A Ya Tẹmpili Kejì sí Mímọ́

515 ṣáájú ìbí Kristi

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ (OYCB)

Esra 6:14–22

14 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbàgbà Júù tẹ̀síwájú wọ́n sì ń gbèrú sí i lábẹ́ ìwàásù wòlíì Hagai àti wòlíì Sekariah, ìran Iddo. Wọ́n parí kíkọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run Israẹli àti àwọn àṣẹ Kirusi, Dariusi àti Artasasta àwọn ọba Persia pọ̀. 15 A parí ilé Olúwa ní ọjọ́ kẹta, oṣù Addari tí í se oṣù kejì ní ọdún kẹfà ti ìjọba ọba Dariusi.

16 Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Israẹli—àwọn àlùfáà, àwọn Lefi àti àwọn ìgbèkùn tí ó padà, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀. 17 Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù, igba àgbò àti irinwó (400) akọ ọ̀dọ́-àgùntàn, àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli, àgbò méjìlá, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Israẹli. 18 Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpín wọ́n àti àwọn Lefi sì ẹgbẹẹgbẹ́ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mose.

19 Ní ọjọ́ kẹrìnlá ti oṣù Nisani, àwọn tí a kó ní ìgbèkùn ṣe ayẹyẹ àjọ ìrékọjá. 20 Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì jẹ́ mímọ́. Àwọn ará Lefi pa ọ̀dọ́-àgùntàn ti àjọ ìrékọjá fún gbogbo àwọn tí a kó ní ìgbèkùn, fún àwọn àlùfáà arákùnrin wọn àti fún ara wọn. 21 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó ti dé láti ìgbèkùn jẹ ẹ́ lápapọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ti ya ara wọn kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ àìmọ́ ti àwọn kèfèrí aládùúgbò wọn láti wá Olúwa Ọlọ́run Israẹli. 22 Fún ọjọ́ méje, wọ́n ṣe ayẹyẹ àkàrà àìwú pẹ̀lú àjẹtì àkàrà. Nítorí tí Olúwa ti kún wọn pẹ̀lú ayọ̀ nípa yíyí ọkàn ọba Asiria padà, tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ ilé Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.

Saamu 48

Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora.

1 Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn

ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.

2  Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀,

ayọ̀ gbogbo ayé,

òkè Sioni, ní ìhà àríwá

ní ìlú ọba ńlá.

3 Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀;

ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.

4 Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀,

wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ.

5 Wọn rí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n,

a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ.

6 Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀,

ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.

7 Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi,

wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.

8 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́,

bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,

ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun

ní ìlú Ọlọ́run wa,

Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela.

9 Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run,

àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ.

10 Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run,

ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé,

ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo.

11 Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀

kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùn

nítorí ìdájọ́ rẹ.

12 Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀,

ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.

13 Kíyèsi odi rẹ̀,

kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀

kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀.

14 Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé,

Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.

Saamu 81

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu.

1 Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa

ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!

2 Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá,

tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.

3 Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun

àní nígbà tí a yàn;

ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú.

4 Èyí ni àṣẹ fún Israẹli,

àti òfin Ọlọ́run Jakọbu.

5 Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu

nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já.

Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.

6 Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín,

a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.

7 Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là,

mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá,

mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela.

8 “Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín,

bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli.

9 Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín;

ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.

10 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,

ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti.

Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.

11 “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;

Israẹli kò ní tẹríba fún mi.

12 Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn

láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.

13 “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi

bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,

14 ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn

kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!

15 Àwọn tí ó kórìíra Olúwa yóò tẹríba níwájú rẹ̀.

Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé.

16 Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín

èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”

Saamu 146

1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Fi ìyìn fún Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

2 Èmi yóò yin Olúwa ní gbogbo ayé mi,

èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láààyè.

3 Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé,

àní, ọmọ ènìyàn,

lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.

4 Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀,

ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo.

5 Ìbùkún ni fún ẹni tí

Ọlọ́run Jakọbu ń ṣe ìrànlọ́wọ́ rẹ̀

tí ìrètí rẹ̀ wà nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

6 Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé,

òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn,

ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé.

7 Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára,

tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa,

Olúwa, tú àwọn oǹdè sílẹ̀,

8 Olúwa mú àwọn afọ́jú ríran,

Olúwa, gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ ga,

Olúwa fẹ́ràn àwọn olódodo.

9 Olúwa ń dá ààbò bo àwọn àlejò

ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí

ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

10 Olúwa jẹ ọba títí láé;

Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni, àti fún gbogbo ìran.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.