Joẹli Sọtẹ́lẹ̀ Ìṣubú Juda (continued)

Nígbà tí Ussiah ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ pọ̀ sí i, Joẹli sọtẹ́lẹ̀ pé ẹgbẹ́ ọmọ ogun àjèjì kan yóò bì ìjọba Juda ṣubú lọ́jọ́ kan.

ní nǹkan bí 787 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Joẹli 2–3

1 Ẹ fun ìpè ní Sioni,

ẹ sì fún ìpè ìdágìrì ní òkè mímọ́ mi.

Jẹ́ kí àwọn ará ilẹ̀ náà wárìrì,

nítorí tí ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá,

nítorí ó kù sí dẹ̀dẹ̀.

2 Ọjọ́ òkùnkùn àti ìrọ́kẹ̀kẹ̀,

ọjọ́ ìkùùkuu àti òkùnkùn biribiri.

Bí ọyẹ́ òwúrọ̀ ti í la bo orí àwọn òkè ńlá:

àwọn ènìyàn ńlá àti alágbára; ya dé,

ti kó ti ì sí irú rẹ̀ rí,

bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kì yóò sí mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, títí dé ọdún ìran dé ìran.

3 Iná ń jó níwájú wọ́n;

ọwọ́ iná sì ń jó lẹ́yìn wọn.

Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edeni níwájú wọn,

àti lẹ́yìn wọn bí ahoro ijù;

nítòótọ́, kò sì sí ohun tí yóò bọ́ lọ́wọ́ wọn.

4  Ìrí wọn dàbí ìrí àwọn ẹṣin;

wọ́n ń sáré lọ bí àwọn ẹlẹ́ṣin ogun.

5 Bí ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ni

wọn ń fo ní orí òkè

bí ariwo ọ̀wọ́-iná tí ń jó koríko gbígbẹ,

bí akọni ènìyàn tí a kójọ fún ogun.

6 Ní ojú wọn, àwọn ènìyàn yóò jẹ ìrora púpọ̀:

gbogbo ojú ní yóò ṣú dudu.

7 Wọn yóò sáré bi àwọn alágbára;

wọn yóò gùn odi bí ọkùnrin ológun;

olúkúlùkù wọn yóò sì rìn lọ ní ọ̀nà rẹ̀,

wọn kì yóò sì yà kúrò ni ọ̀nà wọn.

8 Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò kọlu ẹnìkejì rẹ̀;

olúkúlùkù wọn yóò rìn ní ọ̀nà rẹ̀,

nígbà tí wọn bá sì ṣubú lù idà

wọn kì yóò gbọgbẹ́.

9 Wọn yóò sáré síwá sẹ́yìn ní ìlú;

wọn yóò súré lórí odi,

wọn yóò gùn orí ilé;

wọn yóò gbà ojú fèrèsé wọ̀ inú ilé bí olè.

10  Ayé yóò mì níwájú wọn;

àwọn ọ̀run yóò wárìrì;

oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn,

àwọn ìràwọ̀ yóò sì fà ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn.

11 Olúwa yóò sì bú ramúramù

jáde níwájú ogun rẹ̀:

nítorí ibùdó rẹ̀ tóbi gidigidi;

nítorí alágbára ní òun, tí n mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;

nítorí ọjọ́ Olúwa tóbi ó sì ní ẹ̀rù gidigidi;

ara ta ni ó lè gbà á?

12 “Ǹjẹ́ nítorí náà nísinsin yìí,” ni Olúwa wí,

“Ẹ fi gbogbo ọkàn yín yípadà sí mi,

àti pẹ̀lú àwẹ̀, àti pẹ̀lú ẹkún, àti pẹ̀lú ọ̀fọ̀.”

13 Ẹ sì fa ọkàn yín ya,

kì í sì í ṣe aṣọ yín,

ẹ sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run yín,

nítorí tí o pọ̀ ní oore-ọ̀fẹ́,

ó sì kún fun àánú, ó lọ́ra láti bínú,

ó sì ṣeun púpọ̀, ó sì ronúpìwàdà láti ṣe búburú.

14 Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà, kí o sì ronúpìwàdà,

kí ó sì fi ìbùkún sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀—

àní ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu

fún Olúwa Ọlọ́run yín?

15 Ẹ fún ìpè ní Sioni,

ẹ ya àwẹ̀ kan sí mímọ́,

ẹ pe àjọ tí ó ni ìrònú.

