Ahasi Bá Tiglat-Pileseri Ṣe Àjọṣepọ̀

Ahasi bá Tiglat-Pileseri, ọba Asiria, ṣe àjọṣepọ̀.

740 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

2 Ọba 16:6–9

6 Ní àkókò náà, Resini ọba Siria gba Elati padà fún Siria, ó sì lé àwọn ènìyàn Juda kúrò ní Elati: àwọn ará Siria sì wá sí Elati, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.

7 Ahasi sì rán oníṣẹ́ sọ́dọ̀ Tiglat-Pileseri ọba Asiria wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni èmi, àti ọmọ rẹ; gòkè wá, kí o sì gbà mi lọ́wọ́ ọba Siria, àti lọ́wọ́ ọba Israẹli tí ó dìde sí mi.” 8 Ahasi sì mú fàdákà àti wúrà tí a rí ní ilé Olúwa, àti nínú ìṣúra ilé ọba, ó sì rán an sí ọba Asiria ní ọrẹ. 9 Ọba Asiria sì gbọ́ tirẹ̀: nítorí ọba Asiria gòkè wá sí Damasku, ó sì kó o, ó sì mú un ní ìgbèkùn lọ sí Kiri, ó sì pa Resini.

Isaiah 28

1 Ègbé ni fún adé ìgbéraga,

fún àwọn ọ̀mùtí Efraimu,

àti fún ìtànná rírọ, ẹwà ògo rẹ̀,

tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú

àti sí ìlú náà

ìgbéraga àwọn tí ọtí wáìnì ń pa tí a rẹ̀ sílẹ̀.

2 Kíyèsi i, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le, tí ó sì lágbára,

gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ yìnyín àti bí ìjì apanirun,

gẹ́gẹ́ bí àrọ̀dá òjò àti òjò tí ó mú ìkún omi wá,

òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀.

3 Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efraimu,

ni a ó fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

4 Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀,

tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú,

yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkórè

bí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ rẹ̀,

òun a sì mì ín.

5 Ní ọjọ́ náà Olúwa àwọn ọmọ-ogun

yóò jẹ́ adé tí ó lógo,

àti adé tí ó lẹ́wà

fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù.

6 Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo

fún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́ ìdájọ́

àti orísun agbára

fún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padà ní ẹnu ibodè.

7 Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí wáìnì

wọ́n pòòrì fún ọtí líle,

àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí líle

wọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnì

wọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí líle,

wọ́n ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran,

wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá.

8 Gbogbo orí tábìlì ni ó kún fún èébì

kò sì ṣí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin.

9 “Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́?

Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìròyìn in rẹ̀ fún?

Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú wọn,

sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú.

10 Nítorí tí í ṣe: báyìí ni orí,

ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe,

àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ;

díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn.”

11  Ó dára báyìí, pẹ̀lú ètè àjèjì àti ahọ́n àìmọ̀

Ọlọ́run yóò bá àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀

12  àwọn tí ó sọ fún wí pé,

“Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”;

àti pé, “Èyí ni ibi ìsinmi”;

ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sílẹ̀.

13 Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa sí wọn yóò di pé,

ṣe èyí, ṣe ìyẹn,

àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ;

díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn,

bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubú sẹ́yìn,

wọn yóò fi ara pa, wọn yóò bọ́ sínú okùn a ó sì gbá wọn mú.

14 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,

tí ń jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jerusalẹmu.

15 Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀,

pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn.

Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá,

kò le kàn wá lára,

nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o wa

àti àìṣòótọ́ ibi ìpamọ́ wa.”

16  Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:

“Kíyèsi i, èmi gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Sioni, òkúta tí a dánwò,

òkúta igun ilé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájú;

ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé

kì yóò ní ìfòyà.

17 Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òsùwọ̀n

àti òdodo òjé òsùwọ̀n;

yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́,

omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tí

ẹ ń fi ara pamọ́ sí mọ́lẹ̀.

18 Májẹ̀mú yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fa igi lé;

àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró.

Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá,

a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀.

19 Nígbàkígbà tí ó bá ti wá ni

yóò máa gbé ọ lọ,

ni àràárọ̀, ní ọ̀sán àti ní òru,

ni yóò máa fẹ́ kọjá lọ.”

Ìmòye ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yìí

yóò máa mú ìpayà ńlá wá.

