Apá 10: Ìjọba Ussiah
Ìjọba Juda
Ìbẹ̀rẹ̀ Ìjọba Ussiah àti Aásìkí Rẹ̀
810 ṣáájú ìbí Kristi
Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)
1 Nígbà náà gbogbo ènìyàn Juda mú Ussiah, ẹni tí ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún wọ́n sì fi jẹ ọba ní ipò baba rẹ̀ Amasiah. 2 Òun ni ẹni náà tí ó tún Elati kọ́, ó sì mú padà sí Juda lẹ́yìn ìgbà tí Amasiah ọba ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀.
3 Ussiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìléláàádọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jekoliah; ó sì wá láti Jerusalẹmu. 4 Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bi baba rẹ̀ Amasiah ti ṣe.
1 Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n tí Jeroboamu ọba Israẹli, Asariah ọmọ Amasiah ọba Juda sì bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba.
5 Ó sì wá Olúwa ní ọjọ́ Sekariah, ẹni tí ó ní òye nínú ìran Ọlọ́run. Níwọ́n ọjọ́ tí ó wá ojú Olúwa, Ọlọ́run fún un ní ohun rere.
6 Ó sì lọ sí ogun pẹ̀lú Filistini ó sì wó odi Gati lulẹ̀, Jabne àti Aṣdodu. Ó sì kó ìlú rẹ̀ tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ Aṣdodu àti níbìkan láàrín àwọn ará Filistini. 7 Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́ lórí àwọn ará Filistini àti Arabia tí ń gbé ní Gur-baali àti lórí àwọn ará Mehuni. 8 Àwọn ará Ammoni gbé ẹ̀bùn wá fún Ussiah, orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri títí ó fi dé àtiwọ Ejibiti, nítorí ó ti di alágbára ńlá.
9 Ussiah sì kọ́ ilé ìṣọ́ ní Jerusalẹmu níbi ẹnu-bodè igun, àti níbi ẹnu-bodè àfonífojì àti níbi ìṣẹ́po odi ó sì mú wọn le 10 Ó sì tún ilé ìṣọ́ aginjù kọ́, ó sì gbẹ́ kànga púpọ̀, nítorí ó ni ẹran ọ̀sìn púpọ̀ ní ilẹ̀ ìsàlẹ̀ àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó sì ní àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ ní pápá àti ọgbà àjàrà ní orí òkè ní ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn àgbẹ̀ ṣíṣe.
11 Ussiah sì ní àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n kọ́ dáradára, wọ́n múra tán láti lọ pẹ̀lú ẹgbẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iye kíkà wọn gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ Jeieli akọ̀wé àti Maaseiah ìjòyè lábẹ́ ọwọ́ Hananiah, ọ̀kan lára àwọn olórí ogun ọba. 12 Àpapọ̀ iye olórí àwọn alágbára akọni ogun jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá (2,600). 13 Lábẹ́ olórí àti olùdarí wọn, wọ́n sì jẹ́ alágbára akọni ogun ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (307,500), tí ó ti múra fún ogun ńlá náà, àti alágbára ńlá jagunjagun kan láti ran ọba lọ́wọ́ sí ọ̀tá rẹ̀. 14 Ussiah sì pèsè ọ̀kọ̀, asà, akọ́rọ́, àti ohun èlò ìhámọ́ra ọrun títí dé òkúta kànnàkànnà fún ọwọ́ àwọn ọmọ-ogun. 15 Ní Jerusalẹmu ó sì ṣe ohun ẹ̀rọ ìjagun, iṣẹ́ ọwọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn, láti wà lórí ilé ìṣọ́ àti lórí igun odi láti fi tafà àti láti fi sọ òkúta ńlá. Orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri, nítorí a ṣe ìrànlọ́wọ́ ìyanu fún un títí ó fi di alágbára.
Joẹli Sọtẹ́lẹ̀ Ìṣubú Juda ní nǹkan bí 787 ṣáájú ìbí Kristi
Nígbà tí Ussiah ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ pọ̀ sí i, Joẹli sọtẹ́lẹ̀ pé ẹgbẹ́ ọmọ ogun àjèjì kan yóò bì ìjọba Juda ṣubú lọ́jọ́ kan.
1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Joẹli ọmọ Petueli wá.
2 Ẹ gbọ́ èyí ẹ̀yin àgbàgbà;
ẹ fi etí sílẹ̀ gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ará ilẹ̀ náà.