16 Ẹ kó àwọn ènìyàn jọ,

ẹ ya ìjọ sí mímọ́;

ẹ pe àwọn àgbàgbà jọ,

ẹ kó àwọn ọmọdé jọ,

àti àwọn tí ń mú ọmú,

jẹ kí ọkọ ìyàwó kúrò nínú ìyẹ̀wù rẹ̀.

Kí ìyàwó sì kúrò nínú iyàrá rẹ̀.

17 Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa,

sọkún láàrín ìloro àti pẹpẹ.

Sí jẹ́ kí wọn wí pé, “Dá àwọn ènìyàn rẹ sí, Olúwa.

Má sì ṣe fi ìní rẹ fun ẹ̀gàn,

tí yóò sì di òwe ní àárín àwọn kèfèrí.

Èéṣe tí wọn yóò fi wí láàrín àwọn ènìyàn pé,

‘Ọlọ́run wọn ha da?’ ”

18 Nígbà náà ní Olúwa yóò jowú fún ilẹ̀ rẹ̀,

yóò sì káàánú fún ènìyàn rẹ̀.

19 Nítòótọ́, Olúwa yóò dá wọn lóhùn, yóò sì wí fun àwọn ènìyàn rẹ̀ pé:

“Wò ó èmi yóò rán ọkà, àti ọtí wáìnì tuntun, àti òróró sí i yín,

a ó sì fi wọn tẹ́ yín lọ́rùn;

Èmi kì yóò sì fi yín ṣe ẹ̀gàn mọ́

láàrín àwọn aláìkọlà.

20 “Ṣùgbọ́n èmi yóò lé ogun àríwá jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ yín,

èmi yóò sì lé e lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣá, tí ó sì di ahoro,

pẹ̀lú ojú rẹ̀ sí Òkun ìlà-oòrùn,

àti ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìwọ̀-oòrùn Òkun.

Òórùn rẹ̀ yóò sì gòkè,

òórùn búburú rẹ̀ yóò sì gòkè.”

Nítòótọ́ ó ti ṣe ohun ńlá.

21 Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀;

jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn kí o sì yọ̀,

nítorí Olúwa ti ṣe ohun ńlá.

22 Ẹ má bẹ̀rù, ẹranko igbó,

nítorí pápá oko aginjù ń rú.

Nítorí igi ń so èso rẹ̀,

igi ọ̀pọ̀tọ́ àti àjàrà ń so èso ọ̀rọ̀ wọn.

23 Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Sioni,

ẹ sì yọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run yín,

nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́,

Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín,

àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní.

24 Àwọn ilẹ̀ ìpakà yóò kún fún ọkà;

àti ọpọ́n wọn nì yóò sàn jáde

pẹ̀lú ọtí wáìnì tuntun àti òróró.

25 “Èmi yóò sì mú ọdún wọ̀nyí ti eṣú jẹ run padà fún un yín.

Èyí tí eṣú agénijẹ àti eṣú jewéjewé

ọwọ́ eṣú agénijẹ àti kòkòrò ajẹnirun mìíràn ti fi jẹ

àwọn ogun ńlá mi tí mo rán sí àárín yín.

26 Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, títí ẹ̀yin yóò fi yó

ẹ ó sì yín orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín,

ẹni tí ó fi ìyanu bá yín lò;

ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi láéláé.

27 Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, èmi wà láàrín Israẹli,

àti pé; Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín,

àti pé kò sí ẹlòmíràn,

ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mí láéláé.

28  “Yóò sì ṣe níkẹyìn ọjọ́,

èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí sí ara ènìyàn gbogbo;

àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀,

àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá,

àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò máa ríran.

29 Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin,

àti sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin,

ní èmi yóò tú ẹ̀mí mí jáde ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì.

30 Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn ní ọrun

àti ní ayé,

ẹ̀jẹ̀ àti iná, àti ọ̀wọ́n èéfín.

31  A á sọ oòrùn di òkùnkùn,

àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀,

kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ẹ̀rù Olúwa tó dé.

32  Yóò sí ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pè

orúkọ Olúwa ní a ó gbàlà,

nítorí ní òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu

ní ìgbàlà yóò gbé wà,

bí Olúwa ti wí,

àti nínú àwọn

ìyókù tí Olúwa yóò pè.

3:1 “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti ní àkókò náà,

nígbà tí èmi tún mú ìgbèkùn Juda àti Jerusalẹmu padà bọ̀.