20 Ibùsùn kúrú púpọ̀ fún ìnara lé lórí,

ìbora kò fẹ̀ tó láti yí ara yín ká.

21 Olúwa yóò dìde sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe

ní òkè Perasimu

yóò ru ara rẹ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe

ní àfonífojì Gibeoni—

láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, abàmì iṣẹ́ ẹ rẹ̀,

yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àní àjèjì iṣẹ́ rẹ̀.

22 Ní ìsinsin yìí ẹ dákẹ́ ẹlẹ́yà ṣíṣe,

bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìdè e yín yóò le sí i;

Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ fún mi

nípa àṣẹ ìparun ti ó ti pa lórí gbogbo ilẹ̀ náà.

23 Tẹ́tí kí o sì gbọ́ ohùn mi,

fi ara balẹ̀ kí o sì gbọ́ ohun tí mo sọ.

24 Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìn

yóò ha máa tulẹ̀ títí bi?

Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kí

ó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí?

25 Nígbà tí òun bá ti tẹ́ ojú ilẹ̀ rẹ̀ pẹrẹsẹ

òun kò ha ń fúnrúgbìn dílì

kí ó sì fúnrúgbìn kummini ká?

Kí ó sì gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ,

barle tí a yàn,

àti spelti ní ipò rẹ̀?

26 Ọlọ́run rẹ̀ tọ́ ọ ṣọ́nà

ó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tó tọ́.

27 Nítorí a kò fi ohun èlò ìpakà dili,

bẹ́ẹ̀ ni a kì í yí kẹ̀kẹ́ ẹrù kiri lórí kummini;

ṣùgbọ́n ọ̀pá ni a fi ń pa dili jáde,

ọ̀gọ ni a sì lu kummini.

28 A gbọdọ̀ lọ ìyẹ̀fun kí a tó ṣe àkàrà;

bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì í máa pa á lọ títí láé.

Bí ó tilẹ̀ yí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ìpakà a rẹ̀ lórí i rẹ̀,

àwọn ẹṣin rẹ̀ kò le lọ̀ ọ́.

29 Gbogbo èyí pẹ̀lú ti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wá,

oníyanu ní ìmọ̀ràn àti ológo ní ọgbọ́n.

2 Kronika 28:20–23

20 Tiglat-Pileseri ọba Asiria wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fún ní ìpọ́njú dípò ìrànlọ́wọ́. 21 Ahasi mú díẹ̀ nínú ìní ilé Olúwa àti láti ilé ọba àti láti ọ̀dọ̀ ọba ó sì fi wọ́n fún ọba Asiria: ṣùgbọ́n èyí kò ràn wọ́n lọ́wọ́.

22 Ní àkókò ìpọ́njú rẹ̀ ọba Ahasi sì di aláìṣòótọ́ sí Olúwa. 23 Ó sì rú ẹbọ sí òrìṣà àwọn Damasku, ẹni tí ó ṣẹ́gun wọn, nítorí ó rò wí pé, “Nítorí àwọn òrìṣà àwọn ọba Siria ti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọn kí ó bà lè ràn mí lọ́wọ́.” Ṣùgbọ́n àwọn ni ìparun rẹ̀ àti ti gbogbo Israẹli.

2 Ọba 16:10–18

10 Ọba sì lọ sí Damasku láti pàdé Tiglat-Pileseri, ọba Asiria, ó sì rí pẹpẹ kan tí ó wà ní Damasku: Ahasi ọba sì rán àwòrán pẹpẹ náà, àti àpẹẹrẹ rẹ̀ sí Uriah àlùfáà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo iṣẹ́ ọ̀nà rẹ̀. 11 Uriah àlùfáà sì kọ́ pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí Ahasi ọba fi ránṣẹ́ sí i láti Damasku; bẹ́ẹ̀ ni Uriah àlùfáà ṣe é dé ìpadàbọ̀ Ahasi ọba láti Damasku. 12 Nígbà tí ọba sì ti Damasku dé, ọba sì rí pẹpẹ náà: ọba sì súnmọ́ pẹpẹ náà, ó sì rú ẹbọ lórí rẹ̀. 13 Ó sì sun ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, o si ta ohun mímu rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà. 14 Ṣùgbọ́n ó mú pẹpẹ idẹ tí ó wà níwájú Olúwa kúrò láti iwájú ilé náà, láti àárín méjì pẹpẹ náà, àti ilé Olúwa, ó sì fi í sí apá àríwá pẹpẹ náà.

