Ahasi Bá Tiglat-Pileseri Ṣe Àjọṣepọ̀ (continued)

Ahasi bá Tiglat-Pileseri, ọba Asiria, ṣe àjọṣepọ̀.

740 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Hosea 6

1 “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwa

ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ

ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá

Ó ti pa wá lára

ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.

2 Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí

ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò

kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀.

3 Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa;

ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n.

Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ,

yóò jáde;

yóò tọ̀ wá wá bí òjò,

bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”

4 “Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu?

Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda?

Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀

bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.

5 Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì,

Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi,

ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín.

6  Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;

àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.

7 Bí i Adamu, wọ́n da májẹ̀mú

wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀.

8 Gileadi jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburú

tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́.

9 Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùba de àwọn ènìyàn

bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀;

tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣekemu,

tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú.

10 Mo ti rí ohun tó ba ni lẹ́rù

ní ilé Israẹli.

Níbẹ̀ Efraimu, fi ara rẹ̀ fún àgbèrè

Israẹli sì di aláìmọ́.

11 “Àti fún ìwọ, Juda,

a ti yan ọjọ́ ìkórè rẹ.

“Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ohun ìní àwọn ènìyàn mi padà,

Ahasi Kú; A Sọtẹ́lẹ̀ Agbára Hesekiah 726 ṣáájú ìbí Kristi

Ikú Ahasi, àti àsọtẹ́lẹ̀ nípa agbára Hesekiah.

2 Kronika 28:26–27

26 Ìyókù iṣẹ́ ìjọba rẹ̀ àti gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Juda àti ti Israẹli. 27  Ahasi sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Jerusalẹmu ṣùgbọ́n wọn kò mú un wá sínú àwọn isà òkú àwọn ọba Israẹli. Hesekiah ọmọ rẹ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Isaiah 14:28–32

28 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Ahasi kú.

29  Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia,

pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá;

láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀

yóò ti hù jáde,

èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni.

30 Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko,

àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu.

Ṣùgbọ́n gbòǹgbò o rẹ̀ ni èmi ó fi ìyàn parun,

yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò.

31 Hu, ìwọ ẹnu-ọ̀nà! Kígbe, ìwọ ìlú!

Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Filistia!

Èéfín kurukuru kan ti àríwá wá,

kò sì ṣí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn.

32 Kí ni ìdáhùn tí a ó fún

agbẹnusọ orílẹ̀-èdè náà?

“Olúwa ti fi ìdí Sioni kalẹ̀,

àti nínú rẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ̀ tí

a ti pọ́n ọn lójú yóò ti rí ààbò o wọn.”

2 Kronika 28:1–3

1  Ahasi sì jẹ́ ẹni ogún ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìndínlógún. Gẹ́gẹ́ bí i Dafidi baba rẹ̀ kò sì ṣe ohun rere ní ojú Olúwa. 2 Ó sì rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli ó sì ṣe ère dídá fún ìsìn Baali 3 Ó sì sun ẹbọ ní àfonífojì Hinnomu, ó sì sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná, gẹ́gẹ́ bí ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli

2 Ọba 16:19–20

19 Àti ìyókù ìṣe Ahasi tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda? 20  Ahasi sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi: Hesekiah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Ìjọba Israẹli 739 ṣáájú ìbí Kristi

Ìjọba Peka àti Hosea

2 Ọba 15:30–31

30 Nígbà náà, Hosea ọmọ Ela, dìtẹ̀ sí Peka ọmọ Remaliah. Ó dojúkọ ọ́, ó sì pa á, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba ní ogún ọdún Jotamu ọmọ Ussiah.

31 Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Peka, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli?

2 Ọba 17:1–2

1 Ní ọdún kejìlá ọba Ahasi ará Juda, Hosea ọmọ Ela jẹ ọba Israẹli ní Samaria, ó sì jẹ fún ọdún mẹ́sàn-án. 2 Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i ti ọba Israẹli ẹni tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀.