A Fi Ẹ̀tẹ̀ Kọlu Ussiah

787 tàbí 765 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

2 Kronika 26:16–21

16 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí Ussiah jẹ́ alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ sì gbé e ṣubú. Ó sì di aláìṣòótọ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì wọ ilé Olúwa láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí. 17 Asariah àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọgọ́rin alágbára àlùfáà Olúwa mìíràn sì tẹ̀lé e. 18 Wọ́n sì takò ọba Ussiah, wọn sì wí pé, “Kò dára fún ọ, Ussiah, láti sun tùràrí sí Olúwa. Èyí fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Aaroni, ẹni tí ó ti yà sí mímọ́ láti sun tùràrí. Fi ibi mímọ́ sílẹ̀, nítorí tí ìwọ ti jẹ́ aláìṣòótọ́, ìwọ kò sì ní jẹ́ ẹni ọlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run.”

19 Ussiah, ẹni tí ó ní àwo tùràrí ní ọwọ́ rẹ̀ tó ṣetán láti sun tùràrí sì bínú. Nígbà tí ó sì ń bínú sí àwọn àlùfáà níwájú wọn, níwájú pẹpẹ tùràrí ní ilé Olúwa, ẹ̀tẹ̀ sì yọ jáde ní iwájú orí rẹ̀. 20  Nígbà tí Asariah olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn àlùfáà yòókù sì wò ó, wọ́n sì rí i wí pé ó ní ẹ̀tẹ̀ níwájú orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì sáré gbé e jáde pẹ̀lúpẹ̀lú, òun tìkára rẹ̀ ti fẹ́ láti jáde, nítorí tí Olúwa ti kọlù ú.

21 Ọba Ussiah sì ní ẹ̀tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Ó sì gbé ní ilé àwọn adẹ́tẹ̀, a sì ké e kúrò ní ilé Olúwa. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.

A Yan Isaiah sí Ipò Wòlíì 758 ṣáájú ìbí Kristi

Isaiah 1:1

1 Ìran sí Juda àti Jerusalẹmu èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí ní àsìkò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah àwọn ọba Juda.

Isaiah 6

1 Ní ọdún tí ọba Ussiah kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ìṣẹ́tí aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. 2 Àwọn Serafu wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò. 3  Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé,

“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun

gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”

4  Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹmpili sì kún fún èéfín.

5 Mo kígbe pé, “Ègbé ni fún mi! Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ.

6 Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn Serafu wọ̀nyí fò wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀yín iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú ní orí pẹpẹ. 7 Èyí ni ó fi kàn mí ní ẹnu tí ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ti kan ètè rẹ; a ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù.”

8 Nígbà náà ni mo sì gbọ́ ohùn Olúwa wí pé, “Ta ni èmi yóò rán? Ta ni yóò sì lọ fún wa?”

Nígbà náà ni èmi sì wí pé, “Èmi nìyí, rán mi!”

9  Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé,

“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;

ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’

10 Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì,

mú kí etí wọn kí ó wúwo,

kí o sì dìwọ́n ní ojú.

Kí wọn kí ó má ba fi ojú wọn ríran,

kí wọn kí ó má ba fi etí wọn gbọ́rọ̀,

kí òye kí ó má ba yé ọkàn wọn,

kí wọn kí ó má ba yípadà

kí a má ba mú wọn ní ara dá.”

11 Nígbà náà ni mo wí pé, “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó Olúwa?”

Òun sì dáhùn pé:

“Títí àwọn ìlú ńlá yóò fi dahoro,

láìsí olùgbé nínú rẹ̀ mọ́,

títí tí àwọn ilé yóò fi wà láìsí ènìyàn,

títí tí ilẹ̀ yóò fi dahoro pátápátá.

12 Títí tí Olúwa yóò fi rán gbogbo wọn jìnnà réré

tí ilẹ̀ náà sì di ìkọ̀sílẹ̀ pátápátá.

13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá ṣẹ́kù lórí ilẹ̀ náà,

yóò sì tún pàpà padà di rírun.

Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí igi tẹrẹbinti àti igi óákù,

ti í fi kùkùté sílẹ̀ nígbà tí a bá gé wọn lulẹ̀,

bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni irúgbìn mímọ́ náà yóò di kùkùté ní ilẹ̀ náà.”

Isaiah 2

1 Èyí ni ohun tí Isaiah ọmọ Amosi rí nípa Juda àti Jerusalẹmu.

2  Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́

òkè tẹmpili Olúwa ni a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀

gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè,

a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ,

gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì máa sàn sínú un rẹ̀.

3 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn yóò sì wí pé,

“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa,

àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu.

Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,

kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.”

Òfin yóò jáde láti Sioni wá,

àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.

4 Òun ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,

yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.

Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀,

wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé.

Orílẹ̀-èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀-èdè mọ́,

bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.

5 Wá, ẹ̀yìn ará ilé e Jakọbu,

ẹ jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Olúwa.

6 Ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,

ìwọ ilé Jakọbu.

Wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí ó ti ìlà-oòrùn wá,

wọ́n ń wo iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Filistini,

wọ́n ń pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà.

7 Ilẹ̀ wọn kún fún fàdákà àti wúrà,

ìṣúra wọn kò sì ní òpin.

Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin,

kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin.

8 Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère,

wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn,

èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tìkára wọn ti ṣe.

9 Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀

ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀,

má ṣe dáríjì wọ́n.

10 Wọ inú àpáta lọ,

fi ara pamọ́ nínú erùpẹ̀

kúrò nínú ìpayà Olúwa,

àti ògo ọláńlá rẹ̀!

11 Ojú agbéraga ènìyàn ni a ó rẹ̀ sílẹ̀

a ó sì tẹrí ìgbéraga ènìyàn ba,

Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà.

12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan ní ìpamọ́

fún gbogbo agbéraga àti ọlọ́kàn gíga

nítorí gbogbo àwọn tí a gbéga (ni a ó rẹ̀ sílẹ̀),

13 nítorí gbogbo igi kedari Lebanoni, tó ga tó rìpó

àti gbogbo óákù Baṣani,

14 nítorí gbogbo òkè gíga ńlá ńlá

àti àwọn òkè kéékèèké,

15 fún ilé ìṣọ́ gíga gíga

àti àwọn odi ìdáàbòbò,

16 fún gbogbo ọkọ̀ àwọn oníṣòwò

àwọn ọkọ̀ tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.

17 Ìgbéraga ènìyàn ni a ó tẹ̀ lórí ba

a ó sì rẹ ìgbéraga ènìyàn sílẹ̀,

Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà,

18 gbogbo ère òrìṣà yóò pòórá.

19 Àwọn ènìyàn yóò sálọ sínú ihò àpáta

àti sínú ihò ilẹ̀

kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa

àti ògo ọláńlá rẹ̀,

nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.

20 Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò máa sọ

àwọn ère fàdákà àti ère wúrà

tí wọ́n ti yá fún bíbọ

sí èkúté àti àwọn àdán.

21 Wọn yóò sálọ sínú ihò ìsàlẹ̀ àpáta

àti sínú ihò pàlàpálá àpáta

kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa

àti ògo ọláńlá rẹ̀,

nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.

22 Dẹ́kun à ń gba ènìyàn gbọ́,

èémí ẹni tó wà ní ihò imú rẹ̀.

Nítorí nínú kín ni a lè kà á sí?