15 Ahasi ọba sì pàṣẹ fún Uriah àlùfáà, wí pé, “Lórí pẹpẹ ńlá náà ni kó o máa sun ẹbọ sísun òròwúrọ̀ àti ọrẹ-jíjẹ alaalẹ́, àti ẹbọ sísun ti ọba, àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun tí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọrẹ-jíjẹ wọn, àti ọrẹ ohun mímu wọn; kí o sì wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ sísun náà lórí rẹ̀, àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ mìíràn, ṣùgbọ́n ní ti pẹpẹ idẹ náà èmi ó máa gbèrò ohun tí èmi ó fi ṣe.” 16 Báyìí ni Uriah àlùfáà ṣe, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Ahasi ọba pàṣẹ.

17 Ahasi ọba sì gé igi-ìpílẹ̀ àwọn àgbédúró náà, ó ṣí agbada náà kúrò lára wọn; ó sì gbé agbada ńlá náà kalẹ̀ kúrò lára àwọn màlúù idẹ tí ń bẹ lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbé e ka ilẹ̀ tí a fi òkúta tẹ́. 18 Ibi ààbò fún ọjọ́ ìsinmi tí a kọ́ nínú ilé náà, àti ọ̀nà ìjáde sí òde ọba, ni ó yípadà kúrò ní ilé Olúwa nítorí ọba Asiria.

2 Kronika 28:24–25

24 Ahasi sì kó gbogbo ohun èlò láti ilé Olúwa jọ ó sì kó wọn lọ. Ó sì ti ìlẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tẹ́ pẹpẹ fún ara rẹ̀ ní gbogbo igun Jerusalẹmu. 25 Ní gbogbo ìlú Juda ó sì kọ́ ibi gíga láti sun ẹbọ fún àwọn ọlọ́run mìíràn. Kí ó sì mú Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn bínú.

Hosea 5

1 “Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà!

Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Israẹli!

Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba!

Ìdájọ́ yìí kàn yín.

Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní Mispa

àwọ̀n ti a nà sílẹ̀ lórí Tabori.

2 Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyàn

gbogbo wọn ni èmi ó bá wí,

3 mo mọ ohun gbogbo nípa Efraimu

Israẹli kò sì pamọ́ fún mi

Efraimu, ní báyìí ó ti ṣe àgbèrè

Israẹli sì ti díbàjẹ́.

4 “Ìṣe wọn kò gbà wọ́n láààyè

láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn.

Ẹ̀mí àgbèrè wà ni ọkàn wọn,

wọn kò sì mọ Olúwa.

5 Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí lé wọn;

àwọn ọmọ Israẹli, àti Efraimu pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Juda náà sì kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn.

6 Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹran

àti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa,

wọn kò ní rí i,

ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrín wọn.

7 Wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Olúwa

wọ́n sì bí àwọn àjèjì ọmọ.

Nísinsin yìí, ọdún oṣù tuntun wọn,

ni yóò pa wọn run pẹ̀lú ìpín wọn.

8 “Fọn fèrè ní Gibeah,

kí ẹ sì fun ìpè ní Rama.

Ẹ pariwo ogun ní Beti-Afeni;

máa wárìrì, ìwọ Benjamini.

9 Efraimu yóò di ahoro

ní ọjọ́ ìbáwí

láàrín àwọn ẹ̀yà Israẹli,

Mo sọ ohun tí ó dájú.

10 Àwọn olórí Juda dàbí àwọn tí í

máa yí òkúta ààlà kúrò.

Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé

wọn lórí bí ìkún omi.

11 A ni Efraimu lára,

a sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ìdájọ́,

nítorí pé, ó pinnu láti tẹ̀lé òrìṣà.

12 Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí Efraimu,

Mo sì dàbí ìdin ara Juda.

13 “Nígbà ti Efraimu ri àìsàn rẹ̀,

tí Juda sì rí ojú egbò rẹ̀

ni Efraimu bá tọ ará Asiria lọ,

ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́.

Ṣùgbọ́n kò le è wò ó sàn

bẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná.

14 Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Efraimu,

bí i kìnnìún ńlá sí ilé Juda.

Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ;

Èmi ó gbé wọn lọ, láìsí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.

15 Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mi

títí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀bi

wọn yóò sì wá ojú mi

nínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”