2 Èmi yóò kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ

pẹ̀lú èmi yóò sì mú wọn wá sí àfonífojì Jehoṣafati.

Èmi yóò sì bá wọn wíjọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi,

àti nítorí Israẹli ìní mi,

tí wọ́n fọ́nká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè,

wọ́n sì pín ilẹ̀ mi.

3 Wọ́n si ti di ìbò fún àwọn ènìyàn mi;

wọ́n sì ti fi ọmọdékùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan,

wọ́n sì ta ọmọdébìnrin kan fún ọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu.

4  “Nísinsin yìí, kí ni ẹ̀yin ní fi mí ṣe Tire àti Sidoni, àti gbogbo ẹ̀yin ẹkún Filistia? Ẹ̀yin yóò ha sàn ẹ̀san fún mi? Bí ẹ̀yin bá sì san ẹ̀san fún mi, ní kánkán àti ní kíákíá ní èmi yóò san ẹ̀san ohun ti ẹ̀yin ṣe padà sórí ara yín. 5 Nítorí tí ẹ̀yin tí mú fàdákà mi àti wúrà mi, ẹ̀yin si tí mú ohun rere dáradára mi lọ sínú tẹmpili yín. 6 Àti àwọn ọmọ Juda, àti àwọn ọmọ Jerusalẹmu ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ará Giriki, kí ẹ̀yin bá à lè sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìní wọn.

7 “Kíyèsi í, èmi yóò gbé wọ́n dìde kúrò níbi tì ẹ̀yin ti tà wọ́n sí, èmi yóò sì san ẹ̀san ohun ti ẹ ṣe padà sórí ara yín. 8 Èmi yóò si tà àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Juda, wọ́n yóò sì tà wọ́n fún àwọn ara Sabeani, fún orílẹ̀-èdè kan tí ó jìnnà réré.” Nítorí Olúwa ní o ti sọ ọ.

9 Ẹ kéde èyí ní àárín àwọn kèfèrí;

ẹ dira ogun,

ẹ jí àwọn alágbára.

Jẹ kí àwọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun.

10  Ẹ fi irin ìtulẹ̀ yín rọ idà,

àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀.

Jẹ́ kí aláìlera wí pé,

“Ara mi le koko.”

11 Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin kèfèrí láti gbogbo àyíká,

kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri.

Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ sọ̀kalẹ̀, Olúwa.

12 “Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí àfonífojì

Jehoṣafati ẹ̀yin kèfèrí:

nítorí níbẹ̀ ní èmi yóò jókòó láti ṣe

ìdájọ́ àwọn kèfèrí yí káàkiri.

13 Ẹ tẹ dòjé bọ̀ ọ́,

nítorí ìkórè pọ́n.

Ẹ wá, ẹ sọ̀kalẹ̀,

nítorí ìfúntí kún,

nítorí àwọn ọpọ́n kún àkúnwọ́sílẹ̀,

nítorí ìwà búburú wọn pọ̀!”

14 Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀

ní àfonífojì ìpinnu!

Nítorí ọjọ́ Olúwa kù si dẹ̀dẹ̀

ní àfonífojì ìdájọ́.

15 Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn,

àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́.

16 Olúwa yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá,

yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá;

àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì.

Ṣùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀,

àti agbára àwọn ọmọ Israẹli.

17 “Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín,

tí ń gbé Sioni òkè mímọ́ mi.

Ìgbà náà ni Jerusalẹmu yóò jẹ́ mímọ́;

àwọn àjèjì kì yóò sì kó o mọ́.

18 “Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀,

àwọn òkè kéékèèké yóò máa sàn fún wàrà;

gbogbo odò Juda tí ó gbẹ́ yóò máa sàn fún omi.

Orísun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ilé Olúwa wá,

yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣittimu.

19 Ṣùgbọ́n Ejibiti yóò di ahoro,

Edomu yóò sì di aṣálẹ̀ ahoro,

nítorí ìwà ipá tí a hù sì àwọn ọmọ Juda,

ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.

20 Ṣùgbọ́n Juda yóò jẹ́ ibùgbé títí láé,

àti Jerusalẹmu láti ìran dé ìran.

21 Nítorí èmi yóò wẹ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn nù, tí èmi kò tí ì wẹ̀nù.

Nítorí Olúwa ń gbé Sioni.”