nínú oko ẹ̀gúnsí,

àti bí ìlú tí a dó tì.

9 Àyàfi bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun

bá ṣẹ́ díẹ̀ kù fún wà,

a ò bá ti rí bí Sodomu,

a ò bá sì ti dàbí Gomorra.

10 Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa,

ẹ̀yin aláṣẹ Sodomu,

tẹ́tí sí òfin Ọlọ́run wa,

ẹ̀yin ènìyàn Gomorra!

11 “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín

kín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi?” ni Olúwa wí.

“Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísun

ti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa,

Èmi kò ní inú dídùn

nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntàn àti ti òbúkọ.

12 Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi,

ta ni ó béèrè èyí lọ́wọ́ yín,

gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi?

13 Ẹ má mú ọrẹ asán wá mọ́!

Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi,

oṣù tuntun àti ọjọ́ ìsinmi àti àwọn àpéjọ,

Èmi kò lè faradà á, ẹ̀ṣẹ̀ ni àpéjọ yín wọ̀nyí.

14 Ayẹyẹ oṣù tuntun yín àti àjọ̀dún tí a yàn,

ni ọkàn mi kórìíra.

Wọ́n ti di àjàgà sí mi ní ọrùn,

Ó sú mi láti fi ara dà wọ́n.

15 Nígbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sókè ni àdúrà,

Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín,

kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà,

Èmi kò ni tẹ́tí sí i.

“Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.

16 “Wẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ara yín mọ́.

Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi!

Dáwọ́ àìṣedéédéé dúró,

17 kọ́ láti ṣe rere!

Wá ìdájọ́ òtítọ́,

tu àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú.

Ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,

gbà ẹjọ́ opó rò.

18 “Ẹ wá ní ìsinsin yìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàṣàrò,”

ni Olúwa wí.

“Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn,

wọn ó sì funfun bí i yìnyín,

bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀,

wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n òwú.

19 Tí ẹ̀yin bá fẹ́, tí ẹ sì gbọ́rọ̀,

ẹ̀yin yóò sì jẹ ojúlówó adùn ilẹ̀ náà.

20 Ṣùgbọ́n tí ẹ bá kọ̀ tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀,

idà ni a ó fi pa yín run.”

Nítorí ẹnu Olúwa la ti sọ ọ́.

21 Wo bí ìlú òtítọ́ ṣe di àgbèrè!

Ó ti kún fún ìdájọ́ òtítọ́ nígbà kan rí,

òdodo ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí,

ṣùgbọ́n báyìí àwọn apànìyàn!

22 Fàdákà rẹ ti di ìpẹ́pẹ́,

ààyò wáìnì rẹ la ti bu omi là.

23 Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín,

akẹgbẹ́ àwọn olè,

gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀

wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri.

Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,

ẹjọ́ opó kì í sì í dé iwájú wọn.

24 Nítorí náà ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,

alágbára kan ṣoṣo tí Israẹli sọ wí pé:

“Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá mi

n ó sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi.

25 Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ,

èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù,

n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.

26 Èmi yóò mú àwọn adájọ́ rẹ bọ̀ sí ipò gẹ́gẹ́ bí i ti àtijọ́,

àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ bí i ti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.

Lẹ́yìn náà ni a ó pè ọ ní ìlú òdodo, ìlú òtítọ́.”

27 A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Sioni padà,

àti àwọn tí ó ronúpìwàdà pẹ̀lú òdodo.

28 Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó parun.

Àwọn tí ó bá sì kọ Olúwa sílẹ̀ ni yóò ṣègbé.

29 “Ojú yóò tì yín nítorí igi óákù mímọ́

èyí tí ẹ ní inú dídùn sí,

a ó kàn yín lábùkù nítorí àwọn ọgbà yìí

tí ẹ ti yàn fúnra yín.

30 Ẹ ó sì dàbí igi óákù tí ewé rẹ̀ ti rọ,

bí ọgbà tí kò ní omi.

31 Alágbára ọkùnrin náà yóò sì dàbí ohun ìdáná,

iṣẹ́ rẹ̀ bí ẹ̀ṣẹ́-iná,

àwọn méjèèjì ni yóò jóná papọ̀,

láìsí ẹni tí yóò lè pa iná yìí.”