Ǹjẹ́ irú èyí ha wà ní ọjọ́ yín,
tàbí ní ọjọ́ àwọn baba yín?
3 Ẹ sọ ọ́ fún àwọn ọmọ yín,
ki àwọn ọmọ yín sọ fún àwọn ọmọ wọn,
ki àwọn ọmọ wọn sọ fún àwọn ìran mìíràn.
4 Èyí tí eṣú tí agénijẹ jẹ kù
ní ọ̀wọ́ eṣú ńlá ńlá ti jẹ,
èyí tí ọ̀wọ́ eṣú ńlá ńlá jẹ kù
ní eṣú kéékèèké jẹ,
èyí tí eṣú kéékèèké jẹ kù
ni eṣú apanirun mìíràn jẹ.
5 Ẹ jí gbogbo ẹ̀yin ọ̀mùtí kí ẹ sì sọkún
ẹ hu gbogbo ẹ̀yin ọ̀mu-wáìnì;
ẹ hu nítorí wáìnì tuntun
nítorí a gbà á kúrò lẹ́nu yín.
6 Nítorí orílẹ̀-èdè kan ti ṣígun sí ilẹ̀ mìíràn
ó ní agbára púpọ̀, kò sì ní òǹkà;
ó ní eyín kìnnìún
ó sì ní èrìgì abo kìnnìún.
7 Ó ti pa àjàrà mi run,
ó sì ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi kúrò,
ó ti bò èèpo rẹ̀ jálẹ̀, ó sì sọ ọ́ nù;
àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ni a sì sọ di funfun.
8 Ẹ pohùnréré ẹkún bí wúńdíá
tí a fi aṣọ ọ̀fọ̀ dí ni àmùrè, nítorí ọkọ ìgbà èwe rẹ̀.
9 A ké ọrẹ jíjẹ́ àti ọrẹ mímu
kúrò ní ilé Olúwa.
Àwọn àlùfáà ń ṣọ̀fọ̀,
àwọn ìránṣẹ́ Olúwa.
10 Oko di ìgboro, ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀,
nítorí a fi ọkà ṣòfò:
ọtí wáìnì tuntun gbẹ, òróró ń bùṣe.
11 Kí ojú kí ó tì yín, ẹ̀yin àgbẹ̀;
ẹ pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùtọ́jú àjàrà,
nítorí alikama àti nítorí ọkà barle;
nítorí ìkórè oko ṣègbé.
12 Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù;
igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú,
àti igi apiili, gbogbo igi igbó ni o rọ.
Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
13 Ẹ di ara yín ni àmùrè,
sí pohùnréré ẹkún ẹ̀yin àlùfáà:
ẹ pohùnréré ẹkún, ẹ̀yin ìránṣẹ́ pẹpẹ:
ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀,
ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi, nítorí tí a dá ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ
mímu dúró ní ilé Ọlọ́run yín.
14 Ẹ yà àwẹ̀ kan sí mímọ́,
ẹ pe àjọ kan tí o ní ìrònú,
ẹ pe àwọn àgbàgbà,
àti gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà
jọ sí ilé Olúwa Ọlọ́run yín,
kí ẹ sí ké pe Olúwa.
15 A! Fún ọjọ́ náà,
nítorí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀,
yóò de bí ìparun láti ọwọ́ Olódùmarè.
16 A kò ha ké oúnjẹ kúrò níwájú
ojú wá yìí,
ayọ̀ àti inú dídùn kúrò nínú ilé
Ọlọ́run wá?
17 Irúgbìn bàjẹ́ nínú ebè wọn,
a sọ àká di ahoro, a wó àká palẹ̀;
nítorí tí a mú ọkà rọ.
18 Àwọn ẹranko tí ń kérora tó!
Àwọn agbo ẹran dààmú,
nítorí tí wọ́n kò ni pápá oko;
nítòótọ́, àwọn agbo àgùntàn jìyà.
19 Olúwa, sí ọ ni èmi o ké pè,
nítorí iná tí run pápá oko tútù aginjù,
ọwọ́ iná sí ti jó gbogbo igi igbó.
20 Àwọn ẹranko igbó gbé ojú sókè sí ọ pẹ̀lú,
nítorí tí àwọn ìṣàn omi gbẹ,
iná sí ti jó àwọn pápá oko aginjù run.